Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Mọyì Ìfẹ́ Ọlọ́run?

Ǹjẹ́ O Mọyì Ìfẹ́ Ọlọ́run?

Ǹjẹ́ O Mọyì Ìfẹ́ Ọlọ́run?

NÍGBÀ kan rí, ọkùnrin náà Jóòbù ṣàpèjúwe ipò ẹ̀dá ènìyàn báyìí, ó ní: “Ènìyàn, tí obìnrin bí, ọlọ́jọ́ kúkúrú ni, ó sì kún fún ṣìbáṣìbo. Ó jáde wá bí ìtànná, a sì ké e kúrò, ó sì fẹsẹ̀ fẹ bí òjìji, kò sì sí mọ́.” (Jóòbù 14:1, 2) Ìgbésí ayé Jóòbù nígbà yẹn kún fún làásìgbò àti ìbànújẹ́. Ǹjẹ́ o ti ní irú ìrírí yẹn rí?

Àmọ́ o, láìfi gbogbo ìnira àti ìṣòro tá a lè dojú kọ pè, ìrètí tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ wà, èyí tá a gbé karí ìfẹ́ àti ìyọ́nú Ọlọ́run. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, Baba wa ọ̀run aláàánú ti pèsè ẹbọ ìràpadà láti fi ra aráyé padà kúrò nínú ipò àìpé àti ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n wà. Gẹ́gẹ́ bí Jòhánù 3:16, 17 ti wí, Jésù Kristi sọ pé: “Nítorí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé [aráyé] tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun. Nítorí Ọlọ́run rán Ọmọ rẹ̀ [Jésù] jáde sí ayé, kì í ṣe kí ó lè ṣèdájọ́ ayé, bí kò ṣe kí a lè gba ayé là nípasẹ̀ rẹ̀.”

Tún ronú nípa ojú àánú Ọlọ́run sí àwa ẹ̀dá aláìpé. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kéde pé: “Láti ara ọkùnrin kan ni ó sì ti dá gbogbo orílẹ̀-èdè àwọn ènìyàn, láti máa gbé ní ojú gbogbo ilẹ̀ ayé pátá, ó sì gbé àṣẹ kalẹ̀ nípa àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀ àti àwọn ààlà ibùgbé tí a gbé kalẹ̀ fún àwọn ènìyàn, fún wọn láti máa wá Ọlọ́run, bí wọ́n bá lè táràrà fún un, kí wọ́n sì rí i ní ti gidi, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ní ti tòótọ́, kò jìnnà sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa.” (Ìṣe 17:26, 27) Àbí ẹ ò rí nǹkan! Bí a tilẹ̀ jẹ́ ẹ̀dá aláìpé, a ṣì lè gbádùn àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run, Ẹlẹ́dàá wa onífẹ̀ẹ́.

Nítorí náà, a ò mikàn nípa ọjọ́ ọ̀la, nítorí a mọ̀ pé Ọlọ́run bìkítà nípa wa, ó sì ti fi tìfẹ́tìfẹ́ ṣe ètò tó máa wà fún ire wa ayérayé. (1 Pétérù 5:7; 2 Pétérù 3:13) Nítorí náà, ó dájú pé ó yẹ ká túbọ̀ mọ̀ nípa Ọlọ́run wa onífẹ̀ẹ́ nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ.