Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Ọmọ Ìyá Kan Náà Tí Ìwà Wọ́n Yàtọ̀ Síra

Àwọn Ọmọ Ìyá Kan Náà Tí Ìwà Wọ́n Yàtọ̀ Síra

Àwọn Ọmọ Ìyá Kan Náà Tí Ìwà Wọ́n Yàtọ̀ Síra

ÌPINNU táwọn òbí ṣe kì í ṣàìnípa lórí àwọn ọmọ wọn. Ọ̀rọ̀ yìí jóòótọ́ lónìí, bó ṣe rí gan-an nígbà yẹn lọ́hùn-ún nínú ọgbà Édẹ́nì. Ìwà ọ̀tẹ̀ Ádámù àti Éfà ní ipa jíjinlẹ̀ lórí gbogbo aráyé. (Jẹ́nẹ́sísì 2:15, 16; 3:1-6; Róòmù 5:12) Àmọ́, kálukú wa ló ní àǹfààní láti ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Ẹlẹ́dàá wa bá a bá fẹ́ bẹ́ẹ̀. Ìtàn kan tó ti èyí lẹ́yìn ni ìtàn Kéènì àti Ébẹ́lì, tẹ̀gbọ́n-tàbúrò àkọ́kọ́ nínú ìtàn ẹ̀dá ènìyàn.

A kò rí àkọsílẹ̀ kan nínú Ìwé Mímọ́ tó fi hàn pé Ọlọ́run bá Ádámù àti Éfà sọ̀rọ̀ lẹ́yìn tó lé wọn jáde kúrò ní Édẹ́nì. Àmọ́ Jèhófà kò ní ṣàìbá àwọn ọmọ wọn sọ̀rọ̀. Àwọn òbí Kéènì àti Ébẹ́lì kò ní ṣàìsọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún wọn. Wọ́n á rí “àwọn kérúbù . . . àti abẹ idà tí ń jó lala, tí ń yí ara rẹ̀ láìdáwọ́ dúró láti máa ṣọ́ ọ̀nà tí ó lọ síbi igi ìyè náà.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:24) Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí tún fojú ara wọn rí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run sọ pé nínú òógùn ojú wọn àti nínú ìrora ni wọn óò máa gbé ọjọ́ ayé wọn.—Jẹ́nẹ́sísì 3:16, 19.

Kéènì àti Ébẹ́lì ti ní láti gbọ́ nípa ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ fún ejò náà pé: “Èmi yóò sì fi ìṣọ̀tá sáàárín ìwọ àti obìnrin náà àti sáàárín irú-ọmọ rẹ àti irú-ọmọ rẹ̀. Òun yóò pa ọ́ ní orí, ìwọ yóò sì pa á ní gìgísẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:15) Ohun tí Kéènì àti Ébẹ́lì mọ̀ nípa Jèhófà á jẹ́ kí wọ́n sapá láti ní àjọṣe tó gbámúṣé pẹ̀lú rẹ̀.

Ríronú nípa àsọtẹ́lẹ̀ Jèhófà àtàwọn ànímọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Olóore kò ní ṣàìmú kí Kéènì àti Ébẹ́lì fẹ́ láti wá ojú rere Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n báwo ni ìfẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀ yóò ṣe jinlẹ̀ tó? Ṣé wọ́n á fẹ́ ṣe ohun tí ọkàn wọn ń sọ fún wọn pé ànímọ́ àdámọ́ni lọ̀ràn sísin Ọlọ́run, kí wọ́n sì jẹ́ kí nǹkan tẹ̀mí jẹ wọ́n lógún débi pé wọ́n á lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀?—Mátíù 5:3.

Tẹ̀gbọ́n-Tàbúrò Náà Mú Ọrẹ Ẹbọ Wá

Nígbà tó ṣe, Kéènì àti Ébẹ́lì mú ọrẹ ẹbọ wá fún Ọlọ́run. Kéènì mú irè oko wá. Ébẹ́lì sì mú àwọn àkọ́bí nínú agbo ẹran rẹ̀ wá. (Jẹ́nẹ́sísì 4:3, 4) Ó ṣeé ṣe kí àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ti tó ẹni ọgọ́rùn-ún ọdún, torí pé ẹni àádóje [130] ọdún ni Ádámù nígbà tó bí Sẹ́ẹ̀tì ọmọ rẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 4:25; 5:3.

Ọrẹ ẹbọ tí Kéènì àti Ébẹ́lì mú wá fi hàn pé wọ́n mọ̀ pé ẹlẹ́ṣẹ̀ làwọn, àwọn sì fẹ́ ojú rere Ọlọ́run. Ó kéré tán, wọ́n á ti ronú lórí ìlérí Jèhófà nípa ejò náà àti Irú Ọmọ obìnrin náà. A kò mọ bí Kéènì àti Ébẹ́lì ti forí fọrùn ṣe tó nínú wíwá ọ̀nà láti ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Jèhófà. Ṣùgbọ́n ojú tí Ọlọ́run fi wo ọrẹ ẹbọ wọn jẹ́ ká mọ ohun tó wà lọ́kàn kálukú wọn.

Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan dá a lábàá pé Éfà ka Kéènì sí “irú ọmọ” tí yóò pa ejò náà run, torí pé nígbà tó bí Kéènì, ohun tó sọ ni pé: “Mo ti mú ọkùnrin kan jáde nípasẹ̀ àrànṣe Jèhófà.” (Jẹ́nẹ́sísì 4:1) Bó bá jẹ́ ojú tí Kéènì fi ń wo ara rẹ̀ nìyí, ibi tó fojú sí ọ̀nà ò gbabẹ̀ rárá. Àmọ́ Ébẹ́lì ní tirẹ̀ ní ìgbàgbọ́ ní àfikún sí ẹbọ tó rú. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé “nípa ìgbàgbọ́ ni Ébẹ́lì rú ẹbọ tí ó níye lórí ju ti Kéènì sí Ọlọ́run.”—Hébérù 11:4.

Ìjìnlẹ̀ òye tẹ̀mí tí Ébẹ́lì ní, tí Kéènì kò ní, kọ́ ni kìkì ìyàtọ̀ tó wà láàárín tẹ̀gbọ́n-tàbúrò yìí. Ìṣesí wọ́n tún yàtọ̀ síra. Nítorí náà, nígbà tó jẹ́ pé “Jèhófà fi ojú rere wo Ébẹ́lì àti ọrẹ ẹbọ rẹ̀, òun kò fi ojú rere kankan wo Kéènì àti ọrẹ ẹbọ rẹ̀.” Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Kéènì kò bìkítà nípa ẹbọ tó rú, kó jẹ́ pé ẹbọ gbà-máà-póò-rọ́wọ́-mi ló rú. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ò fẹ́ ìjọsìn tí kò dénú. Kéènì ti di onínú burúkú, Jèhófà sì rí i pé inú rẹ̀ ò dáa. Bí Kéènì ṣe hùwà padà nígbà tí Ọlọ́run kọ ẹbọ rẹ̀ fi ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ gan-an hàn. Kàkà kí Kéènì ṣàtúnṣe, ńṣe ni “ìbínú Kéènì . . . gbóná gidigidi, ojú rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí rẹ̀wẹ̀sì.” (Jẹ́nẹ́sísì 4:5) Ìṣarasíhùwà rẹ̀ fi hàn pé ó ń gbèrò ibi lọ́wọ́.

Ìkìlọ̀ àti Ojú Tó Fi Wo Ìkìlọ̀ Náà

Nígbà tí Ọlọ́run rí irú ẹ̀mí tí Kéènì ní, ó gbà á nímọ̀ràn pé: “Èé ṣe tí ìbínú rẹ fi gbóná, èé sì ti ṣe tí ojú rẹ fi rẹ̀wẹ̀sì? Bí ìwọ bá yíjú sí ṣíṣe rere, ara rẹ kò ha ní yá gágá bí? Ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá yíjú sí ṣíṣe rere, ẹ̀ṣẹ̀ lúgọ sí ẹnu ọ̀nà, ìfàsí-ọkàn rẹ̀ sì wà fún ọ; ní tìrẹ, ìwọ yóò ha sì kápá rẹ̀ bí?”—Jẹ́nẹ́sísì 4:6, 7.

A lè fi èyí ṣe àríkọ́gbọ́n. Ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé ẹ̀ṣẹ̀ ń lúgọ de kálukú wa, kí ọwọ́ rẹ̀ lè tẹ̀ wá. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run fún wa lómìnira láti ṣe ohun tó wù wá, a sì lè yàn láti ṣe ohun tó tọ́. Jèhófà ní kí Kéènì “yíjú sí ṣíṣe rere,” ṣùgbọ́n Jèhófà kò fi túláàsì mú un láti yí padà. Kéènì ló yan ọ̀nà tó wù ú.

Ìtàn tá a mí sí náà ń bá a lọ pé: “Lẹ́yìn ìyẹn, Kéènì sọ fún Ébẹ́lì arákùnrin rẹ̀ pé: ‘Jẹ́ kí a kọjá lọ sínú pápá.’ Ó wá ṣẹlẹ̀ pé, nígbà tí wọ́n wà nínú pápá, Kéènì bẹ̀rẹ̀ sí fipá kọlu Ébẹ́lì arákùnrin rẹ̀, ó sì pa á.” (Jẹ́nẹ́sísì 4:8) Bí Kéènì ṣe di aláìgbọràn, òṣìkàpànìyàn nìyẹn o. Kò tiẹ̀ kábàámọ̀ ohun tó ṣe rárá nígbà tí Jèhófà bi í pé: “Ibo ni Ébẹ́lì arákùnrin rẹ wà?” Kàkà bẹ́ẹ̀, ohùn agídí àti ohùn afojúdi ni Kéènì fi fèsì pé: “Èmi kò mọ̀. Èmi ha ni olùtọ́jú arákùnrin mi bí?” (Jẹ́nẹ́sísì 4:9) Irọ́ burúkú àti sísẹ́ tí Kéènì sẹ́ yẹn ló fi hàn pé onínú burúkú ni.

Jèhófà gégùn-ún fún Kéènì, ó sì lé e jìnnàjìnnà kúrò ní sàkáání Édẹ́nì. Ègún tó ti wà lórí ilẹ̀ tẹ́lẹ̀ á túbọ̀ jà lórí Kéènì, ilẹ̀ ò sì ní méso jáde fún un. Yóò di alárìnkiri àti ìsáǹsá lórí ilẹ̀ ayé. Bí Kéènì ṣe ráhùn pé ẹjọ́ tí Ọlọ́run dá òun ti le koko jù fi hàn pé ó ń bẹ̀rù pé a ó gbẹ̀san pípa tí òun pa àbúrò òun lára òun. Ṣùgbọ́n kò fẹ̀mí ìrònúpìwàdà hàn rárá. Jèhófà fi “àmì” kan sí Kéènì lára—bóyá àṣẹ pàtàkì kan táwọn èèyàn mọ̀, tí wọ́n sì ń pa mọ́, kí àwọn èèyàn má bàa pa á láti fi gbẹ̀san.—Jẹ́nẹ́sísì 4:10-15.

Kéènì wá “lọ kúrò ní ojú Jèhófà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé ilẹ̀ Ìsáǹsá ní ìhà ìlà-oòrùn Édẹ́nì.” (Jẹ́nẹ́sísì 4:16) Ó mú ọ̀kan lára àwọn àbúrò rẹ̀ tàbí ọmọ àbúrò rẹ̀ ṣaya, ó sì tẹ ìlú kan dó, tó fi orúkọ Énọ́kù, àkọ́bí rẹ̀ pè. Lámékì, àtọmọdọ́mọ Kéènì pẹ̀lú di oníwà ipá bíi ti baba ńlá rẹ̀ aláìnáání Ọlọ́run. Àmọ́ Ìkún Omi ọjọ́ Nóà ló pa ìlà ìdílé Kéènì rẹ́.—Jẹ́nẹ́sísì 4:17-24.

Ẹ̀kọ́ Àríkọ́gbọ́n fún Wa

A lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú ìtàn Kéènì àti Ébẹ́lì. Àpọ́sítélì Jòhánù gba àwọn Kristẹni níyànjú pé kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn lẹ́nì kìíní kejì, “kì í ṣe bí Kéènì, ẹni tí ó pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ ẹni burúkú náà, tí ó sì fikú pa arákùnrin rẹ̀ . . . Àwọn iṣẹ́ [Kéènì] burú, ṣùgbọ́n àwọn ti arákùnrin rẹ̀ jẹ́ òdodo.” Jòhánù tún sọ pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ó bá kórìíra arákùnrin rẹ̀ jẹ́ apànìyàn, ẹ̀yin sì mọ̀ pé kò sí apànìyàn kankan tí ìyè àìnípẹ̀kun dúró nínú rẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni o, bá a ṣe ń ṣe sí àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa kan àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run àti ìrètí wa ọjọ́ iwájú. A kò lè rí ojú rere Ọlọ́run bí a bá kórìíra èyíkéyìí lára àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa.—1 Jòhánù 3:11-15; 4:20.

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé bákan náà la ṣe tọ́ Kéènì àti Ébẹ́lì dàgbà, ṣùgbọ́n Kéènì kò nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run. Ní tòótọ́, ó ní irú ìṣarasíhùwà Èṣù, tó jẹ́ ‘apànìyàn àti baba irọ́’ ní ìpilẹ̀ṣẹ̀. (Jòhánù 8:44) Ọ̀nà tí Kéènì tọ̀ fi hàn pé gbogbo wa ló ní àǹfààní láti yan ọ̀nà tó wù wá, pé àwọn tó yàn láti tọ ọ̀nà ẹ̀ṣẹ̀ ń ya ara wọn nípa sí Ọlọ́run, àti pé Jèhófà kò ní ṣàìdá àwọn aláìronúpìwàdà lẹ́jọ́.

Ébẹ́lì, ní tirẹ̀, lo ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà. Ní tòótọ́, “nípa ìgbàgbọ́ ni Ébẹ́lì rú ẹbọ tí ó níye lórí ju ti Kéènì sí Ọlọ́run, nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ náà tí ó fi ní ẹ̀rí tí a jẹ́ sí i pé ó jẹ́ olódodo, tí Ọlọ́run ń jẹ́rìí nípa àwọn ẹ̀bùn rẹ̀.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ Ébẹ́lì kankan kò sí lákọọ́lẹ̀ nínú Ìwé Mímọ́, ó ṣì “ń sọ̀rọ̀” nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ rẹ̀ tó jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ.—Hébérù 11:4.

Ébẹ́lì lẹni àkọ́kọ́ lára gbogbo àwọn olùpàwàtítọ́mọ́. Ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ tó ‘ké jáde sí Jèhófà láti inú ilẹ̀’ kò tíì di ìgbàgbé. (Jẹ́nẹ́sísì 4:10; Lúùkù 11:48-51) Bá a bá ní irú ìgbàgbọ́ tí Ébẹ́lì ní, àwa náà lè ní àjọṣe tó gbámúṣé, tó ṣeyebíye pẹ̀lú Jèhófà.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 22]

ÀGBẸ̀ ÀTI OLÙṢỌ́ ÀGÙNTÀN

Ríro ilẹ̀ àti títọ́jú àwọn ẹran wà lára iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé Ádámù lọ́wọ́ níbẹ̀rẹ̀ pàá. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28; 2:15; 3:23) Àgbẹ̀ ni Kéènì ọmọ rẹ̀. Olùṣọ́ àgùntàn sì ni Ébẹ́lì. (Jẹ́nẹ́sísì 4:2) Ṣùgbọ́n kí nìdí fún jíjẹ́ olùṣọ́ àgùntàn nígbà tó jẹ́ pé èso àti ewébẹ̀ nìkan loúnjẹ téèyàn ń jẹ kí Ìkún Omi tó dé?—Jẹ́nẹ́sísì 1:29; 9:3, 4.

Kí àwọn àgùntàn lè máa bí sí i, èèyàn ní láti máa tọ́jú wọn. Iṣẹ́ Ébẹ́lì fi hàn pé láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìtàn aráyé làwọn èèyàn ti ń sin ẹran ọ̀sìn wọ̀nyí. Ìwé Mímọ́ kò sọ bóyá àwọn ará ìgbàanì ń mu wàrà, ṣùgbọ́n àwọn tí kì í jẹ ẹran pàápàá ń lo irun àgùntàn. Nígbà tí àgùntàn bá sì kú, awọ rẹ̀ wúlò lọ́pọ̀lọpọ̀. Fún àpẹẹrẹ, nígbà tí Jèhófà máa dáṣọ fún Ádámù àti Éfà, ńṣe ló “fi awọ ṣe ẹ̀wù gígùn” fún wọn.—Jẹ́nẹ́sísì 3:21.

Bó ti wù kó rí, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé níbẹ̀rẹ̀, Kéènì àti Ébẹ́lì fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ara wọn. Wọ́n jùmọ̀ pèsè nǹkan tí àwọn yòókù nínú ìdílé wọn nílò láti lè rí aṣọ wọ̀, kí wọ́n sì rí oúnjẹ jẹ.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

“Àwọn iṣẹ́ [Kéènì] burú, ṣùgbọ́n àwọn ti arákùnrin rẹ̀ jẹ́ òdodo”