Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbísí Bíbùáyà Mú Kí Ìmúgbòòrò Ojú Ẹsẹ̀ Pọn Dandan

Ìbísí Bíbùáyà Mú Kí Ìmúgbòòrò Ojú Ẹsẹ̀ Pọn Dandan

“Ẹ Wá Sọ́dọ̀ Mi, . . . Èmi Yóò Sì Tù Yín Lára”

Ìbísí Bíbùáyà Mú Kí Ìmúgbòòrò Ojú Ẹsẹ̀ Pọn Dandan

JÉSÙ KRISTI sọ pé: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, . . . èmi yóò sì tù yín lára.” (Mátíù 11:28) Ẹ ò rí i pé ìkésíni amọ́kànyọ̀ gan-an lèyí, látọ̀dọ̀ Orí ìjọ Kristẹni! (Éfésù 5:23) Nígbà tá a bá ronú jinlẹ̀ lórí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn, kò sí bí a ò ṣe ní mọrírì orísun ìtura pàtàkì tá a ní—ìyẹn ni ìfararora pẹ̀lú àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa nípa tẹ̀mí láwọn ìpàdé Kristẹni. A gbà pé òótọ́ gidi ni ọ̀rọ̀ onísáàmù náà, ẹni tó kọ ọ́ lórin pé: “Ó mà dára o, ó mà dùn o, pé kí àwọn ará máa gbé pa pọ̀ ní ìṣọ̀kan!”—Sáàmù 133:1.

Láìṣe àní-àní, ìfararora tá à ń ní láwọn ibi ìkórajọ fún ìjọsìn wọ̀nyẹn ni èyí tó dára jù lọ, ibẹ̀ ń fini lọ́kàn balẹ̀ nípa tẹ̀mí, afẹ́fẹ́ àlàáfíà ló sì ń fẹ́ níbẹ̀. Abájọ tí Kristẹni ọ̀dọ́ kan fi sọ pé: “Mo máa ń lọ síléèwé lójoojúmọ́, ó sì máa ń jẹ́ kó rẹ̀ mí tẹnutẹnu. Àmọ́ àwọn ìpàdé dà bíi pápá oko tútù nínú aṣálẹ̀, ibẹ̀ ni mo ti máa ń rí ìtura tó ń jẹ́ kí n lè kojú ìpèníjà iléèwé níjọ́ kejì.” Ọ̀dọ́ kan tó jẹ́ ọmọ Nàìjíríà sọ pé: “Mo rí i pé níní ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn èèyàn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ń ràn mí lọ́wọ́ láti sún mọ́ ọn pẹ́kípẹ́kí.”

Gbọ̀ngàn Ìjọba àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò ni ibi tá à ń lò gẹ́gẹ́ bí ibùdó ìjọsìn tòótọ́. Ní ibi púpọ̀ jù lọ, a máa ń ṣe àwọn ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba ní ó kéré tán ìgbà méjì lọ́sẹ̀, a sì máa ń rọ àwọn tá à ń bá ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láti tètè bẹ̀rẹ̀ sí dara pọ̀ kí wọ́n lè jàǹfààní nínú ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ atunilára tó wà níbẹ̀.—Hébérù 10:24, 25.

Ohun Tó Ń Fẹ́ Àbójútó ní Kíákíá

Àmọ́, ó yẹ fún àfiyèsí pé, kì í ṣe gbogbo Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tó bójú mu. Ìbísí bíbùáyà tó ń wáyé nínú iye àwọn olùpòkìkí Ìjọba náà jákèjádò ayé ti fa ohun kan tó ń fẹ́ àbójútó ní kíákíá. A ṣì nílò ẹgbẹẹgbẹ̀rún Gbọ̀ngàn Ìjọba, àgàgà láwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà.—Aísáyà 54:2; 60:22.

Bí àpẹẹrẹ, Gbọ̀ngàn Ìjọba mẹ́wàá péré ló wà fún ìjọ igba ó lé àádọ́rùn-ún [290] tó wà ní olú ìlú Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti Kóńgò. Orílẹ̀-èdè yẹn nílò ọ̀pọ̀ Gbọ̀ngàn Ìjọba ní kíákíá. Ọ̀pọ̀ jù lọ ìjọ tó wà ní Àǹgólà ló máa ń ṣe ìpàdé wọn níta gbangba nítorí pé àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà níbẹ̀ kò pọ̀ rárá. Irú ohun kan náà sì ń fẹ́ àbójútó ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè mìíràn.

Nítorí ìdí èyí, àtọdún 1999 la ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣètò láti kọ́wọ́ ti kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba láwọn orílẹ̀-èdè tí wọn ò ti fi bẹ́ẹ̀ rí towó ṣe. Àwọn Ẹlẹ́rìí tó nírìírí ti yọ̀ǹda ara wọn fún iṣẹ́ yìí kí wọ́n lè ṣèrànwọ́ láti bójú tó iṣẹ́ ìkọ́lé ní irú àwọn ilẹ̀ bẹ́ẹ̀. Nígbà tá a bá pa irú ìsapá bẹ́ẹ̀ pọ̀ mọ́ ẹ̀mí ìmúratán àti wíwà táwọn tó yọ̀ǹda ara wọn ládùúgbò wà lárọ̀ọ́wọ́tó, àbájáde rẹ̀ máa ń wúni lórí gan-an ni. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ládùúgbò máa ń jàǹfààní nínú ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n ń gbà. Gbogbo èyí ló ń jẹ́ kó ṣeé ṣe láti kájú ohun tá à ń fẹ́ láti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba láwọn orílẹ̀-èdè wọn.

A sì tipa bẹ́ẹ̀ ṣètò ìrànlọ́wọ́ tó gbéṣẹ́ fún lílo onírúurú ọ̀nà láti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba lọ́nà tó bá bí wọ́n ṣe ń kọ́lé ládùúgbò mu, a sì ń lo àwọn ohun èlò tó wà ládùúgbò. Kì í ṣe kíkọ́ ọ̀pọ̀ Gbọ̀ngàn Ìjọba nìkan ló ká wa lára, àmọ́ láti tún ṣètò bíbójútó Gbọ̀ngàn Ìjọba wọ̀nyẹn bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ.—2 Kọ́ríńtì 8:14, 15.

Àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀ Tuntun Tó Ń Mórí Ẹni Wú

Ipa wo ni ìsapá láti pèsè àwọn ibi ìjọsìn wọ̀nyí ti ní? Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2001, ìròyìn kan láti Màláwì sọ pé: “Ohun tá a ti ṣàṣeparí rẹ̀ lórílẹ̀-èdè yìí wúni lórí gan-an. A ó parí àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba mìíràn ní oṣù méjì sí àkókò tá a wà yìí.” (Àwòrán 1àti 2) Ní Tógò, ó ṣeé ṣe fún àwọn tó jẹ́ olùyọ̀ǹda ara ẹni láti kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba mọ́ńbé bíi mélòó kan lẹ́nu àwọn oṣù àìpẹ́ yìí. (Àwòrán 3) Iṣẹ́ àtàtà táwọn tó yọ̀ǹda ara wọn tinútinú wọ̀nyí ṣe tún ń jẹ́ kó ṣeé ṣe láti ní àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tó bójú mu ní ìlú Mẹ́síkò, lórílẹ̀-èdè Brazil, àti láwọn orílẹ̀-èdè mìíràn.

Àwọn ìjọ ti kíyè sí i pé ìgbà táwọn bá kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tán làwọn aládùúgbò máa ń rí i pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti fìdí múlẹ̀ síbẹ̀. Ọ̀pọ̀ ni kì í fẹ́ dara pọ̀ mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí títí dìgbà tí wọ́n bá rí i pé wọ́n ti ní ibi ìjọsìn tó bójú mu. Ìjọ Nafisi tó wà ní Màláwì ròyìn pé: “Gbọ̀ngàn Ìjọba bíbójúmu tá a ní nísinsìnyí ti ń yọrí sí ìjẹ́rìí àtàtà. Nítorí náà, ó wá rọrùn láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.”

Ọ̀pọ̀ ìfiniṣẹ̀sín ni àwọn ará ìjọ Krake ní orílẹ̀-èdè Benin tí fara dà sẹ́yìn nítorí pé Gbọ̀ngàn Ìjọba tí wọ́n ní tẹ́lẹ̀ kò bójú mu rárá ní ìfiwéra pẹ̀lú àwọn ṣọ́ọ̀ṣì kan. (Àwòrán 4) Nísinsìnyí, ìjọ náà ti ní Gbọ̀ngàn Ìjọba rèǹtèrente tó ń ṣojú fún ìjọsìn tòótọ́ lọ́nà tó bójú mu tó sì gbayì. (Àwòrán 5) Ìjọ yìí ní àwọn akéde Ìjọba mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n nínú, ìpíndọ́gba àwọn mẹ́tàléláàádọ́rin ló sì máa ń wá sípàdé láwọn ọjọ́ Sunday. Àmọ́ ẹgbẹ̀ta ó lé mọ́kànléláàádọ́ta [651] èèyàn ló pésẹ̀ nígbà tí wọ́n ya Gbọ̀ngàn Ìjọba náà sí mímọ́. Àwọn aráàlú ló pọ̀ jù lọ lára àwọn tó wá. Wọ́n wá nítorí pé ó yà wọ́n lẹ́nu gan-an nígbà tí wọ́n rí i pé àwọn Ẹlẹ́rìí kọ́ gbọ̀ngàn kan parí láàárín àkókò kúkúrú. Nígbà tí wọ́n gbé ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá lórí ọ̀ràn yìí yẹ̀ wò, ẹ̀ka ti Zimbabwe kọ̀wé pé: “Àwọn tó ń wá sí ìpàdé sábà máa ń di ìlọ́po méjì láàárín oṣù kan tí wọ́n bá kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun.”—Àwòrán 6 àti 7.

Láìsí àní-àní, ọ̀pọ̀ Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun tó wà ń pèsè ibi ìtura nípa tẹ̀mí fún àwọn Kristẹni tó ti ya ara wọn sí mímọ́ àtàwọn olùfìfẹ́hàn. Ohun tí Ẹlẹ́rìí kan sọ ní Ukraine lẹ́yìn tí ìjọ àdúgbò náà bẹ̀rẹ̀ sí lo Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn tuntun ni pé: “Inú wa dùn gan-an ni. A ti fi ojú ara wa rí i bí Jèhófà ṣe ń ran àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́.”

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10, 11]

A Mọrírì Ìtìlẹ́yìn Ọlọ́làwọ́ Yín

Inú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà dùn láti rí ìsapá gidi tá a ti ṣe láti kájú ohun tá à ń fẹ́ láti ní àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun kárí ayé. Ìbísí láìsọsẹ̀ tó ń wáyé nínú iye àwọn olùjọ́sìn Jèhófà láwọn ilẹ̀ bíi mélòó kan fi hàn pé a ní láti kọ́ ọ̀pọ̀ Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun lọ́jọ́ iwájú. Àní sẹ́, ní ìpíndọ́gba, ìjọ tuntun méjìlélọ́gbọ̀n là ń dá sílẹ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ nínú ọdún iṣẹ́ ìsìn 2001! Irú àwọn ìjọ bẹ́ẹ̀ nílò ibi tí wọn ó ti máa pàdé, tí wọn ó sì ti máa jọ́sìn.

Ìbéèrè náà lè dìde pé, ‘Báwo la ṣe ń rówó ná sórí irú iṣẹ́ bíi kíkọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun, àgàgà láwọn orílẹ̀-èdè táwọn ará ò ti fi bẹ́ẹ̀ rí towó ṣe?’ Ìdáhùn rẹ̀ ni pé ìtìlẹ́yìn Ọlọ́run àti ẹ̀mí ọ̀làwọ́ àwọn èèyàn ni.

Gẹ́gẹ́ bí ìlérí Jèhófà, ó ń tú ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ dà sórí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, kí ó lè ṣeé ṣe fún wọn “láti máa ṣe rere, láti jẹ́ ọlọ́rọ̀ nínú àwọn iṣẹ́ àtàtà, láti jẹ́ aláìṣahun, kí wọ́n múra tán láti ṣe àjọpín.” (1 Tímótì 6:18) Ẹ̀mí Ọlọ́rùn ló ń sún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà ní gbogbo ọ̀nà—wọ́n ń lo àkókò wọn, agbára wọn, iṣẹ́ ọwọ́ wọn, àti àwọn nǹkan mìíràn fún ìgbòkègbodò Kristẹni.

Ẹ̀mí ọ̀làwọ́ ló ń mú kí àwọn Ẹlẹ́rìí àtàwọn mìíràn tó ń ṣètìlẹ́yìn máa fowó ṣèrànwọ́ fún ìmúgbòòrò àti àwọn iṣẹ́ ìkọ́lé. Yàtọ̀ sí ṣíṣèrànwọ́ láti kájú àwọn ìnáwó tó máa ń yọjú láwọn ìjọ àdúgbò, wọ́n tún máa ń dáwó fún iṣẹ́ ìkọ́lé tó ń lọ láwọn apá ibòmíràn lórí ilẹ̀ ayé.

Nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan, àwọn àpótí kan wà tí a kọ “Contributions for the Worldwide Work [Ọrẹ fún Iṣẹ́ Kárí Ayé]—Mátíù 24:14,” sí lára. Àwọn èèyàn lè fi ọrẹ àtinúwá wọn sínú àpótí náà. (2 Àwọn Ọba 12:9) Gbogbo ọrẹ wọ̀nyẹn, àti ńlá àti kékeré, la mọrírì. (Máàkù 12:42-44) Onírúurú ọ̀nà la gbà ń lo àwọn owó wọ̀nyí ní ìbámu pẹ̀lú ohun tá à ń fẹ́, títí kan kíkọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba. A kì í fi irú owó bẹ́ẹ̀ san owó oṣù fáwọn lọ́gàálọ́gàá, nítorí pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò ní ohun tó jọ bẹ́ẹ̀.

Ǹjẹ́ à ń lo ọrẹ fún iṣẹ́ kárí ayé fún ohun tá a ṣètò rẹ̀ fún? Bẹ́ẹ̀ ni. Ẹ̀ka iléeṣẹ́ tó wà ní Liberia—ìyẹn orílẹ̀-èdè tí ogun abẹ́lé ti sọ di ẹdun arinlẹ̀—ròyìn pé èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ládùúgbò náà ni kò níṣẹ́ lọ́wọ́, tí ìṣòro àìrówóná sì ń bá wọn fínra. Báwo làwọn ènìyàn Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè yìí ṣe wá máa ní ibi ìjọsìn tó bójú mu? Ẹ̀ka iléeṣẹ́ wa tó wà níbẹ̀ sọ pé: “Ọrẹ táwọn ará fi ẹ̀mí ọ̀làwọ́ ṣe láti àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn la máa ń lò fún iṣẹ́ náà. Ìṣètò tó mọ́gbọ́n dání, tó sì fìfẹ́ hàn gbáà lèyí!”

Àwọn ará tó wà ládùúgbò wọ̀nyí pẹ̀lú ń dáwó, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò fi bẹ́ẹ̀ ní lọ́wọ́. Orílẹ̀-èdè Sierra Leone tó wà nílẹ̀ Áfíríkà ròyìn pé: “Àwọn ará tó wà níbí ń ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ ọ̀hún, inú wọn sì dùn láti lo gbogbo agbára wọn, kí wọ́n sì fi iyekíye tí wọ́n bá rí ṣètìlẹ́yìn fún kíkọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba.”

Ní òpin gbogbo rẹ̀, àwọn ilé tá a kọ́ yìí ń mú ìyìn bá Jèhófà. Àwọn ará láti Liberia fi tìtaratìtara sọ pé: “Kíkọ́ ibi tó bójú mu fún ìjọsìn jákèjádò orílẹ̀-èdè yìí yóò jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé ìjọsìn tòótọ́ ti fìdí múlẹ̀ níhìn-ín, yóò sì bu iyì àti ọlá fún orúkọ ńlá Ọlọ́run wa.”