Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Kí ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ tó wà nínú Hébérù 12:4, tó kà pé: “Ẹ kò tíì dúró tiiri títí dé orí ẹ̀jẹ̀”?
Gbólóhùn náà, “dúró tiiri títí dé orí ẹ̀jẹ̀” túmọ̀ sí fífara dà á títí dé ojú ikú, ìyẹn ni pé kí ẹnì kan jẹ́ kí a ta ẹ̀jẹ̀ òun sílẹ̀.
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé àwọn Kristẹni kan tó jẹ́ Hébérù ti “fara da ìdíje ńláǹlà lábẹ́ àwọn ìjìyà” nítorí ìgbàgbọ́ wọn. (Hébérù 10:32, 33) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń tọ́ka síyẹn, ó dà bí ẹni pé àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́ ló ń lò nípa àwọn tó ń tiraka láti gbégbá orókè nínú ìdíje táwọn Gíríìkì máa ń ṣe, èyí tó lè ní eré sísá, ìjàkadì, kíkan ẹ̀ṣẹ́, àti jíju ọ̀kọ̀ nínú. Ìyẹn ló jẹ́ kó rọ àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ nínú Hébérù 12:1, pé: “Ẹ jẹ́ kí àwa pẹ̀lú mú gbogbo ẹrù wíwúwo kúrò àti ẹ̀ṣẹ̀ tí ó máa ń wé mọ́ wa pẹ̀lú ìrọ̀rùn, ẹ sì jẹ́ kí a fi ìfaradà sá eré ìje tí a gbé ka iwájú wa.”
Ó ní láti jẹ́ pé ńṣe ni Pọ́ọ̀lù ti orí ọ̀rọ̀ sárésáré bọ́ sórí ti ẹni tó ń kan ẹ̀ṣẹ́ nínú ọ̀rọ̀ tó sọ ní ẹsẹ mẹ́ta lẹ́yìn ìyẹn, ní Hébérù 12:4. (Àwọn eléré méjèèjì ló mẹ́nu kàn nínú 1 Kọ́ríńtì 9:26.) Ọṣán ni wọ́n fi ń di ẹ̀ṣẹ́ àti ọrùn ọwọ́ àwọn tí ń kan ẹ̀ṣẹ́ láyé ọjọ́un. Ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kí wọ́n so “òjé, irin, tàbí àwọn òníní tí a fi mẹ́táàlì ṣe, èyí tó máa ń dá egbò burúkú sára àwọn tó ń kan ẹṣẹ́,” mọ́ ọṣán náà kí ó lè wúwo. Irú ìjà àjàkú-akátá bẹ́ẹ̀ máa ń jẹ́ kí ara èèyàn ṣẹ̀jẹ̀ gan-an, ó sì máa ń yọrí sí ikú nígbà mìíràn.
Lọ́rọ̀ kan ṣá, àwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù ti rí ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run tá a ṣe inúnibíni sí, tá a hùwà òkú òǹrorò sí, kódà dójú ikú pàápàá, ìyẹn “títí dé orí ẹ̀jẹ̀.” Kíyè sí àyíká ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù ti pe àfiyèsí sí ohun tójú àwọn olóòótọ́ ayé ìgbàanì rí:
“A sọ wọ́n ní òkúta, a dán wọn wò, a fi ayùn rẹ́ wọn sọ́tọ̀ọ̀tọ̀, wọ́n kú nípa fífi idà pa wọ́n, wọ́n lọ káàkiri nínú awọ àgùntàn, nínú awọ ewúrẹ́, nígbà tí wọ́n wà nínú àìní, nínú ìpọ́njú, lábẹ́ ìṣẹ́níṣẹ̀ẹ́.” Ẹ̀yìn ìyẹn ni Pọ́ọ̀lù wá sọ̀rọ̀ nípa Jésù, Aláṣepé ìgbàgbọ́ wa, pé: “Ó fara da òpó igi oró, ó tẹ́ńbẹ́lú ìtìjú, ó sì ti jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọlọ́run.”—Hébérù 11:37; 12:2.
Bẹ́ẹ̀ ni o, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti “dúró tiiri títí dé orí ẹ̀jẹ̀,” ìyẹn títí dé ojú ikú. Dídúró tiiri wọn kọjá ìjàkadì tí à ń bá ẹ̀ṣẹ̀ àti àìní ìgbàgbọ́ jà nínú lọ́hùn-ún. Wọ́n dúró ṣinṣin nígbà táwọn èèyàn ń fìyà líle koko jẹ wọ́n, àní wọ́n di ìṣòtítọ́ wọn mú títí dé ojú ikú.
Àwọn ẹni tuntun tó wà nínú ìjọ Jerúsálẹ́mù, tó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìgbà tí inúnibíni líle koko ayé ìgbàanì rọlẹ̀ ni wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ di Kristẹni, kò rí irú àdánwò líle koko bẹ́ẹ̀ rí. (Ìṣe 7:54-60; 12:1, 2; Hébérù 13:7) Síbẹ̀, àwọn àdánwò tí kò le tó ìwọ̀nyẹn pàápàá ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn kan tí wọn ò fi fẹ́ máa bá eré ìje náà lọ mọ́; ó ń ‘rẹ̀ wọ́n, wọ́n sì ń rẹ̀wẹ̀sì nínú ọkàn wọn.’ (Hébérù 12:3) Wọ́n ní láti tẹ̀ síwájú dé ìdàgbàdénú. Ìyẹn yóò sọ wọ́n di alágbára láti fara da ohunkóhun tó lè ṣẹlẹ̀, kódà bó tilẹ̀ kan ìlunibolẹ̀ títí dórí títa ẹ̀jẹ̀ wọn sílẹ̀ pàápàá.—Hébérù 6:1; 12:7-11.
Ọ̀pọ̀ Kristẹni òde òní ló ti “dúró tiiri títí dé orí ẹ̀jẹ̀,” táwọn èèyàn ti pa wọ́n nítorí pé wọ́n kọ̀ láti sẹ́ ìgbàgbọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí Kristẹni. Dípò tá a fi máa jẹ́ kí ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ nínú Hébérù 12:4 kó ìpayà bá wa, a lè wò ó bí èyí tó ń tọ́ka sí ibi tí ìpinnu wa láti jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run lè gbòòrò dé. Lẹ́yìn ìyẹn, nínú lẹ́tà kan náà tí Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn Hébérù yìí, ó kọ̀wé pé: “Ẹ jẹ́ kí á máa bá a lọ láti ní inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí, nípasẹ̀ èyí tí a fi lè ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún Ọlọ́run lọ́nà tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà pẹ̀lú ìbẹ̀rù Ọlọ́run àti ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀.”—Hébérù 12:28.