Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jèhófà Jẹ́ Aláìlẹ́gbẹ́ Nínú Rere Ṣíṣe

Jèhófà Jẹ́ Aláìlẹ́gbẹ́ Nínú Rere Ṣíṣe

Jèhófà Jẹ́ Aláìlẹ́gbẹ́ Nínú Rere Ṣíṣe

“Ẹ gbé Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun lárugẹ, nítorí tí Jèhófà jẹ́ ẹni rere!”—JEREMÁYÀ 33:11.

1. Kí nìdí tí ọkàn wa fi ń sún wa láti yin Ọlọ́run lógo fún oore rẹ̀?

 JÈHÓFÀ ỌLỌ́RUN jẹ́ ẹni rere látòkè délẹ̀, láìkù síbì kan. Wòlíì náà, Sekaráyà, kéde pé: “Wo bí oore rẹ̀ ti pọ̀ tó!” (Sekaráyà 9:17) Àní sẹ́, rere ṣíṣe fara hàn nínú gbogbo iṣẹ́ Ọlọ́run nígbà tó ń dá ilẹ̀ ayé fún ìgbádùn wa. (Jẹ́nẹ́sísì 1:31) Kò sí bá a ṣe lè rídìí gbogbo ìlànà dídíjú tí Ọlọ́run gbé kalẹ̀ nígbà tó ṣẹ̀dá àgbáyé. (Oníwàásù 3:11; 8:17) Àmọ́ kékeré tá a mọ̀ nípa àgbáyé ń sún wa láti yin Ọlọ́run lógo fún oore rẹ̀.

2. Báwo lo ṣe máa ṣàpèjúwe ìwà rere?

2 Kí ni ìwà rere? Ó túmọ̀ sí ṣíṣe àwọn èèyàn lóore. Àmọ́, ó tún ré kọjá ṣíṣàì hùwà búburú. Ìwà rere jẹ́ ara èso tẹ̀mí, ó sì wé mọ́ ṣíṣe ohun tó dára. (Gálátíà 5:22, 23) A lè sọ pé a ṣe rere nígbà tá a bá ṣe àwọn nǹkan tó ṣàǹfààní fáwọn èèyàn. Nínú ètò àwọn nǹkan yìí, ohun táwọn kan kà sí ìwà rere lè jẹ́ ìwà búburú lọ́dọ̀ àwọn míì. Àmọ́, bí a óò bá gbádùn àlàáfíà àti ayọ̀, ìlànà kan ṣoṣo ló wà fún ìwà rere. Ta ló lẹ́tọ̀ọ́ láti pinnu ìlànà náà?

3. Kí ni Jẹ́nẹ́sísì 2:16, 17 sọ nípa ìlànà ìwà rere?

3 Ọlọ́run ló ń pinnu ìlànà ìwà rere. Ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìtàn aráyé, Jèhófà pàṣẹ fún ọkùnrin àkọ́kọ́ pé: “Nínú gbogbo igi ọgbà ni kí ìwọ ti máa jẹ àjẹtẹ́rùn. Ṣùgbọ́n ní ti igi ìmọ̀ rere àti búburú, ìwọ kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú rẹ̀, nítorí ọjọ́ tí ìwọ bá jẹ nínú rẹ̀, dájúdájú, ìwọ yóò kú.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:16, 17) Bẹ́ẹ̀ ni o, ojú Ẹlẹ́dàá ló yẹ kí èèyàn máa wò láti mọ ohun tó jẹ́ rere àti búburú.

Oore Àìlẹ́tọ̀ọ́sí

4. Kí ni Ọlọ́run ti ṣe fáráyé látìgbà tí Ádámù ti dẹ́ṣẹ̀?

4 Ìrètí aráyé fún ayọ̀ ayérayé nínú ìjẹ́pípé fẹ́rẹ̀ẹ́ wọmi nígbà tí Ádámù dẹ́ṣẹ̀, tó sì kọ̀ láti gbà pé Ọlọ́run ló lẹ́tọ̀ọ́ láti pinnu ìlànà ìwà rere. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6) Ṣùgbọ́n kó tó di pé Ádámù bí àwọn ọmọ rẹ̀ tó máa jogún ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú ni Ọlọ́run ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa Irú Ọmọ pípé kan tí ń bọ̀. Nígbà tí Jèhófà ń bá “ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà,” ìyẹn Sátánì Èṣù wí, ó sọ pé: “Èmi yóò sì fi ìṣọ̀tá sáàárín ìwọ àti obìnrin náà àti sáàárín irú-ọmọ rẹ àti irú-ọmọ rẹ̀. Òun yóò pa ọ́ ní orí, ìwọ yóò sì pa á ní gìgísẹ̀.” (Ìṣípayá 12:9; Jẹ́nẹ́sísì 3:15) Ète Jèhófà ni láti ra aráyé ẹlẹ́ṣẹ̀ padà. Oore tí a kò lẹ́tọ̀ọ́ sí rárá ni Jèhófà ṣe fún wa nígbà tó ṣe ètò yẹn fún ìgbàlà àwọn tó bá lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n.—Mátíù 20:28; Róòmù 5:8, 12.

5. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti dẹni tí ń gbèrò ibi, èé ṣe tá a fi lè máa ṣe rere títí dé àyè kan?

5 Àmọ́ ṣá o, ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù ló jẹ́ ká dẹni tó ń gbèrò ibi. (Jẹ́nẹ́sísì 8:21) Ṣùgbọ́n a dúpẹ́ pé Jèhófà ń ràn wá lọ́wọ́ láti máa hùwà rere títí dé àyè kan. Títẹ̀síwájú nínú àwọn ohun tí a ti kọ́ nínú Ìwé Mímọ́, ìwé àtàtà nì, ‘ń sọ wá di ọlọgbọ́n fún ìgbàlà,’ ó sì ‘ń mú wa gbára dì fún iṣẹ́ rere gbogbo.’ Àmọ́ kò mọ síbẹ̀ yẹn. Àní ó tún ń jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti máa ṣe ohun rere lójú Ọlọ́run. (2 Tímótì 3:14-17) Ṣùgbọ́n kí á bàa lè jàǹfààní látinú ìtọ́ni Ìwé Mímọ́, ká sì máa ṣe rere nìṣó, a gbọ́dọ̀ ní irú ẹ̀mí tí onísáàmù náà ní, nígbà tó kọ ọ́ lórin pé: “Ẹni rere ni ọ́ [Jèhófà], o sì ń ṣe rere. Kọ́ mi ní àwọn ìlànà rẹ.”—Sáàmù 119:68.

A Gbé Ìwà Rere Jèhófà Lárugẹ

6. Lẹ́yìn tí Dáfídì Ọba ṣètò pé kí wọ́n gbé àpótí májẹ̀mú wá sí Jerúsálẹ́mù, orin wo làwọn ọmọ Léfì kọ?

6 Dáfídì Ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì sọ pé ẹni rere ni Ọlọ́run, ó sì wá ìtọ́sọ́nà Rẹ̀. Dáfídì sọ pé: “Ẹni rere àti adúróṣánṣán ni Jèhófà. Ìdí nìyẹn tí ó fi ń fún àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ìtọ́ni ní ọ̀nà náà.” (Sáàmù 25:8) Ara ìtọ́ni tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni Òfin Mẹ́wàá, ìyẹn àwọn àṣẹ pàtàkì tá a kọ sára wàláà òkúta méjì, tá a sì fi sínú àpótí mímọ́ tá à ń pè ní àpótí májẹ̀mú. Lẹ́yìn tí Dáfídì ṣètò pé kí wọ́n gbé Àpótí náà wá sí Jerúsálẹ́mù, olú ìlú Ísírẹ́lì, àwọn ọmọ Léfì kọ orin kan tó ní ọ̀rọ̀ wọ̀nyí nínú: “Ẹ fi ọpẹ́ fún Jèhófà, nítorí tí ó jẹ́ ẹni rere, nítorí tí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ wà fún àkókò tí ó lọ kánrin.” (1 Kíróníkà 16:34, 37-41) Orin táwọn ọmọ Léfì akọrin kọ yìí á mà dùn-ún gbọ́ o!

7. Kí ló ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tá a gbé Àpótí náà wá sí Ibi Mímọ́ Jù Lọ àti lẹ́yìn àdúrà ìyàsímímọ́ tí Sólómọ́nì gbà?

7 Ọ̀rọ̀ ìyìn wọ̀nyẹn tún dún ketekete nígbà ìyàsímímọ́ tẹ́ńpìlì Jèhófà, tí Sólómọ́nì ọmọ Dáfídì kọ́. Lẹ́yìn tí wọ́n gbé àpótí májẹ̀mú sí Ibi Mímọ́ Jù Lọ nínú tẹ́ńpìlì tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ náà, àwọn ọmọ Léfì bẹ̀rẹ̀ sí yin Jèhófà lógo, “nítorí tí ó jẹ́ ẹni rere, nítorí tí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ wà fún àkókò tí ó lọ kánrin.” Lákòókò yẹn, ṣe ni tẹ́ńpìlì náà ṣàdédé kún fún ìkuukùu, tó fi hàn pé Jèhófà wà níbẹ̀ tògotògo. (2 Kíróníkà 5:13, 14) Lẹ́yìn àdúrà ìyàsímímọ́ tí Sólómọ́nì gbà, “iná sọ̀ kalẹ̀ wá láti ọ̀run, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí jó ọrẹ ẹbọ sísun àti àwọn ẹbọ náà run.” Nígbà tí wọ́n rí èyí, “gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì . . . lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ . . . tẹrí ba mọ́lẹ̀ ní ìdojúbolẹ̀ lórí ibi títẹ́, wọ́n sì wólẹ̀, wọ́n sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà, ‘nítorí tí ó jẹ́ ẹni rere, nítorí tí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ wà fún àkókò tí ó lọ kánrin.’” (2 Kíróníkà 7:1-3) Lẹ́yìn àjọyọ̀ ọlọ́jọ́ mẹ́rìnlá, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì padà sílé, “wọ́n kún fún ìdùnnú àti ìjẹ̀gbádùn nínú ọkàn-àyà lórí oore tí Jèhófà ṣe fún Dáfídì àti fún Sólómọ́nì àti fún Ísírẹ́lì àwọn ènìyàn rẹ̀.”—2 Kíróníkà 7:10.

8, 9. (a) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yin Jèhófà nítorí pé ó jẹ́ ẹni rere, ìgbésẹ̀ wo ni wọ́n gbé nígbà tó yá? (b) Kí ni Jeremáyà sọ tẹ́lẹ̀ nípa Jerúsálẹ́mù, báwo sì ni àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣe nímùúṣẹ?

8 Ó bani nínú jẹ́ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣíwọ́ gbígbé níbàámu pẹ̀lú orin ìyìn tí wọ́n kọ sí Ọlọ́run. Bí àkókò ti ń lọ, àwọn èèyàn Júdà bẹ̀rẹ̀ sí ‘fi kìkì ètè wọn yin Jèhófà.’ (Aísáyà 29:13) Dípò tí wọn ì bá fi mú ara wọn bá ìlànà ìwà rere Ọlọ́run mu, ńṣe ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí hùwà búburú. Kí ni díẹ̀ lára ìwà ibi wọn? Àní, wọ́n lọ́wọ́ nínú ìbọ̀rìṣà, ìṣekúṣe, níni àwọn òtòṣì lára, àtàwọn ìwàkíwà míì tó burú jáì! Ìdí nìyẹn tá a fi pa Jerúsálẹ́mù run, tá a sì kó àwọn olùgbé Júdà lọ sígbèkùn ní Bábílónì lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa.

9 Ìyà tí Ọlọ́run fi jẹ àwọn èèyàn rẹ̀ nìyẹn. Ṣùgbọ́n ó gbẹnu wòlíì Jeremáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé ní Jerúsálẹ́mù, àkókò ń bọ̀ tí a óò máa gbọ́ ohùn àwọn tí ń sọ pé: “Ẹ gbé Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun lárugẹ, nítorí tí Jèhófà jẹ́ ẹni rere; nítorí tí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ wà fún àkókò tí ó lọ kánrin!” (Jeremáyà 33:10, 11) Bọ́ràn sì ṣe rí gẹ́lẹ́ nìyẹn. Lẹ́yìn tí ilẹ̀ náà dahoro fún àádọ́rin ọdún, nígbà tó di ọdún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa, àṣẹ́kù àwọn Júù padà bọ̀ sí Jerúsálẹ́mù. (Jeremáyà 25:11; Dáníẹ́lì 9:1, 2) Wọ́n tún pẹpẹ tó wà níbi tí tẹ́ńpìlì wà tẹ́lẹ̀ lórí Òkè Móráyà kọ́, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí rúbọ níbẹ̀. Ọdún kejì tí wọ́n padà dé ni wọ́n fi ìpìlẹ̀ tẹ́ńpìlì lélẹ̀. Ayọ̀ abara tín-ń-tín! Ẹ́sírà sọ pé: “Nígbà tí àwọn akọ́lé fi ìpìlẹ̀ tẹ́ńpìlì Jèhófà lélẹ̀, nígbà náà ni àwọn àlùfáà nínú aṣọ iṣẹ́ wọn, ti àwọn ti kàkàkí, àti àwọn ọmọ Léfì tí í ṣe àwọn ọmọ Ásáfù, ti àwọn ti aro, dìde dúró láti yin Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ìdarí tí Dáfídì ọba Ísírẹ́lì ṣe. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í dáhùn padà nípa yíyin Jèhófà àti fífi ọpẹ́ fún un, ‘nítorí tí ó jẹ́ ẹni rere, nítorí tí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ sí Ísírẹ́lì wà fún àkókò tí ó lọ kánrin.’”—Ẹ́sírà 3:1-11.

10. Gbólóhùn pàtàkì wo ló bẹ̀rẹ̀, tó sì parí Sáàmù 118?

10 Irú ọ̀rọ̀ ìyìn bẹ́ẹ̀ nípa jíjẹ́ tí Jèhófà jẹ́ ẹni rere tún wà nínú àwọn sáàmù mélòó kan. Lára irú sáàmù bẹ́ẹ̀ ni Sáàmù 118, tí àwọn agboolé ní Ísírẹ́lì máa ń kọ lórin nígbà tí wọ́n bá ń kádìí àjọ̀dún Ìrékọjá nílẹ̀. Àwọn ọ̀rọ̀ tó bẹ̀rẹ̀, tó sì parí sáàmù náà ni: “Ẹ fi ọpẹ́ fún Jèhófà, nítorí tí ó jẹ́ ẹni rere; nítorí tí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ wà fún àkókò tí ó lọ kánrin.” (Sáàmù 118:1, 29) Ó kúkú lè jẹ́ pé èyí ni orin ìyìn ìkẹyìn tí Jésù Kristi àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ olóòótọ́ kọ lóru ọjọ́ tó ṣáájú ọjọ́ ikú rẹ̀ lọ́dún 33 Sànmánì Tiwa.—Mátíù 26:30.

“Jọ̀wọ́, Jẹ́ Kí N Rí Ògo Rẹ”

11, 12. Nígbà tí Mósè kófìrí ògo Ọlọ́run, ìkéde wo ló gbọ́?

11 Ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ṣáájú àkókò Ẹ́sírà la ti kọ́kọ́ fi hàn pé ìwà rere Jèhófà àti inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ jọ ń rìn ni. Kété lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bọ ère ọmọ màlúù oníwúrà náà ní aginjù, tá a sì pa àwọn tó bọ ère yìí, ni Mósè bẹ Jèhófà pé: “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí n rí ògo rẹ.” Níwọ̀n bí Jèhófà ti mọ̀ pé Mósè kò lè rí ojú Òun kí ó sì yè, ó sọ pé: “Èmi fúnra mi yóò mú kí gbogbo oore mi kọjá níwájú rẹ.”—Ẹ́kísódù 33:13-20.

12 Oore Jèhófà kọjá níwájú Mósè lọ́jọ́ tó tẹ̀ lé e lórí Òkè Sínáì. Nígbà yẹn ni Mósè kófìrí ògo Ọlọ́run, tó sì gbọ́ ìkéde yìí, pé: “Jèhófà, Jèhófà, Ọlọ́run aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́, ó ń lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ yanturu ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti òtítọ́, ó ń pa inú-rere-onífẹ̀ẹ́ mọ́ fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún, ó ń dárí ìṣìnà àti ìrélànàkọjá àti ẹ̀ṣẹ̀ jì, ṣùgbọ́n lọ́nàkọnà, kì í dáni sí láìjẹni-níyà, ó ń mú ìyà wá sórí àwọn ọmọ àti sórí àwọn ọmọ-ọmọ, sórí ìran kẹta àti sórí ìran kẹrin nítorí ìṣìnà àwọn baba.” (Ẹ́kísódù 34:6, 7) Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fi hàn pé oore Jèhófà àti inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ jọ ń rìn pẹ̀lú àwọn ànímọ́ rẹ̀ yòókù ni. Gbígbé ànímọ́ wọ̀nyí yẹ̀ wò yóò jẹ́ ká máa ṣe rere. Ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ gbé ànímọ́ tá a mẹ́nu kàn lẹ́ẹ̀mejì nínú ìkéde àgbàyanu nípa oore Ọlọ́run yìí yẹ̀ wò.

‘Ọlọ́run . . . Tó Pọ̀ ní Inú-Rere-Onífẹ̀ẹ́’

13. Nínú ìkéde oore Ọlọ́run, ànímọ́ wo la mẹ́nu kàn lẹ́ẹ̀mejì, èé sì ṣe tó fi yẹ bẹ́ẹ̀?

13 “Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run . . . tó pọ̀ yanturu ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́ . . . , tó ń pa inú-rere-onífẹ̀ẹ́ mọ́ fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún.” Ọ̀rọ̀ Hébérù tá a tú sí “inú-rere-onífẹ̀ẹ́” tún túmọ̀ sí “ìfẹ́ dídúróṣinṣin.” Ànímọ́ yìí nìkan la mẹ́nu kàn lẹ́ẹ̀mejì nínú ohun tí Ọlọ́run kéde fún Mósè. Ẹ ò rí i pé ó yẹ bẹ́ẹ̀, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé ìfẹ́ ni olórí ànímọ́ Jèhófà! (1 Jòhánù 4:8) Gbólóhùn náà tá a fi ń yin Jèhófà, “nítorí tí ó jẹ́ ẹni rere, nítorí tí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ wà fún àkókò tí ó lọ kánrin,” tó jẹ́ gbólóhùn tá a mọ̀ bí ẹní mowó, gbé ànímọ́ yìí yọ lákànṣe.

14. Àwọn wo ní pàtàkì ló ń gbádùn oore àti inú-rere-onífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run?

14 Ọ̀kan lára ẹ̀rí pé Jèhófà jẹ́ ẹni rere ni pé ó “pọ̀ yanturu ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́.” Èyí hàn kedere, pàápàá jù lọ, nínú bó ṣe rọra ń tọ́jú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́, tó ti ya ara wọn sí mímọ́ fún un. (1 Pétérù 5:6, 7) Gẹ́gẹ́ bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti lè jẹ́rìí sí i, ó ‘ń pa inú-rere-onífẹ̀ẹ́ mọ́’ fún àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, tí wọ́n sì ń sìn ín. (Ẹ́kísódù 20:6) Orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àbínibí pàdánù inú-rere-onífẹ̀ẹ́ Jèhófà tàbí ìfẹ́ rẹ̀ dídúróṣinṣin, nítorí pé wọ́n kọ Ọmọ rẹ̀ sílẹ̀. Ṣùgbọ́n oore Ọlọ́run àti ìfẹ́ rẹ̀ dídúróṣinṣin yóò wà títí láé fún àwọn Kristẹni olóòótọ́ látinú gbogbo orílẹ̀-èdè.—Jòhánù 3:36.

Jèhófà—Ọlọ́run Aláàánú àti Olóore Ọ̀fẹ́

15. (a) Kí ni gbólóhùn tó bẹ̀rẹ̀ ìkéde tí Mósè gbọ́ lórí Òkè Sínáì? (b) Kí ni àánú wé mọ́?

15 Gbólóhùn tó bẹ̀rẹ̀ ìkéde tí Mósè gbọ́ lórí Òkè Sínáì ni: “Jèhófà, Jèhófà, Ọlọ́run aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́.” Ọ̀rọ̀ Hébérù tá a tú sí “àánú” lè tọ́ka sí “ìfun,” kò sì fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ sí ọ̀rọ̀ náà “ilé ọlẹ̀.” Fún ìdí yìí, ọ̀ràn àánú wé mọ́ ìyọ́nú àtọkànwá. Ṣùgbọ́n àánú kì í kàn-án ṣe ọ̀ràn ìbánikẹ́dùn lásán. Ó yẹ kó sún wa láti ṣe nǹkan kan láti ran àwọn tó wà nínú ìṣòro lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, àwọn Kristẹni alàgbà máa ń rí i pé ó pọn dandan láti fi àánú hàn sí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn, ‘kí wọ́n máa fi àánú hàn tọ̀yàyàtọ̀yàyà’ nígbà tó bá yẹ láti ṣe bẹ́ẹ̀.—Róòmù 12:8; Jákọ́bù 2:13; Júúdà 22, 23.

16. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé Jèhófà jẹ́ olóore ọ̀fẹ́?

16 Ìwà rere Ọlọ́run tún hàn nínú oore ọ̀fẹ́ rẹ̀. Ẹnì kan tó jẹ́ olóore ọ̀fẹ́ máa ń “gba ti ẹlòmíràn rò gidigidi,” ó sì máa ń ‘ṣojú àánú ní pàtàkì sí àwọn ẹni rírẹlẹ̀.’ Jèhófà jẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ nínú oore ọ̀fẹ́ tó nawọ́ rẹ̀ sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́. Fún àpẹẹrẹ, nínú oore ọ̀fẹ́ Ọlọ́run, ó tipasẹ̀ áńgẹ́lì fún wòlíì Dáníẹ́lì àgbàlagbà lókun, ó sì tipasẹ̀ áńgẹ́lì sọ fún Màríà, ọ̀dọ́bìnrin wúńdíá nì, nípa àǹfààní tó máa ní láti di ìyá Jésù. (Dáníẹ́lì 10:19; Lúùkù 1:26-38) Dájúdájú àwa èèyàn Jèhófà mọrírì bó ṣe ń fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ bá wa sọ̀rọ̀ nínú Bíbélì. A ń yìn ín nítorí oore rẹ̀ yìí. A sì ń fẹ́ láti máa fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ bá àwọn ẹlòmíràn lò. Nígbà táwọn tó tóótun nípa tẹ̀mí bá fẹ́ tọ́ onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn sọ́nà “nínú ẹ̀mí ìwà tútù,” wọ́n máa ń gbìyànjú láti jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́ àti oníyọ̀ọ́nú.—Gálátíà 6:1.

Ọlọ́run Tí Ó Ń Lọ́ra Láti Bínú

17. Èé ṣe tá a fi mọyì lílọ́ra tí Jèhófà “ń lọ́ra láti bínú”?

17 “Ọlọ́run . . . [] ó ń lọ́ra láti bínú.” Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ń pe àfiyèsí sí ohun mìíràn tí oore Jèhófà wé mọ́. Jèhófà máa ń mú sùúrù fún wa nígbà tá a bá ṣe ohun tó kù díẹ̀ káàtó. Ó sì máa ń yọ̀ǹda àkókò fún wa kí á lè borí àwọn àléébù wíwúwo, kí á sì tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. (Hébérù 5:12–6:3; Jákọ́bù 5:14, 15) Sùúrù Ọlọ́run tún ń ṣe àwọn tí kò tíì di ìránṣẹ́ rẹ̀ láǹfààní. Èyí ṣí àǹfààní sílẹ̀ fún wọn láti gbọ́ ìhìn rere Ìjọba náà, kí wọ́n sì ronú pìwà dà. (Róòmù 2:4) Bí Jèhófà tilẹ̀ ní sùúrù, ìwà rere rẹ̀ máa ń jẹ́ kó fi ìbínú rẹ̀ hàn, gẹ́gẹ́ bó ti ṣe nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì jọ́sìn ère ọmọ màlúù oníwúrà ní Òkè Sínáì. Ọlọ́run yóò fi ìbínú rẹ̀ hàn láìpẹ́ lọ́nà tó tún jù bẹ́ẹ̀ lọ nígbà tó bá pa ètò búburú Sátánì run.—Ìsíkíẹ́lì 38:19, 21-23.

18. Nígbà tó bá kan sísọ òtítọ́, kí ni ìyàtọ̀ tó wà láàárín Jèhófà àtàwọn ẹ̀dá ènìyàn olùṣàkóso?

18 “Jèhófà [jẹ́] Ọlọ́run . . . [] pọ̀ yanturu ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti òtítọ́.” Ẹ wo bí Jèhófà ti yàtọ̀ sí àwọn ẹ̀dá ènìyàn tó jẹ́ olùṣàkóso tó, tí wọ́n máa ń ṣe àwọn ìlérí ńláńlá, ṣùgbọ́n tí wọn kì í mú un ṣẹ! Ní ìyàtọ̀ pátápátá sí èyí, àwọn olùjọsìn Jèhófà lè fọkàn tán gbogbo ohun tó sọ nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ onímìísí. Níwọ̀n bí Ọlọ́run ti pọ̀ yanturu ní òtítọ́, a lè gbẹ́kẹ̀ lé àwọn ìlérí rẹ̀ nígbà gbogbo. Nínú oore rẹ̀, Baba wa ọ̀run ń gbọ́ àdúrà wa pé kí ó fún wa ní òtítọ́ tẹ̀mí, ó sì ń fi í fún wa lọ́pọ̀ yanturu.—Sáàmù 43:3; 65:2.

19. Oore pàtàkì wo ni Jèhófà ṣe fún àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó ronú pìwà dà?

19 “Jèhófà [jẹ́] Ọlọ́run . . . [] ń dárí ìṣìnà àti ìrélànàkọjá àti ẹ̀ṣẹ̀ jì.” Nínú oore rẹ̀, Jèhófà ṣe tán láti dárí ji àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó ronú pìwà dà. Dájúdájú, a mọrírì rẹ̀ gan-an pé Baba wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́ ti ṣètò fún ìdáríjì nípasẹ̀ ẹbọ Jésù. (1 Jòhánù 2:1, 2) Ní tòótọ́, inú wa dùn pé gbogbo àwọn tó bá lo ìgbàgbọ́ nínú ìràpadà ló ní àǹfààní láti gbádùn àjọṣe tó gbámúṣé pẹ̀lú Jèhófà, pẹ̀lú ìrètí ìyè àìlópin nínú ayé tuntun tó ṣèlérí. Ẹ ò rí i pé ìdí pàtàkì nìwọ̀nyí láti yin Jèhófà fún oore tó ṣe fáráyé!—2 Pétérù 3:13.

20. Ẹ̀rí wo la ní pé Ọlọ́run kì í fàyè gba ìwà búburú?

20 “Lọ́nàkọnà, [Jèhófà] kì í dáni sí láìjẹni-níyà.” Ní ti gidi, ìdí mìíràn rèé tó fi yẹ ká máa kókìkí Jèhófà nítorí jíjẹ́ tó jẹ́ ẹni rere. Èé ṣe? Nítorí pé apá tó ṣe kókó nínú ọ̀ràn ìwà rere rẹ̀ ni pé kì í gba ìwà ibi láyè lọ́nàkọnà. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, “nígbà ìṣípayá Jésù Olúwa láti ọ̀run tòun ti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ alágbára,” ẹ̀san á ké lórí “àwọn tí kò mọ Ọlọ́run àti àwọn tí kò ṣègbọràn sí ìhìn rere.” Wọn “yóò fara gba ìyà ìdájọ́ ìparun àìnípẹ̀kun.” (2 Tẹsalóníkà 1:6-9) Àwọn olùjọsìn Jèhófà tó bá là á já yóò wá máa gbádùn ìwàláàyè ní kíkún, láìsí pé àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run, tí wọ́n jẹ́ “aláìní ìfẹ́ ohun rere,” ń kó wàhálà bá wọn.—2 Tímótì 3:1-3.

Fara Wé Ìwà Rere Jèhófà

21. Èé ṣe tó fi yẹ ká máa ṣe rere?

21 Láìsí àní-àní ìdí pọ̀ tó fi yẹ ká máa yin Jèhófà, ká sì máa dúpẹ́ fún oore rẹ̀. Ǹjẹ́ kò yẹ kí àwa tá a jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ máa sa gbogbo ipá wa láti ní ànímọ́ yìí? Bẹ́ẹ̀ ni, nítorí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, pé: “Ẹ di aláfarawé Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ tí í ṣe olùfẹ́ ọ̀wọ́n.” (Éfésù 5:1) Ìgbà gbogbo ni Baba wa ọ̀run ń ṣe rere, bẹ́ẹ̀ ló sì yẹ kí àwa náà máa ṣe nígbà gbogbo.

22. Kí ni a óò jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí?

22 Bó bá jẹ́ pé tọkàntọkàn la ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà, ó dájú pé yóò jẹ́ ìfẹ́ wa àtọkànwá láti fara wé e nínú rere ṣíṣe. Nítorí pé a jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ádámù ẹlẹ́ṣẹ̀, kì í rọrùn fún wa láti máa ṣe rere. Àmọ́, nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí, a óò rí ìdí tó fi ṣeé ṣe fún wa láti máa ṣe rere. A óò tún jíròrò onírúurú ọ̀nà tá a fi lè fara wé Jèhófà tó jẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ nínú rere ṣíṣe.

Báwo Ni Wàá Ṣe Dáhùn?

• Kí ni ìwà rere?

• Àwọn gbólóhùn wo nínú Ìwé Mímọ́ ló fi oore Ọlọ́run hàn kedere?

• Kí ni díẹ̀ lára rere tí Jèhófà ṣe?

• Èé ṣe tó fi yẹ ká fara wé Jèhófà nínú rere ṣíṣe?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Jèhófà fìyà jẹ àwọn èèyàn rẹ̀ ìgbàanì nítorí pé wọ́n ṣíwọ́ gbígbé níbàámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ìyìn tó tẹnu wọn jáde

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Àṣẹ́kù tó jẹ́ olóòótọ́ padà wá sí Jerúsálẹ́mù

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Mósè gbọ́ ìkéde àgbàyanu nípa oore Ọlọ́run

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Oore Jèhófà hàn nínú bó ṣe ń bá wa sọ̀rọ̀ nínú Bíbélì