Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ Wà Lójúfò, Kí Ẹ sì Máa Tẹ̀ Síwájú Láìfòyà!

Ẹ Wà Lójúfò, Kí Ẹ sì Máa Tẹ̀ Síwájú Láìfòyà!

Ẹ Wà Lójúfò, Kí Ẹ sì Máa Tẹ̀ Síwájú Láìfòyà!

Ìròyìn Nípa Àwọn Àkànṣe Ìpàdé

TA LÓ máa sọ pé òun ò gbà pé “àwọn àkókò lílekoko tó nira láti bá lò” là ń gbé lónìí? Àwọn pákáǹleke ìgbésí ayé ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” wọ̀nyí kò yọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sílẹ̀. (2 Tímótì 3:1-5) Ṣùgbọ́n a mọ̀ pé àwọn èèyàn ń fẹ́ ìrànlọ́wọ́. Wọn ò mọ̀dí gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé. Wọ́n ń fẹ́ ìtùnú àti ìrètí. Kí ni iṣẹ́ pàtàkì tó já lé wa léjìká tá a bá fẹ́ ran àwọn èèyàn ẹlẹgbẹ́ wa lọ́wọ́?

Iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé wa lọ́wọ́ ni pé ká máa polongo ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tá a ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀. (Mátíù 24:14) Àwọn èèyàn gbọ́dọ̀ mọ̀ pé Ìjọba ọ̀run yìí nìkan ni ìrètí aráyé. Àmọ́, kì í ṣe gbogbo ìgbà làwọn èèyàn ń fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ wa. Láwọn ibì kan, wọ́n ti gbẹ́sẹ̀ lé iṣẹ́ wa, wọ́n sì ń ṣe inúnibíni sáwọn ará wa. Síbẹ̀ a ò ní tìtorí ìyẹn juwọ́ sílẹ̀. Pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú Jèhófà, a ti pinnu láti wà lójúfò, ká sì máa tẹ̀ síwájú láìfòyà, lẹ́nu iṣẹ́ kíkéde ìhìn rere náà láìdábọ̀.—Ìṣe 5:42.

Ìpinnu àìyẹsẹ̀ yìí hàn kedere nígbà àwọn àkànṣe ìpàdé tó wáyé ní October 2001. Ọjọ́ Sátidé, October 6, la ṣe ìpàdé ọdọọdún ti Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Jersey City, Ìpínlẹ̀ New Jersey, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. a Lọ́jọ́ tó tẹ̀ lé e, a tún ṣe àwọn ìpàdé mìíràn níbi mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, mẹ́ta ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, ọ̀kan ní Kánádà. b

Nígbà tí alága ìpàdé ọdọọdún náà, Arákùnrin Samuel F. Herd, tó jẹ́ ara Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ń ṣí ìpàdé náà, ó tọ́ka sí Sáàmù 92:1, 4, ó sì wí pé: “A fẹ́ fi hàn pé a moore.” Láìṣe àní-àní, ìròyìn márààrún táwọn ará mú wá láti igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àgbáyé fi hàn pé ó yẹ ká fọpẹ́ hàn lóòótọ́.

Ìròyìn Láti Igun Mẹ́rẹ̀ẹ̀rin Ayé

Arákùnrin Alfred Kwakye ròyìn bí iṣẹ́ ìwàásù náà ṣe ń tẹ̀ síwájú sí ní Gánà. Wọ́n gbẹ́sẹ̀ lé iṣẹ́ wa fún ọdún mélòó kan ní orílẹ̀-èdè yẹn. Nígbà yẹn, àwọn èèyàn máa ń béèrè pé: “Kí ló dé tí wọ́n fi gbẹ́sẹ̀ lé iṣẹ́ yín ná? Kí lẹ ṣe?” Arákùnrin Kwakye ṣàlàyé pé èyí máa ń ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún ìjẹ́rìí. Nígbà tí wọ́n gbẹ́sẹ̀ kúrò lórí iṣẹ́ wa lọ́dún 1991, 34,421 Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló wà ní Gánà. Ní August 2001, àròpọ̀ àwọn tó wà níbẹ̀ jẹ́ 68,152—tó jẹ́ ìbísí ìpín méjìdínlọ́gọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún. Ètò ń lọ lọ́wọ́ láti kọ́ Gbọ̀ngàn Àpéjọ tó lè gba ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá èèyàn. Ó ṣe kedere pé àwọn ará wa nípa tẹ̀mí ní Gánà ń lo òmìnira ìjọsìn tí wọ́n ní lọ́nà rere.

Láìfi rúkèrúdò tí ọ̀ràn ìṣèlú dá sílẹ̀ pè, àwọn ará wa ní Ireland ń sa gbogbo ipá wọn nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà. Àwọn èèyàn sì ń bọ̀wọ̀ fún wọn nítorí bí wọn ò ṣe dá sí tọ̀tún tòsì. Arákùnrin Peter Andrews, tó jẹ́ Akóṣẹ́jọ Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka Ireland, sọ pé ìjọ márùndínlọ́gọ́fà [115] àti àyíká mẹ́fà ló wà ní Ireland. Arákùnrin Andrews sọ ìrírí Liam, ọmọ ọdún mẹ́wàá, tí kì í bẹ̀rù láti wàásù níléèwé. Liam fún àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n àti olùkọ́ rẹ̀ ní ẹ̀dà ìwé náà Iwe Itan Bibeli Mi, tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde. Liam fẹ́ ṣèrìbọmi, ṣùgbọ́n ẹnì kan ń béèrè pé ǹjẹ́ kò ti kéré jù báyìí. Liam fèsì pé: “Kì í ṣe ọjọ́ orí mi ló yẹ ká gbé ìpinnu náà kà, bí kò ṣe ìfẹ́ tí mo ní fún Jèhófà. Ìrìbọmi mi ni yóò fi bí mo ṣe fẹ́ràn Jèhófà tó hàn.” Iṣẹ́ míṣọ́nnárì ni Liam fẹ́ fi ìgbésí ayé rẹ̀ ṣe.

Lọ́dún 1968, iye akéde tó wà lórílẹ̀-èdè Venezuela jẹ́ 5,400. Àmọ́, Arákùnrin Stefan Johansson, akóṣẹ́jọ Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka lórílẹ̀-èdè yẹn sọ pé wọ́n ti di 88,000 báyìí. Wọ́n sì ṣẹ̀ṣẹ̀ ń mẹ́yẹẹ́ bọ̀ lápò ni, nítorí pé àwọn tó lé ní 296,000 ló wá síbi Ìṣe Ìrántí lọ́dún 2001. Ní December 1999, òjò àrọ̀ọ̀rọ̀dá ṣokùnfà ọ̀gbàrá ẹrẹ̀ tó pa nǹkan bí ẹgbàá mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [50,000] èèyàn, títí kan àwọn Ẹlẹ́rìí mélòó kan. Ẹrẹ̀ kún inú Gbọ̀ngàn Ìjọba títí tó fi fẹ́rẹ̀ẹ́ kan àjà. Nígbà tẹ́nì kan dá a lábàá pé kí àwọn ará pa ilé náà tì, èsì wọn ni pé: “Àgbẹdọ̀! Gbọ̀ngàn Ìjọba wa ni, a ò kàn lè pa á tì báyẹn.” Wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lórí rẹ̀, wọ́n ń kó ẹrẹ̀, òkúta àtàwọn pàǹtírí míì dà nù. Wọ́n tún ilé náà ṣe, ó wá rí rèǹtè-rente, àwọn ará sì sọ pé ilé ọba tó jó ni, ẹwà ló bù kún un!

Arákùnrin Denton Hopkinson, tí í ṣe akóṣẹ́jọ Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka Philippines sọ pé èdè mẹ́tàdínláàádọ́rùn-ún [87] ni wọ́n ń sọ ní orílẹ̀-èdè Philippines. Ọdún iṣẹ́ ìsìn tó kọjá la gbé Bíbélì Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde ní lájorí èdè mẹ́ta tí wọ́n ń sọ lórílẹ̀-èdè náà—ìyẹn Cebuano, Iloko àti Tagalog. Arákùnrin Hopkinson sọ ìrírí ọmọ ọdún mẹ́sàn-án kan tó ka ìwé náà, Good News—To Make You Happy, tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde. Ó gba àwọn ìtẹ̀jáde míì láti ẹ̀ka iléeṣẹ́ náà, ó sì kà wọ́n. Àmọ́ ìdílé rẹ̀ gbógun tì í. Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, nígbà tó wà ní ilé ẹ̀kọ́ ìṣègùn, ó kàn sí ẹ̀ka iléeṣẹ́ wa, ó sì béèrè fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó ṣe batisí lọ́dún 1996. Kò sì pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn tó wọnú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Òun àti ìyàwó rẹ̀ ń sìn ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ wa báyìí.

Arákùnrin Ronald Parkin, tí í ṣe akóṣẹ́jọ Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka iléeṣẹ́ wa ní Puerto Rico sọ pé ‘ẹnu iṣẹ́ “fífi àwọn Ẹlẹ́rìí ránṣẹ́ sí ilẹ̀ mìíràn” làwọ́n wà ní pẹrẹu.’ Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25,000] akéde ló wà ní erékùṣù náà, ó sì ti wà bẹ́ẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún, láìdín láìlé. Èé ṣe? Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún akéde ni Puerto Rico ń “fi ránṣẹ́” sí Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà lọ́dọọdún. Ọ̀pọ̀ nínú wọn ló ń ṣí lọ síbẹ̀ nítorí ọ̀ràn àtijẹ àtimu. Arákùnrin Parkin sọ nípa ẹjọ́ mánigbàgbé tí wọ́n dá fún Ẹlẹ́rìí kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Lius, ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún, tó ní àrùn leukemia. Wọ́n gbé ẹjọ́ Lius lọ sí kóòtù nítorí pé ó kọ̀ láti gbẹ̀jẹ̀ sára. Adájọ́ lọ bá Lius ní ọsibítù, ó lóun á fẹ́ gbọ́rọ̀ látẹnu ọlọ́rọ̀. Lius bi í pé: “Kí ló dé tó fi jẹ́ pé bó bá jẹ́ ọ̀ràn ni mo dá, àgbàlagbà lẹ máa pè mí, àmọ́ nítorí pé mo fẹ́ ṣègbọràn sí Ọlọ́run, ẹ ní ọmọdé tí kò tójúúbọ́ ni mí?” Ó wá dá adájọ́ náà lójú pé ọmọ yìí tójúúbọ́, ó sì lè dá ṣèpinnu.

Lẹ́yìn àwọn ìròyìn kan láti àwọn ilẹ̀ òkèèrè, Arákùnrin Harold Corkern, tí í ṣe ara Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, fi ọ̀rọ̀ wá àwọn èèyàn mẹ́rin tó ti ń sin Jèhófà láti ọdún pípẹ́ lẹ́nu wò. Arákùnrin Arthur Bonno ti lo ọdún mọ́kànléláàádọ́ta lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún, ó sì ń sìn lọ́wọ́lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí ara Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka orílẹ̀-èdè Ecuador. Arákùnrin Angelo Catanzaro ti lo ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́ta nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún, èyí tó pọ̀ jù lọ nínú ọdún wọ̀nyí ló fi ṣe iṣẹ́ alábòójútó arìnrìn àjò. Arákùnrin Richard Abrahamson kẹ́kọ̀ọ́ yege ní ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì lọ́dún 1953, ó sì láǹfààní láti bojú tó iṣẹ́ náà ní orílẹ̀-èdè Denmark fún ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n kó tó padà wá sí Bẹ́tẹ́lì ní Brooklyn. Níkẹyìn, inú gbogbo èèyàn dùn láti gbọ́rọ̀ látẹnu Arákùnrin Carey W. Barber, tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìndínlọ́gọ́rùn-ún. Ọdún 1921 ni Arákùnrin Barber ṣèrìbọmi. Ó sì ti lo ọdún méjìdínlọ́gọ́rin nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Ó ti di ara Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso láti ọdún 1978.

Àwọn Àwíyé Tí Ń Tani Jí

A sọ àwọn àwíyé tó lárinrin nígbà ìpàdé ọdọọdún náà. Arákùnrin Robert W. Wallen sọ̀rọ̀ lórí ẹṣin ọ̀rọ̀ náà “Àwọn Èèyàn Kan fún Orúkọ Rẹ̀.” Àwa ló ń jẹ́ orúkọ mọ́ Ọlọ́run, a sì wà ní àwọn ilẹ̀ tó lé ní igba ó lé ọgbọ̀n [230]. Jèhófà ti fún wa “ní ọjọ́ ọ̀la kan àti ìrètí kan.” (Jeremáyà 29:11) A gbọ́dọ̀ máa pòkìkí Ìjọba Ọlọ́run nìṣó, ká máa kéde ọ̀rọ̀ ìtùnú àti ọ̀rọ̀ ìṣírí tó gbámúṣé náà. (Aísáyà 61:1) Arákùnrin Wallen wá parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Ǹjẹ́ ká máa bá a nìṣó, láti ọjọ́ dé ọjọ́, láti máa gbé níbàámu pẹ̀lú orúkọ wa náà, Ẹlẹ́rìí Jèhófà.”—Aísáyà 43:10.

Apá tó gbẹ̀yìn nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà jẹ́ àpínsọ ọ̀rọ̀ látẹnu mẹ́ta lára Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso. Àkòrí rẹ̀ ni “Àkókò Nìyí Láti Wà Lójúfò, Láti Dúró Gbọn-in àti Láti Di Alágbára Ńlá.”—1 Kọ́ríńtì 16:13.

Nínú apá kìíní, Arákùnrin Stephen Lett sọ̀rọ̀ lórí kókó náà “Ẹ Wà Lójúfò ní Wákàtí Ìkẹyìn Yìí.” Arákùnrin Lett ṣàlàyé pé ẹ̀bùn ni oorun jẹ́. Ó ń jẹ́ kára wa jí pépé. Àmọ́, oorun tẹ̀mí kò dáa rárá. (1 Tẹsalóníkà 5:6) Báwo wá la ṣe lè wà lójúfò nípa tẹ̀mí? Arákùnrin Lett mẹ́nu kan “oògùn” tẹ̀mí mẹ́ta: (1) Máa ní púpọ̀ rẹpẹtẹ láti ṣe nínú iṣẹ́ Olúwa. (1 Kọ́ríńtì 15:58) (2) Jẹ́ kí àìní rẹ nípa tẹ̀mí máa jẹ ọ́ lọ́kàn. (Mátíù 5:3) (3) Máa kọbi ara sí ìmọ̀ràn Bíbélì kí o lè hùwà ọgbọ́n.—Òwe 13:20.

Arákùnrin Theodore Jaracz sọ ọ̀rọ̀ alárinrin kan tá a pe àkòrí rẹ̀ ní “Ẹ Dúró Gbọn-in Nígbà Ìdánwò.” Arákùnrin Jaracz tọ́ka sí Ìṣípayá 3:10, ó sì béèrè pé: “Kí ni ‘wákàtí ìdánwò’?” “Ọjọ́ Olúwa” ni ìdánwò yẹn dé, àkókò yẹn sì ni a wà yìí. (Ìṣípayá 1:10) Ìdánwò náà dá lórí kókó pàtàkì náà—ṣé ìhà Ìjọba Ọlọ́run tá a ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ la wà ni tàbí ìhà ètò àwọn nǹkan búburú ti Sátánì? Kò sí ni, a óò máa fojú winá àdánwò àti ìṣòro kí wákàtí yẹn tó dópin. Ṣé a óò dúró ṣinṣin ti Jèhófà àti ètò rẹ̀? Arákùnrin Jaracz sọ pé: ‘Gbogbo wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ló gbọ́dọ̀ fi irú ìdúróṣinṣin bẹ́ẹ̀ hàn.’

Ní paríparí rẹ̀, Arákùnrin John E. Barr sọ̀rọ̀ lórí ẹṣin ọ̀rọ̀ náà “Ẹ Di Alágbára Ńlá Gẹ́gẹ́ bí Ẹni Tẹ̀mí.” Ó tọ́ka sí Lúùkù 13:23-25, ó sì wá sọ pé a gbọ́dọ̀ sapá “láti gba ẹnu ọ̀nà tóóró wọlé.” Ọ̀pọ̀ ni kò lè gba ọ̀nà yẹn wọlé nítorí pé wọn ò sapá tó láti di alágbára ńlá. Tá a bá fẹ́ di géńdé Kristẹni, a gbọ́dọ̀ máa fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò nínú gbogbo apá ìgbésí ayé wa. Arákùnrin Barr sọ pé: “Ó dá mi lójú pé ẹ ó gbà pé àkókò nìyí láti (1) fi Jèhófà sí ipò àkọ́kọ́; (2) láti di alágbára ńlá; àti (3) láti máa sa gbogbo ipá wa nínú ṣíṣe ìfẹ́ Jèhófà. Ṣíṣe èyí la ó fi lè gba ẹnu ọ̀nà tóóró tí ń sinni lọ sí ìyè àgbàyanu tí kò nípẹ̀kun.”

Bí ìpàdé ọdọọdún náà ṣe ń lọ sópin, ìbéèrè kan ṣì wà tí a ò tíì dáhùn. Ìbéèrè náà ni: Kí ni ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọdún iṣẹ́ ìsìn 2002? Ọjọ́ kejì la dáhùn ìbéèrè yẹn.

Ìpàdé Mìíràn Tó Wáyé Láfikún

Ojú wà lọ́nà gan-an láàárọ̀ Sunday bí ìtòlẹ́sẹẹsẹ àfikún ìpàdé náà ṣe bẹ̀rẹ̀. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ ti ọ̀sẹ̀ náà la fi bẹ̀rẹ̀ ìpàdé yìí. Lẹ́yìn náà la wá mẹ́nu kan àwọn kókó pàtàkì-pàtàkì inú ìpàdé ọdọọdún náà ní ṣókí. Lẹ́yìn èyí, inú gbogbo àwọn ará dùn láti gbọ́ ọ̀rọ̀ nípa ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ti ọdún 2002, tó kà pé: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, . . . èmi yóò sì tù yín lára.” (Mátíù 11:28) A gbé ọ̀rọ̀ náà ka àwọn àpilẹ̀kọ fún ìkẹ́kọ̀ọ́, èyí tó wà nínú ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ ti oṣù December 15, 2001.

Lẹ́yìn ìyẹn ni àwọn kan tó lọ sí àkànṣe Àpéjọ “Olùkọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run,” tó wáyé ní ilẹ̀ Faransé àti Ítálì ní August 2001 wá tẹnu bọ ìròyìn. c Níkẹyìn, gẹ́gẹ́ bí apá mánigbàgbé nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ náà, àwọn olùbánisọ̀rọ̀ tá a rán wá láti Bẹ́tẹ́lì ti Brooklyn ló sọ àsọyé méjì tó kẹ́yìn lọ́jọ́ náà.

Àkòrí ọ̀rọ̀ àkọ́kọ́ ni “Gbígbẹ́kẹ̀lé Jèhófà Láìmikàn ní Àkókò Lílekoko Yìí.” Àwọn kókó pàtàkì tí olùbánisọ̀rọ̀ náà sọ̀rọ̀ lé lórí nìwọ̀nyí: (1) Gbígbẹ́kẹ̀lé Jèhófà láìmikàn sábà máa ń ṣe pàtàkì fáwọn èèyàn Ọlọ́run. Ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ àwọn tó lo ìgboyà àti ìgbàgbọ́ nígbà àtakò ló wà nínú Bíbélì. (Hébérù 11:1–12:3) (2) Jèhófà fún wa ní ìdí gúnmọ́ tó fi yẹ ká gbára lé òun pátápátá. Àwọn iṣẹ́ àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú un dá wa lójú pé ó ń tọ́jú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, kò sì ní gbàgbé wọn láé. (Hébérù 6:10) (3) Ìgboyà àti ìgbẹ́kẹ̀lé ṣe pàtàkì gidigidi lónìí. A jẹ́ “ẹni ìkórìíra,” gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe sọ tẹ́lẹ̀. (Mátíù 24:9) Ká lè fara dà á, ó ṣe pàtàkì pé ká gbára lé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ká ní ìdánilójú pé ẹ̀mí rẹ̀ wà pẹ̀lú wa, ká sì ní ìgboyà láti máa kéde ìhìn rere náà nìṣó. (4) À ń rí àwọn àpẹẹrẹ tó fi hàn pé à ń dojú kọ àtakò lọ́wọ́ tá a wà yìí. Ọ̀rọ̀ náà wọ gbogbo èèyàn lára nígbà tí olùbánisọ̀rọ̀ náà ròyìn ohun tí ojú àwọn ará wa ń rí ní Armenia, ilẹ̀ Faransé, Georgia, Kazakhstan, Rọ́ṣíà àti Turkmenistan. Láìsí àní-àní, àkókò nìyí láti ní ìgboyà, ká sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà!

Ẹni tó sọ̀rọ̀ kẹ́yìn sọ̀rọ̀ lórí ẹṣin ọ̀rọ̀ náà “Fífi Ìṣọ̀kan Tẹ̀ Síwájú Pẹ̀lú Ètò Jèhófà.” Ọ̀rọ̀ náà dá lórí àwọn kókó kan tó bọ́ sákòókò. (1) Jákèjádò ayé làwọn èèyàn ń ṣàkíyèsí ìtẹ̀síwájú àwọn èèyàn Jèhófà. Iṣẹ́ ìwàásù àtàwọn àpéjọ wa ń pe àfiyèsí àwọn èèyàn sí wa. (2) Jèhófà ti dá ètò kan tó wà níṣọ̀kan sílẹ̀. Lọ́dún 29 Sànmánì Tiwa, a fi ẹ̀mí mímọ́ yan Jésù kí ó lè mú “ohun gbogbo”—àwọn tí yóò lọ sọ́run àtàwọn tí yóò wà lórí ilẹ̀ ayé—wá sínú ìdílé Ọlọ́run tó wà níṣọ̀kan. (Éfésù 1:8-10) (3) Àwọn àpéjọ jẹ́ ẹ̀rí tí kò ṣeé já ní koro nípa ìṣọ̀kan wa kárí ayé. Èyí hàn gbangba nínú àwọn àkànṣe àpéjọ tó wáyé nílẹ̀ Faransé àti Ítálì ní oṣù August ọdún tó kọjá. (4) A ṣe ìpinnu alárinrin kan nílẹ̀ Faransé àti Ítálì. Olùbánisọ̀rọ̀ náà mẹ́nu kan díẹ̀ lára ìpinnu alárinrin náà. Ìpinnu náà látòkèdélẹ̀ ló wà nísàlẹ̀ yìí.

Nígbà tí olùbánisọ̀rọ̀ tá a rán wá náà parí ọ̀rọ̀ tó kẹ́yìn náà, ó ka ìfilọ̀ kan tó wúni lórí látọ̀dọ̀ Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso. Ara ìfilọ̀ náà ni pé: “Àkókò nìyí láti wà lójúfò, ká sì máa ṣọ́nà, ká máa kíyè sí àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé. . . . A fẹ́ kẹ́ ẹ mọ̀ pé Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso nífẹ̀ẹ́ yín tọkàntọkàn, wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ gbogbo àwọn èèyàn Ọlọ́run pẹ̀lú. Ǹjẹ́ kí ó bù kún yín lọ́pọ̀ yanturu bí ẹ ṣe ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀ tọkàntọkàn.” Àwọn èèyàn Jèhófà níbi gbogbo ti pinnu láti wà lójúfò ní àkókò líle koko yìí, kí wọ́n sì máa bá ètò Jèhófà tó wà níṣọ̀kan tẹ̀ síwájú láìfòyà.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Lórí ẹ̀rọ alátagbà ni àwọn èèyàn ní àwọn ibi mélòó kan ti gbọ́ ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìpàdé ọdọọdún náà. Èyí ló mú kí àròpọ̀ gbogbo àwọn tó gbọ́ ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà jẹ́ 13,757.

b Àwọn ìpàdé tá a ṣe ní àfikún náà wáyé nílùú Long Beach, ní Ìpínlẹ̀ California; ìlú Pontiac, ní Ìpínlẹ̀ Michigan; àgbègbè Uniondale, ní Ìpínlẹ̀ New York; àti ìlú Hamilton, ní Ìpínlẹ̀ Ontario. Àròpọ̀ gbogbo àwọn tó wá, títí kan àwọn tó gbọ́ ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà lórí ẹ̀rọ alátagbà láwọn ibòmíràn, jẹ́ 117,885.

c A ṣe àwọn àkànṣe àpéjọ mẹ́ta nílẹ̀ Faransé—nílùú Paris, Bordeaux àti Lyons. Ní Ítálì, àwọn aṣojú tó wá láti Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ṣe àpéjọ tiwọn nílùú Róòmù àti Milan. Àmọ́ àròpọ̀ àpéjọ mẹ́sàn-án la ṣe lákòókò kan náà.

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29-31]

Ìpinnu

Ní August 2001, a ṣe àkànṣe Àpéjọ “Àwọn Olùkọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” nílẹ̀ Faransé àti Ítálì. A ṣe ìpinnu alárinrin kan nígbà àpéjọ wọ̀nyẹn. Ìpinnu ọ̀hún ló tẹ̀ lé e yìí.

“GBOGBO àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tá a pésẹ̀ sí Àpéjọ ‘Àwọn Olùkọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run’ yìí la ti kọ́ ní ẹ̀kọ́ tó ṣàǹfààní lọ́pọ̀lọpọ̀. A mọ ẹni tó ṣètò ẹ̀kọ́ yìí dunjú. Ọ̀dọ̀ èèyàn kọ́ ni ẹ̀kọ́ yìí ti wá. Ọ̀dọ̀ Ẹni tí Aísáyà wòlíì ìgbàanì pè ní ‘Olùkọ́ni wa Atóbilọ́lá’ ni ẹ̀kọ́ náà ti wá. (Aísáyà 30:20) Kíyè sí ohun tí Jèhófà rán wa létí nínú Aísáyà 48:17, pé: ‘Èmi, Jèhófà, ni Ọlọ́run rẹ, Ẹni tí ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní, Ẹni tí ń mú kí o tọ ọ̀nà tí ó yẹ kí o máa rìn.’ Báwo ló ṣe ń ṣe èyí? Ohun pàtàkì tó ń lò ni Bíbélì, ìwé tá a túmọ̀, tá a sì pín kiri jù lọ lágbàáyé. Ìwé ọ̀hún sọ láìfọ̀rọ̀ bọpo bọyọ̀ pé: ‘Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní.’—2 Tímótì 3:16.

“Aráyé nílò irú ẹ̀kọ́ tó ṣàǹfààní gan-an bẹ́ẹ̀ lóde òní. Èé ṣe tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Tá a bá wo bí ayé yìí ṣe ń yí padà, tó sì ń dojú rú, kí ni àwọn ọ̀mọ̀ràn ń sọ? Kò ju pé: Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àìmọye èèyàn ló jẹ́ ọ̀mọ̀wé hán-únhán-ún, àwọn èèyàn ò mọ ibi táyé wọn dorí kọ rárá, wọn ò sì mọ ọwọ́ ọ̀tún wọn yàtọ̀ sí tòsì. (Aísáyà 5:20, 21) Àwọn èèyàn ò mọ dòò nínú Bíbélì. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ òde òní ń tú ọ̀pọ̀ ìsọfúnni jáde nípasẹ̀ kọ̀ǹpútà, ibo la ti lè rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè pàtàkì bíi, Kí ni ète ìgbésí ayé? Kí ni gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lákòókò wa yìí túmọ̀ sí? Ǹjẹ́ ìrètí gidi wà fọ́jọ́ ọ̀la? Ǹjẹ́ àlàáfíà àti ààbò yóò wà láé? Síwájú sí i, ẹgbàágbèje ìwé ló wà tó ń ṣàlàyé gbogbo ìgbòkègbodò ọmọ ẹ̀dá. Síbẹ̀, ọmọ aráyé ò fi ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn ṣàríkọ́gbọ́n. Ńṣe nìwà ọ̀daràn ń peléke. Ńṣe làwọn àrùn tá a rò pé a ti kápá rẹ̀ tẹ́lẹ̀ tún ń gbọ̀nà ẹ̀bùrú yọ, tí àwọn míì, bí àrùn éèdì, sì ti di àjàkálẹ̀ àrùn. Ìdílé ń tú ká. Àwọn èèyàn ń ba àyíká jẹ́. Ìpániláyà àti àwọn ohun ìjà runlérùnnà ń dí àlàáfíà àti ààbò lọ́wọ́. Àwọn ìṣòro tí kò lójútùú ń pọ̀ sí i. Ẹrù iṣẹ́ wo ló já lé wa léjìká nínú ríran àwọn èèyàn ẹlẹgbẹ́ wa lọ́wọ́ ní àkókò líle koko yìí? Ǹjẹ́ ẹ̀kọ́ kankan wà tó ṣàlàyé ibi tí ọ̀ràn aráyé ti wọ́ wá, tí kò fọ̀rọ̀ mọ sórí títọ́ka sí ọ̀nà ìgbésí ayé rere nísinsìnyí nìkan, àmọ́ tó tún tọ́ka sí ìrètí ológo tó dájú fún ọjọ́ ọ̀la?

“Iṣẹ́ tí Ìwé Mímọ́ gbé lé wa lọ́wọ́ ni ‘ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí Kristi pa láṣẹ mọ́.’ (Mátíù 28:19, 20) Jésù Kristi ló ní ká lọ máa ṣe iṣẹ́ yìí lẹ́yìn ikú àti àjíǹde rẹ̀, lẹ́yìn tí Ọlọ́run fún un ní gbogbo ọlá àṣẹ lọ́run àti láyé. Iṣẹ́ yìí ṣe pàtàkì ju gbogbo iṣẹ́ táwọn èèyàn dáwọ́ lé. Lójú Ọlọ́run, iṣẹ́ wa, tó dá lórí bíbójútó àìní tẹ̀mí àwọn èèyàn tí òùngbẹ òdodo ń gbẹ, ni iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ. Ìwé Mímọ́ tẹ̀ ẹ́ mọ́ wa létí pé iṣẹ́ tá a gbọ́dọ̀ mú ní ọ̀kúnkúndùn ni.

“Èyí fi hàn pé iṣẹ́ yìí ló yẹ kó gba ipò kìíní nínú ìgbésí ayé wa. Lágbára Ọlọ́run, a ó ṣe iṣẹ́ náà láṣeyọrí, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ nǹkan ló ń pín ọkàn níyà, pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ohun ìdènà àti àtakò lágbo ẹ̀sìn àti ìṣèlú, tó ń wá ọ̀nà láti fawọ́ aago ètò ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ kárí ayé yìí sẹ́yìn. Ọkàn wa balẹ̀, a sì nígbàgbọ́ pé iṣẹ́ yìí yóò máa tẹ̀ síwájú, títí a ó fi ṣe é parí. Èé ṣe tó fi dá wa lójú tó bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé Jésù Kristi Olúwa ṣèlérí pé òun á wà pẹ̀lú wa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé wa lọ́wọ́ yìí títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan yìí.

“Òpin ti dé tán fún aráyé tí wàhálà bá. A gbọ́dọ̀ parí iṣẹ́ tá à ń ṣe yìí kí òpin pátápátá tó dé. Fún ìdí yìí, àwa, Ẹlẹ́rìí Jèhófà, pinnu pé:

“Ení: Gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ tó ti ṣe ìyàsímímọ́, a ti pinnu pé ire Ìjọba Ọlọ́run ni a óò máa fi sípò àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé wa, a ó sì máa tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. Láti ṣe èyí láṣeyọrí, ohun tí à ń gbà ládùúrà lohun tó wà nínú Sáàmù 143:10, pé: ‘Kọ́ mi láti máa ṣe ìfẹ́ rẹ, nítorí pé ìwọ ni Ọlọ́run mi.’ Èyí ń béèrè pé ká jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ aláápọn, tó ń sapá láti ka Bíbélì lójoojúmọ́, tó ń dá kẹ́kọ̀ọ́, tó sì ń ṣe ìwádìí dáadáa. Kí ìtẹ̀síwájú wa lè hàn sí gbogbo èèyàn, a óò máa sa gbogbo ipá wa láti múra sílẹ̀ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ ká lè jàǹfààní nínú ètò ẹ̀kọ́ tẹ̀mí tá à ń rí gbà nínú ìpàdé ìjọ, àpéjọ àyíká àti ti àgbègbè, àpéjọ kan ṣoṣo fún odindi orílẹ̀-èdè àti ti àgbáyé.—1 Tímótì 4:15; Hébérù 10:23-25.

“Èjì: Kí Ọlọ́run lè máa kọ́ wa, orí tábìlì rẹ̀ nìkan la ó ti máa jẹun, a ó sì kíyè sára gidigidi láti ṣègbọràn sí ìkìlọ̀ Bíbélì nípa àwọn ẹ̀kọ́ ẹ̀mí èṣù tí ń ṣini lọ́nà. (1 Kọ́ríńtì 10:21; 1 Tímótì 4:1) A óò ṣọ́ra gidigidi láti yàgò fún àwọn ohun tó lè ṣàkóbá fún wa, bí ẹ̀kọ́ ìsìn èké, àwọn ìrònú tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀, ìwà ìṣekúṣe tí ń tini lójú, àwọn ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè tó pọ̀ jáǹrẹrẹ, eré ìnàjú tí kò bójú mu, àti gbogbo ohun tí kò ‘fara mọ́ àwọn ẹ̀kọ́ afúnni-nílera.’ (Róòmù 1:26, 27; 1 Kọ́ríńtì 3:20; 1 Tímótì 6:3; 2 Tímótì 1:13) Nítorí ọ̀wọ̀ tá a ní fún ‘àwọn ẹ̀bùn tó jẹ́ ènìyàn,’ àwọn tó tóótun láti kọ́ wa ní ẹ̀kọ́ tó mọ́yán lórí, a óò máa fi tọkàntọkàn mọrírì ìsapá wọn, a ó sì máa fi tinútinú fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú wọn nínú rírọ̀ mọ́ ìlànà òdodo tó jẹ́ mímọ́ nípa ìwà híhù àti nípa tẹ̀mí, èyí tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.—Éfésù 4:7, 8, 11, 12; 1 Tẹsalóníkà 5:12, 13; Títù 1:9.

“Ẹ̀ta: Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni òbí, ohun tí a óò máa fi tọkàntọkàn sapá láti ṣe ni pé ká kọ́ àwọn ọmọ wa lẹ́kọ̀ọ́, kì í ṣe lọ́rọ̀ ẹnu nìkan, ṣùgbọ́n ní ìṣe pẹ̀lú. Ohun tó jẹ wá lógún ni láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ìgbà ọmọ ọwọ́ láti ‘mọ ìwé mímọ́, kí wọ́n lè di ọlọ́gbọ́n fún ìgbàlà.’ (2 Tímótì 3:15) A ò ní gbàgbé pé títọ́ wọn nínú ìbáwí àti ìrònú Jèhófà ni yóò jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wọn láti rí ìmúṣẹ ìlérí Ọlọ́run pé ‘nǹkan yóò lọ dáadáa fún wọn, wọn ó sì wà fún àkókò gígùn lórí ilẹ̀ ayé.’—Éfésù 6:1-4.

“Ẹ̀rin: Nígbà tá a bá dojú kọ àníyàn tàbí ìṣòro tó nípọn, ohun tí a óò kọ́kọ́ ṣe ni pé, ‘a óò sọ àwọn ohun tí a fẹ́ di mímọ̀ fún Ọlọ́run,’ pẹ̀lú ìdánilójú pé ‘àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú èèyàn yọ’ yóò máa ṣọ́ wa. (Fílípì 4:6, 7) A mọ̀ pé a óò rí ìtura, nítorí pé a wà lábẹ́ àjàgà Kristi. Níwọ̀n bí a ti mọ̀ pé Ọlọ́run bìkítà nípa wa, a óò múra tán láti kó àníyàn wa lé e.—Mátíù 11:28-30; 1 Pétérù 5:6, 7.

“Àrún: Láti fi hàn pé a mọrírì àǹfààní tí Jèhófà fún wa láti jẹ́ olùkọ́ni ní Ọ̀rọ̀ rẹ̀, a óò fi kún ìsapá wa láti ‘fi ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́ rẹ̀,’ a ó sì ‘ṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa ní kíkún.’ (2 Tímótì 2:15; 4:5) Níwọ̀n bí a ti mọ ohun tí èyí wé mọ́ ní àmọ̀dunjú, ohun tó jẹ wá lógún ni láti wá àwọn ẹni yíyẹ kàn, ká sì máa bomi rin irúgbìn tá a ti gbìn. Láfikún sí i, a óò túbọ̀ jára mọ́ ẹ̀kọ́ wa nípa dídarí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé púpọ̀ sí i lọ́nà tó gbámúṣé. Èyí yóò jẹ́ ká túbọ̀ máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, pé ‘kí gbogbo onírúurú ènìyàn lè rí ìgbàlà, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.’—1 Tímótì 2:3, 4.

“Ẹ̀fà: Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti fojú winá onírúurú àtakò àti inúnibíni ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀ ní gbogbo ọ̀rúndún tó kọjá àti ní ọ̀rúndún yìí. Ṣùgbọ́n Jèhófà wà lẹ́yìn wa. (Róòmù 8:31) Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí kò lè ṣàṣìṣe mú un dá wa lójú pé ‘kò sí ohun ìjà tí wọ́n bá ṣe sí wa’ láti fi dí wa lọ́wọ́ tàbí láti fi mú kí ọwọ́ wa rọ tàbí láti fi dáwọ́ iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà àti iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ náà dúró tí yóò kẹ́sẹ járí. (Aísáyà 54:17) A ò ní ṣíwọ́ sísọ òtítọ́, ì báà jẹ́ ní àkókò tí ó wọ̀ tàbí ní àkókò tí kò wọ̀. Ìpinnu wa ni láti ṣe iṣẹ́ ìwàásù àti iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ wa láṣeparí, láìfi falẹ̀ rárá. (2 Tímótì 4:1, 2) Ohun tí à ń lépa ni láti fi gbogbo okun wa kópa nínú wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fáwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè. Wọn ó sì tipa báyìí ní àǹfààní láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ètò tí a ṣe fún jíjèrè ìyè àìnípẹ̀kun nínú ayé tuntun òdodo. Gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ àwọn olùkọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó wà níṣọ̀kan, ìpinnu wa ni láti máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù Kristi, Olùkọ́ Ńlá náà, kí àwa náà sì ní irú àwọn ànímọ́ Ọlọ́run tó ní. A ó ṣe gbogbo èyí sí ọlá àti ìyìn Jèhófà Ọlọ́run, Olùkọ́ni wa Atóbilọ́lá àti Ẹni tó fún wa ní ìyè.

“Ǹjẹ́ kí gbogbo àwọn tó wà ní àpéjọ yìí, tó tẹ́wọ́ gba ìpinnu yìí jọ̀wọ́ sọ pé BẸ́Ẹ̀ NI!”

Nígbà tá a béèrè ìbéèrè tó kádìí ìpinnu náà lọ́wọ́ ọ̀kẹ́ mẹ́jọ [160,000] tó pé jọ sí àpéjọ mẹ́ta nílẹ̀ Faransé àti 289,000 tó pé jọ sí àpéjọ mẹ́sàn-án ní Ítálì, ṣe ni ìró “Bẹ́ẹ̀ Ni” milẹ̀ tìtì ní onírúurú èdè àwọn tó wà níbẹ̀.