Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Ìbùkún Ìhìn Rere

Àwọn Ìbùkún Ìhìn Rere

Àwọn Ìbùkún Ìhìn Rere

“Jèhófà ti fòróró yàn mí láti sọ ìhìn rere fún àwọn ọlọ́kàn tútù. Ó ti rán mi láti di ọgbẹ́ àwọn oníròbìnújẹ́-ọkàn, . . . láti tu gbogbo àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ nínú.”—AÍSÁYÀ 61:1, 2.

1, 2. (a) Kí ni Jésù fi hàn pé òun jẹ́, lọ́nà wo sì ni? (b) Àwọn ìbùkún wo ni ìhìn rere tí Jésù ń kéde rẹ̀ mú wá?

 JÉSÙ wà nínú sínágọ́gù ní Násárétì lọ́jọ́ sábáàtì kan, nígbà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí àkọsílẹ̀ náà wí, “a fi àkájọ ìwé wòlíì Aísáyà lé e lọ́wọ́, ó sì ṣí àkájọ ìwé náà, ó sì rí ibi tí a ti kọ ọ́ pé: ‘Ẹ̀mí Jèhófà ń bẹ lára mi, nítorí tí ó fòróró yàn mí láti polongo ìhìn rere.’” Jésù tún ka àsọtẹ́lẹ̀ náà síwájú sí i. Lẹ́yìn náà ó jókòó, ó sì wí pé: “Lónìí, ìwé mímọ́ tí ẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ gbọ́ tán yìí ní ìmúṣẹ.”—Lúùkù 4:16-21.

2 Báyìí ni Jésù ṣe fi hàn pé òun ni ajíhìnrere tí a sọ tẹ́lẹ̀ náà, ìyẹn ẹni tó ń sọ ìhìn rere, tó sì ń tu àwọn èèyàn nínú. (Mátíù 4:23) Ẹ ò rí i pé ìhìn rere ni Jésù ń sọ lóòótọ́! Ó sọ fún àwọn olùgbọ́ rẹ̀ pé: “Èmi ni ìmọ́lẹ̀ ayé. Ẹni tí ó bá ń tọ̀ mí lẹ́yìn kì yóò rìn nínú òkùnkùn lọ́nàkọnà, ṣùgbọ́n yóò ní ìmọ́lẹ̀ ìyè.” (Jòhánù 8:12) Ó tún sọ pé: “Bí ẹ bá dúró nínú ọ̀rọ̀ mi, ọmọ ẹ̀yìn mi ni ẹ̀yin jẹ́ ní ti tòótọ́, ẹ ó sì mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì dá yín sílẹ̀ lómìnira.” (Jòhánù 8:31, 32) Bẹ́ẹ̀ ni o, Jésù lẹni tí ń sọ “àwọn àsọjáde ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòhánù 6:68, 69) Dájúdájú, ìbùkún tó ṣeyebíye gbáà ni ìmọ́lẹ̀, ìyè àti òmìnira jẹ́!

3. Ìhìn rere wo làwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù wàásù rẹ̀?

3 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn ń bá iṣẹ́ ìwàásù Jésù lọ lẹ́yìn Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa. Wọ́n wàásù “ìhìn rere ìjọba” náà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtàwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè. (Mátíù 24:14; Ìṣe 15:7; Róòmù 1:16) Àwọn tó tẹ́wọ́ gbà á wá mọ Jèhófà Ọlọ́run. Wọ́n bọ́ lọ́wọ́ oko ẹrú ìsìn, wọ́n sì di ara orílẹ̀-èdè tẹ̀mí tuntun náà, “Ísírẹ́lì Ọlọ́run,” tí àwọn mẹ́ńbà rẹ̀ ní ìrètí ṣíṣàkóso títí láé ní ọ̀run pẹ̀lú Olúwa wọn, Jésù Kristi. (Gálátíà 5:1; 6:16; Éfésù 3:5-7; Kólósè 1:4, 5; Ìṣípayá 22:5) Àwọn ìbùkún tó ṣeyebíye nìwọ̀nyẹn lóòótọ́!

Iṣẹ́ Ìjíhìnrere Lóde Òní

4. Ọ̀nà wo ni a gbà ń mú àṣẹ náà láti wàásù ìhìn rere ṣẹ lóde òní?

4 Lóde òní, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, tí “ogunlọ́gọ̀ ńlá” ti “àwọn àgùntàn mìíràn” tí ń pọ̀ sí i ń tì lẹ́yìn, ń bá a lọ láti mú iṣẹ́ tá a gbé lé Jésù fúnra rẹ̀ lọ́wọ́ nínú àsọtẹ́lẹ̀ ṣẹ. (Ìṣípayá 7:9; Jòhánù 10:16) Àbájáde rẹ̀ ni pé, ìhìn rere náà ti di èyí tá a ti wàásù rẹ̀ débi gbígbòòrò ju ti ìgbàkigbà rí lọ. Igba ó lé márùndínlógójì [235] ilẹ̀ àti àwọn ìpínlẹ̀ ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti jáde lọ “láti sọ ìhìn rere fún àwọn ọlọ́kàn tútù . . . , láti di ọgbẹ́ àwọn oníròbìnújẹ́-ọkàn, láti pòkìkí ìdásílẹ̀ lómìnira fún àwọn tí a mú ní òǹdè àti ìlajúsílẹ̀ rekete àní fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n; láti pòkìkí ọdún ìtẹ́wọ́gbà níhà ọ̀dọ̀ Jèhófà àti ọjọ́ ẹ̀san níhà ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wa; láti tu gbogbo àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ nínú.” (Aísáyà 61:1, 2) Nítorí náà, iṣẹ́ ìjíhìnrere táwa Kristẹni ń ṣe ń bá a lọ láti mú àwọn ìbùkún wá fún ọ̀pọ̀ ènìyàn àti láti fún “àwọn tí ó wà nínú ìpọ́njú èyíkéyìí” ní ojúlówó ìtùnú.—2 Kọ́ríńtì 1:3, 4.

5. Nínú ọ̀ràn wíwàásù ìhìn rere, báwo làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe yàtọ̀ sí àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì?

5 Òótọ́ ni pé àwọn ṣọ́ọ̀ṣì máa ń ṣonígbọ̀wọ́ onírúurú ètò ìjíhìnrere. Ọ̀pọ̀ ló máa ń rán àwọn míṣọ́nnárì jáde láti sọ àwọn èèyàn di aláwọ̀ṣe ní àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn. Bí àpẹẹrẹ, ìwé ìròyìn The Orthodox Christian Mission Center Magazine ròyìn ìgbòkègbodò àwọn míṣọ́nnárì ìjọ Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ní Madagascar, gúúsù Áfíríkà, Tanzania, àti Zimbabwe. Àmọ́, nínú Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì, bó ṣe rí nínú àwọn ṣọ́ọ̀ṣì yòókù, ìwọ̀nba kéréje lára àwọn mẹ́ńbà wọn ló ń kópa nínú irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀. Ní ìyàtọ̀ pátápátá sí ìyẹn, gbogbo Ẹlẹ́rìí tó ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà ló ń kópa nínú iṣẹ́ ìjíhìnrere. Wọ́n mọ̀ pé kíkéde ìhìn rere náà jẹ́ ẹ̀rí tó ń fi bí ìgbàgbọ́ wọn ṣe jẹ́ ojúlówó tó hàn. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ọkàn-àyà ni a fi ń lo ìgbàgbọ́ fún òdodo, ṣùgbọ́n ẹnu ni a fi ń ṣe ìpolongo ní gbangba fún ìgbàlà.” Lẹ́nu kan, ìgbàgbọ́ tí kò bá ti lè súnni ṣiṣẹ́ jẹ́ òkú.—Róòmù 10:10; Jákọ́bù 2:17.

Ìhìn Rere Tó Ń Mú Àwọn Ìbùkún Ayérayé Wá

6. Ìhìn rere wo ni a ń wàásù rẹ̀ lóde òní?

6 Ìhìn rere táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń wàásù ni ìhìn rere tó dára jù lọ. Wọ́n ń ṣí Bíbélì wọn, wọ́n sì ń fi han àwọn tó ní etí ìgbọ́ àti àyà ìgbàṣe pé Jésù fi ẹ̀mí rẹ̀ rúbọ kí ọ̀nà lè là fún aráyé láti tọ Ọlọ́run lọ, láti rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà, àti láti ní ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun. (Jòhánù 3:16; 2 Kọ́ríńtì 5:18, 19) Wọ́n ń kéde pé a ti fìdí Ìjọba Ọlọ́run múlẹ̀ ni ọ̀run, lábẹ́ Jésù Kristi, Ọba tí a fòróró yàn, àti pé láìpẹ́ yóò mú ìwà ibi kúrò lórí ilẹ̀ ayé, yóò sì rí sí i pé a mú Párádísè padà bọ̀ sípò. (Ìṣípayá 11:15; 21:3, 4) Ní ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, wọ́n ń sọ fún àwọn aládùúgbò wọn pé ìsinsìnyí ni “ọdún ìtẹ́wọ́gbà níhà ọ̀dọ̀ Jèhófà” nígbà tí àǹfààní ṣì wà fún aráyé láti gbọ́ ìhìn rere náà. Wọ́n tún ń kìlọ̀ pé láìpẹ́ “ọjọ́ ẹ̀san níhà ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wa” yóò dé, nígbà tí Jèhófà yóò pa àwọn olubi tí kò ronú pìwà dà run.—Sáàmù 37:9-11.

7. Ìrírí wo ló fi ìṣọ̀kan tó wà láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà hàn, kí sì nìdí tí wọ́n fi ní irú ìṣọ̀kan bẹ́ẹ̀?

7 Nínú ayé tó kún fún rògbòdìyàn àti àjálù, ìhìn rere yìí nìkan ló ní àwọn àǹfààní ayérayé nínú. Àwọn tó tẹ́wọ́ gbà á ń di ara ẹgbẹ́ àwọn ará ti àwọn Kristẹni tó wà ní ìṣọ̀kan kárí ayé, tí wọn kì í jẹ́ kí ìyàtọ̀ láàárín orílẹ̀-èdè, ẹ̀yà, tàbí ipò ọrọ̀ ajé pín wọn níyà. Wọ́n ti ‘fi ìfẹ́ wọ ara wọn láṣọ, nítorí pé ìfẹ́ ni ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé.’ (Kólósè 3:14; Jòhánù 15:12) A rí ẹ̀rí èyí ní orílẹ̀-èdè kan nílẹ̀ Áfíríkà lọ́dún tó kọjá. Ìró ìbọn ló jí àwọn tó ń gbé olú ìlú orílẹ̀-èdè náà ní òwúrọ̀ ọjọ́ kan. Àwọn kan fẹ́ dìtẹ̀ gbàjọba. Nígbà tí ọ̀ràn náà wá di ti kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà, wọ́n bá ìdílé Ẹlẹ́rìí kan wí pé wọ́n gba àwọn Ẹlẹ́rìí ẹlẹgbẹ́ wọn tó jẹ́ ẹ̀yà mìíràn sílé. Ìdílé náà fèsì pé: “Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni gbogbo àwa tá a jọ wà nínú ilé.” Inú ẹ̀yà téèyàn ti wá kò já mọ́ nǹkan kan lójú tiwọn; ìfẹ́ Kristẹni—ìyẹn títu àwọn tó wà nípò ìṣòro nínú ni wọ́n kà sí pàtàkì. Ẹbí wọn kan tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí sọ pé: “Mẹ́ńbà gbogbo ẹ̀sìn tó kù ló da àwọn olùjọsìn ẹlẹgbẹ́ wọn. Kìkì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni kò ṣe bẹ́ẹ̀.” Ọ̀pọ̀ irú ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn là ń gbọ́ láti àwọn orílẹ̀-èdè tí ogun abẹ́lé ti pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ, tó ń fi hàn pé lóòótọ́ ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà “ní ìfẹ́ fún gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ará.”—1 Pétérù 2:17.

Ìhìn Rere Náà Ń Yí Àwọn Èèyàn Padà

8, 9. (a) Ìyípadà wo ni àwọn tó tẹ́wọ́ gba ìhìn rere náà ń ṣe? (b) Àwọn ìrírí wo ló fi agbára ìhìn rere náà hàn?

8 Ìhìn rere náà ní í ṣe pẹ̀lú ohun tí Pọ́ọ̀lù pè ní “ìyè ti ìsinsìnyí àti ti èyí tí ń bọ̀.” (1 Tímótì 4:8) Kì í ṣe pé ó fúnni ní àgbàyanu ìrètí tí ó dájú fún ọjọ́ iwájú nìkan ni, àmọ́ ó tún ń jẹ́ kí “ìyè ti ìsinsìnyí” sunwọ̀n sí i. Lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló ń darí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, láti mú kí ìgbésí ayé wọn wà níṣọ̀kan pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run. (Sáàmù 119:101) Àkópọ̀ ìwà wọn ń di tuntun bí wọ́n ṣe ń mú àwọn ànímọ́ bí òdodo àti ìdúróṣinṣin dàgbà.—Éfésù 4:24.

9 Gbé àpẹẹrẹ Franco yẹ̀ wò. Ìṣòro rẹ̀ ni pé ó máa ń tètè bínú. Bí nǹkan kan bá ṣẹlẹ̀ pẹ́nrẹ́n, ńṣe ló máa tutọ́ sókè táá fojú gbà á, táá sì máa fọ́ àwọn nǹkan. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í bá ìyàwó rẹ̀ ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ànímọ́ Kristẹni tí Franco rí lára wọn ràn án lọ́wọ́ láti rí i pé òun ní láti ṣàtúnṣe. Ó kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ wọn, ó sì ṣeé ṣe fún un láti ní àwọn èso ti ẹ̀mí bí àlàáfíà àti ìkóra-ẹni-níjàánu níkẹyìn. (Gálátíà 5:22, 23) Ó wà lára àwọn ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta dín mẹ́jọ [492] èèyàn tó ṣèrìbọmi ní orílẹ̀-èdè Belgium láàárín ọdún iṣẹ́ ìsìn 2001. Gbé ọ̀ràn ti Alejandro náà yẹ̀ wò. Ọ̀dọ́kùnrin yìí di ajoògùnyó débi pé ó máa ń lọ sórí ààtàn, táá máa ṣa ohunkóhun tó bá rí níbẹ̀, kí ó lè tà á láti rówó fi ra oògùn olóró. Nígbà tí Alejandro wà lọ́mọ ọdún méjìlélógún, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ pé kó wá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì gbà. Ó ń ka Bíbélì lójoojúmọ́, ó sì ń lọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni. Ojú ẹsẹ̀ ló jáwọ́ nínú gbogbo ìwàkíwà tó ń hù, débi pé kó tó pé oṣù mẹ́fà, ó ti tóótun láti kópa nínú iṣẹ́ wíwàásù ìhìn rere—ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn 10,115 èèyàn tó ṣe bẹ́ẹ̀ ní Panama lọ́dún tó kọjá.

Ìhìn Rere Náà—Ìbùkún fún Àwọn Ọlọ́kàn Tútù

10. Irú àwọn èèyàn wo ló ń tẹ́wọ́ gba ìhìn rere, báwo sì ni ìṣesí wọn ṣe ń yí padà?

10 Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé a ó wàásù ìhìn rere náà fún àwọn ọlọ́kàn tútù. Àwọn wo làwọn ọlọ́kàn tútù wọ̀nyí? Àwọn ni ìwé Ìṣe pè ní àwọn tó “ní ìtẹ̀sí-ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun.” (Ìṣe 13:48) Wọ́n jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ tá a máa ń rí nínú gbogbo àwùjọ, tí wọ́n máa ń ṣí ọkàn wọn payá láti gba ìhìn òtítọ́. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ gbà pé ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ń mú àwọn ìbùkún dídọ́ṣọ̀ wá ju ohunkóhun tí ayé lè fúnni lọ. (1 Jòhánù 2:15-17) Àmọ́, báwo làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń dé inú ọkàn àwọn èèyàn nínú iṣẹ́ ìwàásù wọn?

11. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Pọ́ọ̀lù wí, báwo ló ṣe yẹ ká máa wàásù ìhìn rere?

11 Tóò, gbé àpẹẹrẹ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù yẹ̀ wò. Ó kọ̀wé sí àwọn ará Kọ́ríńtì pé: “Nígbà tí mo wá sí ọ̀dọ̀ yín, ẹ̀yin ará, èmi kò wá pẹ̀lú ọ̀rọ̀ àsọrégèé tàbí ọgbọ́n ní pípolongo àṣírí ọlọ́wọ̀ Ọlọ́run fún yín. Nítorí mo pinnu láti má ṣe mọ ohunkóhun láàárín yín àyàfi Jésù Kristi, ẹni tí a sì kàn mọ́gi.” (1 Kọ́ríńtì 2:1, 2) Pọ́ọ̀lù kò gbìyànjú láti fi ẹ̀kọ́ rẹ̀ ṣe fọ́rífọ́rí fún àwọn olùgbọ́ rẹ̀. Kò fi ohunkóhun tó yàtọ̀ sí àwọn òtítọ́ Ọlọ́run tó dájú kọ́ni, àwọn òtítọ́ tá a ń kà nínú Bíbélì lónìí. Tún kíyè sí ìṣírí tí Pọ́ọ̀lù fún Tímótì, ajíhìnrere ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé: “Wàásù ọ̀rọ̀ náà, wà lẹ́nu rẹ̀ ní kánjúkánjú.” (2 Tímótì 4:2) Tímótì ní láti wàásù “ọ̀rọ̀ náà,” ìyẹn ìhìn Ọlọ́run. Pọ́ọ̀lù tún kọ̀wé sí Tímótì pé: “Sa gbogbo ipá rẹ láti fi ara rẹ hàn fún Ọlọ́run ní ẹni tí a tẹ́wọ́ gbà, aṣiṣẹ́ tí kò ní ohun kankan láti tì í lójú, tí ń fi ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́.”—2 Tímótì 2:15.

12. Báwo ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà òde òní ṣe ń tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù àti àpẹẹrẹ rẹ̀?

12 Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù àti ọ̀rọ̀ tó sọ fún Tímótì. Wọ́n mọ bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe lágbára tó, wọ́n sì ń lò ó dáadáa bí wọ́n ṣe ń gbìyànjú láti fi ìrètí àti ọ̀rọ̀ ìtùnú yíyẹ han àwọn aládùúgbò wọn. (Sáàmù 119:52; 2 Tímótì 3:16, 17; Hébérù 4:12) Ní ti tòótọ́, ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n ń lo àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kí àwọn olùfìfẹ́hàn lè túbọ̀ jèrè ìmọ̀ Bíbélì nígbà tí ọwọ́ wọn bá dilẹ̀. Àmọ́ ọ̀rọ̀ inú Ìwé Mímọ́ ni wọ́n máa ń gbìyànjú láti fi han àwọn èèyàn. Wọ́n mọ̀ pé Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí yóò gún ọkàn àwọn onírẹ̀lẹ̀ ní kẹ́ṣẹ́. Lílò ó ní ọ̀nà yìí sì ń fún ìgbàgbọ́ àwọn fúnra wọn lókun pẹ̀lú.

“Tu Gbogbo Àwọn Tí Ń Ṣọ̀fọ̀ Nínú”

13. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wo ló wáyé lọ́dún 2001, tó fi di dandan láti tu àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ nínú?

13 Oríṣiríṣi àjálù ló já lu àwọn èèyàn lọ́dún 2001. Ìdí nìyẹn tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi nílò ìtùnú. Irú àjálù bẹ́ẹ̀ ni ìṣẹ̀lẹ̀ mérìíyìírí tó wáyé ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ní oṣù September ọdún tó kọjá jẹ́. Èyí tó wáyé nígbà tí àwọn apániláyà kọ lu ilé ìtajà tó tóbi jù lọ lágbàáyé, èyí tá a mọ̀ sí World Trade Center nílùú New York àti orílé-iṣẹ́ tó ń rí sọ́ràn ààbò, ìyẹn Pentagon nítòsí Washington, D.C. Ẹ wo ìpayà ńláǹlà tí àjálù wọ̀nyẹn kó bá gbogbo orílẹ̀-èdè náà! Nígbà tí irú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ wáyé, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tún sapá láti ṣe iṣẹ́ tí a rán wọn, ìyẹn ni láti “tu gbogbo àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ nínú.” Àwọn ìrírí díẹ̀ yóò fi bí wọ́n ṣe ṣe èyí hàn.

14, 15. Báwo ló ṣe ṣeé ṣe fún àwọn Ẹlẹ́rìí láti fi Ìwé Mímọ́ tu àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ nínú nígbà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀?

14 Ẹlẹ́rìí kan tó jẹ́ ajíhìnrere alákòókò kíkún lọ bá obìnrin kan ní ọ̀nà ẹlẹ́sẹ̀, ó sì béèrè èrò obìnrin náà nípa ohun tí àwọn apániláyà ṣe ní lọ́ọ́lọ́ọ́. Ńṣe lobìnrin náà bú sẹ́kún. Ó ní ó ba òun nínú jẹ́ gan-an ni, ó sì wu òun láti ṣèrànwọ́ lọ́nà kan ṣáá. Ẹlẹ́rìí náà sọ fún un pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ sí gbogbo wa pátá, ó sì ka Aísáyà 61:1, 2. Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí yìí mọ́gbọ́n dání lójú obìnrin náà, ó sọ pé gbogbo èèyàn ló ń ṣọ̀fọ̀ báyìí. Ó gba ìwé àṣàrò kúkúrú kan, ó sì ní kí Ẹlẹ́rìí náà bẹ òun wò nílé.

15 Àwọn Ẹlẹ́rìí méjì tí wọ́n wà lóde ẹ̀rí bá ọkùnrin kan níbi iṣẹ́ rẹ̀. Wọ́n béèrè bí àwọn bá lè fi ọ̀rọ̀ ìtùnú hàn án látinú Ìwé Mímọ́ nítorí àjálù tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí ilé ìtajà World Trade Center náà. Nígbà tó gbà pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n ka 2 Kọ́ríńtì 1:3-7 fún un, lára ọ̀rọ̀ tó wà níbẹ̀ ni: “Ìtùnú . . . nípasẹ̀ Kristi pọ̀ gidigidi.” Inú ọkùnrin náà dùn gan-an pé ọ̀rọ̀ ìtùnú ni àwọn Ẹlẹ́rìí tó jẹ́ aládùúgbò òun ń sọ fún àwọn ẹlòmíràn, ó sì sọ pé: “Kí Ọlọ́run bù kún iṣẹ́ àtàtà tí ẹ̀ ń ṣe.”

16, 17. Àwọn ìrírí méjì wo ló fi hàn pé Bíbélì ní agbára láti ran àwọn tínú wọn bà jẹ́ nítorí àjálù lọ́wọ́?

16 Ẹlẹ́rìí kan tó ń padà bẹ àwọn èèyàn wò bá ọmọ obìnrin kan tó ti fìfẹ́ hàn tẹ́lẹ̀ pàdé, ó sì ṣàlàyé fún un pé òun ń ṣàníyàn nípa bí àwọn aládùúgbò òun ti ń ṣe sí lẹ́yìn àjálù lọ́ọ́lọ́ọ́. Ó ya ọkùnrin náà lẹ́nu pé Ẹlẹ́rìí náà lè ráyè àtimáa bẹ àwọn èèyàn wò láti mọ bí wọ́n ṣe ń ṣe sí. Ó sọ pé itòsí ilé ìtajà World Trade Center náà lòún ti ń ṣiṣẹ́ nígbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé, òun sì fi ojú ara òun rí gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀. Nígbà tó béèrè ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìjìyà, Ẹlẹ́rìí náà ka àwọn ẹsẹ bíi mélòó kan fún un nínú Bíbélì, títí kan Sáàmù 37:39, tó kà pé: “Ọ̀dọ̀ Jèhófà sì ni ìgbàlà àwọn olódodo ti wá; òun ni odi agbára wọn ní àkókò wàhálà.” Ọkùnrin náà wá fi ohùn jẹ́jẹ́ béèrè àlàáfíà Ẹlẹ́rìí náà àti ìdílé rẹ̀, ó ní kó tún padà wá, ó sì fi ìmọrírì hàn fún wíwá tó wá.

17 Ẹlòmíràn lára ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀, tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tù nínú lẹ́yìn tí àwọn apániláyà náà ṣọṣẹ́ ni obìnrin kan tí àwọn Ẹlẹ́rìí bá pàdé nígbà tí wọ́n ń bẹ àwọn aládùúgbò wọn wò. Ohun tó ṣẹlẹ̀ náà bà á nínú jẹ́ gan-an, ó sì tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́ bí wọ́n ṣe ń ka Sáàmù 72:12-14 fún un pé: “Òun yóò dá òtòṣì tí ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ nídè, ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ pẹ̀lú, àti ẹnì yòówù tí kò ní olùrànlọ́wọ́. Òun yóò káàánú ẹni rírẹlẹ̀ àti òtòṣì, yóò sì gba ọkàn àwọn òtòṣì là. Yóò tún ọkàn wọn rà padà lọ́wọ́ ìnilára àti lọ́wọ́ ìwà ipá, ẹ̀jẹ̀ wọn yóò sì ṣe iyebíye ní ojú rẹ̀.” Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn mà fakíki o! Obìnrin náà ní kí àwọn Ẹlẹ́rìí ọ̀hún tún ẹsẹ náà kà lẹ́ẹ̀kan sí i, ó sì ní kí wọ́n wọlé wá, kí wọ́n lè máa bá ìjíròrò náà lọ. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lẹ́yìn ìjíròrò náà.

18. Báwo ni Ẹlẹ́rìí kan ṣe ran àwọn aládùúgbò rẹ̀ lọ́wọ́ nígbà tí wọ́n pè é láti ṣáájú wọn nínú àdúrà?

18 Ẹlẹ́rìí kan ń ṣiṣẹ́ nílé àrójẹ kan tó wà lágbègbè kan tí àwọn olówó pọ̀ sí, táwọn èèyàn kì í ti í fi bẹ́ẹ̀ tẹ́tí sí ìhìn rere Ìjọba náà tẹ́lẹ̀. Lẹ́yìn tí àwọn apániláyà náà ṣọṣẹ́, ìṣẹ̀lẹ̀ náà gbò wọ́n gan-an ládùúgbò yẹn. Ní alẹ́ ọjọ́ Friday lẹ́yìn àjálù náà, máníjà ilé àrójẹ náà ní kí gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ jáde síta, kí wọ́n mú àbẹ́là, kí wọ́n sì wà ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́ fún ìṣẹ́jú bíi mélòó kan ní ìrántí àwọn tó pàdánù ẹ̀mí wọn. Kó má bàa dà bí àfojúdi, Ẹlẹ́rìí náà jáde síta, àmọ́ ó rọra lọ dúró sí ibi ọ̀nà ẹlẹ́sẹ̀ láìfọhùn. Máníjà náà mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni, nítorí náà lẹ́yìn tí àkókò ìdákẹ́jẹ́ẹ́ náà parí, máníjà náà ní kó ṣáájú gbogbo wọn nínú àdúrà. Ẹlẹ́rìí náà gbà láti ṣe bẹ́ẹ̀. Nínú àdúrà rẹ̀, ó mẹ́nu kan ọ̀fọ̀ tó bá gbogbo ènìyàn náà, àmọ́ ó sọ pé kí àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ má ṣe banú jẹ́ láìsí ìrètí. Ó sọ̀rọ̀ nípa àkókò tí irú ìṣẹ̀lẹ̀ tó burú jáì bẹ́ẹ̀ kò ní wáyé mọ́, ó wá ní kí gbogbo wọn sún mọ́ Ọlọ́run ìtùnú nípasẹ̀ ìmọ̀ pípéye látinú Bíbélì. Lẹ́yìn tí wọ́n sọ pé “Àmín,” máníjà náà wá bá Ẹlẹ́rìí náà, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, ó dì mọ́ ọn, ó sì sọ pé òun ò tíì gbọ́ irú àdúrà tó dára tó báyẹn rí. Àwọn tó lé ní ọgọ́ta tó wà ní ìta ilé àrójẹ náà wá bá a pẹ̀lú.

Ìbùkún Ni Wọ́n Láwùjọ

19. Ìrírí wo ló fi hàn pé àwọn kan mọyì ìlànà gíga àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

19 Àgàgà ní àkókò tá a wà yìí, àwọn àwùjọ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wà ń jàǹfààní gan-an nínú wíwà níbẹ̀ wọn—gẹ́gẹ́ bí ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn ti sọ. Báwo làwọn èèyàn tó jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà, tí wọ́n jẹ́ aláìlábòsí, tí wọ́n sì ní ìwà rere kò fi ní ṣe àwùjọ láǹfààní? Ní orílẹ̀-èdè kan ní Àárín Gbùngbùn Éṣíà, àwọn Ẹlẹ́rìí bá aláṣẹ kan tó ti fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ pàdé. Ó ní ìgbà kan wà tí wọ́n yan òun láti lọ wádìí onírúurú ètò ẹ̀sìn. Nígbà tó wádìí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àìlábòsí àti ìwà rere wọn wú u lórí. Ó gbóṣùbà fún ìgbàgbọ́ wọn tó fẹsẹ̀ múlẹ̀, àti bí wọ́n ṣe gbé àwọn ẹ̀kọ́ wọn karí Ìwé Mímọ́. Ọkùnrin yìí gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

20. (a) Kí ni ìgbòkègbodò táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ròyìn lọ́dún tó kọjá fi hàn? (b) Kí ló fi hàn pé iṣẹ́ púpọ̀ ṣì wà láti ṣe, ojú wo la sì fi ń wo àǹfààní tá a ní láti wàásù?

20 Látinú àwọn ìrírí díẹ̀ tá a mẹ́nu kàn nínú àpilẹ̀kọ yìí, tó jẹ́ díẹ̀ lára ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìrírí tá a ti gbọ́, ó hàn gbangba pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe gudugudu méje nínú ọdún iṣẹ́ ìsìn 2001. a Wọ́n bá ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn sọ̀rọ̀. Wọ́n tu ọ̀pọ̀ àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ nínú, iṣẹ́ ìwàásù wọn sì yọrí sí rere. Àwọn 263,431 ló fi ìyàsímímọ́ wọn sí Ọlọ́run hàn nípa ṣíṣe batisí. Jákèjádò ayé, iye àwọn ajíhìnrere fi ohun tó lé ní ìpín kan ààbọ̀ nínú ọgọ́rùn-ún lọ sókè. Òtítọ́ náà pé àwọn 15,374,986 ló wá síbi Ìṣe Ìrántí ikú Jésù tí à ń ṣe lọ́dọọdún fi hàn pé iṣẹ́ ṣì pọ̀ láti ṣe. (1 Kọ́ríńtì 11:23-26) Ǹjẹ́ ká máa bá a lọ láti wá àwọn ọlọ́kàn tútù tí yóò tẹ́wọ́ gba ìhìn rere náà rí. Àti pé bí ọdún ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà bá ṣì ń bá a lọ, ká máa tẹ̀ síwájú láti tu àwọn “oníròbìnújẹ́-ọkàn” nínú. Ẹ ò rí i pé àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ la ní yìí! Dájúdájú, gbogbo wa la fara mọ́ ọ̀rọ̀ tí Aísáyà sọ pé: “Láìkùnà, èmi yóò yọ ayọ̀ ńláǹlà nínú Jèhófà. Ọkàn mi yóò kún fún ìdùnnú nínú Ọlọ́run mi.” (Aísáyà 61:10) Ǹjẹ́ kí Ọlọ́run máa lò wá nìṣó, bó ti ń mú àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣẹ pé: “Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ yóò mú kí òdodo àti ìyìn rú jáde ní iwájú gbogbo orílẹ̀-èdè.”—Aísáyà 61:11.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àtẹ ìsọfúnni tó wà ní ojú ìwé 19 sí 22 fi ìròyìn ìgbòkègbodò àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ọdún iṣẹ́ ìsìn 2001 hàn.

Ǹjẹ́ O Rántí?

• Báwo ni ìhìn rere tí Jésù wàásù rẹ̀ ṣe ṣàǹfààní fún àwọn ọlọ́kàn tútù?

• Ìbùkún wo làwọn tó tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ ìwàásù táwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ṣe ní ọ̀rúndún kìíní rí gbà?

• Báwo ni ìhìn rere náà ṣe ṣàǹfààní fún àwọn tó ní etí ìgbọ́ àti àyà ìgbàṣe lóde òní?

• Ojú wo la fi ń wo àǹfààní jíjẹ́ tá a jẹ́ ajíhìnrere?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 19-22]

ÌRÒYÌN ỌDÚN IṢẸ́ ÌSÌN 2001 TI ÀWA ẸLẸ́RÌÍ JÈHÓFÀ KÁRÍ AYÉ

(Wo àdìpọ̀)

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Gbogbo ìgbà làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń rántí ojúṣe wọn láti jíhìn rere

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Àwọn tó tẹ́wọ́ gba ìhìn rere náà ń dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ ará tó wà níṣọ̀kan kárí ayé