Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Lóòótọ́ Lo Gbà Pé Kristi Ni Aṣáájú Wa?

Ṣé Lóòótọ́ Lo Gbà Pé Kristi Ni Aṣáájú Wa?

Ṣé Lóòótọ́ Lo Gbà Pé Kristi Ni Aṣáájú Wa?

“Bẹ́ẹ̀ ni kí a má pè yín ní ‘aṣáájú,’ nítorí ọ̀kan ni Aṣáájú yín, Kristi.”—MÁTÍÙ 23:10.

1. Ta ni Aṣáájú kan ṣoṣo táwọn Kristẹni tòótọ́ ní?

 TUESDAY, Nísàn 11 ni ọjọ́ náà. Ọjọ́ mẹ́ta lẹ́yìn náà ni wọ́n máa pa Jésù Kristi. Ìgbà tó máa wọ tẹ́ńpìlì gbẹ̀yìn nìyẹn. Ọjọ́ tá à ń wí yìí ni Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ àti ogunlọ́gọ̀ tó kóra jọ síbẹ̀ ní ẹ̀kọ́ pàtàkì kan. Ó sọ pé: “Kí a má ṣe pè yín ní Rábì, nítorí ọ̀kan ni olùkọ́ yín, nígbà tí ó jẹ́ pé arákùnrin ni gbogbo yín jẹ́. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹ má pe ẹnikẹ́ni ní baba yín lórí ilẹ̀ ayé, nítorí ọ̀kan ni Baba yín, Ẹni ti ọ̀run. Bẹ́ẹ̀ ni kí a má pè yín ní ‘aṣáájú,’ nítorí ọ̀kan ni Aṣáájú yín, Kristi.” (Mátíù 23:8-10) Láìsí àní-àní, Jésù Kristi ni Aṣáájú àwọn Kristẹni tòótọ́.

2, 3. Kí ni ipa tí fífetísí Jèhófà àti títẹ́wọ́gba Aṣáájú tó yàn ń ní lórí ìgbésí ayé wa?

2 Ipa tó dára mà ni jíjẹ́ tí Jésù jẹ́ Aṣáájú ní lórí ìgbésí ayé wa o, tá a bá tẹ́wọ́ gbà á! Nígbà tí Jèhófà Ọlọ́run ń sọ tẹ́lẹ̀ nípa bíbọ̀ Aṣáájú yìí, ó gbẹnu wòlíì Aísáyà polongo pé: “Kére o, gbogbo ẹ̀yin tí òùngbẹ ń gbẹ! Ẹ wá síbi omi. Àti ẹ̀yin tí kò ní owó! Ẹ wá, ẹ rà, kí ẹ sì jẹ. Bẹ́ẹ̀ ni, ẹ wá, ẹ ra wáìnì àti wàrà, àní láìsí owó àti láìsí ìdíyelé. . . . Ẹ fetí sí mi dáadáa, kí ẹ sì máa jẹ ohun tí ó dára, kí ọkàn yín sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀rá. . . . Wò ó! Mo ti fi í fún àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí, gẹ́gẹ́ bí aṣáájú àti aláṣẹ fún àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè.”—Aísáyà 55:1-4.

3 Aísáyà lo àwọn ohun tí gbogbo èèyàn mọ̀—bí omi, wàrà àti wáìnì—gẹ́gẹ́ bí àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́ láti fi hàn bí ayé wa yóò ti dùn tó bí a bá fetí sí Jèhófà, tá a sì tẹ̀ lé Aṣáájú àti Aláṣẹ tí ó fún wa. Èyí á jẹ́ kí ayé wa tòrò, kí ara tù wá pẹ̀sẹ̀. Ńṣe ló máa dà bí ìgbà tá a bá mu ife omi tútù lọ́jọ́ tí oòrùn mú gan-an. Yóò pa òùngbẹ òtítọ́ àti òùngbẹ òdodo tó ń gbẹ wá. Bí wàrà ṣe ń fún ìkókó lókun, tó sì ń jẹ́ kó tètè dàgbà, bẹ́ẹ̀ náà ni ‘wàrà tí ó jẹ́ ti ọ̀rọ̀ náà’ ń fún wa lókun, tó sì ń jẹ́ kí ìdàgbàsókè tẹ̀mí wà nínú àjọṣe àárín àwa àti Ọlọ́run. (1 Pétérù 2:1-3) Ta ni kò sì gbà pé wáìnì ń fi kún ayọ̀ àríyá? Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni sísin Ọlọ́run tòótọ́ àti títẹ̀lé ìṣísẹ̀ Aṣáájú tó yàn ṣe ń jẹ́ kí ìgbésí ayé “kún fún ìdùnnú.” (Diutarónómì 16:15) Nítorí náà, ó ṣe pàtàkì pé kí gbogbo wa—lọ́mọdé lágbà, lọ́kùnrin lóbìnrin—fi hàn pé lóòótọ́ la gbà pé Kristi ni Aṣáájú wa. Ṣùgbọ́n o, báwo la ṣe lè fi hàn nínú ìgbésí ayé wa ojoojúmọ́ pé Mèsáyà ni Aṣáájú wa?

Ẹ̀yin Ọ̀dọ́—Ẹ Máa ‘Tẹ̀ Síwájú ní Ọgbọ́n’

4. (a) Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jésù ọmọ ọdún méjìlá lọ sí Jerúsálẹ́mù nígbà Ìrékọjá? (b) Báwo ni òye Jésù ti pọ̀ tó lẹ́ni ọdún méjìlá péré?

4 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ tí Aṣáájú wa fi lélẹ̀ fáwọn ọ̀dọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ nípa ìgbà ọmọdé Jésù, síbẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ kan wà tó jẹ́ ká mọ bó ṣe lo ìgbà ọmọdé rẹ̀. Nígbà tí Jésù jẹ́ ọmọ ọdún méjìlá, àwọn òbí rẹ̀ mú un dání lọ sí Jerúsálẹ́mù gẹ́gẹ́ bí ìṣe wọn ọdọọdún, láti lọ ṣe Ìrékọjá níbẹ̀. Nígbà ìrìn àjò yìí, ìjíròrò látinú Ìwé Mímọ́ gbà á lọ́kàn pátápátá, ìdílé rẹ̀ sì já a sílẹ̀ láìmọ̀. Ọjọ́ mẹ́ta lẹ́yìn náà ni Jósẹ́fù àti Màríà, àwọn òbí rẹ̀ tí ìdààmú ti bá, tó rí i nínú tẹ́ńpìlì, “ó jókòó sáàárín àwọn olùkọ́, ó sì ń fetí sí wọn, ó sì ń bi wọ́n ní ìbéèrè.” Síwájú sí i, “gbogbo àwọn tí ń fetí sí i ni wọ́n ń ṣe kàyéfì léraléra nítorí òye rẹ̀ àti àwọn ìdáhùn rẹ̀.” Fojú inú wò ó ná, Jésù, ọmọ ọdún méjìlá péré, mọ bá a ṣe ń béèrè gbankọgbì ìbéèrè nípa àwọn nǹkan tẹ̀mí, èsì tó sì ń jáde lẹ́nu rẹ̀ fi hàn pé ọlọ́pọlọ pípé ni! Láìsí àní-àní, ẹ̀kọ́ táwọn òbí rẹ̀ kọ́ ọ wà lára ohun tó ràn án lọ́wọ́.—Lúùkù 2:41-50.

5. Báwo làwọn ọ̀dọ́ ṣe lè mọ ìṣarasíhùwà wọn sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ìdílé?

5 Bóyá ọ̀dọ́ ni ìwọ náà. Bí àwọn òbí rẹ bá jẹ́ olùfọkànsin Ọlọ́run, ó ṣeé ṣe kí ẹ ní ètò ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ìdílé tí ẹ̀ ń ṣe déédéé nínú ilé yín. Ojú wo lo fi ń wo ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé? Ǹjẹ́ kò ní dáa kó o fara balẹ̀ ronú lórí àwọn ìbéèrè bíi: ‘Ǹjẹ́ mò ń fi tọkàntọkàn gbárùkù ti ètò ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ìdílé wa? Ǹjẹ́ mo máa ń yẹra fún ṣíṣe ohun tó máa da ètò yẹn rú?’ (Fílípì 3:16) ‘Ǹjẹ́ mo máa ń lóhùn sí ọ̀rọ̀ tá a bá ń sọ nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ náà? Nígbà tó bá yẹ bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ mo máa ń béèrè ìbéèrè nípa kókó tá à ń kẹ́kọ̀ọ́ lé lórí, kí n sì ṣàlàyé nípa bí ọ̀rọ̀ náà ṣe kàn mí? Bí mo ṣe ń tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, ǹjẹ́ mò ń kúndùn “oúnjẹ líle [tó] jẹ́ ti àwọn ènìyàn tí ó dàgbà dénú”?’—Hébérù 5:13, 14.

6, 7. Báwo ni ètò Bíbélì kíkà lójoojúmọ́ ṣe wúlò tó fáwọn ọ̀dọ́?

6 Ètò Bíbélì kíkà lójoojúmọ́ tún ṣe kókó. Onísáàmù náà kọ ọ́ lórin pé: “Aláyọ̀ ni ènìyàn tí kò rìn nínú ìmọ̀ràn àwọn ẹni burúkú, . . . ṣùgbọ́n [tí] inú dídùn rẹ̀ wà nínú òfin Jèhófà, [tí] ó sì ń fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ka òfin rẹ̀ tọ̀sán-tòru.” (Sáàmù 1:1, 2) Jóṣúà, tó rọ́pò Mósè, ‘ń fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ka ìwé òfin náà lọ́sàn-án àti lóru.’ Èyí ló jẹ́ kó hùwà ọgbọ́n, tó sì ṣe àṣeyọrí rere nínú iṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn fún un. (Jóṣúà 1:8) Jésù Kristi, Aṣáájú wa sọ pé: “A kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Ènìyàn kì yóò wà láàyè nípasẹ̀ oúnjẹ nìkan ṣoṣo, bí kò ṣe nípasẹ̀ gbogbo àsọjáde tí ń jáde wá láti ẹnu Jèhófà.’” (Mátíù 4:4) Bó bá jẹ́ pé ojoojúmọ́ la nílò oúnjẹ tara, mélòómélòó la nílò oúnjẹ tẹ̀mí déédéé!

7 Nicole ọmọ ọdún mẹ́tàlá bẹ̀rẹ̀ sí ka Bíbélì lójoojúmọ́ nítorí pé nǹkan tẹ̀mí jẹ ẹ́ lọ́kàn. a Nísinsìnyí tó ti pé ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún, ó ti ka Bíbélì parí lẹ́ẹ̀kan, ó tún ti bá a dé ìdajì báyìí lẹ́ẹ̀kejì. Bó ṣe ń ṣe é rọrùn gan-an ni. Ó sọ pé: “Mo máa ń rí i dájú pé mo ka ó kéré tán orí kan lójúmọ́.” Ìrànlọ́wọ́ wo ni Bíbélì kíkà lójoojúmọ́ ti ṣe fún un? Ó dáhùn pé: “Àwọn nǹkan búburú tó lè kó èèràn ranni pọ̀ lóde òní. Ojoojúmọ́ ni mo ń ko ìṣòro tó ń dán ìgbàgbọ́ mi wò níléèwé àti láwọn ibòmíràn. Kíka Bíbélì lójoojúmọ́ máa ń jẹ́ kí n tètè rántí àwọn òfin àti ìlànà Bíbélì tó ń jẹ́ kó ṣeé ṣe fún mi láti borí àwọn ìṣòro wọ̀nyí. Èyí sì ń jẹ́ kí n túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà àti Jésù.”

8. Kí ni àṣà Jésù nígbà tó bá lọ sí sínágọ́gù, báwo sì ni àwọn ọ̀dọ́ ṣe lè fara wé e?

8 Ó jẹ́ àṣà Jésù láti máa fúnra rẹ̀ ka Ìwé Mímọ́ àti láti máa fetí sí i nígbà táwọn èèyàn bá ń kà á ní sínágọ́gù. (Lúùkù 4:16; Ìṣe 15:21) Ì bá mà dára o, bí àwọn ọ̀dọ́ bá lè máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ yẹn nípa lílọ sáwọn ìpàdé Kristẹni déédéé, níbi tá a ti ń ka Bíbélì, tá a sì ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀! Richard ọmọ ọdún mẹ́rìnlá mọyì irú àwọn ìpàdé bẹ́ẹ̀, ó sì sọ pé: “N kì í fi ìpàdé ṣeré rárá. Ibẹ̀ la ti ń rán mi létí déédéé nípa ohun tó dára àtohun tó burú, ohun tó jẹ́ ìwà rere àtohun tó jẹ́ ìwà pálapàla, àwọn ànímọ́ tó bá ti Kristi mu àtàwọn tí kò bá a mu. Mi ò ní láti dúró dìgbà tí mo bá kó sí wàhálà kí n tó kọ́gbọ́n.” Bẹ́ẹ̀ ni o, “ìránnilétí Jèhófà ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé, ó ń sọ aláìní ìrírí di ọlọ́gbọ́n.” (Sáàmù 19:7) Nicole pẹ̀lú kì í pa ìkankan jẹ lára àwọn ìpàdé márààrún tí ìjọ ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Ó tún ń fi wákàtí méjì sí mẹ́ta múra ìpàdé sílẹ̀.—Éfésù 5:15, 16.

9. Báwo làwọn ọ̀dọ́ ṣe lè máa “bá a lọ ní títẹ̀síwájú ní ọgbọ́n”?

9 Ìgbà èwe jẹ́ ìgbà jíjèrè ‘ìmọ̀ Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà, àti ti ẹni tí ó rán jáde, Jésù Kristi.’ (Jòhánù 17:3) O lè mọ àwọn ọ̀dọ́ tó ń jókòó ti àwọn ìwé àkàrẹ́rìn-ín, tàbí tẹlifíṣọ̀n, tàbí eré orí fídíò, tàbí wíwá ìsọfúnni kiri lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Kí ló dé tí wàá fi fara wé wọn, nígbà tó jẹ́ pé o lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ pípé tí Aṣáájú wa fi lélẹ̀? Nígbà tó wà lọ́mọdé, ó kúndùn kíkẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà. Kí sì ni ìyọrísí rẹ̀? Nítorí ìfẹ́ tí Jésù ní sí nǹkan tẹ̀mí, ó “ń bá a lọ ní títẹ̀síwájú ní ọgbọ́n.” (Lúùkù 2:52) Ìwọ náà lè ṣe bẹ́ẹ̀.

“Ẹ Wà Ní Ìtẹríba fún Ara Yín”

10. Kí ni yóò jẹ́ kí ìgbésí ayé ìdílé jẹ́ orísun àlàáfíà àti ayọ̀?

10 Ilé lè tòrò minimini, kí ó jẹ́ ibi àlàáfíà àti ayọ̀. Bẹ́ẹ̀ náà ló tún lè jẹ́ ojú ogun, níbi tí eruku ìjà ti ń sọ lálá. (Òwe 21:19; 26:21) Gbígbà tá a bá gbà pé Kristi ni Aṣáájú wa ń fi kún ayọ̀ àti àlàáfíà ìdílé wa. Àní sẹ́, àpẹẹrẹ Kristi jẹ́ àwòkọ́ṣe nípa bó ṣe yẹ káwọn mẹ́ńbà ìdílé máa bára wọn lò. Ìwé Mímọ́ sọ pé: “Ẹ wà ní ìtẹríba fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì nínú ìbẹ̀rù Kristi. Kí àwọn aya wà ní ìtẹríba fún àwọn ọkọ wọn gẹ́gẹ́ bí fún Olúwa, nítorí pé ọkọ ni orí aya rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti jẹ́ orí ìjọ, bí òun ti jẹ́ olùgbàlà ara yìí. . . . Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa bá a lọ ní nínífẹ̀ẹ́ àwọn aya yín, gan-an gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti nífẹ̀ẹ́ ìjọ, tí ó sì jọ̀wọ́ ara rẹ̀ lọ́wọ́ fún un.” (Éfésù 5:21-25) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí ìjọ tí ń bẹ ní Kólósè pé: “Ẹ̀yin ọmọ, ẹ jẹ́ onígbọràn sí àwọn òbí yín nínú ohun gbogbo, nítorí èyí dára gidigidi nínú Olúwa.”—Kólósè 3:18-20.

11. Báwo ni ọkọ kan ṣe lè fi hàn pé lóòótọ́ lòun gbà pé Kristi ni Aṣáájú òun?

11 Títẹ̀lé ìmọ̀ràn yìí túmọ̀ sí pé ọkọ yóò máa mú ipò orí nínú ìdílé, aya rẹ̀ yóò máa tì í lẹ́yìn gbágbáágbá, àwọn ọmọ yóò sì máa gbọ́ràn sí òbí wọn lẹ́nu. Àmọ́ o, àfi tí ọkùnrin bá ń lo ipò orí lọ́nà yíyẹ nìkan ló fi lè yọrí sí ayọ̀. Ọkọ tó bá gbọ́n yóò mọ bá a ṣe ń lo ipò orí nípa fífarawé Kristi Jésù, tí í ṣe Orí àti Aṣáájú òun alára. (1 Kọ́ríńtì 11:3) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé nígbẹ̀yìn Jésù di “orí lórí ohun gbogbo fún ìjọ,” wíwá tó wá sáyé “kì í ṣe kí a lè ṣe ìránṣẹ́ fún un, bí kò ṣe kí ó lè ṣe ìránṣẹ́” fúnni. (Éfésù 1:22; Mátíù 20:28) Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Kristẹni ọkọ kò ní máa lo ipò orí rẹ̀ lọ́nà ìmọtara-ẹni-nìkan, bí kò ṣe fún ire aya àtàwọn ọmọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni, fún ire ìdílé rẹ̀ lódindi. (1 Kọ́ríńtì 13:4, 5) Yóò máa sapá láti fara wé irú àwọn ànímọ́ Ọlọ́run tí Jésù Kristi, orí rẹ̀ ní. Bíi ti Jésù, yóò jẹ́ onínú tútù àti ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà. (Mátíù 11:28-30) Àwọn ọ̀rọ̀ bíi “máà bínú” tàbí “ìwọ lo tọ̀nà” kò ní wọ́n lẹ́nu rẹ̀ nígbà tó bá ṣe ohun tó kù díẹ̀ káàtó. Àpẹẹrẹ rere tó ń fi lélẹ̀ á jẹ́ kó rọrùn fún aya láti jẹ́ “olùrànlọ́wọ́,” “àṣekún” àti “ẹnì kejì” irú ọkùnrin bẹ́ẹ̀, á máa kẹ́kọ̀ọ́ lára rẹ̀, á sì máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 2:20; Málákì 2:14.

12. Kí ni yóò ran aya lọ́wọ́ láti fara mọ́ ìlànà ipò orí?

12 Ó yẹ kí aya pẹ̀lú máa tẹrí bá fún ọkọ rẹ̀. Àmọ́ bí ẹ̀mí ayé bá kó sí i lórí, ó lè bẹ̀rẹ̀ sí tàpá sí ìlànà ipò orí. Àtitẹríba fún ọkùnrin kan sì lè wá di ẹtì sí i lọ́rùn. Ìwé Mímọ́ kò sọ pé kí ọkùnrin jẹ́ apàṣẹwàá, àmọ́ ó sọ pé kí àwọn aya máa tẹrí ba fún àwọn ọkọ wọn. (Éfésù 5:24) Pẹ̀lúpẹ̀lù, Bíbélì sọ pé ọkọ tàbí bàbá yóò jíhìn, nítorí náà tá a bá tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́, ilé á wà lálàáfíà, á wà létòlétò.—Fílípì 2:5.

13. Kí ni àpẹẹrẹ ìtẹríba tí Jésù fi lélẹ̀ fáwọn ọmọ?

13 Ó yẹ kí àwọn ọmọ máa gbọ́ràn sí àwọn òbí wọn lẹ́nu. Jésù fi àpẹẹrẹ àtàtà lélẹ̀ nínú ọ̀ràn yìí. Lẹ́yìn ohun tó ṣẹlẹ̀ ní tẹ́ńpìlì, nígbà tí wọ́n fi Jésù tó jẹ́ ọmọ ọdún méjìlá sílẹ̀ sẹ́yìn fún ọjọ́ mẹ́ta, ó “bá [àwọn òbí rẹ̀] sọ̀ kalẹ̀ lọ, wọ́n sì wá sí Násárétì, ó sì ń bá a lọ ní fífi ara rẹ̀ sábẹ́ wọn.” (Lúùkù 2:51) Títẹríba táwọn ọmọ bá ń tẹrí ba fún òbí wọn ń fi kún àlàáfíà àti ìṣọ̀kan ìdílé. Nígbà tí gbogbo mẹ́ńbà ìdílé bá sì ń tẹrí ba fún Kristi gẹ́gẹ́ bí Aṣáájú, ìdílé náà yóò jẹ́ aláyọ̀.

14, 15. Kí ni yóò jẹ́ ká kẹ́sẹ járí nígbà tí ìṣòro bá yọjú nínú ilé? Mú àpẹẹrẹ wá.

14 Kódà nígbà tí ìṣòro bá yọjú nínú ilé, ọ̀nà pàtàkì tá a lè gbà yanjú rẹ̀ ni pé ká fara wé Jésù, ká sì tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà rẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, ìgbéyàwó àárín Jerry ẹni ọdún márùndínlógójì àti Lana, ìyá ọ̀dọ́mọbìnrin kan, fa ìṣòro tí wọn ò rò tì. Jerry ṣàlàyé pé: “Mo mọ̀ pé bí èmi yóò bá jẹ́ olórí tí ń lo ipò aṣáájú lọ́nà rere, mo ní láti máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì kan náà tó ń mú kí àwọn ìdílé yòókù kẹ́sẹ járí. Ṣùgbọ́n kò pẹ́ tí mo wá rí i pé mo ní láti sán okùn ṣòkòtò mi, kí n túbọ̀ fi ọgbọ́n àti ìfòyemọ̀ lo ìlànà wọ̀nyẹn.” Ojú tí ọmọ ìyàwó rẹ̀ fi ń wò ó ni pé ó wá gba màmá òun mọ́ òun lọ́wọ́, kò sì fẹ́ rí ọkọ ìyá rẹ̀ sójú rárá. Ìfòyemọ̀ ló jẹ́ kí Jerry rí i pé ẹ̀mí yìí ló ń sún ọmọbìnrin náà máa ṣe bó ṣe ń ṣe. Ọgbọ́n wo ló wá dá sọ́ràn náà? Jerry fèsì pé: “Èmi àti Lana pinnu pé ó kéré tán lọ́wọ́ tá a wà nígbà yẹn, Lana nìkan ni òbí tí yóò máa bá ọmọ náà wí. Ṣùgbọ́n èmi á máa wá ọ̀nà tí àárín èmi àti ọmọ náà yóò fi gún. Láìpẹ́, ọgbọ́n yìí ṣiṣẹ́.”

15 Nígbà tá a bá dojú kọ ipò líle koko nínú ilé, ó yẹ ká ní ìfòyemọ̀ ká lè mọ ìdí tí àwọn aráalé wa fi ń ṣe bí wọ́n ṣe ń ṣe. A tún nílò ọgbọ́n láti mọ bó ṣe yẹ ká lo àwọn ìlànà Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, Jésù fi òye mọ ìdí tí obìnrin tó ní ìsun ẹ̀jẹ̀ fi fọwọ́ kàn án. Ó sì fọgbọ́n bá a sọ̀rọ̀ tìyọ́nú-tìyọ́nú. (Léfítíkù 15:25-27; Máàkù 5:30-34) Ọgbọ́n àti ìfòyemọ̀ wà lára ànímọ́ Aṣáájú wa. (Òwe 8:12) A óò jẹ́ aláyọ̀ bá a bá fìwà jọ ọ́.

‘Ẹ Máa Wá Ìjọba Náà Lákọ̀ọ́kọ́’

16. Kí ló yẹ kó gbawájú nínú ìgbésí ayé wa, báwo sì ni Jésù ṣe fi àpẹẹrẹ èyí lélẹ̀?

16 Jésù sojú abẹ níkòó nípa ohun tó yẹ kí ó gbawájú nínú ìgbésí ayé àwọn tó bá ka òun sí Aṣáájú wọn. Ó sọ pé: “Ẹ máa bá a nìṣó, nígbà náà, ní wíwá ìjọba náà àti òdodo Rẹ̀ [ìyẹn ti Ọlọ́run] lákọ̀ọ́kọ́.” (Mátíù 6:33) Ó sì fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ nípa bá a ṣe lè máa ṣe èyí. Jésù dojú kọ àdánwò lẹ́yìn ogójì ọjọ́ tó fi gbààwẹ̀, tó fi ṣàṣàrò, tó sì fi gbàdúrà lẹ́yìn ìbatisí rẹ̀. Sátánì Èṣù sọ pé òun máa fún un ní ìṣàkóso lórí “gbogbo ìjọba ayé.” Ẹ wo ìgbésí ayé gbẹdẹmukẹ tí Jésù ì bá máa gbé ká ní ó gba ohun tí Èṣù fi lọ̀ ọ́! Àmọ́ ohun tó wà ní góńgó ẹ̀mí Kristi ni ṣíṣe ìfẹ́ Baba rẹ̀. Bákan náà, ó mọ̀ pé irú ìgbésí ayé bẹ́ẹ̀ nínú ayé Sátánì kò lè tọ́jọ́. Ojú ẹsẹ̀ ló kọ ohun tí Èṣù fi lọ̀ ọ́, tó sì sọ pé: “A kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni ìwọ gbọ́dọ̀ jọ́sìn, òun nìkan ṣoṣo sì ni ìwọ gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún.’” Láìpẹ́ lẹ́yìn náà ni Jésù “bẹ̀rẹ̀ wíwàásù, ó sì ń wí pé: ‘Ẹ ronú pìwà dà, nítorí ìjọba ọ̀run ti sún mọ́lé.’” (Mátíù 4:2, 8-10, 17) Gbogbo ìyókù ọjọ́ tí Kristi lò láyé ló fi ń polongo Ìjọba Ọlọ́run.

17. Báwo la ṣe lè fi hàn pé ire Ìjọba náà ló wà ní ipò àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé wa?

17 Á dáa ká fìwà jọ Aṣáájú wa, ká má sì jẹ́ kí ayé Sátánì mú ká sọ wíwá iṣẹ́ olówó ńlá di ohun bàbàrà nínú ìgbésí ayé wa. (Máàkù 1:17-21) Áà, yóò mà burú o, bí a bá ri ara wa bọnú àwọn ohun ayé, tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tá a wá fọwọ́ rọ́ ire Ìjọba Ọlọ́run sẹ́yìn! Jésù ti gbé iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn lé wa lọ́wọ́. (Mátíù 24:14; 28:19, 20) Òótọ́ ni pé ẹrù iṣẹ́ ìdílé àtàwọn ẹrù iṣẹ́ míì lè já lé wa léjìká, àmọ́ ǹjẹ́ inú wa kì í dùn láti lo ìrọ̀lẹ́ àti òpin ọ̀sẹ̀ láti ṣe ojúṣe wa gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni nínú iṣẹ́ wíwàásù àti kíkọ́ni? Ẹ sì wo bó ṣe wúni lórí tó pé ní ọdún iṣẹ́ ìsìn 2001, nǹkan bíi 780,000 ló sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà, ìyẹn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún!

18. Kí ló ń jẹ́ ká ní ayọ̀ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà?

18 Àwọn ìwé Ìhìn Rere fi hàn pé Jésù jẹ́ akíkanjú ọkùnrin, àmọ́ ó tún lójú àánú. Nígbà tó rí ebi tẹ̀mí tó ń pa àwọn èèyàn tó yí i ká, àánú wọ́n ṣe é, ojú ẹsẹ̀ ló sì ràn wọ́n lọ́wọ́. (Máàkù 6:31-34) Iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa máa ń fún wa láyọ̀ bó bá jẹ́ pé ìfẹ́ fún àwọn èèyàn àti ìfẹ́ àtọkànwá láti ràn wọ́n lọ́wọ́ ló ń sún wa ṣe é. Ṣùgbọ́n báwo la ṣe lè ní irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀? Ọ̀dọ́kùnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jayson sọ pé: “Nígbà tí mo jẹ́ ọ̀dọ́langba, mo kàn ń rọ́jú ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà ni.” Kí ló wá jẹ́ kó fẹ́ràn iṣẹ́ yìí? Jayson dáhùn pé: “Nínú ìdílé wa, a sábà máa ń jáde òde ẹ̀rí ní àràárọ̀ Sátidé. Èyí ṣe mí láǹfààní gan-an nítorí pé bí mo ṣe túbọ̀ ń jáde òde ẹ̀rí ni mo túbọ̀ ń rí ohun rere tí iṣẹ́ náà ń ṣe láṣeyọrí, bẹ́ẹ̀ náà ni mo sì túbọ̀ ń gbádùn rẹ̀.” Ó yẹ kí àwa náà máa gbìyànjú láti jáde òde ẹ̀rí déédéé.

19. Kí ló yẹ kó jẹ́ ìpinnu wa nípa jíjẹ́ tí Kristi jẹ́ Aṣáájú wa?

19 Ó ń tuni lára, ó sì ń mérè wá láti tẹ́wọ́ gba Kristi gẹ́gẹ́ bí Aṣáájú wa. Bá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, a óò máa tẹ̀ síwájú nínú ìmọ̀ àti ọgbọ́n nígbà èwe wa. Ìdílé wa á jẹ́ ibi àlàáfíà àti ayọ̀, iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà á sì jẹ́ iṣẹ́ aláyọ̀ àti iṣẹ́ àṣegbádùn. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká pinnu pé a óò máa fi hàn gbangba nínú ìgbésí ayé wa ojoojúmọ́ àti nínú ìpinnu tí à ń ṣe, pé lóòótọ́ la gbà pé Kristi ni Aṣáájú wa. (Kólósè 3:23, 24) Àmọ́ o, Jésù Kristi tún jẹ́ Aṣáájú wa lọ́nà mìíràn—ìyẹn nínú ìjọ Kristẹni. Àpilẹ̀kọ tó kàn yóò ṣàlàyé bá a ṣe lè jàǹfààní nínú ìṣètò yìí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ kan padà.

Ǹjẹ́ O Rántí?

• Báwo la ṣe ń jàǹfààní nínú títọ Aṣáájú tí Ọlọ́run yàn lẹ́yìn?

• Báwo làwọn ọ̀dọ́ ṣe lè fi hàn pé àwọn fẹ́ máa tọ Jésù Aṣáájú wa lẹ́yìn?

• Ipa wo ni jíjẹ́ tí Kristi jẹ́ Aṣáájú wa ń ní lórí ìgbésí ayé ìdílé àwọn tó fara mọ́ ọn?

• Báwo ni iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa ṣe lè fi hàn pé a gbà lóòótọ́ pé Kristi ni Aṣáájú wa?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Ìgbà èwe jẹ́ ìgbà tó dára láti jèrè ìmọ̀ nípa Ọlọ́run àti Aṣáájú tó yàn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Títẹríba fún Kristi gẹ́gẹ́ bí Aṣáájú wa ń fi kún ayọ̀ ìdílé

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Jésù fi wíwá Ìjọba náà sípò àkọ́kọ́. Ìwọ ńkọ́?