Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Nígbà tí Jòhánù rí “ogunlọ́gọ̀ ńlá” tí ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ nínú tẹ́ńpìlì Jèhófà, apá ibo ni wọ́n ti ń ṣe iṣẹ́ ìsìn yìí nínú tẹ́ńpìlì náà?—Ìṣípayá 7:9-15.

Ó bọ́gbọ́n mu láti sọ pé ogunlọ́gọ̀ ńlá ń jọ́sìn Jèhófà ní ọ̀kan lára àwọn àgbàlá orí ilẹ̀ ayé nínú tẹ́ńpìlì tẹ̀mí títóbi rẹ̀. Ní pàtó, àgbàlá tó dọ́gba pẹ̀lú àgbàlá ti òde ní tẹ́ńpìlì Sólómọ́nì ni.

Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, ohun tá a máa ń sọ ni pé ogunlọ́gọ̀ ńlá wà nínú àgbàlá tẹ̀mí tó dúró fún Àgbàlá àwọn Kèfèrí tó wà nígbà ayé Jésù. Àmọ́ o, ìwádìí síwájú sí i ti jẹ́ ká rí i pé ọ̀ràn ò rí bẹ́ẹ̀, ó kéré tán fún ìdí márùn-ún. Èkíní, kì í ṣe gbogbo ohun tó wà nínú tẹ́ńpìlì ti Hẹ́rọ́dù ló ní ohun tó dúró fún nínú tẹ́ńpìlì tẹ̀mí títóbi ti Jèhófà. Fún àpẹẹrẹ, tẹ́ńpìlì Hẹ́rọ́dù ní Àgbàlá àwọn Obìnrin àti Àgbàlá Ísírẹ́lì. Tọkùnrin tobìnrin ló lè wọ Àgbàlá àwọn Obìnrin. Àmọ́ àwọn ọkùnrin nìkan ló lè wọ Àgbàlá Ísírẹ́lì. Nínú àwọn àgbàlá orí ilẹ̀ ayé ti tẹ́ńpìlì tẹ̀mí títóbi ti Jèhófà, ńṣe ni tọkùnrin tobìnrin ń jọ́sìn pa pọ̀. (Gálátíà 3:28, 29) Ìyẹn ló fi jẹ́ pé kò sí ibì kankan tó dúró fún Àgbàlá àwọn Obìnrin àti Àgbàlá Ísírẹ́lì nínú tẹ́ńpìlì tẹ̀mí.

Ìkejì, kò sí Àgbàlá àwọn Kèfèrí nínú àwòrán tẹ́ńpìlì tí Ọlọ́run gbé kalẹ̀ fún tẹ́ńpìlì Sólómọ́nì tàbí tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran; bẹ́ẹ̀ náà ni kò sí Àgbàlá àwọn Kèfèrí nínú tẹ́ńpìlì tí Serubábélì tún kọ́. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé kò sídìí láti gbà pé Àgbàlá àwọn Kèfèrí yóò wà nínú ìṣètò tẹ́ńpìlì tẹ̀mí títóbi ti Jèhófà, èyí tó wà fún ìjọsìn, àgàgà tá a bá gbé kókó kẹta yẹ̀ wò.

Ìkẹta, Ọba Hẹ́rọ́dù ará Édómù ló kọ́ Àgbàlá àwọn Kèfèrí láti fi ṣe ara rẹ̀ lógo, kí ó sì fi wá ojú rere Róòmù. Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ ọdún 18 tàbí 17 ṣááju Sànmánì Tiwa ni Hẹ́rọ́dù bẹ̀rẹ̀ sí ṣàtúnṣe tẹ́ńpìlì Serubábélì. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, The Anchor Bible Dictionary ṣàlàyé pé: “Àwọn ilé ràgàjì tó jẹ́ ààyò ilẹ̀ ọba Ìwọ̀ Oòrùn [ìyẹn Róòmù] . . . á jẹ́ kí wọ́n fẹ́ láti kọ́ tẹ́ńpìlì tó tóbi ju irú àwọn èyí tó wà ní àwọn ìlú ìlà oòrùn.” Ṣùgbọ́n a ti díwọ̀n bí tẹ́ńpìlì náà ṣe gbọ́dọ̀ fẹ̀ tó. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà ṣàlàyé pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Tẹ́ńpìlì náà kò gbọ́dọ̀ fẹ̀ ju àwọn tẹ́ńpìlì tó wà ṣáájú rẹ̀ [ìyẹn tẹ́ńpìlì ti Sólómọ́nì àti ti Serubábélì], orí Òkè Tẹ́ńpìlì kò ní ààlà ibi tó lè fẹ̀ dé.” Ìdí nìyẹn tí Hẹ́rọ́dù fi fẹ ilẹ̀ àyíká tẹ́ńpìlì náà, tó fi ohun tá à ń pè ní Àgbàlá àwọn Kèfèrí lóde òní kún un. Ṣé ó wá yẹ kí irú àfikún yẹn ní alábàádọ́gba nínú ìṣètò tẹ́ńpìlì tẹ̀mí ti Jèhófà?

Ìkẹrin, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo èèyàn—àti afọ́jú àti arọ àti Kèfèrí aláìdádọ̀dọ́—ló ń wọ Àgbàlá àwọn Kèfèrí. (Mátíù 21:14, 15) Òótọ́ ni pé àgbàlá náà wúlò fún ọ̀pọ̀ Kèfèrí aláìdádọ̀dọ́ tí wọ́n fẹ́ rú ẹbọ sí Ọlọ́run. Ibẹ̀ ni Jésù ti máa ń bá àwọn ogunlọ́gọ̀ sọ̀rọ̀ nígbà mìíràn. Ẹ̀ẹ̀mejì ló sì lé àwọn tí ń ṣe pàṣípààrọ̀ owó àtàwọn oníṣòwò kúrò níbẹ̀, tó sọ fún wọn pé wọ́n ti tàbùkù sí ilé Bàbá òun. (Mátíù 21:12, 13; Jòhánù 2:14-16) Síbẹ̀, The Jewish Encyclopedia sọ pé: “Tá a bá ní ká sọ bí ọ̀rọ̀ ṣe jẹ́ gan-an, àgbàlá òde yìí kì í ṣe ara Tẹ́ńpìlì. Orí ilẹ̀ tá a kọ́ ọ sí kì í ṣe ilẹ̀ mímọ́. Ẹnikẹ́ni ló sì lè débẹ̀.”

Ìkarùn-ún, ọ̀rọ̀ èdè Gíríìkì náà (hi·e·ron’) tá a tú sí “tẹ́ńpìlì,” tá a lò nígbà tá a tọ́ka sí Àgbàlá àwọn Kèfèrí “tọ́ka sí gbogbo ọgbà yẹn, kì í ṣe Tẹ́ńpìlì náà gan-an,” ìyẹn gẹ́gẹ́ bí ìwé náà A Handbook on the Gospel of Matthew, látọwọ́ Barclay M. Newman àti Philip C. Stine ṣe wí. Ní ìyàtọ̀ sí èyí, ọ̀rọ̀ èdè Gíríìkì náà (na·os’) tá a tú sí “tẹ́ńpìlì” nínú ìran Jòhánù nípa ogunlọ́gọ̀ ńlá náà tọ́ka pàtó sí ilé náà. Nígbà tá a bá lo ọ̀rọ̀ náà fún tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù, Ibi Mímọ́ Jù Lọ, ilé tẹ́ńpìlì náà gan-an tàbí àgbègbè tẹ́ńpìlí ló sábà máa ń tọ́ka sí. Nígbà míì, a máa ń túmọ̀ rẹ̀ sí “ibùjọsìn.”—Mátíù 27:5, 51; Lúùkù 1:9, 21; Jòhánù 2:20.

Àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù. Wọ́n jẹ́ mímọ́ nípa tẹ̀mí, nítorí pé wọ́n ti “fọ aṣọ wọn, wọ́n sì ti sọ wọ́n di funfun nínú ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.” Ìdí nìyẹn tá a fi polongo wọn ní olódodo pẹ̀lú ìrètí dídi ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, kí wọ́n sì la ìpọ́njú ńlá já. (Jákọ́bù 2:23, 25) Lọ́pọ̀ ọ̀nà ni wọ́n fi dà bí àwọn aláwọ̀ṣe ní Ísírẹ́lì, tí wọ́n ń pa májẹ̀mú Òfin mọ́, tí wọ́n sì ń jọ́sìn ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.

Àmọ́ o, àwọn aláwọ̀ṣe wọ̀nyẹn kì í sìn nínú àgbàlá inú lọ́hùn-ún, níbi tí àwọn àlùfáà ti ń ṣe iṣẹ́ wọn. Àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá kò sí nínú àgbàlá inú lọ́hùn-ún ti tẹ́ńpìlì tẹ̀mí títóbi ti Jèhófà, tí àgbàlá rẹ̀ dúró fún ipò jíjẹ́ tí àwọn “àlùfáà mímọ́” fún Jèhófà jẹ́ ọmọ pípé, tí wọ́n sì jẹ́ olódodo nígbà tí wọ́n ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé. (1 Pétérù 2:5) Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí alàgbà ọ̀run yẹn ti sọ fún Jòhánù, inú tẹ́ńpìlì gangan ni ogunlọ́gọ̀ ńlá náà wà, kì í ṣe lóde àgbègbè tẹ́ńpìlì, níbi tí wọ́n ń pè ní Agbala àwọn Kèfèrí nípa tẹ̀mí. Àǹfààní ńlá mà lèyí o! Ẹ sì wo bó ṣe fi hàn pé ó ṣe pàtàkì kí olúkúlùkù wà ní mímọ́ nípa tẹ̀mí àti ní ti ìwà rere ní gbogbo ìgbà!

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

Tẹ́ńpìlì Sólómọ́nì

1. Ilé Tẹ́ńpìlì

2. Àgbàlá ti Inú

3. Àgbàlá ti Òde

4. Àtẹ̀gùn tó lọ sí Àgbàlá Tẹ́ńpìlì