‘Wíwàásù Ọ̀rọ̀ Náà’ Ń Mú Ìtura Wá
“Ẹ Wá Sọ́dọ̀ Mi, . . . Èmi Yóò Sì Tù Yín Lára”
‘Wíwàásù Ọ̀rọ̀ Náà’ Ń Mú Ìtura Wá
ẸNI pípé ni, iṣẹ́ pàtàkì kan ló sì wá jẹ́. Ó mọ èèyàn kọ́ débi pé “háà ń ṣe ogunlọ́gọ̀ sí ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀.” (Mátíù 7:28) Ó tún ń wàásù láìsinmi. Gbogbo àkókò rẹ̀, okun rẹ̀ àti agbára rẹ̀ ló fi wàásù nípa Ìjọba Ọlọ́run. Àní sẹ́, Jésù Kristi rin igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ ìbílẹ̀ rẹ̀ já, ó ń wàásù, ó sì ń kọ́ni lọ́nà tí kò láfiwé.—Mátíù 9:35.
Iṣẹ́ kánjúkánjú tá a rán Jésù ni láti “wàásù ìhìn rere ìjọba náà” fún àwọn èèyàn tó wà nígbà ayé rẹ̀, kí ó sì kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ bí wọ́n á ṣe máa ṣe iṣẹ́ kan náà kárí ayé. (Mátíù 4:23; 24:14; 28:19, 20) Ǹjẹ́ iṣẹ́ bàǹtà-banta tí wíwàásù jẹ́ àti bó ṣe jẹ́ kánjúkánjú tó àti bí iṣẹ́ náà ṣe gbòòrò tó, kò ní wọ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ aláìpé, tí agbára wọn mọ níwọ̀n lọ́rùn?
Rárá o! Lẹ́yìn tí Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa gbàdúrà sí Jèhófà Ọlọ́run, tí í ṣe “Ọ̀gá ìkórè,” fún òṣìṣẹ́ púpọ̀ sí i, ó rán wọn jáde kí wọ́n lọ kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́. (Mátíù 9:38; 10:1) Ó wá mú un dá wọn lójú pé ẹrù iṣẹ́ jíjẹ́ ọmọlẹ́yìn òun—títí kan ṣíṣe iṣẹ́ ìwàásù náà—yóò jẹ́ orísun ojúlówó ìtura àti ìtùnú. Jésù sọ pé: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi . . . èmi yóò sì tù yín lára.”—Mátíù 11:28.
Orísun Ayọ̀
Ẹ wo irú ìkésíni oníyọ̀ọ́nú, onífẹ̀ẹ́ àti onínúure tí èyí jẹ́! Ó fi bí ọ̀ràn àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ti jẹ ẹ́ lọ́kàn tó hàn. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ń rí ìtura nínú ṣíṣe ojúṣe wọn lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù “ìhìn rere” Ìjọba Ọlọ́run. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ fún wọn ní ojúlówó ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn.—Jòhánù 4:36.
Tipẹ́tipẹ́ kí Jésù tó wá sáyé ni Ìwé Mímọ́ ti sọ ní àsọtúnsọ pé ayọ̀ gbọ́dọ̀ máa bá iṣẹ́ ìsìn mímọ́ sí Ọlọ́run rìn. Èyí ṣe kedere nínú orin tí onísáàmù náà kọ, pé: “Ẹ kígbe nínú ayọ̀ ìṣẹ́gun sí Jèhófà, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ilẹ̀ ayé. Ẹ fi ayọ̀ yíyọ̀ sin Jèhófà. Ẹ fi igbe ìdùnnú wọlé wá síwájú rẹ̀.” (Sáàmù 100:1, 2) Lónìí, àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè ń yọ̀ nínú Jèhófà, ọ̀rọ̀ ìyìn tó ń tẹnu wọn jáde sì dà bí ìgbà tí ẹgbẹ́ ọmọ ogun tó ja àjàṣẹ́gun bá ń hó ìhó ayọ̀. Àwọn tí ń fi tọkàntọkàn sin Ọlọ́run ń “fi igbe ìdùnnú” wọlé wá síwájú rẹ̀. Bó sì ṣe yẹ kó rí nìyẹn, nítorí pé “Ọlọ́run aláyọ̀” ni Jèhófà, ó sì ń fẹ́ kí àwọn ìránṣẹ́ òun máa láyọ̀ bí wọ́n ṣe ń gbé ìgbésí ayé wọn níbàámu pẹ̀lú ìyàsímímọ́ tí wọ́n ṣe sí i.—1 Tímótì 1:11.
Àwọn Òjíṣẹ́ Tó Rí Ìtura
Báwo ló ṣe jẹ́ pé kàkà kí iṣẹ́ àṣekára nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá mú kó rẹ̀ wá, ńṣe ló ń mára tù wá? Tóò, ńṣe ni ṣíṣe iṣẹ́ Jèhófà dà bí oúnjẹ tí ń sọ agbára dọ̀tun fún Jésù. Ó sọ pé: “Oúnjẹ mi ni kí n ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi àti láti parí iṣẹ́ rẹ̀.”—Jòhánù 4:34.
Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, àwọn Kristẹni onítara tí ń wàásù lónìí jẹ́ aláyọ̀ bí wọ́n ṣe ń “wàásù ọ̀rọ̀ náà.” (2 Tímótì 4:2) Obìnrin Kristẹni kan tó ń jẹ́ Connie, tó ti ń sún mọ́ ẹni àádọ́ta ọdún, tó ń lo nǹkan bí àádọ́rin wákàtí nínú iṣẹ́ ìwàásù náà sọ pé: “Lẹ́yìn tí mo bá ti jáde òde ẹ̀rí, inú mi máa ń dùn, mo máa ń ní ìtẹ́lọ́rùn, kódà bó tilẹ̀ rẹ̀ mí lálẹ́ ọjọ́ yẹn.”
Báwọn èèyàn ò bá fẹ́ gbọ́ ìhìn rere Ìjọba náà ńkọ́? Connie fi kún un pé: “Láìka ìwà àwọn èèyàn sí, kò tíì sí ìgbà tí mo kábàámọ̀ lílọ sóde ẹ̀rí rí. Yàtọ̀ sí pé mo mọ̀ pé mo ń ṣe ohun tínú Jèhófà dùn sí, mo kà á sí nǹkan ayọ̀ láti máa sọ̀rọ̀ nípa òtítọ́, torí pé ńṣe ni ìrètí àgbàyanu látinú Bíbélì túbọ̀ ń wọ̀ mí lọ́kàn ṣinṣin nígbà tí mo bá ń sọ̀rọ̀ nípa òtítọ́.”
Àwọn míì sọ pé ríran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọ́run ń jẹ́ kí ìgbésí ayé àwọn nítumọ̀. Meloney, ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ obìnrin kan tó sábà máa ń lò ju àádọ́ta wákàtí lóṣù nínú iṣẹ́ ìwàásù, sọ pé: “Iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà ń tuni lára nítorí pé ó ń jẹ́ kí ayé mi lójú, kí ó sì ní ìtumọ̀. Àwọn ìṣòro tí kálukú ń bá yí àti wàhálà ojoojúmọ́ máa ń lọ sílẹ̀ nígbà tí mo bá jáde òde ẹ̀rí.”
Millicent, tí í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó kún fún ìtara, sọ pé: “Iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà ń jẹ́ kí ọjọ́ kọ̀ọ̀kan tí mo bá lò láti fi bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa ète Ọlọ́run fún aráyé, tí mo sì fi ṣàlàyé bí a ó ṣe mú Párádísè padà bọ̀ sórí ilẹ̀ ayé jẹ́ ọjọ́ alárinrin. Ó ń jẹ́ kí n máa rí Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ẹni gidi lójoojúmọ́, kí n sì ní àlàáfíà àti ayọ̀ inú lọ́hùn-ún tí n kò lè rí lọ́nà mìíràn.”
Àwọn Tí Ìhìn Náà Tù Lára
Ó dájú pé àwọn oníwàásù Ìjọba Ọlọ́run ń rí ìtura nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni, ó sì dájú pé àwọn tó bá tẹ́wọ́ gba ìhìn tí ń fúnni ní ìyè náà ń rí ìtùnú. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn obìnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé àtàwọn àlùfáà ló tọ́ tíṣà kan ní ilẹ̀ Potogí, síbẹ̀ obìnrin náà rí i pé ṣọ́ọ̀ṣì òun kò kájú àìní òun nípa tẹ̀mí. Kò rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè tó ní nínú Bíbélì. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé, èyí tí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń darí, ló jẹ́ kó wá bẹ̀rẹ̀ sí í lóye Ìwé Mímọ́. Èyí wú tíṣà náà lórí gan-an. Ó sọ pé: “Pẹ̀lú ìháragàgà ni mo máa ń retí kí àkókò ìkẹ́kọ̀ọ́ dé lọ́jọọjọ́ Wednesday, bí mo ti ń rí ìdáhùn ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé sí àwọn ìbéèrè mi, pẹ̀lú ẹ̀rí tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ látinú Bíbélì.” Obìnrin yìí ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́, ó sì ti di ìránṣẹ́ Jèhófà báyìí. Òun náà ti bẹ̀rẹ̀ sí í fi òtítọ́ Bíbélì tu àwọn ẹlòmíràn lára.
Nítorí náà, ó ṣe kedere pé iṣẹ́ takuntakun tí wíwàásù jẹ́ àti bó ṣe jẹ́ iṣẹ́ tó gbòòrò kárí ayé kò fi iṣẹ́ náà sú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Bẹ́ẹ̀ náà ni ìdágunlá àti àtakò kò kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wọn. Wọ́n ń forí ṣe fọrùn ṣe láti lè rí i pé àwọn ṣe iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà ní àṣeparí. Wọ́n ń wàásù ìhìn rere náà níbikíbi táwọn èèyàn bá wà—ì báà jẹ́ ní ibùdókọ̀ kan ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà (1), tàbí ní pápákọ̀ òfuurufú kan ní Kòríà (2), tàbí ní àgbègbè Andes (3), tàbí ní ọjà kan ní London (4). Àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù òde òní ń fi tayọ̀tayọ̀ bá iṣẹ́ wọn tí ń mú èrè wá nìṣó kárí ayé. Gẹ́gẹ́ bí ìlérí Jésù, ó ti tù wọ́n lára, ó sì ti lò wọ́n láti mú ìtura bá ọ̀pọ̀ èèyàn.—Ìṣípayá 22:17.