Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kàyéfì Gbáà Lọ̀rọ̀ Tertullian

Kàyéfì Gbáà Lọ̀rọ̀ Tertullian

Kàyéfì Gbáà Lọ̀rọ̀ Tertullian

‘KÍ LÓ fẹ́ pa Kristẹni àti onímọ̀ ọgbọ́n orí pọ̀? kí ló fẹ́ pa ẹni tó ń ba òtítọ́ jẹ́ àti ẹni tó ń gbé òtítọ́ lárugẹ, tó sì ń fi kọ́ni pọ̀? Àjọṣe wo ló wà láàárín Ẹ̀kọ́ Plato àti Ṣọ́ọ̀ṣì?’ Tertullian, tí í ṣe òǹkọ̀wé tó gbé ayé ní ọ̀rúndún kejì àti ìkẹta Sànmánì Tiwa ló béèrè àwọn ìbéèrè gbankọgbì yẹn. Wọ́n sọ pé “ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó mọwá-mẹ̀yìn gbogbo ìtàn Ṣọ́ọ̀ṣì àtàwọn ẹ̀kọ́ tí wọ́n ń kọ́ni nígbà ayé rẹ̀.” Ṣàṣà ni nǹkan tí kò mọ̀ nípa ọ̀ràn ẹ̀sìn.

Àmọ́ ohun tó jẹ́ kí òkìkí Tertullian kàn tó bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọ̀rọ̀ kàyéfì, tàbí ọ̀rọ̀ àsé, tó máa ń sọ lẹ́nu, bíi: “Àní Ọlọ́run tóbi lọ́ba sẹ́, ìyẹn nígbà tí Ó kéré.” “Dandan ni ká gba [ikú Ọmọ Ọlọ́run] gbọ́, nígbà tí kò kúkú bọ́gbọ́n mu.” “Wọ́n sin [Jésù], ó sì jíǹde; kò sírọ́ ńbẹ̀, torí pé kò ṣeé ṣe.”

Kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹnu Tertullian nìkan ló jẹ́ kàyéfì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó sọ pé òun ń fi àwọn ìwé òun gbèjà òtítọ́, tí òun sì ń fi wọ́n fẹsẹ̀ ṣọ́ọ̀ṣì àtàwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ múlẹ̀, ńṣe ló ń ba àwọn ẹ̀kọ́ tòótọ́ jẹ́ ní ti gidi. Lájorí ẹ̀kọ́ tó gbé kalẹ̀ fún àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ló wá di àbá tí àwọn òǹkọ̀wé ẹ̀yìn ìgbà náà gbé ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan kà. Láti mọ bí èyí ṣe ṣẹlẹ̀, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ wo irú èèyàn tí Tertullian alára jẹ́.

“Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ Ò Lè Sú Èèyàn Láé”

Ìwọ̀nba ni ìsọfúnni tó wà nípa ìgbésí ayé Tertullian. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ fohùn ṣọ̀kan pé nǹkan bí ọdún 160 Sànmánì Tiwa ni wọ́n bí i nílùú Carthage, ní Àríwá Áfíríkà. Ó dájú pé ọ̀mọ̀wé hán-únhán-ún ni. Ó mọ àwọn ẹ̀kọ́ ọgbọ́n orí tó wọ́pọ̀ nígbà ayé rẹ̀ ní àmọ̀dunjú. Ó jọ pé ohun tó wù ú nínú ẹ̀sìn Kristẹni ni bí àwọn tí wọ́n ń pè ní Kristẹni láyé ìgbà yẹn ṣe múra tán láti kú nítorí ẹ̀sìn wọn. Ìbéèrè tó gbé dìde nípa jíjẹ́ Kristẹni ajẹ́rìíkú ni pé: “Ta ni onítọ̀hún tó ń ronú nípa dídi ajẹ́rìíkú tí kò ní kọ́kọ́ wádìí ohun tó ń súnni di ajẹ́rìíkú? ta sì ni kò ní tẹ́wọ́ gba ẹ̀kọ́ wa lẹ́yìn ṣíṣèwádìí?”

Lẹ́yìn tí Tertullian di Kristẹni aláfẹnujẹ́ ló wá di akọ̀wé-kọwúrà tó ń fọ̀rọ̀ dárà. Ìwé náà, The Fathers of the Church, sọ pé: “Irú tirẹ̀ ṣọ̀wọ́n lágbo àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ò lè sú èèyàn láé.” Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan sọ pé: “Tertullian lẹ́bùn ìlò ọ̀rọ̀ lẹ́yọlẹ́yọ, yàtọ̀ sí ìlò gbólóhùn. Ó rọrùn láti lóye àwọn àṣàyàn ọ̀rọ̀ tó sọ ju láti lóye àlàyé rẹ̀ látòkèdélẹ̀. Bóyá ìdí nìyẹn tí àwọn tó máa ń fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ kì í sábà fa apá tó pọ̀ yọ nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀.”

Ó Gbèjà Ẹ̀sìn Kristẹni

Ìwé Tertullian tó gbajúmọ̀ jù lọ ni Apology, táwọn èèyàn sọ pé ó jẹ́ ọ̀kan lára ìwé tí kò lẹ́gbẹ́ nínú gbígbèjà ẹ̀sìn Kristẹni aláfẹnujẹ́. Ó kọ ọ́ lákòókò tí àwọn jàǹdùkú tó gba ohun asán gbọ́ máa ń han àwọn Kristẹni léèmọ̀. Tertullian gbèjà àwọn Kristẹni wọ̀nyí, ó sì ní kí wọ́n ṣíwọ́ fífojú wọn gbolẹ̀. Ó sọ pé: “[Àwọn alátakò] ń sọ pé àwọn Kristẹni ló ń fa gbogbo wàhálà tó bá ìlú àti gbogbo àgbákò tó bá àwọn èèyàn. . . . Bí Odò Náílì kò bá ṣàn yí ká bèbè rẹ̀ láti bomi rin oko wọn, bí ojú ọjọ́ kò bá yí padà, bí ilẹ̀ bá sẹ̀, bí ìyàn bá mú, tàbí bí àjàkálẹ̀ àrùn bá jà—kíá ni wọ́n á figbe ta pé: ‘Ẹ sọ àwọn Kristẹni sẹ́nu kìnnìún!’”

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n máa ń sọ pé ọlọ̀tẹ̀ làwọn Kristẹni jẹ́ sí Ìjọba, Tertullian fi yé wọn pé àwọn Kristẹni gan-an ló ṣeé fọkàn tán jù lọ lórílẹ̀-èdè. Lẹ́yìn tó mẹ́nu kan ìgbà mélòó kan táwọn èèyàn fẹ́ fipá gbàjọba, ó rán àwọn alátakò létí pé àwọn kèfèrí ló dìtẹ̀, kì í ṣe àwọn Kristẹni. Tertullian sọ pé Ìjọba gan-an ló ń pàdánù nígbà tí wọ́n bá pa àwọn Kristẹni.

Àwọn ìwé mìíràn tí Tertullian kọ dá lórí ìgbésí ayé Kristẹni. Bí àpẹẹrẹ, nínú ìwé rẹ̀ On the Shows, Tertullian sọ pé kò dáa láti wà níbi àwọn eré ìnàjú kan, níbi àwọn eré abọ̀rìṣà àti níbi àwọn eré kan ní gbọ̀ngàn ìwòran. Ó jọ pé àwọn kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di onígbàgbọ́ kò rí ohun tó burú nínú pípàdé pọ̀ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, lẹ́sẹ̀ kan náà kí wọ́n tún máa lọ wo àwọn eré abọ̀rìṣà. Láti mú wọn ronú jinlẹ̀, Tertullian kọ̀wé pé: “Ẹ ò rí i pé kò bọ́ sí i rárá kéèyàn kúrò nínú ilé Ọlọ́run, kó wá kọrí sí ilé Èṣù—kéèyàn ti ibi dáradára lọ sí ibi rádaràda.” Ó sọ pé: “Ohun téèyàn kì í báá jẹ, kò yẹ kó máa fi runmú wò.”

Ó Sọ Òtítọ́ Dìdàkudà Níbi Tó Ti Ń Gbèjà Rẹ̀

Ọ̀rọ̀ tí Tertullian fi bẹ̀rẹ̀ àròkọ tó pe àkọlé rẹ̀ ní Against Praxeas, ni pé: “Onírúurú ọ̀nà ni èṣù ń gbà tako òtítọ́, tó sì fẹ́ fi bò ó mọ́lẹ̀. Nígbà mìíràn, ohun tó fẹ́ ṣe ni pé kí ó tẹ òtítọ́ rì nípa sísọ pé òun ń gbèjà rẹ̀.” Ó ṣòro láti mọ ọkùnrin náà pàtó tó ń jẹ́ Praxeas tó kọ̀wé nípa rẹ̀, ṣùgbọ́n Tertullian tako àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ nípa Ọlọ́run àti Kristi. Ó ka Praxeas sí ọmọ Sátánì tó fẹ́ dọ́gbọ́n sọ ẹ̀sìn Kristẹni dìdàkudà.

Àríyànjiyàn ńlá tó ń lọ lọ́wọ́ láàárín àwọn tó pera wọn ní Kristẹni nígbà yẹn ni bí Kristi ṣe jẹ́ sí Ọlọ́run. Ó ṣòro fún àwọn kan lára wọn, àgàgà àwọn Gíríìkì, láti gbà pé Ọlọ́run kan ṣoṣo ló wà, nítorí ipa tí Jésù kó gẹ́gẹ́ bí Olùgbàlà àti Olùràpadà. Praxeas gbìyànjú láti yanjú ìṣòro yìí nípa kíkọ́ni pé Baba kan náà yẹn ló fara hàn ní àwọ̀ Jésù. Ó ní kò sí ìyàtọ̀ láàárín Baba àti Ọmọ. Àbá yìí, tí wọ́n wá ń pè ní Ọlọ́run a-gbé-àwọ̀-mẹ́ta-wọ̀, ṣàlàyé pé Ọlọ́run fara hàn “bí Baba nígbà Ìṣẹ̀dá àti nígbà tó gbé Òfin Mósè kalẹ̀, ó fara hàn bí Ọmọ nínú Jésù Kristi, ó sì fara hàn bí Ẹ̀mí Mímọ́ lẹ́yìn ìgòkè re ọ̀run Kristi.”

Tertullian fi hàn pé Ìwé Mímọ́ sọ ní kedere-kèdèrè pé ìyàtọ̀ wà láàárín Baba àti Ọmọ. Lẹ́yìn tó fa ọ̀rọ̀ inú 1 Kọ́ríńtì 15:27, 28 yọ, ó wá sọ pé: “Ẹni tó fi (ohun gbogbo) sábẹ́ ẹni, àti abẹ́ Ẹni tá a fi ohun gbogbo sí—gbọ́dọ̀ jẹ́ Ẹni méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.” Tertullian wá tọ́ka sí ohun tí Jésù fẹnu ara rẹ̀ sọ, pé: “Baba tóbi jù mí lọ.” (Jòhánù 14:28) Ó tọ́ka sí àwọn ibì kan nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, bíi Sáàmù 8:5, láti fi hàn pé Bíbélì pe Ọmọ ní “ẹni rírẹlẹ̀.” Tertullian wá sọ pé: “Èyí fi hàn pé Baba yàtọ̀ sí Ọmọ, pé ó tóbi ju Ọmọ lọ. Níwọ̀n bí Ẹni tó bíni ti jẹ́ ẹni ọ̀tọ̀, tí Ẹni tá a bí sì jẹ́ ẹni ọ̀tọ̀; bẹ́ẹ̀ náà ló jẹ́ pé Ẹni tó ránni jẹ́ ẹni ọ̀tọ̀, tí Ẹni tá a rán sì jẹ́ ẹni ọ̀tọ̀; bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Ẹni tó ṣẹ̀dá àwọn nǹkan jẹ́ ẹni ọ̀tọ̀, Ẹni tá a sì tipasẹ̀ rẹ̀ ṣẹ̀dá àwọn nǹkan náà jẹ́ ẹni ọ̀tọ̀.”

Tertullian ka Ọmọ sí ẹni rírẹlẹ̀ sí Bàbá. Àmọ́ níbi tó ti ń gbéjà ko ẹ̀kọ́ Ọlọ́run a-gbé-àwọ̀-mẹ́ta-wọ̀, Tertullian wá bọ̀ràn jẹ́, ó lọ “ré kọjá àwọn ohun tí a ti kọ̀wé rẹ̀.” (1 Kọ́ríńtì 4:6) Níbi tí Tertullian ti ń fi àṣìṣe gbé àbá mìíràn kalẹ̀ láti fi hàn pé Jésù jẹ́ ẹni ti ọ̀run, ló wá gbé èròǹgbà tuntun kan jáde tó pè ní “ẹni mẹ́ta nínú ọ̀kan.” Ó fẹ́ tipasẹ̀ èròǹgbà yìí fi hàn pé Ọlọ́run, Ọmọ rẹ̀, àti ẹ̀mí mímọ́ jẹ́ ẹni mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó para pọ̀ jẹ́ ara kan. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé Tertullian lẹni àkọ́kọ́ tó lo ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń lò lédè Látìn fún “mẹ́talọ́kan” fún Baba, Ọmọ àti ẹ̀mí mímọ́.

Ṣọ́ra fún Ìmọ̀ Ọgbọ́n Orí ti Ayé Yìí

Báwo ni Tertullian ṣe gbé àbá èrò orí “ẹni mẹ́ta nínú ọ̀kan” kalẹ̀? A lè rí ìdáhùn sí èyí nínú ohun mìíràn tí ń ṣeni ní kàyéfì nípa ọkùnrin yìí—èyíinì ni ojú tó fi ń wo ìmọ̀ ọgbọ́n orí. Tertullian pe ìmọ̀ ọgbọ́n orí ní “‘ẹ̀kọ́’ àwọn èèyàn àti ‘ti àwọn ẹ̀mí èṣù.’” Ó là á mọ́lẹ̀ pé òun lòdì sí fífi ìmọ̀ ọgbọ́n orí ṣe ìtìlẹyìn fún àwọn òtítọ́ Kristẹni. Ó sọ pé: “Ẹ jẹ́ ká yàgò fún gbogbo àṣà dída ẹ̀sìn Kristẹni pọ̀ mọ́ ẹ̀kọ́ Sítọ́ìkì àti ti Plato àti ti ọgbọ́n orí.” Ṣùgbọ́n Tertullian alára lo ọ̀pọ̀ ìmọ̀ ọgbọ́n orí ti ayé nígbà tó bá bá èrò tirẹ̀ mu.—Kólósè 2:8.

Ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ pé: “Àwọn èròǹgbà àti ẹ̀kọ́ àwọn Hélénì ló jẹ́ igi lẹ́yìn ọgbà fún ẹ̀kọ́ mẹ́talọ́kan.” Ìwé náà, The Theology of Tertullian, sì sọ pé: “Èròǹgbà tó jẹ mọ́ òfin àti ìmọ̀ ọgbọ́n orí ni Tertullian dọ́gbọ́n yí mọ́ra, tó fi gbé ẹ̀kọ́ mẹ́talọ́kan kalẹ̀ nígbà yẹn, tó fi wá di pé bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò tíì lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ dáadáa, síbẹ̀ àbá tó gbé kalẹ̀ yìí ló wá di ìpìlẹ̀ tí Ìgbìmọ̀ Nicaea gbé ẹ̀kọ́ yẹn kà lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.” Nítorí náà, àbá Tertullian—ìyẹn ọlọ́run mẹ́ta nínú ara kan—kó ipa pàtàkì nínú títan ìgbàgbọ́ èké ká gbogbo àwọn ṣọ́ọ̀ṣì.

Tertullian fẹ̀sùn kan àwọn ẹlòmíràn pé wọ́n ń tẹ òtítọ́ rì nígbà tí wọ́n sọ pé àwọn ń gbèjà rẹ̀. Àmọ́, ṣebí ohun tó fẹ̀sùn kan àwọn ẹlòmíràn pé wọ́n ń ṣe lòun náà ṣe, nígbà tó da ìmọ̀ ọgbọ́n orí pọ̀ mọ́ òtítọ́ Bíbélì tí Ọlọ́run mí sí. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká fi ìkìlọ̀ Ìwé Mímọ́ sọ́kàn pé ká yẹra fún “fífi àfiyèsí sí àwọn àsọjáde onímìísí tí ń ṣini lọ́nà àti àwọn ẹ̀kọ́ ẹ̀mí èṣù.”—1 Tímótì 4:1.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29, 30]

Tertullian bẹnu àtẹ́ lu ìmọ̀ ọgbọ́n orí, ṣùgbọ́n ó fi gbé àwọn èròǹgbà tirẹ̀ lárugẹ

[Credit Line]

Ojú ìwé 29 àti 30: © Cliché Bibliothèque nationale de France, Paris

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Àwọn Kristẹni tòótọ́ máa ń yàgò fún dída ìmọ̀ ọgbọ́n orí pọ̀ mọ́ òtítọ́ Bíbélì