Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìfọkànsin Ọlọ́run

Ìfọkànsin Ọlọ́run

Ìfọkànsin Ọlọ́run

ÈYÍ ni ọ̀wọ̀ tí à ń ní fún Ọlọ́run, ìjọsìn, àti iṣẹ́ ìsìn tí à ń ṣe fún un, pa pọ̀ mọ́ jíjẹ́ tí a jẹ́ olóòótọ́ sí ipò ọba aláṣẹ àgbáyé rẹ̀. Eu·seʹbei·a àti àwọn ọ̀rọ̀ ajúwe, ọ̀rọ̀ àpọ́nlé, àti ọ̀rọ̀ ìṣe tó tan mọ́ ọn ni ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí Ìwé Mímọ́ lò. Ọ̀rọ̀ orúkọ tá a sì lò fún un nínú Bíbélì lè túmọ̀ ní ṣáńgílítí sí “ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀,” ó sì ń tọ́ka sí ọ̀wọ̀ tàbí ìfọkànsìn sí nǹkan tó dìídì jẹ́ mímọ́ àti òdodo. (Fi wé 2 Pétérù 1:​6, Kingdom Interlinear) Ọ̀rọ̀ tó jẹ́ òdìkejì “ìfọkànsin Ọlọ́run” ni “àìní ìbẹ̀rù Ọlọ́run” tàbí “àìní ọ̀wọ̀” (tí a mọ̀ sí a·seʹbei·a lédè Gíríìkì).

Nigel Turner kọ ọ́ sínú ìwé Christian Words, pé: “Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ọ̀nà tí wọ́n gbà ń lo ọ̀rọ̀ náà eusebeia nínú àwọn ìwé ìgbàanì fi hàn pé ìtumọ̀ rẹ̀ kò jìnnà sí ìfọkànsìn nínú ẹ̀sìn téèyàn ń ṣe . . . àmọ́ ohun tí gbogbo gbòò gbà pé ó túmọ̀ sí nínú èdè Gíríìkì tí tẹrú-tọmọ ń sọ ní àkókò àwọn ará Róòmù ni ‘ìdúróṣinṣin.‘ . . . Lójú àwọn Kristẹni, eusebeia ni irú ìfọkànsin tó ga jù lọ fún Ọlọ́run.” (1981, ojú ìwé 111) Lílò tí Bíbélì lo gbólóhùn náà “ìfọkànsin Ọlọ́run” ń tọ́ka sí ìfọkànsìn tí ó wé mọ́ ìdúróṣinṣin sí Jèhófà Ọlọ́run fúnra rẹ̀.

Ọ̀rọ̀ ajúwe tó tan mọ́ ọn, ìyẹn eu·se·besʹ, tó túmọ̀ sí “olùfọkànsìn; ti ìfọkànsin Ọlọ́run,” fara hàn nínú Ìṣe 10:​2, 7; 2 Pétérù 2:⁠9. Gẹ́gẹ́ bí John A. H. Tittmann, ṣe sọ ọ́, eu·se·besʹ “ń tọ́ka sí ìfọkànsìn fún Ọlọ́run, èyí tí ń hàn nínú ìṣe, àgàgà nínú jíjọ́sìn Ọlọ́run; . . . olùfọkànsìn [eu·se·besʹ] lẹni tó bá ń fi irú ìfọkànsìn bẹ́ẹ̀ hàn nínú ìṣe rẹ̀.”​—⁠ Remarks on the Synonyms of the New Testament, Edinburgh, 1833, Apá Kìíní, ojú ìwé 253 sí 254.

Ọ̀rọ̀ ìṣe náà eu·se·beʹo la lò nínú 1 Tímótì 5:4 fún ìwà àwọn ọmọ tàbí àwọn ọmọ-ọmọ sí àwọn ìyá tàbí àwọn ìyá wọn àgbà tó jẹ́ opó. Ìwé atúmọ̀ èdè tí ń jẹ́ A Greek and English Lexicon of the New Testament, èyí tí Edward Robinson ṣe (1885, ojú ìwé 307), sọ pé eu·se·beʹo lè túmọ̀ sí jíjẹ́ olùfọkànsìn sí ẹnikẹ́ni. Nítorí ìdí èyí, bí àwọn kan ṣe túmọ̀ àyọkà yìí ni pé: “Wọ́n gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ kọ́ láti ṣe ojúṣe tiwọn nínú ìdílé ti ara wọn.” (The Jerusalem Bible) Àmọ́ Ọlọ́run ni Olùdásílẹ̀ ètò ìdílé (Éfésù 3:​14, 15), Bíbélì sì fi agboolé Ọlọ́run wé ìdílé. Nítorí náà, ìfọkànsìn, tàbí ìfọkànsin Ọlọ́run, nínú àjọṣe ìdílé nínú agboolé Kristẹni yóò jẹ́ bí ìdílé ṣe ń fọkàn sin Ọlọ́run àti bí ó ṣe ń ṣe ìgbọràn sí àwọn àṣẹ Ọlọ́run títí kan ìwà yíyẹ tí àwọn aráalé yẹn ń hù. Títúmọ̀ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí sí, “Bí opó èyíkéyìí bá ní àwọn ọmọ tàbí àwọn ọmọ-ọmọ, kí àwọn wọ̀nyí kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ láti máa fi ìfọkànsin Ọlọ́run ṣe ìwà hù nínú agbo ilé tiwọn” (Ìtumọ̀ ti Ayé Tuntun), bá òye yìí mu.

‘Àṣírí Ọlọ́wọ̀ ti Ìfọkànsìn Ọlọ́run’

Ẹni tó fi àpẹẹrẹ aláìlẹ́gbẹ́ lélẹ̀ nínú ọ̀ràn ìfọkànsìn Ọlọ́run ni Jésù Kristi. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí Tímótì pé: “Ní ti tòótọ́, àṣírí ọlọ́wọ̀ yìí ti fífọkànsin Ọlọ́run ni a gbà pé ó ga lọ́lá: ‘A fi í hàn kedere ní ẹran ara, a polongo rẹ̀ ní olódodo nínú ẹ̀mí, ó fara han àwọn áńgẹ́lì, a wàásù nípa rẹ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, a gbà á gbọ́ nínú ayé, a gbà á sókè nínú ògo.’” (1 Tímótì 3:16) Ádámù, tó jẹ́ ọkùnrin pípé, kò fi àpẹẹrẹ pípé nípa ìfọkànsìn Ọlọ́run lélẹ̀. Kò sì sí èyíkéyìí lára àwọn ọmọ rẹ̀ tá a bí ní aláìpé tó lè ṣe bẹ́ẹ̀. Ta ló wá lè ṣe bẹ́ẹ̀? Wíwá tí ọmọ Ọlọ́run wá sórí ilẹ̀ ayé àti bó ṣe pa ìwà títọ́ mọ́ dáhùn ìbéèrè náà, tó sì tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ kí a rí ojútùú sí àṣírí ọlọ́wọ̀ náà. Òun ni ẹni tí Tímótì ní láti wò fún àpẹẹrẹ pípé ní ti ìwà tó fi ìfọkànsìn Ọlọ́run hàn.​—⁠1 Tímótì 3:⁠15.

Jésù Kristi ni ẹni tó fi ìfọkànsìn Ọlọ́run hàn lọ́nà pípé, nínú ohun gbogbo, tó fi hàn pé ènìyàn ẹlẹ́ran ara lè ní irú ìfọkànsìn bẹ́ẹ̀. Lábẹ́ àdánwò bíburú jáì, títí dé òpin iṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé ni Jésù fi jẹ́ “adúróṣinṣin, aláìlẹ́tàn, aláìlẹ́gbin, tí a yà sọ́tọ̀ kúrò láàárín àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.” (Hébérù 7:26) Kò sí àbààwọ́n kankan nínú ìwà títọ́ rẹ̀, tó lè jẹ́ kí ó dẹni tó lábùkù níwájú Ọlọ́run. Ó sọ ṣáájú ikú rẹ̀ pé: “Mo ti ṣẹ́gun ayé,” ó tún sọ pé, “Olùṣàkóso ayé ń bọ̀. Kò sì ní ìdìmú kankan lórí mi.” (Jòhánù 16:33; 14:30) A ò lè rí àìṣòdodo kankan nínú rẹ̀. Abájọ tó fi sọ fún àwọn ọ̀tá rẹ̀ pé: “Ta ni nínú yín tí ó dá mi lẹ́bi ẹ̀ṣẹ̀?” (Jòhánù 8:46) Ìtumọ̀ ‘àṣírí ọlọ́wọ̀ ti ìfọkànsìn Ọlọ́run yìí’ ga gan-⁠an, ó sì jẹ́ ohun ribiribi fún ìran ènìyàn débi pé a ní láti kéde rẹ̀ jákèjádò ayé. Jésù Kristi fúnra rẹ̀ ni àwòfiṣàpẹẹrẹ nínú ọ̀ràn ìfọkànsìn Ọlọ́run àti ìwà Kristẹni nínú ìjọ.

Fífi Ẹ̀mí Níní Ìtẹ́lọ́rùn Kọ́ra Ṣe Pàtàkì

Kristẹni tó bá fẹ́ ní ìfọkànsìn Ọlọ́run tó kún rẹ́rẹ́ á sapá gidigidi. Ó gba kéèyàn fara da àtakò àti inúnibíni. (2 Tímótì 3:12) Kì í ṣe ìfẹ́ àtikó ọrọ̀ jọ lèèyàn ṣe ń kọ́ ara rẹ̀. Àmọ́, èrè wà fún ẹni tó bá ní ìtẹ́lọ́rùn nínú ipò tó wà, tó ń tẹ̀ síwájú nínú ìfọkànsìn Ọlọ́run pẹ̀lú ẹ̀mí ohun-moní tómi. Ó “ní ìlérí ìyè ti ìsinsìnyí,” ìyẹn ìlera nípa tẹ̀mí, ìtẹ́lọ́rùn, ayọ̀, àti ète nínú ìgbésí ayé. Ó tún ní ìlérí ìyè “tí ń bọ̀.”​—⁠1 Tímótì 4:​7, 8; 6:​6-8; fi wé Òwe 3:​7, 8; 4:​20-22.

Bí inúnibíni àti ìṣòro bá tiẹ̀ dé bá ẹni tó ní ìfọkànsìn Ọlọ́run, kó má bẹ̀rù, nítorí pé “Jèhófà mọ bí a ti ń dá àwọn ènìyàn tí ń fọkàn sin Ọlọ́run nídè kúrò nínú àdánwò.” (2 Pétérù 2:⁠9) Àpọ́sítélì Pétérù gba àwọn Kristẹni níyànjú láti fi ìfọkànsìn Ọlọ́run kún ìfaradà wọn. (2 Pétérù 1:​5, 6) Ó gbà wọ́n níyànjú láti jẹ́ ẹni tí ń ṣe “ìṣe ìwà mímọ́ àti àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run,” kí wọ́n lè la ọjọ́ ìdájọ́ Jèhófà já.​—⁠2 Pétérù 3:​7, 10, 11; 1 Pétérù 4:⁠18.

Agbára Tí Ìfọkànsìn Ọlọ́run Ní

Ẹni tó bá sọ pé òun ní ìfọkànsìn Ọlọ́run gbọ́dọ̀ mọ̀ pé ó lágbára láti yí àkópọ̀ ìwà òun padà, irú ẹni bẹ́ẹ̀ sì gbọ́dọ̀ máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run tọkàntọkàn. (1 Tímótì 6:11; Éfésù 4:​20-24) Ó gbọ́dọ̀ mọ̀ pé inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run la ti lè rí ọ̀nà tí Ọlọ́run fẹ́ ká tọ̀ láti lè jẹ́ olùfọkànsìn Ọlọ́run, ó sì ní láti fara mọ́ àwọn ìlànà rẹ̀. (Títù 1:⁠1; 2 Pétérù 1:⁠3) Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé Ọlọ́run tìkára rẹ̀ là ń fọkàn sìn, Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ẹ̀mí rẹ̀ á jẹ́ ká mọ Jèhófà dáradára, ká sì túbọ̀ dà bíi rẹ̀​—⁠ìyẹn ni pé ká máa fara wé e. (Éfésù 5:⁠1) Irú ẹni bẹ́ẹ̀ yóò túbọ̀ máa gbé àwọn ànímọ́ àtàtà Jèhófà Ọlọ́run yọ.​—⁠2 Kọ́ríńtì 3:⁠18.

Bí ẹnikẹ́ni tó sọ pé òun ń sin Ọlọ́run bá gbẹ́kẹ̀ lé àwọn èrò ti ara rẹ̀ dípò tí ì bá fi máa tẹ̀ lé Bíbélì, bí ẹ̀kọ́ irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò bá sì “wà ní ìbámu pẹ̀lú fífọkànsin Ọlọ́run,” tí ó sì wá tipa bẹ́ẹ̀ hàn pé olùkọ́ náà kì í ṣe olùfọkànsìn Ọlọ́run, a jẹ́ pé “olókùnrùn ní èrò orí” ni onítọ̀hún. (1 Tímótì 6:​3, 4) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ fún Tímótì, òjíṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tí kò tó o lọ́jọ́ orí, pé kí ó ṣọ́ra fún àwọn èèyàn burúkú tí ń pe ara wọn ní olùfọkànsìn Ọlọ́run. Ó kìlọ̀ fún Tímótì láti fi ọwọ́ títọ̀nà mú Ọ̀rọ̀ òtítọ́, kí ó máa yẹra fún àwọn òfìfo ọ̀rọ̀ tí ó máa ń fi àìmọ́ ba ohun mímọ́ jẹ́, kí Tímótì má bàa ṣíwọ́ fífọkànsin Ọlọ́run. Ó wá là á mọ́lẹ̀ pé àwọn kan á wà tí wọ́n óò máa hu onírúurú ìwà ibi, tí wọn óò máa ṣojú ayé pé àwọn ní ìfọkànsìn Ọlọ́run, ṣùgbọ́n tí wọn óò já sí èké ní ti agbára rẹ̀. (2 Tímótì 2:​15, 16; 3:​1-5) Bákan náà ni Júúdà sọ pé irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ kò ní í ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni wọn ò sìn ín tọkàntọkàn, wọn ò ní í ní ọ̀wọ̀ tàbí ìmọrírì fún inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀. Wọ́n á jẹ́ àwọn tó ń fi ìfọkànsin Ọlọ́run bojú láti lè ráyè kó ọrọ̀ jọ tàbí láti lè ráyè tẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wọn lọ́rùn. Ìwà àgàbàgebè wọn la máa ń rí nínú ìṣe àìníjàánu wọn.​—⁠Júúdà 4.

Kí ni “ohun ìjìnlẹ̀ ìwà àìlófin” tí Pọ́ọ̀lù tọ́ka sí?

Ohun ìjìnlẹ̀ mìíràn tún lèyí, èyí yàtọ̀ pátápátá sí “àṣírí ọlọ́wọ̀.” Èyí ni “ohun ìjìnlẹ̀ ìwà àìlófin.” Ohun ìjìnlẹ̀ lèyí jẹ́ fún àwọn Kristẹni tòótọ́ láyé ọjọ́un, nítorí pé nígbà ayé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, “ọkùnrin aláìlófin náà” kò tíì fara hàn kedere gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ kan tó ti fìdí múlẹ̀. Kódà lẹ́yìn tí “ọkùnrin náà” bá fara hàn tán, ẹni tó jẹ́ gan-⁠an yóò ṣì jẹ́ ohun ìjìnlẹ̀ sí ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn nítorí pé ńṣe ni yóò máa fi ìfọkànsìn Ọlọ́run bojú ṣe iṣẹ́ ibi rẹ̀. Ní ti tòótọ́, yóò jẹ́ apẹ̀yìndà sí ojúlówó ìfọkànsìn Ọlọ́run. Pọ́ọ̀lù sọ pé “ohun ìjìnlẹ̀ ìwà àìlófin yìí” ti bẹ̀rẹ̀ nígbà ayé òun, nítorí pé ìwà àìlófin tí ń yọjú nínú ìjọ Kristẹni nígbà yẹn, ìyẹn ló sì máa mú ẹgbẹ́ apẹ̀yìndà náà jáde níkẹyìn. Níkẹyìn, Jésù Kristi yóò pa ẹni yìí run nígbà ìfarahàn wíwàníhìn-⁠ín rẹ̀. Apẹ̀yìndà yìí, ìyẹn “ọkùnrin” tí Sátánì ń darí náà, yóò gbé ara rẹ̀ lékè “gbogbo ẹni tí à ń pè ní ‘ọlọ́run’ tàbí ohun tí à ń fún ní ọ̀wọ̀” (tí a pè ní seʹba·sma lédè Gíríìkì). Nípa bẹ́ẹ̀, ẹni tó ń ṣe àtakò ńlá sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ohun èlò Sátánì yìí yóò tan àwọn èèyàn jẹ jìnnàjìnnà, yóò sì mú ìparun bá àwọn tó ń tẹ̀ lé ìṣe rẹ̀. Ohun tí yóò mú kí “ọkùnrin aláìlófin” náà rí àwọn èèyàn tàn jẹ ni pé yóò gbé àdàmọ̀dì ìfọkànsìn Ọlọ́run wọ̀ nígbà tó bá ń hu ìwà ibi rẹ̀.​—⁠ 2 Tẹsalóníkà 2:​3-12; fi wé Mátíù 7:​15, 21-23.