Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jíjàǹfààní Inú-rere-onífẹ̀ẹ́ Jèhófà

Jíjàǹfààní Inú-rere-onífẹ̀ẹ́ Jèhófà

Jíjàǹfààní Inú-rere-onífẹ̀ẹ́ Jèhófà

“Ta ni ó gbọ́n? Yóò . . . fi ara rẹ̀ hàn ní olùfiyèsí àwọn ìṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́ ti Jèhófà.”—SÁÀMÙ 107:43.

1. Ìgbà wo ni Bíbélì kọ́kọ́ lo ọ̀rọ̀ náà “inú-rere-onífẹ̀ẹ́,” àwọn ìbéèrè wo la ó sì gbé yẹ̀ wò nípa ànímọ́ yìí?

 NÍ NǸKAN bí ẹgbàajì [4,000] ọdún sẹ́yìn, Lọ́ọ̀tì ọmọ ẹ̀gbọ́n Ábúráhámù sọ nípa Jèhófà pé: “Ìwọ . . . ń gbé inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ ga lọ́lá.” (Jẹ́nẹ́sísì 19:19) Ibí yìí ni Bíbélì ti kọ́kọ́ lo ọ̀rọ̀ náà “inú-rere-onífẹ̀ẹ́.” Jékọ́bù, Náómì, Dáfídì àtàwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run yòókù pẹ̀lú sọ̀rọ̀ nípa ànímọ́ Jèhófà yìí. (Jẹ́nẹ́sísì 32:10; Rúùtù 1:8; 2 Sámúẹ́lì 2:6) Àní, ó ju àádọ́ta-lé-rúgba [250] ìgbà tí ọ̀rọ̀ náà “inú-rere-onífẹ̀ẹ́” fara hàn nínú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun. Àmọ́ kí ni inú-rere-onífẹ̀ẹ́ Jèhófà? Àwọn wo ló fi ànímọ́ yìí hàn sí láyé àtijọ́? Báwo la sì ṣe ń jàǹfààní nínú ànímọ́ yìí lóde òní?

2. Kí nìdí tí ọ̀rọ̀ Hébérù tá a tú sí “inú-rere-onífẹ̀ẹ́” fi ṣòroó túmọ̀, gbólóhùn mìíràn wo ló tún túmọ̀ rẹ̀?

2 Nínú Ìwé Mímọ́, “inú-rere-onífẹ̀ẹ́” la fi túmọ̀ ọ̀rọ̀ Hébérù kan tí ìtumọ̀ rẹ̀ pẹ̀ka tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tó fi jẹ́ pé ṣàṣà lèdè tó ní ọ̀rọ̀ kan ṣoṣo tó gbé gbogbo ìtumọ̀ rẹ̀ yọ. Àní, àwọn ọ̀rọ̀ bí “ìfẹ́,” “àánú” àti “ìṣòtítọ́” pàápàá kò gbé gbogbo ìtumọ̀ rẹ̀ yọ. Àmọ́, ọ̀rọ̀ náà “inú-rere-onífẹ̀ẹ́” ní ìtumọ̀ tó gbòòrò, tó fẹ́rẹ̀ẹ́ kárí gbogbo ìtumọ̀ tí ọ̀rọ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà ní. Ó bá a mu wẹ́kú pé Bíbélì Atọ́ka ti Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun (Gẹ̀ẹ́sì) lo gbólóhùn náà “ìfẹ́ adúróṣinṣin” gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ mìíràn tá a lè lò fún ọ̀rọ̀ Hébérù tá a túmọ̀ sí “inú-rere-onífẹ̀ẹ́.”—Ẹ́kísódù 15:13; Sáàmù 5:7; àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW.

Ó Yàtọ̀ sí Ìfẹ́ àti Ìdúróṣinṣin

3. Báwo ni inú-rere-onífẹ̀ẹ́ ṣe yàtọ̀ sí ìfẹ́?

3 Inú-rere-onífẹ̀ẹ́, tàbí ìfẹ́ adúróṣinṣin, tan mọ́ ìfẹ́ àti ìdúróṣinṣin. Síbẹ̀, ó yàtọ̀ sí ànímọ́ wọ̀nyí láwọn ọ̀nà pàtàkì kan. Ẹ jẹ́ ká wo ìyàtọ̀ tó wà láàárín inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti ìfẹ́. Nínú àwọn èdè kan, a lè sọ pé a nífẹ̀ẹ́ nǹkan kan tí kò lẹ́mìí àtàwọn ànímọ́ kan. Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ẹni tó “nífẹ̀ẹ́ wáìnì àti òróró” àti ẹni tó “nífẹ̀ẹ́ ọgbọ́n.” (Òwe 21:17; 29:3) Ṣùgbọ́n àwọn èèyàn la máa ń ṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sí, a kì í ṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sí ìwà kan tàbí sí ohun aláìlẹ́mìí. Fún àpẹẹrẹ, àwọn èèyàn là ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ nígbà tí Ẹ́kísódù 20:6 sọ pé Jèhófà “ń ṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sí ìran ẹgbẹ̀rún.”

4. Báwo ni inú-rere-onífẹ̀ẹ́ ṣe yàtọ̀ sí ìdúróṣinṣin?

4 Ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ Hébérù tá a túmọ̀ sí “inú-rere-onífẹ̀ẹ́” gbòòrò ju ọ̀rọ̀ náà “ìdúróṣinṣin.” Nínú àwọn èdè kan, a sábà máa ń lo ọ̀rọ̀ náà “ìdúróṣinṣin” fún irú ìwà tó yẹ kí ẹni tó jẹ́ ọmọ abẹ́ fi hàn sí ọ̀gá rẹ̀. Àmọ́ olùwádìí kan sọ pé bí Bíbélì ṣe lo inú-rere-onífẹ̀ẹ́ fi hàn pé ó “sábà máa ń tọ́ka sí òdìkejì èyí pátápátá, ìyẹn ni pé alágbára ló ń dúró ṣinṣin ti aláìlágbára tàbí aláìní tàbí ọmọ abẹ́.” Ìyẹn ni Dáfídì Ọba fi lè bẹ Jèhófà pé: “Mú kí ojú rẹ tàn sára ìránṣẹ́ rẹ. Gbà mí là nínú inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́.” (Sáàmù 31:16) Jèhófà, tó jẹ́ alágbára, la bẹ̀ pé kí ó fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́, tàbí ìfẹ́ adúróṣinṣin, hàn sí Dáfídì, tó jẹ́ ẹni rírẹlẹ̀. Níwọ̀n bí ẹni rírẹlẹ̀ kò ti láṣẹ lórí alágbára, inú-rere-onífẹ̀ẹ́ tí alágbára bá fi hàn nínú irú ọ̀ràn bẹ́ẹ̀ jẹ́ àtinúwá, kì í ṣe túláàsì.

5. (a) Kí làwọn àǹfààní tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé ó wà nínú inú-rere-onífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run? (b) Kí ni àwọn nǹkan tá a fẹ́ gbé yẹ̀ wò nípa bí Jèhófà ṣe ń fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ rẹ̀ hàn?

5 Onísáàmù náà béèrè pé: “Ta ni ó gbọ́n? Yóò . . . fi ara rẹ̀ hàn ní olùfiyèsí àwọn ìṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́ ti Jèhófà.” (Sáàmù 107:43) Inú-rere-onífẹ̀ẹ́ Jèhófà lè yọrí sí ìdáǹdè àti ìpamọ́láàyè. (Sáàmù 6:4; 119:88, 159) Ó jẹ́ ààbò àti ìrànlọ́wọ́ pàtàkì tí ń mú ìtura wá nígbà ìṣòro. (Sáàmù 31:16, 21; 40:11; 143:12) Nítorí ànímọ́ yìí, ó ṣeé ṣe láti rí ìràpadà kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀. (Sáàmù 25:7) Bí a bá ṣàyẹ̀wò àwọn ìtàn kan nínú Ìwé Mímọ́, tá a sì yẹ àwọn ẹsẹ Bíbélì kan wò, a óò rí i pé Jèhófà máa ń ṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́ (1) nípa gbígbé àwọn ìgbésẹ̀ kan pàtó àti pé (2) ó máa ń ṣe é fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́.

Ìdáǹdè Jẹ́ Àmì Inú-Rere-Onífẹ̀ẹ́

6, 7. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe gbé inú-rere-onífẹ̀ẹ́ rẹ̀ ga lọ́lá nínú ọ̀ràn Lọ́ọ̀tì? (b) Nígbà wo ni Lọ́ọ̀tì mẹ́nu kan inú-rere-onífẹ̀ẹ́ Jèhófà?

6 Bóyá ọ̀nà tó dára jù lọ láti mọ bí inú-rere-onífẹ̀ẹ́ Jèhófà ti gbòòrò tó ni láti ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ìtàn tó jẹ mọ́ ànímọ́ yìí nínú Ìwé Mímọ́. A kà á nínú Jẹ́nẹ́sísì 14:1-16 pé àwọn ọmọ ogun ọ̀tá mú Lọ́ọ̀tì ọmọ ẹ̀gbọ́n Ábúráhámù lọ. Ṣùgbọ́n Ábúráhámù lọ gba Lọ́ọ̀tì sílẹ̀. Ẹ̀mí Lọ́ọ̀tì tún wà nínú ewu nígbà tí Jèhófà pinnu pé òun máa pa ìlú Sódómù burúkú tí Lọ́ọ̀tì àti ìdílé rẹ̀ ń gbé run.—Jẹ́nẹ́sísì 18:20-22; 19:12, 13.

7 Kété ṣáájú ìparun Sódómù, àwọn áńgẹ́lì Jèhófà sin Lọ́ọ̀tì àti ìdílé rẹ̀ jáde kúrò nílùú yẹn. Ohun tí Lọ́ọ̀tì sọ nígbà yẹn ni pé: “Ìránṣẹ́ rẹ ti rí ojú rere ní ojú rẹ, tó bẹ́ẹ̀ tí ìwọ fi ń gbé inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ ga lọ́lá, èyí tí o ti ṣe sí mi láti pa ọkàn mi mọ́ láàyè.” (Jẹ́nẹ́sísì 19:16, 19) Ọ̀rọ̀ tí Lọ́ọ̀tì sọ yìí fi hàn pé ó mọ̀ pé inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àrà ọ̀tọ̀ ni Jèhófà fi gba ẹ̀mí òun là. Nínú ọ̀ràn yìí, Ọlọ́run fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ rẹ̀ hàn nípa dídá Lọ́ọ̀tì nídè àti nípa dídá ẹ̀mí rẹ̀ sí.—2 Pétérù 2:7.

Inú-Rere-Onífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti Ìtọ́sọ́nà Rẹ̀

8, 9. (a) Iṣẹ́ wo ni Ábúráhámù rán ìránṣẹ́ rẹ̀? (b) Kí nìdí tí ìránṣẹ́ náà fi gbàdúrà fún inú-rere-onífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, kí ló sì ṣẹlẹ̀ bó ṣe ń gbàdúrà lọ́wọ́?

8Jẹ́nẹ́sísì orí 24, a kà nípa àkókò mìíràn tí Ọlọ́run fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́, ìyẹn ìfẹ́ adúróṣinṣin rẹ̀ hàn. Ìtàn náà sọ pé Ábúráhámù sọ fún ìránṣẹ́ rẹ̀ pé kí ó rin ìrìn àjò lọ sí ilẹ̀ àwọn ìbátan Ábúráhámù, kí o lọ wá aya fún Ísákì ọmọ òun níbẹ̀. (Ẹsẹ 2 sí 4) Iṣẹ́ kékeré kọ́ niṣẹ́ yìí o. Àmọ́, ó mú un dá ìránṣẹ́ rẹ̀ lójú pé áńgẹ́lì Jèhófà á sìn ín lọ sìn ín bọ̀. (Ẹsẹ 7) Níkẹyìn, ìránṣẹ́ náà dédìí kànga kan nítòsí “ìlú ńlá ti Náhórì” (bóyá ní Háránì tàbí níbì kan nítòsí ibẹ̀) lákòókò tí àwọn obìnrin máa ń wá fa omi. (Ẹsẹ 10, 11) Nígbà tó rí i pé àwọn obìnrin náà ń sún mọ́ tòsí, ó wá mọ̀ pé iṣẹ́ tí òun wá ṣe ti dójú ẹ̀ gẹ́ẹ́ báyìí. Àmọ́ báwo ló ṣe fẹ́ dá obìnrin tó yẹ kó jẹ́ mọ̀ láàárín wọn?

9 Ìránṣẹ́ Ábúráhámù wá rí i pé iṣẹ́ yìí kọjá agbára òun. Ló bá gbàdúrà sí Ọlọ́run, pé: “Jèhófà Ọlọ́run ọ̀gá mi Ábúráhámù, jọ̀wọ́, mú kí ó ṣẹlẹ̀ níwájú mi ní òní yìí, kí o sì ṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sí ọ̀gá mi Ábúráhámù.” (Ẹsẹ 12) Báwo ni Jèhófà yóò ṣe fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ rẹ̀ hàn? Ìránṣẹ́ yìí béèrè fún àmì kan pàtó tí òun á fi mọ ọ̀dọ́bìnrin náà gan-an tí Ọlọ́run yàn. (Ẹsẹ 13, 14) Obìnrin kan ṣe ohun náà gan-an tí ìránṣẹ́ yìí béèrè lọ́wọ́ Jèhófà. Àní, ńṣe ló dà bíi pé obìnrin náà gbọ́ àdúrà tó gbà! (Ẹsẹ 15 sí 20) Ẹnu ya ìránṣẹ́ náà débi pé ó “tẹjú mọ́ [obìnrin náà] pẹ̀lú kàyéfì.” Ṣùgbọ́n, àwọn kókó pàtàkì kan kò tíì lójú. Ǹjẹ́ ìbátan Ábúráhámù ni obìnrin arẹwà yìí? Ṣé kò tíì lọ́kọ? Ìdí nìyẹn tí ìránṣẹ́ yìí fi wà ní “dídákẹ́jẹ́ẹ́ láti mọ̀ bóyá Jèhófà ti mú kí ìrìnnà àjò òun yọrí sí rere tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́.”—Ẹsẹ 16, 21.

10. Èé ṣe tí ìránṣẹ́ Ábúráhámù fi parí èrò sí pé Jèhófà ti fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ hàn sí ọ̀gá òun?

10 Láìpẹ́ lẹ́yìn ìyẹn ni ọ̀dọ́bìnrin náà sọ pé òun ni “ọmọbìnrin Bẹ́túélì, ọmọkùnrin Mílíkà, tí ó bí fún Náhórì [arákùnrin Ábúráhámù].” (Jẹ́nẹ́sísì 11:26; 24:24) Ojú ẹsẹ̀ ni ìránṣẹ́ yìí mọ̀ pé Jèhófà ti dáhùn àdúrà òun. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí wú u lórí débi pé, ó wólẹ̀, ó sì sọ pé: “Ìbùkún ni fún Jèhófà Ọlọ́run ọ̀gá mi Ábúráhámù, ẹni tí kò fi inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ àti jíjẹ́ aṣeégbẹ́kẹ̀lé rẹ̀ sí ọ̀gá mi sílẹ̀. Bí mo ti wà lójú ọ̀nà, Jèhófà ti ṣamọ̀nà mi sí ilé àwọn arákùnrin ọ̀gá mi.” (Ẹsẹ 27) Nípa títọ́ ìránṣẹ́ yìí sọ́nà, Ọlọ́run fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ hàn sí Ábúráhámù, tí í ṣe ọ̀gá ìránṣẹ́ náà.

Inú-Rere-Onífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run Ń Mú Ìtura àti Ààbò Wá

11, 12. (a) Inú àwọn àdánwò wo ni Jósẹ́fù wà nígbà tó rí inú-rere-onífẹ̀ẹ́ Jèhófà? (b) Báwo ni Ọlọ́run ṣe fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ hàn sí Jósẹ́fù?

11 Wàyí o, ẹ jẹ́ ká gbé Jẹ́nẹ́sísì orí 39 yẹ̀ wò. Ó dá lórí ìtàn Jósẹ́fù àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù, tí wọ́n tà sóko ẹrú Íjíbítì. Síbẹ̀, “Jèhófà wà pẹ̀lú Jósẹ́fù.” (Ẹsẹ 1, 2) Kódà Pọ́tífárì, ará Íjíbítì tí í ṣe ọ̀gá Jósẹ́fù, gbà pé Jèhófà wà pẹ̀lú Jósẹ́fù. (Ẹsẹ 3) Àmọ́, àdánwò ńlá dojú kọ Jósẹ́fù. Wọ́n purọ́ mọ́ ọn pé ó fẹ́ fipá bá aya Pọ́tífárì lò pọ̀, wọ́n sì sọ ọ́ sẹ́wọ̀n. (Ẹsẹ 7 sí 20) “Wọ́n fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ ṣẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀ níṣẹ̀ẹ́, ọkàn rẹ̀ wá sínú àwọn irin” nínú “ihò ẹ̀wọ̀n.”—Jẹ́nẹ́sísì 40:15; Sáàmù 105:18.

12 Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà àdánwò líle koko yẹn? “Jèhófà ń bá a lọ láti wà pẹ̀lú Jósẹ́fù, ó sì ń nawọ́ inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sí i ṣáá.” (Ẹsẹ 21a) Inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àrà ọ̀tọ̀ kan jẹ́ kí àwọn nǹkan bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹnuure fún Jósẹ́fù, tó fi wá bọ́ lọ́wọ́ àwọn ìṣòro tó ń fàyà rán. Jèhófà jẹ́ kí Jósẹ́fù “rí ojú rere ní ojú ọ̀gá àgbà ní ilé ẹ̀wọ̀n.” (Ẹsẹ 21b) Ìyẹn ló jẹ́ kí ọ̀gá náà gbé Jósẹ́fù sí ipò gíga. (Ẹsẹ 22) Ẹ̀yìn ìyẹn ni Jósẹ́fù ṣalábàápàdé ọkùnrin kan tó mú ọ̀ràn rẹ̀ déwájú Fáráò, alákòóso Íjíbítì nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín. (Jẹ́nẹ́sísì 40:1-4, 9-15; 41:9-14) Ọba náà wá sọ Jósẹ́fù di igbákejì alákòóso Íjíbítì, èyí tó jẹ́ kó ní àǹfààní láti gba ẹ̀mí àwọn èèyàn là ní ilẹ̀ Íjíbítì tí ìyàn ti mú. (Jẹ́nẹ́sísì 41:37-55) Ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún ni Jósẹ́fù nígbà tí ìyà yẹn bẹ̀rẹ̀, ó sì lé ní ọdún méjìlá gbáko tí ìyà yẹn fi jẹ ẹ́! (Jẹ́nẹ́sísì 37:2, 4; 41:46) Àmọ́ jálẹ̀ gbogbo ọdún wàhálà àti ìpọ́njú wọ̀nyẹn, Jèhófà Ọlọ́run fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ rẹ̀ hàn sí Jósẹ́fù nípa gbígbà á lọ́wọ́ ìṣòro tó le ju ẹ̀mí rẹ̀ lọ àti nípa dídá a sí kí ó lè kó ipa pàtàkì nínú mímú ète Ọlọ́run ṣẹ.

Inú-Rere-Onífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run Kì Í Kùnà

13. (a) Kí ni Sáàmù 136 sọ nípa bí Jèhófà ṣe fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ hàn? (b) Kí ni inú-rere-onífẹ̀ẹ́ jẹ́ gan-an?

13 Léraléra ni Jèhófà ṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì lápapọ̀. Sáàmù 136 sọ pé nínú inú-rere-onífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ó dá wọn nídè (Ẹsẹ 10 sí 15), ó tọ́ wọn sọ́nà (Ẹsẹ 16), ó sì dáàbò bò wọ́n. (Ẹsẹ 17 sí 20) Ọlọ́run tún ṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sáwọn èèyàn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Ẹni tó ń ṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́ séèyàn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ máa ń fínnúfíndọ̀ ṣe àwọn nǹkan kan tó máa tán àwọn ìṣòro pàtàkì kan. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Bíbélì kan tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ nípa inú-rere-onífẹ̀ẹ́, pé: “Ó jẹ́ ìgbésẹ̀ kan tó ń dá ẹ̀mí sí tàbí tó ń tún ayé àwọn èèyàn ṣe. Ó jẹ́ gbígba ẹnì kan lọ́wọ́ ìyà tàbí wàhálà.” Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan pè é ní “ìfẹ́ tí ń súnni gbégbèésẹ̀.”

14, 15. Báwo ló ṣe dá wa lójú pé ìránṣẹ́ tí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà ni Lọ́ọ̀tì?

14 Àwọn ìtàn tá a ti gbé yẹ̀ wò nínú Jẹ́nẹ́sísì fi hàn pé Jèhófà kì í ṣaláì ṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sí àwọn tó bá nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Lọ́ọ̀tì, Ábúráhámù àti Jósẹ́fù bá ara wọn ní onírúurú ipò, wọ́n sì dojú kọ àwọn àdánwò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ẹ̀dá aláìpé ni wọ́n, àmọ́ Jèhófà tẹ́wọ́ gbà wọ́n gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ rẹ̀, ojú rẹ̀ ni wọ́n sì ń wò. A lè rí ìtùnú nínú mímọ̀ pé Baba wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́ ń fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ hàn sírú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀.

15 Lọ́ọ̀tì ṣe àwọn ìpinnu kan tí kò bọ́gbọ́n mu, tó wá kó o sí yọ́ọ́yọ́ọ́. (Jẹ́nẹ́sísì 13:12, 13; 14:11, 12) Àmọ́, ó tún ní àwọn ànímọ́ rere. Nígbà tí áńgẹ́lì méjì látọ̀dọ̀ Ọlọ́run dé sí Sódómù, Lọ́ọ̀tì ṣaájò wọn. (Jẹ́nẹ́sísì 19:1-3) Ìgbàgbọ́ tó ní ló jẹ́ kó kìlọ̀ fáwọn ọkọ ọmọ rẹ̀ nípa ìparun tó rọ̀ dẹ̀dẹ̀ sórí Sódómù. (Jẹ́nẹ́sísì 19:14) A ó mọ irú ojú tí Ọlọ́run fi wo Lọ́ọ̀tì tá a bá ka 2 Pétérù 2:7-9, tó sọ pé: “[Jèhófà] dá Lọ́ọ̀tì olódodo nídè, ẹni tí ìkẹ́ra-ẹni-bàjẹ́ nínú ìwà àìníjàánu àwọn aṣàyàgbàǹgbà pe òfin níjà kó wàhálà-ọkàn bá gidigidi—nítorí ohun tí ọkùnrin olódodo yẹn rí, tí ó sì gbọ́ nígbà tí ó ń gbé láàárín wọn láti ọjọ́ dé ọjọ́ ń mú ọkàn òdodo rẹ̀ joró nítorí àwọn ìṣe àìlófin wọn—Jèhófà mọ bí a ti ń dá àwọn ènìyàn tí ń fọkàn sin Ọlọ́run nídè kúrò nínú àdánwò.” Dájúdájú, olódodo ni Lọ́ọ̀tì. Ibi tá a kà yìí sì fi hàn pé olùfọkànsìn Ọlọ́run ni. Bíi tirẹ̀, àwa náà ń gbádùn inú-rere-onífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run bá a ṣe ń ṣe àwọn iṣẹ́ tó jẹ́ ti “ìwà mímọ́ àti àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run.”—2 Pétérù 3:11, 12.

16. Kí ni àwọn ọ̀rọ̀ rere tí Bíbélì sọ nípa Ábúráhámù àti Jósẹ́fù?

16 Ìtàn tó wà nínú Jẹ́nẹ́sísì orí 24 fi hàn kedere pé Ábúráhámù ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà. Ẹsẹ kìíní sọ pé ‘Jèhófà ti bù kún Ábúráhámù nínú ohun gbogbo.’ Ìránṣẹ́ Ábúráhámù pe Jèhófà ní “Ọlọ́run ọ̀gá mi Ábúráhámù.” (Ẹsẹ 12, 27) Ọmọ ẹ̀yìn nì, Jákọ́bù, sì sọ pé a ‘polongo Ábúráhámù ní olódodo,’ ó sì “di ẹni tí a ń pè ní ‘ọ̀rẹ́ Jèhófà.’” (Jákọ́bù 2:21-23) Bẹ́ẹ̀ náà ni Jósẹ́fù. Jẹ́nẹ́sísì orí 39 látòkèdélẹ̀ fi hàn pé àjọṣe tímọ́tímọ́ wà láàárín Jèhófà àti Jósẹ́fù. (Ẹsẹ 2, 3, 21, 23) Kò tán síbẹ̀ o, ọmọ ẹ̀yìn nì, Sítéfánù, sọ nípa Jósẹ́fù pé: “Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀.”—Ìṣe 7:9.

17. Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ Lọ́ọ̀tì, Ábúráhámù àti Jósẹ́fù?

17 Àwọn èèyàn tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ̀rọ̀ wọn tán yìí, tí wọ́n rí inú-rere-onífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, jẹ́ àwọn èèyàn tó ní àjọṣe rere pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run, tí wọ́n sì ṣe ìfẹ́ rẹ̀ ní onírúurú ọ̀nà. Wọ́n dojú kọ òkè ìṣòro tí àwọn nìkan kò lè dá borí. Ẹ̀mí Lọ́ọ̀tì wà nínú ewu. Ní ti Ábúráhámù, ìlà ìdílé rẹ̀ lè kú àkúrun. Bí Jósẹ́fù kò bá sì bọ́ nínú ìṣòro tó wà, kò ní lè kó ipa tó yẹ kí ó kó. Jèhófà nìkan ló lè kó àwọn ọkùnrin olùfọkànsìn wọ̀nyí yọ nínú ewu. Ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ nípa ṣíṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sí wọn. Bí a óò bá rí inú-rere-onífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run títí láé, àwa náà gbọ́dọ̀ ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀, ká sì máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀ nìṣó.—Ẹ́sírà 7:28; Sáàmù 18:50.

Àwọn Ìránṣẹ́ Ọlọ́run Wà ní Ipò Ojú Rere

18. Kí làwọn ẹsẹ Bíbélì kan sọ nípa inú-rere-onífẹ̀ẹ́ Jèhófà?

18 Inú-rere-onífẹ̀ẹ́ Jèhófà “ti kún ilẹ̀ ayé,” ẹ sì wo bá a ṣe mọyì ànímọ́ Ọlọ́run yìí tó! (Sáàmù 119:64) Tọkàntọkàn làwa náà fi bá onísáàmù náà gberin, pé: “Kí àwọn ènìyàn máa fi ọpẹ́ fún Jèhófà nítorí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ àti nítorí àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀ fún àwọn ọmọ ènìyàn.” (Sáàmù 107:8, 15, 21, 31) Inú wa dùn pé Jèhófà ń ṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó tẹ́wọ́ gbà—ì báà jẹ́ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan tàbí lápapọ̀. Nígbà tí Dáníẹ́lì ń gbàdúrà, ó pe Jèhófà ní “Ọlọ́run tòótọ́, Ẹni ńlá, Ẹni tí ń múni kún fún ẹ̀rù, tí ń pa májẹ̀mú àti inú-rere-onífẹ̀ẹ́ mọ́ sí àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, tí ó sì ń pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.” (Dáníẹ́lì 9:4) Dáfídì Ọba gbàdúrà pé: “Máa bá inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ nìṣó fún àwọn tí ó mọ̀ ọ́.” (Sáàmù 36:10) A mà dúpẹ́ o, pé Jèhófà ń ṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀!—1 Àwọn Ọba 8:23; 1 Kíróníkà 17:13.

19. Àwọn ìbéèrè wo la óò gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e?

19 Àwa tá a jẹ́ èèyàn Jèhófà, tiwa ti dáa! Yàtọ̀ sí pé à ń jàǹfààní ìfẹ́ tí Ọlọ́run fi hàn sáráyé lápapọ̀, a tún ń gbádùn àwọn ìbùkún àrà ọ̀tọ̀ látinú inú-rere-onífẹ̀ẹ́ Baba wa ọ̀run. (Jòhánù 3:16) A máa ń jàǹfààní ànímọ́ àtàtà ti Jèhófà yìí, àgàgà nígbà ìṣòro. (Sáàmù 36:7) Àmọ́ báwo la ṣe lè fara wé inú-rere-onífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run? Ǹjẹ́ àwa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ń fi ànímọ́ àtàtà yìí hàn? Ìbéèrè wọ̀nyí àtàwọn mìíràn tó tan mọ́ ọn la óò gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e.

Ǹjẹ́ O Rántí?

• Ọ̀rọ̀ mìíràn wo ni Ìwé Mímọ́ lò fún “inú-rere-onífẹ̀ẹ́”?

• Báwo ni inú-rere-onífẹ̀ẹ́ ṣe yàtọ̀ sí ìfẹ́ àti ìdúróṣinṣin?

• Ní àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ hàn sí Lọ́ọ̀tì, Ábúráhámù àti Jósẹ́fù?

• Ìdánilójú wo la ní nítorí ọ̀nà tí Jèhófà gbà fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ hàn sáwọn èèyàn láyé àtijọ́?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Ǹjẹ́ o mọ bí Ọlọ́run ṣe fi inú-rere- onífẹ̀ẹ́ hàn sí Lọ́ọ̀tì?

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Jèhófà fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tọ́ ìránṣẹ́ Ábúráhámù sọ́nà

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Jèhófà fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ rẹ̀ hàn nípa dídáàbò bo Jósẹ́fù