Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jèhófà ti fún Mi Ní “Agbára tí Ọ́ Ré Kọjá Ìwọ̀n ti Ẹ̀dá”

Jèhófà ti fún Mi Ní “Agbára tí Ọ́ Ré Kọjá Ìwọ̀n ti Ẹ̀dá”

Ìtàn Ìgbésí Ayé

Jèhófà ti fún Mi Ní “Agbára tí Ọ́ Ré Kọjá Ìwọ̀n ti Ẹ̀dá”

GẸ́GẸ́ BÍ HELEN MARKS ṢE SỌ Ọ́

Ooru mú gan-an lọ́jọ́ tá à ń wí yìí nígbà ẹ̀ẹ̀rùn ọdún 1986. Èmi nìkan ló wà lábẹ́ òrùlé kan táwọn aṣọ́bodè ń lò, ní ọ̀kan lára pápákọ̀ òfuurufú tó dá jù lọ ní Yúróòpù. Ìlú Tiranë ni mo wà, ìyẹn olú ìlú Albania, tó pe ara rẹ̀ ní “orílẹ̀-èdè tó kọ́kọ́ jẹ́ aláìgbà-pọ́lọ́run-wà lágbàáyé.”

ÀYÀ mi ń já, ọkàn mi ò sì balẹ̀, bí mo ṣe ń wo òṣìṣẹ́ ìjọba tó dìhámọ́ra tó ń tú ẹrù mi. Bí mo bá ṣe nǹkan kan tàbí tí mo sọ nǹkan tó mú ìfura lọ́wọ́ pẹ́nrẹ́n, wọ́n lè tìtorí ìyẹn lé mi jáde nílùú wọn, kí wọ́n sì fi àwọn tó ń dúró dè mí lóde sẹ́wọ̀n tàbí kí wọ́n kó wọn lọ sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́. Inú mi dùn pé ó ṣeé ṣe fún mi láti fa ojú ọkùnrin náà mọ́ra nípa fífún un ní ṣingọ́ọ̀mù àti bisikíìtì. Ṣùgbọ́n, báwo ni èmi obìnrin-bìnrìn, tó ti lé lẹ́ni ọgọ́ta ọdún ṣe bá ara mi nínú ipò yìí? Kí ló sún mi fi ìgbésí ayé gbẹ̀fẹ́ sílẹ̀, tí mo wá ń gbìyànjú láti wá ire Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀kan lára ibi tó ṣẹ́ kù tí àbá èrò orí Marx àti Lenin ti fẹsẹ̀ múlẹ̀ jù lọ?

Ọmọdébìnrin Olójòjò Tí Ọ̀pọ̀ Ìbéèrè Ń Gbin Nínú Rẹ̀

Ọdún méjì lẹ́yìn tá a bí mi ní 1920 nílùú Ierápetra, lórílẹ̀-èdè Kírétè, ni otútù àyà pa bàbá mi. Tálákà ni màmá mi. Kò sì lè fìdí ìgò kọ ó. Èmi ni àbígbẹ̀yìn lára àwọn ọmọ wọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin. Ibà pọ́njú kì í jẹ́ kí n gbádùn. Ó wá jẹ́ kí àwọ̀ ara mi ṣì. Mo sì máa ń ká gúọ́gúọ́ kiri bí olókùnrùn. Àwọn ará àdúgbò sọ fún màmá mi pé kàkà tí ì bá fi máa ṣe wàhálà àṣedànù lórí mi, kó kúkú gbájú mọ́ títọ́jú àwọn ọmọ mẹ́ta tí ara wọn le, kó fi mí sílẹ̀ kí n kú. Mo dúpẹ́ pé kò gbọ́ tiwọn.

Lemọ́lemọ́ ni màmá mi ń lọ sí itẹ́ bàbá mi pẹ̀lú àlùfáà ìjọ Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì láti lè rí i dájú pé wọ́n tẹ́ bàbá mi sáfẹ́fẹ́ rere ní ọ̀run. Àmọ́ àlùfáà kì í wá lọ́fẹ̀ẹ́ o. Mo ṣì rántí ọjọ́ Kérésìmesì kan tí òtútù mú burúkú-burúkú, tí mo ń wọ́ ẹsẹ̀ nílẹ̀ bí èmi àti Màmá ṣe jọ ń bọ̀ láti itẹ́. Àlùfáà ti gba gbogbo owó tó ṣẹ́ kù lọ́wọ́ wa. Lẹ́yìn tí Màmá se ìwọ̀nba ewébẹ̀ tó wà nílé fún àwa ọmọ, ló bá lọ fẹ̀yìn lélẹ̀ ní inúfìfo nínú yàrá mìíràn, tí omijé àròdùn sì bẹ̀rẹ̀ sí dà lójú rẹ̀. Lákòókò kan lẹ́yìn náà, mo lo ìgboyà, mo lọ bá àlùfáà náà, mo sì bi í nípa ìdí tí bàbá mi fi kú àti ìdí tí àlùfáà fi gbọ́dọ̀ máa gbowó lọ́wọ́ màmá mi tó jẹ́ aláìní. Kò rí ọ̀rọ̀ gidi sọ. Ohun tó kàn sọ ni pé: “Bàbá rẹ lọ jẹ́ ìpè Ọlọ́run ni. Báyé ṣe rí nìyẹn. Wàá yè é.”

Èmi ò rí bí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe bá àdúrà Olúwa tí mo kọ́ níléèwé mu. Mo ṣì rántí ọ̀rọ̀ alárinrin tó sì nítumọ̀ tó bẹ̀rẹ̀ àdúrà yẹn, pé: “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́. Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.” (Mátíù 6:9, 10) Bó bá jẹ́ pé lóòótọ́ ni Ọlọ́run fẹ́ kí ìfẹ́ òun di ṣíṣe lórí ilẹ̀ ayé, kí ló dé tí ìyà ń jẹ wá tó báyìí?

Díẹ̀ ló kù kí n rí ìdáhùn sí ìbéèrè yẹn lọ́dún 1929, nígbà tí Emmanuel Lionoudakis, Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó jẹ́ oníwàásù alákòókò kíkún, wá sílé wa. a Nígbà tí màmá mi béèrè ohun tó bá wá, Emmanuel ò gbin pẹ́nkẹ́n. Ńṣe ló kàn gbé káàdì ìjẹ́rìí lé màmá mi lọ́wọ́. Màmá fún mi ní káàdì náà kí n kà á. Nígbà tó sì jẹ́ pé ọmọ ọdún mẹ́sàn-án péré ni mí nígbà yẹn, kò fi bẹ́ẹ̀ yé mi. Màmá rò pé odi ni oníwàásù náà. Ìyẹn ló jẹ́ kó sọ pé: “Ó mà ṣe o, ẹni ẹlẹ́ni! Ìwọ ò lè sọ̀rọ̀, èmi ò sì lè kàwé.” Ó wá rọra juwọ́ sí i pé kó máa lọ.

Ọdún díẹ̀ lẹ́yìn ìyẹn ni mo rí ìdáhùn. Òjíṣẹ́ alákòókò kíkún kan náà ló fún ẹ̀gbọ́n mi, Emmanuel Paterakis, ní ìwé pẹlẹbẹ náà Where Are the Dead? [Níbo Làwọn Òkú Wà?], tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde. b Nígbà tí mo kà á, ara tù mí láti mọ̀ pé Ọlọ́run kọ́ ló mú bàbá mi lọ. Mo wá lóye pé àìpé ẹ̀dá ló fa ikú àti pé bàbá mi yóò jíǹde nígbà tí Párádísè bá dé sórí ilẹ̀ ayé.

“Ìwé Yìí Ti Bayé Ẹ Jẹ́!”

Òtítọ́ Bíbélì là wá lójú. A rí ògbólógbòó Bíbélì kan tó jẹ́ ti bàbá mi. A sì bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀. Iná àbẹ́là la fi ń kà á lẹ́gbẹ̀ẹ́ ààrò. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé èmi nìkan ni ọ̀dọ́bìnrin tó ní ìfẹ́ sí Bíbélì ládùúgbò, wọn ò jẹ́ kí n lọ́wọ́ sì ìgbòkègbodò àwọn Ẹlẹ́rìí kéréje tí ń bẹ ládùúgbò wa. Fún sáà kan, mo gbà tọkàntọkàn—bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀ràn ò rí bẹ́ẹ̀—pé àwọn ọkùnrin nìkan lẹ̀sìn yìí wà fún.

Ìtara tí ẹ̀gbọ́n mi fi ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù náà wú mi lórí. Kò pẹ́ tí àwọn ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ sí fojú sí ìdílé wa lára, tó jẹ́ pé tọ̀sán tòru ni wọ́n wá ń wo Emmanuel bóyá wọn a jẹ́ rí i mú, wọ́n sì tún fẹ́ mọ̀ bóyá ó ní àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́. Mo rántí dáadáa pé àlùfáà kan wá wàásù fún wa pé ká padà sí ṣọ́ọ̀ṣì. Nígbà tí Emmanuel fi hàn án nínú Bíbélì pé Jèhófà lorúkọ Ọlọ́run, ni àlùfáà bá já Bíbélì gbà o, ló bá bẹ̀rẹ̀ sí nà án sí ẹ̀gbọ́n mi lójú, ló bá kígbe pé, “Ìwé yìí ti bayé ẹ jẹ́!”

Ní 1940, nígbà tí Emmanuel kọ̀ láti wọṣẹ́ ológun, wọ́n mú un. Wọ́n fi í ránṣẹ́ sójú ogun ní Albania. A ò gbúròó rẹ̀ mọ́. A tiẹ̀ rò pé ó ti kú ni. Àfìgbà tó di ọdún méjì lẹ́yìn náà tá a ṣàdédé rí lẹ́tà rẹ̀ gbà láti ọgbà ẹ̀wọ̀n. Ó wà láyé, ó tún wà láàyè! Mi ò jẹ́ gbàgbé ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó fà yọ nínú lẹ́tà yẹn, tó kà pé: “Ní ti Jèhófà, ojú rẹ̀ ń lọ káàkiri ní gbogbo ilẹ̀ ayé láti fi okun rẹ̀ hàn nítorí àwọn tí ọkàn-àyà wọn pé pérépéré síhà ọ̀dọ̀ rẹ̀.” (2 Kíróníkà 16:9) Ọ̀rọ̀ ìṣírí yẹn mà bọ́ sákòókò o!

Àtinú ọgbà ẹ̀wọ̀n ni Emmanuel ti ṣètò pé kí àwọn arákùnrin kan wá bẹ̀ mí wò. Kíá la bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àwọn ìpàdé Kristẹni ní ìdákọ́ńkọ́ nínú abà kan lóko. Àṣé wọ́n ń ṣọ́ wa! Lọ́jọ́ Sunday kan, ṣe ni àwọn ọlọ́pàá yí wa ká. Wọ́n kó wa sínú ọkọ̀ kan tí kò nílé lórí. Wọ́n sì wà wá kiri ìgboro ìlú. Mi ò tíì gbàgbé báwọn èèyàn ṣe ń fi wá ṣẹ̀sín, tí wọ́n ń ṣáátá wa. Ṣùgbọ́n Jèhófà fi wá lọ́kàn balẹ̀ nípasẹ̀ ẹ̀mí rẹ̀.

Wọ́n kó wa lọ sílùú mìíràn níbi tí wọ́n ti sọ wá sínú àwọn àtìmọ́lé tó ṣókùnkùn biribiri, tó sì dọ̀tí bí ilé póò. Korobá kan tí kò ní ìdérí ni ilé ìgbọ̀nsẹ̀ tó wà níbi tí wọ́n tì mí mọ́. Ẹ̀ẹ̀kan lóòjọ́ sì ni wọ́n máa ń wá gbé e lọ dà nù. Wọ́n dájọ́ ẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́jọ fún mi, nítorí èmi ni wọ́n pè ní “olùkọ́” ẹgbẹ́ náà. Ṣùgbọ́n, arákùnrin kan tó ń ṣẹ̀wọ̀n níbẹ̀ ṣètò pé kí lọ́yà òun rí sí ẹjọ́ wa, wọ́n sì tú wa sílẹ̀.

Ìgbésí Ayé Tuntun

Nígbà tí Emmanuel tẹ̀wọ̀n dé, ó di alábòójútó arìnrìn-àjò tó ń bẹ àwọn ìjọ tó wà ní Áténì wò. Mo kó lọ síbẹ̀ ní 1947. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, mo wá rí àwùjọ ńlá tó jẹ́ ti àwọn Ẹlẹ́rìí—kì í ṣe kìkì ọkùnrin, ṣùgbọ́n àtobìnrin, àtọmọdé pẹ̀lú. Níkẹyìn, ní July 1947, mo ṣèrìbọmi láti fi hàn pé mo ti ya ara mi sí mímọ́ fún Jèhófà. Ó ti pẹ́ tí iṣẹ́ míṣọ́nnárì ti ń wù mí í ṣe. Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí lọ síléèwé lálaalẹ́ láti lọ kọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì. Mo di aṣáájú ọ̀nà ní 1950. Màmá wá ń gbé lọ́dọ̀ mi. Òun náà sì tẹ́wọ́ gba òtítọ́ Bíbélì. Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni títí dọjọ́ ikú rẹ̀ ní ọdún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n lẹ́yìn náà.

Ọdún yẹn ni mo bá John Marks (Markopoulos) pàdé, ọkùnrin tó dúró dáadáa nípa tẹ̀mí, táwọn èèyàn bọ̀wọ̀ fún gidigidi, tó wá láti Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Ìhà gúúsù Albania ni wọ́n ti bí John. Ìgbà tó ṣí lọ sí Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ló di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó wá sí Gíríìsì ní 1950. Ó ń wá bóun ṣe máa rí ìwé àṣẹ gbà láti wọ orílẹ̀-èdè Albania—tí kò ṣeé wọ̀ nígbà yẹn lọ́hùn-ún lábẹ́ ìjọba Kọ́múníìsì tí kò gba gbẹ̀rẹ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé John kò tíì rí ìdílé rẹ̀ láti 1936, wọn ò jẹ́ kó wọ Albania. Ìtara mímúná tó ní fún iṣẹ́ ìsìn Jèhófà àti ìfẹ́ jíjinlẹ̀ tó ní fún ẹgbẹ́ àwọn ará wọ̀ mí lọ́kàn gan-an. A ṣègbéyàwó ní April 3, 1953. Mo wá bá a lọ sí ibùgbé wa tuntun ní Ìpínlẹ̀ New Jersey, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà.

Ká lè gbọ́ bùkátà ara wa lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù alákòókò kíkún tá à ń ṣe, èmi àti John bẹ̀rẹ̀ sí ṣe òwò kékeré kan ní etídò New Jersey. A ń se oúnjẹ àárọ̀ tà fáwọn apẹja. Ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn nìkan là ń ṣiṣẹ́, láti àfẹ̀mọ́jú títí di aago mẹ́sàn-án àárọ̀. Àìwalé ayé máyà àti gbígbájúmọ́ ìgbòkègbodò tẹ̀mí, jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti lo èyí tó pọ̀ jù lọ lára àkókò wa nínú iṣẹ́ ìwàásù. Bọ́dún ti ń gorí ọdún, la ń ṣí láti ìlú kan lọ sí òmíràn níbi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù. Pẹ̀lú ìtìlẹyìn Jèhófà, a ran àwọn tó fẹ́ gbọ́rọ̀ wa lọ́wọ́ láwọn ibi tá a lọ wọ̀nyẹn. A dá ọ̀pọ̀ ìjọ sílẹ̀, a sì ṣèrànwọ́ láti kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba.

Ríran Àwọn Ará Wa Tó Jẹ́ Aláìní Lọ́wọ́

Àmọ́ láìpẹ́ ni wọ́n gbé iṣẹ́ ńlá kan lé wa lọ́wọ́. Àwọn arákùnrin tó ń bójú tó iṣẹ́ náà fẹ́ máa gbúròó àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wọn tó wà ní àgbègbè Balkan, níbi tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ wa. Fún ọ̀pọ̀ ọdún làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní orílẹ̀-èdè wọ̀nyẹn kò ti ráyè kàn sí ẹgbẹ́ àwọn ará kárí ayé. Tó jẹ́ pé ìwọ̀nba oúnjẹ tẹ̀mí díẹ̀ ni wọ́n ń rí gbà, ìyẹn bí wọ́n bá tilẹ̀ rí rárá. Wọ́n tún ń fojú winá inúnibíni rírorò. Ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wọn ni wọ́n ń ṣọ́ tọwọ́tẹsẹ̀. Ọ̀pọ̀ sì wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n tàbí ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́. Wọ́n nílò àwọn ìtẹ̀jáde tá a gbé ka Bíbélì àti ìtọ́sọ́nà àti ìṣírí ní kánjúkánjú. Fún àpẹẹrẹ, àwọn ìsọfúnni kan tó dún bí ẹnà, tá a rí gbà láti orílẹ̀-èdè Albania kà pé: “Ẹ bá wa gbàdúrà sí Olúwa. Wọ́n wá ń kó ìwé wa láti ilé dé ilé. Wọn ò jẹ́ ká kẹ́kọ̀ọ́. Èèyàn mẹ́ta ti wà lẹ́wọ̀n.”

Ìyẹn ló fi jẹ́ pé ní November 1960, a rin ìrìn àjò tó gba oṣù mẹ́fà gbáko lọ sí mélòó kan lára àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyẹn. Láìsí àní-àní, a nílò “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá,” ìgboyà, àìṣojo àti ọgbọ́n látọ̀dọ̀ Ọlọ́run láti lè ṣe àṣeyọrí. (2 Kọ́ríńtì 4:7) Albania ni a kọ́kọ́ gbà lọ. A ra ọkọ̀ kan nílùú Paris, a sì mú ọ̀nà wa pọ̀n. Nígbà tá a dé Róòmù, John nìkan ni wọ́n fún ní ìwé àṣẹ láti wọ Albania. Ó di dandan kí n lọ dúró dè é nílùú Áténì, ní orílẹ̀-èdè Gíríìsì.

Apá ìparí oṣù February 1961 ni John wọ Albania. Ó sì wà níbẹ̀ títí tí oṣù March fi parí. Ọgbọ̀n arákùnrin ló rí sójú nílùú Tiranë. Ẹ wo bí inú wọ́n ti dùn tó láti rí àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ àti ìṣírí tí wọ́n nílò gan-an gbà! Ó ti pé ọdún mẹ́rìnlélógún tí wọn ò tíì rẹ́ni bẹ̀ wọ́n wò láti ibòmíràn.

Ìwà títọ́ àti ìfaradà àwọn ará wọ̀nyẹn wú John lórí. Ó gbọ́ pé iṣẹ́ ti bọ́ lọ́wọ́ ọ̀pọ̀ nínú wọn. Ọ̀pọ̀ ni wọ́n ti sọ sẹ́wọ̀n nítorí pé wọ́n kọ̀ láti lọ́wọ́ sí ìgbòkègbodò ìjọba Kọ́múníìsì. Àní ó wú u lórí gan-an nígbà tí àwọn arákùnrin méjì tí wọ́n ti lé lẹ́ni ọgọ́rin ọdún fún un ní ọrẹ nǹkan bí ọgọ́rùn-ún owó dọ́là láti fi ti iṣẹ́ ìwàásù náà lẹ́yìn. Ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn ni wọ́n ti ń tere owó yẹn jọ látinú ìwọ̀nba owó ìfẹ̀yìntì tí wọ́n ń rí gbà.

March 30, 1961, ìyẹn ọjọ́ Ìṣe Ìrántí ikú Jésù, ni ọjọ́ tó gbẹ̀yìn ìbẹ̀wò John sí Albania. John ló sọ àsọyé Ìṣe Ìrántí náà, èèyàn mẹ́tàdínlógójì ló sì wá. Nígbà tí àsọyé náà parí, kíá làwọn ará mú John gba ọ̀nà ẹ̀yìnkùlé jáde. Wọ́n sì wà á lọ sí èbúté Durrës, níbi tó ti wọ ọkọ̀ òkun oníṣòwò tó jẹ́ ti ilẹ̀ Turkey, tó forí lé ìlú Piraiévs (Piraeus), nílẹ̀ Gíríìsì.

Inú mi dùn nígbà tó dé láyọ̀ àti lálàáfíà. A lè wá máa bá ìyókù ìrìn àjò eléwu náà nìṣó báyìí. Lẹ́nu ìrìn àjò wa yìí, a tún dé àwọn orílẹ̀-èdè mẹ́ta mìíràn tó wà lágbègbè Balkan, níbi tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ wa—ó sì léwu nínú gan-an nítorí pé a kó àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ẹ̀rọ ìtẹ̀wé àtàwọn nǹkan èlò mìíràn dání. A ní àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ láti pàdé àwọn arákùnrin àti arábìnrin tó jẹ́ adúróṣinṣin, tí wọn ò kọ̀ kí iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ àwọn, tí wọn ò kọ̀ láti lọ sí àtìmọ́lé, àní tí wọn ò kọkú, nítorí Jèhófà. Ìtara àti ojúlówó ìfẹ́ tí wọ́n ní wú wa lórí gan-an ni. Ó tún jẹ́ ìwúrí fún wa láti rí i pé Jèhófà fún wọn ní “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá.”

A lọ, a bọ̀, a ò bọmọ jẹ́, a sì padà sí Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Ní àwọn ọdún tó tẹ̀ lé e, a ń gbìyànjú onírúurú ọ̀nà láti fi ìwé ránṣẹ́ sí Albania, ká sì gbọ́ ìròyìn nípa ìgbòkègbodò àwọn ará wa níbẹ̀.

Ìrìn Àjò Léraléra, Nínú Ewu

Ọ̀pọ̀ ọdún kọjá lọ, ikú John ní 1981, lẹ́ni ọdún mẹ́rìndínlọ́gọ́rin, sì mú kí ayé sú mi. Ọmọ ẹ̀gbọ́n mi, ìyẹn Evangelia àti ọkọ rẹ̀, George Orphanides, fi inú rere gbà mí sọ́dọ̀, wọ́n sì jẹ́ alábàárò mi. Wọ́n ń ṣe ìtìlẹyìn gidi fún mi látìgbà yẹn. Àwọn alára ti rí ìtìlẹyìn Jèhófà nígbà tí wọ́n ń sìn ní Sudan nígbà tí wọ́n fòfin de iṣẹ́ náà. c

Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, wọ́n tún gbìyànjú ọ̀nà míì tí a ó gbà kàn sí àwọn ará ní Albania. Níwọ̀n bí àwọn ẹbí ọkọ mi ti ń gbé níbẹ̀, wọ́n bi mí bóyá màá fẹ́ lọ sí orílẹ̀-èdè yẹn. Mo sọ fún wọn pé màá lọ mọ̀nà!

Ní May 1986, lẹ́yìn ọ̀pọ̀ oṣù tá a ti ń forí ṣe fọrùn ṣe, ni iléeṣẹ́ ìjọba Albania tí ń bẹ nílùú Áténì jàjà fún mi ní ìwé àṣẹ láti wọ ìlú wọn. Àwọn aṣojú wọn kìlọ̀ fún mi gbọnmọgbọnmọ pé bí nǹkan kan bá ṣẹlẹ̀, kí n má retí àtirí ìrànlọ́wọ́ kankan gbà láti orílẹ̀-èdè mìíràn o. Nígbà tí mo lọ bá ọ̀gá iléeṣẹ́ tó máa bá mi ra tíkẹ́ẹ̀tì tí màá fi wọ ọkọ̀ òfuurufú lọ sí Albania, kò mọ ohun tí ì bá sọ. Mi ò jẹ́ kí ìbẹ̀rù dá mi lọ́wọ́ kọ́. Mo wọ bàlúù kan ṣoṣo tó ń lọ láti Áténì sí Tiranë lẹ́ẹ̀kan lọ́sẹ̀. Àwọn arúgbó ará Albania mẹ́ta péré la jọ wà nínú bàlúù náà; wọ́n lọ gba ìtọ́jú lórílẹ̀-èdè Gíríìsì ni ní tiwọn.

Gbàrà tí bàlúù náà balẹ̀ ni wọ́n sọ pé kí n kọjá sábẹ́ òrùlé tí àwọn aṣọ́bodè wà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àbúrò ọkọ mi tó jẹ́ ọkùnrin àti àbúrò rẹ̀ obìnrin kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n múra tán láti bá mi kàn sí àwọn ará díẹ̀ tó wà ládùúgbò yẹn. Lábẹ́ òfin, àwọn èèyàn ọkọ mi wọ̀nyí gbọ́dọ̀ lọ sọ fún aláṣẹ àdúgbò pé mo ti wọ̀lú. Fún ìdí yìí, àwọn ọlọ́pàá ń ṣọ́ mi lójú méjèèjì. Ìdí nìyẹn táwọn èèyàn ọkọ mi fi dá a lábàá pé kí n wà nílé ọ̀dọ̀ àwọn, kí n jẹ́ káwọn lọ bá mi wá méjì lára àwọn arákùnrin tí ń gbé ní Tiranë, kí wọ́n lè wá rí mi.

Nígbà yẹn, àwọn arákùnrin mẹ́sàn-án tí wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́ la mọ̀ pé wọ́n wà ní gbogbo Albania. Ọ̀pọ̀ ọdún tí wọ́n ti fòfin dè wọ́n, tí wọ́n ti ṣe inúnibíni sí wọn, tí wọ́n sì ti ń ṣọ́ wọn tọwọ́tẹsẹ̀ ti jẹ́ kí wọ́n máa fura gan-an. Gbogbo ojú wọn ló ti hunjọ. Lẹ́yìn tí àwọn arákùnrin méjèèjì náà wá rí i pé arábìnrin ni mí lóòótọ́, ìbéèrè tí wọ́n kọ́kọ́ bi mí ni: “Àwọn Ilé Ìṣọ́ dà?” Ìwé ògbólógbòó méjì péré ni wọ́n ní lọ́wọ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún—wọn ò tiẹ̀ ní Bíbélì kan ṣoṣo.

Wọ́n ròyìn ìwà ìkà tí ìjọba ti hù sí àwọn. Wọ́n sọ nípa arákùnrin ọ̀wọ́n kan tó pinnu pé òun ò ní lọ́wọ́ sọ́ràn òṣèlú nínú ìbò kan tí wọ́n fẹ́ dì. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọwọ́ Ìjọba ni gbogbo nǹkan wà, ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé wọn ò ní pín oúnjẹ kankan fún ìdílé arákùnrin yìí. Àwọn ọmọ rẹ̀ tó ti ṣègbéyàwó àti gbogbo ìdílé wọn pátá ló máa ṣẹ̀wọ̀n, bí wọn ò tilẹ̀ fara mọ́ ohun tí bàbá wọn gbà gbọ́. Ìròyìn tá a gbọ́ ni pé, ńṣe làwọn aráalé arákùnrin yìí pa á nítorí ìbẹ̀rù ní òru ọjọ́ tí ìbò ku ọ̀la. Wọ́n ju òkú rẹ̀ sínú kànga. Wọ́n wá sọ pé ńṣe ló pa ara rẹ̀ nítorí ìbẹ̀rù.

Ipò òṣì táwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa wọ̀nyẹn wà ń bani lọ́kàn jẹ́. Síbẹ̀, nígbà tí mo gbìyànjú láti fún ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ogún dọ́là, wọ́n kọ̀ ọ́. Wọ́n ní, “Oúnjẹ tẹ̀mí nìkan là ń fẹ́.” Ọ̀pọ̀ ọdún làwọn arákùnrin ọ̀wọ́n wọ̀nyí ti fi wà lábẹ́ ìjọba aláṣẹ oníkùmọ̀ tó ti sọ ọ̀pọ̀ jù lọ lára ọmọ abẹ́ wọn di aláìgbà-pọ́lọ́run-wà. Ṣùgbọ́n ìgbàgbọ́ àti ìpinnu wọn lágbára bíi tàwọn Ẹlẹ́rìí yòókù. Ohun tó gbà mí lọ́kàn lẹ́yìn tí mo kúrò ní Albania lọ́sẹ̀ méjì lẹ́yìn náà ni bí Jèhófà ṣe ń fún wọ́n ní “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá,” kódà nínú ipò líle koko yìí.

Mo tún ní àǹfààní pípadà lọ sí Albania ni 1989 àti ní 1991. Bí òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ àti ti ẹ̀sìn ṣe bẹ̀rẹ̀ sí fẹsẹ̀ múlẹ̀ díẹ̀díẹ̀ ní orílẹ̀-èdè yẹn, ńṣe ni iye àwọn tó ń sin Jèhófà ń gbèrú sí i. Ìwọ̀nba àwọn Kristẹni tó ti ṣe ìyàsímímọ́ tó wà níbẹ̀ ní 1986 papọ̀ jẹ́ ẹgbàá ó lé igba [2,200], wọ́n sì jẹ́ akéde aláápọn. Lára wọn ni Arábìnrin Melpo, àbúrò ọkọ mi. Ǹjẹ́ iyèméjì wà rárá pé Jèhófà ti bù kún àwùjọ olóòótọ́ yẹn?

Ìgbésí Ayé Mi Mìrìngìndìn, Lọ́lá Jèhófà

Nígbàkigbà tí mo bá wẹ̀yìn wò, ọkàn mi máa ń balẹ̀ pé iṣẹ́ wa—ìyẹn tèmi àti ti John—kò já sásán. A lo okun ìgbà èwe wa lọ́nà tó dáa jù lọ. Iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún tá a fi ìgbésí ayé wa ṣe ṣàǹfààní ju iṣẹ́ èyíkéyìí mìíràn tá a lè jókòó tì. Mo láyọ̀ nítorí ọ̀pọ̀ àwọn ẹni ọ̀wọ́n tá a ti ràn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Bíbélì. Nísinsìnyí tí àgbà ti dé, mo lè fi tọkàntọkàn rọ àwọn ọ̀dọ́ pé kí wọ́n ‘rántí Ẹlẹ́dàá wọn Atóbilọ́lá nígbà èwe wọn.’—Oníwàásù 12:1.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni ọdún mọ́kànlélọ́gọ́rin ni mí, mo ṣì ń sìn gẹ́gẹ́ bí akéde ìhìn rere náà ní àkókò kíkún. Mo máa ń gbéra ní ìdájí láti lọ jẹ́rìí fáwọn èèyàn ní ibùdókọ̀, níbi ìgbọ́kọ̀sí, lójú pópó, ní ṣọ́ọ̀bù, tàbí ní ọgbà ìtura. Àwọn ìṣòro ọjọ́ ogbó kò jẹ́ kí nǹkan rọrùn. Ṣùgbọ́n àwọn arákùnrin àti arábìnrin mi nípa tẹ̀mí tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ mi—ìyẹn ìdílé ńlá mi nípa tẹ̀mí—àti ìdílé ọmọ ẹ̀gbọ́n mi, ń tì mí lẹ́yìn gan-an. Lékè gbogbo rẹ̀, mo ti rí i pé ‘agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá jẹ́ ti Ọlọ́run, kì í ṣe èyí tí ó ti ọ̀dọ̀ àwa fúnra wa jáde.’—2 Kọ́ríńtì 4:7.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ìtàn ìgbésí ayé Emmanuel Lionoudakis wà nínú Ilé Ìṣọ́, September 1, 1999, ojú ìwé 25 sí 29.

b Ìtàn ìgbésí ayé Emmanuel Paterakis wà nínú Ilé Ìṣọ́, November 1, 1996, ojú ìwé 22 sí 27.

c Wo 1992 Yearbook of Jehovah’s Witnesses, ojú ìwé 91 àti 92, tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Lókè: John (ló wà lápá òsì pátápátá), èmi (ni mo wà láàárín), Emmanuel ẹ̀gbọ́n mi ló wà lápá òsì mi, màmá wa ló sì wà lápá òsì rẹ̀, pẹ̀lú àwọn kan lára ìdílé Bẹ́tẹ́lì, ní Áténì, lọ́dún 1950

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Apá òsì: Èmi àti John níbi iṣẹ́ wa ní etídò New Jersey, lọ́dún 1956

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Àpéjọpọ̀ àgbègbè nílùú Tiranë, Albania, lọ́dún 1995

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Tiranë, Albania. Ọdún 1996 la parí rẹ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Èmi àti Evangelia Orphanides ọmọ ẹ̀gbọ́n mi (lápá ọ̀tún) àti George ọkọ rẹ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Lókè: Àpilẹ̀kọ kan látinú “Watchtower” kan tó jáde ní 1940, tá a tú ní ìdákọ́ńkọ́ sí èdè Albania