Bí Ìṣòro Jíjẹ́ Aláàbọ̀ Ara Kò Ṣe Ní Sí Mọ́
Bí Ìṣòro Jíjẹ́ Aláàbọ̀ Ara Kò Ṣe Ní Sí Mọ́
F OJÚ inú wò ó pé àwọn afọ́jú ń ríran, etí àwọn adití ń gbọ́ gbogbo nǹkan pátá, ahọ́n àwọn odi ń kọrin ayọ̀, ẹsẹ̀ àwọn arọ le pọ́nkí, wọ́n sì ń rìn káàkiri! Ìmọ̀ ìṣègùn kọ́ ló ń pa gbogbo itú yìí o. Ohun tí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ṣe fún ọmọ aráyé ni o. Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Ní àkókò yẹn, ojú àwọn afọ́jú yóò là, etí àwọn adití pàápàá yóò sì ṣí. Ní àkókò yẹn, ẹni tí ó yarọ yóò gun òkè gan-an gẹ́gẹ́ bí akọ àgbọ̀nrín ti ń ṣe, ahọ́n ẹni tí kò lè sọ̀rọ̀ yóò sì fi ìyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ ké jáde.” (Aísáyà 35:5, 6) Àmọ́ báwo ló ṣe dá wa lójú pé àsọtẹ́lẹ̀ àgbàyanu tòótọ́ yìí yóò nímùúṣẹ?
Bí a bá tibi pẹlẹbẹ mọ́ọ̀lẹ̀ jẹ, a ó rí i pé nígbà tí Jésù Kristi wà lórí ilẹ̀ ayé, lóòótọ́ ló mú àwọn èèyàn tó ní ọ̀kan-kò-jọ̀kan àìsàn àti àìlera lára dá. Ìyẹn nìkan kọ́ o, ọ̀pọ̀ jù lọ iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ ló ṣojú ẹlẹ́rìí púpọ̀—títí kan àwọn ọ̀tá rẹ̀ pàápàá. Àní, ó kéré tán nígbà kan, àwọn alátakò tí ń ṣiyèméjì tọpinpin ìwòsàn kan tí Jésù ṣe, kí wọ́n lè bẹnu àtẹ́ lù ú. Àmọ́ ẹnu wọn wọhò nígbà tí gbogbo ìwádìí wọ́n fi hàn pé òótọ́ ni iṣẹ́ ìyanu yẹn wáyé. (Jòhánù 9:1, 5-34) Lẹ́yìn tí Jésù tún ṣe iṣẹ́ ìyanu mìíràn tí kò ṣeé sẹ́, ńṣe ni jẹbẹtẹ gbọ́mọ lé wọn lọ́wọ́, tí wọ́n wá sọ pé: “Kí ni kí a ṣe, nítorí ọkùnrin yìí ń ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ àmì?” (Jòhánù 11:47) Ṣùgbọ́n àwọn èèyàn yòókù kò ya òṣónú bíi tiwọn. Ńṣe ni ọ̀pọ̀ lára wọn bẹ̀rẹ̀ sì gba Jésù gbọ́.—Jòhánù 2:23; 10:41, 42; 12:9-11.
Iṣẹ́ Ìyanu Jésù Jẹ́ Àpẹẹrẹ Ìwòsàn Kárí Ayé
Kì í ṣe kìkì pé Jésù ni Mèsáyà àti Ọmọ Ọlọ́run nìkan ni àwọn iṣẹ́ ìyanu Jésù fi hàn, àwọn iṣẹ́ ìyanu náà tún jẹ́ káwọn èèyàn gba àwọn ìlérí Bíbélì gbọ́ pé aráyé onígbọràn yóò rí ìwòsàn lọ́jọ́ iwájú. Ara ìlérí wọ̀nyí ni àsọtẹ́lẹ̀ inú Aísáyà orí karùndínlógójì, tá a tọ́ka sí ní ìpínrọ̀ tó bẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí. Aísáyà 33:24 sọ nípa ìlera ọjọ́ iwájú àwọn olùbẹ̀rù Ọlọ́run pé: “Kò . . . sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’” Bákan náà, Ìṣípayá 21:4 ṣèlérí pé: “[Ọlọ́run] yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ [ìyẹn, àwọn àdánwò àti ìyà òde òní] ti kọjá lọ.”
Léraléra làwọn èèyàn ń gbàdúrà pé kí àsọtẹ́lẹ̀ Mátíù 6:10, Bibeli Mimọ) Bẹ́ẹ̀ ni o, ìfẹ́ Ọlọ́run kan ilẹ̀ ayé àti aráyé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé nítorí ìdí kan, ó fàyè gba àìsàn àti ìṣòro jíjẹ́ aláàbọ̀ ara, láìpẹ́ ìṣòro wọ̀nyẹn ò ní sí mọ́; wọn ò ní máa tàbùkù sí “àpótí ìtìsẹ̀” Ọlọ́run títí láé.—Aísáyà 66:1. a
wọ̀nyí nímùúṣẹ nígbà tí wọ́n bá ń gba àdúrà tí Jésù kọ́ wa. Ara àdúrà náà ni pé: “Ki ijọba rẹ de; Ifẹ tirẹ ni ki a ṣe, bi ti ọrun, bẹni li aiye.” (Ìwòsàn Ọ̀fẹ́ Tí Yóò Dé Wẹ́rẹ́
Láìka irú àìsàn yòówù tó ń pọ́n àwọn èèyàn lójú sí, wẹ́rẹ́ báyìí ni Jésù wò wọ́n sàn, lójú ẹsẹ̀, láìgba kọ́bọ̀ lọ́wọ́ wọn. Kíá ni òkìkí ohun tó ṣe kàn jákèjádò, láìpẹ́ sì ni “àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá tọ̀ ọ́ wá, tí wọ́n mú àwọn ènìyàn tí wọ́n yarọ, aláàbọ̀ ara, afọ́jú, odi, àti ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn wá pẹ̀lú wọn, wọ́n sì rọra gbé wọn kalẹ̀ síbi ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì wò wọ́n sàn.” Báwo ló ṣe rí lára àwọn èèyàn náà? Mátíù tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú rẹ̀ ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Ogunlọ́gọ̀ náà . . . ṣe kàyéfì bí wọ́n ti rí tí àwọn odi ń sọ̀rọ̀, tí àwọn arọ sì ń rìn, tí àwọn afọ́jú sì ń ríran, wọ́n sì yin Ọlọ́run Ísírẹ́lì lógo.”—Mátíù 15:30, 31.
Ṣàkíyèsí pé kì í ṣe pé Jésù dọ́gbọ́n ṣa àwọn tó wò sàn látinú ogunlọ́gọ̀ náà, gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹlẹ́tàn ti ń ṣe. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹbí àtọ̀rẹ́ àwọn aláìsàn ló “gbé wọn kalẹ̀ síbi ẹsẹ̀ [Jésù], ó sì wò wọ́n sàn.” Ẹ wá jẹ́ ká wo àwọn àpẹẹrẹ pàtó nípa agbára tí Jésù ní láti woni sàn.
Afọ́jú: Nígbà tí Jésù wà ní Jerúsálẹ́mù, ó la ojú ọkùnrin kan tó “fọ́jú láti ìgbà ìbí.” Wọ́n mọ afọ́jú tó ń ṣagbe yìí bí ẹní mowó nílùú yẹn. O lè wá fojú inú wo bó ṣe máa ya àwọn èèyàn lẹ́nu tó, tí ariwo á sì sọ, nígbà tí wọ́n rí i pé ọkùnrin yìí ti ríran, tó sì ń rìn kiri! Àmọ́, àwọn kan wà tínú wọn ò dùn. Àwọn kan nínú ẹ̀ya ìsìn Júù kan tí à ń pè ní Farisí, tí wọ́n gbajúmọ̀, tí wọ́n sì jẹ́ abẹnugan, tí inú ń bí nítorí pé Jésù ti tú wọn fó tẹ́lẹ̀, ń wá ẹ̀rí lọ́nàkọnà láti fẹ̀sùn gbájú-ẹ̀ kan Jésù. (Jòhánù 8:13, 42-44; 9:1, 6-31) Ìyẹn ló jẹ́ kí wọ́n lọ lu ọkùnrin tá a wò sàn náà lẹ́nu gbọ́rọ̀. Lẹ́yìn náà, wọ́n tún lọ bá àwọn òbí rẹ̀, lẹ́yìn èyí tí wọ́n tún wá bá ọkùnrin náà lẹ́ẹ̀kan sí i. Àmọ́, ṣe ni ìwádìí àwọn Farisí wulẹ̀ túbọ̀ fìdí iṣẹ́ ìyanu Jésù múlẹ̀, tó tún dá kún ìbínú wọn. Ìwà àyídáyidà àwọn alágàbàgebè ẹlẹ́sìn yìí ya ọkùnrin tá a wò sàn náà lẹ́nu gan-an, tó fi sọ pé: “Láti ìgbà láéláé, a kò gbọ́ ọ rí pé ẹnikẹ́ni la ojú ẹni tí a bí ní afọ́jú. Bí kì í bá ṣe ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ọkùnrin yìí ti wá, kò ní lè ṣe nǹkan kan rárá.” (Jòhánù 9:32, 33) Torí òótọ́ ọ̀rọ̀ tó mọ́gbọ́n dání, tó fi ìgbàgbọ́ hàn, tí ọkùnrin náà sọ yìí, ńṣe làwọn Farisí “sọ ọ́ síta,” tó túmọ̀ sí pé wọ́n lé ọkùnrin tó fọ́jú tẹ́lẹ̀ rí náà kúrò nínú sínágọ́gù.—Jòhánù 9:22, 34.
Adití: Nígbà tí Jésù wà ní Dekapólì, ìyẹn àgbègbè kan ní ìlà oòrùn Odò Jọ́dánì, àwọn ará ibẹ̀ “mú ọkùnrin adití kan tí ó sì ní ìṣòro ọ̀rọ̀ sísọ wá bá a.” (Máàkù 7:31, 32) Kì í ṣe kìkì pé Jésù wo ẹni yìí sàn nìkan ni, àmọ́ ó tún fi hàn pé òun mọ bí nǹkan ṣe ń rí lára àwọn adití, tó ṣeé ṣe kí ojú máa tì wọ́n láàárín èrò. Bíbélì sọ fún wa pé Jésù mú adití náà “kúrò lọ́dọ̀ ogunlọ́gọ̀ náà ní òun nìkan,” ó sì wò ó sàn. Bákan náà, ‘háà ṣe àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú wọn lọ́nà tí ó ṣe àrà ọ̀tọ̀ jù lọ,’ wọ́n sì wí pé: “Ó ti ṣe ohun gbogbo dáadáa. Ó tilẹ̀ ń mú kí àwọn adití gbọ́ràn, kí àwọn aláìlèsọ̀rọ̀ sì sọ̀rọ̀.”—Máàkù 7:33-37.
Àrùn ẹ̀gbà: Nígbà tí Jésù wà ní Kápánáúmù, àwọn èèyàn gbé alárùn ẹ̀gbà kan tó wà lórí bẹ́ẹ̀dì tọ̀ ọ́ wá. (Mátíù 9:2) Ẹsẹ kẹfà sí ìkẹjọ ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀. Ó ní: “[Jésù] sọ fún alárùn ẹ̀gbà náà pé: ‘Dìde, gbé ibùsùn rẹ, kí o sì máa lọ sí ilé rẹ.’ Ó sì dìde, ó sì lọ sí ilé rẹ̀. Ní rírí èyí, ẹ̀rù ba àwọn ogunlọ́gọ̀ náà, wọ́n sì yin Ọlọ́run lógo, ẹni tí ó fi irúfẹ́ ọlá àṣẹ bẹ́ẹ̀ fún àwọn ènìyàn.” Ìṣojú àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù àtàwọn ọ̀tá rẹ̀ ló ti ṣe iṣẹ́ ìyanu yìí pẹ̀lú. Ṣàkíyèsí pé àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù tí ìkórìíra àti ẹ̀tanú kò fọ́ ojú inú wọn “yin Ọlọ́run lógo” nítorí ohun tí wọ́n rí.
Máàkù 1:40-42) Ṣàkíyèsí pé Jésù kò lọ́ tìkọ̀ láti wo ẹni yìí sàn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìyọ́nú àtọkànwá ló sún un wò ó sàn. Ká sọ pé adẹ́tẹ̀ ni ẹ́. Báwo ló ṣe máa rí lára rẹ, ká sọ pé a wò ẹ́ sàn wẹ́rẹ́ báyẹn lójú ẹsẹ̀, tí wọ́n gbà ẹ́ lọ́wọ́ àìsàn burúkú tó ń ba ẹran ara rẹ jẹ́, tó sì sọ ẹ́ di ẹni ìtanù lẹ́gbẹ́? Dájúdájú, wàá rí ìdí tí adẹ́tẹ̀ mìíràn tí Jésù wò sàn lọ́nà iṣẹ́ ìyanu fi “dojú bolẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ Jésù, [tí] ó ń dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀.”—Lúùkù 17:12-16.
Àìsàn: “Adẹ́tẹ̀ kan pẹ̀lú sì wá sọ́dọ̀ [Jésù], ó ń pàrọwà fún un àní lórí ìkúnlẹ̀, ó wí fún un pé: ‘Bí ìwọ bá sáà ti fẹ́ bẹ́ẹ̀, ìwọ lè mú kí èmi mọ́.’ Látàrí ìyẹn, àánú ṣe é, ó sì na ọwọ́ rẹ̀, ó sì fọwọ́ kàn án, ó sì wí fún un pé: ‘Mo fẹ́ bẹ́ẹ̀. Kí ìwọ mọ́.’ Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ẹ̀tẹ̀ náà sì pòórá kúrò lára rẹ̀, ó sì mọ́.” (Ọgbẹ́: Iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe kẹ́yìn kí wọ́n tó mú un, tí wọ́n sì kàn án mọ́gi jẹ́ iṣẹ́ ìmúniláradá. Nígbà tí àpọ́sítélì Pétérù rí àwọn tó fẹ́ wá mú Jésù, ńṣe ló dìde wùyà, “bí ó ti ní idà kan, ó fà á yọ, ó ṣá ẹrú àlùfáà àgbà, ó sì gé etí rẹ̀ ọ̀tún dànù.” (Jòhánù 18:3-5, 10) Àkọsílẹ̀ tó bá a dọ́gba nínú ìwé Lúùkù sọ fún wa pé Jésù “fọwọ́ kan etí náà, ó sì mú un lára dá.” (Lúùkù 22:50, 51) Lẹ́ẹ̀kan sí i, oore tí Jésù ṣe yìí wáyé níṣojú àwọn ọ̀rẹ́ àti ọ̀tá rẹ̀—lọ́tẹ̀ yìí, ìyẹn àwọn tó wá mú un.
Àní sẹ́, bá a bá ṣe túbọ̀ fara balẹ̀ kíyè sí àwọn iṣẹ́ ìyanu Jésù la óò túbọ̀ rí i pé kò ní bojúbojú nínú rárá. (2 Tímótì 3:16) Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ ṣáájú, ó yẹ kí irú ìkẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀ jẹ́ kí ìgbàgbọ́ tá a ní nínú ìlérí Ọlọ́run pé yóò wo aráyé onígbọràn sàn lágbára sí i. Bíbélì pe ìgbàgbọ́ Kristẹni ní “ìfojúsọ́nà tí ó dáni lójú nípa àwọn ohun tí a ń retí, ìfihàn gbangba-gbàǹgbà àwọn ohun gidi bí a kò tilẹ̀ rí wọn.” (Hébérù 11:1) Dájúdájú, Ọlọ́run ò fẹ́ ìgbàgbọ́ oréfèé tàbí lílá àlá tí kò lè ṣẹ. Kàkà bẹ́ẹ̀ ohun tó fẹ́ ni ìgbàgbọ́ tó ní ẹ̀rí tí kò ṣeé já ní koro. (1 Jòhánù 4:1) Bá a ṣe túbọ̀ ń ní irú ìgbàgbọ́ yẹn, a óò rí i pé nípa tẹ̀mí, à ń lágbára sí i, ẹsẹ̀ wa túbọ̀ ń ranlẹ̀, a sì ń láyọ̀ sí i.—Mátíù 5:3; Róòmù 10:17.
Ìwòsàn Tẹ̀mí Ni Ohun Àkọ́kọ́!
Ọ̀pọ̀ èèyàn tí ara wọn le koko ni kò láyọ̀. Àwọn kan tiẹ̀ ti gbìdánwò láti pa ara wọn nítorí pé wọn ò ní ìrètí kankan fún ọjọ́ ọ̀la tàbí nítorí òkè ìṣòro tí wọ́n ń bá yí. Lẹ́nu kan, wọ́n jẹ́ aláìlera nípa tẹ̀mí—lójú Ọlọ́run ipò yìí burú ju jíjẹ́ aláàbọ̀ ara lásán lọ. (Jòhánù 9:41) Ní ọwọ́ kejì, ọ̀pọ̀ tó jẹ́ aláàbọ̀ ara, bíi Christian àti Junior, tá a mẹ́nu kàn nínú àpilẹ̀kọ ìṣáájú, jẹ́ aláyọ̀, ayé wọ́n sì dùn bí oyin. Èé ṣe? Nítorí pé ara wọn le nípa tẹ̀mí. Ìrètí dídájú tá a gbé ka Bíbélì sì ń fún wọn lókun.
Nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa ohun kòṣeémánìí àwa ọmọ aráyé, ó sọ pé: “Ènìyàn kì yóò wà láàyè nípasẹ̀ oúnjẹ nìkan ṣoṣo, bí kò ṣe nípasẹ̀ gbogbo àsọjáde tí ń jáde wá láti ẹnu Jèhófà.” (Mátíù 4:4) Bẹ́ẹ̀ ni o, láìdàbí ẹranko, kì í ṣe ohun ìgbẹ́mìíró nìkan lèèyàn nílò. Nítorí pé Ọlọ́run dá wa ní “àwòrán” ara rẹ̀, a nílò oúnjẹ tẹ̀mí—ìyẹn ìmọ̀ Ọlọ́run àti bí ète rẹ̀ àti ṣíṣe ìfẹ́ rẹ̀ ṣe kàn wá. (Jẹ́nẹ́sísì 1:27; Jòhánù 4:34) Ìmọ̀ Ọlọ́run ń jẹ́ kí ìgbésí ayé wa nítumọ̀, ó sì ń fún wa ní okun tẹ̀mí. Ó tún ń jẹ́ ká ní ìrètí ìyè ayérayé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. Jésù sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.”—Jòhánù 17:3.
Ó yẹ fún àfiyèsí pé àwọn èèyàn ìgbà ayé Jésù kò pè é ní “Oníwòsàn” bí kò ṣe “Olùkọ́.” (Lúùkù 3:12; 7:40) Kí nìdí? Ìdí ni pé ohun tó máa yanjú ìṣòro aráyé pátápátá ni Jésù fi ń kọ́ni—èyíinì ni Ìjọba Ọlọ́run. (Lúùkù 4:43; Jòhánù 6:26, 27) Ìjọba ọ̀run yìí ní ìkáwọ́ Jésù Kristi ni yóò máa ṣàkóso gbogbo ayé, tí yóò sì mú gbogbo ìlérí Bíbélì ṣẹ, èyíinì ni mímú ẹ̀dá ènìyàn olódodo àti ilẹ̀ ayé tó jẹ́ ibùgbé wọn bọ̀ sípò ìjẹ́pípé títí láé. (Ìṣípayá 11:15) Ìdí nìyẹn tí Jésù fi sọ nínú àdúrà tó kọ́ wa, pé Ìjọba Ọlọ́run tí ń bọ̀ wá yìí ni yóò jẹ́ kí ìfẹ́ Ọlọ́run di ṣíṣe lórí ilẹ̀ ayé.—Mátíù 6:10.
Kíkẹ́kọ̀ọ́ nípa ìrètí alárinrin yìí ti sọ omijé Lúùkù 6:21) Àní sẹ́, Ọlọ́run kò ní fi mọ sórí mímú àìsàn àti ìṣòro jíjẹ́ aláàbọ̀ ara kúrò; yóò mú ẹ̀ṣẹ̀ alára kúrò, nítorí pé òun gan-an ló ń kó ìyà jẹ ọmọ aráyé. Kódà, Aísáyà 33:24 àti Mátíù 9:2-7, tá a fa ọ̀rọ̀ wọn yọ ṣáájú, fi hàn pé àwọn àìsàn tó ń ṣe wá lóríṣiríṣi kò ṣẹ̀yìn ipò ẹ̀ṣẹ̀ tá a wà. (Róòmù 5:12) Ìyẹn ló fi jẹ́ pé, bí ẹ̀ṣẹ̀ kò bá sí mọ́, nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín aráyé yóò gbádùn “òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run,” òmìnira tó wé mọ́ ìjẹ́pípé ti èrò inú àti ti ara.—Róòmù 8:21.
ìbànújẹ́ ọ̀pọ̀ àwọn aláàbọ̀ ara di omijé ayọ̀. (Àwọn tí ara wọ́n le kúkú lè má mọyì ohun tí wọ́n ń gbádùn. Àmọ́ àwọn tó jẹ́ aláàbọ̀ ara mọ ohun tójú àwọn ń rí. Wọ́n mọ bí ìlera àti ìwàláàyè ti ṣeyebíye tó àti bí ipò ẹni ṣe lè yí padà bìrí, kí ìṣòro sì dé láìròtẹ́lẹ̀. (Oníwàásù 9:11) Nítorí náà, ìrètí wa ni pé àwọn tó jẹ́ aláàbọ̀ ara lára àwọn tó ń ka ìwé wa yóò fún àwọn àgbàyanu ìlérí Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì ní àfiyèsí àrà ọ̀tọ̀. Jésù fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ kí ìlérí wọ̀nyẹn lè nímùúṣẹ. Ẹ̀rí dídájú wo ló tún lágbára jùyẹn lọ?—Mátíù 8:16, 17; Jòhánù 3:16.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún àlàyé kíkún nípa ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìjìyà, wo ìwé pẹlẹbẹ náà, Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?, tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.