Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Gbogbo Orílẹ̀-Èdè Ni Ọlọ́run Tẹ́wọ́ Gbà

Gbogbo Orílẹ̀-Èdè Ni Ọlọ́run Tẹ́wọ́ Gbà

Gbogbo Orílẹ̀-Èdè Ni Ọlọ́run Tẹ́wọ́ Gbà

BÍ MAMADOU àti ìdílé rẹ̀ ṣe ṣaájò John yà á lẹ́nu gan-an nígbà àkọ́kọ́ tó lọ sí Málì. Bí John ṣe jókòó sórí ilẹ̀, tó sì ń fi ìlọ́ra bá àwọn tó gbà á lálejò jẹun nínú abọ́ kan náà, ló ń ronú nípa ọ̀nà tó dára jù lọ tí òun fi lè bá onílé òun ṣàjọpín ẹ̀bùn tó dára jù lọ—ìyẹn ni ìhìn rere Ìjọba náà látinú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé John gbọ́ èdè Faransé, tí wọ́n ń sọ ní Málì, síbẹ̀ ó ń ronú bí òun ṣe máa bá ìdílé tí ẹ̀sìn wọn àti ọ̀nà tí wọ́n gbà ń ronú yàtọ̀ pátápátá sí tirẹ̀ sọ̀rọ̀.

Abájọ tí John fi ronú kan ìtàn tó wà nínú Bíbélì nípa ìlú Bábélì. Ibẹ̀ ni Ọlọ́run ti da èdè àwọn ọlọ̀tẹ̀ ènìyàn rú. (Jẹ́nẹ́sísì 11:1-9) Ìdí nìyẹn táwọn èèyàn tí èdè wọn yàtọ̀ síra, tí ẹ̀sìn wọn kò bára mu, tí ọ̀nà tí wọ́n gbà ń ronú kò sì rí bákan náà rárá fi wà ní apá ibi púpọ̀ lórí ilẹ̀ ayé. Lóde òní, tí rírin ìrìn àjò àti ṣíṣí láti ibì kan lọ síbòmíràn ti wá wọ́pọ̀ gan-an, ọ̀pọ̀ ló ń dojú kọ irú ìṣòro tí John dojú kọ, kódà ládùúgbò tiwọn fúnra wọn. Ìṣòro yẹn ni: Báwo ni wọ́n ṣe lè sọ ìrètí wọn tá a gbé ka Bíbélì fún àwọn tó ti ibòmíràn wá?

Àpẹẹrẹ Ìgbàanì

Bíi ti àwọn wòlíì mìíràn ní Ísírẹ́lì, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni Jónà bá sọ̀rọ̀ ní pàtàkì. Ó sàsọtẹ́lẹ̀ lákòókò tí ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá tó jẹ́ apẹ̀yìndà ń ṣe àwọn ohun tó tàbùkù sí Ọlọ́run láìfi bò. (2 Àwọn Ọba 14:23-25) Fojú inú wo ìṣarasíhùwà Jónà nígbà tá a fún ní àkànṣe iṣẹ́ náà pé kó fi orílẹ̀-èdè rẹ̀ sílẹ̀, kí ó lọ sí Ásíríà láti lọ wàásù fún àwọn olùgbé Nínéfè, ìyẹn àwọn èèyàn tí ìsìn àti àṣà wọn yàtọ̀ pátápátá sí tirẹ̀. Jónà lè má tiẹ̀ gbọ́ èdè Nínéfè rárá, tó bá sì gbọ́ ọ, ó lè má mọ̀ ọ́n sọ dáadáa. Bó ti wù kó rí, Jónà rí i pé iṣẹ́ yẹn kọjá agbára òun, ó sì fẹsẹ̀ fẹ.—Jónà 1:1-3.

Dájúdájú, ó yẹ kí Jónà mọ̀ pé ojú kọ́ ni Jèhófà Ọlọ́run ń wò, bí kò ṣe ohun tó wà nínú ọkàn. (1 Sámúẹ́lì 16:7) Lẹ́yìn tí Jèhófà fi iṣẹ́ ìyanu gba Jónà là nínú omi tí ì bá kú sí, ó tún pàṣẹ fún un lẹ́ẹ̀kejì pé kó lọ wàásù fún àwọn olùgbé Nínéfè. Jónà ṣègbọràn lọ́tẹ̀ yìí, ìwàásù rẹ̀ sì mú kí àwọn olùgbé Nínéfè ronú pìwà dà lápapọ̀. Síbẹ̀, Jónà kò ní ojú ìwòye tó tọ̀nà. Jèhófà wá kọ́ ọ ní ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n kan tó lágbára, kó lè mọ̀ pé òun ní láti yí ìṣarasíhùwà òun padà. Jèhófà bi Jónà pé: “Kò ha sì yẹ kí n káàánú fún Nínéfè ìlú ńlá títóbi nì, inú èyí tí àwọn ènìyàn tí ó ju ọ̀kẹ́ mẹ́fà wà, tí wọn kò mọ ìyàtọ̀ rárá láàárín ọwọ́ ọ̀tún wọn àti òsì wọn?” (Jónà 4:5-11) Àwa náà ńkọ́ lónìí? Báwo la ṣe lè ran àwọn èèyàn tí ipò àtilẹ̀wá wọn yàtọ̀ sí tiwa lọ́wọ́?

Títẹ́wọ́gba Àwọn Ará Samáríà Àtàwọn Tí Kì Í Ṣe Júù

Ní ọ̀rúndún kìíní, Jésù pàṣẹ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn. (Mátíù 28:19) Èyí kò rọrùn fún wọn. Júù làwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù. Kìkì àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè kan náà, tí àṣà ìbílẹ̀ wọ́n sì bára mu ní wọ́n máa ń bá sọ̀rọ̀, bó ṣe rí ní ti Jónà. Bó ṣe sábà máa ń rí, ẹ̀tanú tó gbòde kan lákòókò yẹn ti ní láti dáyà fo àwọn náà. Àmọ́, Jèhófà darí ọ̀ràn náà, kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé lè fòye mọ ohun tó jẹ́ ìfẹ́ rẹ̀ fún wọn.

Ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ ni láti ṣẹ́pá ẹ̀tanú tó wà láàárín àwọn Júù àtàwọn ará Samáríà. Àwọn Júù kì í bá àwọn ará Samáríà ṣe pọ̀ rárá. Síbẹ̀, kì í ṣe ẹ̀ẹ̀kan péré ni Jésù la ọ̀nà sílẹ̀ fún àwọn ará Samáríà láti tẹ́wọ́ gba ìhìn rere náà lọ́jọ́ iwájú. Ó fi hàn pé òun kì í ṣe ojúsàájú nípa bíbá obìnrin ará Samáríà kan sọ̀rọ̀. (Jòhánù 4:7-26) Ní àkókò mìíràn, ó lo àkàwé ará Samáríà tó jẹ́ aládùúgbò rere láti fi han Júù kan tó jẹ́ olùfọkànsìn pé àwọn èèyàn tí kì í ṣe Júù náà lè nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò wọn. (Lúùkù 10:25-37) Nígbà tí àkókò tó fún Jèhófà láti mú àwọn ará Samáríà wá sínú ìjọ Kristẹni, Fílípì, Pétérù, àti Jòhánù—tí gbogbo wọn jẹ́ Júù—wàásù fún àwọn olùgbé Samáríà. Ìhìn wọn sì yọrí sí ayọ̀ ńlá ní ìlú yẹn.—Ìṣe 8:4-8, 14-17.

Tó bá ṣòro fáwọn Kristẹni tó jẹ́ Júù láti nífẹ̀ẹ́ àwọn ará Samáríà, tí wọ́n tan díẹ̀ mọ́ àwọn Júù, ó ti ní láti ṣòro fún wọn gan-an láti fi ìfẹ́ aládùúgbò hàn sáwọn tí kì í ṣe Júù, tàbí àwọn Kèfèrí, táwọn Júù kórìíra bí ìgbẹ́, tí wọn kì í sì í fẹ́ẹ́ rí ìmí wọn lákìtàn. Síbẹ̀síbẹ̀, lẹ́yìn ikú Jésù, ó ṣeé ṣe láti mú ìdènà tó wà láàárín àwọn Kristẹni tó jẹ́ Júù àtàwọn Kèfèrí kúrò. (Éfésù 2:13, 14) Láti ran Pétérù lọ́wọ́ kó lè tẹ́wọ́ gba ìṣètò tuntun yìí, Jèhófà fi ìran kan hàn án, nínú èyí tí Ó ti sọ fún un pé kí ó “dẹ́kun pípe ohun tí Ọlọ́run ti wẹ̀ mọ́ ní ẹlẹ́gbin.” Ẹ̀mí Jèhófà wá darí rẹ̀ lọ sọ́dọ̀ Kèfèrí kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kọ̀nílíù. Nígbà tí Pétérù lóye ojú ìwòye Ọlọ́run—pé òun kò gbọ́dọ̀ pe ọkùnrin yìí tí ó wá látinú àwọn orílẹ̀-èdè ní ẹlẹ́gbin nítorí pé Ọlọ́run ti wẹ̀ ẹ́ mọ́—ó wá sọ lábẹ́ ìmísí pé: “Dájúdájú, mo róye pé Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.” (Ìṣe 10:9-35) Ẹ wo bó ṣe ṣe Pétérù ní kàyéfì tó nígbà tí Ọlọ́run fi hàn pé òun tẹ́wọ́ gba Kọ̀nílíù àti ìdílé rẹ̀ nípa títú ẹ̀mí mímọ́ dà sórí wọn!

Pọ́ọ̀lù—Ohun Èlò Tí A Yàn Láti Lọ Jíṣẹ́ fún Àwọn Orílẹ̀-Èdè

Iṣẹ́ òjíṣẹ́ Pọ́ọ̀lù jẹ́ àpẹẹrẹ títayọ nípa bí Jèhófà ṣe ń múra àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé láti nífẹ̀ẹ́ onírúurú ènìyàn, kí wọ́n sì ràn wọ́n lọ́wọ́. Ní àkókò tí a yí Pọ́ọ̀lù lọ́kàn padà, Jésù sọ pé Pọ́ọ̀lù yóò sìn gẹ́gẹ́ bí ohun èlò láti gbé orúkọ Òun lọ sọ́dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè. (Ìṣe 9:15) Pọ́ọ̀lù wá kọrí sí Arébíà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ nítorí àtilọ ṣàṣàrò lórí ète Ọlọ́run láti lò ó nínú kíkéde ìhìn rere fún àwọn orílẹ̀-èdè.—Gálátíà 1:15-17.

Nínú ìrìn àjò míṣọ́nnárì tí Pọ́ọ̀lù kọ́kọ́ lọ, ó fi ìtara wàásù fún àwọn tí kì í ṣe Júù. (Ìṣe 13:46-48) Jèhófà bù kún ìgbòkègbodò Pọ́ọ̀lù, tó fi hàn pé àpọ́sítélì náà ń ṣe àwọn nǹkan ní ìbámu pẹ̀lú ìṣètò Jèhófà. Pọ́ọ̀lù fi hàn pé òun lóye ojú ìwòye Ọlọ́run dáadáa nígbà tó fi ìgboyà bá Pétérù wí, nígbà tó fi ojúsàájú yẹra fún àwọn ará tí kì í ṣe Júù.—Gálátíà 2:11-14.

Ẹ̀rí mìíràn tó fi hàn pé Ọlọ́run ló ń darí ìsapá Pọ́ọ̀lù la rí nínú ìrìn àjò rẹ̀ ẹlẹ́ẹ̀kejì, nígbà tí ẹ̀mí mímọ́ kò gba Pọ́ọ̀lù láyè láti wàásù ní ẹkùn ìpínlẹ̀ Róòmù tí à ń pè ní Bítíníà. (Ìṣe 16:7) Àkókò àtilọ síbẹ̀ kọ́ nìyẹn. Àmọ́ ṣá o, nígbà tó yá, àwọn kan lára àwọn ará Bítíníà di Kristẹni. (1 Pétérù 1:1) Nínú ìran kan, ará Makedóníà kan ń pàrọwà fún Pọ́ọ̀lù pé: “Ré kọjá wá sí Makedóníà, kí o sì ràn wá lọ́wọ́.” Pọ́ọ̀lù wá dé ìparí èrò náà pé òun á yí ìrìn àjò òun padà kí òun lè lọ polongo ìhìn rere náà ní ẹkùn ìpínlẹ̀ Róòmù yẹn.—Ìṣe 16:9, 10.

Bí Pọ́ọ̀lù ṣe mọ ọwọ́ yí padà sí hàn kedere nígbà tó wàásù fún àwọn ará Áténì. Òfin Gíríìkì àti ti Róòmù kò fàyè gba àṣà sísọ̀rọ̀ nípa àwọn ọlọ́run àjèjì àti fífi ìsìn tuntun kọ́ni. Ìfẹ́ tí Pọ́ọ̀lù ní sáwọn èèyàn sún un láti fara balẹ̀ kíyè sí ìlànà ẹ̀sìn wọn. Ní Áténì, ó rí pẹpẹ kan tí a kọ “sí Ọlọ́run Àìmọ̀” sí lára. Ó lo ohun tó rí yìí nínú iṣẹ́ ìwàásù rẹ̀. (Ìṣe 17:22, 23) Ẹ ò rí i pé bó ṣe fi inú rere àti ìtẹríba bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí dára gan-an!

Ẹ wo bí inú Pọ́ọ̀lù ti ní láti dùn tó nígbà tó bá ń rántí àwọn àṣeyọrí iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì sí àwọn orílẹ̀-èdè! Ó ṣèrànwọ́ láti dá àwọn ìjọ tó kún fún ọ̀pọ̀ Kristẹni tí kì í ṣe Júù sílẹ̀ ní Kọ́ríńtì, ìlú Fílípì, Tẹsalóníkà, àtàwọn ìlú tó wà ní Gálátíà. Ó ran àwọn ọkùnrin àtobìnrin ìgbàgbọ́ lọ́wọ́, àwọn bíi Dámárì, Díónísíù, Sájíọ́sì Pọ́lọ́sì, àti Títù. Àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ gbáà lèyí, pé ó mú kí àwọn èèyàn tí kò mọ Jèhófà tàbí Bíbélì pàápàá tẹ́wọ́ gba òtítọ́ Kristẹni! Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa ipa tóun kó nínú ríran àwọn tí kì í ṣe Júù lọ́wọ́ láti wá sínú ìmọ̀ òtítọ́, ó sọ pé: “Lọ́nà yìí, ní tòótọ́, mo fi í ṣe ìfojúsùn mi láti má ṣe polongo ìhìn rere níbi tí a bá ti dárúkọ Kristi tẹ́lẹ̀, . . . ṣùgbọ́n, gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: ‘Àwọn tí a kò tíì ṣe ìkéde kankan fún nípa rẹ̀ yóò rí i, àwọn tí kò sì tíì gbọ́ yóò lóye.’” (Róòmù 15:20, 21) Ǹjẹ́ àwa náà lè kópa nínú pípolongo ìhìn rere náà fáwọn tí àṣà wọn yàtọ̀ sí tiwa?

Ríran Gbogbo Èèyàn Orí Ilẹ̀ Ayé Lọ́wọ́

Sólómọ́nì gbàdúrà sí Jèhófà nípa àwọn tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì tó máa wá jọ́sìn ní tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù. Ó bẹ̀bẹ̀ pé: “Kí ìwọ alára fetí sílẹ̀ láti ọ̀run, ibi àfìdímúlẹ̀ tí o ń gbé, kí o sì ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí ọmọ ilẹ̀ òkèèrè náà ké pè ọ́ sí; kí gbogbo ènìyàn ilẹ̀ ayé lè wá mọ orúkọ rẹ.” (1 Àwọn Ọba 8:41-43) Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn olùpòkìkí Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè lónìí ló gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yẹn. Wọ́n ń bá àwọn èèyàn tó dà bí àwọn ará Nínéfè pàdé, ìyẹn àwọn tí ‘kò mọ ìyàtọ̀ láàárín ọwọ́ ọ̀tún wọn àti òsì wọn’ nípa tẹ̀mí. Àwọn oníwàásù Ìjọba náà sì ń hára gàgà láti kópa nínú ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ tó ní í ṣe pẹ̀lú kíkó àwọn olùjọ́sìn tòótọ́ jọ látinú onírúurú orílẹ̀-èdè.—Aísáyà 2:2, 3; Míkà 4:1-3.

Gẹ́gẹ́ bí àwọn tó ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì ṣe tẹ́wọ́ gba ìhìn Bíbélì tó ń fúnni nírètí, àwọn tó tinú ẹ̀sìn mìíràn wá náà ń ṣe bẹ́ẹ̀. Báwo ló ṣe yẹ kí èyí kan ìwọ alára? Yẹ ara rẹ wò dáadáa. Tó o bá rí i pé ẹ̀tanú ti ta gbòǹgbò sọ́kàn rẹ̀, fi ìfẹ́ mú un kúrò. a Má ṣe kọ àwọn èèyàn tí Ọlọ́run múra tán láti tẹ́wọ́ gbà.—Jòhánù 3:16.

Ṣe ìwádìí kó o tó bá àwọn tí àṣà wọn yàtọ̀ sí tìrẹ sọ̀rọ̀. Mọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́, mọ ohun tó jẹ wọ́n lógún, àti ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ronú; lẹ́yìn náà ronú nípa ibi tí èdè yín ti lè yéra. Fi inú rere àti ìyọ́nú hàn sí àwọn ẹlòmíràn. Yẹra fún iyàn jíjà, má ṣe rin kinkin pé tìrẹ ni wọ́n gbọ́dọ̀ gbà, kí ó sì máa gbé wọn ró. (Lúùkù 9:52-56) Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, wàá máa múnú Jèhófà dùn, “ẹni tí ó jẹ́ ìfẹ́ rẹ̀ pé kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.”—1 Tímótì 2:4.

Inú wa mà dùn o, pé àwọn èèyàn tí ipò àtilẹ̀wá wọ́n yàtọ̀ síra lónírúurú ọ̀nà wà nínú ìjọ wa! (Aísáyà 56:6, 7) Ẹ wo bó ṣe ń múnú wa dùn tó lóde oní láti máa gbọ́ àwọn orúkọ tí kì í ṣe Mary, John, Stephen, àti Tom nìkan, àmọ́ tá a tún ń gbọ́ àwọn orúkọ mìíràn bíi Mamadou, Jegan, Reza, àti Chan! Ká sọ tòótọ́, “ilẹ̀kùn ńlá tí ń ṣamọ̀nà sí ìgbòkègbodò ni a ti ṣí sílẹ̀” fún wa. (1 Kọ́ríńtì 16:9) Ǹjẹ́ kí a lo gbogbo àǹfààní tó bá yọjú láti polongo ìkésíni tí Jèhófà, Ọlọ́run tí kì í ṣojúsàájú, nawọ́ rẹ̀ sáwọn èèyàn, ká sì tẹ́wọ́ gba àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè!

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo Jí!, July 8, 1996, ojú ìwé 5 sí 7, “Àwọn Ògiri Ìdènà Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀.”

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Mímọ bí a ṣe ń yíwọ́ padà mú kí Pọ́ọ̀lù sọ ìhìn rere náà fún àwọn èèyàn níbi gbogbo

. . ní Áténì

. . nílùú Fílípì

. . nígbà tó ń rìnrìn àjò