Báwo Lo Ṣe Lè La Òpin Ayé Yìí Já?
Báwo Lo Ṣe Lè La Òpin Ayé Yìí Já?
BÍBÉLÌ pe òpin ètò nǹkan ìsinsìnyí ní “ọjọ́ ìbínú kíkan, ọjọ́ wàhálà àti làásìgbò, ọjọ́ ìjì àti ìsọdahoro, ọjọ́ òkùnkùn àti ìṣúdùdù, ọjọ́ àwọsánmà àti ìṣúdùdù tí ó nípọn.” (Sefanáyà 1:15) Ó dájú pé èyí kì í ṣe irú ọjọ́ tó máa ń ṣe èèyàn bíi pé kó dé, kó dé! Àmọ́, àpọ́sítélì Pétérù gba àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ níyànjú pé kí wọ́n máa ‘dúró de wíwàníhìn-ín ọjọ́ Jèhófà, kí wọ́n sì máa fi í sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí, nípasẹ̀ èyí tí àwọn ọ̀run tí wọ́n ti gbiná yóò di yíyọ́, tí àwọn ohun ìpìlẹ̀ tí ó ti gbóná janjan yóò sì yọ́! Ṣùgbọ́n ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun wà tí a ń dúró dè ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí rẹ̀, nínú ìwọ̀nyí ni òdodo yóò sì máa gbé.’—2 Pétérù 3:12, 13.
Ohun tí Pétérù ń sọ níhìn-ín kì í ṣe ìparun àwọn ọ̀run àti ilẹ̀ ayé gidi. “Àwọn ọ̀run” àti “ilẹ̀ ayé” tí Pétérù ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ níhìn-ín dúró fún àwọn ìjọba ènìyàn oníwà ìbàjẹ́ àti agbo àwọn èèyàn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run tí ń bẹ nísinsìnyí. “Ọjọ́ Jèhófà” kò ní pa ilẹ̀ ayé fúnra rẹ̀ run ṣùgbọ́n yóò “pa àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ilẹ̀ náà rẹ́ ráúráú kúrò lórí rẹ̀.” (Aísáyà 13:9) Nítorí náà, ọjọ́ ìgbàlà ni ọjọ́ Jèhófà yóò jẹ́ fáwọn “tí ń mí ìmí ẹ̀dùn, tí wọ́n sì ń kérora nítorí gbogbo ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí” tó ń ṣẹlẹ̀ lóde òní lágbo àwọn ẹni ibi.—Ìsíkíẹ́lì 9:4.
Báwo wá lèèyàn ṣe lè yè bọ́ ní “ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù ti Jèhófà”? “Ọ̀rọ̀ Jèhófà” tí a ṣí payá fún ọ̀kan lára àwọn wòlíì rẹ̀ dáhùn ìbéèrè náà, ó sọ pé: “Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń ké pe orúkọ Jèhófà ni yóò yè bọ́.” (Jóẹ́lì 1:1; 2:31, 32) Inú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò dùn láti jẹ́ kí o mọ ohun tí kíké pe orúkọ Jèhófà túmọ̀ sí.