Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìgbà Tó Bọ́gbọ́n Mu Láti Sá

Ìgbà Tó Bọ́gbọ́n Mu Láti Sá

Ìgbà Tó Bọ́gbọ́n Mu Láti Sá

Ẹ̀MÍ ìṣàyàgbàǹgbà àti àtakò tàbí àwọn ipò tó ń dẹni wò ló wọ́pọ̀ jù lọ láyé òde òní. Ọ̀lẹ tàbí ojo làwọn èèyàn máa ń pe ẹni tó bá sá kúrò níbi tí nǹkan kò ti bára dé. Ó tiẹ̀ lè dẹni tí wọ́n ń fi ṣẹlẹ́yà pàápàá.

Àmọ́, Bíbélì mú un ṣe kedere pé àwọn ìgbà kan wà tí sísá lọ jẹ́ ìwà ọgbọ́n, tó sì fi hàn pé onítọ̀hún nígboyà. Kẹ́ ẹ lè mọ pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí, kí Jésù Kristi tó rán àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ jáde sínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà, ó sọ fún wọn pé: “Nígbà tí wọ́n bá ṣe inúnibíni sí yín ní ìlú ńlá kan, ẹ sá lọ sí òmíràn.” (Mátíù 10:23) Bẹ́ẹ̀ ni o, àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ní láti wá ọ̀nà tí wọ́n máa gbà bọ́ lọ́wọ́ àwọn tó ń ṣe inúnibíni sí wọn. Wọn ò gbọ́dọ̀ ja ogun ẹ̀sìn kankan, ìyẹn ni pé kí wọ́n máa gbìyànjú àtifi tipátipá yí àwọn ẹlòmíràn lọ́kàn padà. Iṣẹ́ àlàáfíà ni wọ́n ń jẹ́ fáwọn èèyàn. (Mátíù 10:11-14; Ìṣe 10:34-37) Nítorí náà, dípò tí wọ́n fi máa fàbínú yọ, sísá làwọn Kristẹni máa ń sá kúrò níbi tọ́rọ̀ ìbínú bá ti wáyé. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n á ní ẹ̀rí ọkàn rere, àjọṣe gbígbámúṣé àárín àwọn àti Jèhófà kò sì ní bà jẹ́.—2 Kọ́ríńtì 4:1, 2.

Àpẹẹrẹ tó yàtọ̀ pátápátá sí èyí la rí nínú ìwé Òwe inú Bíbélì. Ó sọ nípa ọ̀dọ́kùnrin kan, tó jẹ́ pé kàkà tí ì bá fi sá nígbà tó rí ìdẹwò, ńṣe ló ń tẹ̀ lé aṣẹ́wó kan lọ gọ̀ọ́gọ̀ọ́ “bí akọ màlúù tí ń bọ̀ àní fún ìfikúpa.” Kí ni àbájáde rẹ̀? Àjálù ni, nítorí pé ó jọ̀wọ́ ara rẹ̀ fún ìdẹwò tó wé mọ́ ìwàláàyè rẹ̀ gan-an.—Òwe 7:5-8, 21-23.

Tó o bá dojú kọ ìdẹwò láti lọ́wọ́ sí ìwà àìmọ́ takọtabo tàbí láti ṣe àwọn nǹkan míì tó léwu ńkọ́? Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wí, ohun tó bọ́gbọ́n mu jù ni fífẹsẹ̀ fẹ, ìyẹn ni pé kó o sá kúrò níbẹ̀ lójú ẹsẹ̀.—Òwe 4:14, 15; 1 Kọ́ríńtì 6:18; 2 Tímótì 2:22.