Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bí Ọmọ Kan Ṣe Ran Bàbá Rẹ̀ Lọ́wọ́

Bí Ọmọ Kan Ṣe Ran Bàbá Rẹ̀ Lọ́wọ́

Bí Ọmọ Kan Ṣe Ran Bàbá Rẹ̀ Lọ́wọ́

JAMES, ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, tó ti lé díẹ̀ lẹ́ni ọgbọ̀n ọdún, ní àrùn ọdẹ orí, tó ń mú kó máa ṣe bíi dìndìnrìn. Síbẹ̀, fún ọ̀pọ̀ ọdún báyìí lòun àti ìyá rẹ̀ àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀ obìnrin ti ń wá sípàdé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ṣùgbọ́n bàbá rẹ̀ kò nífẹ̀ẹ́ sí ìgbàgbọ́ wọn. Lálẹ́ ọjọ́ kan, lẹ́yìn ìpàdé kan tí wọ́n ti ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè pe mọ̀lẹ́bí wá sí Ìṣe Ìrántí ikú Kristi, James sáré gba iyàrá rẹ̀ lọ. Kíá ni ìyá rẹ̀ gbá tẹ̀ lé e, ó sì rí i tó ń tú àwọn ògbólógbòó ẹ̀dá ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! kíkankíkan. Ó wá mú ọ̀kan jáde tí àwòrán ìwé ìkésíni sí Ìṣe Ìrántí wà lára èèpo ẹ̀yìn rẹ̀. Ó sì sáré gbọ̀nà ọ̀dọ̀ bàbá rẹ̀ lọ. Ó kọ́kọ́ nawọ́ sí àwòrán náà, ó wá nawọ́ sí bàbá rẹ̀, ó ní “Ìwọ!” Bàbá àti màmá rẹ̀ wojú ara wọn tìyanu-tìyanu bí wọ́n ṣe rí i pé ńṣe ni James ń pe bàbá rẹ̀ wá sí Ìṣe Ìrántí. Bàbá rẹ̀ sọ pé ó ṣeé ṣe kí òun wá.

Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Ìṣe Ìrántí, James lọ sí ibi tí bàbá rẹ̀ ń kó aṣọ sí, ó mú ṣòkòtò kan lọ bá bàbá rẹ̀, ó sì fara ṣàpèjúwe pé kí ó wọ̀ ọ́. Bàbá rẹ̀ fèsì pé òun ò ní lè lọ sípàdé yẹn. Bí James àti màmá rẹ̀ ṣe gbọ̀nà Gbọ̀ngàn Ìjọba ní àwọn nìkan nìyẹn.

Àmọ́ bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, James wá bẹ̀rẹ̀ sí kọ̀ fún ìyá rẹ̀ nígbà tó bá fẹ́ múra ìpàdé fún un. Ó fẹ́ máa jókòó ti bàbá rẹ̀ nílé. Nígbà tó di àárọ̀ ọjọ́ Sunday kan, James tún kọ̀ nígbà tí màmá rẹ̀ fẹ́ múra ìpàdé fún un. Ìyàlẹ́nu ńlá ló jẹ́ fún ìyá James nígbà tí bàbá rẹ̀ yíjú sí James tó sọ pé, “James, bí mo bá lọ sípàdé lónìí, ṣé ìwọ náà á lọ?” Inú James dùn. Ó gbá bàbá rẹ̀ mọ́ra, ó sì sọ pé “Bẹ́ẹ̀ ni!” gbogbo wọ́n sì jọ lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba lọ́jọ́ yẹn.

Látọjọ́ yẹn ni bàbá James ti ń lọ sí gbogbo ìpàdé ọjọ́ Sunday, ó sì sọ láìpẹ́ lẹ́yìn náà pé bí òun bá fẹ́ tẹ̀ síwájú, ó di dandan kóun máa lọ sáwọn ìpàdé yòókù. (Hébérù 10:24, 25) Bó ṣe ń wá sí gbogbo ìpàdé nìyẹn o. Oṣù méjì lẹ́yìn náà ló sì bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé. Ó tẹ̀ síwájú kánmọ́kánmọ́. Kíá ló tún ìgbésí ayé rẹ̀ ṣe, kò sì pẹ́ tó bẹ̀rẹ̀ sí wàásù Ìjọba Ọlọ́run. Ọdún kan lẹ́yìn tó bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ló ya ìgbésí ayé rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà, ó sì fi ẹ̀rí èyí hàn nípa ṣíṣe ìrìbọmi. Ó ń sìn gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ nínú ìjọ rẹ̀ nísinsìnyí. Gbogbo ìdílé náà ló ń para pọ̀ sin Jèhófà báyìí.