A Ti Mú Wa Gbára Dì Fún Iṣẹ́ Olùkọ́ni Ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
A Ti Mú Wa Gbára Dì Fún Iṣẹ́ Olùkọ́ni Ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
“Ọlọ́run, . . . ti mú wa tóótun tẹ́rùntẹ́rùn ní tòótọ́ láti jẹ́ òjíṣẹ́.”—2 KỌ́RÍŃTÌ 3:5, 6.
1, 2. Ìsapá wo làwọn kan máa ń ṣe láti wàásù nígbà míì, àmọ́ kí nìdí tí wọ́n fi máa ń kógbá sílé?
BÁWO ló ṣe máa rí lára rẹ, bí wọ́n bá ní kó o lọ ṣe iṣẹ́ kan tí o ò mọ̀-ọ́n ṣe? Fojú inú wò ó ná: Àwọn ohun tó o nílò ló wà níwájú rẹ yìí. Irinṣẹ́ sì ń bẹ lóríṣiríṣi. Ṣùgbọ́n bó o ṣe fẹ́ ṣe iṣẹ́ ọ̀hún ò yé ọ rárá. Iṣẹ́ tí à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí tún wá lọ jẹ́ iṣẹ́ kánjúkánjú. Ìwọ làwọn èèyàn ń dúró dè. Ẹ wo bó ṣe máa fayé súni tó!
2 Irú ìṣòro tó kani láyà bẹ́ẹ̀ ń ṣẹlẹ̀ dáadáa. Gbé àpẹẹrẹ kan yẹ̀ wò. Nígbà míì, ọ̀kan lára àwọn ṣọ́ọ̀ṣì máa ń gbìyànjú láti ṣètò àtilọ wàásù láti ilé dé ilé. Àìmọye ìgbà ni irú ìsapá bẹ́ẹ̀ ń forí ṣánpọ́n, tí wọ́n á sì ti kógbá sílé láàárín ọ̀sẹ̀ tàbí oṣù díẹ̀. Kí ló fà á? Àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì kò ran àwọn ọmọ ìjọ wọn lọ́wọ́ láti tóótun fún iṣẹ́ náà ni. Àwọn àlùfáà alára kò tóótun fún iṣẹ́ ìwàásù yẹn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti lo ọ̀pọ̀ ọdún ní iléèwé ayé àti ní ilé ẹ̀kọ́ àwọn àlùfáà. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀?
3. Ní 2 Kọ́ríńtì 3:5, 6, gbólóhùn wo la lò lẹ́ẹ̀mẹta, kí ló sì túmọ̀ sí?
3 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣàlàyé ohun tí ń múni tóótun láti jẹ́ oníwàásù òdodo nínú iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Kristẹni. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé lábẹ́ ìmísí pé: “Kì í ṣe pé àwa fúnra wa tóótun tẹ́rùntẹ́rùn láti ṣírò ohunkóhun gẹ́gẹ́ bí èyí tí ń ti ọ̀dọ̀ àwa fúnra wa jáde wá, ṣùgbọ́n títóótun wa tẹ́rùntẹ́rùn ń jáde wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ẹni tí ó ti mú wa tóótun tẹ́rùntẹ́rùn ní tòótọ́ láti jẹ́ òjíṣẹ́.” (2 Kọ́ríńtì 3:5, 6) Kíyè sí gbólóhùn tá a lò lẹ́ẹ̀mẹta níbẹ̀, èyíinì ni, “tóótun tẹ́rùntẹ́rùn.” Kí ló túmọ̀ sí? Ìwé Vine’s Expository Dictionary of Biblical Words sọ pé: “Tá a bá lo [ọ̀rọ̀ Gíríìkì yìí] fún àwọn nǹkan, ó lè túmọ̀ sí ‘tó’ . . . ; àmọ́ tá a bá lò ó féèyàn, ohun tó túmọ̀ sí ni ‘pegedé,’ tàbí ‘yẹ.’” Ìyẹn ló fi jẹ́ pé ẹni tó bá “tóótun tẹ́rùntẹ́rùn” ló pegedé, tó sì yẹ láti ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí. Òdodo ọ̀rọ̀, àwọn tó jẹ́ ojúlówó òjíṣẹ́ ìhìn rere tóótun láti ṣe iṣẹ́ yìí. Wọ́n pegedé, wọ́n kúnjú òṣùwọ̀n, àní wọ́n yẹ láti wàásù.
4. (a) Báwo ni àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù ṣe fi hàn pé a kò fi títóótun fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni mọ sọ́dọ̀ kìkì àwọn ọ̀tọ̀kùlú kéréje? (b) Kí ni ohun mẹ́ta tí Jèhófà ń lò láti fi mú ká tóótun gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́?
4 Àmọ́ kí ló mú wọn tóótun ná? Ṣé ẹ̀bùn àbínibí wọn ni? Ṣé torí pé wọ́n jẹ́ ọ̀mọ̀ràn tí ń mọ oyún ìgbín nínú ìkarawun ni? Ṣé nítorí pé wọ́n lọ kọ́ àkànṣe ẹ̀kọ́ ní àwọn iléèwé ńláńlá kan ni? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kúkú ní gbogbo nǹkan wọ̀nyẹn. (Ìṣe 22:3; Fílípì 3:4, 5) Síbẹ̀, ó fi tìrẹ̀lẹ̀-tìrẹ̀lẹ̀ sọ pé títóótun tí òun tóótun gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ kì í ṣe nítorí àwọn iléèwé ńlá tóun lọ, bí kò ṣe látọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run. Ṣé àwọn ọ̀tọ̀kùlú kéréje nìkan ló láǹfààní láti di ẹni tó tóótun? Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí ìjọ Kọ́ríńtì nípa “títóótun wa tẹ́rùntẹ́rùn.” Èyí fi hàn kedere pé Jèhófà ló ń rí sí i pé gbogbo àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ òun pegedé, kí wọ́n lè ṣe iṣẹ́ tóun yàn fún wọn. Báwo ni Jèhófà ṣe ń sọ àwọn Kristẹni tòótọ́ di ẹni tó tóótun lónìí? Ẹ jẹ́ ká jíròrò ohun mẹ́ta tó ń lò: (1) Ọ̀rọ̀ rẹ̀, (2) ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ àti (3) ètò àjọ rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé.
Ọ̀rọ̀ Jèhófà Ń Mú Wa Tóótun
5, 6. Kí ni ipa tí Ìwé Mímọ́ ń ní lórí àwọn Kristẹni tòótọ́?
5 Lákọ̀ọ́kọ́ ná, báwo ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe ń mú ká tóótun gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́? Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, fún mímú àwọn nǹkan tọ́, fún bíbániwí nínú òdodo, kí ènìyàn Ọlọ́run lè pegedé ní kíkún, tí a mú gbára dì pátápátá fún iṣẹ́ rere gbogbo.” (2 Tímótì 3:16, 17) Nítorí náà, Ìwé Mímọ́ lè mú ká di ẹni tó “pegedé ní kíkún, tí a mú gbára dì pátápátá” láti ṣe “iṣẹ́ rere” ti kíkọ́ àwọn èèyàn ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n gbogbo àwọn tó wá ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì ńkọ́? Bíbélì sáà ń bẹ lárọ̀ọ́wọ́tó àwọn náà. Báwo ni ìwé kan náà ṣe lè ran àwọn kan lọ́wọ́ láti di òjíṣẹ́ tó pegedé, tí kò sì ran àwọn mìíràn lọ́wọ́? Ó sinmi lórí ojú tá a fi ń wo Bíbélì.
6 Ó bani nínú jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn tó ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì ni kò tẹ́wọ́ gba ìsọfúnni tó wà nínú Bíbélì “gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ lótìítọ́, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.” (1 Tẹsalóníkà 2:13) Ipa tí àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì kó nínú ọ̀ràn yìí sì burú gan-an ni. Ṣé táwọn àlùfáà bá ti fi ọ̀pọ̀ ọdún kẹ́kọ̀ọ́ ní àwọn ilé ẹ̀kọ́ ìsìn, wọ́n á ti wá dẹni tó gbára dì láti di olùkọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run? Rárá o. Ṣebí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan tó gba Bíbélì gbọ́ kí wọ́n tó wọ ilé ẹ̀kọ́ ìsìn di oníyèméjì nígbà tí wọ́n fi máa gboyè jáde! Lẹ́yìn fífi ilé ẹ̀kọ́ ọ̀hún sílẹ̀ ńkọ́, dípò kí wọ́n máa wàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run—èyí tí ọ̀pọ̀ nínú wọn ò gbà gbọ́ mọ́—ọ̀tọ̀ lohun tí wọ́n wá gbájú mọ́ níbi iṣẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n láwọn ń ṣe. Ìdí ọ̀rọ̀ ìṣèlú la ti ń bá wọn, tàbí kí wọ́n máa sá sókè sódò nídìí pé àwọn fẹ́ fi ìlànà Kristẹni yanjú ìṣòro ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà, tàbí kí ó jẹ́ pé ọ̀rọ̀ ọgbọ́n ayé yìí ni lájorí ohun tí wọ́n ń wàásù rẹ̀. (2 Tímótì 4:3) Ní ìyàtọ̀ pátápátá sí èyí, àpẹẹrẹ Jésù Kristi làwọn Kristẹni tòótọ́ ń tẹ̀ lé.
7, 8. Báwo ni ìṣarasíhùwà Jésù nípa Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe yàtọ̀ sí ti àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ìgbà ayé rẹ̀?
7 Jésù kò jẹ́ kí àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ìgbà ayé rẹ̀ sọ òun dà bí wọ́n ti dà. Ì báà jẹ́ àwùjọ kéréje, irú bí àwọn àpọ́sítélì rẹ̀, tàbí ọ̀pọ̀ èrò ni Jésù ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́, kò lè ṣe kí ó máà lo Ìwé Mímọ́. (Mátíù 13:10-17; 15:1-11) Àṣà yìí jẹ́ kó yàtọ̀ pátápátá sáwọn aṣáájú ẹ̀sìn ìgbà yẹn. Wọn ò fẹ́ kí àwọn gbáàtúù mọ àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run rárá. Àní, ó wọ́pọ̀ láyé ọjọ́un kí olùkọ́ sọ pé àwọn ibì kan nínú Ìwé Mímọ́ ti jinlẹ̀ ju ohun tóun kàn lè máa ṣàlàyé fún ẹnikẹ́ni yàtọ̀ sí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó sún mọ́ òun tímọ́tímọ́—pẹ̀lú ìyẹn náà, yóò tún máa jí i sọ wúyẹ́wúyẹ́ sí wọn létí ni, yóò sì tún da nǹkan borí pàápàá. Àní bí àwọn aṣáájú ẹ̀sìn wọ̀nyẹn ṣe sọ pé èèwọ̀ ni pípe orúkọ Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n mà ṣe fẹ́ sọ jíjíròrò àwọn apá ibì kan nínú Bíbélì di èèwọ̀!
8 Kristi kì í ṣe irú èèyàn bẹ́ẹ̀. Lójú tirẹ̀, kì í ṣe àwọn kéréje kan, bí kò ṣe gbogbo èèyàn ló yẹ kó mọ̀ nípa “gbogbo àsọjáde tí ń jáde wá láti ẹnu Jèhófà.” Jésù ò gbà pé àwọn ọ̀tọ̀kùlú tó sọ pé àwọn ń kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ jinlẹ̀ nìkan ló yẹ ká fi kọ́kọ́rọ́ ìmọ̀ dá lọ́lá. Ó sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ohun tí mo sọ fún yín nínú òkùnkùn, ẹ sọ ọ́ nínú ìmọ́lẹ̀; ohun tí ẹ sì gbọ́ tí a sọ wúyẹ́wúyẹ́, ẹ wàásù rẹ̀ láti orí ilé.” (Mátíù 4:4; 10:27) Jésù fi taratara fẹ́ láti tan ìmọ̀ nípa Ọlọ́run dé ọ̀dọ̀ gbogbo èèyàn tó bá láǹfààní láti tàn án dé.
9. Báwo làwọn Kristẹni tòótọ́ ṣe ń lo Bíbélì?
9 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló yẹ ká gbé ẹ̀kọ́ wa kà. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tá a bá níṣẹ́ ní Gbọ̀ngàn Ìjọba àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kò yẹ ká fi mọ sórí wíwulẹ̀ ka àwọn ẹsẹ Bíbélì kan. Á dáa ká ṣàlàyé rẹ̀, ká fọ́ ọ sí wẹ́wẹ́, ká sì sọ bí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà ṣe kàn wá. Ohun tá à ń lépa ni láti la ìhìn Bíbélì yé àwọn olùgbọ́ wa yékéyéké, kí ó sì wọ̀ wọ́n lọ́kàn ṣinṣin. (Nehemáyà 8:8, 12) Ó tún yẹ ká máa lo Bíbélì nígbà tá a bá fẹ́ fúnni nímọ̀ràn tàbí ìbáwí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn Jèhófà ń sọ èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, tí wọ́n sì dàgbà lábẹ́ onírúurú ipò, gbogbo wọn ló ń fi ojú ribiribi wo ọba ìwé náà—Bíbélì.
10. Agbára wo ni ìsọfúnni onímìísí tó wà nínú Bíbélì lè sà lórí wa?
10 Nígbà tá a bá lo ìhìn inú Bíbélì tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, ó máa ń sa agbára. (Hébérù 4:12) Ó máa ń sún àwọn èèyàn láti ṣe ìyípadà pàtàkì nínú ìgbésí ayé wọn, irú bíi jíjáwọ́ nínú àwọn ìwàkiwà tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu, bí àgbèrè, panṣágà, ìbọ̀rìṣà, ìmutíyó, àti olè jíjà. Ó ti ran ọ̀pọ̀lọpọ̀ lọ́wọ́ láti bọ́ ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà sílẹ̀, kí wọ́n sì gbé tuntun wọ̀. (Éfésù 4:20-24) Ó sì dájú pé bí a bá bọ̀wọ̀ fún Bíbélì ju èrò tàbí àṣà àtọwọ́dọ́wọ́, tá a sì ń fi ìṣòtítọ́ lò ó, ó lè mú wa pegedé, ká sì gbára dì gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
Ẹ̀mí Jèhófà Ń Mú Ká Tóótun
11. Kí nìdí tó fi bá a mu wẹ́kú láti pe ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà ní “olùrànlọ́wọ́ náà”?
11 Ìkejì, ẹ jẹ́ ká jíròrò ipa tí ẹ̀mí mímọ́, ìyẹn ipá ìṣiṣẹ́ Jèhófà, ń kó nínú mímú wa gbára dì. Ká má gbàgbé o, pé ẹ̀mí Jèhófà ni ipá tó lágbára jù lọ. Jèhófà fún Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n lágbára láti lo ipá ńláǹlà yìí fún ire gbogbo Kristẹni tòótọ́. Abájọ tí Jésù fi pe ẹ̀mí mímọ́ ní “olùrànlọ́wọ́ náà.” (Jòhánù 16:7) Ó rọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n tọrọ ẹ̀mí yẹn lọ́wọ́ Jèhófà, ó sì fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ pé Jèhófà yóò fún wọn láìṣahun.—Lúùkù 11:10-13; Jákọ́bù 1:17.
12, 13. (a) Èé ṣe tó fi ṣe pàtàkì láti máa gbàdúrà pé kí ẹ̀mí mímọ́ ràn wá lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa? (b) Báwo làwọn Farisí ṣe fi hàn pé ẹ̀mí mímọ́ kò sí nínú àwọn?
12 Ó yẹ ká máa gbàdúrà fún ẹ̀mí mímọ́ lójoojúmọ́, pàápàá jù lọ pé kí ó ràn wá lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Agbára wo ni ipá ìṣiṣẹ́ yìí lè sà lórí wa? Ó máa ń sa agbára lórí èrò inú àti ọkàn wa, ó ń ràn wá lọ́wọ́ láti yí padà, láti dàgbà dénú, láti fi àkópọ̀ ìwà tuntun rọ́pò ti ògbólógbòó. (Kólósè 3:9, 10) Ó ń ràn wá lọ́wọ́ láti mú irú àwọn ànímọ́ ṣíṣeyebíye, tí Kristi ní, dàgbà. Ọ̀pọ̀ nínú wa ló lè ka Gálátíà 5:22, 23 láti orí. Ẹsẹ wọ̀nyẹn to èso tẹ̀mí Ọlọ́run lẹ́sẹẹsẹ. Ìfẹ́ ni àkọ́kọ́. Ànímọ́ yẹn ṣe pàtàkì nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Èé ṣe?
13 Ìfẹ́ ló máa ń súnni gbégbèésẹ̀. Ìfẹ́ fún Jèhófà àti fún ọmọnìkejì ló ń sún àwọn Kristẹni tòótọ́ láti máa wàásù ìhìn rere. (Máàkù 12:28-31) Láìsí irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀, a ò lè tóótun ní tòótọ́ láti di olùkọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ẹ ṣàkíyèsí ìyàtọ̀ tó wà láàárín Jésù àtàwọn Farisí. Mátíù 9:36 sọ nípa Jésù pé: “Nígbà tí ó rí àwọn ogunlọ́gọ̀, àánú wọn ṣe é, nítorí a bó wọn láwọ, a sì fọ́n wọn ká bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn.” Ojú wo làwọn Farisí fi ń wo àwọn èèyàn? Wọ́n sọ pé: “Ogunlọ́gọ̀ yìí tí kò mọ Òfin jẹ́ ẹni ègún.” (Jòhánù 7:49) Àwọn Farisí yẹn ò nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn rárá. Ojú ẹ̀gàn ni wọ́n fi ń wò wọ́n. Ó dájú pé kò sí ẹ̀mí Jèhófà nínú wọn.
14. Ipa wo ló yẹ kí fífi tí Jésù fìfẹ́ hàn nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ní lórí wa?
14 Àánú àwọn èèyàn ṣe Jésù. Ó mọ ohun tójú wọ́n ń rí. Ó mọ̀ pé ojú wọ́n ti rí màbo. Wọ́n ti jẹ wọ́n kan eegun. Wọ́n sì ti tú wọn ká, bí àgùntàn tí kò ní olùṣọ́. Jòhánù 2:25 sọ fún wa pé Jésù “mọ ohun tí ó wà nínú ènìyàn.” Nítorí pé Jésù ni Àgbà Òṣìṣẹ́ tí Jèhófà lò nígbà ìṣẹ̀dá, ó mọ irú ẹ̀dá téèyàn jẹ́ lámọ̀dunjú. (Òwe 8:30, 31) Òye yẹn jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ̀ túbọ̀ jinlẹ̀ sí i. Ǹjẹ́ kí irú ìfẹ́ yẹn máa sún wa ṣiṣẹ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù wa! Bí a bá ríbi tó ti yẹ ká ṣàtúnṣe nínú ọ̀ràn yìí, ẹ jẹ́ ká gbàdúrà pé kí Jèhófà fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, ká sì ṣiṣẹ́ lórí àdúrà wa. Jèhófà yóò dá wa lóhùn. Yóò rán ipá tí kò ṣeé dè lọ́nà yìí sí wa láti ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ jẹ́ oníwà bí Kristi, ẹni tó tóótun ní gbogbo ọ̀nà láti wàásù ìhìn rere náà.
15. Báwo ni ọ̀rọ̀ inú Aísáyà 61:1-3 ṣe bá Jésù mu, tó sì tú àwọn akọ̀wé òfin àtàwọn Farisí fó lákòókò kan náà?
15 Ta ló fọwọ́ sí i pé Jésù tóótun? Ó sọ pé: “Ẹ̀mí Jèhófà ń bẹ lára mi.” (Lúùkù 4:17-21) Bẹ́ẹ̀ ni o, Jèhófà tìkára rẹ̀ ló fi ẹ̀mí mímọ́ yan Jésù. Jésù kò nílò ìwé ẹ̀rí kankan. Ṣé ẹ̀mí mímọ́ ló yan àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ìgbà ayé rẹ̀ ni? Rárá o. Bẹ́ẹ̀ ni a kò mú wọn gbára dì láti mú àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà 61:1-3 ṣẹ, èyí tí Jésù kà sókè ketekete, tó sì ṣàlàyé pé ó ṣẹ sí òun lára. Jọ̀wọ́ ka ẹsẹ wọ̀nyẹn, kí o sì fojú ara rẹ rí i pé àwọn akọ̀wé òfin àtàwọn Farisí alágàbàgebè wọ̀nyẹn kò kúnjú ìwọ̀n. Wọn ò kúkú ní ìhìn rere kankan láti polongo fáwọn òtòṣì. Báwo sì ni wọ́n ṣe lè wàásù ìtúsílẹ̀ fáwọn òǹdè àti ìtúnríran fáwọn afọ́jú? Ṣebí afọ́jú làwọn náà nípa tẹ̀mí, tí àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ ṣì gbé wọn dè! Láìdàbí àwọn Farisí yẹn, ǹjẹ́ àwa kò tóótun láti kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́?
16. Ìdánilójú wo làwọn èèyàn Jèhófà òde òní lè ní láti sọ pé àwọn tóótun gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́?
16 Òótọ́ ni pé a kò lọ kàwé láwọn iléèwé gíga ti àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì. Iléèwé àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀sìn kọ́ ló yanṣẹ́ olùkọ́ni fún wa. Ṣé ìyẹn wá sọ pé a kò tóótun ni bí? Ó tì o! Jèhófà ló yàn wá gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí rẹ̀. (Aísáyà 43:10-12) Bá a bá ń gbàdúrà pé kó fún wa ní ẹ̀mí rẹ̀, tá a sì ń ṣiṣẹ́ lórí àdúrà wa, kò sẹ́ni tó tóótun tó wa. A mọ̀ pé ẹ̀dá aláìpé ni wá, kì í sì í ṣe ìgbà gbogbo là ń dé ojú ìlà àpẹẹrẹ tí Jésù Olùkọ́ Ńlá náà fi lélẹ̀. Síbẹ̀síbẹ̀, ǹjẹ́ a kò dúpẹ́ pé Jèhófà ń lo ẹ̀mí rẹ̀ láti fi mú wa tóótun, ká sì gbára dì gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ni ní Ọ̀rọ̀ rẹ̀?
Ètò Àjọ Jèhófà Ń Mú Ká Tóótun
17-19. Báwo ni ìpàdé márààrún tí ètò àjọ Jèhófà pèsè lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ láti tóótun gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́?
17 Wàyí o, ẹ jẹ́ ká jíròrò ohun kẹta tí Jèhófà ń lò láti fi mú wa gbára dì gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ni ní Ọ̀rọ̀ rẹ̀—èyíinì ni ìjọ rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé, ìyẹn ètò àjọ rẹ̀, tó ń dá wa lẹ́kọ̀ọ́ láti di òjíṣẹ́. Lọ́nà wo? Sáà ronú nípa ìtòlẹ́sẹẹsẹ ẹ̀kọ́ tá à ń rí gbà! A máa ń ṣe ìpàdé Kristẹni márùn-ún lọ́sẹ̀. (Hébérù 10:24, 25) A ń pé jọ ní àwọn àwùjọ kéékèèké ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ láti gbádùn ẹ̀kọ́ àkọ́jinlẹ̀ nínú Bíbélì nípa lílo ọ̀kan lára ìwé tí ètò àjọ Jèhófà pèsè. Nípa fífetísílẹ̀ àti dídáhùn, à ń kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ ara wa lẹ́nì kìíní kejì, a sì ń fún ara wa níṣìírí. Alábòójútó ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé ìjọ sì máa ń fún ẹnì kọ̀ọ̀kan wa nítọ̀ọ́ni àti àfiyèsí. À ń jẹ ọ̀pọ̀ oúnjẹ tẹ̀mí tó dọ́ṣọ̀ nígbà Ìpàdé fún Gbogbo Ènìyàn àti nígbà Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́.
18 A gbé Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run kalẹ̀ kí a lè máa gba ìtọ́ni lórí bí a ṣe ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́. Nípa mímúra àwọn ọ̀rọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ sílẹ̀, à ń mọ bá a ṣe ń fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kọ́ni lórí oríṣiríṣi kókó ẹ̀kọ́. (1 Pétérù 3:15) Ǹjẹ́ a ti yan kókó ẹ̀kọ́ kan tó jọ pé o mọ̀ dunjú fún ọ pé kí o sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ rí, àmọ́ tó o wá rí i pé ò ń rí ẹ̀kọ́ tuntun kọ́ nípa rẹ̀? Ìyẹn máa ń ṣẹlẹ̀ dáadáa. Kò sí nǹkan míì tó tún ń mú kí ohun tá a mọ̀ nípa kókó ẹ̀kọ́ kan túbọ̀ kún rẹ́rẹ́ ju fífi kọ́ àwọn ẹlòmíràn. Kódà bí kì í bá ṣe àwa ló ni ọ̀rọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ kan, a ṣì ń rí nǹkan kọ́, tó ń mú ká túbọ̀ já fáfá gẹ́gẹ́ bí olùkọ́. A máa ń rí àwọn ànímọ́ rere lára akẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan, a sì máa ń ronú nípa bí àwa náà ṣe lè nírú ànímọ́ yẹn.
19 Bákan náà ni a gbé Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn kalẹ̀ kí ó lè mú wa gbára dì gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ la máa ń gbádùn ọ̀rọ̀ tí ń tani jí, àtàwọn ìjíròrò àti àṣefihàn tó jẹ mọ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Báwo la ṣe fẹ́ gbọ́rọ̀ kalẹ̀? Báwo la ṣe lè kojú ìpèníjà àrà ọ̀tọ̀ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa fún gbogbo èèyàn? Àwọn àǹfààní wo la lè ronú kàn, tó ṣí sílẹ̀ fún wa láti wàásù? Kí ni yóò jẹ́ ká túbọ̀ jẹ́ olùkọ́ tó gbéṣẹ́ nígbà tá a bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò, tá a sì ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? (1 Kọ́ríńtì 9:19-22) Irú ìbéèrè báwọ̀nyí àtàwọn mìíràn là ń dáhùn, tá a sì ń jíròrò lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ nínú Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn. Ọ̀pọ̀ lára apá ìpàdé là ń gbé ka àwọn àpilẹ̀kọ látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa, tí í ṣe irinṣẹ́ mìíràn tá a pèsè láti mú wa gbára dì fún iṣẹ́ pàtàkì tí à ń ṣe.
20. Báwo la ṣe lè jàǹfààní lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ nínú àwọn ìpàdé àtàwọn àpéjọ?
20 À ń gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lóríṣiríṣi ọ̀nà bá a ti ń múra sílẹ̀ fáwọn ìpàdé wa, tá a sì ń pésẹ̀ síbẹ̀, tá a sì ń fi àwọn ohun tá à ń kọ́ sílò nínú iṣẹ́ wa gẹ́gẹ́ bí olùkọ́. Àmọ́, ó ṣì kù. A tún ní àwọn ìpàdé ńláńlá àti àwọn àpéjọ tó ń mú wa gbára dì gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ẹ sì wo bá a ṣe ń múra tán láti fetí sílẹ̀ dáadáa àti láti fi irú ìmọ̀ràn bẹ́ẹ̀ sílò!—Lúùkù 8:18.
21. Ẹ̀rí wo ló fi hàn pé ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tá à ń rí gbà gbéṣẹ́, ta sì ni ọpẹ́ yẹ?
21 Ǹjẹ́ ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí Jèhófà pèsè gbéṣẹ́? Wíwulẹ̀ wo ìyọrísí rẹ̀ ti tó. Lọ́dọọdún, ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún èèyàn là ń ràn lọ́wọ́ láti mọ àwọn ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ Bíbélì, kí wọ́n sì máa gbé níbàámu pẹ̀lú ohun tí Ọlọ́run ń béèrè lọ́wọ́ wọn. Iye wa ń pọ̀ sí i, àmọ́ kò sí ẹnì kankan lára wa tó lè sọ pé ọpẹ́lọpẹ́ òun ni. A gbọ́dọ̀ gbé ògo rẹ̀ fún ẹni tó tọ́ sí, gẹ́gẹ́ bí Jésù ti ṣe. Ó sọ pé: “Kò sí ènìyàn kankan tí ó lè wá sọ́dọ̀ mi láìjẹ́ pé Baba, tí ó rán mi, fà á.” Gẹ́gẹ́ bíi ti àwọn àpọ́sítélì ìgbàanì, àwọn tí kò kàwé àti gbáàtúù ló pọ̀ jù lọ lára wa. (Jòhánù 6:44; Ìṣe 4:13) Jèhófà, tí ń fa àwọn olóòótọ́ ọkàn wá sínú òtítọ́, ló ń jẹ́ ká kẹ́sẹ járí. Bó ṣe rí gẹ́lẹ́ ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe sọ ọ́, ó ní: “Èmi gbìn, Àpólò bomi rin, ṣùgbọ́n Ọlọ́run ń mú kí ó máa dàgbà.”—1 Kọ́ríńtì 3:6.
22. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká rẹ̀wẹ̀sì jù láti nípìn-ín kíkún nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni?
22 Bẹ́ẹ̀ ni o, Jèhófà Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa lójú méjèèjì bá a ṣe ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ni ní Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Nígbà míì, a lè máa rò ó pé a ò tóótun gẹ́gẹ́ bí olùkọ́. Àmọ́ rántí o, Jèhófà ló ń fa àwọn èèyàn sọ́dọ̀ ara rẹ̀ àti Ọmọ rẹ̀. Jèhófà ló ń mú ká tóótun gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ fún àwọn ẹni tuntun wọ̀nyẹn, nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ àti ètò àjọ rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé. Ẹ jẹ́ ká máa kọbi ara sí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí Jèhófà ń fún wa, nípa lílo àwọn ohun rere tó ń pèsè fún wa báyìí láti mú wa gbára dì gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run!
Báwo Ni Wàá Ṣe Dáhùn?
• Báwo ni Bíbélì ṣe ń mú wa gbára dì fún iṣẹ́ ìwàásù?
• Ipa wo ni ẹ̀mí mímọ́ ń kó nínú mímú ká tóótun gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́?
• Àwọn ọ̀nà wo ni ètò àjọ Jèhófà orí ilẹ̀ ayé ti gbà ràn ọ́ lọ́wọ́ láti tóótun gẹ́gẹ́ bí oníwàásù ìhìn rere?
• Èé ṣe tí ọkàn wa fi ń balẹ̀ nígbà tá a bá ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, Jésù fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn