Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìmọ́tótó Báwo Ló Ti Ṣe Pàtàkì Tó?

Ìmọ́tótó Báwo Ló Ti Ṣe Pàtàkì Tó?

Ìmọ́tótó Báwo Ló Ti Ṣe Pàtàkì Tó?

Ọ̀TỌ̀Ọ̀TỌ̀ ni bọ́ràn ìmọ́tótó ṣe yé kálukú sí. Fún àpẹẹrẹ, bí ìyá ọmọ kékeré kan bá sọ fún un pé kó lọ fọwọ́ kó sì bọ́jú, ó lè rò pé wíwulẹ̀ fomi ṣan orí ìka ọwọ́, kí ó sì fi ọwọ́ tọ́ omi díẹ̀ sí ètè ti tó. Ṣùgbọ́n ìyá rẹ̀ mọ̀ pé ìyẹn kò tó. Ìyá rẹ̀ á wá ní kó nìṣó nídìí omi. Á wá fi ọṣẹ àti omi tó pọ̀ fọ ọwọ́ àti ojú ọmọ náà dáadáa—bí ọmọ náà tilẹ̀ figbe bọnu!

Àmọ́ o, ìlànà lórí ọ̀ràn ìmọ́tótó yàtọ̀ síra kárí ayé. Ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ sì ni ẹ̀kọ́ tá a fi tọ́ àwọn èèyàn dàgbà nípa ìmọ́tótó. Láyé àtijọ́, ọgbà iléèwé tó mọ́ tónítóní, tó sì wà létòlétò ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ń ran àwọn ọmọléèwé lọ́wọ́ láti jẹ́ onímọ̀ọ́tótó. Lóde òní, ìdọ̀tí máa ń pọ̀ rẹpẹtẹ ni ọgbà iléèwé débi pé kò fẹ́rẹ̀ẹ́ yàtọ̀ sí orí ààtàn, dípò tí ì bá fi jẹ́ ibi tí wọ́n ti lè ṣeré ìdárayá. Inú kíláàsì ńkọ́? Darren, tí í ṣe aṣọ́gbà ní iléèwé girama kan ní Ọsirélíà, sọ pé: “Ìdọ̀tí ti dénú kíláàsì báyìí.” Lójú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan, bí ìgbà téèyàn ń fìyà jẹ wọ́n ni téèyàn bá sọ fún wọn pé “Ṣa ìdọ̀tí yẹn” tàbí “Gbá ibẹ̀ yẹn mọ́.” Ohun tó ń fa ìṣòro yẹn ni pé iṣẹ́ ìmọ́tótó wà lára ìyà táwọn tíṣà kan fi ń jẹ àwọn tó bá ṣẹ̀.

Yàtọ̀ síyẹn, àwọn àgbàlagbà kì í sábàá fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ nínú ọ̀ràn ìmọ́tótó, yálà nínú ìgbòkègbodò ojoojúmọ́ tàbí níbi iṣẹ́. Fún àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ àwọn ibi tí èrò ti ń wọ́ nígboro ló dọ̀tí, tí kò sì ṣeé rí. Àwọn iléeṣẹ́ kan ń ba àyíká jẹ́. Ṣùgbọ́n kì í ṣe iléeṣẹ́ àti okòwò ló ń ba àyíká jẹ́, àwọn èèyàn tó wà níbẹ̀ kúkú ni. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọra ló wà nídìí ìṣòro ìbàyíkájẹ́ kárí ayé tó sì ti dá ọ̀pọ̀ wàhálà sílẹ̀, ara ohun tó tún ń fa ìṣòro náà ni ìwà ọ̀bùn kálukú. Ẹni tó jẹ́ gíwá àjọ Kájọlà tẹ́lẹ̀ rí ní Ọsirélíà kín ọ̀rọ̀ yìí lẹ́yìn nígbà tó sọ pé: “Àwọn ọ̀ràn tó jẹ mọ́ ìlera ará ìlú dá lórí ìwà ìmọ́tótó kálukú.”

Àmọ́ o, àwọn kan sọ pé kò séyìí tó kan àwọn ẹlòmíràn nípa ọwọ́ tí kálukú bá fi mú ọ̀ràn ìmọ́tótó. Ṣé lóòótọ́ ni?

Ìmọ́tótó ṣe pàtàkì gan-an ni, pàápàá tó bá dọ̀ràn oúnjẹ wa—yálà a lọ rà á lọ́jà, tàbí a lọ jẹ ẹ́ nílé àrójẹ, tàbí a lọ jẹ ẹ́ nílé ọ̀rẹ́ wa. Àwọn tó ń se oúnjẹ àtàwọn tó ń gbé e fúnni ò gbọ́dọ̀ fojú kékeré wo ọ̀ràn ìmọ́tótó rárá. Oríṣiríṣi àrùn la lè kó tá a bá fi ọwọ́ tó dọ̀tí kan oúnjẹ—ì báà jẹ́ ọwọ́ àwọn tó ń sè é tàbí ọwọ́ àwa tá a jẹ ẹ́. Ẹ gbọ́ o, ọsibítù wá ńkọ́, níbi tá a ti retí pé kí ọ̀ràn ìmọ́tótó jẹ àwọn èèyàn lógún jù lọ? Ìwé ìròyìn The New England Journal of Medicine ròyìn pé àwọn dókítà àtàwọn nọ́ọ̀sì tí kì í fọwọ́ wọn ló ń fà á tí àwọn aláìsàn tí ń bẹ ní ọsibítù fi ń kó àìsàn tó ń ná wọn tó bílíọ̀nù mẹ́wàá owó dọ́là láti fi wo àwọn àìsàn ọ̀hún. Bẹ́ẹ̀, a ò retí pé kí ìwà ọ̀bùn ẹnì kan fi ẹ̀mí wa wewu.

Pẹ̀lúpẹ̀lù, kì í ṣe nǹkan kékeré o, bí ẹnì kan bá mọ̀ọ́mọ̀ sọ omi wa di ẹlẹ́gbin, tàbí kí ó ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí àìbìkítà. Báwo sì ni ọkàn wa ṣe lè balẹ̀ láti máa rìn létíkun láìwọ bàtà, nígbà tá a bá ń rí abẹ́rẹ́ táwọn ajoògùnyó àti àwọn ẹlòmíràn ti lò kù nílẹ̀? Bóyá ìbéèrè tó kan kálukú gbọ̀ngbọ̀n ni pé: Ǹjẹ́ ọ̀ràn ìmọ́tótó jẹ wá lógún nínú ilé wa?

Suellen Hoy, tó kọ ìwé náà Chasing Dirt, béèrè pé: “Ǹjẹ́ ọ̀ràn ìmọ́tótó ṣì ká wa lára bíi ti tẹ́lẹ̀?” Ó dáhùn pé: “Kò jọ bẹ́ẹ̀.” Obìnrin yìí sọ pé àṣà ìgbàlódé ni ohun pàtàkì tó fà á. Nígbà táwọn èèyàn ò fi bẹ́ẹ̀ jókòó sílé mọ́, ẹlòmíràn ni wọ́n sábà máa ń sanwó fún kí ó máa bá wọn tọ́jú ilé wọn. Ìyẹn làwọn èèyàn ò fi ṣú já ọ̀ràn títọ́jú àyíká mọ́. Ọkùnrin kan sọ pé: “Kò sóhun tó kàn mí pẹ̀lú fífọ balùwẹ̀, kí n sáà ti wẹ̀ ni tèmi. Bí ilé mi tiẹ̀ dọ̀tí, bí ara tèmi ò bá ti dọ̀tí, àbùṣe-bùṣe.”

Ṣùgbọ́n ọ̀ràn ìmọ́tótó kọjá ìrísí òde ara. Gbogbo ọ̀rọ̀ ìlera nínú ìgbé-ayé ló kàn látòkèdélẹ̀. Ọ̀ràn ìmọ́tótó tún wé mọ́ ipò èrò inú àti ọkàn wa, àní títí kan ìwà àti ìjọsìn wa. Ẹ jẹ́ ká wo ìdí tí ọ̀rọ̀ fi rí bẹ́ẹ̀.