Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Ta ni Àwọn Ènìyàn Ń Sọ Pé Mo Jẹ́?”

“Ta ni Àwọn Ènìyàn Ń Sọ Pé Mo Jẹ́?”

“Ta ni Àwọn Ènìyàn Ń Sọ Pé Mo Jẹ́?”

KÉRÉSÌMESÌ tún ti dé o. Àwọn èèyàn jákèjádò ayé yàn láti ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí kan. Ọjọ́ ìbí ta ni? Ṣé ti Ọmọ Ọlọ́run ni àbí ti Júù olùfọkànsìn kan tó fẹ́ ṣàtúnṣe ẹ̀sìn tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń ṣe lágbègbè rẹ̀ ní ọ̀rúndún kìíní? Ṣé ọjọ́ ìbí ẹnì kan tó ń gbèjà àwọn òtòṣì ni, àbí ti ọlọ̀tẹ̀ kan tó jẹ́ ewu fún Ilẹ̀ Ọba Róòmù débi pe pípa ni wọ́n pa á, ó ha sì lè jẹ́ ti amòye kan tó ń fọ́nnu pé òun ní ìmọ̀, pé ọgbọ́n sì kún inú òun? O ní ìdí gúnmọ́ láti ṣe kàyéfì pé, ‘Ní ti tòótọ́, ta ni Jésù Kristi?’

Jésù alára fẹ́ mọ báwọn èèyàn ṣe máa dáhùn ìbéèrè yẹn. Ìgbà kan wà tó bi àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ta ni àwọn ènìyàn ń sọ pé mo jẹ́?” (Máàkù 8:27) Kí nìdí tó fi béèrè ìbéèrè yẹn? Ọ̀pọ̀ èèyàn ti sá padà lẹ́yìn rẹ̀. Ọkàn àwọn mìíràn ti pòrúurùu, inú wọn ò sì dùn sí i mọ́ nítorí pé kò jẹ́ kí wọ́n fi òun jọba. Yàtọ̀ síyẹn, nígbà táwọn ọ̀tá rẹ̀ gbéjà kò ó, Jésù ò fi àmì kankan hàn látọ̀run láti jẹ́ kí wọ́n mọ ẹni tí òun jẹ́. Nítorí náà, nígbà tí wọ́n dáhùn ìbéèrè yẹn, kí ni àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ sọ nípa irú ẹni tó jẹ́? Wọ́n mẹ́nu kan díẹ̀ lára àwọn èrò tó gbilẹ̀ láàárín àwọn ènìyàn, wọ́n ní: “Àwọn kan sọ pé Jòhánù Oníbatisí, àwọn mìíràn Èlíjà, síbẹ̀ àwọn mìíràn Jeremáyà tàbí ọ̀kan nínú àwọn wòlíì.” (Mátíù 16:13, 14) Wọn ò mẹ́nu kan ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ ìṣáátá táwọn èèyàn ń sọ kiri nígbà yẹn

nípa Jésù ní Palẹ́sìnì—wọ́n pè é ní asọ̀rọ̀-òdì, atannijẹ, wòlíì èké, kódà wọ́n pè é ní wèrè.

Onírúurú Ohun Tí Wọ́n Ń Sọ Nípa Jésù

Ká ní Jésù tún fẹ́ béèrè ìbéèrè kan náà lóde òní, ó le sọ ọ́ lọ́nà mìíràn pé: “Ta ni àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ń sọ pé mo jẹ́?” Lẹ́ẹ̀kan sí i, ó ṣeé ṣe kí ìdáhùn náà jẹ́: Onírúurú èrò tó yàtọ̀ síra ló wà. David Tracy tó wà ní Yunifásítì Chicago sọ pé: “Onírúurú ènìyàn ló ti ní èrò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, tí wọ́n sì ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ tó yàtọ̀ síra nípa Jésù, nípa ohun tó sọ àti ohun tó ṣe. Jálẹ̀ ọ̀rúndún tó kọjá ni àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ti gbé ọ̀pọ̀ àlàyé dídíjú karí àjọṣepọ̀ láàárín ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà, àbùdá ọmọ aráyé àti ìmọ̀ ìjìnlẹ̀, láti lè rí ìdáhùn sí ìbéèrè náà nípa ẹni tí Jésù jẹ́ gan-an. Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ta ni wọ́n wá rò pé Jésù jẹ́ gan-an?

Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan gbà pé Jésù inú ìtàn jẹ́ wòlíì ẹlẹ́sìn Júù kan tó ń wàásù ìrònúpìwàdà nítorí pé òpin ayé ti sún mọ́lé. Àmọ́, wọn ò gbà pé òun ni Ọmọ Ọlọ́run, Mèsáyà, àti Olùtúnniràpadà. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ló ń ṣiyèméjì nípa ìtàn Bíbélì tó sọ pé ọ̀run ni Jésù ti wá sáyé àti pé ó jíǹde. Lójú àwọn mìíràn, Jésù wulẹ̀ jẹ́ ọkùnrin kan tó jẹ́ pé nípasẹ̀ ìgbésí ayé àwòfiṣàpẹẹrẹ tó gbé àti àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀, ó ṣeé ṣe fún un láti dá àwọn ẹ̀sìn kan sílẹ̀, tí gbogbo wọ́n sì wá para pọ̀ di ẹ̀sìn Kristẹni ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀. Gẹ́gẹ́ bó tún ṣe wà nínú ìwé Theology Today, àní, àwọn mìíràn ń wo Jésù bí “alárìíwísí, amòye tó ń fẹsẹ̀ palẹ̀ kiri, tàbí mẹ̀kúnnù kan tó jẹ́ aláwo; ẹni tó ń kẹ́gbẹ́ jọ, akéwì kan tó ń ṣe lámèyítọ́ ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà tàbí alágbárí kan tó ń fi ọ̀rọ̀ dídùn yí àwọn gbáàtúù lérò padà láwọn abúlé Palẹ́sínì tí rògbòdìyàn ti sábà máa ń bẹ́ sílẹ̀.”

Àwọn èròǹgbà mìíràn tún wà tó tún burú ju ìyẹn lọ. Àwòrán Jésù aláwọ̀ dúdú ti dénú orin ọlọ́rọ̀ wótòwótò, wọ́n sì ti gbẹ́ ẹ ní ère sáwọn ìlú ńlá, kódà wọ́n ń jó ijó rẹ̀. a Àwọn mìíràn tiẹ̀ ń sọ pé obìnrin ni Jésù. Ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ọdún 1993, àwọn tó ṣèbẹ̀wò sí Ibi Ìpàtẹ Ọjà Orange County ní California rí ère kan tí wọ́n pè ní ti “Christie,” ìyẹn ère abo “Kristi” tó wà ní ìhòòhò goloto lórí àgbélébùú. Láàárín àkókò kan náà ni wọ́n tẹ́ fádà “Christa”—ìyẹn abo “Jésù” tí wọ́n kàn mọ́ àgbélébùú—sí New York. Àwọn ère méjèèjì ló dá ọ̀pọ̀ àríyànjiyàn sílẹ̀. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1999, àwọn tó ń rajà ń rí ìwé kan “nípa ìfẹ́ [tí] Ọ̀dọ́mọdé Jésù àti ajá rẹ̀ tó ń jẹ́ Áńgẹ́lì ní fún ara wọn.” Àjọṣe tó wà láàárín wọn ni wọ́n ṣàpèjúwe gẹ́gẹ́ bí èyí tí “ó wúni lórí nípa tẹ̀mí, tó sì ń fi bí ọ̀dọ́mọdé náà àti ajá náà ṣe múra àtifi ẹ̀mí ara wọn rúbọ fún ara wọn hàn.”

Ṣé Bẹ́ẹ̀ Ló Ṣe Pàtàkì Tó Ni?

Èé ṣe tó fi yẹ kó o nífẹ̀ẹ́ sí mímọ ẹni tí Jésù jẹ́ nígbà yẹn lọ́hùn-ún àti ẹni tó jẹ́ nísinsìnyí? Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Napoleon wí, ìdí kan ni pé “Jésù Kristi ti nípa lórí àwọn ọmọlẹ́yìn Rẹ̀, ó sì ti darí wọn láìsí òun fúnra Rẹ̀ nítòsí.” Nípa ọ̀nà gbígbéṣẹ́ tó gbà kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ àti irú ìgbésí ayé tó gbé, Jésù ti nípa tó lágbára lórí ìgbésí ayé àìmọye bílíọ̀nù ènìyàn fún ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún ọdún méjì báyìí. Òǹkọ̀wé kan sọ ọ́ lọ́nà ṣíṣe wẹ́kú pé: “Gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ ogun tó tíì tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ rí, gbogbo ọmọ ogun ojú omi tí a tíì kó jọ rí, àti gbogbo ìgbìmọ̀ aṣòfin tó tíì jókòó rí, gbogbo ọba tó tíì jẹ rí, gbogbo wọn lápapọ̀ kò tíì nípa lórí ìgbésí ayé ènìyàn lórí ilẹ̀ ayé lọ́nà lílágbára bẹ́ẹ̀.”

Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ó yẹ kó o mọ ẹni tí Jésù jẹ́ nítorí pé yóò ní ipa tààràtà lórí ọjọ́ ọ̀la rẹ. O láǹfààní láti di ọmọ abẹ́ ìjọba ọ̀run kan tí a ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀—ìyẹn ni Ìjọba Ọlọ́run lábẹ́ Jésù. Ilẹ̀ ayé wa tó kún fún wàhálà yìí yóò padà di èyí tó kún fún onírúurú ohun alààyè pẹ̀lú àjọṣepọ̀ tó dán mọ́rán láàárín wọn lábẹ́ ìdarí Jésù. Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì mú un dá wa lójú pé Ìjọba Jésù yóò bọ́ àwọn tí ebi ń pa ní àbọ́yó, yóò bójú tó àwọn òtòṣì, yóò mú àwọn aláìsàn lára dá, yóò sì jí àwọn òkú dìde.

Ó dájú pé wàá fẹ́ mọ irú ẹni tó máa jẹ́ olórí ìjọba tó máa wúlò fún wa tó bẹ́ẹ̀. Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mọ ẹni tí Jésù jẹ́ ní ti gidi.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Láti mọ bí wọ́n ṣe sọ pé Jésù rí, wo àpilẹ̀kọ náà “Báwo ni Jésù Ṣe Rí?,” nínú ẹ̀dà Jí! ti December 8, 1998.