Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Wo Ni Yóò La Ọjọ́ Jèhófà Já?

Àwọn Wo Ni Yóò La Ọjọ́ Jèhófà Já?

Àwọn Wo Ni Yóò La Ọjọ́ Jèhófà Já?

“Ọjọ́ náà ń bọ̀ tí ń jó bí ìléru.”—MÁLÁKÌ 4:1.

1. Báwo ni Málákì ṣe ṣàpèjúwe òpin ètò búburú yìí?

 ỌLỌ́RUN mí sí wòlíì Málákì láti ṣe àkọsílẹ̀ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ pípabanbarì tí yóò wáyé láìpẹ́ láìjìnnà. Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí máa kan gbogbo ẹni tó wà láyé pátá. Málákì 4:1 sọ tẹ́lẹ̀ pé: “‘Wò ó! ọjọ́ náà ń bọ̀ tí ń jó bí ìléru, gbogbo àwọn oníkùgbù àti gbogbo àwọn tí ń hùwà burúkú yóò sì dà bí àgékù pòròpórò. Ọjọ́ náà tí ń bọ̀ yóò sì jẹ wọ́n run dájúdájú,’ ni Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí, ‘tó bẹ́ẹ̀ tí kì yóò fi fi yálà gbòǹgbò tàbí ẹ̀tun sílẹ̀ fún wọn.’” Báwo ni ètò àwọn nǹkan búburú yìí yóò ṣe pa run yán-ányán-án tó? Ńṣe ni yóò dà bí igi kan tí wọ́n pa gbòǹgbò rẹ̀ run, tí igi ọ̀hún ò fi ní lè gbérí mọ́ láé.

2. Báwo làwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan ṣe ṣàpèjúwe ọjọ́ Jèhófà?

2 O lè wá béèrè pé, ‘“Ọjọ́” wo ni wòlíì Málákì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀?’ Ọjọ́ kan náà tí Aísáyà 13:9 sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ni, nígbà tó kéde pé: “Wò ó! Àní ọjọ́ Jèhófà ń bọ̀, ó níkà pẹ̀lú ìbínú kíkan àti pẹ̀lú ìbínú jíjófòfò, láti lè sọ ilẹ̀ náà di ohun ìyàlẹ́nu, kí ó sì lè pa àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ilẹ̀ náà rẹ́ ráúráú kúrò lórí rẹ̀.” Sefanáyà 1:15 ṣàpèjúwe rẹ̀ lọ́nà yìí, ó ní: “Ọjọ́ yẹn jẹ́ ọjọ́ ìbínú kíkan, ọjọ́ wàhálà àti làásìgbò, ọjọ́ ìjì àti ìsọdahoro, ọjọ́ òkùnkùn àti ìṣúdùdù, ọjọ́ àwọsánmà àti ìṣúdùdù tí ó nípọn.”

“Ìpọ́njú Ńlá Náà”

3. Kí ni “ọjọ́ Jèhófà”?

3 Nínú lájorí ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Málákì, “ọjọ́ Jèhófà” ni sáà tá a pè ní “ìpọ́njú ńlá.” Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Nítorí nígbà náà ni ìpọ́njú ńlá yóò wà, irúfẹ́ èyí tí kò tíì ṣẹlẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé títí di ìsinsìnyí, rárá o, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò tún ṣẹlẹ̀ mọ́.” (Mátíù 24:21) Ronú nípa bí wàhálà tí ayé ti fojú winá rẹ̀ ti pọ̀ tó, àgàgà láti ọdún 1914. (Mátíù 24:7-12) Àní Ogun Àgbáyé Kejì nìkan mú ẹ̀mí tó lé ní àádọ́ta mílíọ̀nù lọ! Síbẹ̀, kékeré ni ìwọ̀nyẹn máa jẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ wàhálà tó máa bẹ́ sílẹ̀ nígbà “ìpọ́njú ńlá náà.” Ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn, tí í ṣe ohun kan náà tá a pè ní ọjọ́ Jèhófà, yóò dópin ní Amágẹ́dọ́nì, tí yóò kásẹ̀ àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ètò búburú yìí nílẹ̀.—2 Tímótì 3:1-5, 13; Ìṣípayá 7:14; 16:14, 16.

4. Nígbà tí ọjọ́ Jèhófà bá fi máa parí, kí ni yóò ti ṣẹlẹ̀?

4 Nígbà tí ọjọ́ Jèhófà bá fi máa parí, a ó ti pa ayé Sátánì àtàwọn alátìlẹ́yìn rẹ̀ run. Gbogbo ẹ̀sìn èké ni yóò kọ́kọ́ lọ. Ẹ̀yìn ìyẹn ni ìdájọ́ Jèhófà máa dé sórí ètò ọrọ̀ ajé àti ti ìṣèlú Sátánì. (Ìṣípayá 17:12-14; 19:17, 18) Ìsíkíẹ́lì sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé: “Wọn yóò sọ fàdákà wọn pàápàá sí ojú pópó, wúrà wọn yóò sì di ohun ìkórìíra tẹ̀gàntẹ̀gàn. Fàdákà wọn tàbí wúrà wọn kì yóò lè dá wọn nídè ní ọjọ́ ìbínú kíkan ti Jèhófà.” (Ìsíkíẹ́lì 7:19) Ní ti ọjọ́ náà, Sefanáyà 1:14 sọ pé: “Ọjọ́ ńlá Jèhófà sún mọ́lé. Ó sún mọ́lé, ìyára kánkán rẹ̀ sì pọ̀ gidigidi.” Lójú ohun tí Bíbélì sọ nípa ọjọ́ Jèhófà, ó yẹ ká pinnu láti gbé ìgbésẹ̀ tó bá ìlànà òdodo Ọlọ́run mu.

5. Báwo ni nǹkan yóò ṣe rí fáwọn tó bẹ̀rù orúkọ Jèhófà?

5 Lẹ́yìn sísọ àsọtẹ́lẹ̀ ohun tí ọjọ́ Jèhófà yóò ṣe fún ayé Sátánì, Málákì 4:2 wá ṣàkọsílẹ̀ ọ̀rọ̀ Jèhófà tó sọ pé: “Oòrùn òdodo yóò sì ràn dájúdájú fún ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù orúkọ mi, pẹ̀lú ìmúniláradá ní ìyẹ́ apá rẹ̀; ẹ ó sì jáde lọ ní ti tòótọ́, ẹ ó sì fi àtẹ́sẹ̀ talẹ̀ bí àwọn ọmọ màlúù àbọ́sanra.” Jésù Kristi ni “oòrùn òdodo” náà. Òun ni “ìmọ́lẹ̀ ayé” nípa tẹ̀mí. (Jòhánù 8:12) Jésù ń ràn lọ́nà tí ń múni lára dá, lákọ̀ọ́kọ́ ná, ìmúniláradá tẹ̀mí, tí ń ṣẹlẹ̀ lónìí, àti lẹ́yìn náà, ìmúniláradá pátápátá nípa tara, tí yóò ṣẹlẹ̀ ní ayé tuntun. Gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti wí, àwọn tá a mú lára dá yóò ‘jáde lọ, wọn ó sì fi àtẹ́sẹ̀ talẹ̀ bí àwọn ọmọ màlúù àbọ́sanra’ tí ń fi ìháragàgà àti ìdùnnú retí ìtúsílẹ̀ kúrò nínú àkámọ́.

6. Ayẹyẹ ìṣẹ́gun wo làwọn ìránṣẹ́ Jèhófà yóò gbádùn?

6 Àwọn tí kò náání àwọn ohun tí Jèhófà béèrè wá ńkọ́? Málákì 4:3 kà pé: “‘Ẹ [ìyẹn, àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run] ó sì tẹ àwọn ẹni burúkú mọ́lẹ̀ dájúdájú, nítorí wọn yóò dà bí erukutu lábẹ́ àtẹ́lẹsẹ̀ yín ní ọjọ́ náà tí èmi yóò gbé ìgbésẹ̀,’ ni Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí.” Àwọn èèyàn tó jẹ́ olùjọ́sìn Ọlọ́run kò ní kópa nínú pípa ayé Sátánì run. Dípò ìyẹn, wọ́n ń “tẹ àwọn ẹni burúkú mọ́lẹ̀” lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ nípa kíkópa nínú ayẹyẹ ìṣẹ́gun ńlá tí yóò wáyé lẹ́yìn ọjọ́ Jèhófà. Ayẹyẹ ńlá wáyé lẹ́yìn tí Fáráò àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ ṣègbé sínú Òkun Pupa. (Ẹ́kísódù 15:1-21) Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ayẹyẹ ìṣẹ́gun yóò wáyé lẹ́yìn tá a bá mú Sátánì àti ayé rẹ̀ kúrò nígbà ìpọ́njú ńlá. Àwọn olóòótọ́ tó la ọjọ́ Jèhófà já yóò ké jáde pé: “Ẹ jẹ́ kí a kún fún ìdùnnú kí a sì máa yọ̀ nínú ìgbàlà láti ọ̀dọ̀ rẹ̀.” (Aísáyà 25:9) Ayọ̀ ọ̀hún yóò mà pọ̀ lọ́jọ́ yẹn o, nígbà tá a bá dá ipò ọba aláṣẹ Jèhófà láre, tí a sì fọ ayé mọ́, tó di ibùgbé àlàáfíà!

Àwọn Oníṣọ́ọ̀ṣì Ń Fara Wé Ísírẹ́lì

7, 8. Ṣàpèjúwe bí ipò tẹ̀mí Ísírẹ́lì ṣe rí nígbà ayé Málákì.

7 Àwọn tó wà ní ipò ojú rere lọ́dọ̀ Jèhófà làwọn tó ń sìn ín, kì í ṣe àwọn tí kò sìn ín. Bákan náà ló rí nígbà tí Málákì kọ̀wé rẹ̀. Ọdún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa la mú ìyókù orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì padà bọ̀ lẹ́yìn àádọ́rin ọdún tí wọ́n fi wà ní ìgbèkùn Bábílónì. Àmọ́, ní ohun tó lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún lẹ́yìn náà, orílẹ̀-èdè tá a mú padà bọ̀ sípò náà tún bẹ̀rẹ̀ sí padà sínú ìpẹ̀yìndà àti ìwà ibi. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn èèyàn náà ń tàbùkù sí orúkọ Jèhófà; wọn ò náání àwọn òfin òdodo rẹ̀; wọ́n sì ń sọ tẹ́ńpìlì rẹ̀ dìbàjẹ́ nípa mímú àwọn ẹran tó fọ́jú, èyí tó yarọ, àti èyí tó ń ṣàìsàn wá fún ìrúbọ. Wọ́n sì ń jáwèé ìkọ̀sílẹ̀ fún àwọn aya ìgbà èwe wọn.

8 Ìyẹn ló jẹ́ kí Jèhófà sọ fún wọn pé: “Dájúdájú, èmi yóò sì sún mọ́ yín fún ìdájọ́, èmi yóò sì di ẹlẹ́rìí yíyára kánkán lòdì sí àwọn oníṣẹ́ oṣó, àti lòdì sí àwọn panṣágà, àti lòdì sí àwọn tí ń ṣe ìbúra èké, àti lòdì sí àwọn tí ń lu jìbìtì sí owó ọ̀yà òṣìṣẹ́ tí ń gbowó ọ̀yà, sí opó àti sí ọmọdékùnrin aláìníbaba, àti àwọn tí ń lé àtìpó dànù, nígbà tí wọn kò bẹ̀rù mi, . . . nítorí èmi ni Jèhófà; èmi kò yí padà.” (Málákì 3:5, 6) Síbẹ̀, Jèhófà pàrọwà fún àwọn tó bá fẹ́ fi àwọn ọ̀nà búburú wọn sílẹ̀, ó ní: “Ẹ padà sọ́dọ̀ mi, dájúdájú, èmi yóò sì padà sọ́dọ̀ yín.”—Málákì 3:7.

9. Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ Málákì ṣe ní ìmúṣẹ ìṣáájú?

9 Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn tún ní ìmúṣẹ ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa. Àṣẹ́kù àwọn Júù tó sin Jèhófà di ara “orílẹ̀-èdè” tuntun ti àwọn Kristẹni tá a fẹ̀mí yàn, a sì fi àwọn Kèfèrí kún wọn lẹ́yìn náà. Àmọ́ ọ̀pọ̀ jù lọ Ísírẹ́lì àbínibí ló kọ Jésù sílẹ̀. Ìdí nìyẹn tí Jésù fi sọ fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì pé: “Wò ó! A pa ilé yín tì fún yín.” (Mátíù 23:38; 1 Kọ́ríńtì 16:22) Ní ọdún 70 Sànmánì Tiwa, gẹ́gẹ́ bí Málákì 4:1 ti sọ tẹ́lẹ̀, “ọjọ́ náà . . . tí ń jó bí ìléru” dé bá Ísírẹ́lì ti ara. Wọ́n pa Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ run, a sì gbọ́ pé ìyàn, ìfagagbága, àti ogun táwọn ọmọ ogun Róòmù gbé wá jà wọ́n, ṣekú pa iye àwọn tó ju mílíọ̀nù kan lọ. Àmọ́, àwọn tó sin Jèhófà bọ́ lọ́wọ́ ìpọ́njú ńlá yẹn.—Máàkù 13:14-20.

10. Ọ̀nà wo làwọn èèyàn lápapọ̀ àtàwọn àlùfáà gbà ń fara wé Ísírẹ́lì ọ̀rúndún kìíní?

10 Aráyé, àgàgà àwọn tó ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì, ń fara wé orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ti ọ̀rúndún kìíní. Àwọn èèyàn tó ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì àtàwọn aṣáájú wọn fẹ́ràn àwọn ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn tiwọn ju àwọn òtítọ́ Ọlọ́run tí Jésù fi kọ́ni lọ. Àwọn àlùfáà ló jẹ̀bi ọ̀rọ̀ náà ní pàtàkì. Wọ́n kọ̀ láti lo orúkọ Jèhófà, àní wọ́n yọ ọ́ kúrò nínú ọ̀pọ̀ ẹ̀dà Bíbélì wọn. Wọ́n ń fi àwọn ẹ̀kọ́ tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu, àwọn ẹ̀kọ́ kèfèrí bí ìdálóró ayérayé nínú ọ̀run àpáàdì, ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan, àìleèkú ọkàn, àti ẹfolúṣọ̀n tàbùkù Jèhófà. Wọ́n tipa bẹ́ẹ̀ ń fi ìyìn tó yẹ orúkọ Jèhófà dù ú, gẹ́gẹ́ bí àwọn àlùfáà ọjọ́ Málákì ti ṣe.

11. Báwo làwọn ìsìn ayé ṣe fi ẹni náà gan-an táwọn ń sìn hàn?

11 Nígbà táwọn ọjọ́ ìkẹyìn bẹ̀rẹ̀ ní 1914, àwọn ẹ̀sìn ayé yìí, àgàgà àwọn tó ń pera wọn ní Kristẹni, fi ẹni náà gan-an táwọn ń sìn hàn. Nígbà tí Ogun Àgbáyé méjèèjì ń jà lọ́wọ́, wọ́n rọ àwọn ọmọ ìjọ wọn pé kí wọ́n lọ sójú ogun nítorí aáwọ̀ àárín àwọn orílẹ̀-èdè, kódà bí ìyẹn tiẹ̀ máa jẹ́ kí wọ́n pa àwọn ọmọ ìjọ tiwọn pàápàá. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi àwọn tó ń ṣègbọràn sí Jèhófà àtàwọn tí kò ṣègbọràn sí i hàn kedere, ó sọ pé: “Àwọn ọmọ Ọlọ́run àti àwọn ọmọ Èṣù hàn gbangba nípasẹ̀ òtítọ́ yìí: Olúkúlùkù ẹni tí kì í bá a lọ ní ṣíṣe òdodo kò pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí kò nífẹ̀ẹ́ arákùnrin rẹ̀. Nítorí èyí ni ìhìn iṣẹ́ tí ẹ ti gbọ́ láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀, pé a ní láti ní ìfẹ́ ara wa lẹ́nì kìíní-kejì; kì í ṣe bí Kéènì, ẹni tí ó pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ ẹni burúkú náà, tí ó sì fikú pa arákùnrin rẹ̀.”—1 Jòhánù 3:10-12.

Mímú Àsọtẹ́lẹ̀ Ṣẹ

12, 13. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wo làwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ń mú ṣẹ lákòókò tá a wà yìí?

12 Nígbà tí Ogun Àgbáyé Kìíní fi máa parí ní 1918, àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà rí i pé Ọlọ́run ti dẹ́bi fún àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì àti gbogbo ìsìn èké yòókù. Látìgbà yẹn ni ìpè náà ti dún jáde fún àwọn olódodo pé: “Ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀, ẹ̀yin ènìyàn mi, bí ẹ kò bá fẹ́ ṣàjọpín pẹ̀lú rẹ̀ nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, bí ẹ kò bá sì fẹ́ gbà lára àwọn ìyọnu àjàkálẹ̀ rẹ̀. Nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ti wọ́ jọpọ̀ títí dé ọ̀run, Ọlọ́run sì ti mú àwọn ìṣe àìṣèdájọ́ òdodo rẹ̀ wá sí ìrántí.” (Ìṣípayá 18:4, 5) A bẹ̀rẹ̀ sí fọ àbààwọ́n ẹ̀sìn èké kúrò lára gbogbo àwọn tó fẹ́ sin Jèhófà. Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí wàásù ìhìn rere Ìjọba tó ti fìdí múlẹ̀ náà kárí ayé, ìyẹn iṣẹ́ tá a gbọ́dọ̀ parí kí òpin ètò búburú ìsinsìnyí tó dé.—Mátíù 24:14.

13 Èyí jẹ́ láti mu àsọtẹ́lẹ̀ inú Málákì 4:5 ṣẹ, níbi tí Jèhófà ti sọ pé: “Wò ó! Èmi yóò rán Èlíjà wòlíì sí yín ṣáájú dídé ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù ti Jèhófà.” Ìgbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jòhánù Oníbatisí, ẹni tí Èlíjà ṣàpẹẹrẹ rẹ̀, ni àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ní ìmúṣẹ rẹ̀ àkọ́kọ́. Jòhánù ṣe irú iṣẹ́ tí Èlíjà ṣe nígbà tó batisí àwọn Júù tó ronú pìwà dà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá sí májẹ̀mú Òfin. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, Jòhánù lẹni tá a rán ṣíwájú Mèsáyà. Àmọ́, ńṣe ni iṣẹ́ Jòhánù wulẹ̀ mú àsọtẹ́lẹ̀ Málákì ṣẹ lọ́nà ráńpẹ́. Bí Jésù ṣe sọ̀rọ̀ Jòhánù gẹ́gẹ́ bí Èlíjà kejì fi hàn pé a ṣì máa ṣe irú iṣẹ́ tí “Èlíjà” ṣe lọ́jọ́ iwájú.—Mátíù 17:11, 12.

14. Iṣẹ́ pàtàkì wo la gbọ́dọ̀ ṣe kí ètò yìí tó dópin?

14 Àsọtẹ́lẹ̀ Málákì fi hàn pé a ó ṣe iṣẹ́ Èlíjà títóbi yìí ṣáájú dídé “ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù ti Jèhófà.” Ọjọ́ yẹn yóò dé òtéńté rẹ̀ nínú ogun Amágẹ́dọ́nì, tí í ṣe ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè tó kù sí dẹ̀dẹ̀ báyìí. Èyí túmọ̀ sí pé iṣẹ́ kan tó bá ìgbòkègbodò Èlíjà mu yóò wáyé kí òpin ètò àwọn nǹkan búburú yìí tó dé, kí Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀run lábẹ́ Jésù Kristi tá a ti gbé gorí ìtẹ́ tó bẹ̀rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ náà sì ti wí, kí Jèhófà tó pa ètò búburú yìí run, ẹgbẹ́ Èlíjà òde òní, tí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wọn tó ní ìrètí ti orí ilẹ̀ ayé ń tì lẹ́yìn, ń fi taratara ṣe iṣẹ́ mímú ìjọsìn mímọ́ bọ̀ sípò, wọ́n ń gbé orúkọ Jèhófà ga, wọ́n sì ń fi òtítọ́ Bíbélì kọ́ àwọn ẹni bí àgùntàn.

Jèhófà Ń Bù Kún Àwọn Ìránṣẹ́ Rẹ̀

15. Báwo ni Jèhófà ṣe ń rántí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀?

15 Jèhófà ń bù kún àwọn tó ń sìn ín. Málákì 3:16 sọ pé: “Ní àkókò yẹn, àwọn tí ó bẹ̀rù Jèhófà bá ara wọn sọ̀rọ̀ lẹ́nì kìíní-kejì, olúkúlùkù pẹ̀lú alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀, Jèhófà sì ń fiyè sí i, ó sì ń fetí sílẹ̀. Ìwé ìrántí kan ni a sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ sílẹ̀ níwájú rẹ̀ fún àwọn tí ó bẹ̀rù Jèhófà àti fún àwọn tí ń ronú lórí orúkọ rẹ̀.” Látìgbà Ébẹ́lì síwájú ni Ọlọ́run ti ń kọ orúkọ àwọn èèyàn tí yóò fi ìyè àìnípẹ̀kun dá lọ́lá sínú ìwé kan, lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. Àwọn wọ̀nyí ni Jèhófà sọ fún pé: “Ẹ mú gbogbo ìdá mẹ́wàá wá sínú ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́, kí oúnjẹ bàa lè wà nínú ilé mi; kí ẹ sì jọ̀wọ́, dán mi wò nínú ọ̀ràn yìí . . . bóyá èmi kì yóò ṣí ibodè ibú omi ọ̀run fún yín, kí èmi sì tú ìbùkún dà sórí yín ní ti tòótọ́ títí kì yóò fi sí àìní mọ́.”—Málákì 3:10.

16, 17. Báwo ni Jèhófà ṣe bù kún àwọn èèyàn rẹ̀ àti iṣẹ́ wọn?

16 Láìsí àní-àní, Jèhófà ti bù kún àwọn tó ń sìn ín. Lọ́nà wo? Òye tó túbọ̀ kún rẹ́rẹ́ nípa àwọn ète rẹ̀ jẹ́ ọ̀nà kan. (Òwe 4:18; Dáníẹ́lì 12:10) Ọ̀nà mìíràn ni nípa jíjẹ́ kí iṣẹ́ ìwàásù wọn so èso jìngbìnnì. Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn olóòótọ́ ọkàn ló ti dara pọ̀ mọ́ wọn nínú ìjọsìn tòótọ́. Àwọn wọ̀nyí ló para pọ̀ di “ogunlọ́gọ̀ ńlá, . . . láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n, . . . wọ́n sì ń bá a nìṣó ní kíké pẹ̀lú ohùn rara, pé: ‘Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wa, ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́, àti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà ni ìgbàlà wa ti wá.’” (Ìṣípayá 7:9, 10) Ogunlọ́gọ̀ ńlá yìí ti fara hàn lọ́nà àgbàyanu. Iye àwọn tó ń fi taratara sin Jèhófà mà ti lé ní mílíọ̀nù mẹ́fà báyìí, nínú àwọn ìjọ tó lé ní ọ̀kẹ́ mẹ́rin lé ẹ̀ẹ́dégbèje [93,000] kárí ayé!

17 Kò mọ síbẹ̀ o, Jèhófà tún ń bù kún wa ní ti pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tíì pín àwọn ìwé tí ń ṣàlàyé Bíbélì kiri jù lọ nínú gbogbo ìtàn. Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, nǹkan bí àádọ́rùn-ún [90] mílíọ̀nù ẹ̀dà ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! là ń tẹ̀ jáde lóṣooṣù, à ń tẹ Ilé Ìṣọ́ ní èdè mọ́kànlélógóje [144], a sì ń tẹ Jí! ní èdè mẹ́tàdínláàádọ́rùn-ún [87]. Iye ẹ̀dà tá a pín kiri nínú ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà, Otitọ ti Nsinni Lọ si Iye Aiyeraiye, tá a tẹ̀ jáde ní 1968, lé ní mílíọ̀nù mẹ́tàdínláàádọ́fà [107] ní èdè mẹ́tàdínlọ́gọ́fà [117]. Ìwé Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye, tá a mú jáde ní 1982, lé ní mílíọ̀nù mọ́kànlélọ́gọ́rin [81] ẹ̀dà ní èdè mọ́kànléláàádóje [131]. Ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, tá a mú jáde ní 1995, ti ní ẹ̀dà tó lé ní mílíọ̀nù márùnlélọ́gọ́rin ní èdè mẹ́rìnléláàádọ́jọ [154] báyìí. Iye tá a ti pín kiri nínú ẹ̀dà ìwé pẹlẹbẹ náà, Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?, èyí tá a mú jáde ní 1996, jẹ́ àádọ́jọ [150] mílíọ̀nù ní ìgbà ó lé mẹ́rìnlélógójì [244] èdè báyìí.

18. Èé ṣe tá a fi ń gbádùn aásìkí tẹ̀mí láìfi àtakò pè?

18 A sì ti gbádùn aásìkí nípa tẹ̀mí yìí láìfi àtakò gbígbóná janjan tó ti wà tipẹ́ látọ̀dọ̀ ayé Sátánì pè. Èyí fi hàn pé òótọ́ lọ̀rọ̀ tó wà nínú Aísáyà 54:17 pé: “‘Ohun ìjà yòówù tí a bá ṣe sí ọ kì yóò ṣe àṣeyọrí sí rere, ahọ́n èyíkéyìí tí ó bá sì dìde sí ọ nínú ìdájọ́ ni ìwọ yóò dá lẹ́bi. Èyí ni ohun ìní àjogúnbá àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà, ọ̀dọ̀ mi sì ni òdodo wọn ti wá,’ ni àsọjáde Jèhófà.” Ó mà ń tu àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà nínú o, láti mọ̀ pé àwọn gan-an ni Málákì 3:17 ń ṣẹ sí lára: “‘Dájúdájú, wọn yóò sì di tèmi,’ ni Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí, ‘ní ọjọ́ náà nígbà tí èmi yóò mú àkànṣe dúkìá wá.’”

Sísin Jèhófà Tayọ̀tayọ̀

19. Báwo làwọn tó ń sin Jèhófà ṣe yàtọ̀ sí àwọn tí kò sìn ín?

19 Bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́ ni ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà àtàwọn tó wà nínú ayé Sátánì túbọ̀ ń hàn gbangba-gbàǹgbà. Málákì 3:18 sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Dájúdájú, ẹ ó sì tún rí ìyàtọ̀ láàárín olódodo àti ẹni burúkú, láàárín ẹni tí ń sin Ọlọ́run àti ẹni tí kò sìn ín.” Ọ̀kan lára ọ̀pọ̀ ìyàtọ̀ náà ni pé àwọn tó ń sin Jèhófà ń ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ayọ̀ ńlá. Ọ̀kan lára ìdí tí èyí fi rí bẹ́ẹ̀ ni ìrètí àgbàyanu tí wọ́n ní. Wọ́n ní ìgbọ́kànlé kíkún nínú Jèhófà, nígbà tó sọ pé: “Èmi yóò dá ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun; àwọn ohun àtijọ́ ni a kì yóò sì mú wá sí ìrántí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò wá sí ọkàn-àyà. Ṣùgbọ́n ẹ yọ ayọ̀ ńláǹlà, kí ẹ sì kún fún ìdùnnú títí láé nínú ohun tí èmi yóò dá.”—Aísáyà 65:17, 18; Sáàmù 37:10, 11, 29; Ìṣípayá 21:4, 5.

20. Kí nìdí tá a fi jẹ́ ènìyàn aláyọ̀?

20 A gba ìlérí tí Jèhófà ṣe gbọ́ pé àwọn èèyàn òun tó jẹ́ adúróṣinṣin yóò la ọjọ́ ńlá òun já, a ó sì mú wọn wọ ayé tuntun. (Sefanáyà 2:3; Ìṣípayá 7:13, 14) Bí ọjọ́ ogbó, àìsàn, tàbí jàǹbá bá tiẹ̀ mú kí àwọn kan sùn nínú ikú ṣáájú àkókò yẹn, Jèhófà mú un dá wa lójú pé òun yóò jí wọn dìde sí ìyè àìnípẹ̀kun. (Jòhánù 5:28, 29; Títù 1:2) Nítorí náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé bí a ti ń sún mọ́ òpin ọjọ́ Jèhófà yìí, gbogbo wa la ní àwọn ìṣòro àti ìpèníjà tí à ń bá yí, síbẹ̀ àwa ló yẹ ká láyọ̀ jù lọ lórí ilẹ̀ ayé.

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

• Kí ni “ọjọ́ Jèhófà”?

• Báwo làwọn ìsìn ayé ṣe ń fara wé Ísírẹ́lì ìgbàanì?

• Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wo ló ń ṣẹ sí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lára?

• Báwo ni Jèhófà ṣe ń bù kún àwọn ènìyàn rẹ̀?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Jerúsálẹ́mù ọ̀rúndún kìíní “jó bí ìléru”

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Jèhófà ń pèsè fún àwọn tó ń sìn ín

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà jẹ́ aláyọ̀ ní tòótọ́ nítorí ìrètí àgbàyanu tí wọ́n ní