Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Iṣẹ́ Àtàtà Ń Yin Ọlọ́run Lógo

Iṣẹ́ Àtàtà Ń Yin Ọlọ́run Lógo

Iṣẹ́ Àtàtà Ń Yin Ọlọ́run Lógo

ÀWỌN Kristẹni tòótọ́ ń mú ògo wá fún Ọlọ́run, nípasẹ̀ ìwà rere tí wọ́n ń hù àti àwọn iṣẹ́ àtàtà tí wọ́n ń ṣe. (1 Pétérù 2:12) A lè rí èyí nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ ní Ítálì láwọn ọdún àìpẹ́ yìí.

Ní September 1997, ìsẹ̀lẹ̀ lílágbára kan wáyé ní àwọn apá ibi mélòó kan ní àgbègbè Marche àti Umbria, ó sì ba àwọn ilé bí ẹgbàá márùnlélógójì [90,000] jẹ́. Ojú ẹsẹ̀ ni àwùjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣèrànwọ́ fáwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn àtàwọn ẹlòmíràn. Wọ́n kó àwọn ọkọ̀ àfiṣelé, àpò àtẹ́sùn, sítóòfù, ẹ̀rọ amúnáwá, àti àwọn nǹkan mìíràn tí wọ́n máa nílò wá fún wọn. Gbogbo ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n ṣe wọ̀nyí làwọn èèyàn kíyè sí.

Ìwé ìròyìn Il Centro ròyìn pé: “Àwọn to kọ́kọ́ kó àwọn ohun àfiṣèrànwọ́ wá sí àwọn àgbègbè tí ọ̀ràn kàn náà ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Roseto [ní ẹkùn-ìpínlẹ̀ Teramo] . . . Yàtọ̀ sí pípàdé láti gbàdúrà lóòrèkóòrè, àwọn tó jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà wọ̀nyẹn tún ń ṣe àwọn ohun tó wúlò fáwọn èèyàn, wọ́n ń ṣèrànwọ́ fáwọn tí ìyà ń jẹ, láìfi ẹ̀sìn yòówù tí wọ́n ń ṣe pè.”

Olórí ìlú Nocera Umbra, ìyẹn ọ̀kan lára àwọn ìlú tí ọ̀ràn náà kàn jù lọ, kọ̀wé sí àwọn Ẹlẹ́rìí, ó ní: “Mo dúpẹ́ gidigidi lọ́wọ́ yín fún ìrànlọ́wọ́ tí ẹ ṣe fún àwa ará ìlú Nocera. Ó sì dá mi lójú pé gbogbo aráàlú ló mọrírì ohun tí ẹ ṣe.” Ìyẹn nìkan kọ́ o, Ilé Iṣẹ́ Ọ̀ràn Abẹ́lé tún fún Congregazione Cristiana dei Testimoni di Geova (Ìjọ Kristẹni ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà) ní ìwé ẹ̀rí ìgbóríyìnfúnni àti àmì ẹ̀yẹ kan “láti jẹ́rìí sí iṣẹ́ tí wọ́n ṣe àti jíjẹ́ tí wọ́n jẹ́ aláápọn nínú iṣẹ́ pàjáwìrì tó yọjú ní àwọn ẹkùn ilẹ̀ Umbria àti Marche.”

Ní October ọdún 2000, ìkún omi bíburú jáì kan ṣẹlẹ̀ ní ẹkùn Piedmont tó wà ní àríwá Ítálì. Ojú ẹsẹ̀ làwọn Ẹlẹ́rìí tún gbégbèésẹ̀ láti ṣèrànwọ́. Àwọn èèyàn sì kíyè sí àwọn iṣẹ́ àtàtà wọ̀nyí. Ẹkùn Ilẹ̀ náà fún wọn ní àmì ẹ̀yẹ kan fún “iṣẹ́ àtàtà tí wọ́n fínnúfíndọ̀ ṣe láti ṣèrànwọ́ fún àwọn ará Piedmont tó fojú winá ìkún omi náà.”

Jésù Kristi fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nítọ̀ọ́ni pé: “Kí ìmọ́lẹ̀ yín máa tàn níwájú àwọn ènìyàn, kí wọ́n lè rí àwọn iṣẹ́ àtàtà yín, kí wọ́n sì lè fi ògo fún Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run.” (Mátíù 5:16) Nípa ṣíṣe “iṣẹ́ àtàtà” láti fi ran àwọn aládùúgbò wọn lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí àti láwọn ọ̀nà mìíràn, Ọlọ́run ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń fi tayọ̀tayọ̀ yìn lógo, kì í ṣe ara wọn.