Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bí A Ṣe Gbin Ìfẹ́ Fún Jèhófà Sọ́kàn Àwọn Ọmọ Wa

Bí A Ṣe Gbin Ìfẹ́ Fún Jèhófà Sọ́kàn Àwọn Ọmọ Wa

Ìtàn Ìgbésí Ayé

Bí A Ṣe Gbin Ìfẹ́ Fún Jèhófà Sọ́kàn Àwọn Ọmọ Wa

GẸ́GẸ́ BÍ WERNER MATZEN ṢE SỌ Ọ́

Ní ọdún mélòó kan sẹ́yìn, àkọ́bí mi Hans Werner, fún mi ní Bíbélì kan. Ó kọ ọ́ sínú èèpo ẹ̀yìn Bíbélì náà pé: “Bàbá Mi Ọ̀wọ́n, Ǹjẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Jèhófà máa ṣamọ̀nà ìdílé wa nìṣó sí ọ̀nà ìyè. Ẹ ṣeun, èmi àkọ́bí yín ọ̀wọ́n.” Àwọn tó bá jẹ́ òbí á lóye bí ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn ṣe fi ọpẹ́ àti ayọ̀ kún ọkàn mi tó. Nígbà yẹn, mi ò tíì mọ irú ìpèníjà tí ìdílé wa ṣì máa dojú kọ.

ỌDÚN 1924 la bí mi nílùú Halstenbek, tó wà ní nǹkan bí ogún kìlómítà sílùú Hamburg tó wà létíkun orílẹ̀-èdè Jámánì. Màmá mi àti bàbá mi àgbà ló tọ́ mi dàgbà. Lẹ́yìn tí mo kọ́ṣẹ́ ṣíṣe onírúurú irinṣẹ́, wọ́n fagbára mú mi wọ ẹgbẹ́ ológun tí wọ́n ń pè ní Wehrmacht lọ́dún 1942. Ìyà tó jẹ mí lójú ogun nílẹ̀ Rọ́ṣíà nígbà Ogun Àgbáyé Kejì kọjá sísọ. Ibà jẹ̀funjẹ̀fun kọlù mí, ṣùgbọ́n wọ́n dá mi padà sójú ogun nígbà tí wọ́n tọ́jú mi tán. Ní January 1945, mo wà nílùú Lodz, lórílẹ̀-èdè Poland, níbi tí mo ti fara pa yánnayànna, tí wọn sì gbé mi lọ sí ọsibítù ológun. Ibẹ̀ ni mo wà nígbà tí ogun yẹn fi parí. Mo láǹfààní láti ronú síwá sẹ́yìn ní ọsibítù náà àti ní àtìmọ́lé tí mo wà lẹ́yìn náà nílùú Neuengamme. Àwọn ìbéèrè tó bẹ̀rẹ̀ sí dà mí láàmú ni, Ǹjẹ́ Ọlọ́run wà lóòótọ́? Bí ó bá wà, kí ló dé tó fàyè gba ìwà ìkà tó pọ̀ báyìí?

Láìpẹ́ lẹ́yìn tí wọ́n tú mi sílẹ̀ látìmọ́lé ní September 1947 ni mo gbé Karla níyàwó. Ìlú kan náà la ti jọ dàgbà. Ẹlẹ́sìn Kátólíìkì ni Karla. Àmọ́ wọn ò fi ìlànà ẹ̀sìn kankan tọ́ mi dàgbà. Àlùfáà tó darí ayẹyẹ ìgbéyàwó wa sọ pé ó kéré tán ká máa gbìyànjú láti gba Àdúrà Olúwa pa pọ̀ lálaalẹ́. À ń ṣe bó ṣe wí, láìmọ ohun náà gan-an tí à ń gbàdúrà fún.

Ọdún kan lẹ́yìn náà la bí Hans Werner. Sáà yẹn ni Wilhelm Ahrens, tá a jọ ń ṣiṣẹ́, wàásù fún mi nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó fi hàn mí látinú Bíbélì pé ọjọ́ ń bọ̀ tí ogun ò ní sí mọ́. (Sáàmù 46:9) Ìgbà ìwọ́wé ọdún 1950 ni mo ya ìgbésí ayé mi sí mímọ́ fún Jèhófà, tí mo sì ṣe batisí. Ẹ wo bí inú mi ti dùn tó lọ́dún kan lẹ́yìn náà tí aya mi àtàtà pẹ̀lú ṣe batisí!

Títọ́ Àwọn Ọmọ ní Ọ̀nà Jèhófà

Mo kà á nínú Bíbélì pé Jèhófà ló dá ìgbéyàwó sílẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 1:26-28; 2:22-24) Wíwà tí mo wà níbẹ̀ nígbà ìbí gbogbo àwọn ọmọ wa—ìyẹn Hans Werner, Karl-Heinz, Michael, Gabriele àti Thomas—jẹ́ kí ìpinnu mi láti jẹ́ ọkọ rere àti bàbá rere túbọ̀ lágbára sí i. Nǹkan ayọ̀ ni ìbí ọmọ kọ̀ọ̀kan jẹ́ fún èmi àti Karla.

Àpéjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wáyé lọ́dún 1953 nílùú Nuremberg jẹ́ àkókò mánigbàgbé fún ìdílé wa. Ní ọ̀sán Friday, nígbà tí olùbánisọ̀rọ̀ ń sọ̀rọ̀ lórí ẹṣin ọ̀rọ̀ náà “Títọ́ Ọmọ Láàárín Àwọn Ọmọ Ẹgbẹ́ Ayé Tuntun,” ó sọ nǹkan kan tí a ò lè gbàgbé láé. Ó ní: “Ogún tó níye lórí jù lọ tá a lè fún àwọn ọmọ wa ni ìfẹ́ láti di ìránṣẹ́ Ọlọ́run.” Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, ohun tí èmi àti Karla fẹ́ láti ṣe gan-an nìyẹn. Àmọ́ báwo la ṣe máa ṣe é?

A bẹ̀rẹ̀ níbi gbígbàdúrà pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdílé lójoojúmọ́. Èyí jẹ́ káwọn ọmọ mọ ìjẹ́pàtàkì àdúrà. Ọmọ kọ̀ọ̀kan mọ̀ láti kékeré pínníṣín pé a gbọ́dọ̀ gbàdúrà ká tó jẹun. Kódà nígbà tí wọ́n ṣì wà lọ́mọ ọwọ́ pàápàá, gbàrà tí wọ́n bá ti rí ìgò oúnjẹ wọn ni wọ́n á ti tẹ orí wọn kóńkóló ba, tí wọ́n á sì di ọwọ́ wọn kékeré pọ̀. Nígbà kan, wọ́n pè wá síbi ìgbéyàwó ẹbí ìyàwó mi kan, tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí. Lẹ́yìn ayẹyẹ náà, àwọn òbí ìyàwó sọ pé kí àwọn àlejò wá sílé wa láti fi nǹkan panu. Kálukú ti fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí máa jẹun. Ṣùgbọ́n ọmọ wa Karl-Heinz, ọmọ ọdún márùn-ún, rí i pé ìyẹn ò bọ́ sí i rárá. Ó sọ pé: “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ gbàdúrà ná.” Àwọn àlejò wò ó lójú, wọ́n tún wò wá lójú, wọ́n wá yíjú sí onílé. Kó tó dọ̀rọ̀ ìtìjú, mo sọ pé kí wọ́n jẹ́ kí n gbàdúrà sórí oúnjẹ náà, onílé sì gbà bẹ́ẹ̀.

Ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn rán mi létí ọ̀rọ̀ Jésù, pé: “Láti ẹnu àwọn ìkókó àti àwọn ọmọ ẹnu ọmú ni o ti mú ìyìn jáde.” (Mátíù 21:16) Ó dá wa lójú pé àwọn àdúrà àtọkànwá tí à ń gbà déédéé ran àwọn ọmọ wa lọ́wọ́ láti ka Jèhófà sí Baba wọn ọ̀run onífẹ̀ẹ́.

Ojúṣe Wa Níwájú Jèhófà

Kíkọ́ àwọn ọmọ láti nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tún ń béèrè pé ká máa ka Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ká sì máa kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ déédéé. Ìdí nìyẹn tá a fi ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. A sábà máa ń ṣe é lálaalẹ́ ọjọ́ Monday. Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé ọdún mẹ́sàn-án ló wà láàárín àkọ́bí àti àbígbẹ̀yìn, ohun tí àwọn ọmọ wa nílò yàtọ̀ síra pátápátá. Ìdí nìyẹn tá ò fi lè máa lo ìsọfúnni kan náà fún gbogbo wọn ní gbogbo ìgbà.

Bí àpẹẹrẹ, ìsọfúnni tó rọrùn gan-an là ń lò fáwọn ọmọ tí kò tíì tó iléèwé lọ. Ẹsẹ Bíbélì kan ṣoṣo ni Karla máa ń jíròrò pẹ̀lú wọn, tàbí kí ó lo àwòrán inú àwọn ìtẹ̀jáde tá a gbé ka Bíbélì. Inú mi ṣì máa ń dùn nígbà tí mo bá rántí bí àwọn ọmọ wa kékeré ṣe máa ń gun orí bẹ́ẹ̀dì wá bá wa láàárọ̀ kùtùkùtù nígbà tí a ṣì ń sùn lọ́wọ́, tí wọ́n á fi àwòrán tó wù wọ́n jù lọ nínú ìwé The New World a hàn wá.

Karla kúndùn fífi sùúrù kọ́ àwọn ọmọ ní ọ̀pọ̀ ìdí tó fi yẹ kí gbogbo wa nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Ó lè dún bí ohun tó rọrùn, tí kò gba akitiyan. Àmọ́ iṣẹ́ àṣeṣúlẹ̀ tó lè tánni lókun, ní ti ara àti ní ti ìmí ẹ̀dùn, ló jẹ́ fún èmi àti Karla. Ṣùgbọ́n a ò juwọ́ sílẹ̀. A fẹ́ rí i dájú pé a gbin nǹkan sọ́kàn wọn tó ṣì rọ̀ báyìí, kó tó di pé àwọn èèyàn míì tí kò mọ Jèhófà yóò nípa lórí wọn. Ìyẹn ló jẹ́ ká fi dandan lé e pé àwọn ọmọ wa gbọ́dọ̀ máa wà níbi tá a ti ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé ní gbàrà tí wọ́n bá ti lè jókòó.

Gẹ́gẹ́ bí òbí, èmi àti Karla mọ ìjẹ́pàtàkì fífi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fáwọn ọmọ wa nínú ọ̀ràn ìjọsìn. Ì báà jẹ́ oúnjẹ là ń jẹ, tàbí à ń ṣiṣẹ́ nínú ọgbà, tàbí a kàn ṣeré jáde lọ, a máa ń gbìyànjú láti mú kí àjọṣe tí ọmọ kọ̀ọ̀kan ní pẹ̀lú Jèhófà lágbára sí i. (Diutarónómì 6:6, 7) A rí i dájú pé ọmọ kọ̀ọ̀kan ló ní Bíbélì tirẹ̀ láti kékeré. Síwájú sí i, gbàrà tá a bá rí ìwé ìròyìn gbà ni mo máa ń kọ orúkọ kálukú nínú ìdílé wa sára ẹ̀dà tirẹ̀. Ìyẹn jẹ́ kí ọmọ kọ̀ọ̀kan dá ìwé tirẹ̀ mọ̀. A ṣètò yíyan àwọn àpilẹ̀kọ kan pàtó nínú Jí! fún àwọn ọmọ láti kà. Lẹ́yìn oúnjẹ ọ̀sán ní Sunday, wọ́n á wá ṣàlàyé bí ohun tí wọ́n kà ṣe yé wọn sí.

Fífún Àwọn Ọmọ Ní Àfiyèsí Tí Wọ́n Ń Fẹ́

Ká sòótọ́, kì í ṣe ìgbà gbogbo ni nǹkan lọ geere. Bí àwọn ọmọ ti ń dàgbà, a rí i pé láti lè gbin ìfẹ́ sí wọn lọ́kàn, a gbọ́dọ̀ mọ ohun tí ń bẹ nínú ọkàn wọn. Èyí ń béèrè pé ká fetí sí wọn. Nígbà míì, àwọn ọmọ wa máa ń rí nǹkan kan tí inú wọn ò dùn sí. Fún ìdí yìí, èmi àti Karla á jókòó bá wọn jíròrò ọ̀ràn náà. A ṣètò ọgbọ̀n ìṣẹ́jú àkànṣe lẹ́yìn ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé fún èyí. A fún kálukú láyè láti sọ tinú rẹ̀ jáde.

Fún àpẹẹrẹ, Thomas àti Gabriele, ìyẹn àwọn ọmọ wa méjì tó kéré jù lọ, gbà pé àwa òbí ń ṣe ojúsàájú fún ẹ̀gbọ́n wọn àgbà. Nígbà ìjíròrò kan, wọ́n sọ èrò ọkàn wọn pé: “Dádì, lójú tiwa ẹ̀yin àti Mọ́mì ń gba Hans Werner láyè láti ṣe bó ṣe wù ú.” Bí ẹni pé àlá ni mò ń lá ló kọ́kọ́ jọ lójú mi. Àmọ́ lẹ́yìn tá a gbé ọ̀ràn náà sọ́tùn-ún, tá a gbé e sósì, èmi àti Karla ní láti gbà pé òótọ́ ọ̀rọ̀ làwọn ọmọ yẹn ń sọ. Nítorí náà, a túbọ̀ sapá láti máa bá gbogbo àwọn ọmọ lò lọ́gbọọgba.

Ìgbà mìíràn wà tí mo máa ń fi ìwàǹwára fìyà jẹ àwọn ọmọ, tàbí kí n bá wọn wí láìyẹ. Nígbà tí irú yẹn bá wáyé, ó di dandan kí àwa òbí tọrọ àforíjì. Lẹ́yìn ìyẹn, a óò wá tọ Jèhófà lọ nínú àdúrà. Ó ṣe pàtàkì bí àwọn ọmọ ṣe ń rí i pé bàbá wọn ṣe tán láti tọrọ àforíjì lọ́dọ̀ Jèhófà, ó sì tún ń tọrọ àforíjì lọ́dọ̀ àwọn náà, ìyẹn àwọn ọmọ wa. Ìyẹn ló jẹ́ kí àárín àwa àtàwọn ọmọ gún régé. Wọ́n máa ń sọ fún wa pé, “Ọ̀rẹ́ wa àtàtà ni yín.” Ìyẹn máa ń mú inú wa dùn gan-an.

Ṣíṣiṣẹ́ pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdílé ń mú ìṣọ̀kan wá. Fún ìdí yìí, kálukú ló ní iṣẹ́ ilé tá a pín fún un. Hans Werner ló máa ń lọ ra nǹkan lọ́jà lẹ́ẹ̀kan lọ́sẹ̀, tó túmọ̀ sí pé àá fún un lówó àti àkọsílẹ̀ àwọn nǹkan tó máa rà. Ọ̀sẹ̀ kan wà tí a ò fún un ní owó àti àkọsílẹ̀ nǹkan tó máa rà. Ó béèrè lọ́wọ́ ìyá rẹ̀, ìyá rẹ̀ sì sọ fún un pé kò tíì sówó nílẹ̀. Tóò, àwọn ọmọ bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ wúyẹ́wúyẹ́ láàárín ara wọn. Kálukú wọ́n wá lọ gbé àpótí owó tirẹ̀, wọ́n sì da gbogbo owó tó wà nínú rẹ̀ sórí tábìlì. Gbogbo wọ́n wá sọ pé: “Mọ́mì, ọjà ti yá báyìí!” Bẹ́ẹ̀ ni o, àwọn ọmọ ti kọ́ láti ṣèrànwọ́ lákòókò ìṣòro, èyí sì jẹ́ kí ìdílé wa túbọ̀ fara mọ́ra.

Bí àwọn ọmọkùnrin wa ti ń dàgbà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí fojú sí obìnrin lára. Bí àpẹẹrẹ, Thomas bẹ̀rẹ̀ sí fìfẹ́ hàn sí Ẹlẹ́rìí kan tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún. Mo ṣàlàyé fún un pé bó bá jẹ́ lóòótọ́ ni ọmọbìnrin náà wù ú, ó gbọ́dọ̀ ṣe tán láti fẹ́ ẹ, kí ó sì ṣe tán láti tẹ́rí gba ẹrù iṣẹ́ níní ìyàwó àti ọmọ. Thomas gbà pé òun ò tíì tó ìyàwó gbé, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé ọmọ ọdún méjìdínlógún péré lòun.

Títẹ̀síwájú Gẹ́gẹ́ Bí Ìdílé

Nígbà tí ọjọ́ orí wọ́n ṣì kéré ni ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọ wa ti forúkọ sílẹ̀ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run. A máa ń fetí sílẹ̀ dáadáa sí ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ wọn. Inú wa sì máa ń dùn, nítorí pé a rí i pé ṣe ni àwọn ọmọ wa dìídì nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run látọkànwá. Àwọn alábòójútó àyíká àti ti àgbègbè tó máa ń dé sọ́dọ̀ wa lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan máa ń sọ ìrírí ara wọn tàbí kí wọ́n ka Bíbélì fún wa. Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí àtàwọn aya wọn bá wa gbin ìfẹ́ fún iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún sọ́kàn ìdílé wa.

Ojú wa máa ń wà lọ́nà gan-an fún àpéjọ àgbègbè. Ó máa ń fún wa láǹfààní láti gbin ìfẹ́ jíjẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run sí àwọn ọmọ wa lọ́kàn. Fún àwọn ọmọ, kò sóhun tó dùn tó lílẹ káàdì wọn mọ́ àyà, bá a ṣe ń múra àtigbéra lọ sí ilẹ̀ àpéjọ. Inú wa dùn gan-an nígbà tí Hans Werner ṣèrìbọmi lọ́mọ ọdún mẹ́wàá. Àwọn kan sọ pé ó ti kéré jù láti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà. Àmọ́ nígbà tó pé ẹni àádọ́ta ọdún, ó sọ fún mi pé inú òun dùn gan-an pé òun ti lo ogójì ọdún nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.

A jẹ́ kí àwọn ọmọ wa mọ̀ pé níní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà ṣe pàtàkì. Ṣùgbọ́n a ò fagbára mú wọn ṣe ìyàsímímọ́. Síbẹ̀, inú wa dùn gan-an nígbà tí àwọn yòókù ṣe ìrìbọmi lákòókò tó tọ́ lójú wọn láti ṣe bẹ́ẹ̀.

Kíkọ́ Láti Kó Ẹrù Wa Lọ Sọ́dọ̀ Jèhófà

Inú wa dùn kọjá sísọ ní 1971, nígbà tí Hans Werner kẹ́kọ̀ọ́ jáde ní kíláàsì kọkànléláàádọ́ta ti ilé ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead, tí wọ́n sì ní kó lọ ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì ní Sípéènì. Lọ́kọ̀ọ̀kan, àwọn ọmọ yòókù pẹ̀lú kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Èyí sì mú inú àwa òbí dùn gan-an ni. Sáà yìí ni Hans Werner fún mi ní Bíbélì tí mo sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí. Ó jọ pé ayọ̀ ìdílé wa ti kún.

Àmọ́, a wá rí i pé ó di dandan ká rọ̀ mọ́ Jèhófà tímọ́tímọ́. Kí nìdí? Ìdí ni pé àwọn kan lára àwọn ọmọ wa tó ti dàgbà ń dojú kọ àwọn ìṣòro wíwúwo tó ń dán ìgbàgbọ́ wọn wò. Fún àpẹẹrẹ, ojú Gabriele ọmọbìnrin wa ọ̀wọ́n rí ìyọnu. Ọdún 1976 ló fẹ́ Lothar. Kò pẹ́ lẹ́yìn ìgbéyàwó wọn ni àìsàn kọlu Lothar. Gabriele ló ń tọ́jú rẹ̀ bí òkùnrùn ọ̀hún ṣe ń sọ ọ́ di hẹ́gẹhẹ̀gẹ títí tó fi kú. Rírí tá a rí aráalé wa tí àìsàn kọlù, tó sì kú, rán wa létí bá a ṣe ń fẹ́ ìrànlọ́wọ́ onífẹ̀ẹ́ Jèhófà tó.—Aísáyà 33:2.

Àwọn Àǹfààní Nínú Ètò Àjọ Jèhófà

Nígbà tá a yàn mí ṣe ìránṣẹ́ ìjọ (tí à ń pè ní alábòójútó olùṣalága lóde òní) ní 1955, ó ṣe mí bíi pé mi ò tóótun fún ẹrù iṣẹ́ yẹn. Iṣẹ́ pọ̀ láti ṣe, ọ̀nà kan ṣoṣo tí mo sì lè gbà ṣe iṣẹ́ mi bí iṣẹ́ ni kí n máa jí ní aago mẹ́rin ìdájí nígbà míì. Aya mi àtàwọn ọmọ mi jẹ́ igi-lẹ́yìn-ọgbà fún mi. Wọ́n ń rí i dájú pé kò sẹ́ni tó ń yọ mí lẹ́nu lálẹ́ nígbà tí àwọn nǹkan kan bá ṣì wà fún mi láti bójú tó.

Síbẹ̀síbẹ̀, a máa ń wá àkókò láti fi ṣe fàájì pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdílé. Nígbà mìíràn, ẹni tó gbà mí síṣẹ́ máa ń yá mi ní ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ rẹ̀ kí n fi gbé ìdílé mi ṣeré jáde. Àwọn ọmọ máa ń gbádùn ìgbà kọ̀ọ̀kan tá a máa ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ nínú igbó. A tún máa ń jùmọ̀ rin ìrìn gbẹ̀fẹ́ jáde, nígbà míì tí a óò máa kọrin, tí màá sì máa fun fèrè mi kékeré sí i bá a ṣe ń rin inú ẹgàn kọjá.

Ní 1978, wọ́n yàn mí ṣe adelé alábòójútó àyíká (òjíṣẹ́ arìnrìn àjò). Ó kà mí láyà débi pé mo gbàdúrà pé: “Jèhófà, mi ò rò pé mo lẹ́mìí iṣẹ́ yìí o. Àmọ́ tó o bá fẹ́ kí n gbìyànjú ẹ̀ wò, màá ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe.” Ọdún méjì lẹ́yìn náà, lẹ́ni ọdún mẹ́rìnléláàádọ́ta, mo ní kí Thomas ọmọkùnrin tá a bí gbẹ̀yìn máa bójú tó iṣẹ́ ajé kékeré tá a fi ń pawọ́ dà.

Àwọn ọmọ wa ti dàgbà. Èyí sì fún èmi àti Karla ní àǹfààní láti ṣe púpọ̀ sí i fún Jèhófà. Ọdún kan náà yẹn la sọ mi dí alábòójútó àyíká. A sì yàn mí sí apá kan Hamburg àti gbogbo àgbègbè Schleswig-Holstein. Nítorí pé a ti ní ìrírí ọmọ títọ́, ó ṣeé ṣe fún wa láti lóye àwọn òbí àtàwọn ọmọ wọn. Ọ̀pọ̀ nínú àwọn ará ló bẹ̀rẹ̀ sí pè wá ní òbí àyíká àwọn.

Lẹ́yìn ọdún mẹ́wàá tí Karla fi ń bá mi lọ káàkiri nínú iṣẹ́ àyíká, ó wá di dandan kí wọ́n ṣe iṣẹ́ abẹ fún un. Láàárín ọdún kan náà làwọn oníṣègùn tún rí i pé kókó kan wà nínú ọpọlọ mi. Ìyẹn ló jẹ́ kí n fi iṣẹ́ alábòójútó àyíká sílẹ̀ nígbà tí wọ́n fẹ́ ṣe iṣẹ́ abẹ ọpọlọ fún mi. Ọdún mẹ́ta kọjá kí n tó tún bẹ̀rẹ̀ sí sìn gẹ́gẹ́ bí adelé alábòójútó àyíká. Èmi àti Karla ti lé lẹ́ni àádọ́rin ọdún báyìí, a ò sì ṣe iṣẹ́ arìnrìn àjò mọ́. Jèhófà ràn wá lọ́wọ́ láti rí i pé kò sídìí fún dídiwọ́ mọ́ àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tí apá mi ò ká mọ́.

Bá a ṣe ń wẹ̀yìn wò, èmi àti Karla dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún bó ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti gbin ìfẹ́ fún òtítọ́ sọ́kàn àwọn ọmọ wa. (Òwe 22:6) Jálẹ̀ gbogbo àwọn ọdún wọ̀nyí, Jèhófà ti tọ́ wa sọ́nà, ó ti kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́, ó sì ti ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe ojúṣe wa. Bí a tilẹ̀ ti darúgbó, tí ara ò sì ṣe ṣámúṣámú mọ́, síbẹ̀ ìfẹ́ fún Jèhófà ṣì tuntun lọ́kàn wa, ó sì lágbára ju ti ìgbàkígbà rí lọ.—Róòmù 12:10, 11.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ ìwé yìí, àmọ́ kò sí ńlẹ̀ mọ́.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Ìdílé wa rèé, bá a ṣe ń rìn lẹ́bàá Odò Elbe, ní Hamburg, 1965

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Àwọn kan nínú ìdílé wa nígbà àpéjọ àgbáyé nílùú Berlin ní 1998

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Èmi àti Karla, aya mi