Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Yíyin Ọlọ́run Lógo Láwọn Òkè Ńlá Philippines

Yíyin Ọlọ́run Lógo Láwọn Òkè Ńlá Philippines

Yíyin Ọlọ́run Lógo Láwọn Òkè Ńlá Philippines

Tó o bá rò pé orílẹ̀-èdè kan tó kún fún erékùṣù ni Philippines, o gbà á. Àmọ́ ó tún jẹ́ orílẹ̀-èdè táwọn òkè rírẹwà pọ̀ sí. Wíwàásù láwọn ìlú ńlá àtàwọn àgbègbè tó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ jẹ́ ohun tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣòro, tó sì gbéṣẹ́ fáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àmọ́ ipò nǹkan yàtọ̀ pátápátá láwọn àgbègbè olókè.

ÀWỌN òkè ọlọ́lá ńlá tó wà ní orílẹ̀-èdè náà yàtọ̀ pátápátá sí àwọn etíkun oníyanrìn, àwọn òkìtì ẹ̀dá omi abìlẹ̀kẹ̀, abúlé tí wọ́n ti ń pẹja, àtàwọn ìlú tí èrò ti ń wọ́ lọ wọ́ bọ̀ láwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ tí í ṣe erékùṣù. Àwọn òkè ńlá náà tún jẹ́ kí wíwàásù “ìhìn rere” Ìjọba Ọlọ́run túbọ̀ nira.—Mátíù 24:14.

Àwọn Erékùṣù Philippines wà ní ibi tí ipele ilẹ̀ méjì ti pàdé. Dídì tí ilẹ̀ dì léra ní àgbègbè yìí ló fa ọ̀wọ́ àwọn òkè ńlá láwọn erékùṣù tó tóbi. Àwọn erékùṣù tó lé ní ẹgbẹ̀rún méje àti ọ̀gọ́rùn-ún [7,100] tó para pọ̀ jẹ́ orílẹ̀-èdè Philippines wà ní ìhà ìwọ̀ oòrùn ibi tí à ń pè ní Pacific Ring of Fire. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn òkè ayọnáyèéfín pọ̀ ní erékùṣù wọ̀nyí, ó tún wà lára ìdí tí òkè ńláńlá fi pọ̀ níbẹ̀. Ilẹ̀ olókè bẹ́ẹ̀ ló mú káwọn tó ń gbé láwọn òkè ńlá wọ̀nyẹn wà ní àdádó. Kò rọrùn rárá láti dé ọ̀dọ̀ wọn nítorí pé àwọn ọ̀nà tí ọkọ̀ lè rìn débẹ̀ kò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀.

Láìfi gbogbo ìdènà wọ̀nyí pè, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà rí i pé àwọn gbọ́dọ̀ dé ọ̀dọ̀ “gbogbo onírúurú ènìyàn.” (1 Tímótì 2:4) Nítorí náà, àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní Philippines ti ṣiṣẹ́ níbàámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tó wà nínú Aísáyà 42:11, 12, tó sọ pé: “Kí àwọn olùgbé orí àpáta gàǹgà fi ìdùnnú ké jáde. Kí àwọn ènìyàn ké sókè láti orí àwọn òkè ńlá. Kí wọ́n gbé ògo fún Jèhófà, kí wọ́n sì sọ ìyìn rẹ̀ jáde àní ní àwọn erékùṣù.”

Ìsapá gidi láti wàásù fáwọn tó ń gbé láwọn òkè ńlá náà ti bẹ̀rẹ̀ láti ohun tó lé ní àádọ́ta ọdún sẹ́yìn. Lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì, àwọn míṣọ́nnárì ṣèrànwọ́ láti mú kí iṣẹ́ náà tẹ̀ síwájú. Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń gbé ládùúgbò náà ló tẹ́wọ́ gba òtítọ́ Bíbélì, àwọn ló sì wá tan òtítọ́ yìí dé àwọn abúlé jíjìnnà réré lórí àwọn òkè ńlá náà. Èyí sì ní àbájáde tó dára gan-an. Bí àpẹẹrẹ, àwọn tó jẹ́ akéde ìhìn rere náà ní àwọn òkè tó wà ní Àárín Gbùngbùn Cordillera, ní ìhà àríwá Luzon, lé ní ẹgbàáta [6,000]. Ọ̀pọ̀ jù lọ wọn ló sì jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀, títí kan Ibaloi, Ifugao, àti Kalinga.

Àmọ́ ṣá o, àwọn àgbègbè kan ṣì wà tó ṣòroó dé láwọn òkè ńlá náà. Wọn ò gbàgbé àwọn èèyàn tó ń gbé níbẹ̀. Báwo ni wọ́n ṣe rọ́nà dé ọ̀dọ̀ àwọn kan lára wọn, kí ló sì tibẹ̀ jáde?

Ojúlówó Ìgbàgbọ́ Rọ́pò Àṣà Àtọwọ́dọ́wọ́

Ní erékùṣù Luzon tí ń bẹ ní àríwá, àwọn ẹ̀yà Tinggian ló ń gbé àgbègbè òkè tó wà ní ẹkùn-ìpínlẹ̀ Abra. Ó lè jẹ́ inú ọ̀rọ̀ Malay ìgbàanì tí wọ́n ń pè ní tinggi, tó túmọ̀ sí “òkè ńlá,” ni orúkọ yìí ti pilẹ̀ ṣẹ̀. Ẹ ò rí i bó ṣe ba á mu wẹ́kú! Àwọn èèyàn náà tún máa ń pe ara wọn àti èdè wọn ní Itneg. Wọ́n gba ọlọ́run tí wọ́n ń pè ní Kabunian gbọ́, ìgbàgbọ́ nínú ohun asán ló sì ń darí ìgbésí ayé wọn ojoojúmọ́. Bí àpẹẹrẹ, bí ẹni tó ń múra àtilọ síbì kan bá sín, àpẹẹrẹ burúkú nìyẹn. Ó gbọ́dọ̀ dúró fún wákàtí bíi mélòó kan kí ipa búburú yẹn lè kúrò nílẹ̀.

Àwọn ará Sípéènì mú ẹ̀sìn Kátólíìkì wá síbẹ̀ ní ọdún 1572, àmọ́ wọn ò fi ojúlówó ìsìn Kristẹni kọ́ àwọn Tinggian. Àwọn tó di Kátólíìkì nínú wọn ṣì gba Kabunian gbọ́, wọ́n sì ń tẹ̀ lé àwọn àṣà ìbílẹ̀ wọn. Ìmọ̀ pípéye nípa Bíbélì kọ́kọ́ dé ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn wọ̀nyí láwọn ọdún 1930, nígbà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí tan ìhìn Ìjọba náà ká àwọn òkè ńlá wọ̀nyẹn. Àtìgbà yẹn ni ọ̀pọ̀ àwọn Tinggian tó jẹ́ ọlọ́kàn rere ti bẹ̀rẹ̀ sí yin Jèhófà lógo “láti orí àwọn òkè ńlá.”

Bí àpẹẹrẹ, baálẹ̀ kan táwọn èèyàn bọ̀wọ̀ fún lágbègbè yẹn ni Lingbaoan tẹ́lẹ̀. Kò fọ̀rọ̀ àwọn àṣà ìbílẹ̀ Tinggian ṣeré rárá. Ó ní: “Tọkàntọkàn ni mo fi ń tẹ̀ lé àwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ Tinggian. Bí wọ́n bá pa ẹnì kan, a óò jó lẹ́yìn ìsìnkú náà, a ó sì lu agogo. A tún máa ń fi àwọn ẹran rúbọ. A gba Kabunian gbọ́, mi ò sì mọ Ọlọ́run Bíbélì.” Bẹ́ẹ̀, Kátólíìkì ló pe ara rẹ̀ lákòókò yẹn o.

Àwọn òjíṣẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá wàásù lágbègbè yẹn. Wọ́n bá Lingbaoan pàdé, wọ́n sì rọ̀ ọ́ pé kó máa ka Bíbélì. Ó sọ pé: “Bíbélì ló mú un dá mi lójú pé Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́.” Ẹlẹ́rìí kan wá bá a ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, Lingbaoan sì pinnu láti sin Ọlọ́run tòótọ́. Ó fi ọ̀nà tó ń tọ̀ tẹ́lẹ̀ sílẹ̀, títí kan ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi baálẹ̀. Ìgbésẹ̀ yìí bí àlùfáà àdúgbò náà àtàwọn tí Lingbaoan ń bá kẹ́gbẹ́ tẹ́lẹ̀ nínú gan-an. Àmọ́ Lingbaoan pinnu láti tẹ̀ lé òtítọ́ tó rí nínú Bíbélì. Ó ti ń sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà nínú ìjọ kan báyìí.

Ọ̀sán Méje àti Òru Mẹ́fà

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn apá kan ní Abra ti ń gbọ́ ìhìn rere náà déédéé báyìí, ọ̀nà àwọn tó kù jìn, ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan ni wọ́n sì máa ń rẹ́ni jẹ́rìí fún wọn. Nígbà kan, àwọn Ẹlẹ́rìí gbìyànjú láti dé ọ̀kan lára àwọn àgbègbè wọ̀nyí. Àwọn Ẹlẹ́rìí márùndínlógójì gbéra láti lọ wàásù ní àgbègbè tí a kò pín fúnni ní Tineg, lágbègbè Abra, níbi tí wọn ò tíì bẹ̀ wò fún ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n.

Ẹsẹ̀ ni wọ́n fi rin ìrìn àjò yìí, ó sì gbà wọ́n ní nǹkan bí ọjọ́ méje. Fojú inú wo gbígba orí àwọn afárá tí wọ́n fi okùn so àtàwọn odò jíjìn kọjá, rírin ọ̀pọ̀ wákàtí lórí ọ̀wọ́ àwọn òkè ńlá, pẹ̀lú ẹrù lórí—gbogbo ẹ̀ nítorí àtiwàásù ìhìn rere fáwọn tí kì í sábà gbọ́ ọ! Nínú àwọn òru mẹ́fà tí wọ́n fi rìn yẹn, mẹ́rin níbẹ̀ ni wọ́n fi sùn síta gbangba nínú afẹ́fẹ́ òkè ńlá náà.

Àwọn akíkanjú Ẹlẹ́rìí, tí wọ́n ń rin ìrìn àjò akọni yìí gbé oúnjẹ lọ́wọ́. Àmọ́ wọn ò lè gbé oúnjẹ tó máa tó fún gbogbo ìrìn àjò náà. Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, èyí kì í ṣe ìṣòro, nítorí pé inú àwọn èèyàn náà dùn láti fi oúnjẹ ṣe pàṣípààrọ̀ àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àwọn Ẹlẹ́rìí náà rí ọ̀pọ̀ irè oko, ẹja, àti ẹran ìgalà gbà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé nǹkan ò fi bẹ́ẹ̀ bára dé, síbẹ̀ àwùjọ náà sọ pé: “Ayọ̀ ńláǹlà tá a ní bo àwọn ìṣòro náà mọ́lẹ̀.”

Láàárín ọjọ́ méje náà, àwọn òjíṣẹ́ wọ̀nyí jẹ́rìí ní abúlé mẹ́wàá, wọ́n fi ọgọ́ta ìwé ńlá, igba ó dín mẹ́rìnlá [186] ìwé ìròyìn, àádọ́ta ìwé pẹlẹbẹ, àti ọ̀pọ̀ ìwé àṣàrò kúkúrú sóde. Wọ́n fi bí a ṣe ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì han èèyàn mẹ́rìnléláàádọ́rin. Ní ìlú Tineg, àwọn aláṣẹ àdúgbò náà àtàwọn èèyàn jàǹkànjàǹkàn kan níbẹ̀ sọ pé káwọn ará ṣe ìpàdé ìjọ níbẹ̀. Èèyàn méjìdínlọ́gọ́rin ló pésẹ̀ síbẹ̀. Àwọn olùkọ́ àtàwọn ọlọ́pàá ló pọ̀ jù lára àwọn tó wá síbẹ̀. A nírètí pé púpọ̀ sí i àwọn Tinggian ṣì máa dara pọ̀ mọ́ àwọn tí ń “ké jáde,” tí wọ́n sì ń yin Jèhófà láti orí àwọn òkè ńlá.

Ohun Tó Sàn Ju Wúrà Lọ

Àwọn erékùṣù kan wà láwọn apá ibi tó jìn ní ìhà gúúsù Philippines níbi táwọn ará Sípéènì ti ń rí wúrà. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ń pè wọ́n ní Mindoro, àpèjá rẹ̀ lédè Spanish ni mina de oro, ìyẹn “ibi tí a ti ń wa wúrà.” Àmọ́, a ti wá ń rí ohun tó sàn ju wúrà láwọn erékùṣù wọ̀nyẹn báyìí—ìyẹn àwọn èèyàn tó fẹ́ sin Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́.

Nǹkan bí ọ̀kẹ́ mẹ́fà ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [125,000] ọmọ ìbílẹ̀ tá à ń pè láwọn Mangyan ló ń gbé nínú igbó jíjìnnà tó wà ní Mindoro. Ìgbésí ayé ṣe-bó-o-ti-mọ ni wọ́n ń gbé, wọn kì í sábà bá àwọn ẹ̀yà mìíràn ṣe pọ̀, wọ́n sì ní èdè tiwọn. Ọ̀pọ̀ jù lọ wọn ló jẹ́ abọmọlẹ̀ àti àwọn tó nígbàgbọ́ nínú ọ̀pọ̀ ọlọ́run, wọ́n sì gba onírúurú àwọn ẹ̀mí gbọ́.

Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, tí kò bá sí oúnjẹ àtàwọn nǹkan mìíràn, àwọn Mangyan kan máa ń wáṣẹ́ wá sáwọn àgbègbè etíkun. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Pailing nìyẹn, ẹni tó wá látinú ẹ̀yà kékeré kan ní Mangyan, tí wọ́n ń pè ní Batangan. Àárín àwọn èèyàn rẹ̀ nínú àwọn igbó orí òkè ńlá ni wọ́n ti tọ́ ọ dàgbà, ó sì fara mọ́ ìgbàgbọ́ àti àṣà àwọn Batangan. Aṣọ ni wọ́n máa ń lọ́ mọ́dìí. Àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn Batangan béèrè pé kí àwọn olùjọ́sìn pa adìyẹ kan, kí wọ́n sì jẹ́ kí ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ máa kán sínú omi nígbà tí wọ́n bá ń gbàdúrà, kí ohun ọ̀gbìn wọn lè so wọ̀ǹtìwọnti.

Pailing kò bá wọn lọ́wọ́ sí àṣà wọ̀nyẹn mọ́. Kí nìdí? Nígbà tó lọ sí àgbègbè pẹ̀tẹ́lẹ̀, ọ̀dọ̀ àwọn ìdílé tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ríṣẹ́ sí. Ọ̀kan lára àwọn ìdílé wọ̀nyí lo àǹfààní yẹn láti fi òtítọ́ Bíbélì han Pailing. Ó tẹ́wọ́ gbà á, ó sì rí i pé ó yẹ kí òun kẹ́kọ̀ọ́ nípa ète Jèhófà fún ènìyàn àti ilẹ̀ ayé. Wọ́n rán an lọ sílé ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀, wọ́n sì tún kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ọmọ ọdún mẹ́rìnlélógún ni Pailing nígbà tó ṣèrìbọmi gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nígbà tó fi máa pé ẹni ọgbọ̀n ọdún, ó ti wà ní kíláàsì kejì ní ilé ẹ̀kọ́ gíga, ó sì fi ilé ìwé náà ṣe ìpínlẹ̀ tó ti ń wàásù. Rolando ni wọ́n ń pè é báyìí (ìyẹn orúkọ táwọn tó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ ń jẹ́).

Tó o bá rí Rolando báyìí, ó ti di òjíṣẹ́ tó ń múra dáadáa pẹ̀lú ẹ̀rín músẹ́ lẹ́nu, ó sì ń sìn gẹ́gẹ́ bí oníwàásù alákòókò kíkún àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ nínú ọ̀kan lára àwọn ìjọ tó wà ní Mindoro. Ẹnu àìpẹ́ yìí ni Rolando padà lọ sí òkè ńlá tó ti wá, kì í ṣe láti lọ bá àwọn Batangan lọ́wọ́ nínú àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ wọn o, bí kò ṣe láti lọ sọ fún wọn nípa òtítọ́ Bíbélì tí ń fúnni ní ìyè.

Wọ́n Fẹ́ Kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba Tiwọn

Ẹkùn ìpínlẹ̀ Bukidnon—tó túmọ̀ sí “Àwọn Ará Orí Òkè” lédè Cebuano—wà ní erékùṣù kan níhà gúúsù tí à ń pè ní Mindanao. Àgbègbè yìí ní àwọn òkè ńlá, àwọn òkè tó ní àfonífojì láàárín, àfonífojì olómi, àti òkè olórí títẹ́jú. Ilẹ̀ ẹlẹ́tùlójú yìí dára fún ọ̀pẹ̀yìnbó, àgbàdo, kọfí, ìrẹsì, àti ọ̀gẹ̀dẹ̀ wẹ́wẹ́. Ibẹ̀ làwọn ẹ̀yà Talaandig àti Higaonon tí ń gbé lórí òkè wà. Ó yẹ káwọn èèyàn wọ̀nyí náà kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àǹfààní yìí ṣí sílẹ̀ lọ́nà tó dùn mọ́ni nínú gan-an nítòsí ìlú Talakag.

Àwọn Ẹlẹ́rìí tó ń lọ sí àwọn ilẹ̀ olókè rí i pé ilẹ̀ olótùútù ni ibẹ̀, àmọ́ àwọn ará ibẹ̀ fi tọ̀yàyàtọ̀yàyà kí wọn káàbọ̀. Àwọn tó ń gbé níbẹ̀ sọ pé àwọn gba Ọlọ́run Olódùmarè, tó jẹ́ Baba gbọ́, àmọ́ wọn ò mọ orúkọ rẹ̀. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé inú igbó ni wọ́n ti ń lo èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àkókò wọn, ìgbà àkọ́kọ́ rèé tí wọ́n máa bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pàdé. Wọ́n sọ orúkọ Ọlọ́run fún wọn, àti ète àgbàyanu Ìjọba rẹ̀. Inú àwọn èèyàn náà dùn gan-an, àwọn ará wá pinnu láti padà wá bẹ̀ wọ́n wò lábúlé wọn.

Wọ́n bẹ̀ wọ́n wò nígbà bíi mélòó kan. Nítorí ìdí èyí, àwọn ará ibẹ̀ fún wọn ní ilẹ̀ kan tí wọ́n máa kọ́ “ilé” àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sí. Inú àwọn Ẹlẹ́rìí dùn gan-an sí ilẹ̀ náà. Ilẹ̀ náà wà ní orí òkè tó ga jù lọ lágbègbè yẹn, èèyàn sì lè máa wo ojú ọ̀nà látibẹ̀. Igi, ọparun, àti imọ̀ ọ̀pẹ ni wọ́n fi kọ́ ilé ọ̀hún. Oṣù mẹ́ta àti ọjọ́ mẹ́wàá ni wọ́n fi parí ilé náà. Gàdàgbà gadagba ni àkọlé náà, “Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà” hàn níwájú ilé náà. Ìwọ rò ó wò ná, wọ́n ti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba kí ìjọ tó débẹ̀!

Àtìgbà yẹn ni alàgbà ìjọ kan tó jẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ti kó lọ síbẹ̀, àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan pẹ̀lú. Àwọn arákùnrin wọ̀nyí àtàwọn Ẹlẹ́rìí kan nítòsí sakun láti dá ìjọ kan sílẹ̀ níbẹ̀. Wọ́n dá ìjọ náà sílẹ̀ ní August 1998. Ìjọ kékeré kan ti ń lo Gbọ̀ngàn Ìjọba náà báyìí, tí wọ́n ń ran àwọn tó ń gbé lórí òkè náà lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Bíbélì.

Ní ti tòótọ́, ọ̀nà tó lágbára ni Jèhófà gbà lo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó wà ní Philippines láti tan òtítọ́ Ìjọba náà kálẹ̀ títí dé àwọn òkè ńlá tó ṣòroó dé pàápàá. Èyí rán wa létí ohun tó wà nínú Aísáyà 52:7, tó sọ pé: “Ẹsẹ̀ ẹni tí ń mú ìhìn rere wá mà dára rèǹtè-rente lórí àwọn òkè ńlá o.”

[Àwọn àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 11]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

ABRA

MINDORO

BUKIDNON

[Credit Line]

Àwòrán Àgbáyé: Mountain High Maps® Copyright © 1997 Digital Wisdom, Inc.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Wíwàásù láwọn òkè ńlá wọ̀nyẹn gba kéèyàn fi ọ̀pọ̀ wákàtí máa rìn gba àárín ilẹ̀ kángunkàngun kọjá

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Wọ́n ń ṣe batisí nínú odò kan tó wà ní òkè ńlá