Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ta Ni Ọlọ́run?

Ta Ni Ọlọ́run?

Ta Ni Ọlọ́run?

IWÉ gbédègbẹ́yọ̀ The Encyclopedia Americana sọ pé: “Ọlọ́run ni orúkọ tá a máa ń pe orísun àti agbára tó ga jù lọ láyé àtọ̀run, òun sì ni àwọn ẹ̀dá máa ń sìn.” Ọ̀rọ̀ náà “Ọlọ́run” túmọ̀ sí ẹni gíga jù lọ. Báwo ni ẹni àgbàyanu yẹn ṣe rí gan-an?

Ṣé agbára kan lásán tí kò sí níbì kankan ni Ọlọ́run tàbí ẹni gidi kan? Ǹjẹ́ ó ní orúkọ? Ṣé Mẹ́talọ́kan ni, bí àwọn kan ṣe rò? Báwo la ṣe lè mọ Ọlọ́run? Bíbélì fúnni ní ìdáhùn tó jẹ́ òótọ́, tó sì tẹ́ni lọ́rùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí. Àní, ó gbà wá níyànjú láti wá Ọlọ́run, ó ní: “Kò jìnnà sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa.”—Ìṣe 17:27.

Ṣé Agbára Kan Lásán Ni Tàbí Ẹni Gidi?

Ọ̀pọ̀ tó gba Ọlọ́run gbọ́ ló rò pé agbára kan ni, pé kì í ṣe ẹnì kan. Bí àpẹẹrẹ, láwọn àdúgbò kan, wọ́n gbà pé àwọn ọlọ́run ló máa ń wà nídìí àwọn ipá àdáyébá. Àwọn kan tó ti ṣàyẹ̀wò àwọn ẹ̀rí tí wọ́n kó jọ látinú ìwádìí táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣe lórí bí àgbáyé ṣe rí àti bí ìwàláàyè lórí ilẹ̀ ayé ṣe rí gan-an ti parí èrò sí pé Orísun kan gbọ́dọ̀ wà. Síbẹ̀síbẹ̀, wọn ò gbà pé ẹni gidi kan ni Orísun yìí.

Àmọ́, ǹjẹ́ àwọn ohun àwámárìídìí inú ìṣẹ̀dá kò fi hàn pé Orísun náà gbọ́dọ̀ ní làákàyè tó ga? Làákàyè ò lè wà láìsí èrò inú. Ẹni tó ní èrò inú gíga tó mú kí gbogbo ìṣẹ̀dá wà ni Ọlọ́run. Bẹ́ẹ̀ ni o, Ọlọ́run ní ara, àmọ́ kì í ṣe èyí tó ṣeé fojú rí bíi tiwa, ara ẹ̀mí ni. Bíbélì sọ pé: “Bí ara ìyára bá wà, èyí ti ẹ̀mí wà pẹ̀lú.” (1 Kọ́ríńtì 15:44) Nígbà tí Bíbélì ń ṣàlàyé bí Ọlọ́run ṣe jẹ́, ó sọ ọ́ ní kedere pé: “Ọlọ́run jẹ́ Ẹ̀mí.” (Jòhánù 4:24) Irú ìwàláàyè tí àwọn ẹni ti ẹ̀mí ní yàtọ̀ sí tiwa pátápátá, ojú ènìyàn kò sì lè rí i. (Jòhánù 1:18) Àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí tí kò ṣeé fojú rí wà pẹ̀lú. Áńgẹ́lì ni wọ́n—“àwọn ọmọ Ọlọ́run tòótọ́.”—Jóòbù 1:6; 2:1.

Níwọ̀n bí Ọlọ́run ti jẹ́ ẹni tí a kò dá, tó ní ara ti ẹ̀mí, ó ní láti ní ibi tó ń gbé. Nígbà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa ibùgbé àwọn ẹni ẹ̀mí, ó sọ fún wa pé ọ̀run ni ‘ibi tí Ọlọ́run ń gbé.’ (1 Àwọn Ọba 8:43) Bákan náà ni Pọ́ọ̀lù tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kọ Bíbélì sọ pé: ‘Kristi wọlé sí ọ̀run láti fara hàn níwájú Ọlọ́run fún wa.’—Hébérù 9:24.

A tún lo ọ̀rọ̀ náà “ẹ̀mí” lọ́nà mìíràn nínú Bíbélì. Nígbà tí onísáàmù ń gbàdúrà sí Ọlọ́run, ó sọ pé: “Bí ìwọ bá rán ẹ̀mí rẹ jáde, a óò dá wọn.” (Sáàmù 104:30) Ẹ̀mí yìí kì í ṣe Ọlọ́run fúnra rẹ̀, àmọ́ ó jẹ́ ipá kan tí Ọlọ́run ń rán jáde, tàbí tí ó ń lò láti ṣe ohunkóhun tó bá wù ú. Nípasẹ̀ rẹ̀ ni Ọlọ́run dá àwọn nǹkan tí ń bẹ lójú ọ̀run, ayé àti gbogbo ohun alààyè. (Jẹ́nẹ́sísì 1:2; Sáàmù 33:6) Ẹ̀mí rẹ̀ ni à ń pè ní ẹ̀mí mímọ́. Ọlọ́run lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ láti mí sí àwọn tó kọ Bíbélì. (2 Pétérù 1:20, 21) Nítorí náà, ẹ̀mí mímọ́ ni ipá ìṣiṣẹ́ tí a kò lè fojú rí, èyí tí Ọlọ́run ń lò láti mú àwọn ète rẹ̀ ṣẹ.

Ọlọ́run ní Orúkọ Aláìlẹ́gbẹ́ Kan

Ágúrì, tó jẹ́ òǹkọ̀wé Bíbélì béèrè pé: “Ta ni ó kó ẹ̀fúùfù jọ sínú ìtẹkòtò ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì? Ta ni ó pọ́n omi sínú aṣọ àlàbora? Ta ni ó mú kí gbogbo òpin ilẹ̀ ayé dìde? Kí ni orúkọ rẹ̀, kí sì ni orúkọ ọmọ rẹ̀?” (Òwe 30:4) Lẹ́nu kan, ohun tí Ágúrì ń béèrè ni pé, ‘Ǹjẹ́ o mọ orúkọ tàbí ìlà ìdílé ẹni tó ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí?’ Ọlọ́run nìkan ló ní agbára láti darí àwọn ipá àdáyébá. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìṣẹ̀dá fún wa ní ẹ̀rí tí kò ṣeé já ní koro pé Ọlọ́run wà, kò sọ ohunkóhun fún wa nípa orúkọ Ọlọ́run. Ká sọ tòótọ́, kò sí bá a ṣe lè mọ orúkọ Ọlọ́run láìjẹ́ pé òun fúnra rẹ̀ sọ ọ́ fún wa. Ó sì ti ṣe bẹ́ẹ̀. Ẹlẹ́dàá náà sọ pé: “Èmi ni Jèhófà, èyí ni orúkọ mi.”—Aísáyà 42:8.

Jèhófà, orúkọ aláìlẹ́gbẹ́ tí Ọlọ́run ń jẹ́ yìí, fara hàn ní ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún méje [7,000] ìgbà nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù nìkan. Jésù Kristi sọ orúkọ yẹn di mímọ̀ fún àwọn ẹlòmíràn, ó sì yìn ín lógo níṣojú wọn. (Jòhánù 17:6, 26) Orúkọ yẹn wà nínú ìwé tó kẹ́yìn nínú Bíbélì, ó jẹ́ ara gbólóhùn náà “Halelúyà,” tó túmọ̀ sí “ẹ yin Jáà.” “Jáà” sì jẹ́ ìkékúrú “Jèhófà.” (Ìṣípayá 19:1-6, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW) Àmọ́, ọ̀pọ̀ àwọn Bíbélì òde òní ni kò lo orúkọ yẹn mọ́. Wọ́n sábà máa ń lo ọ̀rọ̀ náà “OLÚWA” tàbí “ỌLỌ́RUN,” tí wọ́n fi lẹ́tà ńlá kọ láti fìyàtọ̀ sáàárín òun àtàwọn orúkọ òye bíi “Olúwa” àti “Ọlọ́run.” Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan dámọ̀ràn pé ó lè jẹ́ pé Yáwè ni ọ̀nà tí wọ́n gbà ń pe orúkọ Ọlọ́run.

Èé ṣe táwọn èèyàn fi ní èrò tó yàtọ̀ síra bẹ́ẹ̀ nípa orúkọ Ẹni tó ga jù lọ láyé òun ọ̀run? Ọ̀rúndún mélòó kan sẹ́yìn ni ìṣòro náà bẹ̀rẹ̀ nígbà táwọn Júù tìtorí ìgbàgbọ́ nínú ohun asán ṣíwọ́ pípe orúkọ Ọlọ́run, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi ọ̀rọ̀ Hébérù fún “Olúwa Ọba Aláṣẹ” rọ́pò rẹ̀ nígbàkigbà tí wọ́n bá ti bá a pàdé bí wọ́n ṣe ń ka Ìwé Mímọ́. Nítorí pé wọ́n kì í kọ fáwẹ́ẹ̀lì sílẹ̀ nínú èdè Hébérù tí wọ́n fi kọ Bíbélì, kò sí bá a ṣe lè mọ bí Mósè, Dáfídì àtàwọn ará ìgbàanì mìíràn ṣe pe àwọn lẹ́tà tó para pọ̀ jẹ́ orúkọ Ọlọ́run. Àmọ́, ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún la ti ń lo Jèhófà lédè Yorùbá, àwọn èèyàn sì mọ orúkọ yìí bí ẹní mowó lónìí ní onírúurú èdè tiwọn.—Ẹ́kísódù 6:3; Aísáyà 26:4, King James Version.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò lè sọ pàtó bí wọ́n ṣe ń pe orúkọ Ọlọ́run ní èdè Hébérù ìgbàanì, síbẹ̀ ìtumọ̀ rẹ̀ kì í ṣe àdììtú rárá. Orúkọ rẹ̀ túmọ̀ sí “Alèwílèṣe.” Jèhófà Ọlọ́run wá tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé òun ni Awímáyẹhùn. Ó máa ń mú àwọn ète àti ìlérí rẹ̀ ṣẹ ní gbogbo ìgbà. Ọlọ́run tòótọ́, tó ní agbára láti ṣe èyí nìkan ló lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ orúkọ yẹn.—Aísáyà 55:11.

Láìṣe àní-àní, orúkọ náà Jèhófà la fi ń dá Ọlọ́run Olódùmarè mọ̀ yàtọ̀ sí gbogbo ọlọ́run yòókù. Ìdí nìyẹn tórúkọ yẹn fi fara hàn lọ́pọ̀ ìgbà nínú Bíbélì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìtumọ̀ ni kò lo orúkọ àtọ̀runwá náà, Sáàmù 83:18 là á mọ́lẹ̀ pé: “Ìwọ, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà, ìwọ nìkan ṣoṣo ni Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé.” Nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù Kristi lórí ilẹ̀ ayé, ó kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Kí ẹ máa gbàdúrà ní ọ̀nà yìí: ‘Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́.’” (Mátíù 6:9) Nítorí náà, ó yẹ ká máa lo orúkọ Ọlọ́run nígbà tá a bá ń gbàdúrà, nígbà tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, àti nígbà tá a bá ń yìn ín lójú àwọn ẹlòmíràn.

Ṣé Jésù Ni Ọlọ́run?

Jèhófà Ọlọ́run fúnra rẹ̀ kò fi wá sínú òkùnkùn nípa ẹni tí Ọmọ rẹ̀ jẹ́. Ìhìn Rere Mátíù sọ fún wa pé lẹ́yìn ìbatisí Jésù, “ohùn kan wá láti ọ̀run tí ó wí pé: ‘Èyí ni Ọmọ mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà.’” (Mátíù 3:16, 17) Jésù Kristi ni Ọmọ Ọlọ́run.

Àmọ́, àwọn ẹlẹ́sìn kan ń sọ pé Jésù ni Ọlọ́run. Àwọn mìíràn ń sọ pé Ọlọ́run jẹ́ Mẹ́talọ́kan. Ohun tí ẹ̀kọ́ yìí ń sọ ni pé, “Baba jẹ́ Ọlọ́run, Ọmọ jẹ́ Ọlọ́run, Ẹ̀mí Mímọ́ náà sì jẹ́ Ọlọ́run, síbẹ̀ kì í ṣe Ọlọ́run mẹ́ta ló wà bí kò ṣe Ọlọ́run kan.” Wọ́n ní àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta “jọ jẹ́ ẹni ayérayé, wọ́n sì bára dọ́gba.” (The Catholic Encyclopedia) Ǹjẹ́ irú èrò yẹn tọ̀nà?

Ìwé Mímọ́ tí a mí sí sọ nípa Jèhófà pé: “Àní láti àkókò tí ó lọ kánrin títí dé àkókò tí ó lọ kánrin, ìwọ ni Ọlọ́run.” (Sáàmù 90:2) Òun ni “Ọba ayérayé”—kò ní ìbẹ̀rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò lópin. (1 Tímótì 1:17) Jésù ní tirẹ̀ ni “àkọ́bí nínú gbogbo ìṣẹ̀dá,” “ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìṣẹ̀dá láti ọwọ́ Ọlọ́run.” (Kólósè 1:13-15; Ìṣípayá 3:14) Jésù sọ pé Baba òun ni Ọlọ́run jẹ́, ó sì sọ pé: “Baba tóbi jù mí lọ.” (Jòhánù 14:28) Jésù tún ṣàlàyé pé àwọn nǹkan kan wà tí òun kò mọ̀, tí àwọn áńgẹ́lì ọ̀run pàápàá kò mọ̀, tó jẹ́ pé Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ló mọ̀ wọ́n. (Máàkù 13:32) Jésù tún gbàdúrà sí Baba rẹ̀, ó ní: “Kì í ṣe ìfẹ́ mi ni kí ó ṣẹ, bí kò ṣe tìrẹ.” (Lúùkù 22:42) Ta ló ń gbàdúrà sí, bí kì í bá ṣe Ẹni tó tóbi jù ú lọ? Ọlọ́run ló sì jí Jésù dìde kúrò nínú ikú, kì í ṣe Jésù ló jí ara rẹ̀ dìde.—Ìṣe 2:32.

Gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ṣe fi hàn, Jèhófà ni Ọlọ́run Olódùmarè, Jésù sì ni Ọmọ rẹ̀. Àwọn méjèèjì kò bára dọ́gba kí Jésù tó wá sórí ilẹ̀ ayé tàbí nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé; bẹ́ẹ̀ náà ni Jésù kò bá Baba rẹ̀ dọ́gba lẹ́yìn tó jíǹde tó sì gòkè re ọ̀run. (1 Kọ́ríńtì 11:3; 15:28) Gẹ́gẹ́ bá a ṣe rí i, èyí tí wọ́n ń pè ní ẹni kẹta nínú Mẹ́talọ́kan, ìyẹn ẹ̀mí mímọ́, kì í ṣe ẹni gidi kan. Kàkà bẹ́ẹ̀, ipá tí Ọlọ́run ń lò láti ṣe ohunkóhun tó bá fẹ́ ṣe ni. Nítorí náà, ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan kò bá Ìwé Mímọ́ mu. a Bíbélì sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run wa, Jèhófà kan ṣoṣo ni.”—Diutarónómì 6:4.

Túbọ̀ Mọ Ọlọ́run Dunjú

Ká tó lè nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, ká sì máa fún un ní ìfọkànsìn àyàsọ́tọ̀ gédégbé tó tọ́ sí i, a ní láti mọ Ẹni tó jẹ́ gan-an. Báwo la ṣe lè túbọ̀ mọ Ọlọ́run dunjú? Bíbélì sọ pé: “Àwọn ànímọ́ rẹ̀ tí a kò lè rí ni a rí ní kedere láti ìgbà ìṣẹ̀dá ayé síwájú, nítorí a ń fi òye mọ̀ wọ́n nípasẹ̀ àwọn ohun tí ó dá, àní agbára ayérayé àti jíjẹ́ Ọlọ́run rẹ̀.” (Róòmù 1:20) Ọ̀nà kan láti túbọ̀ mọ Ọlọ́run dunjú ni nípa wíwo àwọn ohun tó dá, ká sì máa fi ìmọrírì ronú jinlẹ̀ nípa wọn.

Àmọ́, àwọn ohun tó dá, kò lè sọ gbogbo ohun tó yẹ ká mọ̀ nípa Ọlọ́run fún wa. Fún àpẹẹrẹ, ká tó lè mọ̀ pé Ẹni ẹ̀mí gidi tó ní orúkọ aláìlẹ́gbẹ́ kan ni, a gbọ́dọ̀ yẹ Bíbélì wò. Ní tòótọ́, kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni ọ̀nà tó dára jù lọ láti túbọ̀ mọ Ọlọ́run dunjú. Nínú Ìwé Mímọ́, Jèhófà sọ ohun púpọ̀ gan-an fún wa nípa irú Ọlọ́run tó jẹ́. Ó tún ṣí àwọn ète rẹ̀ payá fún wa, ó sì kọ́ wa ní àwọn ọ̀nà rẹ̀. (Ámósì 3:7; 2 Tímótì 3:16, 17) Inú wa mà dùn o, pé Ọlọ́run fẹ́ kí a “wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́,” kí a lè jàǹfààní látinú ìpèsè onífẹ̀ẹ́ rẹ̀! (1 Tímótì 2:4) Fún ìdí yìí, ẹ jẹ́ ká sa gbogbo ipá wa láti kọ́ gbogbo ohun tá a bá lè kọ́ nípa Jèhófà.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé lórí kókó yìí, wo ìwé pẹlẹbẹ Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí?, tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Ọlọ́run lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ láti dá ayé àti láti mí sí àwọn èèyàn láti kọ Bíbélì

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Ohùn kan láti ọ̀run wí pé: “Èyí ni Ọmọ mi”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Jésù gbàdúrà sí Ọlọ́run—Ẹni tí ó tóbi jù ú lọ

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Jésù sọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ̀ fún àwọn ẹlòmíràn

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

A lè túbọ̀ mọ Ọlọ́run dunjú