Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Nìdí Tí Ayé Ìgbàanì Fi Ṣègbé?

Kí Nìdí Tí Ayé Ìgbàanì Fi Ṣègbé?

Kí Nìdí Tí Ayé Ìgbàanì Fi Ṣègbé?

ÀKÚNYA omi tó bo ayé ìgbàanì kì í ṣe àjálù tó ṣàdédé ṣẹlẹ̀. Ìdájọ́ Ọlọ́run ni. Ìkìlọ̀ dún, ṣùgbọ́n àwọn èèyàn kọ etí ikún sí ìkìlọ̀ náà. Èé ṣe? Jésù ṣàlàyé pé: “Ní ọjọ́ wọnnì ṣáájú ìkún omi, [àwọn èèyàn] ń jẹ, wọ́n sì ń mu, àwọn ọkùnrin ń gbéyàwó, a sì ń fi àwọn obìnrin fúnni nínú ìgbéyàwó, títí di ọjọ́ tí Nóà wọ ọkọ̀ áàkì; wọn kò sì fiyè sí i títí ìkún omi fi dé, tí ó sì gbá gbogbo wọn lọ.”—Mátíù 24:38, 39.

Ayé Ọ̀làjú Layé Ọ̀hún

Láwọn ọ̀nà kan, ayé tó wà ṣáájú Ìkún Omi ní àwọn àǹfààní kan tí a kò ní lónìí. Bí àpẹẹrẹ, èdè kan náà ni gbogbo èèyàn ń sọ nígbà yẹn. (Jẹ́nẹ́sísì 11:1) Èyí á mú kó rọrùn láti ṣe ọ̀pọ̀ àṣeyọrí nínú iṣẹ́ ọnà àti ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ tó ń béèrè pé kí ọ̀pọ̀ èèyàn pa òye wọn pọ̀. Pẹ̀lúpẹ̀lù, pípẹ́ tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń pẹ́ láyé nígbà yẹn á jẹ́ kó rọrùn fún wọn láti máa gba ìmọ̀ kún ìmọ̀ fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún.

Àmọ́ àwọn kan sọ pé àwọn ará ìgbà yẹn kì í pẹ́ láyé tó bí a ṣe rò. Wọ́n ní oṣù lásán ni Bíbélì ń pè lọ́dún. Ṣé òótọ́ ni? Tóò, ẹ jẹ́ ká gbé ọ̀ràn ti Máhálálélì yẹ̀ wò. Bíbélì sọ pé: “Máhálálélì sì ń bá a nìṣó láti wà láàyè fún ọdún márùn-dín-láàádọ́rin. Lẹ́yìn náà, ó bí Járédì. . . . Gbogbo ọjọ́ Máhálálélì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ọdún ó dín márùn-ún, ó sì kú.” (Jẹ́nẹ́sísì 5:15-17) Bó bá jẹ́ pé oṣù ni Bíbélì pè lọ́dún, á jẹ́ pé ọmọ ọdún márùn-ún péré ni Máhálálélì nígbà tó di bàbá ọlọ́mọ! Ọ̀ràn ò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé àwọn ará ìgbàanì ṣì ní ìlera tó dára bíi ti Ádámù, ọkùnrin àkọ́kọ́. Òótọ́ ni wọ́n lo ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún láyé. Kí ni wọ́n ṣe láṣeyọrí?

Ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ṣáájú Ìkún Omi, iye àwọn èèyàn tó wà láyé ti pọ̀ débi pé Kéènì, ọmọ Ádámù, tẹ ìlú ńlá kan dó, tó pè ní Énọ́kù. (Jẹ́nẹ́sísì 4:17) Ọ̀pọ̀ iléeṣẹ́ ló wà ní sànmánì tó ṣáájú Ìkún Omi. Àwọn èèyàn ń rọ “gbogbo onírúurú irinṣẹ́ bàbà àti irin.” (Jẹ́nẹ́sísì 4:22) Láìsí àní-àní, wọ́n ń lo irinṣẹ́ wọ̀nyí fún iṣẹ́ ìkọ́lé, iṣẹ́ gbẹ́nàgbẹ́nà, iṣẹ́ aṣọ rírán àti iṣẹ́ àgbẹ̀. Àkọsílẹ̀ tó sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹ̀dá ènìyàn tó kọ́kọ́ gbé ayé mẹ́nu kan gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ wọ̀nyí.

Ìmọ̀ tí wọ́n kó jọ á jẹ́ kí àtọmọdọ́mọ wọn mọ̀ nípa àwọn àkànṣe iṣẹ́ bí ẹ̀kọ́ nípa irin ṣíṣe, ìmọ̀ nípa ọ̀gbìn oko, iṣẹ́ ẹran sísìn, ìwé kíkọ àti iṣẹ́ ọnà. Fún àpẹẹrẹ, Júbálì ni “olùpilẹ̀ṣẹ̀ gbogbo àwọn tí ń lo háàpù àti fèrè ape.” (Jẹ́nẹ́sísì 4:21) Ayé yẹn lajú gan-an ni. Ṣùgbọ́n, gbogbo rẹ̀ dópin lójijì. Kí ló ṣẹlẹ̀?

Kí Ni Ohun Tó Wọ́?

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìran tó gbé ayé ṣáájú Ìkún Omi ní gbogbo àǹfààní wọ̀nyẹn, àtìbẹ̀rẹ̀ ni nǹkan ti wọ́ wá. Ádámù, tó pilẹ̀ ìran yẹn, jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run. Kéènì, tó tẹ ìlú ńlá àkọ́kọ́ nínú àkọsílẹ̀ dó, pa àbúrò rẹ̀. Abájọ tí ìwà ibi fi wá ń pe ìwà ibi rán níṣẹ́! Ìyọrísí ogún búburú tí Ádámù fi sílẹ̀ sẹ́yìn fún àtọmọdọ́mọ rẹ̀ lé kenkà.—Róòmù 5:12.

Nígbà tọ́ràn náà wá fẹ́ dójú ẹ̀ ni Jèhófà pinnu pé ọgọ́fà ọdún péré ló kù fún ìran náà. (Jẹ́nẹ́sísì 6:3) Bíbélì sọ pé: “Ìwà búburú ènìyàn pọ̀ yanturu ní ilẹ̀ ayé, gbogbo ìtẹ̀sí ìrònú ọkàn-àyà rẹ̀ sì jẹ́ kìkì búburú ní gbogbo ìgbà. . . . Ilẹ̀ ayé sì wá kún fún ìwà ipá.”—Jẹ́nẹ́sísì 6:5, 11.

Bí àkókò ti ń lọ, a wá sọ ọ́ ní pàtó fún Nóà pé Ọlọ́run yóò fi ìkún omi pa gbogbo ẹ̀dá ẹlẹ́ran ara run. (Jẹ́nẹ́sísì 6:13, 17) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Nóà di “oníwàásù òdodo,” síbẹ̀ ó jọ pé kò rọrùn fáwọn èèyàn láti gbà pé gbogbo ohun tó wà láyìíká wọn máa lọ ní àlọ-rámirámi. (2 Pétérù 2:5) Èèyàn mẹ́jọ péré ló gba ìkìlọ̀ náà. Àwọn nìkan ló sì rí ìgbàlà. (1 Pétérù 3:20) Kí nìdí tí èyí fi kàn wá gbọ̀ngbọ̀n lónìí?

Báwo Ló Ṣe Kàn Wá?

Ìgbà tiwa kò yàtọ̀ sí ìgbà ti Nóà. Gbogbo ìgbà là ń gbọ́ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ tí ń páni láyà, ìgbésẹ̀ láti pa odindi ẹ̀yà run, àwọn oníbọn tó kàn ń yìnbọn pa ọ̀pọ̀ èèyàn láìsí ìdí gúnmọ́ àti ìwà ipá tó lé kenkà nínú ilé. Ayé tún ti kún fún ìwà ipá bíi tayé ọjọ́un. Ìkìlọ̀ ìdájọ́ tí ń bọ̀ sì ti ń dún gbọnmọgbọnmọ kárí ayé báyìí. Jésù fúnra rẹ̀ sọ pé òun ń bọ̀ wá gẹ́gẹ́ bí Onídàájọ́ tí Ọlọ́run yàn, láti wá ya àwọn èèyàn sọ́tọ̀, bí olùṣọ́ àgùntàn ṣe ń ya àgùntàn sọ́tọ̀ kúrò lára ewúrẹ́. Jésù sọ pé àwọn aláìyẹ yóò “lọ sínú ìkékúrò àìnípẹ̀kun.” (Mátíù 25:31-33, 46) Àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, Bíbélì sọ pé àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ni yóò là á já—ìyẹn ogunlọ́gọ̀ ńlá tó ń sin Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà. Nínú ayé tí ń bọ̀, àwọn wọ̀nyí ni yóò máa gbádùn àlàáfíà àti ààbò pípẹ́títí, irú èyí tí kò sí rí.—Míkà 4:3, 4; Ìṣípayá 7:9-17.

Yẹ̀yẹ́ lọ̀pọ̀ èèyàn máa ń ṣe nígbà tí wọ́n bá gbọ́ irú gbólóhùn bẹ́ẹ̀ látinú Bíbélì àtàwọn ìkìlọ̀ nípa ìdájọ́ tí yóò fi hàn pé òótọ́ ni. Ṣùgbọ́n àpọ́sítélì Pétérù ṣàlàyé pé àìfẹ́ gbọ́ òótọ́ ọ̀rọ̀ ló ń yọ irú àwọn alárìíwísí bẹ́ẹ̀ lẹ́nu. Ó kọ̀wé pé: “Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn olùyọṣùtì yóò wá . . . wọn yóò sì máa wí pé: ‘Wíwàníhìn-ín rẹ̀ yìí tí a ti ṣèlérí dà?‘ . . . Nítorí, ní ìbámu pẹ̀lú ìdàníyàn wọn, òtítọ́ yìí bọ́ lọ́wọ́ àfiyèsí wọn, pé àwọn ọ̀run wà láti ìgbà láéláé àti ilẹ̀ ayé kan tí ó dúró digbí-digbí láti inú omi àti ní àárín omi nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run; àti nípasẹ̀ ohun wọnnì, ayé ìgbà yẹn jìyà ìparun nígbà tí a fi àkúnya omi bò ó mọ́lẹ̀. Ṣùgbọ́n nípa ọ̀rọ̀ kan náà, àwọn ọ̀run àti ilẹ̀ ayé tí ó wà nísinsìnyí ni a tò jọ pa mọ́ fún iná, a sì ń fi wọ́n pa mọ́ de ọjọ́ ìdájọ́ àti ti ìparun àwọn ènìyàn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run.”—2 Pétérù 3:3-7.

Ìkìlọ̀ kárí ayé nípa ọjọ́ ìdájọ́ tí ń bọ̀ yìí àti ìhìn rere nípa àlàáfíà tí yóò tẹ̀ lé e ni à ń kéde tìtara-tìtara lónìí níbàámu pẹ̀lú àṣẹ tí Jésù pa nínú àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀. (Mátíù 24:14) Ìkìlọ̀ yìí kì í ṣe ọ̀ràn eré rárá. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Olódùmarè kò ní ṣaláì ṣẹ.

Ayé Tí Ń Bọ̀

Kí ni ọjọ́ ọ̀la aráyé lójú ìyípadà ńláǹlà tí ń bọ̀ yìí? Nígbà tí Jésù bẹ̀rẹ̀ Ìwàásù rẹ̀ olókìkí lórí Òkè, ó ṣèlérí pé: “Aláyọ̀ ni àwọn onínú tútù, níwọ̀n bí wọn yóò ti jogún ilẹ̀ ayé.” Ó wá kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ kí wọ́n máa gbàdúrà sí Ọlọ́run pé: “Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.” (Mátíù 5:5; 6:10) Dájúdájú, Jésù alára fi kọ́ni pé ọjọ́ ọ̀la àgbàyanu ń bọ̀ fún àwọn olóòótọ́, níhìn-ín lórí ilẹ̀ ayé. Ó pe èyí ní “àtúndá.”—Mátíù 19:28.

Nítorí náà, bó o ṣe ń ronú nípa ọjọ́ ọ̀la, má ṣe jẹ́ kí àwọn olùyọṣùtì mú ọ ṣiyèméjì nípa ìkìlọ̀ Ọlọ́run. Lóòótọ́, ó lè dà bíi pé kò sí nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ àti pé ayé yìí ti wà tipẹ́. Síbẹ̀, ayé yìí ò láyọ̀lé o. A ti dá a lẹ́jọ́. Fún ìdí yìí, jẹ́ kí ọ̀rọ̀ àsọparí inú lẹ́tà àpọ́sítélì Pétérù mú ọ lọ́kàn le. Ó kà pé:

“Níwọ̀n bí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò ti di yíyọ́ báyìí, irú ènìyàn wo ni ó yẹ kí ẹ jẹ́ nínú ìṣe ìwà mímọ́ àti àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run, ní dídúró de wíwàníhìn-ín ọjọ́ Jèhófà àti fífi í sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí . . . Níwọ̀n bí ẹ ti ń dúró de nǹkan wọ̀nyí, ẹ sa gbogbo ipá yín kí òun lè bá yín nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín ní àìléèérí àti ní àìlábààwọ́n àti ní àlàáfíà. . . . Ẹ máa bá a lọ ní dídàgbà nínú inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti ìmọ̀ nípa Olúwa àti Olùgbàlà wa Jésù Kristi.” (2 Pétérù 3:11, 12, 14, 18) Nítorí náà, fi ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà ayé Nóà ṣe àríkọ́gbọ́n. Sún mọ́ Ọlọ́run. Túbọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jésù Kristi. Máa fọkàn sin Ọlọ́run, kí o sì wà lára àràádọ́ta ọ̀kẹ́ tó yàn láti la òpin ayé yìí já, bọ́ sínú ayé alálàáfíà tí ń bọ̀.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Àwọn èèyàn ti ń fi irin rọ nǹkan ṣáájú Ìkún Omi

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Ọjọ́ ọ̀la tó gbámúṣé ń bẹ níwájú