Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Dídé Ojú Ìwọ̀n Ohun Tí Ọlọ́run Béèrè Ń Gbé Jèhófà Ga

Dídé Ojú Ìwọ̀n Ohun Tí Ọlọ́run Béèrè Ń Gbé Jèhófà Ga

Dídé Ojú Ìwọ̀n Ohun Tí Ọlọ́run Béèrè Ń Gbé Jèhófà Ga

“Èmi yóò . . . fi ìdúpẹ́ gbé e ga lọ́lá.”—SÁÀMÙ 69:30.

1. (a) Èé ṣe tó fi yẹ ká gbé Jèhófà ga? (b) Báwo la ṣe ń fi ìdúpẹ́ gbé e ga?

 JÈHÓFÀ ni Ọlọ́run olódùmarè, òun ni Ọba Aláṣẹ Ayé òun Ọ̀run, òun sì ni Ẹlẹ́dàá. Ìdí nìyẹn tó fi yẹ ká gbé orúkọ rẹ̀ àtàwọn ète rẹ̀ ga. Gbígbé Jèhófà ga túmọ̀ sí pé ká buyì fún un gan-an, ká gbé e lárugẹ, ká sì fi ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa yìn ín lógo. Láti “fi ìdúpẹ́” ṣe bẹ́ẹ̀ béèrè pé ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ ní gbogbo ìgbà nítorí àwọn ohun tó ń ṣe fún wa nísinsìnyí àtàwọn ohun tó máa ṣe fún wa lọ́jọ́ iwájú. Ìṣarasíhùwà tó yẹ ká ní ni èyí tó wà nínú ìwé Ìṣípayá 4:11, níbi táwọn ẹ̀dá ẹ̀mí tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ ní ọ̀run ti polongo pé: “Jèhófà, àní Ọlọ́run wa, ìwọ ni ó yẹ láti gba ògo àti ọlá àti agbára, nítorí pé ìwọ ni ó dá ohun gbogbo, àti nítorí ìfẹ́ rẹ ni wọ́n ṣe wà, tí a sì dá wọn.” Báwo la ṣe ń gbé Jèhófà ga? Nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀, ká sì máa ṣe ohun tó béèrè lọ́wọ́ wa. Irú ìmọ̀lára tí onísáàmù náà ní ló yẹ kí àwa náà ní, nígbà tó sọ pé: “Kọ́ mi láti máa ṣe ìfẹ́ rẹ, nítorí pé ìwọ ni Ọlọ́run mi.”—Sáàmù 143:10.

2. Kí ni Jèhófà yóò ṣe fún àwọn tó gbé e ga àtàwọn ti kò ṣe bẹ́ẹ̀?

2 Jèhófà mọyì àwọn tó ń gbé e ga. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ “olùsẹ̀san fún àwọn tí ń fi taratara wá a.” (Hébérù 11:6) Kí ni ẹ̀san ọ̀hún? Jésù sọ nínú àdúrà tó gbà sí Baba rẹ̀ ọ̀run pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.” (Jòhánù 17:3) Bẹ́ẹ̀ ni o, àwọn tó “ń fi ìdúpẹ́ gbé [Jèhófà] ga lọ́lá” ni yóò “ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.” (Sáàmù 37:29) Ní ìyàtọ̀ síyẹn, “kì yóò sí ọjọ́ ọ̀la fún ẹni búburú kankan.” (Òwe 24:20) Yíyẹ tí ó yẹ láti gbé Jèhófà ga ti di ọ̀ràn kánjúkánjú láwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí nítorí pé láìpẹ́, yóò pa àwọn ẹni ibi run, yóò sì dá àwọn olódodo sí. “Ayé ń kọjá lọ, bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.”—1 Jòhánù 2:17; Òwe 2:21, 22.

3. Èé ṣe tó fi yẹ ká fiyè sí ìwé Málákì?

3 Ohun tó jẹ́ ìfẹ́ Jèhófà wà nínú Bíbélì, nítorí pé “gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí.” (2 Tímótì 3:16) Ọ̀pọ̀ ìtàn nípa bí Jèhófà ṣe bù kún àwọn tó gbé e ga àti ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn tí kò ṣe bẹ́ẹ̀ wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ọ̀kan lára irú ìtàn bẹ́ẹ̀ ní í ṣe pẹ̀lú ohun tó ṣẹlẹ̀ ní Ísírẹ́lì nígbà ayé wòlíì Málákì. Nǹkan bí ọdún 443 ṣááju Sànmánì Tiwa, ní àkókò tí Nehemáyà fi jẹ́ gómìnà Júdà ni Málákì kọ ìwé tá a fi orúkọ rẹ̀ pè. Ìwé àtàtà tó jẹ́ àkàgbádùn yìí ní àwọn ìsọfúnni àti àsọtẹ́lẹ̀ nínú, èyí tá a “kọ̀wé wọn kí ó lè jẹ́ ìkìlọ̀ fún àwa tí òpin àwọn ètò àwọn nǹkan dé bá.” (1 Kọ́ríńtì 10:11) Fífiyèsí ọ̀rọ̀ Málákì lè ràn wá lọ́wọ́ láti múra sílẹ̀ de “ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù ti Jèhófà,” nígbà tí yóò pa ètò búburú yìí run.—Málákì 4:5.

4. Àwọn kókó mẹ́fà wo la mú wá sí àfiyèsí wa nínú Málákì orí kìíní?

4 Báwo ni ìwé Málákì, tó ti kọ láti ohun tó lé ní egbèjìlá [2,400] ọdún sẹ́yìn, ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ ní ọ̀rúndún kọkànlélógún yìí, láti múra sílẹ̀ de ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù ti Jèhófà? Orí kìíní ìwé náà pe àfiyèsí wa sí, ó kéré tán, àwọn kókó pàtàkì mẹ́fà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó fi yẹ ká máa fi ìdúpẹ́ gbé Jèhófà ga, kí a lè rí ojú rere rẹ̀ àti ìyè àìnípẹ̀kun: (1) Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn rẹ̀. (2) A gbọ́dọ̀ mọrírì àwọn ohun mímọ́. (3) Jèhófà retí pé ká fóun ní ohun tó dára jù lọ. (4) Ìfẹ́ aláìmọtara-ẹni-nìkan ló ń súnni ṣe ìjọsìn tòótọ́, kì í ṣe ìwọra. (5) Ṣíṣe iṣẹ́ ìsìn tó ṣètẹ́wọ́gbà lójú Ọlọ́run kì í ṣe ẹrù ìnira. (6) Ẹnì kọ̀ọ̀kan wa gbọ́dọ̀ jíhìn fún Ọlọ́run. Nítorí náà, nínú apá àkọ́kọ́ yìí lára àwọn àpilẹ̀kọ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tó dá lórí ìwé Málákì, ẹ jẹ́ ká gbé ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn kókó wọ̀nyí yẹ̀ wò ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé, bá a ṣe fẹ́ fojú ṣùnnùkùn wo Málákì orí kìíní.

Jèhófà Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Ènìyàn Rẹ̀

5, 6. (a) Kì nìdí tí Jèhófà fi nífẹ̀ẹ́ Jékọ́bù? (b) Bá a bá fara wé ìṣòtítọ́ Jékọ́bù, kí la lè retí?

5 A mú ìfẹ́ Jèhófà ṣe kedere láwọn ẹsẹ tó ṣáájú nínú ìwé Málákì. Ìwé náà bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ náà: “Ọ̀rọ̀ ìkéde: Ọ̀rọ̀ Jèhófà nípa Ísírẹ́lì.” Síwájú sí i, Ọlọ́run sọ pé: “Mo nífẹ̀ẹ́ yín.” Jèhófà wá mẹ́nu kan àpẹẹrẹ kan nínú ẹsẹ kan náà yẹn, ó ní: “Mo nífẹ̀ẹ́ Jékọ́bù.” Jékọ́bù jẹ́ ọkùnrin tó nígbàgbọ́ nínú Jèhófà. Nígbà tó yá, Jèhófà yí orúkọ Jékọ́bù padà sí Ísírẹ́lì, ó sì di baba ńlá orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. Jèhófà nífẹ̀ẹ́ Jékọ́bù nítorí pé ó jẹ́ ọkùnrin ìgbàgbọ́. Jèhófà tún nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ní irú ẹ̀mí tí Jékọ́bù ní sí I.—Málákì 1:1, 2.

6 Bá a bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, tá a sì dúró ṣinṣin ti àwọn èèyàn rẹ̀, a lè rí ìtùnú nínú ọ̀rọ̀ tó wà nínú 1 Sámúẹ́lì 12:22, tó sọ pé: “Jèhófà kì yóò kọ àwọn ènìyàn rẹ̀ tì, nítorí orúkọ ńlá rẹ̀.” Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn rẹ̀, ó ń san èrè fún wọn, yóò sì fún wọn ní ìyè àìnípẹ̀kun nígbẹ̀yìn gbẹ́yín. Ìdí nìyẹn tá a fi kà á pé: “Gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, kí o sì máa ṣe rere; máa gbé ilẹ̀ ayé, kí o sì máa fi ìṣòtítọ́ báni lò. Pẹ̀lúpẹ̀lù, máa ní inú dídùn kíkọyọyọ nínú Jèhófà, òun yóò sì fún ọ ní àwọn ìbéèrè tí ó ti inú ọkàn-àyà rẹ wá.” (Sáàmù 37:3, 4) Nínífẹ̀ẹ́ Jèhófà wé mọ́ kókó kejì tí Málákì orí kìíní mú wá sí àfiyèsí wa.

Mọrírì Àwọn Ohun Mímọ́

7. Kí nìdí tí Jèhófà fi kórìíra Ísọ̀?

7 Gẹ́gẹ́ bá a ṣe kà á nínú Málákì 1:2, 3, lẹ́yìn tí Jèhófà sọ pé, “Mo nífẹ̀ẹ́ Jékọ́bù,” ó wá sọ pé, “Ísọ̀ ni mo sì kórìíra.” Èé ṣe tọ́ràn fi rí bẹ́ẹ̀? Jékọ́bù gbé Jèhófà ga, ṣùgbọ́n Ísọ̀, tí òun pẹ̀lú rẹ̀ jọ jẹ́ ìbejì kò ṣe bẹ́ẹ̀. Ísọ̀ tún ń jẹ́ Édómù. Málákì 1:4 pe ilẹ̀ Édómù ní ìpínlẹ̀ ìwà ibi, ó sì fi àwọn ènìyàn ibẹ̀ bú. Orúkọ náà, Édómù (tó túmọ̀ sí “Pupa”), ni wọ́n fún Ísọ̀, lẹ́yìn tó tìtorí ẹ̀wà pupa ta ogún ìbí rẹ̀ ṣíṣeyebíye fún Jékọ́bù. Ìwé Jẹ́nẹ́sísì 25:34 sọ pé: “Ísọ̀ tẹ́ńbẹ́lú ogún ìbí náà.” Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé kí wọ́n ṣọ́ra kí “ó má bàa sí àgbèrè kankan tàbí ẹnikẹ́ni tí kò mọrírì àwọn ohun ọlọ́wọ̀, bí Ísọ̀, ẹni tí ó fi àwọn ẹ̀tọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àkọ́bí tọrẹ ní pàṣípààrọ̀ fún oúnjẹ ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo.”—Hébérù 12:14-16.

8. Kí ló mú kí Pọ́ọ̀lù fi Ísọ̀ wé alágbèrè?

8 Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi fi ohun tí Ísọ̀ ṣe wé ìwà àgbèrè? Ìdí ni pé níní irú ẹ̀mí tí Ísọ̀ ní lè jẹ́ kéèyàn fojú tín-ínrín àwọn ohun mímọ́. Èyí sì lè wá yọrí sí ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo, bí àgbèrè. Nítorí ìdí èyí, a lè bi ara wa pé: ‘Nígbà míì, ǹjẹ́ ó máa ń ṣe mí bíi pé kí n fi ogún Kristẹni mi—ìyẹn ìyè àìnípẹ̀kun—ṣe pàṣípààrọ̀ fún ohun kan tí kò fi bẹ́ẹ̀ ní láárí bí àwo ẹ̀wà lẹ́ńtìlì? Bóyá láìmọ̀ọ́mọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀, mo ha ń tẹ́ńbẹ́lú àwọn ohun mímọ́ bí?’ Ísọ̀ ṣe wàdùwàdù láti tẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ara lọ́rùn. Ó sọ fún Jékọ́bù pé: “Jọ̀wọ́, tètè fún mi ní ìwọ̀n tí ó ṣe é gbé mì lẹ́ẹ̀kan lára pupa.” (Jẹ́nẹ́sísì 25:30) Ó ṣeni láàánú pé ìṣe àwọn ará kan kò yàtọ̀ sí tẹni tí ń sọ pé: “Tètè! Kí là ń dúró de ìgbéyàwó tó lọ́lá fún?” Ìfẹ́ láti ní ìbálòpọ̀ láìbìkítà fún ohun tó lè tìdí ẹ̀ yọ ti di àwo ẹ̀wà lẹ́ńtìlì tiwọn.

9. Báwo la ṣe lè níbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ fún Jèhófà?

9 Ǹjẹ́ kí a má ṣe tẹ́ńbẹ́lú àwọn ohun mímọ́ nípa fífojú ẹ̀gàn wo ìwà mímọ́, ìwà títọ́, àti ogún tẹ̀mí wa. Dípò tá a ó fi ṣe bíi ti Ísọ̀, ẹ jẹ́ kí a dà bíi Jékọ́bù olóòótọ́, ká níbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ fún Ọlọ́run nípa níní ìmọrírì tó jinlẹ̀ fún àwọn ohun mímọ́. Báwo la ṣe lè ṣe èyí? Nípa ṣíṣọ́ra láti dé ojú ìwọ̀n àwọn ohun tí Jèhófà béèrè. Èyí ló wá mú wa lọ sórí kókó kẹta tí Málákì orí kìíní tọ́ka sí. Kí nìyẹn?

Fífún Jèhófà ní Ohun Tó Dára Jù Lọ

10. Ọ̀nà wo làwọn àlùfáà gbà ń tẹ́ńbẹ́lú tábìlì Jèhófà?

10 Àwọn àlùfáà Júdà tó ń sìn nínú tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù nígbà ayé Málákì kò fún Jèhófà ní ẹbọ tó dára jù lọ. Málákì 1:6-8 sọ pé: “‘Ọmọ, ní tirẹ̀, ń bọlá fún baba; ìránṣẹ́, sì ń bọlá fún ọ̀gá rẹ̀ atóbilọ́lá. Nítorí náà bí mo bá jẹ́ baba, ọlá mi dà? Bí mo bá sì jẹ́ Atóbilọ́lá Ọ̀gá, ẹ̀rù mi dà?’ ni Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí fún yín, ẹ̀yin àlùfáà tí ń tẹ́ńbẹ́lú orúkọ mi.” Àwọn àlùfáà náà béèrè pé: “Ọ̀nà wo ni a gbà tẹ́ńbẹ́lú orúkọ rẹ?” Jèhófà fèsì pé: “Nípa mímú oúnjẹ eléèérí wá sórí pẹpẹ mi ni.” Àwọn àlùfáà náà tún béèrè pé: “Ọ̀nà wo ni a gbà sọ ìwọ di eléèérí?” Jèhófà wá sọ fún wọn pé: “Nípa sísọ tí ẹ ń sọ pé: ‘Tábìlì Jèhófà jẹ́ ohun ìtẹ́ńbẹ́lú.’” Àwọn àlùfáà yẹn ń tẹ́ńbẹ́lú tábìlì Jèhófà ní gbogbo ìgbà tí wọ́n bá rú ẹbọ tó lábùkù, tí wọ́n sì ń sọ pé: “Kì í ṣe ohun tí ó burú.”

11. (a) Kí ni Jèhófà sọ nípa àwọn ẹbọ tí kò ṣètẹ́wọ́gbà? (b) Ọ̀nà wo làwọn èèyàn náà lápapọ̀ gbà jẹ̀bi?

11 Jèhófà wá bá wọn fèrò wérò nípa irú àwọn ẹbọ tí kò ṣètẹ́wọ́gbà bẹ́ẹ̀, ó ní: “Jọ̀wọ́, mú un wá sọ́dọ̀ gómìnà rẹ. Yóò ha ní inú dídùn sí ọ, tàbí yóò ha fi inú rere gbà ọ́?” Rárá o, inú gómìnà wọn ò lè dùn sírú ẹ̀bùn bẹ́ẹ̀. Ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ Ọba Aláṣẹ Ayé òun Ọ̀run, kò jẹ́ gba ọrẹ tó lábùkù bẹ́ẹ̀! Kì í sì í ṣe àwọn àlùfáà nìkan ló jẹ̀bi ọ̀rọ̀ yìí. Lóòótọ́ ni wọ́n ń tẹ́ńbẹ́lú Jèhófà nípa rírú àwọn ẹbọ náà. Àmọ́, ṣé àwọn èèyàn náà lápapọ̀ kò jẹ̀bi? Wọ́n jẹ̀bi mọ̀nà! Àwọn ló lọ ṣa ẹran tó fọ́jú, èyí tó yarọ, àti èyí tó ń ṣàìsàn, tí wọ́n sì mú wọn wá fún àwọn àlùfáà láti fi rúbọ. Ẹ̀ṣẹ̀ ńlá gbáà ni!

12. Báwo la ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ láti fún Jèhófà ní ohun tó dára jù lọ?

12 Fífún Jèhófà ní ohun tó dára jù ni ọ̀nà tá a lè gbà fi hàn pé a dìídì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. (Mátíù 22:37, 38) Ní ìyàtọ̀ pátápátá sí àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ oníwàkiwà nígbà ayé Málákì yẹn, ètò àjọ Jèhófà máa ń fúnni láwọn ìtọ́ni àtàtà látinú Ìwé Mímọ́, èyí tó ń ràn wá lọ́wọ́ láti máa fi ìdúpẹ́ gbé Jèhófà ga nípa kíkún ojú ìwọ̀n àwọn ohun tí Ọlọ́run béèrè. Èyí tó tún tan mọ́ èyí ni kókó pàtàkì kẹrin tá a lè fà yọ nínú Málákì orí kìíní.

Ìfẹ́ Ló Ń Súnni Ṣe Ìjọsìn Tòótọ́, Kì Í Ṣe Ìwọra

13. Kí làwọn àlùfáà yẹn ń ṣe tó fi hàn pé oníwọra ni wọ́n?

13 Àwọn àlùfáà ọjọ́ ayé Málákì jẹ́ onímọtara-ẹni-nìkan, wọn kò nífẹ̀ẹ́, wọ́n sì fẹ́ràn owó bí nǹkan míì. Báwo la ṣe mọ̀? Málákì 1:10 sọ pé: “‘Ta sì ni nínú yín tí yóò ti àwọn ilẹ̀kùn? Ẹ kò sì dá iná pẹpẹ mi—lásán. Èmi kò ní inú dídùn sí yín,’ ni Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí, ‘èmi kò sì ní ìdùnnú nínú ọrẹ ẹbọ ẹ̀bùn láti ọwọ́ yín.’” Họ́wù, àwọn àlùfáà oníwọra wọ̀nyẹn máa ń béèrè owó fún èyí tó kéré jù lọ nínú iṣẹ́ ìsìn tẹ́ńpìlì! Kódà, wọ́n máa ń béèrè owó fún pípa àwọn ilẹ̀kùn dé àti dídá àwọn iná pẹpẹ! Abájọ tí Jèhófà kò fi ní inú dídùn sí ọrẹ ẹbọ láti ọwọ́ wọn!

14. Èé ṣe tá a fi lè sọ pé ìfẹ́ ló ń sún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe iṣẹ́ wọn?

14 Ìwà ìwọra àti ìmọtara-ẹni-nìkan àwọn àlùfáà ẹlẹ́ṣẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù ìgbàanì lè rán wa létí pé àwọn oníwọra kò ní jogún Ìjọba Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti wí. (1 Kọ́ríńtì 6:9, 10) Ríronú lórí àwọn ọ̀nà tí àwọn àlùfáà wọ̀nyẹn gbà ń du ire tara wọn nìkan jẹ́ ká túbọ̀ mọyì iṣẹ́ ìwàásù táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe jákèjádò ayé. Iṣẹ́ ìyọ̀ǹda ara ẹni ni; a kì í sì í béèrè owó fún apá èyíkéyìí nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Ó tì o, “àwa kì í ṣe akirità ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.” (2 Kọ́ríńtì 2:17) Bíi ti Pọ́ọ̀lù, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lè sọ ní ti tòótọ́ pé: “Lọ́fẹ̀ẹ́ ni mo fi ìyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ polongo ìhìn rere Ọlọ́run fún yín.” (2 Kọ́ríńtì 11:7) Ṣàkíyèsí pé Pọ́ọ̀lù “fi ìyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ polongo ìhìn rere.” Ìyẹn jẹ́ ká rí kókó karùn-ún tá a mú wá sí àfiyèsí wa nínú Málákì orí kìíní.

Iṣẹ́ Ìsìn Wa sí Ọlọ́run Kì Í Ṣe Ẹrù Ìnira

15, 16. (a) Irú ẹ̀mí wo làwọn àlùfáà ní sí ẹbọ rírú? (b) Báwo làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń rú ẹbọ tiwọn?

15 Àwọn àlùfáà aláìnígbàgbọ́ ní Jerúsálẹ́mù ìgbàanì wo ẹbọ rírú gẹ́gẹ́ bí ààtò ìsìn tí ń dáni lágara. Ẹrù ìnira ló jẹ́ lójú wọn. Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Málákì 1:13, Ọlọ́run sọ fún wọn pé: “Ẹ sì ti wí pé, ‘Wò ó! Ẹ wo bí ìdánilágara rẹ̀ ti pọ̀ tó!’ ẹ sì ti mú kí a ṣítìmú sí i.” Àwọn àlùfáà wọ̀nyẹn ṣítìmú, tàbí ká sọ pé wọ́n pẹ̀gàn àwọn ohun mímọ́ Ọlọ́run. Ẹ jẹ́ ká gbàdúrà pé àwa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan kò ní dà bíi wọn láé. Dípò ìyẹn, ǹjẹ́ ká fìgbà gbogbo máa ní irú ẹ̀mí tó hàn gbangba nínú ọ̀rọ̀ tó wà nínú 1 Jòhánù 5:3 pé: “Èyí ni ohun tí ìfẹ́ fún Ọlọ́run túmọ̀ sí, pé kí a pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́; síbẹ̀ àwọn àṣẹ rẹ̀ kì í ṣe ẹrù ìnira.”

16 Ẹ jẹ́ ká máa fi tayọ̀tayọ̀ rú ẹbọ tẹ̀mí sí Ọlọ́run, kí a má ka èyí sí ẹrù tí ń dáni lágara láé. Ǹjẹ́ kí a kọbi ara sí ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ náà pé: “Gbogbo yín, ẹ sọ fún [Jèhófà] pé, ‘Kí o dárí ìṣìnà jì; kí o sì tẹ́wọ́ gba ohun rere, àwa yóò sì fi ẹgbọrọ akọ màlúù ètè wa rúbọ ní ìdápadà.’” (Hóséà 14:2) Gbólóhùn náà, “ẹgbọrọ akọ màlúù ètè wa,” túmọ̀ sí ẹbọ tẹ̀mí, ìyẹn ọ̀rọ̀ tá a fi ń yin Jèhófà àti èyí tá à ń sọ nípa àwọn ète rẹ̀. Ìwé Hébérù 13:15 sọ pé: “Nípasẹ̀ [Jésù Kristi], ẹ jẹ́ kí a máa rú ẹbọ ìyìn sí Ọlọ́run nígbà gbogbo, èyíinì ni, èso ètè tí ń ṣe ìpolongo ní gbangba sí orúkọ rẹ̀.” Inú wa mà dùn o, pé àwọn ẹbọ wa tẹ̀mí kì í ṣe èyí tí kò dénú ọkàn, bí kò ṣe èyí tó fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tọkàntọkàn! Èyí sún wá dórí kókó kẹfà tá a rí fà yọ nínú Málákì orí kìíní.

Olúkúlùkù Wa Gbọ́dọ̀ Jíhìn

17, 18. (a) Èé ṣe tí Jèhófà gégùn-ún fún “ẹni tí ń hùwà àlùmọ̀kọ́rọ́yí”? (b) Kí làwọn tó ń hùwà àlùmọ̀kọ́rọ́yí yìí kò ronú lé lórí?

17 Gbogbo àwọn tó gbáyé ní ọjọ́ Málákì ló jíhìn iṣẹ́ ọwọ́ wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, bẹ́ẹ̀ làwa náà yóò ṣe. (Róòmù 14:12; Gálátíà 6:5) Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, Málákì 1:14 sọ pé: “Ègún sì ni fún ẹni tí ń hùwà àlùmọ̀kọ́rọ́yí nígbà tí akọ ẹran [tí kò lábùkù] wà nínú agbo ẹran ọ̀sìn rẹ̀, tí ó sì ń jẹ́ ẹ̀jẹ́, tí ó sì ń fi èyí tí ó ti di alábùkù rúbọ sí Jèhófà.” Kì í ṣe ẹran kan ṣoṣo gíro—bí ẹyọ àgùntàn kan ṣoṣo—ni ẹni tó ní agbo ẹran ọ̀sìn ní, tá a fi lè sọ pé kò rí ọgbọ́n mìíràn dá. Nígbà tónítọ̀hún bá fẹ́ yan ẹran tó fẹ́ lò fún ìrúbọ, kò sídìí fún yíyan èyí tó fọ́jú, èyí tó yarọ, tàbí èyí tó ń ṣàìsàn. Tó bá lọ yan ẹran tó lábùkù lára, ìyẹn á fi hàn pé ó tẹ́ńbẹ́lú ètò tí Jèhófà ṣe fún ìrúbọ nìyẹn, nítorí ó dájú pé kò lè burú-burú kí ọkùnrin kan tó ní agbo ẹran ọ̀sìn máà lè rí ọ̀kan tí kò ní àbùkù lára!

18 Abájọ tí Jèhófà fi gégùn-ún fún ẹni tó ń hùwà àlùmọ̀kọ́rọ́yí, tó ní akọ ẹran tó dára, àmọ́ tó mú ẹran tó fọ́jú, èyí tó yarọ, tàbí èyí tó ń ṣàìsàn wá, bóyá ńṣe ló tiẹ̀ wọ́ ọ wá sọ́dọ̀ àlùfáà fún ìrúbọ. Síbẹ̀, kò tiẹ̀ sí ohun tó fi hàn rárá pé àlùfáà èyíkéyìí mẹ́nu kan òfin Ọlọ́run pé irú ẹran tó lábùkù bẹ́ẹ̀ kò ṣètẹ́wọ́gbà. (Léfítíkù 22:17-20) Àwọn tó bá mọ inú rò nínú wọn ti ní láti mọ̀ pé àwọn ò ní fara re lọ, bí wọ́n bá ṣèèṣì mú irú ẹ̀bùn bẹ́ẹ̀ lọ fún gómìnà wọn. Bẹ́ẹ̀, Jèhófà, Ọba Aláṣẹ Ayé òun Ọ̀run ni wọ́n ń ṣe bẹ́ẹ̀ sí, ẹni tó ga ju gómìnà lọ fíìfíì. Málákì 1:14 sọ ọ̀rọ̀ náà lọ́nà yìí pé: “‘Ọba ńlá ni mi,’ ni Jèhófà àwọn ọmọ ogun wí, ‘orúkọ mi yóò sì jẹ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.’”

19. Kí là ń wọ̀nà fún, kí ló sì yẹ ká máa ṣe?

19 Gẹ́gẹ́ bí adúróṣinṣin ìránṣẹ́ Ọlọ́run, à ń wọ̀nà fún ọjọ́ náà tí gbogbo aráyé yóò máa bọlá fún Jèhófà Ọba Ńlá náà. Ní àkókò yẹn, “ilẹ̀ ayé yóò kún fún ìmọ̀ Jèhófà bí omi ti bo òkun.” (Aísáyà 11:9) Ní báyìí ná, ẹ jẹ́ ká sa gbogbo ipá wa láti kúnjú ìwọ̀n ohun tí Jèhófà béèrè nípa fífarawé onísáàmù tó sọ pé: “Èmi yóò . . . fi ìdúpẹ́ gbé e ga lọ́lá.” (Sáàmù 69:30) Láti ṣe èyí, àsọtẹ́lẹ̀ Málákì ní ìmọ̀ràn tó lè túbọ̀ ṣàǹfààní fún wa. Ẹ jẹ́ ká gbé àwọn apá mìíràn nínú ìwé Málákì yẹ̀ wò dáadáa nínú àpilẹ̀kọ méjì tó tẹ̀ lé e.

Ṣé O Rántí?

• Èé ṣe tó fi yẹ ká gbé Jèhófà ga?

• Kí nìdí tí ẹbọ táwọn àlùfáà ń rú nígbà ayé Málákì kò fi ṣètẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Jèhófà?

• Báwo la ṣe ń rú ẹbọ ìyìn sí Jèhófà?

• Kí ló yẹ kó máa súnni ṣe ìjọsìn tòótọ́?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Àsọtẹ́lẹ̀ Málákì tọ́ka sí ọjọ́ wa

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Ísọ̀ kò mọyì àwọn ohun mímọ́

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]

Àwọn àlùfáà àtàwọn èèyàn náà ń rú ẹbọ tí kò ṣètẹ́wọ́gbà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Jákèjádò ayé làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń rú ẹbọ ìyìn ní fàlàlà