Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ibo Lo Ti Lè Rí Ìfọ̀kànbalẹ̀?

Ibo Lo Ti Lè Rí Ìfọ̀kànbalẹ̀?

Ibo Lo Ti Lè Rí Ìfọ̀kànbalẹ̀?

Ní abúlé kékeré kan ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà, Josué tó jẹ́ ọ̀dọ́ juwọ́ sí àwọn ẹbí àtọ̀rẹ́ rẹ̀ pé ó dìgbóṣe. a Bó ṣe forí lé ìlú ńlá nìyẹn, tó wá owó lọ. Àmọ́, kò pẹ́ tó débẹ̀ tó fi rí i pé gbogbo ohun tó ń dán kọ́ ni wúrà.

GBOGBO nǹkan wá tojú sú Josué bó ṣe ń tiraka láti jẹ́ kí ìlú ńlá bá òun lára mu. Bí ìlú ńlá náà ṣe rí yàtọ̀ pátápátá sí bó ṣe rò pé ó máa rí. Ní gbogbo àkókò yẹn, ohun tó wu Josué láti ṣe ni pé kó padà sọ́dọ̀ àwọn ẹbí àtọ̀rẹ́ rẹ̀ lábúlé kékeré tó fi sílẹ̀. Ṣùgbọ́n ó ń bẹ̀rù pé àwọn kan lábúlé yóò fi òun ṣe ẹlẹ́yà. Ó ń dààmú pé: ‘Wọ́n a sọ pé aláṣetì ni mí, nítorí pé mi ò rí towó ṣe nílùú ńlá.’

Èyí tó tiẹ̀ tún ká a lára jù lọ ní bí ọ̀rọ̀ náà ṣe máa dun àwọn òbí rẹ̀ tó. Wọ́n ti gbé gbogbo ara lé e pé òun ló máa bá àwọn gbọn ìyà nù. Bí ìrònú yìí ṣe dorí Josué kodò, ló rí iṣẹ́ kan táwọn èèyàn ò kà kún rárá. Gbogbo àkókò rẹ̀ niṣẹ́ yìí ń gbà, owó tí wọ́n sì ń san fún un kéré gan-an sí iye tó ń retí. Iṣẹ́ àṣekúdórógbó yìí máa ń jẹ́ kó rẹ̀ ẹ́ tẹnutẹnu. Bí ọ̀sẹ̀ sì ti ń gorí ọ̀sẹ̀ ni ìgbòkègbodò Kristẹni tí kì í fi ṣeré rárá bẹ̀rẹ̀ sí í jó àjórẹ̀yìn. Nítorí pé ọ̀nà rẹ̀ jìn sí àwọn ẹbí àtọ̀rẹ́ tí ì bá máa dá a lára yá, inú rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí bà jẹ́, kò sì ní alábàárò kankan. Ó rí i pé ìlú ńlá náà kò fún òun ní ìfọ̀kànbalẹ̀ tí òun ń wá.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé orúkọ èèyàn àti ti ìlú yàtọ̀ síra, síbẹ̀ ìrírí búburú tí Josué ní yìí kò ṣàjèjì rárá. Kì í ṣe pé ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan ló mú kí Josué filé sílẹ̀—ó wulẹ̀ ń wá ìfọ̀kànbalẹ̀ ni. Ó sì fi tọkàntọkàn gbà pé òun á lè rọ́wọ́ mú nílùú ńlá ju abúlé rẹ̀ kékeré lọ. Lóòótọ́, àwọn ìgbà mìíràn wà tí nǹkan lè ṣẹnuure fún ẹnì kan, àmọ́ ìyẹn ò túmọ̀ sí ojúlówó ìfọ̀kànbalẹ̀. Ó dájú pé kò rí bẹ́ẹ̀ fún Josué, bẹ́ẹ̀ náà ló lè máà rí bẹ́ẹ̀ fún ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn mìíràn tó gbìyànjú àtiṣe bákan náà. Èyí ló wá jẹ́ ká béèrè pé, ‘Kí ni ìfọ̀kànbalẹ̀?’

Ojú ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni onírúurú èèyàn fi ń wo ohun tí à ń pè ní ìfọ̀kànbalẹ̀. Ìwé atúmọ̀ èdè kan sọ pé ìfọ̀kànbalẹ̀ jẹ́ “bíbọ́ lọ́wọ́ ewu” tàbí “bíbọ́ lọ́wọ́ ẹ̀rù tàbí hílàhílo.” Ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn ló mọ̀ pé kò sóhun tó ń jẹ́ “bíbọ́ lọ́wọ́ ewu” pátápátá láyé òde òní. Bí ọkàn wọn bá ṣáà ti balẹ̀, àbùṣe ti bùṣe, láìfi ipò ìjayà tó ṣeé ṣe kó yí wọn ká pè.

Ìwọ ńkọ́? Ibo lo rò pé o ti lè rí ìfọ̀kànbalẹ̀? Ṣé ìlú ńlá ni ìfọ̀kànbalẹ̀ wà, tí kò sí ní abúlé bí èrò Josué? Tàbí ṣé owó ló ń fini lọ́kàn balẹ̀, láìka ibi tó o ti rí i tàbí ọ̀nà tó o gbà rí i sí? Àbí ó lè jẹ́ pé dídi ẹni ńlá láwùjọ ló ń fini lọ́kàn balẹ̀? Ibi yòówù kó o rò pé o ti lè rí ìfọ̀kànbalẹ̀, báwo ni ìwọ àti ìdílé rẹ ṣe lè gbádùn ìfọ̀kànbalẹ̀ yẹn pẹ́ tó?

Ẹ jẹ́ ká gbé ọ̀nà mẹ́ta táwọn èèyàn gbà ń wá ìfọ̀kànbalẹ̀ yẹ̀ wò—ibi téèyàn ń gbé; owó; ipò. Lẹ́yìn ìyẹn, a óò wá ṣàyẹ̀wò ibi tá a ti lè rí ojúlówó ìfọ̀kànbalẹ̀ tó wà pẹ́ títí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí orúkọ rẹ̀ padà.