Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Wò Ó, Ó Lè Dùn Ẹ́ O”

“Wò Ó, Ó Lè Dùn Ẹ́ O”

“Wò Ó, Ó Lè Dùn Ẹ́ O”

ǸJẸ́ o ti gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn rí? Bóyá o ti gbọ́ ọ rí lẹ́nu dókítà tàbí nọ́ọ̀sì, bó ṣe fẹ́ lo nǹkan kan fún ẹ.

Bóyá lo máa tìtorí pé á dùn ẹ́ kó o wá sọ pé o ò fẹ́ ìtọ́jú náà mọ́. Dípò tí wàá fi sọ bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wàá mú un mọ́ra nítorí ìlera rẹ ẹ̀yìnwá ọ̀la. Nínú àwọn ọ̀ràn tó le gan-an, gbígba ìtọ́jú kan tó mú ìrora lọ́wọ́ tàbí kíkọ irú ìtọ́jú bẹ́ẹ̀ lè pinnu bóyá wàá yè é tàbí wàá kú.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe ìgbà gbogbo là ń lọ gba ìtọ́jú lọ́dọ̀ oníṣègùn, gbogbo àwa ẹ̀dá aláìpé la nílò ìbáwí, tàbí ìtọ́sọ́nà, kódà ìbáwí tó ń dunni wọra láwọn ìgbà mìíràn pàápàá. (Jeremáyà 10:23) Nígbà tí Bíbélì ń ṣàlàyé bí àwọn ọmọdé ṣe nílò ìbáwí tó, ó sọ pé: “Ọkàn-àyà ọmọdékùnrin ni ìwà òmùgọ̀ dì sí; ọ̀pá ìbáwí ni yóò mú un jìnnà réré sí i.”—Òwe 22:15.

Ọ̀pá tí à ń sọ yìí ni ọ̀pá àṣẹ tá a gbé lé àwọn òbí lọ́wọ́. Òótọ́ ni pé ṣàṣà lọmọ tó fẹ́ ká bá òun wí. Bó bá tún lọ jẹ́ èyí tó mú ìfìyàjẹni lọ́wọ́, wọ́n lè kọ̀ ọ́. Àmọ́, àwọn òbí tó gbọ́n, tó sì nífẹ̀ẹ́ kì í ro kìkì bó ṣe máa dun ọmọ náà sí. Kàkà bẹ́ẹ̀ oore tí ìbáwí ọ̀hún máa ṣe fún ọmọ náà lẹ́yìnwá ọ̀la ni wọ́n máa ń rò. Àwọn Kristẹni òbí mọ̀ pé òótọ́ ni ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wí, nígbà tó sọ pé: “Kò sí ìbáwí tí ó dà bí ohun ìdùnnú nísinsìnyí, bí kò ṣe akó-ẹ̀dùn-ọkàn-báni; síbẹ̀ nígbà tí ó bá yá, fún àwọn tí a ti kọ́ nípasẹ̀ rẹ̀, a máa so èso ẹlẹ́mìí àlàáfíà, èyíinì ni, òdodo.”—Hébérù 12:11; Òwe 13:24.

Àmọ́, àwọn ọmọdé nìkan kọ́ ló nílò ìbáwí o. Àwọn àgbà pàápàá nílò ìbáwí. Àwọn àgbà ni Bíbélì ń bá sọ̀rọ̀ nígbà tó sọ pé: “Di ìbáwí mú; má ṣe jẹ́ kí ó lọ. Fi ìṣọ́ ṣọ́ ọ, nítorí òun ni ìwàláàyè rẹ.” (Òwe 4:13) Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn tó bá gbọ́n, ì báà jẹ́ ọmọdé tàbí àgbà, yóò gba ìbáwí tá a gbé ka Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Nítorí pé ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò dá ẹ̀mí wọn sí nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín.