Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Títí dé àyè wo ni ìkàléèwọ̀ tó wà nínú Òfin Mósè, pé kéèyàn má ṣègbéyàwó pẹ̀lú ìbátan rẹ̀, fi kan àwọn Kristẹni lóde òní?

Òfin tí Jèhófà fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì kò ṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé lórí ọ̀ràn ayẹyẹ ìgbéyàwó àti gbogbo ìlànà tó wé mọ́ ọn. Àmọ́, ó ka irú àwọn ìgbéyàwó kan léèwọ̀. Fún àpẹẹrẹ, Léfítíkù 18:6-20 ṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn ìbálòpọ̀ kan tá a kà léèwọ̀ láàárín ‘ìbátan tímọ́tímọ́.’ Àkọsílẹ̀ náà ṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé nípa àwọn ẹbí tí kò gbọ́dọ̀ bá ara wọn lò pọ̀. Ṣùgbọ́n o, Kristẹni kò sí lábẹ́ Òfin Mósè, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ìlànà rẹ̀ kò dè wọ́n. (Éfésù 2:15; Kólósè 2:14) Àmọ́ ìyẹn ò wá ní kí àwọn Kristẹni kàn ṣe bíi pé ọ̀ràn yìí kò kan àwọn, nígbà tí wọ́n bá fẹ́ yan ẹni tí wọ́n máa fẹ́. Ìdí bíi mélòó kan sì wà tí kò fi yẹ kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀.

Lákọ̀ọ́kọ́ ná, àwọn òfin ìjọba kan wà tí kò fàyè gba ìgbéyàwó láàárín ìbátan tímọ́tímọ́. A sì ti sọ fáwọn Kristẹni pé kí wọ́n ṣègbọràn sí òfin orílẹ̀-èdè tí wọ́n ń gbé. (Mátíù 22:21; Róòmù 13:1) Ṣùgbọ́n irú òfin bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ láti ibì kan síbòmíràn. Èyí tó pọ̀ jù lọ nínú irú òfin bẹ́ẹ̀ lóde òní ló wáyé nítorí àwọn èròjà tí ń pilẹ̀ àbùdá. Àwọn èèyàn ti mọ̀ lónìí pé ó ṣeé ṣe kí ìgbéyàwó láàárín àwọn ẹbí tímọ́tímọ́ mú kí àbùkù wà nínú èròjà tí ń pilẹ̀ àbùdá àwọn ọmọ tí wọ́n bá bí, tàbí kí àwọn ọmọ náà kó àwọn àrùn kan tó jẹ́ àbímọ́ni. Fún ìdí yìí àti nítorí pé àwọn Kristẹni fẹ́ “wà lábẹ́ àwọn aláṣẹ onípò gíga,” wọ́n máa ń pa òfin tí orílẹ̀-èdè wọn bá ṣe lórí ọ̀ràn ìgbéyàwó mọ́.

Ẹ tún jẹ́ ká ronú lórí ọ̀ràn ohun tó bójú mu àti ohun tí kò bójú mu láwùjọ ẹni. Ṣàṣà ni àdúgbò tí kò ti sófin tàbí àṣà tó ka ìgbéyàwó láàárín àwọn ẹbí tímọ́tímọ́ léèwọ̀, tí wọ́n máa ń ka irú ìgbéyàwó bẹ́ẹ̀ sí ohun tí etí méjì ò gbọ́dọ̀ gbọ́. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ládùúgbò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ìyàtọ̀ lè wà nínú irú àwọn ẹbí pàtó tí ọ̀ràn yìí kàn, ìwé náà The Encyclopædia Britannica sọ pé, “ní gbogbo gbòò, bí àwọn èèyàn méjì bá ṣe sún mọ́ra tó, bẹ́ẹ̀ ni èèwọ̀ náà pé wọn ò gbọ́dọ̀ bára wọn lò pọ̀ ṣe lágbára tó.” Fún ìdí yìí, kódà bí ko bá tiẹ̀ sí ọ̀ràn ìbálòpọ̀ láàárín ìbátan kan náà, àwọn Kristẹni kò ní fẹ́ tàpá sí àṣà ìbílẹ̀ tàbí àwọn ìlànà tó bójú mu láwùjọ, kí wọ́n má bàa kó ẹ̀gàn bá ìjọ Kristẹni tàbí orúkọ Ọlọ́run.—2 Kọ́ríńtì 6:3.

A ò tún gbọ́dọ̀ gbójú fo ẹ̀rí ọkàn tí Ọlọ́run fún wa dá. Gbogbo èèyàn la dá pẹ̀lú ànímọ́ mímọ ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́, ohun rere àtohun búburú. (Róòmù 2:15) Ẹ̀rí ọkàn wọn ń jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tó yẹ, tó sì bójú mu àtohun tí kò bójú mu, tó sì ta létí, àyàfi tí wọ́n bá ti sọ ẹ̀rí ọkàn wọn dìdàkudà tàbí tí wọ́n ti mú kó yigbì nítorí ìwàkíwà tí wọ́n ń hù. Jèhófà tọ́ka sí òtítọ́ yìí nígbà tó fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní òfin náà pé kò gbọ́dọ̀ sí ìgbéyàwó láàárín ẹbí tó sún mọ́ra. Òfin náà kà pé: “Bí ilẹ̀ Íjíbítì tí ẹ gbé inú rẹ̀ ti ṣe ni ẹ kò gbọ́dọ̀ ṣe; àti bí ilẹ̀ Kénáánì, inú èyí tí èmi yóò mu yín lọ ti ń ṣe ni ẹ kò gbọ́dọ̀ ṣe; ẹ kò sì gbọ́dọ̀ rìn nínú ìlànà àgbékalẹ̀ wọn.” (Léfítíkù 18:3) Àwọn Kristẹni mọyì ẹ̀rí ọkàn wọn tá a fi Bíbélì kọ́, wọn ò sì gbà kí èrò òdì àwọn orílẹ̀-èdè nípa ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́ sọ ọ́ dìdàkudà.—Éfésù 4:17-19.

Ibo wá la lè parí èrò sí? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Kristẹni kò sí lábẹ́ Òfin Mósè, ẹ̀rí ọkàn wọn ń sọ fún wọn ní kedere pé ìgbéyàwó láàárín àwọn ẹbí tímọ́tímọ́—gẹ́gẹ́ bíi láàárín bàbá àti ọmọbìnrin rẹ̀, ìyá àti ọmọkùnrin rẹ̀, tàbí láàárín tẹ̀gbọ́n-tàbúrò—kò gbọ́dọ̀ wáyé rárá lágbo àwọn Kristẹni. a Bí ìbátan láàárín àwọn ẹbí ṣe ń gbòòrò sí i, àwọn Kristẹni mọ̀ pé àwọn òfin àti ìlànà kan wà tó de ìgbéyàwó tó bófin mu àti pé àwọn ìlànà kan wà tó bójú mu nínú ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà àti nínú àṣà ìbílẹ̀. A gbọ́dọ̀ gbé ìwọ̀nyí yẹ̀ wò kínníkínní, ká lè tẹ̀ lé ìlànà Ìwé Mímọ́ tó sọ pé: “Kí ìgbéyàwó ní ọlá láàárín gbogbo ènìyàn.”—Hébérù 13:4.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Láti rí kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé lórí ọ̀ràn yìí, jọ̀wọ́ wo àpilẹ̀kọ náà “Awọn Igbeyawo Aimọ—Oju Wo Li O Yẹ Ki Awọn Kristian Fi Wò Wọn?” nínú Ile-Iṣọ Na, September 15, 1978, ojú ìwé 16 àti 17.