Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

A Kì Í Dàgbà Jù Láti Kẹ́kọ̀ọ́

A Kì Í Dàgbà Jù Láti Kẹ́kọ̀ọ́

A Kì Í Dàgbà Jù Láti Kẹ́kọ̀ọ́

ỌDÚN 1897 ni wọ́n bí Kseniya. Ó lọ́mọbìnrin mẹ́ta, ọmọkùnrin kan, ọmọ-ọmọ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, àti ọmọ-ọmọ-ọmọ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n. Láti kékeré ló ti ń ṣe ohun tí àwọn òbí rẹ̀ kọ́ ọ pé kó ṣe. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Abkhaz tí ogun ti sọ di ẹdun arinlẹ̀, èyí tó wà láàárín Òkun Dúdú àti àgbègbè Caucasus ni obìnrin yìí ti wá sí Moscow gẹ́gẹ́ bí olùwá-ibi-ìsádi, síbẹ̀ ọkàn rẹ̀ balẹ̀, pàápàá jù lọ lórí ohun tó pè ní ẹ̀sìn àwọn baba ńlá òun.

Meri, ọmọbìnrin Kseniya di Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́dún 1993. Meri bẹ̀rẹ̀ sí bá Kseniya sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà Ọlọ́run àti Bíbélì, ṣùgbọ́n kò fẹ́ gbọ́. Ohun tí Kseniya ń sọ fún ọmọbìnrin rẹ̀ ni pé, “Mi ò lè ṣẹ̀ṣẹ̀ máa fi arúgbó ara kọ́ nǹkan tuntun o.”

Ṣùgbọ́n Meri, ọmọbìnrin rẹ̀; Londa, ìyàwó ọmọ-ọmọ rẹ̀; Nana àti Zaza, àwọn ọmọ-ọmọ-ọmọ rẹ̀, tí gbogbo wọ́n ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kò yéé bá Kseniya sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì. Lálẹ́ ọjọ́ kan lọ́dún 1999, wọ́n ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tó wú Kseniya lórí. Ọ̀rọ̀ tó wà níbẹ̀ ni ọ̀rọ̀ wíwọnilọ́kàn tí Jésù sọ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ olóòótọ́ nígbà tó ń dá Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa sílẹ̀. (Lúùkù 22:19, 20) Lẹ́ni ọdún méjì lé lọ́gọ́rùn-ún [102], Kseniya pinnu lálẹ́ ọjọ́ yẹn pé òun máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Kseniya sọ pé: “Lẹ́yìn tí mo ti lo ọdún méjì lé lọ́gọ́rùn-ún lókè eèpẹ̀ ni mo ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ ìtumọ̀ ìgbésí ayé. Mo wá mọ̀ báyìí pé kò sóhun tó dáa tó sísin Jèhófà Ọlọ́run wa ẹlẹ́bùrú ìkẹ́. Ọpọlọ mi ṣì jí pépé. Ara mi ṣì le koko. Mo lè kàwé láìlògò. Mi ò sì gbẹ́yìn nínú àwọn ìgbòkègbodò ìdílé wa.”

November 5, 2000, ni Kseniya ṣe batisí. Ó sọ pé: “Wàyí o, mo ti fi ayé mi fún Jèhófà láti máa sìn ín tìfẹ́tìfẹ́. Mo máa ń fi ìwé ìròyìn àti ìwé àṣàrò kúkúrú síta nígbà tí mo bá jókòó sí ibùdókọ̀ tó wà nítòsí ilé mi. Mo sì máa ń fi tayọ̀tayọ̀ kéde òtítọ́ nípa Jèhófà fún àwọn ẹbí mi nígbà tí wọ́n bá wá kí mi.”

Kseniya ń wọ̀nà fún ọjọ́ tí ‘ara rẹ̀ yóò jà yọ̀yọ̀ ju ti ìgbà èwe, tí yóò sì padà sí àwọn ọjọ́ okun ìgbà èwe rẹ̀.’ (Jóòbù 33:25) Bí ẹni tó ti lé lọ́gọ́rùn-ún ọdún bá gbà pé òun ò dàgbà jù láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìtumọ̀ ìgbésí ayé látinú Bíbélì, ìwọ ńkọ́?