Àwọn Ìlànà Ọlọ́run Lè Ṣe Ọ́ Láǹfààní
Àwọn Ìlànà Ọlọ́run Lè Ṣe Ọ́ Láǹfààní
LÁÌSÍ àní-àní, o mọ̀ pé agbára ìsúnniṣe ló ń darí àwọn ẹranko. Ọ̀pọ̀ ẹ̀rọ ló sì ní àwọn ìtọ́ni tí wọ́n ń tẹ̀ lé. Àmọ́ ńṣe la dìídì dá àwọn èèyàn kí ìlànà lè máa tọ́ wọn sọ́nà. Báwo la ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀? Tóò, Jèhófà, tó jẹ́ Olùdásílẹ̀ gbogbo ìlànà òdodo, kéde nígbà tó fẹ́ dá àwọn ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́ pé: “Jẹ́ kí a ṣe ènìyàn ní àwòrán wa, ní ìrí wa.” Ẹ̀mí ni Ẹlẹ́dàá; kò ní ẹran ara bíi tiwa. Nítorí náà, ó dá wa ní “àwòrán” rẹ̀ ní ti pé a lè gbé àwọn àkópọ̀ ìwà rẹ̀ yọ, ká sì ní àwọn ànímọ́ àtàtà tó ní. Àwọn èèyàn ní làákàyè láti darí ìgbésí ayé wọn ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà, ìyẹn ni, ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí wọ́n gbà pé ó jẹ́ ọ̀nà ìhùwà tí ó tọ́. Jèhófà ti mú kí a kọ ọ̀pọ̀ lára àwọn ìlànà wọ̀nyí sílẹ̀ nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 1:26; Jòhánù 4:24; 17:17.
Ẹnì kan lè sọ pé: ‘Àmọ́ ọgọ́rọ̀ọ̀rún ìlànà ló wà nínú Bíbélì. Mi ò rò pé mo lè mọ gbogbo wọn tán.’ Òtítọ́ ni. Àmọ́, gbé kókó yìí yẹ̀ wò: Nígbà tó jẹ́ pé gbogbo ìlànà Ọlọ́run ló ṣàǹfààní, síbẹ̀ àwọn kan tẹ̀wọ̀n ju àwọn mìíràn lọ. Mátíù 22:37-39, níbi tí Jésù ti fi hàn pé nínú gbogbo àṣẹ àtàwọn ìlànà tó ń bá wọn rìn nínú Òfin Mósè, àwọn kan ṣe pàtàkì ju àwọn mìíràn lọ.
O lè rí ìyẹn nínúÀwọn ìlànà wo ló tẹ̀wọ̀n jù? Àwọn ìlànà tó ṣe kókó jù lọ nínú Bíbélì làwọn tó kan àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà gbọ̀ngbọ̀n. Bá a bá fi ìwọ̀nyí sọ́kàn, a jẹ́ pé Ẹlẹ́dàá la fi sí ipò kìíní nínú ohun tá a gbé ìlànà ìwà rere wa kà. Ní àfikún sí i, àwọn ìlànà kan tún wà tó nípa lórí àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Fífi èyí sílò yóò ràn wá lọ́wọ́ láti kápá ẹ̀mí tèmi-nìkan-ṣáá, lọ́nàkọnà tó lè gbà yọjú.
Ẹ jẹ́ ká bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀kan lára àwọn òtítọ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú Bíbélì. Òtítọ́ wo nìyẹn, báwo ló sì ṣe kàn wá?
“Ẹni Gíga Jù Lọ Lórí Gbogbo Ilẹ̀ Ayé”
Ìwé Mímọ́ mú un ṣe kedere pé Jèhófà ni Atóbilọ́lá Ẹlẹ́dàá wa, Ọlọ́run Olódùmarè. Kò láfiwé, kò sì sẹ́ni tó lè gbapò rẹ̀. Èyí jẹ́ òtítọ́ pàtàkì kan tá a kọ sínú Bíbélì.—Jẹ́nẹ́sísì 17:1; Oníwàásù 12:1.
Ọ̀kan lára àwọn tó kọ ìwé Sáàmù sọ nípa Jèhófà pé: “Ìwọ nìkan ṣoṣo ni Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé.” Dáfídì Ọba ìgbàanì kọ̀wé pé: “Tìrẹ ni ìjọba, Jèhófà, ìwọ Ẹni tí ń gbé ara rẹ sókè ṣe olórí pẹ̀lú lórí ohun gbogbo.” Wòlíì tó gbajúmọ̀ nì, Jeremáyà, kọ̀wé pé: “Lọ́nàkọnà, kò sí ẹnikẹ́ni tí ó dà bí ìwọ, Jèhófà. O tóbi, orúkọ rẹ sì pọ̀ ní agbára ńlá.”—Sáàmù 83:18; 1 Kíróníkà 29:11; Jeremáyà 10:6.
Báwo la ṣe lè fi àwọn òtítọ́ wọ̀nyí nípa Ọlọ́run sílò nínú ìgbésí ayé wa ojoojúmọ́?
Láìsí tàbí-tàbí, a mọ ẹni tó yẹ́ kó gba ipò kìíní nínú ìgbésí ayé wa—Ẹlẹ́dàá wa Ẹni tó fún wa ní ìyè ni. Ǹjẹ́ kò ní dára ká dènà èrò èyíkéyìí tó lè mú ká pe àfiyèsí sí ara wa—èrò tó lè lágbára lára àwọn kan ju ti àwọn mìíràn lọ? Ìlànà ọlọgbọ́n kan tó lè tọ́ni sọ́nà ni pé ká “máa ṣe ohun gbogbo fún ògo Ọlọ́run.” (1 Kọ́ríńtì 10:31) Wòlíì Dáníẹ́lì fi àpẹẹrẹ àtàtà lélẹ̀ nínú ọ̀ràn yìí.
Àkọsílẹ̀ ìtàn náà sọ fún wa pé ìgbà kan wà tí àlá tí Nebukadinésárì Ọba Bábílónì lá kó ṣìbáṣìbo bá a, tó sì fẹ́ mọ ìtumọ̀ rẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo àwọn tó kù kò lè rọ́ àlá náà, Dáníẹ́lì sọ ohun tí ọba náà fẹ́ mọ̀ fún un láìfi ìkan pe méjì. Ǹjẹ́ Dáníẹ́lì fi ògo náà fún ara rẹ̀? Rárá o, ó fi ògo fún ‘Ọlọ́run tó wà ní ọ̀run tí ó jẹ́ Olùṣí àwọn àṣírí payá.’ Dáníẹ́lì ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó ní: “Kì í ṣe nípasẹ̀ ọgbọ́n èyíkéyìí tí ó wà nínú mi tí ó ju ti inú àwọn mìíràn tí ó wà láàyè lọ ni a fi ṣí àṣírí yìí payá fún mi.” Dáníẹ́lì jẹ́ ẹni tó ń tẹ̀ lé ìlànà. Abájọ tó fi jẹ́ pé nínú ìwé Dáníẹ́lì, ìgbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ la pè é ní ẹni tí ó “fani lọ́kàn mọ́ra gidigidi” lójú Ọlọ́run.—Dáníẹ́lì 2:28, 30; 9:23; 10:11, 19.
Yóò ṣe ọ́ láǹfààní tó o bá fara wé Dáníẹ́lì. Láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Dáníẹ́lì, ohun tó máa pinnu kókó ibẹ̀ ni irú ẹ̀mí tó o fi ṣe é. Ta ló máa gba ògo ohun tó o ṣe? Láìfi ipòkípò tó o wà pè, o láǹfààní láti gbégbèésẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà Bíbélì tó ṣe pàtàkì yìí—ìyẹn ni pé Jèhófà ni Olúwa Ọba Aláṣẹ. Ṣíṣe tí o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ yóò jẹ́ kí o di ẹni tó “fani lọ́kàn mọ́ra gidigidi” ní ojú rẹ̀.
Ẹ jẹ́ ká wá gbé àwọn ìlànà pàtàkì méjì yẹ̀ wò, èyí tó lè darí wa nínú bí a ṣe ń bá àwọn ẹlòmíràn lò. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ àfèmi-àfèmi ti gbòde kan, ìṣòro ńlá ni apá yìí jẹ́ nínú ìgbésí ayé.
“Pẹ̀lú Ìrẹ̀lẹ̀ Èrò Inú”
Àwọn tó fi tara wọn sípò kìíní kì í sábàá nítẹ̀ẹ́lọ́rùn. Ọ̀pọ̀ jù lọ wọn ló ń fẹ́ ìgbésí ayé tó sàn ju èyí lọ, wọn sì ń fẹ́ ẹ lójú ẹsẹ̀. Lójú tiwọn, àìlera ni wíwà níwọ̀ntúnwọ̀nsì jẹ́. Wọ́n gbà pé àwọn ẹlòmíràn ló yẹ kó ní sùúrù. Kò sóhun tí wọn ò lè ṣe láti dépò iwájú. Ǹjẹ́ o rò pé ó ṣeé ṣe láti yẹra fún irú ìwà bẹ́ẹ̀?
Ojoojúmọ́ làwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run máa ń rí irú ìṣarasíhùwà yẹn, àmọ́ wọn ò gbọ́dọ̀ bá wọn hu irú ìwà bẹ́ẹ̀. Àwọn Kristẹni tó dàgbà dénú tẹ́wọ́ gba ìlànà tó sọ pé “kì í ṣe ẹni tí ń dámọ̀ràn ara rẹ̀ fún ìtẹ́wọ́gbà ni a tẹ́wọ́ gbà, bí kò ṣe ẹni tí Jèhófà dámọ̀ràn fún ìtẹ́wọ́gbà.”—2 Kọ́ríńtì 10:18.
Fífi ìlànà tó wà nínú Fílípì 2:3, 4 sílò yóò ṣèrànwọ́. Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yẹn gbà ọ́ nímọ̀ràn láti má ṣe ṣe ‘ohunkóhun láti inú ẹ̀mí asọ̀ tàbí láti inú ìgbéra-ẹni-lárugẹ, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, kí o máa kà á sí pé àwọn ẹlòmíràn lọ́lá jù ọ́ lọ.’ Nípa bẹ́ẹ̀ o ò ní ‘máa mójú tó ire ara ẹni nínú kìkì àwọn ọ̀ràn ti ara rẹ nìkan, ṣùgbọ́n ire ara ẹni ti àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú.’
Ẹnì kan tó mọ̀wọ̀n ara rẹ̀, tí kò sì ro ara rẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ ni Gídíónì, tó jẹ́ adájọ́ láàárín àwọn Hébérù ìgbàanì. Kò gbìyànjú láti jẹ́ aṣáájú Ísírẹ́lì. Àní, nígbà tí wọ́n yàn án láti wá gba Àwọn Onídàájọ́ 6:12-16.
ipò yẹn, ńṣe ni Gídíónì tún ń fi yé wọn pé ipò yẹn kò tọ́ sóun rárá. Ó ṣàlàyé pé: “Ẹgbẹ̀rún tèmi ni èyí tí ó kéré jù lọ ní Mánásè, èmi sì ni ó kéré jù lọ ní ilé baba mi.”—Jù bẹ́ẹ̀ lọ, lẹ́yìn tí Jèhófà fún Gídíónì ní ìṣẹ́gun, àwọn ọkùnrin Éfúráímù bẹ̀rẹ̀ sí í bá a ṣe aáwọ̀. Kí ni Gídíónì wá ṣe? Ǹjẹ́ ìjagunmólú yẹn kó sí i lórí? Rárá o. Ó sá fún wàhálà nípa fífi sùúrù dá wọn lóhùn. Ó ní: “Kí sì ni mo tíì ṣe ní ìfiwéra pẹ̀lú yín?” Gídíónì jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ní èrò inú.—Àwọn Onídàájọ́ 8:1-3.
Òótọ́ ni pé ó ti pẹ́ gan-an tí ìtàn Gídíónì yìí ti ṣẹlẹ̀. Síbẹ̀, ó mọ́gbọ́n dání láti gbé àkọsílẹ̀ náà yẹ̀ wò. Wàá rí i pé Gídíónì ní ìṣarasíhùwà kan tó yàtọ̀ pátápátá sí èyí tó gbòde kan lóde òní, ó gbé ní ìbámu pẹ̀lú ìṣarasíhùwà náà, ó sì ṣe é láǹfààní.
Ẹ̀mí àfèmi-àfèmi tó gbòde kan lè jẹ́ ká ní èrò òdì pé a tó báyìí a jù báyìí lọ. Àwọn ìlànà Bíbélì tún èrò òdì yẹn ṣe, ó jẹ́ ká mọ bá a ṣe jẹ́ gan-an lójú Ẹlẹ́dàá àti lójú àwọn ẹlòmíràn.
Nípa títẹ̀lé àwọn ìlànà Bíbélì, a óò lè kápá ẹ̀mí tèmi-nìkan-ṣáá tó gbòde. Bí nǹkan ṣe ń rí lára ẹni tàbí irú ẹni tá a jẹ́ kò ní darí wa mọ́. Bí a ṣe túbọ̀ ń kọ́ nípa àwọn ìlànà òdodo, bẹ́ẹ̀ náà la óò túbọ̀ máa sún mọ́ ẹni tó jẹ Olùdásílẹ̀ wọn. Bẹ́ẹ̀ ni o, pípe àfiyèsí àrà ọ̀tọ̀ sáwọn ìlànà Ọlọ́run nígbà tá a bá ń ka Bíbélì tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ.—Wo àpótí.
Jèhófà mú káwọn èèyàn lọ́lá ju àwọn ẹranko lọ, àwọn tó jẹ́ pé kìkì agbára ìsúnniṣe ló ń darí wọn. Ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run wé mọ́ fífi àwọn ìlànà Ọlọ́run sílò. A lè tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ kí atọ́ka ìwà rere wa máa ṣiṣẹ́ dáadáa, ìyẹn atọ́ka tí yóò darí wa sínú ètò tuntun ti Ọlọ́run. Bíbélì sọ ìdí tá a fi ní láti máa retí ètò tuntun kan tó kárí ayé láìpẹ́, nínú èyí tí “òdodo yóò sì máa gbé.”—2 Pétérù 3:13.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Àwọn Ìlànà Bíbélì Tó Lè Ṣèrànwọ́
Láàárín Ìdílé:
“Kí olúkúlùkù má ṣe máa wá àǹfààní ti ara rẹ̀, bí kò ṣe ti ẹnì kejì.” —1 Kọ́ríńtì 10:24.
“Ìfẹ́ . . . kì í wá àwọn ire tirẹ̀ nìkan.”—1 Kọ́ríńtì 13:4, 5.
“Kí olúkúlùkù yín lẹ́nì kọ̀ọ̀kan máa nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀.”—Éfésù 5:33.
“Ẹ̀yin aya, ẹ wà ní ìtẹríba fún àwọn ọkọ yín.”—Kólósè 3:18.
“Fetí sí baba rẹ tí ó bí ọ, má sì tẹ́ńbẹ́lú ìyá rẹ kìkì nítorí pé ó ti darúgbó.”—Òwe 23:22.
Nílé ìwé, lẹ́nu iṣẹ́, tàbí níbi ìṣòwò:
“Òṣùwọ̀n aláwẹ́ méjì tí a fi ń rẹ́ni jẹ jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí . . . Ẹni burúkú ń pa owó ọ̀yà èké.”—Òwe 11:1, 18.
“Kí ẹni tí ń jalè má jalè mọ́, ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, kí ó máa ṣe iṣẹ́ àṣekára.”—Éfésù 4:28.
“Bí ẹnikẹ́ni kò bá fẹ́ ṣiṣẹ́, kí ó má ṣe jẹun.”—2 Tẹsalóníkà 3:10.
“Ohun yòówù tí ẹ bá ń ṣe, ẹ fi tọkàntọkàn ṣe é bí ẹni pé fún Jèhófà.”—Kólósè 3:23.
“A ti dàníyàn láti máa hùwà láìṣàbòsí nínú ohun gbogbo.”—Hébérù 13:18.
Ìṣarasíhùwà nípa ọrọ̀:
“Ẹni tí ó bá ń ṣe kánkán láti jèrè ọrọ̀ kì yóò máa bá a nìṣó láti jẹ́ aláìmọwọ́-mẹsẹ̀.”—Òwe 28:20.
“Olùfẹ́ fàdákà kì yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú fàdákà.”—Oníwàásù 5:10.
Mímọ̀wọ̀n ara ẹni:
“Kí àwọn ènìyàn sì máa wá ògo ara wọn, ṣé ògo ni?”—Òwe 25:27.
“Àjèjì ni kí ó yìn ọ́, kí ó má ṣe jẹ́ ẹnu ìwọ fúnra rẹ.”—Òwe 27:2.
“Mo sọ fún gbogbo ẹni tí ń bẹ láàárín yín níbẹ̀ láti má ṣe ro ara rẹ̀ ju bí ó ti yẹ ní rírò lọ.”—Róòmù 12:3.
“Bí ẹnikẹ́ni bá rò pé òun jẹ́ nǹkan kan nígbà tí kò jẹ́ nǹkan kan, ó ń tan èrò inú ara rẹ̀ jẹ.”—Gálátíà 6:3.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Dáníẹ́lì fún Ọlọ́run ní ọ̀wọ̀ tó yẹ ẹ́
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Bíbá àwọn ẹlòmíràn lò ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà Ọlọ́run ń mú àjọṣe tó lárinrin àti ayọ̀ wá
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 7]
U.S. Fish & Wildlife Service, Washington, D.C./Robert Bridges