Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Onírúurú Nǹkan Ló Ń Sọni Di Aláàbọ̀ Ara

Onírúurú Nǹkan Ló Ń Sọni Di Aláàbọ̀ Ara

Onírúurú Nǹkan Ló Ń Sọni Di Aláàbọ̀ Ara

À WỌN sójà fipá gbé ọkùnrin kan tí ń jẹ́ Christian, tó ń gbé lórílẹ̀-èdè kan ní Áfíríkà, wọ́n fẹ́ fi túláàsì sọ ọ́ di ológun. Àmọ́, ó kọ̀ jálẹ̀ nítorí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ tó ti fi Bíbélì kọ́ lẹ́kọ̀ọ́. Bí àwọn sójà náà ṣe mú un lọ sí àgọ́ àwọn ológun nìyẹn o. Ni wọ́n bá fi odindi ọjọ́ mẹ́rin lù ú bí ẹní máa kú. Lẹ́yìn náà ni ọ̀kan lára wọ́n wá yìnbọn fún un lẹ́sẹ̀. Christian rọ́jú dé ọsibítù. Àmọ́ gígé ni wọ́n gé ẹsẹ̀ ọ̀hún nísàlẹ̀ orúnkún. Ní orílẹ̀-èdè mìíràn ní Áfíríkà, àwọn jagunjagun adàlúrú kan ń gé ọwọ́ tàbí ẹsẹ̀ àwọn ọmọdé pàápàá. Láti orílẹ̀-èdè Cambodia dé àgbègbè Balkan àti láti orílẹ̀-èdè Afghanistan dé Àǹgólà làwọn ohun abúgbàù tí wọ́n rì mọ́lẹ̀ ti ń ṣọṣẹ́, tí wọ́n ń sọ tọmọdé tàgbà di aláàbọ̀ ara.

Àwọn nǹkan mìíràn tó tún ń sọni di aláàbọ̀ ara ni jàǹbá, àti àìsàn bí àtọ̀gbẹ. Kódà àwọn nǹkan olóró tó kún inú afẹ́fẹ́ lè sọni di aláàbọ̀ ara. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n bí àwọn ọmọ mélòó kan tí ọ́kan lára ọwọ́ wọ́n jẹ́ ààbọ̀ ní àwọn àgbègbè ìlú kan ní Ìlà Oòrùn Yúróòpù. Ìwọ̀nba díẹ̀ ni ọwọ́ ọ̀tún wọ́n fi gùn kọjá ìgúnpá. Ẹ̀rí fi hàn pé àwọn kẹ́míkà burúkú tó ti dabarú ètò ìṣiṣẹ́ ara wọn ló ń ṣọṣẹ́ yìí. Àìmọye èèyàn tún wà tó jẹ́ pé gbogbo ara wọ́n ló pé, àmọ́ tí wọ́n ṣì jẹ́ abirùn síbẹ̀, bóyá nítorí ẹ̀yà ara kan tó ti rọ tàbí nítorí ìṣòro mìíràn. Àní sẹ́, onírúurú nǹkan ló ń sọni di aláàbọ̀ ara.

Ohun yòówù kó fà á, ohun ìbànújẹ́ gbáà ni kéèyàn jẹ́ aláàbọ̀ ara. Ọmọ ogún ọdún ni Junior nígbà tí apá ìsàlẹ̀ ẹsẹ̀ òsì rẹ̀ gé. Ọmọkùnrin náà sọ lẹ́yìn náà pé: “Àròdùn tó dé bá mi kò kéré. Mo sunkún-sunkún nítorí pé ẹsẹ̀ mi ti lọ gbé nìyẹn. Mi ò mọ ohun tí ǹ bá ṣe. Gbogbo rẹ̀ tojú sú mi.” Nígbà tó yá ṣá, ìṣarasíhùwà Junior wá yàtọ̀ gan-an. Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kì í ṣe kìkì pé àwọn ohun tó kọ́ jẹ́ kí ó lè kojú ipò tó bá ara rẹ̀ yìí nìkan ni, àmọ́ jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹ̀kọ́ yìí tún fún un ní ìrètí àgbàyanu nípa ọjọ́ ọ̀la aláyọ̀ níhìn-ín lórí ilẹ̀ ayé. Bó o bá jẹ́ aláàbọ̀ ara, ṣé ìwọ náà á fẹ́ irú ìrètí yẹn?

Bó o bá fẹ́ ní ìrètí yẹn, jọ̀wọ́ ka àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e. A dá a lábàá pé kí o ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tọ́ka sí nínú Bíbélì tìrẹ, kí ìwọ fúnra rẹ lè rí ohun tí Ẹlẹ́dàá yóò ṣe lọ́jọ́ iwájú fáwọn tó bá mọ̀ nípa ète rẹ̀, tí wọ́n sì yí ìgbésí ayé wọn padà láti mú un bá ète yìí mu.