Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

O Lè Borí Ìnìkanwà

O Lè Borí Ìnìkanwà

O Lè Borí Ìnìkanwà

TA LÓ lè sọ pé òun kò nírìírí ìbànújẹ́ ọkàn tí ìnìkanwà máa ń mú wá rí? Ọ̀pọ̀ nǹkan ló lè mú wa ronú pé a dá nìkan wà. Àmọ́, èyí tó burú jáì ni ìnìkanwà àwọn obìnrin tí kò lọ́kọ rí tàbí àwọn opó tàbí àwọn tí ọkọ wọn kọ̀ sílẹ̀.

Bí àpẹẹrẹ, ọ̀dọ́bìnrin Kristẹni kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Frances sọ pé: “Nígbà tí mo fi máa pé ọmọ ọdún mẹ́tàlélógún, ó dà bíi pé gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ mi ló ti lọ́kọ tán, ó sì wá ku èmi nìkan ṣoṣo.” a Ìrètí àtirí ọkọ fẹ́ lè máa dín kù sí i bí ọdún ṣe ń gorí ọdún, ṣùgbọ́n ìrònú pé èèyàn dá nìkan wà máa ń lágbára sí i ni. Sandra, tó ti ń lọ sí ẹni àádọ́ta ọdún báyìí, sọ pé: “Kì í ṣe pé mo dìídì fẹ́ wà láìlọ́kọ. Títí di bá a ṣe ń wí yìí, ó ṣì ń wù mí kí n ṣègbéyàwó tí àǹfààní rẹ̀ bá yọ.” Angela, tó ti lé ní ẹni àádọ́ta ọdún là á mọ́lẹ̀ pé: “Mi ò fìgbà kan rí pinnu pé mo máa wà láìlọ́kọ, ṣùgbọ́n ipò tí mo bá ara mi báyìí nìyẹn. Ìwọ̀nba àwọn arákùnrin díẹ̀ ló wà lágbègbè tí wọ́n yàn mí sí gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe.”

Ó yẹ ká gbóríyìn fún ọ̀pọ̀ Kristẹni arábìnrin tó yàn láti má ṣègbéyàwó nítorí pé wọ́n fẹ́ fi ìṣòtítọ́ ṣègbọràn sí ìmọ̀ràn Jèhófà pé ká ṣègbéyàwó “kìkì nínú Olúwa.” (1 Kọ́ríńtì 7:39) Jíjẹ́ àpọ́n ti mọ́ àwọn kan lára, àmọ́ bí ọdún ṣe ń gorí ọdún ló ń wu àwọn mìíràn pé káwọn ṣáà ṣègbéyàwó káwọn sì bí àwọn ọmọ tiwọn. Sandra jẹ́wọ́ pé: “Ìmọ̀lára wíwà láìní alábàárò, tí àìlọ́kọ fà fún mi, ni mò ń bá yí lójoojúmọ́.”

Àwọn kókó mìíràn, bíi títọ́jú àwọn òbí tó ti darúgbó, tún lè dá kún ìmọ̀lára ìnìkanwà. Sandra sọ pé: “Nítorí pé mi ò lọ́kọ, àwọn ẹbí gbà pé èmi ló yẹ kó máa tọ́jú àwọn òbí wa tó jẹ́ arúgbó. Ogún ọdún gbáko ni mo fi gbé apá tó pọ̀ jù nínú ẹrù iṣẹ́ yìí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwa mẹ́fà ni ìyá wa bí. Ìgbésí ayé ì bá rọrùn fún mi jùyẹn lọ, tó bá jẹ́ pé mo lọ́kọ tí ì bá bá mi gbé lára ẹrù náà.”

Frances mẹ́nu kan nǹkan mìíràn tó jẹ́ kí ìnìkanwà túbọ̀ jẹ́ ìṣòro fóun. Ó sọ pé: “Nígbà mìíràn, àwọn ènìyàn máa ń bi mí láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ rárá pé, ‘Kí ló dé tó ò tíì ṣègbéyàwó?’ Irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ máa ń jẹ́ kí n ronú pé ẹ̀bi mi ni wíwà tí mo wà láìlọ́kọ. Ṣàṣà nibi ìgbéyàwó tí mo lọ táwọn èèyàn kì í bi mí ní ìbéèrè tí ń kani láyà náà pé, ‘Ìgbà wo lo tiẹ̀ fẹ́ ṣègbéyàwó ná?’ Màá wá bẹ̀rẹ̀ sí ronú pé, ‘Bí mi ò bá wu àwọn arákùnrin tí nǹkan tẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ni mi ò ní àwọn ànímọ́ Kristẹni tó yẹ kí n ní tàbí bóyá mi ò tiẹ̀ lẹ́wà rárá.’”

Báwo lèèyàn ṣe lè borí ìṣòro dídá nìkan wà? Ǹjẹ́ ohunkóhun tiẹ̀ wà táwọn ẹlòmíràn lè ṣe láti ṣèrànwọ́?

Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà

Onísáàmù náà kọ ọ́ lórin pé: “Ju ẹrù ìnira rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀, òun fúnra rẹ̀ yóò sì gbé ọ ró. Kì yóò jẹ́ kí olódodo ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n láé.” (Sáàmù 55:22) Ọ̀rọ̀ náà “ẹrù,” bí wọ́n ṣe lò ó nínú èdè Hébérù wulẹ̀ túmọ̀ sí “ìpín,” ó sì ń tọ́ka sí ìdààmú àti hílàhílo tó lè bá wa nítorí ohun tó jẹ́ ìpín tiwa láyé. Jèhófà mọ àwọn ẹrù wọ̀nyí ju ẹnikẹ́ni lọ, ó sì lè fún wa ní okun láti kojú wọn. Ìgbẹ́kẹ̀lé tí Angela ní nínú Jèhófà Ọlọ́run ló ràn án lọ́wọ́ láti fara da dídá nìkan wà. Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún tó ń ṣe, ó sọ pé: “Nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà, èmi àti ẹnì kejì mi ń gbé ní ọ̀nà jíjìn sí ìjọ tó sún mọ́ wa jù lọ. A kọ́ bí a ṣe ní láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá. Ìgbẹ́kẹ̀lé yìí sì ti ràn mí lọ́wọ́ ní gbogbo ìgbésí ayé mi. Nígbà tí mo bá fẹ́ ní èrò òdì, mo máa ń bá Jèhófà sọ̀rọ̀, ó sì máa ń ràn mí lọ́wọ́. Sáàmù Kẹtàlélógún ti jẹ́ ìtùnú ńlá fún mi, mo sì máa ń kà á ní gbogbo ìgbà.”

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní ẹrù ìnira kan láti fara dà. Ó kéré tán, ìgbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló ‘pàrọwà sí Olúwa pé kí ẹ̀gún tí ó wà lára òun lè kúrò níbẹ̀.’ A kò fi iṣẹ́ ìyanu mú un kúrò lára Pọ́ọ̀lù, ṣùgbọ́n a ṣèlérí fún un pé inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run yóò mẹ́sẹ̀ rẹ̀ dúró. (2 Kọ́ríńtì 12:7-9) Pọ́ọ̀lù tún rí àṣírí níní ìtẹ́lọ́rùn. Ó kọ̀wé lẹ́yìn náà pé: “Nínú ohun gbogbo àti nínú ipò gbogbo, mo ti kọ́ àṣírí bí a ti ń jẹ àjẹyó àti bí a ti ń wà nínú ebi, bí a ti ń ní ọ̀pọ̀ yanturu àti bí a ti ń jẹ́ aláìní. Mo ní okun fún ohun gbogbo nípasẹ̀ agbára ìtóye ẹni tí ń fi agbára fún mi.”—Fílípì 4:12, 13.

Báwo lèèyàn ṣe lè rí okun gbà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run nígbà tó bá ní ìrẹ̀wẹ̀sì tàbí tó bá dá nìkan wà? Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun, ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run; àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà yín àti agbára èrò orí yín nípasẹ̀ Kristi Jésù.” (Fílípì 4:6, 7) Sandra fi ìmọ̀ràn yìí sílò. Ó ṣàlàyé pé: “Nítorí pé mi ò lọ́kọ, ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo máa ń dá nìkan wà. Èyí fún mi ní àǹfààní tó pọ̀ láti gbàdúrà sí Jèhófà. Mo sún mọ́ ọn pẹ́kípẹ́kí, mo sì lè bá a sọ̀rọ̀ fàlàlà nípa àwọn ìṣòro mi àti ayọ̀ mi.” Frances ní tirẹ̀ sọ pé: “Gbígbógunti èrò òdì ni ìṣòro ńlá tí mò ń bá yí. Àmọ́ bí mo ṣe ń sọ ìmọ̀lára mi fún Jèhófà láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ ti ràn mí lọ́wọ́ gan-an. Ó dá mi lójú pé Jèhófà fẹ́ kí n dúró sán-ún nípa tẹ̀mí àti nípa ti ìmí ẹ̀dùn.”—1 Tímótì 5:5.

“Ẹ Máa Bá A Lọ Ní Ríru Ẹrù Ìnira Ara Yín Lẹ́nì Kìíní-Kejì”

Kò yẹ ká máa nìkan gbé ẹrù ìnira wa láàárín ẹgbẹ́ àwọn ará Kristẹni. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbani níyànjú pé: “Ẹ máa bá a lọ ní ríru àwọn ẹrù ìnira ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì tipa báyìí mú òfin Kristi ṣẹ.” (Gálátíà 6:2) Nípasẹ̀ ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa, a lè rí “ọ̀rọ̀ rere” tó ń fúnni níṣìírí, tó lè dín ìṣòro ìnìkanwà kù.—Òwe 12:25.

Tún ronú lórí ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa ọmọbìnrin Jẹ́fútà, Adájọ́ Ísírẹ́lì nì. Kó tó di pé Jẹ́fútà ṣẹ́gun agbo ọmọ ogun Ámónì ọ̀tá rẹ̀ ló ti jẹ́jẹ̀ẹ́ pé òun yóò fún Jèhófà ní ẹni tó bá kọ́kọ́ jáde nínú agbo ilé òun láti wá bá òun yọ̀. Ó wá ṣẹlẹ̀ pé ọmọbìnrin rẹ̀ ni. (Àwọn Onídàájọ́ 11:30, 31, 34-36) Bí èyí tiẹ̀ túmọ̀ sí pé ó ní láti wà láìlọ́kọ, kó sì yááfì fífẹ́ láti ní ìdílé tirẹ̀, síbẹ̀ ọmọbìnrin Jẹ́fútà fi tinútinú fara mọ́ ẹ̀jẹ́ yìí, ó sì fi gbogbo èyí tó kù nínú ìgbésí ayé rẹ̀ sìn ní ibi ìjọsìn ní Ṣílò. Ǹjẹ́ ìrúbọ tó ṣe yìí já sí asán? Rárá o. Kàkà bẹ́ẹ̀, Bíbélì sọ pé: “Láti ọdún dé ọdún, àwọn ọmọbìnrin Ísírẹ́lì á lọ láti gbóríyìn fún ọmọbìnrin Jẹ́fútà tí í ṣe ọmọ Gílíádì, ní ọjọ́ mẹ́rin lọ́dún.” (Àwọn Onídàájọ́ 11:40) Bẹ́ẹ̀ ni o, yinniyinni kẹ́ni ṣe míì ṣáà la máa ń wí. Nítorí náà, ẹ má ṣe jẹ́ ká kùnà láti gbóríyìn fún àwọn tí oríyìn tọ́ sí.

Ì bá dára ká gbé àpẹẹrẹ ti Jésù alára yẹ̀ wò. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe àṣà àwọn Júù pé kí ọkùnrin máa bá àwọn obìnrin sọ̀rọ̀, síbẹ̀, Jésù wá àyè gbọ́ ti Màríà àti Màtá. Ó ṣeé ṣe kí àwọn obìnrin yìí jẹ́ opó tàbí kí wọn máà tilẹ̀ lọ́kọ rí rárá. Jésù fẹ́ kí àwọn méjèèjì gbádùn àǹfààní tẹ̀mí tí ń bẹ nínú jíjẹ́ ọ̀rẹ́ òun. (Lúùkù 10:38-42) A lè fara wé àpẹẹrẹ Jésù, nípa pípe àwọn arábìnrin wà nípa tẹ̀mí, tí wọn ò lọ́kọ, síbi àpèjẹ àti nípa ṣíṣètò láti bá wọn jáde òde ẹ̀rí. (Róòmù 12:13) Ǹjẹ́ wọ́n mọrírì irú àfiyèsí bẹ́ẹ̀? Arábìnrin kan sọ pé: “Mo mọ̀ pé àwọn ará nífẹ̀ẹ́ mi, wọ́n sì mọyì mi, àmọ́ inú mi máa ń dún gan-an nígbà tí wọ́n bá túbọ̀ fi ìfẹ́ hàn sí mi.”

Sandra ṣàlàyé pé: “Nítorí pé a kò ní ìdílé tiwa, ó ṣe pàtàkì káwọn èèyàn túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ wa, ká lè mọ̀ pé a jẹ́ apá kan ìdílé àwọn arákùnrin àti arábìnrin nípa tẹ̀mí.” Ó dájú pé Jèhófà bìkítà fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀, a sì ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ nígbà tá a bá jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé a mọyì wọn, a sì nífẹ̀ẹ́ wọn pẹ̀lú. (1 Pétérù 5:6, 7) Irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ kò ní já sásán, nítorí pé “ẹni tí ń fi ojú rere hàn sí ẹni rírẹlẹ̀, Jèhófà ni ó ń wín, Òun [Jèhófà Ọlọ́run] yóò sì san ìlòsíni rẹ̀ padà fún un.”—Òwe 19:17.

“Olúkúlùkù Ni Yóò Ru Ẹrù Ti Ara Rẹ̀”

Bó tilẹ̀ jẹ pé àwọn ẹlòmíràn lè ṣèrànwọ́, ìtìlẹ́yìn wọn ṣì lè fúnni níṣìírí, síbẹ̀, “olúkúlùkù ni yóò ru ẹrù ti ara rẹ̀.” (Gálátíà 6:5) Àmọ́, ká tó lè gbé ẹrù ìnìkanwà, a ní láti ṣọ́ra fún àwọn ewu kan. Fún àpẹẹrẹ, ìnìkanwà lè borí wa tá a bá bẹ̀rẹ̀ sí ká sójú kan, tá ò báwọn èèyàn sọ̀rọ̀ mọ́. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, a lè fìfẹ́ ṣẹ́gun ìnìkanwà. (1 Kọ́ríńtì 13:7, 8) Fífúnni àti ṣíṣàjọpín ni ọ̀nà tó dára jù lọ láti rí ayọ̀—láìka ipòkípò tá a lè wà sí. (Ìṣe 20:35) Arábìnrin kan tó jẹ́ aṣáájú ọ̀nà tó ń ṣe iṣẹ́ àṣekára sọ pé: “Mi ò ní àkókò púpọ̀ láti máa ronú lórí ìnìkanwà. Nígbà tí mo bá rí i pé mo wúlò, tí ọwọ́ mi sì dí, n kì í nímọ̀lára pé mo dá nìkan wà.”

A tún gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kí ìnìkanwà má lọ sún wa bẹ̀rẹ̀ sí ṣèṣekúṣe. Fún àpẹẹrẹ, ẹ ò rí i pé ìbànújẹ́ ńlá ló máa jẹ́ tá a bá lọ jẹ́ kí ìfẹ́ láti ṣègbéyàwó sún wa láti gbójú fo ọ̀pọ̀ ìṣòro tó máa ń tẹ̀yìn fífẹ́ aláìgbàgbọ́ jáde, àgàgà tí irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ bá sún wa tàpá sí ìmọ̀ràn tí Ìwé Mímọ́ fún wa láti yẹra fún títọrùn bọ irú àjàgà bẹ́ẹ̀! (2 Kọ́ríńtì 6:14) Kristẹni obìnrin kan tí ọkọ rẹ̀ kọ̀ sílẹ̀ sọ pé: “Ohun kan wà tó burú ju àìlọ́kọ lọ. Òun ni kéèyàn fẹ́ ẹni tí kò yẹ kó fẹ́.”

Ńṣe lèèyàn máa ń fara da ìṣòro tí kò bá níyanjú, ó kéré tán lọ́wọ́ tá a wà yìí. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run, ìmọ̀lára ìnìkanwà ṣeé fara dà. Bá a ṣe ń sin Jèhófà nìṣó, ǹjẹ́ kí ó dá wa lójú pé ọjọ́ kan ń bọ̀ tí Ọlọ́run á ṣe ohun tí yóò tẹ́ gbogbo wa lọ́rùn lọ́nà tó dára jù lọ.—Sáàmù 145:16.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí orúkọ àwọn obìnrin tó sọ̀rọ̀ wọ̀nyí padà.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

A lè ṣẹ́gun ìnìkanwà nípa fífúnni àti ṣíṣàjọpín