Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìmọ́tótó—Kí Ló Túmọ̀ sí Gan-an?

Ìmọ́tótó—Kí Ló Túmọ̀ sí Gan-an?

Ìmọ́tótó—Kí Ló Túmọ̀ sí Gan-an?

NÍTORÍ bí ilẹ̀ Yúróòpù àti Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ṣe dọ̀tí bí ilé póò ní ọ̀rúndún kejìdínlógún àti ìkọkàndínlógún, ohun táwọn míṣọ́nnárì ìgbà yẹn ń wàásù rẹ̀ la lè pè ni “ẹ̀kọ́ ìmọ́tótó.” Ìwàásù yìí fi yéni pé ẹ̀ṣẹ̀ ni ìwà ọ̀bùn jẹ́, ṣùgbọ́n ìmọ́tótó ń múni sún mọ́ Ọlọ́run. Bóyá ibẹ̀ lọ̀rọ̀ táwọn eléèbó máa ń sọ yẹn ti wá, pé “Lẹ́yìn ìfọkànsin Ọlọ́run, ìmọ́tótó ló kàn.”

Èyí ni ìgbàgbọ́ ṣọ́ọ̀ṣì Ẹgbẹ́ Ọmọ Ogun Ìgbàlà, tí William àti Catherine Booth dá sílẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìwé náà, Health and Medicine in the Evangelical Tradition ti wí, ọ̀kan lára ọ̀rọ̀ amóríwú tí wọ́n fi ń ṣorin kọ nígbà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dá ṣọ́ọ̀ṣì náà sílẹ̀ ni: “Ọṣẹ, Ọbẹ̀ àti Ìgbàlà.” Nígbà tí Louis Pasteur àtàwọn mìíràn wá fi hàn gbangba pé kòkòrò bakitéríà wà lára àwọn nǹkan tí ń fa àrùn, ńṣe lohun tí ìwádìí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ fi hàn yìí wá túbọ̀ jẹ́ kí wọ́n gba ọ̀ràn ìlera ìlú kanrí.

Ara ìgbésẹ̀ tí wọ́n gbé lójú ẹsẹ̀ ni pé, wọ́n ní kì í ṣe dandan mọ́ pé kí ẹni tó wá jẹ́rìí ní kóòtù fi Bíbélì kan ẹnu nígbà tó bá fẹ́ fi búra. Wọ́n tún fòpin sí kí gbogbo èèyàn máa fi ife kan náà mu omi níléèwé àti ní ibùdókọ̀ rélùwéè. Wọ́n tiẹ̀ gbìyànjú láti fún olúkúlùkù ní ife tí yóò máa lò nígbà tí wọ́n bá wá ṣèsìn ní ṣọ́ọ̀ṣì. Bẹ́ẹ̀ ni, ó jọ pé àwọn aráabí yẹn kẹ́sẹ járí títí dé àyè kan nínú yíyí èrò àwọn èèyàn nípa ọ̀ràn ìmọ́tótó padà. Àní wọ́n kẹ́sẹ járí débi pé òǹkọ̀wé kan sọ pé akitiyan wọn yọrí sí mímú táwọn èèyàn wá “mú ọ̀ràn ìmọ́tótó ní ọ̀kúnkúndùn.”

Àmọ́ ojú ayé lásán ni mímú táwọn èèyàn sọ pé àwọn “mú ọ̀ràn ìmọ́tótó ní ọ̀kúnkúndùn” yìí. Ṣebí kò pẹ́ sí àkókò yẹn táwọn oníṣòwò bòńbàtà fi sọ ọṣẹ lásán-làsàn di èròjà ìṣaralóge. Àwọn ìpolówó ọjà tó kún fún ọgbọ́n féfé ń fi yé àwọn oníbàárà pé àwọn èròjà tó jẹ́ pé kìkì ìtọ́jú ara ni wọ́n wà fún, tún ń sọ àwọn tó bá ń lò ó di sànmọ̀rí láwùjọ. Tẹlifíṣọ̀n dá kún ìgbéni-gẹṣin-aáyán yìí. A kì í rí i kí àwọn gbajúmọ̀, àwọn èèyàn tó gbáfẹ́, tí wọ́n fi ń polówó ọjà, tí wọ́n ń ṣeré lórí tẹlifíṣọ̀n máa ṣe iṣẹ́ títọ́jú ilé, kí wọ́n máa gbálẹ̀ ilé, kí wọ́n máa gbé ìdọ̀tí lọ dà nù, tàbí kí wọ́n máa fi ìgbálẹ̀ gbá ìgbẹ́ tí ológbò àti ajá wọn yà.

Àwọn kan tún wà tí wọ́n sọ pé jíjáde lọ ṣiṣẹ́ nìkan lèèyàn fi lè rówó gbọ́ bùkátà ìdílé, kì í ṣe kéèyàn jókòó ti iṣẹ́ ilé tàbí àwọn iṣẹ́ ìmọ́tótó mìíràn tí kì í mówó wọlé. Níwọ̀n bí kò ti sí owó nídìí iṣẹ́ bíbójú àyíká, èrèdí ṣíṣe irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀? Èyí ló fà á táwọn kan lónìí fi ń ronú pé kí ara sáà ti wà ní mímọ́ tónítóní nìkan lọ̀ràn ìmọ́tótó wé mọ́.

Ojú Tí Ọlọ́run Fi Ń Wo Ọ̀ràn Ìmọ́tótó

Òótọ́ ni pé akitiyan táwọn èèyàn ṣe nígbà yẹn lọ́hùn-ún láti kọ́ àwọn èèyàn ní ìwà ìmọ́tótó jẹ́ kí ìgbésí ayé wọn dára sí i. Ó sì yẹ kó rí bẹ́ẹ̀, nítorí pé ìmọ́tótó jẹ́ ànímọ́ tó pilẹ̀ṣẹ̀ látọ̀dọ̀ Jèhófà, Ọlọ́run mímọ́. Ó ń kọ́ wa ká lè ṣe ara wa láǹfààní, ká lè mọ́ ní gbogbo ọ̀nà wa.—Aísáyà 48:17; 1 Pétérù 1:15.

Jèhófà Ọlọ́run jẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ nínú ọ̀ràn yìí. Ìmọ́tótó àtàwọn ànímọ́ rẹ̀ yòókù tí a kò lè rí, hàn kedere nínú àwọn ohun tí a lè fojú rí, tí Ọlọ́run dá. (Róòmù 1:20) Àwa náà rí i pé kò sí nǹkan kan nínú ìṣẹ̀dá Ọlọ́run tí ń ba àyíká jẹ́. Ó ní ọ̀nà àrà tí ilẹ̀ ayé àtàwọn ohun alààyè tí ń bẹ nínú rẹ̀ fi ń fọ ara wọn mọ́, èyí sì jẹ́ ká mọ̀ pé ìgbé-ayé tó mọ́ tónítóní la ṣètò kéèyàn máa gbé láyé. Ẹlẹ́dàá tí kò fi ọ̀ràn ìmọ́tótó ṣeré nìkan ló lè ṣe irú ètò mímọ́ tónítóní bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, a lè tinú èyí rí i pé ó yẹ kí àwọn olùjọsìn Ọlọ́run jẹ́ mímọ́ ní gbogbo ọ̀nà ìgbésí ayé wọn.

Ìhà Mẹ́rin Tí Ìjẹ́mímọ́ Pín Sí

Bíbélì mẹ́nu kan ìhà mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí àwọn olùjọsìn Ọlọ́run ti gbọ́dọ̀ làkàkà láti wà ní mímọ́ tónítóní. Ẹ jẹ́ ká gbé wọn yẹ̀ wò lọ́kọ̀ọ̀kan.

Nípa tẹ̀mí. A lè sọ pé èyí ni ìjẹ́mímọ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ, nítorí ó wé mọ́ ìrètí fún ìyè àìnípẹ̀kun. Ṣùgbọ́n ìhà yìí gan-an làwọn èèyàn kì í sábàá kọbi ara sí nínú ọ̀ràn ìmọ́tótó. Láìfọ̀rọ̀ gùn, láti jẹ́ mímọ́ nípa tẹ̀mí túmọ̀ sí láti má ṣe ré òfin Ọlọ́run kọjá lórí ọ̀ràn ìjọsìn tòótọ́ àti ìjọsìn èké, nítorí pé Ọlọ́run ka gbogbo ìjọsìn èké sí ohun àìmọ́. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “‘Ẹ jáde kúrò láàárín wọn, kí ẹ sì ya ara yín sọ́tọ̀,’ ni Jèhófà wí, ‘kí ẹ sì jáwọ́ nínú fífọwọ́kan ohun àìmọ́’; ‘dájúdájú, èmi yóò sì gbà yín wọlé.’” (2 Kọ́ríńtì 6:17) Ọmọ ẹ̀yìn náà Jákọ́bù tún sọjú abẹ níkòó nígbà tó sọ pé: “Ọ̀nà ìjọsìn tí ó mọ́, tí ó sì jẹ́ aláìlẹ́gbin ní ojú ìwòye Ọlọ́run àti Baba wa ni èyí: . . . láti pa ara ẹni mọ́ láìní èérí kúrò nínú ayé.”—Jákọ́bù 1:27.

Kedere-kèdèrè ni Ọlọ́run fi hàn pé òun kórìíra dída ìjọsìn èké pọ̀ mọ́ ìjọsìn tòótọ́ tòun. Ìjọsìn èké sábà máa ń wé mọ́ àwọn àṣà tó jẹ́ aláìmọ́ àtàwọn òrìṣà àtàwọn ọlọ́run tí ń kóni nírìíra. (Jeremáyà 32:35) Ìdí nìyẹn tá a fi rọ àwọn Kristẹni tòótọ́ pé kí wọ́n yàgò fún ìjọsìn àìmọ́.—1 Kọ́ríńtì 10:20, 21; Ìṣípayá 18:4.

Ní ti ìwà rere. Níhìn-ín pẹ̀lú, Ọlọ́run pààlà sáàárín ohun tó mọ́ àtohun tí kò mọ́. Ohun tí ayé ti dà lódindi kò yàtọ̀ sóhun tó wà nínú Éfésù 4:17-19, tó kà pé: “Wọ́n . . . wà nínú òkùnkùn ní ti èrò orí, . . . a sì sọ wọ́n di àjèjì sí ìyè tí ó jẹ́ ti Ọlọ́run . . . Níwọ̀n bí wọ́n ti wá ré kọjá gbogbo agbára òye ìwà rere, wọ́n fi ara wọn fún ìwà àìníjàánu láti máa fi ìwà ìwọra hu onírúurú ìwà àìmọ́ gbogbo.” Irú èròkérò bẹ́ẹ̀ máa ń jẹ jáde ní onírúurú ọ̀nà, yálà láìfi bò rárá tàbí lọ́nà ọgbọ́n àyínìke. Fún ìdí yìí, ó yẹ káwọn Kristẹni ṣọ́ra gan-an.

Àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run mọ̀ pé iṣẹ́ aṣẹ́wó, ìbẹ́yà-kannáà-lòpọ̀, ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó àti wíwo àwọn ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè jẹ́ rírú òfin Jèhófà nípa ọ̀ràn ìjẹ́mímọ́. Ṣùgbọ́n ìwàkíwà wọ̀nyí wọ́pọ̀ nínú eré ìnàjú àti nínú àṣà tó lòde. Nítorí náà, àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ yàgò pátápátá fún irú ìtẹ̀sí wọ̀nyí. Wíwọ aṣọ péńpé tí ń fi àwọn ibi kọ́lọ́fín ara hàn wá sí àwọn ìpàdé Kristẹni tàbí lọ síbi ìkónilẹ́nujọ, ń pe àfiyèsí tí kò yẹ sí ara èèyàn, ó sì fi hàn pé ìwà ẹni tó wọ irú aṣọ bẹ́ẹ̀ kò tíì mọ́ tó. Yàtọ̀ sí pé irú ìmúra bẹ́ẹ̀ ń mú ìrònú ayé aláìmọ́ wọ àárín àwọn Kristẹni, ó tún lè mú ọkàn ẹlòmíràn lọ sórí àwọn ohun tí kò mọ́. Èyí jẹ́ ìhà kan tó yẹ káwọn Kristẹni ti sapá gidigidi láti lo “ọgbọ́n tí ó wá láti òkè.”—Jákọ́bù 3:17.

Ní ti èrò orí. Kò yẹ kí èrò àìmọ́ lọ fi inú wa lọ́hùn-ún ṣelé. Jésù kìlọ̀ nípa èrò àìmọ́ nígbà tó sọ pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ń bá a nìṣó ní wíwo obìnrin kan láti ní ìfẹ́ onígbòónára sí i, ti ṣe panṣágà pẹ̀lú rẹ̀ ná nínú ọkàn-àyà rẹ̀.” (Mátíù 5:28; Máàkù 7:20-23) Ọ̀rọ̀ yìí tún kan wíwo àwọn àwòrán àti fíìmù tí ń ru ìfẹ́ ìṣekúṣe sókè, kíka àwọn ìwé tí ń ṣàlàyé kúlẹ̀kúlẹ̀ ìbálòpọ̀ takọtabo àti gbígbọ́ àwọn orín tí ń múni ròròkurò. Nípa báyìí, àwọn Kristẹni kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí èrò àìmọ́ tó lè súnná sí ọ̀rọ̀ àti ìwà àìmọ́ sọ wọ́n di ẹlẹ́gbin.—Mátíù 12:34; 15:18.

Ní ti ara. Bíbélì fi hàn pé ìjẹ́mímọ́ àti ìmọ́tótó jọ ń rìn pọ̀ ni. Fún àpẹẹrẹ, Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹ jẹ́ kí a wẹ ara wa mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin ti ẹran ara àti ti ẹ̀mí, kí a máa sọ ìjẹ́mímọ́ di pípé nínú ìbẹ̀rù Ọlọ́run.” (2 Kọ́ríńtì 7:1) Ìdí nìyẹn tó fi yẹ kí àwọn Kristẹni tòótọ́ sapá gidigidi láti rí i dájú pé ara wọn, ilé wọn àti àyíká wọn wà ní mímọ́ tónítóní, bó bá ṣe lè ṣeé ṣe tó. Kódà níbi tí omi ìwẹ̀ tàbí omi fún fífọ nǹkan bá ti ṣọ̀wọ́n, ó yẹ kí àwọn Kristẹni sa gbogbo ipá wọn láti wà ní mímọ́ tónítóní, kí wọ́n sì ṣeé rí mọ́ni.

Fífẹ́ láti wà ní mímọ́ tónítóní yóò tún jẹ́ ká yàgò fún lílo tábà lọ́nà èyíkéyìí, mímu ọtí àmujù àti lílo oògùn ní ìlòkulò, nítorí pé nǹkan wọ̀nyí ń sọ ara di ẹlẹ́gbin, wọ́n sì ń ba ara jẹ́. Òórùn dídùn tó ń já fírífírí láti ara aṣọ ọmọdébìnrin Ṣúlámáítì ta sánsán sí olùṣọ́ àgùntàn tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú Orin Sólómọ́nì nímú. (Orin Sólómọ́nì 4:11) Ọ̀nà kan tá a lè gbà fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ ni láti máa rí i dájú pé a wà ní mímọ́ tónítóní, níwọ̀n bí a kò ti fẹ́ kí ara wa máa rùn sí àwọn tó wà láyìíká wa. Òótọ́ ni pé lọ́fínńdà máa ń ta sánsán, àmọ́ kò yẹ kó rọ́pò ìwẹ̀ wíwẹ̀ àti wíwọṣọ tó mọ́.

Wíwà Ní Ìwọ̀ntúnwọ̀nsì

Àwọn èèyàn máa ń ṣàṣejù lórí ọ̀ràn ìmọ́tótó. Ní ọwọ́ kan, ṣíṣe àṣerégèé nínú ọ̀ràn ìmọ́tótó kò ní jẹ́ ká gbádùn ẹ̀mí wa. Ó tún lè gba àkókò gidi. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ilé tó kún fún ẹ̀gbin, tó rí jákujàku máa ń ṣòroó tún ṣe, ìnáwó ńlá ló máa ń kóni sí. Kò yẹ ká fì sápá kan jù nínú ìhà méjèèjì yìí. Ó yẹ ká wà ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì nínú ọ̀ràn rírí i dájú pé ilé wa wà ní mímọ́ tónítóní, kí ó sì ṣeé rí mọ́ni.

Kí ẹrù má pọ̀ jù. Ilé tàbí iyàrá tó rí wúruwùru máa ń ṣòroó tọ́jú, ìdọ̀tí sì máa ń ṣòroó rí tí ẹrù bá pọ̀ jánganjàngan. Ilé tó wà ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì, tí kò rí wúruwùru kì í ṣòroó tọ́jú. Bíbélì fi hàn pé jíjẹ́ oníwọ̀ntúnwọ̀nsì ló dáa jù, ó ní: “Bí a bá ti ní ohun ìgbẹ́mìíró àti aṣọ, àwa yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú nǹkan wọ̀nyí.”—1 Tímótì 6:8.

Jẹ́ kí ó wà létòlétò. Ojúṣe gbogbo àwọn tó ń gbénú ilé ni láti rí sí i pé ó wà ní mímọ́ tónítóní. Ilé tó bá rí wúruwùru, inú iyàrá ló ti máa ń bẹ̀rẹ̀. Kílé wà létòlétò túmọ̀ sí kí ohun gbogbo wà níbi tó yẹ kó wà. Fún àpẹẹrẹ, inú iyàrá ibùsùn kọ́ ló yẹ kí á kó aṣọ tó dọ̀tí sí. Ewu tún wà nínú jíjẹ́ kí àwọn ohun ìṣiré àti irinṣẹ́ fọ́n káàkiri ilẹ̀. Ọ̀pọ̀ jàǹbá tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ilé ni fífi àwọn nǹkan sílẹ̀ jánganjàngan máa ń fà.

Ó ṣe kedere pé ìmọ́tótó àti ìgbésí ayé Kristẹni kò ṣeé yà nípa. Wòlíì Aísáyà pé ìgbésí ayé tí Ọlọ́run fẹ́ ní “Ọ̀nà Ìjẹ́mímọ́.” Ó sì fi ọ̀rọ̀ tó ń múni ronú jinlẹ̀ yìí kún un pé “aláìmọ́ kì yóò gbà á kọjá.” (Aísáyà 35:8) Nítorí náà, jíjẹ́ onímọ̀ọ́tótó nísinsìnyí ń fi hàn pé lóòótọ́ la ní ìgbàgbọ́ nínú ìlérí Ọlọ́run pé láìpẹ́, yóò sọ ilé ayé di Párádísè mímọ́ tónítóní. Tó bá dìgbà yẹn, ibi gbogbo lórí ilẹ̀ ayé ẹlẹ́wà yìí lèèyàn ó ti máa yin Jèhófà Ọlọ́run lógo nípa fífi tọkàntọkàn tẹ̀ lé ìlànà pípé tó gbé kalẹ̀ nípa ìmọ́tótó.—Ìṣípayá 7:9.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Ojúṣe gbogbo àwọn tí ń gbénú ilé ni láti rí sí i pé ó wà ní mímọ́ tónítóní

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Ilẹ̀ ayé ní ọ̀nà àrà tó fi ń fọ ara rẹ̀ mọ́