Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ibo La Ti Lè Rí—Aṣáájú Rere?

Ibo La Ti Lè Rí—Aṣáájú Rere?

Ibo La Ti Lè Rí—Aṣáájú Rere?

BÍBÉLÌ sọ pé: “Olúkúlùkù ilé ni a kọ́ láti ọwọ́ ẹnì kan, ṣùgbọ́n ẹni tí ó kọ́ ohun gbogbo ni Ọlọ́run.” (Hébérù 3:4; Ìṣípayá 4:11) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́ náà ni Ẹlẹ́dàá wa, ó “mọ ẹ̀dá wa.” (Sáàmù 103:14) Ó mọ ibi tí agbára wa mọ, ó sì mọ gbogbo ohun tó yẹ ká ní. Níwọ̀n bí òun ti jẹ́ Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́, yóò fún wa ní gbogbo nǹkan wọ̀nyẹn. (Sáàmù 145:16; 1 Jòhánù 4:8) Ara ohun tó yẹ ká ní sì ni aṣáájú rere.

Jèhófà gbẹnu wòlíì Aísáyà kéde pé: “Wò ó! Mo ti fi í fún àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí, gẹ́gẹ́ bí aṣáájú àti aláṣẹ fún àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè.” (Aísáyà 55:4) Ara ohun tí yóò yanjú ìṣòro àìsí aṣáájú rere lóde òní ni mímọ Aṣáájú tí Olódùmarè tìkára rẹ̀ yàn yìí, ká sì gbà pé òun ni aṣáájú wa. Ta wá ni Aṣáájú àti Aláṣẹ tá a sọ tẹ́lẹ̀ yìí? Kí ni àwọn ànímọ́ tó ní tó fi hàn pé aṣáájú ni lóòótọ́? Ibo ló ń ṣáájú wa lọ? Kí ni a gbọ́dọ̀ ṣe láti jàǹfààní nínú ipò aṣáájú rẹ̀?

Aṣáájú Tá A Ṣèlérí Náà Dé

Nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀tàlá [2,500] ọdún sẹ́yìn ni áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì yọ sí wòlíì Dáníẹ́lì, tó sì sọ fún un pé: “Kí o mọ̀, kí o sì ní ìjìnlẹ̀ òye pé láti ìjáde lọ ọ̀rọ̀ náà láti mú Jerúsálẹ́mù padà bọ̀ sípò àti láti tún un kọ́ títí di ìgbà Mèsáyà Aṣáájú, ọ̀sẹ̀ méje yóò wà, àti ọ̀sẹ̀ méjì-lé-lọ́gọ́ta. Òun yóò padà, a ó sì tún un kọ́ ní ti gidi, pẹ̀lú ojúde ìlú àti yàrà ńlá, ṣùgbọ́n ní àkókò wàhálà kíkangógó.”—Dáníẹ́lì 9:25.

Ó ṣe kedere pé ohun tí áńgẹ́lì náà ń sọ fún Dáníẹ́lì ni àkókò pàtó tí Aṣáájú tí Jèhófà yàn yóò dé. “Mèsáyà Aṣáájú” yóò dé lópin ọ̀sẹ̀ mọ́kàndínláàádọ́rin, ìyẹn ọ̀rìn-lé-nírínwó ó lé mẹ́ta [483] ọdún, bí a bá kà á láti ọdún 455 ṣááju Sànmánì Tiwa, nígbà tí àṣẹ náà jáde pé kí wọn lọ tún Jerúsálẹ́mù kọ́. a (Nehemáyà 2:1-8) Kí ló ṣẹlẹ̀ lópin sáà yẹn? Lúùkù òǹkọ̀wé Ìhìn Rere ròyìn pé: “Ní ọdún kẹẹ̀ẹ́dógún ìgbà ìjọba Tìbéríù Késárì, nígbà tí Pọ́ńtíù Pílátù jẹ́ gómìnà Jùdíà, tí Hẹ́rọ́dù sì jẹ́ olùṣàkóso àgbègbè Gálílì [ọdún 29 Sànmánì Tiwa], . . . Ìpolongo Ọlọ́run tọ Jòhánù ọmọkùnrin Sekaráyà wá nínú aginjù. Nítorí náà, ó wá sí gbogbo ìgbèríko tí ó wà ní àyíká Jọ́dánì, ó ń wàásù ìbatisí gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ ìrònúpìwàdà fún ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀.” Nígbà yẹn, “àwọn ènìyàn náà ti ń fojú sọ́nà” fún Mèsáyà Aṣáájú náà. (Lúùkù 3:1-3, 15) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ogunlọ́gọ̀ wá sọ́dọ̀ Jòhánù, òun kọ́ ni Aṣáájú náà.

Nígbà tó wá di nǹkan bí October ọdún 29 Sànmánì Tiwa, Jésù ará Násárétì tọ Jòhánù wá pé kó batisí òun. Jòhánù jẹ́rìí, pé: “Mo rí tí ẹ̀mí ń sọ kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àdàbà láti ọ̀run, ó sì bà lé e. Èmi pàápàá kò mọ̀ ọ́n tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n Ẹni náà gan-an tí ó rán mi láti batisí nínú omi sọ fún mi pé, ‘Ẹnì yòówù tí o bá rí tí ẹ̀mí ń sọ kalẹ̀ lé, tí ó sì dúró, èyí ni ẹni tí ń fi ẹ̀mí mímọ́ batisí.’ Mo sì ti rí i, mo sì ti jẹ́rìí pé ẹni yìí ni Ọmọ Ọlọ́run.” (Jòhánù 1:32-34) Ìgbà tá a batisí Jésù ló di Aṣáájú tá a fẹ̀mí yàn—èyíinì ni Mèsáyà, tàbí Kristi.

Ní tòótọ́, Jésù Kristi ni “aṣáájú àti aláṣẹ fún àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè.” Tá a bá sì wo àwọn ànímọ́ tó ní gẹ́gẹ́ bí aṣáájú, a óò rí i kedere pé bó ṣe ń ṣe aṣáájú tirẹ̀ dára lọ́pọ̀lọpọ̀ ju ti aṣáájú èyíkéyìí táwọn èèyàn lóde òní kà sí aṣáájú tó dáńgájíá.

Mèsáyà Náà—Aṣáájú Tó Dáńgájíá Ni

Aṣáájú tó bá pegedé á rí i dájú pé òun fún àwọn ọmọ abẹ́ òun ní ìtọ́sọ́nà tó ṣe kedere, á kì wọ́n láyà, á sì kọ́ wọn lọ́gbọ́n tí wọ́n á fi lè yanjú ìṣòro. Ìwé náà, 21st Century Leadership: Dialogues With 100 Top Leaders, sọ pé: ‘Èyí jẹ́ ọ̀kan lára ànímọ́ tí ẹni tó bá fẹ́ jẹ́ aṣáájú tó dáńgájíá ní ọ̀rúndún kọkànlélógún yìí gbọ́dọ̀ ní.’ Ẹ wo bí Jésù ṣe múra àwọn olùgbọ́ rẹ̀ sílẹ̀ tó láti kojú ipòkípò tó bá yọjú! Ronú nípa àsọyé olókìkí jù lọ tó sọ—èyíinì ni Ìwàásù Lórí Òkè. Àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú Mátíù orí karùn-ún sí ìkeje kún fún ìmọ̀ràn tó gbéṣẹ́.

Fún àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká gbé ìmọ̀ràn tí Jésù fún wa nípa bí a ṣe lè yanjú èdèkòyédè yẹ̀ wò. Ó sọ pé: “Nígbà náà, bí ìwọ bá ń mú ẹ̀bùn rẹ bọ̀ níbi pẹpẹ, tí o sì rántí níbẹ̀ pé arákùnrin rẹ ní ohun kan lòdì sí ọ, fi ẹ̀bùn rẹ sílẹ̀ níbẹ̀ níwájú pẹpẹ, kí o sì lọ; kọ́kọ́ wá àlàáfíà, ìwọ pẹ̀lú arákùnrin rẹ, àti lẹ́yìn náà, nígbà tí o bá ti padà wá, fi ẹ̀bùn rẹ rúbọ.” (Mátíù 5:23, 24) Ohun àkọ́múṣe ni yíyanjú aáwọ̀ àárín àwa àtàwọn ẹlòmíì jẹ́. Àní ó ṣe pàtàkì ju ṣíṣe àwọn ojúṣe kan tí ẹ̀sìn là sílẹ̀, irú bíi mímú ẹ̀bùn wá sórí pẹpẹ ní tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù, gẹ́gẹ́ bí Òfin Mósè ṣe là á sílẹ̀. Ọlọ́run kò ní tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wa bí a kò bá kọ́kọ́ yanjú irú aáwọ̀ bẹ́ẹ̀. Ìmọ̀ràn Jésù ṣì wúlò lóde òní, bó ṣe wúlò ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún sẹ́yìn.

Jésù tún kọ́ àwọn olùgbọ́ rẹ̀ bí wọ́n ṣe lè yẹra fún kíkó sínú páńpẹ́ ìṣekúṣe. Ó gbà wọ́n níyànjú pé: “Ẹ gbọ́ pé a sọ ọ́ pé, ‘Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe panṣágà.’ Ṣùgbọ́n mo wí fún yín pé olúkúlùkù ẹni tí ń bá a nìṣó ní wíwo obìnrin kan láti ní ìfẹ́ onígbòónára sí i, ti ṣe panṣágà pẹ̀lú rẹ̀ ná nínú ọkàn-àyà rẹ̀.” (Mátíù 5:27, 28) Ìkìlọ̀ yìí mà mọ́gbọ́n dání o! Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ohun téèyàn kì í jẹ, kì í fi í runmú, kí nìdí tí a ó fi rìn ní bèbè panṣágà nípa jíjẹ́ kí ọkàn wa máa ronú nípa rẹ̀? Jésù sọ pé inú ọkàn ni àgbèrè àti panṣágà ti ń wá. (Mátíù 15:18, 19) Á dáa ká dáàbò bo ọkàn wa.—Òwe 4:23.

Ìwàásù Lórí Òkè tún ní ìmọ̀ràn tó múná dóko nínú nípa nínífẹ̀ẹ́ ọ̀tá ẹni, nípa jíjẹ́ ọ̀làwọ́, nípa ojú tó yẹ ká fi wo àwọn nǹkan tara àti tẹ̀mí, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. (Mátíù 5:43-47; 6:1-4, 19-21, 24-34) Kódà, Jésù fi ọ̀nà táwọn olùgbọ́ rẹ̀ fi lè rí ìrànlọ́wọ́ gbà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run hàn wọ́n nípa kíkọ́ wọn bí a ṣe ń gbàdúrà. (Mátíù 6:9-13) Mèsáyà Aṣáájú fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lókun, ó tún múra wọn sílẹ̀ láti kojú àwọn ìṣòro tọ́mọ aráyé ń bá yí.

Nínú Ìwàásù Lórí Òkè, ẹ̀ẹ̀mẹfà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Jésù fi gbólóhùn náà “ẹ gbọ́ pé a sọ ọ́ pé” tàbí “síwájú sí i, a sọ ọ́ pé” nasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀. Àmọ́ lẹ́yìn náà ni á tún wá gbé èrò mìíràn kalẹ̀, nípa sísọ pé “Bí ó ti wù kí ó rí, mo wí fún yín pé.” (Mátíù 5:21, 22, 27, 28, 31-34, 38, 39, 43, 44) Ìyẹn fi hàn pé òfin àtẹnudẹ́nu àwọn Farisí làwọn olùgbọ́ rẹ̀ ń tẹ̀ lé tẹ́lẹ̀. Àmọ́ Jésù wá ń fi ọ̀nà mìíràn hàn wọ́n báyìí—tó máa jẹ́ kí wọ́n lóye ohun náà gan-an tí Òfin Mósè ń sọ. Jésù tipa bẹ́ẹ̀ mú ìyípadà dé wẹ́rẹ́, ó sì mú un wá lọ́nà tó rọrùn fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti tẹ́wọ́ gbà á. Bẹ́ẹ̀ ni o, Jésù mú kí àwọn èèyàn ṣe ìyípadà ńláǹlà nínú ìgbésí ayé wọn, nípa tẹ̀mí àti ní ti ìwà rere. Àmì aṣáájú rere nìyí.

Ìwé kan tó dá lórí ètò àbójútó sọ bó ṣe nira tó láti mú irú ìyípadà bẹ́ẹ̀ wá. Ó ní: “[Aṣáájú] tó fẹ́ mú ìyípadà wá gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tó láájò bí òṣìṣẹ́ afẹ́nifẹ́re, kí ó jẹ́ onírònújinlẹ̀ bí afìṣemọ̀rònú, kí ó ní ìmí bí eléré ẹlẹ́mìí ẹṣin, kí ó ní ìrọ́jú bí ajá ọdẹ, kí ó jẹ́ ẹni tó lè dánú rò bí ẹni tí ń dá gbé, kí ó sì ní irú sùúrù tí olùfọkànsìn ń ní. Kódà, bó ní gbogbo ànímọ́ wọ̀nyí pàápàá, kò sí ìdánilójú pé yóò kẹ́sẹ járí.”

Àpilẹ̀kọ kan tá a pe àkọlé rẹ̀ ní “Ǹjẹ́ Ìwà Ẹni Tó Jẹ́ Aṣáájú Ṣe Pàtàkì?,” sọ pé: “Àwọn aṣáájú gbọ́dọ̀ máa hùwà bí wọ́n ṣe fẹ́ kí àwọn ọmọ abẹ́ wọn máa hùwà.” Ní tòdodo, aṣáájú rere máa ń fi ohun tó bá ń wàásù ṣèwà hù. Bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ sì ni Jésù Kristi ṣe! Ó kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n níwà ìrẹ̀lẹ̀, òun alára sì fi àpẹẹrẹ èyí lélẹ̀ nígbà tó wẹ ẹsẹ̀ wọn. (Jòhánù 13:5-15) Kì í ṣe pé ó kàn rán àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n lọ máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, àmọ́ òun alára forí fọrùn ṣe nínú iṣẹ́ yẹn. (Mátíù 4:18-25; Lúùkù 8:1-3; 9:1-6; 10:1-24; Jòhánù 10:40-42) Jésù tún fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ ní ti ojú tó fi ń wo jíjẹ́ aṣáájú. Ó sọ nípa ara rẹ̀ pé: “Ọmọ kò lè ṣe ẹyọ ohun kan ní àdáṣe ti ara rẹ̀, bí kò ṣe kìkì ohun tí ó rí tí Baba ń ṣe.”—Jòhánù 5:19.

Àwọn ohun tá a gbé yẹ̀ wò lókè yìí nípa ohun tí Jésù sọ àti ohun tó ṣe, fi hàn kedere pé Aṣáájú tó dáńgájíá ni. Àní sẹ́, àwọn ànímọ́ rẹ̀ ta yọ gbogbo ọ̀pá ìdiwọ̀n táwọn èèyàn fi ń dá aṣáájú tó dáńgájíá mọ̀. Jésù jẹ́ ẹni pípé. Jésù wà títí ayé, nítorí pé ó ti gba àìleèkú lẹ́yìn ikú àti àjíǹde rẹ̀. (1 Pétérù 3:18; Ìṣípayá 1:13-18) Aṣáájú ẹ̀dá ènìyàn wo ló ní irú ànímọ́ wọ̀nyẹn?

Kí Ló Yẹ Ká Ṣe?

Gẹ́gẹ́ bí Ọba tí ń jọba lọ́wọ́lọ́wọ́ nínú Ìjọba Ọlọ́run, “Mèsáyà Aṣáájú” yóò rọ̀jò ìbùkún sórí aráyé onígbọràn. Ìwọ̀nyí ni òjò ìbùkún tí Ìwé Mímọ́ ṣèlérí pé: “Ilẹ̀ ayé yóò kún fún ìmọ̀ Jèhófà bí omi ti bo òkun.” (Aísáyà 11:9) “Àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.” (Sáàmù 37:11) “Wọn yóò sì jókòó ní ti tòótọ́, olúkúlùkù lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, kì yóò sì sí ẹnì kankan tí yóò máa mú wọn wárìrì.” (Míkà 4:4) “Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yóò sì wà pẹ̀lú wọn. Yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.”—Ìṣípayá 21:3, 4.

Aṣáájú rere wọ́n bí ojú láyé òde òní. Àmọ́, Jésù Kristi ń ṣamọ̀nà àwọn ọlọ́kàn tútù lọ sínú ayé tuntun alálàáfíà, níbi tí aráyé onígbọràn yóò ti máa fi ìṣọ̀kan sin Jèhófà Ọlọ́run, tí wọ́n yóò sì máa tẹ̀ síwájú sí ìjẹ́pípé. Ẹ wo bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká sapá láti jèrè ìmọ̀ nípa Ọlọ́run tòótọ́ náà àti nípa Aṣáájú tí ó yàn, kí a sì máa fi ohun tá à ń kọ́ ṣèwà hù!—Jòhánù 17:3.

Ọ̀kan lára ọ̀nà tó dára jù lọ tá a lè gbà buyì fún èèyàn ni ká máa fara wé onítọ̀hún. Fún ìdí yìí, ǹjẹ́ kò yẹ ká fara wé Jésù Kristi, tí í ṣe Aṣáájú gíga jù lọ nínú ìtàn aráyé? Báwo la ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀? Ipa wo ni títẹ̀lé ìtọ́sọ́nà rẹ̀ yóò ní lórí ìgbésí ayé wa? A óò jíròrò ìbéèrè wọ̀nyí àtàwọn ìbéèrè mìíràn nínú àpilẹ̀kọ méjèèjì tó tẹ̀ lé èyí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo ojú ìwé 186 sí 192 nínú ìwé náà Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì!, tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Dáníẹ́lì sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa bíbọ̀ Aṣáájú tí Ọlọ́run yàn

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Àwọn ẹ̀kọ́ Jésù jẹ́ káwọn èèyàn mọ bí wọ́n ṣe lè kojú àwọn ìṣòro inú ìgbésí ayé

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Jésù yóò ṣamọ̀nà aráyé onígbọràn lọ sínú ayé tuntun alálàáfíà