Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo—Látorí Jíjẹ́ Aládàámọ̀ Dórí Jíjẹ́ Pùròtẹ́sítáǹtì

Àwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo—Látorí Jíjẹ́ Aládàámọ̀ Dórí Jíjẹ́ Pùròtẹ́sítáǹtì

Àwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo—Látorí Jíjẹ́ Aládàámọ̀ Dórí Jíjẹ́ Pùròtẹ́sítáǹtì

Ọdún 1545 ni, ní àgbègbè Lubéron rírẹwà ti Provence ní gúúsù ilẹ̀ Faransé. Ẹgbẹ́ ọmọ ogun kan kóra jọ láti ṣe iṣẹ́ ibi kan nítorí ẹ̀tanú nípa ọ̀ràn ẹ̀sìn. Odindi ọ̀sẹ̀ kan ni wọ́n fi tàjẹ̀ sílẹ̀.

WỌ́N pa àwọn abúlé rẹ́ ráúráú, wọ́n sì kó àwọn olùgbé ibẹ̀ sẹ́wọ̀n, wọ́n sì pa àwọn míì lára wọn. Ìwà ìkà bíburú jáì làwọn sójà tó jẹ́ òkú òǹrorò yìí hù nígbà ìpakúpa tó mú káwọn ará Yúróòpù gbọ̀n rìrì. Nǹkan bí ẹgbẹ̀rìnlá ó dín ọgọ́rùn-ún [2,700] ọkùnrin ni wọ́n pá, wọ́n sì rán ẹgbẹ̀ta [600] lọ ṣiṣẹ́ nínú ọkọ̀ òkun tí wọ́n fi ń jagun, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ máa sọ ti ìyà tí wọ́n fi jẹ àwọn obìnrin àtàwọn ọmọdé. Ọba ilẹ̀ Faransé àti Póòpù gbóṣùbà fún ọ̀gágun tó ṣe iṣẹ́ ibi yìí.

Ẹgbẹ́ Ìsìn Alátùn-únṣe ti pín ilẹ̀ Jámánì yẹ́lẹyẹ̀lẹ nígbà tí Ọba Francis Kìíní ti ilẹ̀ Faransé tó jẹ́ ẹlẹ́sìn Kátólíìkì wà lórí oyè. Àníyàn tí ọba yìí ń ṣe nípa bí ẹ̀sìn Pùròtẹ́sítáǹtì ṣe tàn kálẹ̀ ló mú kó ṣèwádìí nípa àwọn tí wọ́n pè ní aládàámọ̀ nínú ìjọba rẹ̀. Dípò tí wọn ì bá fi rí àwọn èèyàn kọ̀ọ̀kan tó jẹ́ aládàámọ̀, àwọn aláṣẹ ní Provence ṣàwárí àwọn abúlé tí gbogbo àwọn olùgbé ibẹ̀ jẹ́ ara ìyapa ẹ̀sìn yìí. Bí ìjọba ṣe fọwọ́ sí àṣẹ tó sọ pé kí wọ́n pa àwọn aládàámọ̀ náà run nìyẹn, wọ́n sì mú un ṣẹ nígbà ìpakúpa tó wáyé lọ́dún 1545.

Àwọn wo ni aládàámọ̀ wọ̀nyí? Kí sì nìdí táwọn tó ní ẹ̀tanú lórí ọ̀ràn ẹ̀sìn fi ń gbógun tì wọ́n?

Wọ́n Ti Orí Jíjẹ́ Ọlọ́rọ̀ Di Ẹdun Arinlẹ̀

Àwọn tí wọ́n pa nínú ìpakúpa náà jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ ẹ̀ya ẹ̀sìn kan tó ti wà láti ọ̀rúndún kejìlá, tó sì wà lágbègbè tó pọ̀ gan-an ní Yúróòpù. Ọ̀nà tí ẹ̀sìn náà gbà tàn kálẹ̀ tó sì wà fún ọ̀rúndún bíi mélòó kan ló fi jẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ nínú àkọsílẹ̀ ìtàn ìsìn. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn òpìtàn ló gbà pé ẹ̀sìn yìí ti bẹ̀rẹ̀ láti nǹkan bí ọdún 1170. Ìlú Lyons nílẹ̀ Faransé ni oníṣòwò kan tó lówó rẹpẹtẹ, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Vaudès, ti fi tọkàntọkàn fẹ́ láti kọ́ bí òun ṣe lè ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Ó hàn gbangba pé ọ̀rọ̀ ìṣílétí tí Jésù Kristi sọ fún ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan pé kí ó lọ ta ohun ìní rẹ̀ kí ó sì kó o fún àwọn tálákà, ló mú kí Vaudès ṣètò ọ̀ràn àtijẹ àtimu ìdílé rẹ̀, tó fi ọrọ̀ rẹ̀ sílẹ̀ tó sì bẹ̀rẹ̀ sí wàásù Ìhìn Rere. (Mátíù 19:16-22) Kò pẹ́ tó fi ní àwọn ọmọ ẹ̀yìn tá a wá mọ̀ sí Àwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo níkẹyìn. a

Ipò òṣì, iṣẹ́ ìwàásù, àti Bíbélì ni olórí ohun tó gba Vaudès lọ́kàn. Sísọ̀rọ̀ lòdì sí ìkọ́rọ̀jọ kì í ṣe ohun tuntun sí wọn. Ìgbà kan wà táwọn àlùfáà alátakò bíi mélòó kan bẹnu àtẹ́ lu ìwà ìbàjẹ́ tó ń lọ nínú ṣọ́ọ̀ṣì àti báwọn kan ṣe ń ṣi ọlá àṣẹ wọn lò. Àmọ́ ọ̀gbẹ̀rì ni Vaudès, bẹ́ẹ̀ náà sì ni èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. Ó dájú pé ìdí nìyẹn tó fi gbà pé ó pọn dandan kí Bíbélì wà ní èdè ìbílẹ̀, ìyẹn èdè tí gbogbo èèyàn ń sọ. Nítorí pé àwọn àlùfáà nìkan ni Bíbélì èdè Látìn tí ṣọ́ọ̀ṣì ní wà fún, Vaudès ṣètò pé kí wọ́n túmọ̀ àwọn ìwé Ìhìn Rere àtàwọn ìwé mìíràn nínú Bíbélì sí èdè tí tẹrú tọmọ ń sọ ní ìhà ìlà oòrùn àárín gbùngbùn ilẹ̀ Faransé. b Àwọn Òtòṣì Ìlú Lyons bẹ̀rẹ̀ sí wàásù ní gbangba, gẹ́gẹ́ bí Jésù ti pa á láṣẹ. (Mátíù 28:19, 20) Òpìtàn nì, Gabriel Audisio, ṣàlàyé pé àìdáwọ́ ìwàásù tí wọ́n ń ṣe ní gbangba dúró ló fa ìwà tí ṣọ́ọ̀ṣì wá ń hù sí àwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo.

Látinú Ẹ̀sìn Kátólíìkì Dórí Jíjẹ́ Aládàámọ̀

Láyé ọjọ́un, àwọn àlùfáà nìkan ló lè wàásù, ṣọ́ọ̀ṣì ló sì lè fúnni láṣẹ láti wàásù. Àwọn àlùfáà ka àwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo sí aláìmọ̀kan àti ọ̀gbẹ̀rì. Àmọ́ nígbà tó di ọdún 1179, Vaudès lọ bá Póòpù Alexander Kẹta láti gba àṣẹ fún iṣẹ́ ìwàásù tó ń ṣe. Ó fún un ní àṣẹ náà—àmọ́ àfi táwọn àlùfáà àdúgbò bá fọwọ́ sí i ló tó lè ṣeé ṣe. Òpìtàn Malcolm Lambert sọ pé èyí “kò fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ sí pé wọ́n kọ̀ jálẹ̀.” Àní bíṣọ́ọ̀bù àgbà nì, Jean Bellesmains, ti ìlú Lyons kò gba àwọn ọ̀gbẹ̀rì láyè láti wàásù rárá. Ohun tó wà nínú Ìṣe 5:29 ni Vaudès fi fèsì, èyí tó sọ pé: “Àwa gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.” Nítorí pé Vaudès kò fara mọ́ òfin tí wọ́n fi de ìwàásù yìí, wọ́n yọ ọ́ lẹ́gbẹ́ nínú ṣọ́ọ̀ṣì náà lọ́dún 1184.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n lé àwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo kúrò ní ṣọ́ọ̀ṣì Lyons, tí wọ́n sì tún lé wọn jáde nílùú, ó dà bíi pé ìdálẹ́bi àkọ́kọ́ yẹn kò fi bẹ́ẹ̀ lẹ́sẹ̀ nílẹ̀. Ọ̀pọ̀ mẹ̀kúnnù ló ń gbóṣùbà fún òótọ́ inú àti ọ̀nà ìgbésí ayé àwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo, kódà àwọn bíṣọ́ọ̀bù ṣì ń bá wọn sọ̀rọ̀.

Gẹ́gẹ́ bí ohun tí òpìtàn Euan Cameron sọ, kò dà bíi pé ńṣe ni àwọn oníwàásù Ọmọlẹ́yìn Waldo “dìídì fẹ́ gbéjà ko Ṣọ́ọ̀ṣì Róòmù.” Wọ́n wulẹ̀ “fẹ́ wàásù kí wọ́n sì kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ ni.” Àwọn òpìtàn sọ pé onírúurú àwọn àṣẹ tó ń dìde, tó wá dín agbára àti ìtẹ̀síwájú ẹ̀ya ẹ̀sìn yìí kù ni wọ́n fi sọ wọ́n di aládàámọ̀. Àbájáde ẹ̀bi tí Ṣọ́ọ̀ṣì dá wọn ni yíyọ tí Àpérò Lateran Kẹrin fọwọ́ sí i pé kí wọ́n yọ àwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo lẹ́gbẹ́ ní ọdún 1215. Ipa wo lèyí ní lórí iṣẹ́ ìwàásù wọn?

Wọ́n Ń Ṣe É Lábẹ́lẹ̀

Vaudès kú ní ọdún 1217. Inúnibíni sì fọ́n àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ká lọ sí àwọn Àfonífojì Olókè Faransé, Jámánì, àríwá Ítálì, àti Àárín Gbùngbùn àti Ìlà Oòrùn Yúróòpù. Inúnibíni tún jẹ́ káwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo tẹ̀ dó sí àwọn abúlé, èyí sì wá dí iṣẹ́ ìwàásù wọn kù ní ọ̀pọ̀ ọ̀nà.

Ọdún 1229 ni Ìjọ Kátólíìkì parí Ogun Ìsìn tí wọ́n ń bá àwọn Cathari tàbí àwọn Albigen jà ní ìhà gúúsù ilẹ̀ Faransé. c Àwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo ni wọ́n wá gbé irú àtakò líle koko bẹ́ẹ̀ dìde sí lẹ́yìn ìyẹn. Kò ní pẹ́ tí ìwádìí láti gbógun ti àdámọ̀ yóò di èyí tí wọ́n dojú rẹ̀ kọ gbogbo àwọn ọ̀tá ṣọ́ọ̀ṣì. Ìbẹ̀rù wá mú káwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo máa báṣẹ́ wọn lọ lábẹ́lẹ̀. Nígbà tó fi máa di ọdún 1230, wọn ò wàásù ní gbangba mọ́. Audisio ṣàlàyé pé: “Dípò tí wọn ì bá fi máa wá àwọn àgùntàn tuntun . . . , wọ́n ń fi gbogbo ara bójú tó àwọn tí wọ́n ti yí lọ́kàn padà tẹ́lẹ̀, wọ́n ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti dúró nínú ìgbàgbọ́, láìka iná táwọn èèyàn ń fín mọ́ wọn àti inúnibíni sí.” Ó fi kún un pé “ìwàásù ṣì ṣe pàtàkì síbẹ̀, àmọ́ ọ̀nà tí wọ́n gbà ń ṣe é ti yí padà pátápátá.”

Ìgbàgbọ́ Wọn àti Ìṣe Wọn

Dípò tí wọn ì bá fi jẹ́ kí tọkùnrin tobìnrin máa kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù, nígbà tó fi máa di ọ̀rúndún kẹrìnlá, àwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo ti fìyàtọ̀ sáàárín àwọn oníwàásù àtàwọn onígbàgbọ́. Kìkì àwọn ọkùnrin tí wọ́n dá lẹ́kọ̀ọ́ dáadáa ló lè kópa nínú iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn. Àwọn òjíṣẹ́ arìnrìn-àjò wọ̀nyí ni wọ́n wá ń pè ní barba (ẹ̀gbọ́n) nígbà tó yá.

Ohun tó wà ní góńgó ẹ̀mí àwọn barba tó ń bẹ ìdílé àwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo wò ni bí ẹ̀sìn yẹn ò ṣe ní pa rẹ́, kì í ṣe láti tàn án kálẹ̀. Gbogbo àwọn barba ló mọ̀wé kà tí wọ́n sì mọ̀wé kọ, orí Bíbélì sì ni ìdánilẹ́kọ̀ọ́, tí wọ́n ń fi odindi ọdún mẹ́fà gbà, dá lé. Lílo Bíbélì èdè ìbílẹ̀ ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣàlàyé rẹ̀ fún agbo wọn. Kódà, àwọn tó jẹ́ alátakò wọn pàápàá gbà pé àwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo, títí kan àwọn ọmọ wọn, ń tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì tímọ́tímọ́, wọ́n sì lè tọ́ka síbi tó pọ̀ nínú Ìwé Mímọ́.

Díẹ̀ lára ohun táwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo kò fara mọ́ ni irọ́ pípa, ìgbàgbọ́ pọ́gátórì, Máàsì fún àwọn òkú, agbára póòpù láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ jini, àti jíjọ́sìn Màríà àti “àwọn ẹni mímọ́.” Wọ́n tún máa ń ṣayẹyẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Lambert wí, ọ̀nà tí wọ́n gbà ń jọ́sìn “kò yàtọ̀ sí ìsìn àwọn ọ̀gbẹ̀rì lásán.”

“Gbígbé Ìgbésí Ayé Méjì”

Àwùjọ àwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo kì í yara wọn lẹ́sẹ̀ kan. Inú ìsìn yẹn ni wọ́n ti máa ń ní ọkọ tàbí aya, èyí sì jẹ́ kí wọ́n ní àwọn orúkọ ẹbí tó jẹ mọ́ ẹ̀sìn àwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo láti àwọn ọ̀rúndún wọ̀nyí wá. Àmọ́ níbi táwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo ti ń tiraka láti máa wà nìṣó, wọ́n gbìyànjú láti fi èrò ọkàn wọn pa mọ́. Bí wọn ò ṣe jẹ́ káwọn èèyàn rí àṣírí ohun tó jẹ́ ìgbàgbọ́ àti ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn wọn ló mú kó rọrùn fáwọn ọ̀tá wọn láti fẹ̀sùn èké kàn wọ́n. Fún àpẹẹrẹ, wọ́n sọ pé wọ́n ń lọ́wọ́ nínú ìjọsìn Èṣù. d

Ọ̀nà kan táwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo gbà yẹra fún irú ẹ̀sùn èké bẹ́ẹ̀ ni pé wọ́n ń sẹ́ ìgbàgbọ́ wọn, wọ́n sì ń ṣe ohun tí òpìtàn Cameron pè ní “ìdọ́gbọ́n fara mọ́” ẹ̀sìn Kátólíìkì. Ọ̀pọ̀ àwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo ló lọ ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ fún àlùfáà ìjọ Kátólíìkì, tí wọ́n ń lọ sí Máàsì, tí wọ́n ń lo omi mímọ́, kódà wọ́n ń rin ìrìn àjò lọ síbi mímọ́ pàápàá. Lambert sọ pé: “Ọ̀pọ̀ nǹkan ni wọ́n ń ṣe tí kò yàtọ̀ sí àwọn ohun tí aládùúgbò wọn tó jẹ́ Kátólíìkì ń ṣe.” Audisio là á mọ́lẹ̀ pé bí àkókò ti ń lọ, àwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo bẹ̀rẹ̀ sí “gbé ìgbésí ayé méjì.” Ó fi kún un pé: “Ní ọwọ́ kan, wọ́n ń ṣe Kátólíìkì lóde, kí wọ́n má bàa kóra wọn sí yọ́ọ́yọ́ọ́; ní ọwọ́ kejì, wọ́n ní àwọn ààtò àti àṣà bíi mélòó kan láàárín ara wọn tí kò ní jẹ́ kí ẹ̀sìn wọn kásẹ̀ nílẹ̀.”

Látorí Jíjẹ́ Aládàámọ̀ Dórí Jíjẹ́ Pùròtẹ́sítáǹtì

Ní ọ̀rúndún kẹrìndínlógún, Ẹgbẹ́ Ìsìn Alátùn-únṣe yí ìsìn ilẹ̀ Yúróòpù padà pátápátá. Àwọn táwọn ẹlẹ́tanú ẹ̀sìn ń fìyà jẹ láǹfààní láti kọ ìyà lábẹ́ òfin lórílẹ̀-èdè tiwọn tàbí kí wọ́n ṣí lọ síbòmíràn tẹ́nikẹ́ni ò ti ní fìyà jẹ wọ́n. Ọ̀ràn nípa àdámọ̀ kò wá fi bẹ́ẹ̀ le bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́, níwọ̀n bí ọ̀pọ̀ èèyàn ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣe lámèyítọ́ ìlànà ẹ̀sìn tó ti fìdí múlẹ̀.

Àtọdún 1523 ni Martin Luther, Alátùn-únṣe tí gbogbo èèyàn mọ̀ bí ẹní mowó nì, ti mẹ́nu kan àwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo. Ní 1526, ọ̀kan lára àwọn barba tí í ṣe Ọmọlẹ́yìn Waldo mú ìròyìn bí ọ̀ràn ìsìn ṣe ń lọ ní Yúróòpù wá sí Alps. Sáà kan tí àwùjọ àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì fi ń bá àwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo fèrò wérò ló tẹ̀ lé èyí. Àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì gba àwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo níyànjú láti ṣagbátẹrù ìtumọ̀ Bíbélì àkọ́kọ́ pàá láti àwọn èdè ìjímìjí sí èdè Faransé. Wọ́n tẹ̀ ẹ́ jáde ní ọdún 1535. Orúkọ tí wọ́n sì wá ń pè é lẹ́yìn náà ni Bíbélì Olivétan. Àmọ́, ó mà ṣe o, èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo ni kò gbọ́ èdè Faransé.

Bí inúnibíni tí Ìjọ Kátólíìkì ń gbé dìde ṣe ń bá a lọ, àwọn tó pọ̀ gan-an lára àwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo wá fìdí kalẹ̀ sí àgbègbè Provence tí ọkàn wọn á ti balẹ̀ ní ìhà gúúsù ilẹ̀ Faransé, ibẹ̀ náà ni àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì kan ṣí wá. Kò pẹ́ táwọn aláṣẹ fi gbọ́ nípa ìṣíwọ̀lú yìí. Láìfi ọ̀pọ̀ ìròyìn rere táwọn èèyàn ń sọ nípa ọ̀nà ìgbésí ayé àti ìwà rere àwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo pè, àwọn èèyàn kan ṣì ń kọminú nípa ìdúróṣinṣin wọn, wọ́n sì ń fẹ̀sùn kàn wọ́n pé ọ̀tá àlàáfíà ni wọ́n jẹ́. Wọ́n wá gbé àṣẹ kan tí wọ́n pè ní Mérindol edict kalẹ̀, èyí tó yọrí sí ìtàjẹ̀sílẹ̀ rẹpẹtẹ tá a mẹ́nu kàn níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.

Bí àjọṣe àárín àwọn Kátólíìkì àtàwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo ṣe ń bà jẹ́ lọ nìyẹn. Àwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo tiẹ̀ yọwọ́ ìjà ní ti gidi láti gbèjà ara wọn nítorí ogun tí wọ́n gbé dìde sí wọn. Ìforígbárí yìí ló wá sọ wọ́n di Pùròtẹ́sítáǹtì. Àwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo wá tipa bẹ́ẹ̀ lẹ̀dí àpò pọ̀ mọ́ àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì tó wọ́pọ̀ jù lọ.

Láti àwọn ọ̀rúndún wọ̀nyí wá ni ṣọ́ọ̀ṣì àwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo ti fìdí múlẹ̀ láwọn orílẹ̀-èdè tó jìnnà gan-an sí ilẹ̀ Faransé bí Uruguay àti Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Àmọ́ ṣá o, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn òpìtàn ló fara mọ́ ọ̀rọ̀ tí Audisio sọ, pé “ẹ̀sìn àwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo wá sópin ní àkókò Ẹgbẹ́ Ìsìn Alátùn-únṣe,” nígbà tí ẹ̀sìn Pùròtẹ́sítáǹtì “gbé e mi.” Ká sọ tòótọ́, ọ̀rúndún bíi mélòó kan ṣáájú àkókò yẹn làwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo ti pàdánù ìtara tí wọ́n ní níbẹ̀rẹ̀. Ìyẹn ṣẹlẹ̀ nígbà táwọn ẹlẹ́sìn yẹn fi ìbẹ̀rù pa iṣẹ́ wíwàásù àti kíkọ́ni tí Bíbélì lànà rẹ̀ tì.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Vaudès kan náà yìí ni wọ́n tún ń pè ní Valdès, Valdesius, tàbí Waldo. Inú orúkọ tó kẹ́yìn yẹn ni orúkọ náà “Àwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo” ti wá. Àwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo yìí la tún mọ̀ sí àwọn Òtòṣì ìlú Lyons.

b Àtọdún 1199 ni bíṣọ́ọ̀bù ìlú Metz, ní ìhà àríwá ìlà oòrùn ilẹ̀ Faransé, ti rojọ́ fún Póòpù Innocent Kẹta pé àwọn èèyàn ń ka Bíbélì, wọ́n sì ń jíròrò rẹ̀ ní èdè ìbílẹ̀ wọn. Ó dájú pé àwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo ni bíṣọ́ọ̀bù ọ̀hún ń tọ́ka sí.

c Wo “Àwọn Cathar—Kristian Ajẹ́rìíkú Ha Ni Wọ́n Bí?” nínú Ilé-Ìṣọ́nà, September 1, 1995, ojú ìwé 27 sí 30.

d Bí wọ́n ṣe ń ba àwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo lórúkọ jẹ́ ní gbogbo ìgbà làwọn èèyàn fi ń pè wọ́n ní vauderie (tí wọ́n mú jáde látinú ọ̀rọ̀ Faransé náà, vaudois). Orúkọ yìí ni wọ́n fi ń pe ẹni tí wọ́n bá fura sí pé ó jẹ́ aládàámọ̀ tàbí olùjọsìn Èṣù.

[Àwòrán ilẹ̀/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

Àwọn Àgbègbè tí Àwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo nípa lé lórí

ILẸ̀ FARANSÉ

Lyons

PROVENCE

Lubéron

Strasbourg

Milan

Róòmù

Berlin

Prague

Vienna

[Àwòrán]

Àwọn Ọmọlẹ́yìn Waldo ló ṣagbátẹrù ìtumọ̀ Bíbélì Olivétan lọ́dún 1535

[Credit Line]

Bíbélì: © Cliché Bibliothèque nationale de France, Paris

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20, 21]

VAUDÈS

Wọ́n finá sun àwọn àgbàlagbà obìnrin méjì tí wọ́n jẹ́ Ọmọlẹ́yìn Waldo

[Credit Line]

Ojú ìwé 20 àti 21: © Landesbildstelle Baden, Karlsruhe