Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbatisí Clovis—Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ Ọdún Ẹ̀sìn Kátólíìkì Nílẹ̀ Faransé

Ìbatisí Clovis—Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ Ọdún Ẹ̀sìn Kátólíìkì Nílẹ̀ Faransé

Ìbatisí Clovis—Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ Ọdún Ẹ̀sìn Kátólíìkì Nílẹ̀ Faransé

“NÍ ORÚKỌ Póòpù, bú gbàù,” bí ìsọfúnni tó wà lára ayédèrú bọ́ǹbù kan tí wọ́n rí ní ṣọ́ọ̀ṣì kan tó yẹ kí Póòpù John Paul Kejì bẹ̀ wò nílẹ̀ Faransé ní September 1996 ṣe kà nìyẹn. Èyí jẹ́ àpẹẹrẹ àrà ọ̀tọ̀ nípa irú àtakò tí wọ́n gbé dìde nígbà ìbẹ̀wò rẹ̀ ẹlẹ́ẹ̀karùn-ún sí ilẹ̀ Faransé. Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn bí ọ̀kẹ́ mẹ́wàá [200,000] èèyàn ló wá sí ìlú ńlá Reims ní ilẹ̀ Faransé lọ́dún yẹn, láti wá bá Póòpù ṣayẹyẹ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ [1,500] ọdún tí Clovis Ọba àwọn ẹ̀yà Frank di ẹlẹ́sìn Kátólíìkì. Ta ni ọba yìí, tí ìbatisí rẹ̀ di èyí tí wọ́n ń pè ní ìbatisí ilẹ̀ Faransé? Èé sì ti ṣe tí ṣíṣe ayẹyẹ rẹ̀ fi ń dá họ́wùhọ́wù sílẹ̀?

Ilẹ̀ Ọba Tí Ń Dín Kù

Wọ́n bí Clovis ní nǹkan bí ọdún 466 Sànmánì Tiwa. Ọmọ Childeric Kìíní, tó jẹ́ ọba Salian ẹ̀yà Frank ni. Lẹ́yìn tí àwọn ará Róòmù tẹ̀ wọ́n lórí ba ní ọdún 358 Sànmánì Tiwa ni wọ́n gba ẹ̀yà Jámánì yìí láyè láti tẹ̀ dó síbi tá a wá mọ̀ sí Belgium lóde òní, lórí àdéhùn pé wọ́n á máa dáàbò bo ààlà ilẹ̀ náà, wọ́n á sì máa kó àwọn ọmọ ogun fún ẹgbẹ́ ọmọ ogun Róòmù. Àjọṣe tímọ́tímọ́ tí wọ́n ní pẹ̀lú àwọn Faransé àtàwọn ará Róòmù yìí ni àwọn ẹ̀yà Frank wọ̀nyí fi wá di aláwọ̀ṣe Róòmù ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀. Childeric Kìíní jẹ́ olùgbèjà àwọn ará Róòmù, ó ń bá àwọn ẹ̀yà Jámánì mìíràn jagun, ìyẹn àwọn ẹ̀yà bíi Visigoth àtàwọn Saxon. Èyí ló wá jẹ́ kó rí ojú rere àwọn Faransé àtàwọn ará Róòmù.

Ẹkùn ìpínlẹ̀ Róòmù tó ń jẹ́ Gaul nasẹ̀ láti Odò Rhine, ní ìhà àríwá, lọ sí Pyrenees, ní ìhà gúúsù. Àmọ́, lẹ́yìn ikú Aetius, Ọ̀gágun Róòmù, ní ọdún 454 Sànmánì Tiwa, ilẹ̀ náà wà láìní alákòóso fún ìgbà díẹ̀. Ìyẹn nìkan kọ́ o, ìṣubú Romulus Augustulus, olú ọba tó jẹ kẹ́yìn nílẹ̀ Róòmù, ní ọdún 476 Sànmánì Tiwa àti wíwá tí apá ìwọ̀ oòrùn Ilẹ̀ Ọba Róòmù wá sópin mú kí ọ̀ràn ìṣèlú ilẹ̀ náà di èyí tí kò fẹsẹ̀ múlẹ̀ mọ́. Àbájáde rẹ̀ ni pé, Gaul wá dà bí èso àjàrà tó ti pọ́n, tó ń retí pé kí ọ̀kan lára àwọn ẹ̀yà tó tẹ̀dó sí ààlà ilẹ̀ náà wá já òun. Kò fi bẹ́ẹ̀ yani lẹ́nu pé nígbà tí Clovis jọba lẹ́yìn bàbá rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí wá bó ṣe máa fẹ ilẹ̀ ìjọba rẹ̀. Ní ọdún 486 Sànmánì Tiwa, ó ṣẹ́gun èyí tó kẹ́yìn nínú àwọn aṣojú Róòmù ní Gaul nínú ogun kan tí wọ́n jà nítòsí ìlú ńlá Soissons. Ìṣẹ́gun yìí ló wá sọ ọ́ di olórí gbogbo ìpínlẹ̀ tó wà láàárín odò Somme, ní ìhà àríwá, àti odò Loire, ní àárín gbùngbùn àti ìwọ̀ oòrùn Gaul.

Ọkùnrin Tí Yóò Di Ọba

Láìdàbí àwọn ẹ̀yà Jámánì mìíràn, kèfèrí paraku làwọn ẹ̀yà Frank. Àmọ́, fífi tí Clovis fi ọmọ ọba Burgundy kan, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Clotilda, ṣaya nípa tó lágbára lórí ìgbésí ayé rẹ̀. Clotilda, tó jẹ́ Kátólíìkì paraku, sa gbogbo ipá rẹ̀ láti yí ọkọ rẹ̀ lọ́kàn padà. Ní ìbámu pẹ̀lú ìtàn tí Gregory ará Tours kọ sílẹ̀ ní ọ̀rúndún kẹfà Sànmánì Tiwa, ọdún 496 Sànmánì Tiwa, nígbà ogun tí Clovis bá àwọn ẹ̀yà Alemanni jà nílùú Tolbiac (Zülpich, Jámánì) ni Clovis ṣèlérí pé òun yóò fi ìsìn Kèfèrí sílẹ̀ bí Ọlọ́run Clotilda bá lè fún òun ní ìṣẹ́gun. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé díẹ̀ ló kù kí wọ́n ṣẹ́gun àwọn ọmọ ogun Clovis, síbẹ̀ wọ́n rí ọba Alemanni pa, àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ sí juwọ́ sílẹ̀. Lójú Clovis, Ọlọ́run Clotilda ló fún òun ní ìṣẹ́gun. Gẹ́gẹ́ bí ìtàn àtọwọ́dọ́wọ́ ti wí, Remigius “Mímọ́” ló batisí Clovis ní kàtídírà ti Reims, ní December 25, ọdún 496 Sànmánì Tiwa. Àmọ́, àwọn kan gbà pé ọdún 498 tàbí 499 Sànmánì Tiwa ló ní láti jẹ́.

Ìgbìdánwò Clovis láti gba ìjọba Burgundy tó wà níhà gúúsù forí ṣánpọ́n. Àmọ́ ó kẹ́sẹ járí nínú ogun tó gbé dìde sí àwọn Visigoth. Nígbà tó di ọdún 507 Sànmánì Tiwa, ó ṣẹ́gun wọn ní Vouillé, nítòsí Poitiers, ìṣẹ́gun yìí ló sọ ọ́ di ẹni tó ń ṣàkóso apá tó pọ̀ jù lọ ní gúúsù ìwọ̀ oòrùn Gaul. Nítorí ìṣẹ́gun yìí, Anastasius, tó jẹ́ olú ọba apá Ìlà Oòrùn Ilẹ̀ Ọba Róòmù, fi oyè aṣojú dá Clovis lọ́lá. Ó wá tipa bẹ́ẹ̀ wà ní ipò tó ga ju ti gbogbo ọba yòókù ní ìwọ̀ oòrùn, ìṣàkóso rẹ̀ sì jẹ́ èyí tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ lábẹ́ òfin lójú àwọn Faransé àtàwọn ará Róòmù.

Níwọ̀n bí Clovis ti di alákòóso ìpínlẹ̀ àwọn ẹ̀yà Frank tó ń gbé ní ìlà oòrùn Odò Rhine, ó fi Paris ṣe olú ìlú rẹ̀. Ní àwọn ọdún díẹ̀ ṣáájú ikú rẹ̀, ó fẹsẹ̀ ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ nípa ṣíṣe àkójọ òfin kan tó wà ní àkọsílẹ̀, èyí tó pè ní Lex Salica, àti nípa yíyan ìgbìmọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì kan ní Orléans pé kí wọ́n ṣàlàyé àjọṣe tó yẹ kó wà láàárín Ṣọ́ọ̀ṣì àti Ìjọba. Nígbà ikú rẹ̀, tó ṣeé ṣe kó jẹ́ ní November 27, ọdún 511 Sànmánì Tiwa, òun ni alákòóso ìdá mẹ́ta nínú mẹ́rin gbogbo àgbègbè tá à ń pè ní Gaul.

Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The New Encyclopædia Britannica pe ìyílọ́kànpadà Clovis sí ẹ̀sìn Kátólíìkì ní “àkókò kan tó gbàfiyèsí nínú ìtàn ìwọ̀ oòrùn Yúróòpù.” Kí nìdí tí ìyípadà ọba kèfèrí yìí fi ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀? Ìjẹ́pàtàkì ibẹ̀ ni kókó náà pé Clovis yan ẹ̀sìn Kátólíìkì dípò dídi ọmọlẹ́yìn Arius.

Àríyànjiyàn Tí Arius Dá Sílẹ̀

Ní nǹkan bí ọdún 320 Sànmánì Tiwa, Arius, àlùfáà kan ní Alẹkisáńdíríà, ilẹ̀ Íjíbítì bẹ̀rẹ̀ sí tan èrò tó yàtọ̀ pátápátá kálẹ̀ nípa Mẹ́talọ́kan. Arius sọ pé Ọmọ kò lè jẹ́ ọ̀kan náà pẹ̀lú Baba. Ọmọ kò lè jẹ́ Ọlọ́run tàbí kó bá Baba dọ́gba, nítorí pé ó ní ìbẹ̀rẹ̀. (Kólósè 1:15) Ní ti ẹ̀mí mímọ́, Arius gbà gbọ́ pé ẹnì kan ni, àmọ́ ó rẹlẹ̀ sí Baba àti Ọmọ. Ẹ̀kọ́ yìí, tí àwọn tó pọ̀ gan-an tẹ́wọ́ gbà, fa àtakò líle koko láàárín ṣọ́ọ̀ṣì. Ní ọdún 325 Sànmánì Tiwa, ní Àpérò Nicea, wọ́n rán Arius lọ sí ìgbèkùn, wọ́n sì fagi lé àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀. a

Àmọ́, àríyànjiyàn náà kò parí síbẹ̀ yẹn. Àríyànjiyàn nípa ẹ̀kọ́ ìsìn náà ń bá a lọ fún nǹkan bí ọgọ́ta ọdún, tí olú ọba kọ̀ọ̀kan tó ń jẹ sì ń fara mọ́ ẹgbẹ́ kan tàbí òmíràn. Níkẹyìn, ní ọdún 392 Sànmánì Tiwa, Olú Ọba Theodosius Kìíní sọ ẹ̀sìn Kátólíìkì ti gbogbo gbòò àti ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan rẹ̀ di ẹ̀sìn tí Ilẹ̀ Ọba Róòmù fẹ́ kí gbogbo ọmọ abẹ́ wọ́n máa ṣe. Kó tó dìgbà yẹn, Ulfilas, tó jẹ́ bíṣọ́ọ̀bù kan ní ilẹ̀ Jámánì, ti sọ àwọn Goth di ọmọ ẹ̀yìn Arius. Kò sì pẹ́ rárá tí àwọn ẹ̀yà Jámánì yòókù fi tẹ́wọ́ gba ẹ̀ya “ẹ̀sìn Kristẹni” yìí. b

Nígbà tó fi máa di àkókò Clovis, wàhálà ti bẹ́ sílẹ̀ nínú Ìjọ Kátólíìkì tó wà ní Gaul. Àwọn Visigoth tó jẹ́ ọmọlẹ́yìn Arius ti ń gbìyànjú láti tẹ ẹ̀sìn Kátólíìkì rì nípa kíkọ̀ láti jẹ́ kí wọ́n fi ẹlòmíràn rọ́pò bíṣọ́ọ̀bù tó bá kú. Àti pé, ìjà ńlá ń lọ lọ́wọ́ nínú ṣọ́ọ̀ṣì náà nítorí ìyapa tó wà láàárín póòpù méjì, àwọn àlùfáà tó wà ní ìhà kọ̀ọ̀kan sì ń pa ara wọn nílùú Róòmù. Ní àfikún sí ìdàrúdàpọ̀ yìí, àwọn òǹkọ̀wé Kátólíìkì kan ti sọ èrò wọn jáde pé ọdún 500 Sànmánì Tiwa ni ayé yóò dópin. Ìdí nìyẹn tí ìyílọ́kànpadà ajagunṣẹ́gun ọmọ ẹ̀yà Frank náà sí ẹ̀sìn Kátólíìkì fi dà bí ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó fọre, tó ń kéde “ẹgbẹ̀rúndún tuntun ti àwọn ẹni mímọ́.”

Àmọ́, àwọn nǹkan wo ni Clovis ní lọ́kàn? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò lè fọwọ́ rọ́ ọ̀ràn ẹ̀sìn sẹ́yìn, síbẹ̀ ó dájú pé ó ní ọ̀ràn ìṣèlú lọ́kàn. Dídi tí Clovis di Kátólíìkì jẹ́ kó rí ojú rere àwọn Faransé àtàwọn ará Róòmù tí ọ̀pọ̀ jù lọ wọ́n jẹ́ Kátólíìkì, ó sì tún rí ìtìlẹ́yìn ẹgbẹ́ alákòóso ṣọ́ọ̀ṣì, táwọn èèyàn bọ̀wọ̀ fún gidigidi. Èyí fún un ní àǹfààní tó lágbára lórí àwọn tí wọ́n jọ ń dupò òṣèlú. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The New Encyclopædia Britannica sọ pé, “ṣíṣẹ́gun tó ṣẹ́gun Gaul di ogun ìdáǹdè kúrò lọ́wọ́ àjàgà àwọn aládàámọ̀ ọmọlẹ́yìn Arius táwọn èèyàn kórìíra.”

Irú Èèyàn Wo Ni Clovis Jẹ́ Gan-an?

Ṣáájú ayẹyẹ ìrántí tó wáyé ní ọdún 1996 yẹn, Gérard Defois, tó jẹ́ bíṣọ́ọ̀bù àgbà ní Reims, sọ pé Clovis “ṣàpẹẹrẹ ẹnì kan tí ìyílọ́kànpadà rẹ̀ jẹ́ èyí tó ronú lé lórí dáadáa, tó sì fi hàn pé ó mọ nǹkan tí òun ń ṣe.” Àmọ́, òpìtàn ará Faransé nì, Ernest Lavisse, sọ pé: “Kò sí ọ̀nà kankan tí ìyílọ́kànpadà Clovis fi yí irú ẹni tó jẹ́ padà; ìwà pẹ̀lẹ́ àti ti ẹlẹ́mìí àlàáfíà Ìhìn Rere náà kò gún ọkàn rẹ̀ ní kẹ́ṣẹ́.” Òpìtàn mìíràn là á mọ́lẹ̀ pé: “Dípò tí ì bá fi ké pe Odin [ọlọ́run àwọn ará Jámánì], ó ké pe Kristi, àmọ́ kò yí ìwà padà rárá.” Ìwà rẹ̀ kò yàtọ̀ rárá sí ìwà Kọnsitatáìnì lẹ́yìn tó sọ pé òun ti yí padà sí ẹ̀sìn Kristẹni. Clovis bẹ̀rẹ̀ sí fìdí ìṣàkóso rẹ̀ múlẹ̀ nípa pípa gbogbo àwọn tó ń bá a du oyè lọ́kọ̀ọ̀kan. Ó pa “gbogbo àwọn ẹbí rẹ̀ run pátá láìdá ẹnikẹ́ni sí.”

Lẹ́yìn ikú Clovis, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí gbé ìtàn àròsọ kan kalẹ̀, èyí tí wọ́n fi ń pè é ní ẹni mímọ́ táwọn èèyàn bọ̀wọ̀ fún gidigidi dípò òǹrorò jagunjagun tó jẹ́. Ìtàn ti Gregory ará Tours, èyí tó kọ ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún lẹ́yìn ìyẹn, jẹ́ èyí tó fẹ́ fi dọ́gbọ́n fi hàn pé Clovis kò yàtọ̀ sí Kọnsitatáìnì, ìyẹn olú ọba Róòmù tó kọ́kọ́ tẹ́wọ́ gba “ìsìn Kristẹni.” Ó sì tún dà bíi pé Gregory ń fi Clovis wé Kristi nípa sísọ pé ẹni ọgbọ̀n ọdún ni Clovis nígbà tó ṣe batisí.—Lúùkù 3:23.

Hincmar, bíṣọ́ọ̀bù Reims, tẹ̀ lé àṣà yìí ní ọ̀rúndún kẹsàn-án. Nígbà kan tí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì ńlá ń jà fún àwọn olùfọkànsìn, ìtàn tó kọ nípa aṣáájú rẹ̀, Remigius “Mímọ́,” dà bí èyí tó mọ̀ọ́mọ̀ kọ láti fi gbé ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀ lárugẹ àti láti fi pa owó fún un. Nínú ìtàn náà, àdàbà funfun kan gbé ìgò òróró kékeré kan wá láti fòróró yan Clovis nígbà tó ṣe batisí—ó hàn gbangba pé ẹ̀mí mímọ́ tá a fi yan Jésù ló ń tọ́ka sí. (Mátíù 3:16) Hincmar wá ń tipa báyìí fi hàn pé ìsopọ̀ wà láàárín Clovis, Reims, àti ilé ọba, ó sì ṣètìlẹ́yìn fún èrò náà pé Clovis ni Olúwa tá a fòróró yàn. c

Ayẹyẹ Tó Fa Àríyànjiyàn

Charles de Gaulle, tó jẹ́ ààrẹ ilẹ̀ Faransé tẹ́lẹ̀ rí, sọ nígbà kan pé: “Lójú tèmi o, ìtàn ilẹ̀ Faransé bẹ̀rẹ̀ látọ̀dọ̀ Clovis, tí àwọn ẹ̀yà Frank yàn gẹ́gẹ́ bí ọba ilẹ̀ Faransé, ẹ̀yà yìí ló sì fi orúkọ wọn sọ ilẹ̀ Faransé.” Àmọ́, gbogbo èèyàn kọ́ ló fi irú ojú yẹn wò ó. Ayẹyẹ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ ọdún ìbatisí Clovis di àríyànjiyàn. Ní orílẹ̀-èdè tí Ṣọ́ọ̀ṣì àti Ìjọba ti yapa síra wọn láti ọdún 1905, ọ̀pọ̀ ló bẹnu àtẹ́ lu Ìjọba fún kíkópa nínú ohun tí wọ́n kà sí ayẹyẹ ìsìn. Nígbà tí ìgbìmọ̀ aṣòfin ìlú Reims kéde pé àwọn fẹ́ sanwó fún pèpéle tí wọ́n máa lò ní àkókò ìbẹ̀wò Póòpù, ẹgbẹ́ kan yí ìpinnu náà padà nílé ẹjọ́, wọ́n sọ pé kò bófin mu. Àwọn mìíràn gbà pé ńṣe ni ṣọ́ọ̀ṣì tún fẹ́ gba ọ̀pá àṣẹ láti tún bẹ̀rẹ̀ sí jẹ gàba lé ilẹ̀ Faransé lórí. Ohun tó tún jẹ́ kí ayẹyẹ náà túbọ̀ dojú rú ni bí wọ́n ṣe pe Clovis ní ọmọ ẹgbẹ́ National Front tó jẹ́ ẹgbẹ́ aláṣẹ bóofẹ́bóokọ̀ àti ọmọ ẹgbẹ́ àwọn Kátólíìkì agbawèrèmẹ́sìn.

Ohun tí ìtàn sọ tún jẹ́ kí àwọn mìíràn bẹnu àtẹ́ lu ayẹyẹ náà. Wọ́n sọ pé kì í ṣe ìbatisí Clovis ló yí ilẹ̀ Faransé padà sí ẹ̀sìn Kátólíìkì, níwọ̀n bí ìsìn yìí ti fẹsẹ̀ múlẹ̀ láàárín àwọn Faransé àtàwọn ará Róòmù ṣáájú àkókò yẹn. Wọ́n tún sọ pé kì í ṣe ìbatisí rẹ̀ ló sọ ilẹ̀ Faransé di orílẹ̀-èdè kan. Wọ́n sọ pé ìgbà tí ilẹ̀ Faransé di orílẹ̀-èdè kan ni ìgbà tí ìjọba Charlemagne pínyà ní ọdún 843 Sànmánì Tiwa, tó fi jẹ́ pé Charles Apárí ni ọba tó kọ́kọ́ jẹ nílẹ̀ Faransé, kì í ṣe Clovis.

Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ Ọdún Ẹ̀sìn Kátólíìkì

Báwo ni ẹ̀sìn Kátólíìkì ṣe wá rí nílẹ̀ Faransé lónìí, lẹ́yìn ohun tó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ ọdún tó ti jẹ́ “àkọ́bí Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì”? Ilẹ̀ Faransé ni àwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì tó ti ṣe batisí pọ̀ sí jù lọ títí di ọdún 1938. Ó ti wà nípò kẹfà báyìí, àwọn orílẹ̀-èdè bíi Philippines àti Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ti gbawájú rẹ̀. Nígbà tó sì jẹ́ pé mílíọ̀nù márùnlélógójì ni àwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì tó wà nílẹ̀ Faransé, mílíọ̀nù mẹ́fà péré ló máa ń lọ sí Máàsì déédéé. Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe láàárín àwọn Kátólíìkì ilẹ̀ Faransé lẹ́nu àìpẹ́ yìí fi hàn pé ìpín márùnlélọ́gọ́ta lára wọn ni “kò ka ẹ̀kọ́ Ṣọ́ọ̀ṣì nípa ọ̀ràn ìbálòpọ̀ sí,” àti pé Jésù kò “já mọ́ nǹkan kan rárá” lójú ìpín márùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún wọn. Irú ìtẹ̀sí tí kò bára dé bẹ́ẹ̀ ló mú kí Póòpù béèrè lọ́wọ́ àwọn ará Faransé nígbà tó ṣèbẹ̀wò síbẹ̀ lọ́dún 1980 pé: “Ẹ̀yin ará Faransé, kí ló ṣẹlẹ̀ sí ìlérí tẹ́ ẹ ṣe nígbà ìbatisí yín?”

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo Ile-Iṣọ Naa, August 15, 1985, ojú ìwé 26.

b Wo Ilé-Ìsọ́nà, May 15, 1994, ojú ìwé 8 sí 9.

c Orúkọ náà Louis wá látinú Clovis, ẹni tí wọ́n fi orúkọ rẹ̀ pe àwọn ọba ilẹ̀ Faransé mọ́kàndínlógún (títí kan Louis Kẹtàdínlógún àti Louis-Philippe).

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 27]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

ÀWỌN SAXON

Odò Rhine

Odò Somme

Soissons

Reims

Paris

GAUL

Odò Loire

Vouillé

Poitiers

PYRENEES

ÀWỌN VISIGOTH

Róòmù

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Ìbatisí Clovis, gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú ìwé àfọwọ́kọ kan ní ọ̀rúndún kẹrìnlá

[Credit Line]

© Cliché Bibliothèque nationale de France, Paris

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Ère ìbatisí Clovis (tó wà láàárín) ní ìta Ṣọ́ọ̀ṣì Ńlá to wà ní ìlú Reims, nílẹ̀ Faransé

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Ìbẹ̀wò tí John Paul Kejì ṣe sílẹ̀ Faransé láti ṣayẹyẹ ìbatisí Clovis fa àríyànjiyàn