Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìṣòro Kárí Ayé Lọ̀ràn Àìsí—Aṣáájú Rere

Ìṣòro Kárí Ayé Lọ̀ràn Àìsí—Aṣáájú Rere

Ìṣòro Kárí Ayé Lọ̀ràn Àìsí—Aṣáájú Rere

Ọkùnrin kan wà, òǹkọ̀wé ni, akéwì sì ni. Ìgbàgbọ́ rẹ̀ ni pé ọjọ́ ọ̀la ń bọ̀ wá dáa. Ní nǹkan bí àádọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn, ó fọkàn yàwòrán “ibì kan tí ọkàn ti balẹ̀ pẹ̀sẹ̀, tí ayé ti san àwọn èèyàn; níbi tí ìmọ̀ wà lọ́fẹ̀ẹ́ lófò; níbi tí ààlà orílẹ̀-èdè kò ti pín ayé sí yẹ́lẹyẹ̀lẹ; níbi táwọn èèyàn ti ń sòótọ́; níbi tí àwọn akitiyan wa yóò ti mú wa sún mọ́ ìjẹ́pípé nínú iṣẹ́ ọwọ́ wa.”

ÒǸKỌ̀WÉ yìí wá sọ pé ìrètí òun ni pé níjọ́ ọjọ́ kan, orílẹ̀-èdè òun àti gbogbo ayé pátá yóò bá ara wọn nínú irú ayé bẹ́ẹ̀. Ká ní akéwì tó gba Ẹ̀bùn Nobel yìí ṣì wà láyé ni, ì bá rí i pé ibi tóun fojú sí, ọ̀nà ò gbabẹ̀ rárá. Nítorí pé ayé ti fọ́ kélekèle ju ti ìgbàkigbà rí lọ, láìka gbogbo ìtẹ̀síwájú àtàwọn àrà tuntun táráyé ń dá sí. Ọjọ́ ọ̀la aráyé lápapọ̀ ṣì pòkúdu.

Nígbà tí wọ́n béèrè lọ́wọ́ àgbẹ̀ kan nípa ohun tó fa wàhálà tó ṣàdédé bẹ́ sílẹ̀ láàárín àwọn èèyàn kan ní orílẹ̀-èdè rẹ̀, ó sọ ohun tó rò pé ó fà á. Ó ní: “Ẹjọ́ àwọn aṣáájú tí kò mọṣẹ́ wọn níṣẹ́ ni.” Òpìtàn nì, Jonathan Glover, sọ ohun tó jọ èyí nínú ìwé rẹ̀, Humanity—A Moral History of the Twentieth Century, pé: “Ìkórìíra ẹlẹ́yàmẹ̀yà tó fa ìpẹ̀yàrun [tó wáyé ní orílẹ̀-èdè kan náà] kò ṣàdédé bẹ̀rẹ̀ lọ́sàn-án kan òru kan, iṣẹ́ ọwọ́ àwọn tó fẹ́ jókòó pa sórí àlééfà ni.”

Nígbà tí ogun bẹ́ sílẹ̀ lápá ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1990 láàárín orílẹ̀-èdè olómìnira méjèèjì tó wà ní Yugoslavia tẹ́lẹ̀ rí, akọ̀ròyìn kan kọ̀wé pé: “Ṣebí tipẹ́tipẹ́ la ti jọ ń gbé pọ̀, láìjà láìta. Ó ti wá di pé ká máa pa àwọn ògo wẹẹrẹ ara wa báyìí. Kí ló ń ṣe wá ná?”

Ẹ jẹ́ ká kúrò ní Yúróòpù, ká tún lọ wo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní iyànníyàn Íńdíà, tí í ṣe ilẹ̀ ìbílẹ̀ akéwì tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀. Nínú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ kan tí wọ́n pe àkòrí rẹ̀ ní “Ṣé Íńdíà Kò Ní Pín sí Orílẹ̀-Èdè Ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ Báyìí?,” òǹkọ̀wé nì, Pranay Gupte, sọ pé: ‘Nǹkan bí ìdá méje nínú mẹ́wàá àwọn èèyàn Íńdíà ni kò tíì pé ẹni ọgbọ̀n ọdún, síbẹ̀ kò sí àwọn aṣáájú tó jẹ́ ẹṣin iwájú tí tẹ̀yìn lè máa wò sáré.’

Ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, ó ti di dandan kí àwọn aṣáájú kọ̀wé fi ipò wọn sílẹ̀ nítorí ẹ̀sùn ìwà ìbàjẹ́ lọ́tùn-ún lósì. Láìsí àní-àní, ọ̀pọ̀ nǹkan ló fà á tí ọ̀ràn aṣáájú fi di ìṣòro ńlá kárí ayé lónìí. Ibi tí ọ̀ràn ọ̀hún sì ti dé báyìí fi hàn pé òótọ́ lọ̀rọ̀ wòlíì kan tó gbé ayé ní nǹkan bí ẹgbẹ̀tàlá [2,600] ọdún sẹ́yìn. Ohun tó sọ ni pé: “Ọ̀nà ará ayé kì í ṣe tirẹ̀. Kì í ṣe ti ènìyàn tí ń rìn àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.”—Jeremáyà 10:23.

Ǹjẹ́ a lè rí ọ̀nà àbáyọ kúrò nínú wàhálà tí ayé kó sí yìí? Ta ló lè mú aráyé dé inú ayé tí kò ti ní sí rògbòdìyàn tàbí ìfòyà mọ́ láwùjọ ẹ̀dá, níbi tí ojúlówó ìmọ̀ yóò ti wà lọ́pọ̀ yanturu, lọ́fẹ̀ẹ́ lófò, níbi tí aráyé yóò ti túbọ̀ sún mọ́ ìjẹ́pípé?

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]

Fatmir Boshnjaku