Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọmọdé Gbọ́n, Àgbà Gbọ́n, . . .

Ọmọdé Gbọ́n, Àgbà Gbọ́n, . . .

Ọmọdé Gbọ́n, Àgbà Gbọ́n, . . .

ÀWỌN kan ní Nàìjíríà máa ń pa á lówe pé: “Ọmọdé gbọ́n, àgbà gbọ́n . . . . ” Edwin, tó jẹ́ Kristẹni alàgbà ní Nàìjíríà, rí i pé òótọ́ lòwe yìí.

Lọ́jọ́ kan, Edwin rí àpótí onírin kan lábẹ́ tábìlì rẹ̀ nílé.

Edwin bi àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta pé: “Ta ló ni àpótí yìí?”

Emmanuel tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́jọ dáhùn pé: “Tèmi ni.” Kíá ló fi kún un pé àpótí onírin tó ti dípẹtà, tí fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ sẹ̀ǹtímítà méjìlá níbùú lóròó, tó ní ihò kan lórí yìí, wà fún ọrẹ tí à ń ṣe fún iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé. Ó ṣàlàyé pé: “Níwọ̀n bí n kì í ti í lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba lójoojúmọ́, ìyẹn ló jẹ́ kí n ṣe àpótí kan, kí n lè máa fi owó ìpápánu tí n kò bá ná sínú rẹ̀.”

Bàbá Emmanuel ní àpótí kan nílé tó ń fowó tí wọ́n á lò lọ sí àpéjọ àgbègbè ọdọọdún pa mọ́ sí. Ṣùgbọ́n nítorí nǹkan kan tó ṣẹlẹ̀ ní pàjáwìrì, wọ́n ti ku owó tó wà níbẹ̀ ná. Láti rí i dájú pé wọn ò ná owó tí òun fẹ́ fi ṣètọrẹ, Emmanuel mú ògbólógbòó agolo kan lọ sọ́dọ̀ àwọn jórinjórin pé kí wọ́n bóun dí i pa. Nígbà tí jórinjórin náà gbọ́ ohun tí Emmanuel fẹ́ fi agolo náà ṣe, ó wá fi àlòkù irin tó ní ṣe àpótí kan fún Emmanuel. Michael ọmọ ọdún márùn-ún, tó jẹ́ àbúrò Emmanuel, náà ní kí wọ́n bóun ṣe àpótí tòun.

Ohun táwọn ọmọ yìí ṣe ya Edwin lẹ́nu gan-an. Ó wá béèrè ìdí tí wọ́n fi ṣe àwọn àpótí náà. Michael fèsì pé: “Èmi náà fẹ́ ṣe ìtọrẹ!”

Láìjẹ́ pé àwọn òbí wọ́n mọ̀, Emmanuel, Michael àti Uchei, ẹ̀gbọ́n wọn obìnrin ọmọ ọdún mẹ́sàn-án, ti ń tere lára owó oúnjẹ ọ̀sán wọn jọ, wọ́n sì ń fi sínú àpótí wọ̀nyẹn. Ta ló kọ́ wọn lọ́gbọ́n yìí? Látìgbà táwọn ọmọ wọ̀nyí ti mọ nǹkan tí wọ́n ń pè lówó làwọn òbí wọn ti kọ́ wọn pé kí wọ́n máa fowó sínú àpótí ọrẹ tí ń bẹ nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba. Láìsí àní-àní, àwọn ọmọ náà fi ohun tá a kọ́ wọn sílò.

Nígbà táwọn àpótí náà kún, wọ́n ṣí i. Àpapọ̀ owó tó wà nínú rẹ̀ jẹ́ àádọ́ta dín nírínwó náírà. Èyí kì í ṣe owó kékeré rárá, lórílẹ̀-èdè tí ìpíndọ́gba iye owó tí ń wọlé fúnni lọ́dún ti jẹ́ nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n náírà péré. Irú ọrẹ tá a fínnú fíndọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ la fi ń ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ ìwàásù táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe ní igba ó lé márùndínlógójì [235] ilẹ̀ kárí ayé nísinsìnyí.