Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ó Yẹ Ká Mọ Ẹni Tí Ọlọ́run Jẹ́

Ó Yẹ Ká Mọ Ẹni Tí Ọlọ́run Jẹ́

Ó Yẹ Ká Mọ Ẹni Tí Ọlọ́run Jẹ́

ǸJẸ́ orí rẹ kì í wú nígbà tó o bá rí òfuurufú tó kún fún ìràwọ̀ ní alẹ́ tí ojú ọ̀run mọ́ roro? Ǹjẹ́ o kì í fẹ́ gbọ́ òórùn títa sánsán àwọn òdòdó aláwọ̀ mèremère? Ǹjẹ́ o kì í gbádùn orin àwọn ẹyẹ àti bí ewé ṣe máa ń fẹ́ lẹ́lẹ́ nígbà tí atẹ́gùn bá rọra ń fẹ́? Sì wo bí àwọn ẹja àbùùbùtán tó lágbára àtàwọn ẹ̀dá mìíràn tó wà nínú òkun ṣe ń fani lọ́kàn mọ́ra tó! Bẹ́ẹ̀ làwa ẹ̀dá ènìyàn tún wà tá a ní ẹ̀rí ọkàn àti ọpọlọ tó jẹ́ àwámárìídìí. Kí lo lè sọ nípa bí gbogbo nǹkan àgbàyanu tó yí wa ká wọ̀nyí ṣe débẹ̀?

Àwọn kan gbà gbọ́ pé ńṣe ni gbogbo nǹkan wọ̀nyí ṣàdédé yọjú. Àmọ́ tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí, èé ṣe táwọn èèyàn fi wá gbà gbọ́ pé Ọlọ́run wà? Báwo ni ọ̀kan-kò-jọ̀kan kẹ́míkà tó ṣèèṣì para pọ̀ ṣe lè mú àwọn ẹ̀dá tó ní ẹ̀mí ìjọsìn jáde?

“Ìsìn ti fìdí múlẹ̀ ṣinṣin sínú ẹ̀dá ènìyàn, ó sì ti di ara gbogbo èèyàn láìfi bí ẹni kan ṣe lówó lọ́wọ́ tó àti bó ṣe kàwé tó pè.” Gbólóhùn yìí ni Ọ̀jọ̀gbọ́n Alister Hardy fi ṣàkópọ̀ ìwádìí tó kọ sínú ìwé rẹ̀, The Spiritual Nature of Man. Àwọn àyẹ̀wò tí wọ́n ṣe lórí ọpọlọ lẹ́nu àìpẹ́ yìí ti jẹ́ káwọn onímọ̀ nípa ètò iṣan ara kan sọ pé ó lè jẹ́ pé ńṣe la “bí” ẹ̀mí ìjọsìn “mọ́” ẹ̀dá ènìyàn. Ìwé tá a pe àkọlé rẹ̀ ní Is God the Only Reality? sọ pé: “Wíwá ìtumọ̀ ìgbésí ayé lọ sínú ẹ̀sìn . . . wọ́pọ̀ nínú gbogbo ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà àti nínú gbogbo sànmánì látìgbà tí ènìyàn ti wà.”

Ronú nípa ohun tí ọkùnrin kan tó jẹ́ ọ̀mọ̀wé sọ ní nǹkan bí ẹgbàá ọdún sẹ́yìn. Ó kọ̀wé pé: “Olúkúlùkù ilé ni a kọ́ láti ọwọ́ ẹnì kan, ṣùgbọ́n ẹni tí ó kọ́ ohun gbogbo ni Ọlọ́run.” (Hébérù 3:4) Kódà, ẹsẹ àkọ́kọ́ pàá nínú Bíbélì sọ pé: “Ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀, Ọlọ́run dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé.”—Jẹ́nẹ́sísì 1:1.

Ta ni Ọlọ́run gan-an? Èrò àwọn èèyàn kò ṣọ̀kan lórí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí. Nígbà tí wọ́n béèrè ẹni tí Ọlọ́run jẹ́, ọ̀dọ́langba ará Japan kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Yoshi fèsì pé: “Mi ò lè sọ. Ẹlẹ́sìn Búdà ni mí, kò sì fìgbà kan jẹ́ nǹkan bàbàrà fún mi láti mọ ẹni tí Ọlọ́run jẹ́.” Àmọ́, Yoshi gbà pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ka Búdà alára sí ọlọ́run. Nick, ọkùnrin oníṣòwò kan tó ti lé lẹ́ni ọgọ́ta ọdún, gba Ọlọ́run gbọ́, ó sì gbà pé alágbára gbogbo ni. Nígbà tí wọ́n sọ pé kó ṣàlàyé ohun tó mọ̀ nípa Ọlọ́run, Nick kọ́kọ́ dákẹ́ lọ gbári, kó tó wá fèsì pé: “Àwé, ìbéèrè yẹn le bí ojú ẹja. Gbogbo ohun tí mo lè sọ ni pé Ọlọ́run ń bẹ. Ó wà.”

Àwọn èèyàn kan “ń jọ́sìn ohun tí Ọlọ́run dá, ìyẹn ni wọ́n sì ń sìn dípò Ẹlẹ́dàá fúnra rẹ̀.” (Róòmù 1:25, Today’s English Version) Ọ̀kẹ́ àìmọye ló ń jọ́sìn àwọn baba ńlá tó ti kú, nítorí wọ́n gbà pé kò sẹ́ni tó lè sún mọ́ Ọlọ́run. Ọ̀pọ̀ ọlọ́run àtàwọn abo-ọlọ́run ló wà nínú ẹ̀sìn Híńdù. Onírúurú àwọn ọlọ́run àjúbàfún, bíi Súúsì àti Hẹ́mísì, làwọn èèyàn ń jọ́sìn nígbà ayé àwọn àpọ́sítélì Jésù Kristi. (Ìṣe 14:11, 12) Ọ̀pọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì ló ń kọ́ni pé Ọlọ́run jẹ́ Mẹ́talọ́kan, tó ní Ọlọ́run Baba, Ọlọ́run Ọmọ àti Ọlọ́run Ẹ̀mí Mímọ́ nínú.

Ní tòótọ́, “ọ̀pọ̀ ‘ọlọ́run’ àti ọ̀pọ̀ ‘olúwa’” ló wà, gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti wí. Àmọ́, ó tún fi kún un pé: “Ní ti gidi, fún àwa, Ọlọ́run kan ní ń bẹ, Baba, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ohun gbogbo ti wá.” (1 Kọ́ríńtì 8:5, 6) Dájúdájú, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo ló wà. Àmọ́ ta ni? Báwo ló ṣe rí? Ó ṣe pàtàkì pé ká rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí. Jésù alára sọ nínú àdúrà tó gbà sí Ẹni yìí pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.” (Jòhánù 17:3) Kò sí àní-àní pé ire wa ayérayé sinmi lórí mímọ òtítọ́ nípa Ọlọ́run.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]

Báwo ni nǹkan wọ̀nyí ṣe débẹ̀?

[Credit Line]

Ẹja àbùùbùtán: Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda Tourism Queensland

[Picture Credit Line on page 2]

Ẹ̀YÌN ÌWÉ: Index Stock Photography © 2002