Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ǹjẹ́ ó tọ́ láti gbàdúrà sí Ọlọ́run láìlo gbólóhùn bíi “ní orúkọ Jésù”?

Bíbélì sọ pé àwọn Kristẹni tó bá fẹ́ tọ Ọlọ́run lọ nínú àdúrà gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ ní orúkọ Jésù. Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Kò sí ẹni tí ń wá sọ́dọ̀ Baba bí kò ṣe nípasẹ̀ mi.” Ó fi kún un pé: “Ohun yòówù kí ó jẹ́ tí ẹ bá béèrè ní orúkọ mi, èmi yóò ṣe èyí dájúdájú, kí a lè yin Baba lógo ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Ọmọ. Bí ẹ bá béèrè ohunkóhun ní orúkọ mi, èmi yóò ṣe é dájúdájú.”—Jòhánù 14:6, 13, 14.

Nígbà tí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Cyclopedia of Biblical, Theological, and Ecclesiastical Literature ń tọ́ka sí ipò aláìlẹ́gbẹ́ tí Jésù wà, ó sọ pé: “Ọlọ́run nìkan ṣoṣo là ń gbàdúrà sí, nípasẹ̀ Jésù Kristi gẹ́gẹ́ bí Alárinà. Nítorí náà, kì í ṣe kìkì pé gbogbo ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí àwọn ẹni mímọ́ tàbí àwọn áńgẹ́lì jẹ́ òtúbáńtẹ́ nìkan ni, àmọ́ irú ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ bẹ́ẹ̀ tún jẹ́ ọ̀rọ̀ òdì pẹ̀lú. Gbogbo jíjọ́sìn ẹ̀dá, bó ti wù kí ẹ̀dà náà ga lọ́lá tó, jẹ́ ìbọ̀rìṣà, a sì kà á léèwọ̀ pátápátá nínú òfin mímọ́ ti Ọlọ́run.”

Bí nǹkan ayọ̀ bá ṣẹlẹ̀ sẹ́nì kan, tó wá sọ pé, “O ṣé o, Jèhófà” láìfi “ní orúkọ Jésù” kún un ńkọ́? Ǹjẹ́ èyí lòdì? Kò fi dandan rí bẹ́ẹ̀. Ká ní Kristẹni kan pàdé ewu òjijì, tó wá kígbe pé: “Gbà mí o, Jèhófà!” Ó dájú pé Jèhófà kò ní kọ̀ láti ṣèrànwọ́ nítorí pé ìránṣẹ́ rẹ̀ kò sọ pé “ní orúkọ Jésù.”

Àmọ́ ṣá o, a tún gbọ́dọ̀ mọ̀ pé wíwulẹ̀ gbóhùn sókè sí Ọlọ́run pàápàá, kò túmọ̀ sí àdúrà. Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tí Jèhófà dájọ́ fún Kéènì nítorí pípa tí ó pa Ébẹ́lì, àbúrò rẹ̀, Kéènì sọ pé: “Ìyà ìṣìnà mi pọ̀ jù fún mi láti rù. Kíyè sí i, ìwọ ní ti tòótọ́ ń lé mi ní òní yìí kúrò ní ojú ilẹ̀, a ó sì fi mí pa mọ́ kúrò ní ojú rẹ; èmi yóò sì di alárìnká àti ìsáǹsá lórí ilẹ̀ ayé, ó sì dájú pé ẹnikẹ́ni tí ó bá rí mi yóò pa mí.” (Jẹ́nẹ́sísì 4:13, 14) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ni Kéènì ń bá sọ̀rọ̀, síbẹ̀ ńṣe ló ń ṣàròyé nípa èso búburú tí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mú jáde.

Bíbélì sọ fún wa pé: “Ọlọ́run kọ ojú ìjà sí àwọn onírera, ṣùgbọ́n ó fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí fún àwọn onírẹ̀lẹ̀.” Ó dájú pé bíbá Ẹni Gíga Jù Lọ sọ̀rọ̀ bí ẹni pé ènìyàn lásán là ń bá sọ̀rọ̀ yóò fi àìní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ hàn. (Jákọ́bù 4:6; Sáàmù 47:2; Ìṣípayá 14:7) Bákan náà ni yóò jẹ́ ìwà àìlọ́wọ̀, tá a bá mọ ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ nípa ipa tí Jésù kó, síbẹ̀ tá a mọ̀ọ́mọ̀ ń gbàdúrà láìlo orúkọ Jésù Kristi.—Lúùkù 1:32, 33.

Èyí kò túmọ̀ sí pé Jèhófà fẹ́ ká tẹ̀ lé àṣà kan pàtó tàbí ká ní àwọn ọ̀rọ̀ kan tá a gbọ́dọ̀ máa sọ nígbà tá a bá ń gbàdúrà. Ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ ni bí ọkàn ẹnì kan ṣe rí. (1 Sámúẹ́lì 16:7) Ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa, ọ̀gá ẹgbẹ́ ọmọ ogun Róòmù kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kọ̀nílíù “ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Ọlọ́run nígbà gbogbo.” Kọ̀nílíù, tó jẹ́ Kèfèrí aláìdádọ̀dọ́, kò ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè má gba àwọn àdúrà rẹ̀ ní orúkọ Jésù, síbẹ̀ wọ́n “gòkè gẹ́gẹ́ bí ìrántí lọ síwájú Ọlọ́run.” Kí nìdí? Nítorí pé “olùṣàyẹ̀wò àwọn ọkàn-àyà” rí i pé Kọ̀nílíù jẹ́ “olùfọkànsìn àti ẹnì kan tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run.” (Ìṣe 10:2, 4; Òwe 17:3) Nígbà tí Kọ̀nílíù gba ìmọ̀ “Jésù tí ó wá láti Násárétì,” ó gba ẹ̀mí mímọ́, ó sì di ọmọ ẹ̀yìn Jésù tó ṣe batisí.—Ìṣe 10:30-48.

Ní àbárèbábọ̀, èèyàn kọ́ ló máa pinnu irú àdúrà tí Ọlọ́run ń gbọ́. Tó bá ṣẹlẹ̀ pé Kristẹni kan bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ nígbà kan, tí kò sì lo gbólóhùn bíi “ní orúkọ Jésù,” kò sídìí fún dídá ara rẹ̀ lẹ́bi. Jèhófà mọ ibi tí agbára wa mọ, ó sì fẹ́ ràn wá lọ́wọ́. (Sáàmù 103:12-14) Ọkàn wa lè balẹ̀ pé tá a bá lo ìgbàgbọ́ nínú “Ọmọ Ọlọ́run . . . , ohun yòówù tí ì báà jẹ́ tí a bá béèrè ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ̀, ó ń gbọ́ tiwa.” (1 Jòhánù 5:13, 14) Àmọ́, nígbà tá a bá ń ṣáájú ọ̀pọ̀ èèyàn nínú àdúrà, àwọn Kristẹni tòótọ́ máa ń fi hàn pé àwọn mọ ipa tí Ìwé Mímọ́ sọ pé Jésù kó nínú ète Jèhófà. Wọ́n sì máa ń fi ìgbọràn gbìyànjú láti bọ̀wọ̀ fún Jésù nípa dídarí àdúrà sí Ọlọ́run nípasẹ̀ rẹ̀.