A Rọ Àwọn Olùkọ́ni ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Láti Ṣe Iṣẹ́ Tá A Gbé Lé Wọn Lọ́wọ́
A Rọ Àwọn Olùkọ́ni ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Láti Ṣe Iṣẹ́ Tá A Gbé Lé Wọn Lọ́wọ́
ẸGBẸẸGBẸ̀RÚN lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn olùkọ́ni ló kóra jọ pọ̀ láti gba ìtọ́ni ní àwọn oṣù lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí. Bẹ̀rẹ̀ láti oṣù May ọdún tó kọjá ni wọ́n ti ń kóra jọ sí ọgọ́rọ̀ọ̀rún Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Àwọn Olùkọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jákèjádò ayé. A rọ àwọn tó pé jọpọ̀ náà pé kí wọ́n kọ́ ara wọn, kí wọ́n túbọ̀ tóótun sí i, kí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ olùkọ́ tí a gbé lé wọn lọ́wọ́.
Ǹjẹ́ o lọ sí ọ̀kan lára àwọn àpéjọpọ̀ wọ̀nyí? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ó dájú pé wàá mọrírì àwọn oúnjẹ àtàtà nípa tẹ̀mí tá a jẹ láwọn àpéjọpọ̀ wọ̀nyí, tó wà fún jíjọ́sìn Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́. Ẹ jẹ́ ká jùmọ̀ gbé ìtòlẹ́sẹẹsẹ tó kún fún ìtọ́ni ní àpéjọpọ̀ náà yẹ̀ wò.
Ọjọ́ Kìíní—Ìwé Mímọ́ Tí Ó Ní Ìmísí Ṣàǹfààní fún Kíkọ́ni
Alága àpéjọpọ̀ náà fi tọ̀yàyàtọ̀yàyà kí àwọn tó pé jọpọ̀ káàbọ̀ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ náà “Ẹ Gba Ìtọ́ni, Ẹ̀yin Olùkọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.” Jésù Kristi di Olùkọ́ Ńlá nítorí pé ó gba ẹ̀kọ́ látọ̀dọ̀ Jèhófà ‘Olùkọ́ni Atóbilọ́lá’ náà. (Aísáyà 30:20; Mátíù 19:16) Bá a bá fẹ́ tẹ̀ síwájú gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àwa náà gbọ́dọ̀ gba ìtọ́ni lọ́dọ̀ Jèhófà.
Ọ̀rọ̀ tí ó tẹ̀ lé e ni “Kíkọ́ Àwọn Ẹlòmíràn Nípa Ìjọba Náà Ń Mú Èso Rere Jáde.” Nípa fífọ̀rọ̀ wá àwọn olùkọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó nírìírí lẹ́nu wò, a rí ayọ̀ àti àwọn ìbùkún tó wà nínú sísọni di ọmọ ẹ̀yìn.
Ìṣe 2:11) Àwa náà lè sún àwọn èèyàn gbégbèésẹ̀ nípa pípolongo irú “àwọn ohun ọlá ńlá” bí àwọn ẹ̀kọ́ inú Ìwé Mímọ́ nípa ìràpadà, àjíǹde, àti májẹ̀mú tuntun.
Ọ̀rọ̀ títanijí kan tí a pe àkòrí rẹ̀ ní “‘Àwọn Ohun Ọlá Ńlá Ọlọ́run’ Ń Ru Wá Sókè Láti Ṣe Rere” ló tẹ̀ lé e. “Àwọn ohun ọlá ńlá” tó ní í ṣe pẹ̀lú Ìjọba Ọlọ́run ló sún àwọn ènìyàn gbégbèésẹ̀ ní ọ̀rúndún kìíní. (Ọ̀rọ̀ tó tẹ̀ lé e rọ gbogbo èèyàn láti “Ní Inú Dídùn Nínú Òdodo Jèhófà.” (Sáàmù 35:27) Yóò ṣeé ṣe fún wa láti máa lépa òdodo bí a bá ń kọ́ láti nífẹ̀ẹ́ òdodo, kí a sì kórìíra ohun búburú, bí a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, bí a bá ń fi taratara gbéjà ko àwọn nǹkan tó lè ṣàkóbá fún wa nípa tẹ̀mí, tí a sì ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀. Irú ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀ yóò dáàbò bò wá kúrò nínú kíkó ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́, kúrò nínú ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì, àti kúrò nínú eré ìnàjú oníwà pálapàla àti oníwà ipá.
Lájorí àsọyé tí a pe àkòrí rẹ̀ ní, “A Ti Mú Wa Gbára Dì fún Iṣẹ́ Olùkọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run,” rán wa létí pé Jèhófà fi wá ṣe òjíṣẹ́ rẹ̀ tí ó tóótun nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, àti ètò àjọ rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé. Nípa lílo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, olùbánisọ̀rọ̀ náà gbà wá níyànjú pé: “Góńgó wa ni láti la ìhìn inú Bíbélì yé àwọn olùgbọ́ wa yékéyéké, kí ó sì wọ̀ wọ́n lọ́kàn ṣinṣin.”
Àkòrí àpínsọ àsọyé àkọ́kọ́ ní àpéjọpọ̀ náà ni “Bá A Ti Ń Kọ́ Àwọn Ẹlòmíràn, Ẹ Jẹ́ Ká Máa Kọ́ Ara Wa.” Apá tó ṣáájú tẹnu mọ́ ọn pé a gbọ́dọ̀ pa ìlànà gíga ti ìwà rere Kristẹni tá a fi ń kọ́ àwọn ẹlòmíràn mọ́. Apá tí ó tẹ̀ lé e gbà wá níyànjú láti “fi ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́.” (2 Tímótì 2:15) Láti kọ́ ara wa, ìdákẹ́kọ̀ọ́ aláápọn tá à ń ṣe déédéé nínú Bíbélì ṣe pàtàkì, bó ti wù kó ti pẹ́ tó tá a ti ń sin Ọlọ́run. Apá tó kẹ́yìn nínú àpínsọ àsọyé náà fi hàn pé Èṣù ń ṣọ́ wá lójú méjèèjì láti rí i bóyá a ní àwọn ìwà bí ìgbéraga, ẹ̀mí jẹ́-n-ṣe-tèmi, ẹ̀mí ìjọra ẹni lójú, owú, ìlara, ìbínú, ìkórìíra, àti ẹ̀mí wíwá ẹ̀sùn síni lọ́rùn lára wa. Àmọ́ bí a bá fi tokuntokun kọjú ìjà sí Èṣù, yóò sá kúrò lọ́dọ̀ wa. Ká tó lè kọjú ìjà sí i, a ní láti sún mọ́ Ọlọ́run.—Jákọ́bù 4:7, 8.
Ọ̀rọ̀ tó bágbà mu náà, “Ẹ Kórìíra Àwọn Ohun Arùfẹ́-Ìṣekúṣe-Sókè Tó Ti Di Àjàkálẹ̀ Hábákúkù 1:13) A gbọ́dọ̀ “fi tẹ̀gàntẹ̀gàn kórìíra ohun burúkú.” (Róòmù 12:9) A wá rọ àwọn òbí láti kíyè sí bí àwọn ọmọ wọn ṣe ń lo Íńtánẹ́ẹ̀tì àti ohun tí wọ́n ń wò lórí tẹlifíṣọ̀n. Olùbánisọ̀rọ̀ náà sọ fáwọn tí ń wo àwọn ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè pé kí wọ́n lọ gba ìrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ tó dàgbà dénú nípa tẹ̀mí. Ohun mìíràn tó tún lè ràn wá lọ́wọ́ ni pé ká máa ṣe àṣàrò lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ bíi Sáàmù 97:10; Mátíù 5:28; 1 Kọ́ríńtì 9:27; Éfésù 5:3, 12; Kólósè 3:5; àti 1 Tẹsalóníkà 4:4, 5, ká sì há wọn sórí pẹ̀lú.
Àrùn Nínú Ayé,” fi hàn wá bí a ó ṣe kojú àwọn ohun tí ń sọ ipò tẹ̀mí wa dìbàjẹ́. Wòlíì Hábákúkù sọ nípa Jèhófà pé: “Ojú rẹ ti mọ́ gaara jù láti rí ohun tí ó burú; ìwọ kò sì lè wo ìdààmú.” (Ọ̀rọ̀ tí ó tẹ̀ lé e, “Jẹ́ Kí Àlàáfíà Ọlọ́run Máa Ṣọ́ Ọ,” tù wá nínú gan-an nípa mímú un dá wá lójú pé nígbà tí àníyàn bá mú wa rẹ̀wẹ̀sì, a lè ju ẹrù ìnira wa sọ́dọ̀ Jèhófà. (Sáàmù 55:22) Bí a bá sọ ohun tó wà lọ́kàn wa jáde nínú àdúrà, Jèhófà yóò fún wa ní “àlàáfíà Ọlọ́run,” ìyẹn ni ìparọ́rọ́ àti ìbàlẹ̀ ọkàn tó máa ń jẹ yọ látinú àjọṣe pàtàkì tá a ní pẹ̀lú rẹ̀.—Fílípì 4:6, 7.
Ọjọ́ kìíní parí lọ́nà tó múnú wa dùn gan-an pẹ̀lú ọ̀rọ̀ náà “Jèhófà Fi Ìmọ́lẹ̀ Bu Ẹwà Kún Àwọn Èèyàn Rẹ̀,” tó ṣàlàyé ìmúṣẹ Aísáyà orí ọgọ́ta. Láàárín òkùnkùn ayé ìsinsìnyí, “àwọn àjèjì”—ìyẹn àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá ti àwọn àgùntàn mìíràn—ń gbádùn ìmọ́lẹ̀ Jèhófà pẹ̀lú àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró. Olùbánisọ̀rọ̀ náà tọ́ka sí ẹsẹ kọkàndínlógún àti ogún, ó sì ṣàlàyé pé: “Jèhófà kò ní ‘wọ̀’ bí oòrùn, bẹ́ẹ̀ ni kò ní ‘wọ̀ọ̀kùn’ bí òṣùpá. Jèhófà yóò máa bá a lọ láti bu ẹwà kún àwọn ènìyàn rẹ̀ nípa títan ìmọ́lẹ̀ sí wọn. Ọ̀rọ̀ yìí mà fi wá lọ́kàn balẹ̀ pẹ̀sẹ̀ o, bí a ṣe ń gbé ní àkókò òpin ayé tó ṣókùnkùn yìí!” Ní ìparí àsọyé náà, olùbánisọ̀rọ̀ náà kéde ìmújáde ìwé Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kejì. Ṣé o ti ka ìtẹ̀jáde tuntun yìí tán?
Ọjọ́ Kejì—A Tóótun Tẹ́rùntẹ́rùn Láti Kọ́ Àwọn Ẹlòmíràn
Lẹ́yìn ìjíròrò ẹsẹ ojoojúmọ́ ní ọjọ́ kejì, a wá tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́ sí àpínsọ àsọyé kejì ní àpéjọpọ̀ náà, “Àwọn Òjíṣẹ́ Táwọn Ẹlòmíràn Ń Tipasẹ̀ Wọn Di Onígbàgbọ́.” Àwọn tó sọ̀rọ̀ lórí àpínsọ àsọyé alápá mẹ́ta yìí tẹnu mọ́ ọ̀kọ̀ọ̀kan lára àwọn apá mẹ́ta tí ríran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti di onígbàgbọ́ pín sí—àwọn ni wíwàásù ìhìn Ìjọba náà, pípadà bẹ àwọn tó fìfẹ́ hàn sí ọ̀rọ̀ wa wò àti kíkọ́ àwọn olùfìfẹ́hàn láti ṣe ohun tí Kristi pa láṣẹ. Nípasẹ̀ ìfọ̀rọ̀wáni-lẹ́nuwò àti ṣíṣe àṣefihàn àwọn ìrírí, ó ṣeé ṣe fún wa láti rí ọ̀nà tá a lè gbà kọ́ àwọn ẹlòmíràn láti di ọmọ ẹ̀yìn.
Apá tí ó tẹ̀ lé e dá lórí ẹṣin ọ̀rọ̀ náà, “Ẹ Fi Ìfọkànsin Ọlọ́run Kún Ìfaradà Yín.” Olùbánisọ̀rọ̀ náà fi hàn pé ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ ni pé ká ‘fara dà á títí dé òpin.’ (Mátíù 24:13) A gbọ́dọ̀ lo gbogbo ohun tí Ọlọ́run pèsè fún wa láti ràn wá lọ́wọ́ kí a lè mú ìfọkànsìn Ọlọ́run dàgbà, ìyẹn àdúrà, ìdákẹ́kọ̀ọ́, ìpàdé, àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà. A ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìfẹ́ ayé àti àwọn ìgbòkègbodò ayé ba ẹ̀mí ìfọkànsin wa jẹ́.
Báwo ni àwọn tí wọ́n ń ṣe làálàá tí a sì di ẹrù wọ̀ lọ́rùn ṣe lè rí ìtura lónìí? Ọ̀rọ̀ náà, “Rírí Ìtura Lábẹ́ Àjàgà Kristi” dáhùn ìbéèrè yẹn. Jésù fi pẹ̀lẹ́tù ké sí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti wá sí abẹ́ àjàgà òun, kí wọ́n sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ òun. (Mátíù 11:28-30) A lè wá sí abẹ́ àjàgà Jésù nípa gbígbé irú ìgbésí ayé oníwọ̀ntúnwọ̀nsì tó gbé. Kókó pàtàkì inú ọ̀rọ̀ yìí la rí kedere nígbà tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá àwọn tó ti gbé ìgbésí ayé oníwọ̀ntúnwọ̀nsì lẹ́nu wò.
Ọ̀kan lára àwọn ohun pàtàkì tó máa ń wáyé nígbà àpéjọpọ̀ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ṣíṣe ìrìbọmi fún àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ya ara wọn sí mímọ́. Arákùnrin tó sọ àwíyé náà “Ìrìbọmi Ń Jẹ́ Ká Láǹfààní Púpọ̀ Sí I Láti Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́” fi tọ̀yàyàtọ̀yàyà kí àwọn tó fẹ́ ṣe batisí káàbọ̀, ó sì ké sí wọn láti kópa nínú àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn púpọ̀ sí i. Àwọn olùkọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe batisí, tí wọ́n sì dójú ìwọ̀n ohun tí Ìwé Mímọ́ là sílẹ̀ lè nàgà fún onírúurú ẹrù iṣẹ́ nínú ìjọ.
“Fara Wé Olùkọ́ Ńlá Náà” ni àkòrí àsọyé àkọ́kọ́ lọ́sàn-án ọjọ́ yẹn. Àìmọye ọdún ni Jésù ti fara balẹ̀ kíyè sí Baba rẹ̀ ní ọ̀run, tó sì fara wé e, tó wá tipa bẹ́ẹ̀ di Olùkọ́ Ńlá náà. Nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé, ó lo ọgbọ́n ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tó gbéṣẹ́, irú bí àwọn ìbéèrè tó wọni lọ́kàn àti àwọn àpèjúwe tó rọrùn tó sì yéni yékéyéké. Jésù gbé ọ̀rọ̀ rẹ̀ ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó sì fi ìtara, ọ̀yàyà, àti ọlá àṣẹ sọ ọ́. Ǹjẹ́ ìyẹn ò wú àwa náà lórí láti fara wé Olùkọ́ Ńlá náà?
Àsọyé mìíràn tó tún tani jí, “Ṣé O Múra Tán Láti Sin Àwọn Ẹlòmíràn?,” gbà wá níyànjú láti fara wé àpẹẹrẹ Jésù nínú sísin àwọn ẹlòmíràn. (Jòhánù 13:12-15) Alásọyé náà bá àwọn ọkùnrin tí ó tóótun sọ̀rọ̀ ní tààràtà nígbà tó rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n fara wé Tímótì ní lílo gbogbo àǹfààní tí wọ́n ní láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́. (Fílípì 2:20, 21) Ó rọ àwọn òbí láti fara wé Ẹlikénà àti Hánà ní ríran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti lépa iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Ó sì gba àwọn ọ̀dọ́ níyànjú láti fara wé àpẹẹrẹ Jésù Kristi àti ti Tímótì ọ̀dọ́ nípa fífi tinútinú yọ̀ǹda ara wọn. (1 Pétérù 2:21) Ọ̀rọ̀ tí àwọn tó ti lo àǹfààní tí wọ́n ní láti sin àwọn ẹlòmíràn sọ ru wá sókè gan-an ni.
Àkòrí àpínsọ àsọyé kẹta ni “Jàǹfààní Ní Kíkún Látinú Ẹ̀kọ́ Tí Ọlọ́run Ń Kọ́ni.” Ẹni tó kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì fífi kún bí a ṣe ń pọkàn pọ̀. Láti ṣe ìyẹn, a lè bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú dídákẹ́kọ̀ọ́ fún àkókò díẹ̀ kí a sì gbìyànjú láti fi kún àkókò náà. Ó tún rọ àwùjọ pé kí wọ́n máa ṣí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́, kí wọ́n sì máa ṣàkọsílẹ̀ nígbà tí ìpàdé bá ń lọ lọ́wọ́. Ẹni tí ó sọ̀rọ̀ ṣìkejì jẹ́ ká mọ ìdí tó fi yẹ láti máa di “àpẹẹrẹ àwọn ọ̀rọ̀ afúnni-nílera” mú ṣinṣin. (2 Tímótì 1:13, 14) Láti dáàbò bo ara wa lọ́wọ́ ìwà pálapàla tí àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn ń gbé jáde, ìmọ̀ ọgbọ́n orí ènìyàn, àwọn aṣelámèyítọ́ ìtàn àti ìtumọ̀ Ìwé Mímọ́, àti ẹ̀kọ́ àwọn apẹ̀yìndà, a gbọ́dọ̀ ra àkókò padà fún dídákẹ́kọ̀ọ́ àti lílọ sí àwọn ìpàdé. (Éfésù 5:15, 16) Ẹni tó sọ apá tó kẹ́yìn nínú àpínsọ náà tẹnu mọ́ ìdí tó fi ṣe pàtàkì láti ṣe ohun tí à ń kọ́ kí á lè jàǹfààní kíkún nínú ẹ̀kọ́ ìṣàkóso Ọlọ́run.—Fílípì 4:9.
Inú wa dùn gan-an láti gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, “Àwọn Ìpèsè Tuntun Tí Yóò Mú Wa Tẹ̀ Síwájú Nípa Tẹ̀mí”! A láyọ̀ láti gbọ́ pé a óò mú ìwé tuntun kan tí a pe àkòrí rẹ̀ ní Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run jáde láìpẹ́. Ńṣe ló dà bíi pé kí ìwé náà ti tẹ̀ wá lọ́wọ́ bí olùbánisọ̀rọ̀ náà ṣe ń ṣàlàyé ohun tó wà nínú rẹ̀ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé. Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí apá tó ní ìmọ̀ràn ọ̀rọ̀ sísọ mélòó kan nínú ìwé náà, ó ní: “Kì í ṣe bíi tàwọn ìwé ayé ni ìwé tuntun yìí ṣe ṣàlàyé àwọn kókó mẹ́tàléláàádọ́ta yìí, tó dá lórí ìwé kíkà, ọ̀rọ̀ sísọ, àti kíkọ́ni lọ́nà tó dára. Orí ìlànà Ìwé Mímọ́ ló gbé àlàyé wọn kà.” Ìwé náà yóò fi bí àwọn wòlíì, Jésù, àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ṣe fi kíkọ́ni lọ́nà tó dára hàn. Dájúdájú, ìwé yìí àti àwọn apá tuntun tí Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run ní yóò ràn wá lọ́wọ́ láti di olùkọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó sunwọ̀n sí i.Ọjọ́ Kẹta—Ẹ Jẹ́ Olùkọ́ Lójú Ìwòye Ibi Tí Àkókò Dé
Lẹ́yìn ìjíròrò ẹ̀kọ́ ojoojúmọ́ ní ọjọ́ tó kẹ́yìn, gbogbo èèyàn ló tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́ sí àpínsọ àsọyé tó kẹ́yìn nínú àpéjọpọ̀ náà, “Àsọtẹ́lẹ̀ Málákì Múra Wa Sílẹ̀ De Ọjọ́ Jèhófà.” Málákì sàsọtẹ́lẹ̀ ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún lẹ́yìn táwọn Júù padà dé láti Bábílónì. Wọ́n tún ti padà sídìí ìpẹ̀yìndà àti ìwà ibi, wọ́n sì ti ń tàbùkù sórúkọ Jèhófà nípa títàpá sí àwọn òfin òdodo rẹ̀, àti nípa mímú àwọn ẹran tó fọ́jú, èyí tó yarọ, àti èyí tó ń ṣàìsàn wá fún ìrúbọ. Ìyẹn nìkan kọ́ o, wọ́n tún ń kọ àwọn aya ìgbà èwe wọn sílẹ̀, bóyá kí wọ́n lè fẹ́ àwọn obìnrin àjèjì.
Orí àkọ́kọ́ nínú àsọtẹ́lẹ̀ Málákì mú un dá wa lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn ènìyàn rẹ̀. Ó tẹnu mọ́ ìdí tó fi ṣe pàtàkì láti ní ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ fún Ọlọ́run, kí a sì mọrírì àwọn ohun mímọ́. Jèhófà retí pé ohun tó ṣeyebíye jù lọ lójú wa ló yẹ ká fún òun, ká máa sin òun nítorí ìfẹ́ àìmọtara ẹni nìkan tá a ní fún òun. Iṣẹ́ ìsìn mímọ́ wa kò gbọ́dọ̀ jẹ́ ojú ayé lásán, a óò jíhìn fún Ọlọ́run.
Nígbà tí ẹni tó sọ̀rọ̀ ṣìkejì ń fi orí kejì Málákì wé ọjọ́ wa, ó béèrè pé: “Ṣé a mọ̀ pé a kò gbọ́dọ̀ rí ‘àìṣòdodo kankan ní ètè wa’?” (Málákì 2:6) Àwọn tó ń mú ipò iwájú nínú kíkọ́ni gbọ́dọ̀ rí i dájú pé orí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run làwọn gbé ohun táwọn ń sọ kà. A gbọ́dọ̀ yẹra fún irú ìwà àdàkàdekè bíi jíjáwèé ìkọ̀sílẹ̀ lọ́nà tí kò tọ́.—Málákì 2:14-16.
Ẹni tó sọ̀rọ̀ kẹ́yìn nínú àpínsọ àsọyé náà múra wa sílẹ̀ de ọjọ́ Jèhófà. Ẹṣin ọ̀rọ̀ tó sọ̀rọ̀ lé lórí ni, “Àwọn Wo Ni Yóò La Ọjọ́ Jèhófà Já?” Olùbánisọ̀rọ̀ náà sọ pé: “Ó mà ń tu àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà nínú o, láti mọ̀ pé àwọn gan-an Málákì orí kẹta, ẹsẹ kẹtàdínlógún, ń ṣẹ sí lára! “Ó sọ pé: ‘“Dájúdájú, wọn yóò sì di tèmi,” ni Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí, “ní ọjọ́ náà nígbà tí èmi yóò mú àkànṣe dúkìá wá. Èmi yóò sì fi ìyọ́nú hàn sí wọn, gan-an gẹ́gẹ́ bí ènìyàn ṣe ń fi ìyọ́nú hàn sí ọmọ rẹ̀ tí ń sìn ín.”’”
niApá pàtàkì mìíràn tí àpéjọpọ̀ náà ní ni àwòkẹ́kọ̀ọ́ tó jẹ́ ti ìgbàanì tá a pè ní “Máa Bọ̀wọ̀ fún Ọlá Àṣẹ Jèhófà,” tó dá lórí àwọn ọmọ Kórà. Láìfi ẹ̀mí ọ̀tẹ̀ tí baba wọn ní sí Mósè àti Áárónì pè, wọ́n dúró ṣinṣin ti Jèhófà àti àwọn aṣojú rẹ̀. Nígbà tí Kórà àtàwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ ṣègbé, àwọn ọmọ Kórà mórí bọ́. Àsọyé tó tẹ̀ lé e, “Fi Ìdúróṣinṣin Tẹrí Ba fún Ọlá Àṣẹ Ọlọ́run,” sọ bí àwòkẹ́kọ̀ọ́ náà ṣe kan ẹnì kọ̀ọ̀kan wa. Olùbánisọ̀rọ̀ náà kìlọ̀ nípa ọ̀nà mẹ́fà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí Kórà àtàwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ ti kùnà: ṣíṣàì fi ìṣòtítọ́ ṣètìlẹyìn fún ọlá àṣẹ Jèhófà; jíjẹ́ kí ìgbéraga, ìkánjú láti dé ipò ọlá, àti owú kó sí wọn lórí; rírí kìkì àìpé àwọn tí Jèhófà yàn; dídi oníkùnsínú; dídi ẹni tí àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tí wọ́n ní kò tẹ́ lọ́rùn; àti kíka àjọṣe àárín ọ̀rẹ́ àti ẹbí sí ohun tó ṣe pàtàkì ju ìdúróṣinṣin sí Jèhófà.
“Àwọn Wo Ló Ń Fi Òtítọ́ Kọ́ Gbogbo Orílẹ̀-Èdè?” ni ẹṣin ọ̀rọ̀ àsọyé fún gbogbo ènìyàn. Òtítọ́ tó ṣàlàyé rẹ̀, kì í ṣe òtítọ́ lásán, bí kò ṣe òtítọ́ nípa ète Jèhófà tí Jésù Kristi jẹ́rìí sí. Olùbánisọ̀rọ̀ náà ṣàgbéyẹ̀wò òtítọ́ tó ní í ṣe pẹ̀lú ìgbàgbọ́, òtítọ́ tó ní í ṣe pẹ̀lú bá a ṣe ń jọ́sìn, àti òtítọ́ tó ní í ṣe pẹ̀lú ìwà wa. Nípa fífi àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní wé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà òde òní, ìdánilójú tá a ní pé ‘Ọlọ́run wà láàárín wa ní ti tòótọ́’ túbọ̀ fìdí múlẹ̀.—1 Kọ́ríńtì 14:25.
Lẹ́yìn àkópọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ fún ọ̀sẹ̀ yẹn ni a gbún gbogbo àwọn olùkọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó wà láwùjọ ní kẹ́sẹ́ nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ àsọparí náà, “Ẹ Jẹ́ Ká Máa Fi Ìyárakánkán Ṣe Iṣẹ́ Ìkọ́ni Táa Gbé Lé Wa Lọ́wọ́.” Àtúnyẹ̀wò ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà ní ṣókí tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì lílo Ìwé mímọ́ nínú iṣẹ́ ìkọ́ni, àwọn ọ̀nà tá a lè gbà di olùkọ́ tí ó tóótun, àti bó ṣe yẹ ká ní ìdánilójú nínú òtítọ́ tá a fi ń kọ́ àwọn ẹlòmíràn. Olùbánisọ̀rọ̀ náà gbà wá níyànjú láti jẹ́ kí ‘ìlọsíwájú wa fara hàn kedere,’ ká sì ‘máa fiyè sí ara wa nígbà gbogbo àti sí ẹ̀kọ́ wa.’—1 Tímótì 4:15, 16.
Ẹ ò rí i pé àsè tẹ̀mí kíkọyọyọ la gbádùn ní Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Àwọn Olùkọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run”! Ǹjẹ́ kí a máa fara wé Jèhófà, Olùkọ́ni wa Atóbilọ́lá, àti Jésù Kristi, Olùkọ́ Ńlá wa, bá a ṣe ń kọ́ àwọn ẹlòmíràn ní ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Àwọn Ìtẹ̀jáde Tuntun Láti Kájú Àwọn Àìní Àrà Ọ̀tọ̀
Àwọn tó wá sí Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Àwọn Olùkọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” fi tayọ̀tayọ̀ gba ìtẹ̀jáde méjì tó máa ṣèrànwọ́ gan-an nínú fífi òtítọ́ inú Ìwé Mímọ́ kọ́ àwọn èèyàn láwọn apá ibì kan láyé. Ìwé àṣàrò kúkúrú tá a pe àkọlé rẹ̀ ní Ǹjẹ́ Ẹ̀mí Èèyàn Máa Ń Kú? yóò jẹ́ ohun èlò tó gbéṣẹ́ gan-an láti bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò pẹ̀lú àwọn tó ń gbé láwọn ilẹ̀ tí èdè àdúgbò kò ti fìyàtọ̀ sáàárín “ọkàn” àti “ẹ̀mí.” Àṣàrò kúkúrú tuntun náà fi hàn kedere pé ipá ẹ̀mí yàtọ̀ sí ẹ̀dá ẹ̀mí, àti pé àwọn èèyàn kì í di ẹ̀dá ẹ̀mí nígbà tí wọ́n bá kú.
Ìwé pẹlẹbẹ náà, A Satisfying Life—How to Attain It la mú jáde lédè Gẹ̀ẹ́sì ní òpin ọjọ́ kejì àpéjọpọ̀ náà. A ṣètò ìwé pẹlẹbẹ yìí fún bíbẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn tí kò mọ̀ pé Ẹlẹ́dàá kan tó jẹ́ ẹni gidi wà, tí wọn ò sì mọ̀ pé ìwé kan wà tí Ọlọ́run mí sí. Ṣé o ti lo ìtẹ̀jáde tuntun wọ̀nyí nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Ọgọ́rọ̀ọ̀rún ènìyàn ló ṣe batisí ní Milan, Ítálì, àti láwọn àpéjọpọ̀ àgbègbè mìíràn kárí ayé
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Àwòkẹ́kọ̀ọ́ náà, “Máa Bọ̀wọ̀ fún Ọlá Àṣẹ Jèhófà,” wú àwùjọ lórí