Máa Fi Àwọn Ìlànà Ọlọ́run Tọ́ Ìṣísẹ̀ Ara Rẹ
Máa Fi Àwọn Ìlànà Ọlọ́run Tọ́ Ìṣísẹ̀ Ara Rẹ
“[Jèhófà] ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní.”—AÍSÁYÀ 48:17.
1. Báwo ni Ẹlẹ́dàá ṣe ń darí ẹ̀dá ènìyàn?
BÁWỌN onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti ń làkàkà láti mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa àgbáyé, háà ń ṣe wọ́n nípa agbára tó gadabú tó kún inú àgbáyé tó yí wa ká. Oòrùn wa—tó jẹ́ ìràwọ̀ alábọ́ọ́dé—ń tú àgbáàràgbá iná jáde, èyí tó tó “ọgọ́rùn-ún bílíọ̀nù bọ́ǹbù hydrogen tó ń bú gbàù ní ìṣẹ́jú àáyá kọ̀ọ̀kan.” Agbára ńlá ń bẹ níkàáwọ́ Ẹlẹ́dàá láti fi darí àwọn ohun mùmùrara tó dá sójú ọ̀run wọ̀nyí. (Jóòbù 38:32; Aísáyà 40:26) Àwa ẹ̀dá ènìyàn tá a ní ẹ̀bùn òmìnira láti ṣe ohun tó wù wá, ẹ̀bùn ìlànà ìwà rere, làákàyè, àti ẹ̀bùn láti mòye àwọn nǹkan tẹ̀mí ńkọ́? Ọ̀nà wo ni Ẹlẹ́dàá wa gbà ń darí wa? Ó ń fi tìfẹ́tìfẹ́ ṣamọ̀nà wa nípasẹ̀ àwọn òfin pípé àtàwọn ìlànà gíga rẹ̀ àti nípasẹ̀ ẹ̀rí ọkàn wa tá a ti kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ dáadáa.—2 Sámúẹ́lì 22:31; Róòmù 2:14, 15.
2, 3. Irú ìgbọràn wo ló máa ń múnú Ọlọ́run dùn?
2 Inú Ọlọ́run máa ń dùn sí àwọn ẹ̀dá onílàákàyè tó yàn láti ṣègbọràn sí i. (Òwe 27:11) Dípò kí Jèhófà ṣe wá ní ẹ̀dá aláìlóye tí a óò máa tì síbí tì sọ́hùn-ún bí ẹ̀rọ bọrọgidi tí kò lè rorí, ó fún wa ní òmìnira láti lo làákàyè wa, ká sì pinnu àtiṣe ohun tó tọ́.—Hébérù 5:14.
3 Jésù, tó fìwà jọ Baba rẹ̀ láìkù síbì kan, sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ọ̀rẹ́ mi ni yín, bí ẹ bá ń ṣe ohun tí mo ń pa láṣẹ fún yín. Èmi kò pè yín ní ẹrú mọ́.” (Jòhánù 15:14, 15) Láyé àtijọ́, ẹrú ò lẹ́nu ọ̀rọ̀, ohun tí olúwa rẹ̀ bá ní kó ṣe ló gbọ́dọ̀ ṣe. Àmọ́ àwọn tí ìwà wọn jọra ló máa ń dọ̀rẹ́, ìyẹn la fi ń sọ pé ìwá jọ̀wà ní í jẹ́ ọ̀rẹ́ jọ̀rẹ́. A lè di ọ̀rẹ́ Jèhófà. (Jákọ́bù 2:23) Ohun tó ń mú kí ọ̀rẹ́ yìí túbọ̀ jinlẹ̀ ni ìfẹ́ láàárín tọ̀túntòsì. Jésù fi hàn pé ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run a máa ṣègbọràn sí i, nígbà tó sọ pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá nífẹ̀ẹ́ mi, yóò pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, Baba mi yóò sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.” (Jòhánù 14:23) Níwọ̀n bí Baba ti nífẹ̀ẹ́ wa, tó sì fẹ́ máa tọ́ wa sọ́nà ààbò—Jèhófà ń ké sí wa pé ká máa gbé níbàámu pẹ̀lú àwọn ìlànà òun.
Àwọn Ìlànà Ọlọ́run
4. Báwo lo ṣe máa ṣàlàyé ìlànà?
4 Kí là ń pè ní ìlànà? Ìlànà jẹ́ “ohun tí gbogbo èèyàn gbà pé ó jẹ́ òtítọ́ pọ́ńbélé: òfin tàbí ẹ̀kọ́ tàbí èròǹgbà gbígbòòrò tó jẹ́ gẹ́gẹ́ bí igi-lẹ́yìn-ọgbà fún àwọn òfin mìíràn, tàbí tá a gbé àwọn òfin mìíràn kà.” (Webster’s Third New International Dictionary) Bí a bá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀, a óò rí i pé Baba wa ọ̀run fún wa ní àwọn ìtọ́sọ́nà pàtàkì tó kárí ọkàn-kò-jọ̀kan ipò nínú ìgbésí ayé. Ó ṣe èyí fún ire wa ayérayé. Èyí wà níbàámu pẹ̀lú ohun tí Sólómọ́nì ọlọgbọ́n Ọba kọ̀wé, pé: “Gbọ́, ọmọ mi, kí o sì tẹ́wọ́ gba àwọn àsọjáde mi. Nígbà náà ni ọdún ìwàláàyè yóò di púpọ̀ fún ọ. Dájúdájú, èmi yóò fún ọ ní ìtọ́ni ní ọ̀nà ọgbọ́n pàápàá; èmi yóò mú kí o rin àwọn òpó ọ̀nà ìdúróṣánṣán.” (Òwe 4:10, 11) Àwọn ìlànà pàtàkì tí Jèhófà gbé kalẹ̀ kan àjọṣe wa pẹ̀lú rẹ̀ àti àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn èèyàn ẹlẹgbẹ́ wa, ìjọsìn wa, àti ìgbésí ayé wa ojoojúmọ́. (Sáàmù 1:1) Ẹ jẹ́ ká gbé díẹ̀ yẹ̀ wò lára àwọn ìlànà pàtàkì wọ̀nyẹn.
5. Mú àpẹẹrẹ àwọn ìlànà pàtàkì kan wá.
5 Jésù sọ nípa àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà pé: “Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú rẹ.” (Mátíù 22:37) Láfikún sí i, Ọlọ́run fún wa ní àwọn ìlànà nípa bó ṣe yẹ ká máa ṣe sí àwọn èèyàn ẹlẹgbẹ́ wa. Ara irú ìlànà bẹ́ẹ̀ ni Òfin Pàtàkì náà, tó sọ pé: “Nítorí náà, gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sí wọn.” (Mátíù 7:12; Gálátíà 6:10; Títù 3:2) Nínú ọ̀ràn ìjọsìn, a gbà wá níyànjú pé: “Ẹ sì jẹ́ kí a gba ti ara wa rò lẹ́nì kìíní-kejì láti ru ara wa sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà, kí a má máa kọ ìpéjọpọ̀ ara wa sílẹ̀.” (Hébérù 10:24, 25) Ní ti bí a ṣe ń gbé ìgbésí ayé wa ojoojúmọ́, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Yálà ẹ ń jẹ tàbí ẹ ń mu tàbí ẹ ń ṣe ohunkóhun mìíràn, ẹ máa ṣe ohun gbogbo fún ògo Ọlọ́run.” (1 Kọ́ríńtì 10:31) Àwọn ìlànà mìíràn tí kò lóǹkà ń bẹ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
6. Báwo ni ìlànà ṣe yàtọ̀ sí òfin?
6 Ìlànà jẹ́ òtítọ́ pàtàkì tó wúlò gan-an. Àwọn Kristẹni tó gbọ́n sì mọ̀ pé ó dáa láti nífẹ̀ẹ́ wọn. Jèhófà mí sí Sólómọ́nì láti kọ̀wé pé: “Ọmọ mi, fetí sí àwọn ọ̀rọ̀ mi. Dẹ etí rẹ sí àwọn àsọjáde mi. Kí wọ́n má lọ kúrò ní ojú rẹ. Pa wọ́n mọ́ sínú ọkàn-àyà rẹ. Nítorí ìwàláàyè ni wọ́n jẹ́ fún àwọn tí ó wá wọn rí àti ìlera fún gbogbo ẹran ara wọn.” (Òwe 4:20-22) Ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín ìlànà àti òfin? Orí ìlànà la gbé òfin kà. Òfin sábà máa ń ṣe pàtó. Ó sì lè wà fún àkókò tàbí ipò kan pàtó. Nígbà tó jẹ́ pé ìlànà kò mọ sí sáà kan. (Sáàmù 119:111) Àwọn ìlànà Ọlọ́run kì í di aláìbódemu, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í di ohun àtijọ́. Òótọ́ lọ̀rọ̀ onímìísí tí wòlíì Aísáyà sọ, pé: “Koríko tútù ti gbẹ dànù, ìtànná ti rọ; ṣùgbọ́n ní ti ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wa, yóò wà fún àkókò tí ó lọ kánrin.”—Aísáyà 40:8.
Gbé Èrò àti Ìṣe Rẹ Karí Ìlànà
7. Báwo ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe fún wa níṣìírí láti máa gbé èrò àti ìṣe wa karí ìlànà?
7 Léraléra ni “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” ń rọ̀ wá pé ká máa gbé èrò àti ìṣe wa karí ìlànà. Nígbà tá a ní kí Jésù ṣàkópọ̀ ohun tó wà nínú Òfin, gbólóhùn méjì tó ṣe ṣókí ló lò—ọ̀kan tó fi ìjẹ́pàtàkì nínífẹ̀ẹ́ Jèhófà hàn, àti èkejì tó tẹnu mọ́ nínífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì. (Mátíù 22:37-40) Gbólóhùn Jésù wọ̀nyí wá látinú ara gbólóhùn tá a sọ ṣáájú láti fi ṣàkópọ̀ lájorí ìlànà inú Òfin Mósè, èyí tí ń bẹ nínú Diutarónómì 6:4, 5, pé: “Jèhófà Ọlọ́run wa, Jèhófà kan ṣoṣo ni. Kí ìwọ sì fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo okunra rẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ.” Ó hàn gbangba pé Jésù kò ṣàì ní ìtọ́ni Ọlọ́run tó wà nínú Léfítíkù 19:18 lọ́kàn pẹ̀lú. Nínú ọ̀rọ̀ ìparí tó ṣe kedere, tó gbámúṣé, tó sì jẹ́ alárinrin tá a fi parí ìwé Oníwàásù, ọ̀rọ̀ Sólómọ́nì Ọba gbé kókó inú ọ̀pọ̀ òfin Ọlọ́run yọ, nígbà tó sọ pé: “Òpin ọ̀ràn náà, lẹ́yìn gbígbọ́ gbogbo rẹ̀, ni pé: Bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́, kí o sì pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́. Nítorí èyí ni gbogbo iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe ti ènìyàn. Nítorí Ọlọ́run tòótọ́ tìkára rẹ̀ yóò mú gbogbo onírúurú iṣẹ́ wá sínú ìdájọ́ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú gbogbo ohun fífarasin, ní ti bóyá ó dára tàbí ó burú.”—Oníwàásù 12:13, 14; Míkà 6:8.
8. Kí nìdí tí níní òye kíkún nípa àwọn lájorí ìlànà Bíbélì fi jẹ́ ààbò fún wa?
8 Lílóye irú àwọn lájorí ìlànà wọ̀nyẹn ní kíkún lè jẹ́ kó rọrùn fún wa láti lóye àti láti fi àwọn ìtọ́ni tó ṣe pàtó sílò. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, bí a kò bá lóye àwọn ìlànà pàtàkì dáadáa, tí a ò sì fara mọ́ ọn délẹ̀délẹ̀, ó lè ṣòro fún wa láti ṣe àwọn ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání. Ó sì ṣeé ṣe kí ìgbàgbọ́ wa tètè mì. (Éfésù 4:14) Bá a bá jẹ́ kí ìlànà wọ̀nyẹn wà ní góńgó ẹ̀mí wa, a ó fi wọ́n sọ́kàn nígbà tá a bá fẹ́ ṣe ìpinnu. Tá a bá fòye lò wọ́n, a óò kẹ́sẹ járí.—Jóṣúà 1:8; Òwe 4:1-9.
9. Kí nìdí tí kì í fi gbogbo ìgbà rọrùn láti mòye àwọn ìlànà Bíbélì, ká sì fi wọ́n sílò?
9 Fífòye mọ ìlànà Bíbélì àti fífi wọ́n sílò kò rọrùn bíi títẹ̀lé òfin. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá aláìpé, a lè máa yẹra fún ìsapá tó ń béèrè láti ronú jinlẹ̀ lórí ìlànà. Nígbà tí a kò bá mọ ìpinnu tó yẹ ká ṣe tàbí tọ́ràn kan rú wa lójú, a lè máa wá ẹni tó máa pàṣẹ ohun tá a máa ṣe fún wa. Nígbà míì, a lè lọ fọ̀ràn lọ Kristẹni kan tó dàgbà dénú—bóyá alàgbà nínú ìjọ—pé kó sọ òfin pàtó tó yẹ ká tẹ̀ lé nínú ipò tá a wà. Bẹ́ẹ̀ rèé, Bíbélì tàbí àwọn ìtẹ̀jáde tá a gbé ka Bíbélì lè máà ní òfin pàtó lórí ọ̀ràn yẹn. Bí òfin pàtó bá tilẹ̀ wà, ó lè ṣàì kárí gbogbo irú ọ̀ràn bẹ́ẹ̀. O lè rántí pé ọkùnrin kan sọ fún Jésù pé: “Olùkọ́, sọ fún arákùnrin mi kí ó pín ogún pẹ̀lú mi.” Kàkà tí Jésù ì bá fi sáré gbé òfin kalẹ̀ láti fi yanjú èdèkòyédè àárín tẹ̀gbọ́n-tàbúrò yìí, ìlànà kan tó jẹ́ ti gbogbo gbòò ni Jésù fún un, pé: “Ẹ la ojú yín sílẹ̀, kí ẹ sì máa ṣọ́ra fún gbogbo onírúurú ojúkòkòrò.” Jésù tipa bẹ́ẹ̀ pèsè ìtọ́sọ́nà tó wúlò nígbà yẹn lọ́hùn-ún, tó tún wúlò títí di òní olónìí.—Lúùkù 12:13-15.
10. Báwo ni híhùwà níbàámu pẹ̀lú ìlànà ṣe ń fi ohun tó wà lọ́kàn wa hàn?
10 Ó ṣeé ṣe kó o ti rí àwọn èèyàn tó jẹ́ pé pípa tí wọ́n ń pa òfin mọ́ kò tọkàn wọn wá, torí ká má bàa fìyà jẹ wọ́n ni. Ẹni tó bá ń fojú pàtàkì wo ìlànà kò ní nírú ẹ̀mí yẹn. Ìlànà fúnra rẹ̀ ló máa ń mú kí àwọn tó bá ń pa á mọ́ ṣe bẹ́ẹ̀ látọkànwá. Ní ti gidi, èyí tó pọ̀ jù lọ nínú ìlànà ni kò sọ nǹkan kan nípa ìyà ojú ẹsẹ̀ tó máa jẹ ẹni tó bá tàpá sí i. Èyí fún wa láǹfààní láti fi ìdí tá a fi ń ṣègbọràn sí Jèhófà hàn. Ó sì ń tipa báyìí fi ohun tó wà lọ́kàn wa hàn. Àpẹẹrẹ kan ni kíkọ̀ tí Jósẹ́fù kọ ìlọ̀kulọ̀ tí aya Pọ́tífárì fi lọ̀ ọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé nígbà yẹn Jèhófà kò tíì ṣe òfin kankan tó wà lákọọ́lẹ̀ tó ka panṣágà léèwọ̀. Kò sì sí ibi tá a kọ ìyà tí Ọlọ́run máa fi jẹ ẹni tó bá bá ìyàwó ẹlòmíràn lò pọ̀ sí. Síbẹ̀ Jósẹ́fù mọ̀ nípa ìlànà Ọlọ́run tó sọ pé kí tọkọtaya jẹ́ olóòótọ́ síra wọn. (Jẹ́nẹ́sísì 2:24; 12:18-20) A lè rí i nínú èsì rẹ̀ pé irú ìlànà bẹ́ẹ̀ nípa lórí rẹ̀ gan-an. Ó sọ pé: “Báwo ni èmi ṣe lè hu ìwà búburú ńlá yìí, kí n sì dẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọ́run ní ti gidi?”—Jẹ́nẹ́sísì 39:9.
11. Nínú àwọn ipò wo làwọn Kristẹni yóò ti fẹ́ kí ìlànà Jèhófà máa tọ́ àwọn sọ́nà?
11 Lóde òní, àwọn Kristẹni ń fẹ́ láti fi ìlànà Jèhófà tọ́ ara wọn sọ́nà nínú ọ̀ràn ara wọn, bí irú ẹgbẹ́ tí wọ́n ń kó, irú eré tí wọ́n fi ń najú, irú orin tí wọ́n ń gbọ́, àti irú ìwé tí wọ́n ń kà. (1 Kọ́ríńtì 15:33; Fílípì 4:8) Bá a ṣe ń gba ìmọ̀ kún ìmọ̀, tá à ń gba òye kún òye, tá a sì túbọ̀ ń mọyì Jèhófà àtàwọn ìlànà rẹ̀, ńṣe ni ẹ̀rí ọkàn wa, tí í ṣe atọ́nà ìwà rere wa, yóò túbọ̀ máa ràn wá lọ́wọ́ láti fi àwọn ìlànà Ọlọ́run sílò lábẹ́ ipòkípò tá a bá dojú kọ, kódà nínú àwọn ọ̀ràn tí ojú ẹlòmíì ò tó. Bá a bá jẹ́ kí ìlànà Bíbélì máa tọ́ wa sọ́nà, a ò ní wá bá a ṣe máa dọ́gbọ́n yẹ òfin Ọlọ́run sílẹ̀; bẹ́ẹ̀ náà la ò ni fara wé àwọn tó máa ń fẹ́ wo ibi tí àwọn lè rìn jìnnà dé ní bèbè ìwà ẹ̀ṣẹ̀. A kúkú mọ̀ pé ẹni tó bá ń ronú bẹ́ẹ̀, ara rẹ̀ ló ń tàn jẹ, iná ló sì fi ń ṣeré yẹn.—Jákọ́bù 1:22-25.
12. Kí ni àṣírí jíjẹ́ ẹni tí ìlànà Ọlọ́run ń tọ́ sọ́nà?
12 Àwọn Kristẹni tó dàgbà dénú mọ̀ pé kókó pàtàkì nínú títẹ̀lé ìlànà Ọlọ́run ni kéèyàn fẹ́ láti mọ ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan náà. Onísáàmù náà gbà wá níyànjú pé: “Ẹ̀yin tí ẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ẹ kórìíra ohun búburú.” (Sáàmù 97:10) Ìwé Òwe 6:16-19 to díẹ̀ lára ohun tí Ọlọ́run kà sí búburú, ó ní: “Ohun mẹ́fà ní ń bẹ tí Jèhófà kórìíra ní tòótọ́; bẹ́ẹ̀ ni, méje ni ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí fún ọkàn rẹ̀: ojú gíga fíofío, ahọ́n èké, àti ọwọ́ tí ń ta ẹ̀jẹ̀ aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ sílẹ̀, ọkàn-àyà tí ń fẹ̀tàn hùmọ̀ àwọn ìpètepèrò tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́, ẹsẹ̀ tí ń ṣe kánkán láti sáré sínú ìwà búburú, ẹlẹ́rìí èké tí ń gbé irọ́ yọ, àti ẹnikẹ́ni tí ń dá asọ̀ sílẹ̀ láàárín àwọn arákùnrin.” Tá a bá lè jẹ́ kí ìfẹ́ láti wo irú àwọn ohun ìpìlẹ̀ bẹ́ẹ̀ bí Jèhófà ṣe ń wò wọ́n máa darí ìgbésí ayé wa, gbígbé níbàámu pẹ̀lú ìlànà á mọ́ wa lára.—Jeremáyà 22:16.
Ó Ń Béèrè Ọkàn Rere
13. Èrò wo ni Jésù tẹnu mọ́ nínú Ìwàásù rẹ̀ Lórí Òkè?
13 Mímọ àwọn ìlànà àti fífi wọ́n sílò tún ń gbà wá lọ́wọ́ kíkó sínú pańpẹ́ ìjọsìn àfaraṣe má fọkàn ṣe. Ìyàtọ̀ wà láàárín títẹ̀lé ìlànà àti wíwulẹ̀ tẹ̀ lé òfin gẹ́gẹ́ bí olófìn-índé. Jésù fi èyí hàn kedere nínú Ìwàásù Lórí Òkè. (Mátíù 5:17-48) Rántí pé Júù làwọn tí Jésù ń bá sọ̀rọ̀, nítorí náà ó yẹ kí ìwà wọ́n bá Òfin Mósè mu. Àmọ́ ojú òdì ni wọ́n fi ń wo Òfin náà. Ńṣe ni wọ́n ń rinkinkin mọ́ ọ̀rọ̀ inú Òfin dípò kíkíyèsí èrò tó ń gbìn síni lọ́kàn. Wọ́n tún ń gbé àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ wọn lárugẹ. Wọ́n tiẹ̀ gbé e lékè ẹ̀kọ́ Ọlọ́run pàápàá. (Mátíù 12:9-12; 15:1-9) Ìyọrísí rẹ̀ ni pé wọn ò kọ́ àwọn èèyàn ní gbogbo gbòò láti máa ronú níbàámu pẹ̀lú ìlànà.
14. Báwo ni Jésù ṣe ran àwọn olùgbọ́ rẹ̀ lọ́wọ́ láti máa ronú níbàámu pẹ̀lú ìlànà?
14 Ní ìyàtọ̀ sí èyí, Jésù sọ̀rọ̀ nípa ìlànà márùn-ún tó jẹ mọ́ ìwà híhù nínú Ìwàásù Lórí Òkè. Ó sọ̀rọ̀ nípa: ìbínú, ìgbéyàwó àti ìkọ̀sílẹ̀, ṣíṣe ìlérí, gbígbẹ̀san àti ìfẹ́ àti ìkórìíra. Nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn, Jésù fi àǹfààní tó wà nínú títẹ̀lé ìlànà hàn. Jésù tipa bẹ́ẹ̀ gbé ọ̀pá ìdiwọ̀n ìwà rere àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ga. Bí àpẹẹrẹ, lórí ọ̀ràn panṣágà, ó fún wa ní ìlànà kan tí kì í ṣe pé ó ń dáàbò bo ìṣe wa nìkan, àmọ́ tó tún ń dáàbò bo èrò àti ìfẹ́ ọkàn wa pẹ̀lú. Ó ní: “Ẹni tí ń bá a nìṣó ní wíwo obìnrin kan láti ní ìfẹ́ onígbòónára sí i, ti ṣe panṣágà pẹ̀lú rẹ̀ ná nínú ọkàn-àyà rẹ̀.”—Mátíù 5:28.
15. Báwo la ṣe lè yẹra fún jíjẹ́ olófìn-índé?
15 Àpẹẹrẹ yìí fi hàn pé kò yẹ ká gbàgbé iṣẹ́ táwọn ìlànà Jèhófà ń ṣe, àti ojú tó yẹ ká máa fi wò wọ́n. Ká má rò pé a lè jèrè ojú rere Ọlọ́run nípa jíjẹ́ olófìn-índé. Láti fi hàn pé irú ẹ̀mí bẹ́ẹ̀ kò lè gbéni débì kankan, Jésù tọ́ka sí àánú àti ìfẹ́ Ọlọ́run. (Mátíù 12:7; Lúùkù 6:1-11) Bá a bá ń tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì, a ó yẹra fún kíka àwọn òfin má-ṣu-má-tọ̀ sílẹ̀ rẹpẹtẹ fúnra wa (tàbí fáwọn ẹlòmíì) ré kọjá ohun tí Bíbélì wí. Ohun tó máa jẹ wá lógún ni àwọn ìlànà onífẹ̀ẹ́ àti ìgbọràn sí Ọlọ́run, dípò ìjọsìn tí kò dénú.—Lúùkù 11:42.
Àwọn Ìyọrísí Aláyọ̀
16. Mú àwọn àpẹẹrẹ kan wá nípa àwọn ìlànà tá a gbé àwọn òfin Bíbélì kan kà.
16 Bá a ṣe ń làkàkà láti ṣègbọràn sí Jèhófà, ó pọn dandan láti mọ̀ pé àwọn ìlànà pàtàkì kan ló gbé àwọn òfin rẹ̀ kà. Bí àpẹẹrẹ, àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ yàgò fún ìbọ̀rìṣà, ìṣekúṣe àti àṣìlò ẹ̀jẹ̀. (Ìṣe 15:28, 29) Kí ní ìdúró àwọn Kristẹni lórí ọ̀ràn wọ̀nyí? Ọlọ́run yẹ ní ẹni tá à ń fún ní ìfọkànsìn tí a yà sọ́tọ̀ gedegbe; ó yẹ ká jẹ́ olóòótọ́ sí ọkọ tàbí aya wa; àti pé Jèhófà ni Olùfúnni-ní-Ìyè. (Jẹ́nẹ́sísì 2:24; Ẹ́kísódù 20:5; Sáàmù 36:9) Lílóye àwọn ìlànà tá a gbé òfin wọ̀nyí kà yóò jẹ́ kó túbọ̀ rọrùn fún wa láti fara mọ́ àwọn òfin tó tinú rẹ̀ jáde, ká sì máa pa wọ́n mọ́.
17. Ìyọrísí rere wo ló ń wá látinú mímòye àwọn ìlànà Bíbélì àti fífi wọ́n sílò?
17 Bá a bá ń mòye àwọn ìlànà ìpìlẹ̀ wọ̀nyí, tá a sì ń fi wọ́n sílò, a óò rí i pé ire wa ni wọ́n wà fún. Àwọn ìbùkún tẹ̀mí táwọn èèyàn Ọlọ́run ń gbádùn sábà máa ń ní àwọn àǹfààní gidi nínú. Bí àpẹẹrẹ, àwọn tí kì í mu sìgá, tí wọ́n ń gbé ìgbé-ayé ìwà rere, tí wọ́n sì ka ẹ̀jẹ̀ sí ohun mímọ́, kì í kó àwọn àrùn kan. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, gbígbé níbàámu pẹ̀lú àwọn òtítọ́ tá a kọ́ nínú Bíbélì lè ṣàǹfààní fún wa nínú ọ̀ràn àtijẹ-àtimu, nínú ọ̀ràn ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà, àti nínú ìdílé. Irú àwọn àǹfààní gidi bẹ́ẹ̀ fi bí àwọn ìlànà Jèhófà ti ṣeyebíye tó hàn, ó fi hàn pé wọ́n wúlò gan-an. Àmọ́ o, àǹfààní wọ̀nyẹn nínú ara wọn kọ́ ni ìdí pàtàkì tá a fi ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Ọlọ́run. Àwọn Kristẹni tòótọ́ ń ṣègbọràn sí Jèhófà nítorí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, nítorí pé ó yẹ ní ẹni tí wọ́n ń jọ́sìn, àti nítorí pé ohun tó tọ́ láti ṣe nìyẹn.—Ìṣípayá 4:11.
18. Bá a bá fẹ́ jẹ́ Kristẹni tó kẹ́sẹ járí, kí ló yẹ kó máa darí ìgbésí ayé wa?
18 Fífi àwọn ìlànà Bíbélì darí ìgbésí ayé á jẹ́ kí ìgbésí ayé wa lárinrin, èyí sì lè mú káwọn ẹlòmíràn bẹ̀rẹ̀ sí tọ ọ̀nà Ọlọ́run. Ní pàtàkì jù lọ, ìgbésí ayé wa ń bọlá fún Jèhófà. A mọ̀ pé lóòótọ́ ni Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́, tó ń fẹ́ kó yẹ wá kalẹ́. Nígbà tá a bá ń ṣe ìpinnu níbàámu pẹ̀lú àwọn ìlànà Bíbélì, tá a sì rí bí Jèhófà ṣe ń bù kún wa, ńṣe ni ọkàn wa óò túbọ̀ máa fà sún mọ́ ọn. Àní sẹ́, ńṣe ni àjọṣe onífẹ̀ẹ́ àárín àwa àti Baba wa ọ̀run yóò túbọ̀ lágbára sí i.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Kí ni ìlànà jẹ́?
• Kí ni ìyàtọ̀ tó wà láàárín ìlànà àti òfin?
• Èé ṣe tó fi dáa láti gbé èrò àti ìṣe wa karí ìlànà?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 20]
Wọ́n sọ fún Wilson, tí í ṣe Kristẹni láti Gánà, pé ní ọjọ́ díẹ̀ sí i, iṣẹ́ máa bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Lọ́jọ́ tó wá síbi iṣẹ́ kẹ́yìn, wọ́n ní kó lọ fọ ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ náà. Nígbà tí Wilson rí owó nínú ọkọ̀ náà, ẹni tó jẹ́ ọ̀gá Wilson sọ fún un pé Ọlọ́run ló bá a ṣe owó yẹn nítorí pé ọjọ́ yẹn ni iṣẹ́ máa bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Àmọ́ Wilson tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì nípa ìṣòtítọ́, ó dá owó náà padà fún ọ̀gá àgbà. Ẹnu ya ọ̀gá àgbà náà, ó sì wú u lórí gan-an. Fún ìdí yìí kì í ṣe kìkì pé ó ní kí Wilson máa báṣẹ́ lọ nìkan ni, ó tún sọ ọ́ di ọ̀kan lára àwọn ọ̀gá ilé iṣẹ́ náà.—Éfésù 4:28.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 21]
Rukia jẹ́ obìnrin ará Albania tó ti lé lẹ́ni ọgọ́ta ọdún. Nítorí èdèkòyédè tó wáyé nínú ìdílé wọn, ó lé ní ọdún mẹ́tàdínlógún gbáko tó fi bá ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin yodì. Nígbà tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó wá rí i pé àwọn Kristẹni tòótọ́ gbọ́dọ̀ wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, láìní ẹnikẹ́ni sínú. Gbogbo òru ló fi gbàdúrà, bó ṣe gbọ̀nà ilé ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lọ nìyẹn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àyà rẹ̀ ń já. Ọmọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ló ṣílẹ̀kùn. Ó ya ọmọ náà lẹ́nu débi tó fi béèrè pé: “Ta ló kú? Kí lẹ wá ṣe?” Rukia sọ pé ẹ̀gbọ́n òun lòun wá rí. Ó fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ṣàlàyé pé kíkẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ìlànà Bíbélì àti nípa Jèhófà ló sún òun láti wá yanjú aáwọ̀ àárín òun àti ẹ̀gbọ́n òun. Lẹ́yìn tí wọ́n da omijé lójú, tí wọ́n tún dì mọ́ra, wọ́n wá ṣayẹyẹ pé àwọn ti padà rẹ́!—Róòmù 12:17, 18.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
“Nígbà tí ó rí àwọn ogunlọ́gọ̀, ó gòkè lọ sí orí òkè ńlá; lẹ́yìn tí ó sì jókòó, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀; ó sì la ẹnu rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn.”—Mátíù 5:1, 2