Máa Ṣe Rere Nìṣó
Máa Ṣe Rere Nìṣó
“Èso ìmọ́lẹ̀ ní gbogbo onírúurú ohun rere àti òdodo àti òtítọ́ nínú.”—ÉFÉSÙ 5:9.
1. Báwo ni àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn lónìí ṣe ń fi hàn pé àwọn fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Sáàmù 31:19?
OHUN rere tó dára jù lọ téèyàn èyíkéyìí lè ṣe ni kí ó máa yin Jèhófà lógo. Lónìí, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ló ń ṣe bẹ́ẹ̀, bí wọ́n ṣe ń yin Ọlọ́run fún oore rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí olóòótọ́ fún Jèhófà, tọkàntọkàn la fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú onísáàmù náà tó kọ ọ́ lórin pé: “Oore rẹ mà pọ̀ yanturu o, èyí tí o ti tò pa mọ́ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ!”—Sáàmù 31:19.
2, 3. Kí ló lè ṣẹlẹ̀ bí ìwà rere ò bá máa bá iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn tí à ń ṣe rìn?
2 Ìbẹ̀rù àtọkànwá fún Jèhófà ń sún wa láti yìn ín fún oore rẹ̀. Ìbẹ̀rù yìí tún ń sún wa láti ‘gbé Jèhófà lárugẹ, láti máa fi ìbùkún fún un, àti láti máa sọ̀rọ̀ nípa ògo ipò ọba rẹ̀.’ (Sáàmù 145:10-13) Ìdí nìyẹn tí a fi ń fi tìtaratìtara ṣiṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà, tá a sì ń sọni di ọmọ ẹ̀yìn. (Mátíù 24:14; 28:19, 20) Láìṣẹ̀ṣẹ̀ tún máa sọ ọ́, ìwà rere gbọ́dọ̀ máa bá iṣẹ́ ìwàásù tí à ń ṣe rìn. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, a lè mú ẹ̀gàn bá orúkọ mímọ́ Jèhófà.
3 Ọ̀pọ̀ èèyàn tó sọ pé àwọn ń sin Ọlọ́run ni ìwà wọn kò bá ìlànà tó wà nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ onímìísí mu. Àpọ́sítélì kọ̀wé nípa àwọn kan tí ìwà wọn ò bá iṣẹ́ rere tí wọ́n sọ pé àwọn ń ṣe mu, pé: “Ǹjẹ́ ìwọ, ẹni tí ń kọ́ ẹlòmíràn, kò kọ́ ara rẹ? Ìwọ, ẹni tí ń wàásù pé ‘Má jalè,’ ìwọ ha ń jalè bí? Ìwọ, ẹni tí ń sọ pé ‘Má ṣe panṣágà,’ ìwọ ha ń ṣe panṣágà bí? . . . ‘Orúkọ Ọlọ́run ni a ń sọ̀rọ̀ òdì sí ní tìtorí yín láàárín àwọn orílẹ̀-èdè’; gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé rẹ̀.”—Róòmù 2:21, 22, 24.
4. Ipa wo ni ìwà rere wa máa ń ní?
4 Dípò tí a ó fi mú ẹ̀gàn bá orúkọ Jèhófà, à ń làkàkà láti fi ìwà rere wa yin orúkọ rẹ̀ lógo. Èyí máa ń ní ipa rere lórí àwọn tó wà lóde ìjọ Kristẹni. Ọ̀kan lára ipa rere tó ń ní ni pé ó ń mú kí kẹ́kẹ́ pa mọ́ àwọn alátakò wa lẹ́nu. (1 Pétérù 2:15) Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ìwà rere wa ń fa àwọn èèyàn wá sínú ètò Jèhófà, ó ń ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún wọn láti yìn ín lógo, kí wọ́n sì ní ìyè àìnípẹ̀kun.—Ìṣe 13:48.
5. Àwọn ìbéèrè wo la fẹ́ gbé yẹ̀ wò báyìí?
5 Níwọ̀n bí a ti jẹ́ aláìpé, báwo la ṣe lè yẹra fún ìwà tó lè tàbùkù Jèhófà, kí ó sì mú kí àwọn tó ń wá òtítọ́ kọsẹ̀? Àní, báwo la ṣe lè kẹ́sẹ járí nínú ṣíṣe rere?
Èso Ìmọ́lẹ̀
6. Kí ni díẹ̀ lára “àwọn iṣẹ́ aláìléso tí ó jẹ́ ti òkùnkùn,” ṣùgbọ́n èso wo ló yẹ kí àwọn Kristẹni máa so?
6 Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni tó ti ṣe ìyàsímímọ́, a ń gbádùn ohun kan tó ń ràn wá lọ́wọ́ láti yàgò fún “àwọn iṣẹ́ aláìléso tí ó jẹ́ ti òkùnkùn.” Irú àwọn iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ tí ń tàbùkù Ọlọ́run ni irọ́ pípa, olè jíjà, ọ̀rọ̀ èébú, ọ̀rọ̀kọ́rọ̀ nípa ìbálòpọ̀ takọtabo, ìwà tí ń tini lójú, ìṣẹ̀fẹ̀ rírùn àti ìmutípara. (Éfésù 4:25, 28, 31; 5:3, 4, 11, 12, 18) Dípò lílọ́wọ́ sí irú iṣẹ́kíṣẹ́ bẹ́ẹ̀, a ń “bá a lọ ní rírìn gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìmọ́lẹ̀.” Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé “èso ìmọ́lẹ̀ ní gbogbo onírúurú ohun rere àti òdodo àti òtítọ́ nínú.” (Éfésù 5:8, 9) Ìyẹn ló fi jẹ́ pé rírìn nínú ìmọ́lẹ̀ yóò jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti máa hùwà rere. Àmọ́ irú ìmọ́lẹ̀ wo nìyí?
7. Kí ni a gbọ́dọ̀ ṣe bí a óò bá máa so èso rere nìṣó?
7 Láìka jíjẹ́ tá a jẹ́ aláìpé sí, a ṣì lè máa hu ìwà rere bá a bá ń rìn nínú ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí. Onísáàmù náà kọ ọ́ lórin pé: “Ọ̀rọ̀ rẹ jẹ́ fìtílà fún ẹsẹ̀ mi, àti ìmọ́lẹ̀ sí òpópónà mi.” (Sáàmù 119:105) Bí a bá fẹ́ máa bá a nìṣó ní síso “èso ìmọ́lẹ̀” nípasẹ̀ “gbogbo onírúurú ohun rere,” ìgbà gbogbo ló yẹ ká máa lo àǹfààní ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyí tá a máa ń gbé yẹ̀ wò kínníkínní nínú àwọn ìtẹ̀jáde Kristẹni, tá a sì máa ń jíròrò déédéé láwọn ibi tá a ti ń pàdé fún ìjọsìn. (Lúùkù 12:42; Róòmù 15:4; Hébérù 10:24, 25) Ó tún yẹ ká pe àfiyèsí pàtàkì sí àpẹẹrẹ àti ẹ̀kọ́ Jésù Kristi, ẹni tí í ṣe “ìmọ́lẹ̀ ayé” àti “àgbéyọ ògo” Jèhófà.—Jòhánù 8:12; Hébérù 1:1-3.
Èso Ti Ẹ̀mí
8. Èé ṣe tá a fi lè máa hùwà rere?
8 Láìsí àní-àní, ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí ń ràn wá lọ́wọ́ láti máa ṣe rere. Láfikún sí i, à ń fi ànímọ́ yìí hàn nítorí pé ẹ̀mí mímọ́, ìyẹn ipá ìṣiṣẹ́ Ọlọ́run, ló ń darí wa. Ìwà rere jẹ́ ara “èso ti ẹ̀mí.” (Gálátíà 5:22, 23) Bí a bá ń tẹ̀ lé ìdarí ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà, wọ̀ǹtìwọnti ni èso ìwà rere tí a óò máa so.
9. Báwo la ṣe lè máa hùwà níbàámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Jésù tó wà ní Lúùkù 11:9-13?
9 Ìfẹ́ àtọkànwá tá a ní láti múnú Jèhófà dùn nípa híhu ìwà rere tí í ṣe ara èso ti ẹ̀mí, yẹ kó sún wa láti máa hùwà níbàámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Jésù, pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní bíbéèrè, a ó sì fi í fún yín; ẹ máa bá a nìṣó ní wíwá kiri, ẹ ó sì rí; ẹ máa bá a nìṣó ní kíkànkùn, a ó sì ṣí i fún yín. Nítorí pé olúkúlùkù ẹni tí ń béèrè ń rí gbà, àti olúkúlùkù ẹni tí ń wá kiri ń rí, olúkúlùkù ẹni tí ó sì ń kànkùn ni a óò ṣí i fún. Ní tòótọ́, baba wo ní ń bẹ láàárín yín tí ó jẹ́ pé, bí ọmọ rẹ̀ bá béèrè ẹja, bóyá tí yóò fi ejò lé e lọ́wọ́ dípò ẹja? Tàbí bí ó bá tún béèrè ẹyin, tí yóò fi àkekèé lé e lọ́wọ́? Nígbà náà, bí ẹ̀yin, [tí ẹ jẹ́ aláìpé, tí ẹ sì tipa báyìí jẹ́] ẹni burúkú [dé àyè kan], bá mọ bí ẹ ṣe ń fi ẹ̀bùn rere fún àwọn ọmọ yín, mélòómélòó ni Baba tí ń bẹ ní ọ̀run yóò fi ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn tí ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀!” (Lúùkù 11:9-13) Ẹ jẹ́ ká tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Jésù nípa gbígbàdúrà fún ẹ̀mí Jèhófà ká lè máa so èso ìwà rere nìṣó.
“Máa Ṣe Rere”
10. Kí ni àwọn apá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ìwà rere Jèhófà tí Ẹ́kísódù 34:6, 7 mẹ́nu kàn?
10 Pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run, a lè “máa ṣe rere.” (Róòmù 13:3) Nípasẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé, a lè mọ púpọ̀ sí i nípa bá a ṣe lè máa fara wé ìwà rere Jèhófà. Àpilẹ̀kọ tó ṣáájú jíròrò onírúurú apá oore Ọlọ́run, nínú ohun tó kéde fún Mósè ní Ẹ́kísódù 34:6, 7, pé: “Jèhófà, Jèhófà, Ọlọ́run aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́, ó ń lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ yanturu ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti òtítọ́, ó ń pa inú-rere-onífẹ̀ẹ́ mọ́ fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún, ó ń dárí ìṣìnà àti ìrélànàkọjá àti ẹ̀ṣẹ̀ jì, ṣùgbọ́n lọ́nàkọnà, kì í dáni sí láìjẹni-níyà.” Fífarabalẹ̀ ṣàyẹ̀wò àwọn apá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wọ̀nyí nínú ìwà rere Jèhófà yóò ràn wá lọ́wọ́ láti “máa ṣe rere.”
11. Ipa wo ló yẹ kí jíjẹ́ tí Jèhófà jẹ́ aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́ ní lórí wa?
11 Ìkéde tí Ọlọ́run ṣe yìí jẹ́ ká rí ìjẹ́pàtàkì fífarawé Jèhófà nípa jíjẹ́ aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́. Jésù sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn aláàánú, níwọ̀n bí a ó ti fi àánú hàn sí wọn.” (Mátíù 5:7; Lúùkù 6:36) Mímọ̀ tá a mọ̀ pé Jèhófà jẹ́ olóore ọ̀fẹ́ yóò sún wa láti jẹ́ olóore ọ̀fẹ́ àti adùn-únbárìn nígbà tí nǹkan bá da àwa àtàwọn ẹlòmíì pọ̀, títí kan àwọn tá à ń wàásù fún. Èyí bá ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù mu, pé: “Ẹ jẹ́ kí àsọjáde yín máa fìgbà gbogbo jẹ́ pẹ̀lú oore ọ̀fẹ́, tí a fi iyọ̀ dùn, kí ẹ lè mọ bí ó ti yẹ kí ẹ fi ìdáhùn fún ẹnì kọ̀ọ̀kan.”—Kólósè 4:6.
12. (a) Níwọ̀n bí Ọlọ́run ti ń lọ́ra láti bínú, báwo ló ṣe yẹ ká máa ṣe sí àwọn ẹlòmíràn? (b) Inú-rere-onífẹ̀ẹ́ Jèhófà ń sún wa láti ṣe kí ni?
12 Níwọ̀n bí Ọlọ́run ti ń lọ́ra láti bínú, fífẹ́ tá a fẹ́ láti “máa ṣe rere” yóò sún wa láti máa gbójú fo àṣìṣe pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa dá, ká sì máa pe àfiyèsí sí àwọn ànímọ́ rere wọn. (Mátíù 7:5; Jákọ́bù 1:19) Inú-rere-onífẹ̀ẹ́ Jèhófà ń mú ká ní ìfẹ́ dídúróṣinṣin, kódà nínú ìṣòro tó gàgaàrá. Ó dájú pé ohun tó fani lọ́kàn mọ́ra gan-an lèyí.—Òwe 19:22.
13. Báwo ló ṣe yẹ kí ó hàn nínú ìwà wa pé Jèhófà ‘pọ̀ yanturu ní òtítọ́’?
13 Níwọ̀n bí Baba wa ọ̀run ti ‘pọ̀ yanturu ní òtítọ́,’ a ń sapá láti ‘dámọ̀ràn ara wa gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ rẹ̀ nípa ọ̀rọ̀ òtítọ́.’ (2 Kọ́ríńtì 6:3-7) Lára ohun méje tó jẹ́ ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jèhófà ni “ahọ́n èké” àti “ẹlẹ́rìí èké tí ń gbé irọ́ yọ.” (Òwe 6:16-19) Fún ìdí yìí, fífẹ́ tá a fẹ́ láti máa múnú Ọlọ́run dùn ti mú ká ‘fi èké ṣíṣe sílẹ̀, ká sì máa sọ òtítọ́.’ (Éfésù 4:25) Ǹjẹ́ kí a má ṣe kùnà láé láti máa hùwà rere nínú ọ̀ràn pàtàkì yìí.
14. Èé ṣe tó fi yẹ ká máa dárí jini?
14 Ó tún yẹ kí ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run kéde létí Mósè sún wa láti máa dárí jini, nítorí pé Jèhófà ṣe tán láti dárí jini. (Mátíù 6:14, 15) Ṣùgbọ́n o, Jèhófà máa ń fìyà jẹ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó bá kọ̀ láti ronú pìwà dà. Fún ìdí yìí, a gbọ́dọ̀ rọ̀ mọ́ ìlànà ìwà rere rẹ̀ nínú rírí i dájú pé ìjọ wà ní mímọ́ nípa tẹ̀mí.—Léfítíkù 5:1; 1 Kọ́ríńtì 5:11, 12; 1 Tímótì 5:22.
“Ẹ Máa Ṣọ́ra Lójú Méjèèjì”
15, 16. Báwo ni ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù ní Éfésù 5:15-19 ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti máa ṣe rere nìṣó?
15 Ó di dandan láti máa kún fún ẹ̀mí Ọlọ́run, ká sì máa ṣọ́ ìrìn wa, bí a óò bá máa hùwà rere nìṣó láìfi ìwà ibi tó yí wa ká pè. Fún ìdí yìí, Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni ní Éfésù níyànjú pé: “Ẹ máa ṣọ́ra lójú méjèèjì pé bí ẹ ṣe ń rìn kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí aláìlọ́gbọ́n ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ọlọ́gbọ́n, ní ríra àkókò tí ó rọgbọ padà fún ara yín, nítorí pé àwọn ọjọ́ burú. Ní tìtorí èyí, ẹ ṣíwọ́ dídi aláìlọ́gbọ́n-nínú, ṣùgbọ́n ẹ máa bá a lọ ní ríróye ohun tí ìfẹ́ Jèhófà jẹ́. Pẹ̀lúpẹ̀lù, ẹ má ṣe máa mu wáìnì ní àmupara, nínú èyí tí ìwà wọ̀bìà wà, ṣùgbọ́n ẹ máa kún fún ẹ̀mí, ẹ máa fi àwọn sáàmù àti ìyìn sí Ọlọ́run àti àwọn orin ẹ̀mí bá ara yín sọ̀rọ̀, kí ẹ máa kọrin, kí ẹ sì máa fi ohùn orin gbè é nínú ọkàn-àyà yín sí Jèhófà.” (Éfésù 5:15-19) Dájúdájú, ìmọ̀ràn yìí wúlò fún wa gan-an ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn líle koko yìí.—2 Tímótì 3:1.
16 Bí a óò bá máa ṣe rere nìṣó, a gbọ́dọ̀ máa ṣọ́ ìrìn wa lójú méjèèjì, ká máa rí i pé a ń rìn gẹ́gẹ́ bí àwọn tó ń lo ọgbọ́n tó wá láti òkè. (Jákọ́bù 3:17) A gbọ́dọ̀ yẹra fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo, kí a sì kún fún ẹ̀mí mímọ́, kí a jẹ́ kí ó máa darí wa. (Gálátíà 5:19-25) Títẹ̀lé àwọn ìtọ́ni tẹ̀mí tá à ń rí gbà ní àwọn ìpàdé àti àpéjọpọ̀ Kristẹni yóò jẹ́ ká máa bá a nìṣó ní ṣíṣe rere. Ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará Éfésù tún lè rán wa létí pé nínú ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ìpàdé ìjọsìn wa, a máa ń jàǹfààní nínú fífi tọkàntọkàn kọ “àwọn orin ẹ̀mí”—ọ̀pọ̀ nínú orin wọ̀nyí ló dá lórí àwọn ànímọ́ tẹ̀mí, bí ìwà rere.
17. Bí ipò tí àwọn Kristẹni tí àìsàn ọlọ́jọ́ pípẹ́ ń ṣe wà kì í báá jẹ́ kí wọ́n wá sípàdé déédéé, ìdánilójú wo ni wọ́n lè ní?
17 Àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa tí kò lè wá sáwọn ìpàdé Kristẹni déédéé nítorí àìsàn ọlọ́jọ́ pípẹ́ ńkọ́? Ìrẹ̀wẹ̀sì lè bá wọn nítorí pé kì í ṣeé ṣe fún wọn nígbà gbogbo láti máa sin Jèhófà ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú àwọn arákùnrin àti arábìnrin wọn nípa tẹ̀mí. Àmọ́ kí ó dá wọn lójú pé Jèhófà rí ipò tí wọ́n wà. Á mẹ́sẹ̀ wọn dúró nínú òtítọ́. Á fún wọn ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. Á sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti máa ṣe rere nìṣó.—Aísáyà 57:15.
18. Kí ni yóò ràn wá lọ́wọ́ láti máa ṣe rere?
18 Lílépa rere ṣíṣe ń béèrè pé ká máa ṣọ́ àwọn tí à ń bá rìn, ká yàgò fún àwọn “aláìní ìfẹ́ ohun rere.” (2 Tímótì 3:2-5; 1 Kọ́ríńtì 15:33) Títẹ̀lé irú ìmọ̀ràn bẹ́ẹ̀ kò ní jẹ́ kí a “kó ẹ̀dùn-ọkàn bá ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run,” nípa títàpá sí ìdarí rẹ̀. (Éfésù 4:30) Jù bẹ́ẹ̀ lọ, yóò túbọ̀ rọrùn láti máa ṣe rere bí a ti ń kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn tó fi ẹ̀rí hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ ohun rere àti pé ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà ń darí àwọn.—Ámósì 5:15; Róòmù 8:14; Gálátíà 5:18.
Ìwà Rere Ń So Èso Rere
19-21. Sọ àwọn ìrírí tó fi hàn pé ìwà rere máa ń so èso rere.
19 Rírìn nínú ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí, títẹ̀lé ìdarí ẹ̀mí Ọlọ́run àti ṣíṣọ́ ìrìn ẹsẹ̀ wa yóò jẹ́ ká yàgò fún ohun búburú, ká sì “máa ṣe rere.” Èyí, ẹ̀wẹ̀, lè so èso rere. Gbé ìrírí Zongezile, tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Gúúsù Áfíríkà yẹ̀ wò. Lọ́jọ́ kan tó ń lọ síléèwé, ó yà lọ yẹ iye owó tó wà nínú àkáǹtì táṣẹ́rẹ́ tó ní ní báǹkì wò. Iye tí ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà fi àṣìṣe ṣírò pé ó wà nínú àkáǹtì rẹ̀ lé ní R42,000 (6,000 dọ́là owó Amẹ́ríkà). Mègáàdì kan tó ń ṣiṣẹ́ ní báǹkì náà sọ pé kí ó gba gbogbo owó yẹn, kí ó lọ fi pa mọ́ sí báǹkì míì. Kìkì tọkọtaya Ẹlẹ́rìí tí Zongezile ń gbé lọ́dọ̀ wọn ló yìn ín pé kò gba kọ́bọ̀ nínú owó náà.
20 Ní ọjọ́ kejì, Zongezile lọ fi àṣìṣe yìí han àwọn òṣìṣẹ́ báǹkì náà. Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé nọ́ńbà àkáǹtì rẹ̀ jọ ti oníṣòwò kan tó jẹ́ olówó. Ọkùnrin olówó yìí ló fi àṣìṣe sanwó sínú àkáǹtì Zongezile. Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ fún oníṣòwò yìí pé Zongezile kò tíì ná kọ́bọ̀ nínú owó yìí. Ìdí nìyẹn tó fi bi í pé: “Ẹ̀sìn wo lò ń ṣe?” Zongezile sọ fún un pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà lòun. Àwọn òṣìṣẹ́ báǹkì náà yìn ín gidigidi. Wọ́n ní: “Ì bá mà dára o, ká ní gbogbo èèyàn ló jẹ́ aláìlábòsí bíi ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.” Lóòótọ́, ìwà àìlábòsí àti ìwà rere lè jẹ́ kí àwọn ẹlòmíì yin Jèhófà lógo.—Hébérù 13:18.
21 Kò dìgbà tí ìwà rere bá ta yọ báyẹn kó tó so èso rere. Àpẹẹrẹ kan rèé: Ẹlẹ́rìí kan tó jẹ́ ọ̀dọ́, tó ń sìn gẹ́gẹ́ bí ajíhìnrere alákòókò kíkún ní ọ̀kan lára àwọn erékùṣù Samoa lọ sí ọsibítù kan ládùúgbò ibẹ̀. Àwọn èèyàn ń dúró láti rí dókítà, Ẹlẹ́rìí náà sì ṣàkíyèsí pé ara ìyá àgbàlagbà kan tó wà lẹ́yìn òun kò yá rárá. Nígbà tó kàn án, ó ní kí ìyá yìí kọ́kọ́ lọ, kí ó lè tètè rí ìtọ́jú gbà. Nígbà tó ṣe lẹ́yìn èyí, Ẹlẹ́rìí náà pàdé ìyá àgbàlagbà yìí lọ́jà. Ìyá yìí rántí rẹ̀ àti oore tó ṣe òun ni ọsibítù. Ó wá sọ pé: “Mo wá mọ̀ báyìí pé lóòótọ́ làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fẹ́ràn aládùúgbò wọn.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í fẹ́ gbọ́ ìhìn rere Ìjọba náà tẹ́lẹ̀, oore tí Ẹlẹ́rìí yìí ṣe é so èso rere. Ó gbà pé kí wọ́n wá máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ilé òun, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í gba ìmọ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
22. Kí ni ọ̀nà pàtàkì tá a lè gbà “máa ṣe rere”?
22 Ìwọ náà ò ní ṣàìní àwọn ìrírí tó fi hàn pé ìwà rere máa ń so èso rere. Ọ̀nà kan pàtàkì tá a lè gbà “máa ṣe rere” ni pípolongo ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run déédéé. (Mátíù 24:14) Ǹjẹ́ kí a máa fi tìtaratìtara ṣe iṣẹ́ pàtàkì yìí. Ká máa rántí pé èyí jẹ́ ọ̀nà kan tá a lè gbà ṣe rere, pàápàá sí àwọn tó bá fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ wa. Lékè gbogbo rẹ̀, iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa àti ìwà rere wa ń fi ògo fún Jèhófà, orísun ohun rere gbogbo.—Mátíù 19:16, 17.
“Máa Ṣe Ohun Rere” Nìṣó
23. Èé ṣe tí iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni fi jẹ́ iṣẹ́ rere?
23 Láìsí tàbí-ṣùgbọ́n, iṣẹ́ rere ni iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Ó lè yọrí sí ìgbàlà fún àwa àti fún àwọn tó bá fetí sí ìhìn Bíbélì, tí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ fi ẹsẹ̀ ara wọn lé ọ̀nà tó ń sinni lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun. (Mátíù 7:13, 14; 1 Tímótì 4:16) Nítorí náà, nígbà tá a bá fẹ́ ṣe àwọn ìpinnu, ó yẹ kí ìfẹ́ láti ṣe ohun rere sún wa láti bi ara wa léèrè pé: ‘Báwo ni ìpinnu yìí yóò ṣe kan iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà? Ṣé ọ̀nà tí mo fẹ́ tọ̀ yìí bọ́gbọ́n mu? Ṣé á jẹ́ kí n lè ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́ láti gbọ́ “ìhìn rere àìnípẹ̀kun,” kí wọ́n sì wá ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run?’ (Ìṣípayá 14:6) Ayọ̀ ńláǹlà ni ìpinnu tó bá fi ire Ìjọba Ọlọ́run sí ipò àkọ́kọ́ máa ń yọrí sí.—Mátíù 6:33; Ìṣe 20:35.
24, 25. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà tá a lè gbà ṣe rere nínú ìjọ, kí ló sì lè dá wa lójú bí a bá ń ṣe rere nìṣó?
24 Ẹ má ṣe jẹ́ ká fojú kéré àǹfààní tó lè jẹ yọ látinú ìwà rere. A lè máa fi ànímọ́ yìí hàn nípa ṣíṣe ìtìlẹyìn fún ìjọ Kristẹni, ká sì máa sa gbogbo ipá wa láti fi ire ìjọ ṣáájú ohun gbogbo. Dájúdájú ohun rere là ń ṣe tá a bá ń lọ sáwọn ìpàdé Kristẹni déédéé, tá a sì ń kópa nínú wọn. Wíwà tá a wà níbẹ̀ jẹ́ ìṣírí fáwọn olùjọsìn ẹlẹgbẹ́ wa. Àwọn ìdáhùn tá a ti múra sílẹ̀ dáadáa sì ń gbé wọn ró nípa tẹ̀mí. A tún ń ṣe rere nígbà tá a bá lo àwọn ohun ìní wa fún iṣẹ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba, tá a sì ń kọ́wọ́ ti iṣẹ́ títún un ṣe. (2 Àwọn Ọba 22:3-7; 2 Kọ́ríńtì 9:6, 7) Àní sẹ́, “níwọ̀n ìgbà tí a bá ní àkókò tí ó wọ̀ fún un, ẹ jẹ́ kí a máa ṣe ohun rere sí gbogbo ènìyàn, ṣùgbọ́n ní pàtàkì sí àwọn tí ó bá wa tan nínú ìgbàgbọ́.”—Gálátíà 6:10.
25 Kò ṣeé ṣe láti mọ gbogbo àwọn àkókò pàtó tí àǹfààní láti ṣe rere yóò ṣí sílẹ̀. Nítorí náà, bá a ṣe ń bá onírúurú ipò tuntun pàdé, ẹ jẹ́ ká máa wá ìtọ́sọ́nà látinú Ìwé Mímọ́. Ká máa gbàdúrà pé kí Jèhófà fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. Ká sì máa sa gbogbo ipá wa láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀ tó dára, tó sì pé. (Róòmù 2:9, 10; 12:2) A ní ìdánilójú pé Jèhófà yóò bù kún wa lọ́pọ̀ yanturu bí a bá ń ṣe rere nìṣó.
Báwo Ni Wàá Ṣe Dáhùn?
• Kí ni ohun rere tó dára jù lọ tá a lè ṣe?
• Kí nìdí tá a fi pe ìwà rere ní “èso ìmọ́lẹ̀”?
• Kí nìdí tá a fi pe ìwà rere ní “èso ti ẹ̀mí”?
• Irú àwọn èso wo ni ìwà rere wa máa ń so?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ń ràn wá lọ́wọ́ láti máa ṣe rere
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Ṣíṣe rere ń so èso rere