Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀bi Ta Ni—Ṣé Ẹ̀bi Rẹ Ni Àbí Ti Apilẹ̀ Àbùdá Rẹ?

Ẹ̀bi Ta Ni—Ṣé Ẹ̀bi Rẹ Ni Àbí Ti Apilẹ̀ Àbùdá Rẹ?

Ẹ̀bi Ta Ni—Ṣé Ẹ̀bi Rẹ Ni Àbí Ti Apilẹ̀ Àbùdá Rẹ?

ÀWỌN onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ń ṣiṣẹ́ kárakára láti rí i bóyá apilẹ̀ àbùdá ló ń fa ìmukúmu ọtí, ìbẹ́yà-kannáà-lòpọ̀, iṣẹ́ aṣẹ́wó, ìwà ipá, àtàwọn ìwàkíwà mìíràn, kódà bóyá òun ló ń fa ikú pàápàá. Ǹjẹ́ ẹrù ńlá kọ́ ló máa kúrò lọ́rùn wa bó bá jẹ́ pé ẹ̀bi wa kọ́ ni gbogbo ohun tí à ń ṣe, tó jẹ́ pé àwọn èròjà tó pilẹ̀ àbùdá ló ń tì wá ṣe wọ́n? Ìwà ẹ̀dá ni láti di ẹ̀bi àṣìṣe rẹ̀ ru ẹlòmíràn tàbí ohun mìíràn.

Bó bá jẹ́ pé ẹ̀bi èròjà tó pilẹ̀ àbùdá ni, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ pé ó ṣeé ṣe kí àwọ́n rọ́gbọ́n dá sí i, kí àwọ́n yí àwọn èròjà kan padà, kí àwọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ mú àwọn ìwà búburú kan kúrò. Àṣeyọrí tí wọ́n ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí nígbà tí wọ́n ṣàwárí gbogbo ọ̀wọ́ èròjà apilẹ̀ àbùdá tó wà lára èèyàn, ló jẹ́ kí wọ́n gbà pé ó ṣeé ṣe káwọn kẹ́sẹ járí.

Àmọ́ o, ohun tí wọ́n gbé àbá yìí kà ni pé ohun tó pilẹ̀ àbùdá wa gan-an ló fà á tá a fi ń dẹ́ṣẹ̀, tá a sì ń ṣàṣìṣe. Ǹjẹ́ àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì wọ̀nyí ti rí ẹ̀rí tó pọ̀ tó láti di ẹ̀bi ru àwọn èròjà tó pilẹ̀ àbùdá wa? Dájúdájú, bá a bá ṣe dáhùn ìbéèrè yìí yóò ní ipa jíjinlẹ̀ lórí irú ojú tí a ó fi máa wo ara wa àti ọjọ́ ọ̀la wa. Ṣùgbọ́n ká tó gbé ẹ̀rí tó wà nílẹ̀ yẹ̀ wò, á dáa ká kọ́kọ́ ṣàyẹ̀wò ìtàn ẹ̀dá ènìyàn látètèkọ́ṣe.

Bá A Ṣe Jogún Àìpé

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti gbọ́ ìtàn bí Ádámù àti Éfà, ìyẹn tọkọtaya àkọ́kọ́, ṣe di ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ nínú ọgbà Édẹ́nì. Ṣé àléébù tàbí àṣìṣe wà nínú àwọn èròjà tó pilẹ̀ àbùdá wọn látìbẹ̀rẹ̀ ni, tó wá sún wọn dẹ́ṣẹ̀, tàbí tó sún wọn ṣàìgbọràn?

Jèhófà Ọlọ́run, Ẹlẹ́dàá wọn, tí gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ jẹ́ pípé, kéde pé iṣẹ́ tí òun fi dé iṣẹ́ ìṣẹ̀dá òun ládé lórí ilẹ̀ ayé “dára gan-an ni.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:31; Diutarónómì 32:4) Láti fi hàn síwájú sí i pé inú òun dùn sí iṣẹ́ òun, ó súre fún tọkọtaya àkọ́kọ́ pé kí wọ́n máa bí sí i, kí wọ́n fi ẹ̀dá ènìyàn kún ilẹ̀ ayé, kí wọ́n sì máa bójú tó àwọn ẹ̀dá tí ń bẹ láyé—èyí fi hàn pé iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ dá a lójú hán-únhán-ún.—Jẹ́nẹ́sísì 1:28.

Nípa bí Ọlọ́run ṣe ṣẹ̀dá tọkọtaya àkọ́kọ́, Bíbélì sọ fún wa pé: “Ọlọ́run sì bẹ̀rẹ̀ sí dá ènìyàn ní àwòrán rẹ̀, àwòrán Ọlọ́run ni ó dá a; akọ àti abo ni ó dá wọn.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:27) Èyí kò túmọ̀ sí pé Ọlọ́run dá ènìyàn kí ó jọ òun ní ìrísí, nítorí pé “Ọlọ́run jẹ́ Ẹ̀mí.” (Jòhánù 4:24) Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó túmọ̀ sí ni pé Ọlọ́run fún ẹ̀dá ènìyàn ní irú ànímọ́ tí òun ní, àti ìmọ̀ nípa rere àti búburú, ìyẹn ẹ̀rí ọkàn. (Róòmù 2:14, 15) Pẹ̀lúpẹ̀lù, wọ́n jẹ́ ẹ̀dá amọnúúrò, tó lè gbé nǹkan yẹ̀ wò, kí ó sì pinnu ìgbésẹ̀ tí òun yóò gbé.

Ṣùgbọ́n kì í ṣe pé àwọn òbí wa àkọ́kọ́ wà láìsí ìtọ́ni. Kàkà bẹ́ẹ̀, a kìlọ̀ fún wọn nípa àbájáde ìwà àìtọ́. (Jẹ́nẹ́sísì 2:17) Nítorí náà, ẹ̀rí fi hàn pé nígbà tí Ádámù dojú kọ ìpinnu nípa ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́, òun ló yàn láti ṣe ohun tó rò pé ó máa ṣe òun láǹfààní lójú ẹsẹ̀. Ó dara pọ̀ mọ́ aya rẹ̀ láti hùwà àìtọ́, dípò kí ó ronú lórí àjọṣe àárín òun àti Ẹlẹ́dàá rẹ̀ tàbí kí ó ronú lórí àbájáde ìgbésẹ̀ rẹ̀ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Ó tún gbìyànjú lẹ́yìn náà láti dá Jèhófà lẹ́bi. Ó ní ìyàwó tí Ó fún òun ló ṣi òun lọ́nà.—Jẹ́nẹ́sísì 3:6, 12; 1 Tímótì 2:14.

Ìgbésẹ̀ tí Ọlọ́run gbé lẹ́yìn tí Ádámù àti Éfà ṣẹ̀ tún yẹ fún àfiyèsí. Kò sọ pé ‘àléébù’ kan wà nínú apilẹ̀ àbùdá wọn, tí òun fẹ́ tún ṣe. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ kí wọ́n jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn, tó wá yọrí sí ikú wọn nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín. (Jẹ́nẹ́sísì 3:17-19) Ìtàn ìjímìjí yìí jẹ́ ká túbọ̀ lóye ìhùwàsí ẹ̀dá. a

Ẹ̀rí Tó Fi Hàn Pé Kì Í Ṣe Ẹ̀bi Apilẹ̀ Àbùdá

Ọjọ́ ti pẹ́ táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti ń ṣiṣẹ́ àṣekúdórógbó láti lè rí ipa tí apilẹ̀ àbùdá ń kó nínú àìsàn àti ìhùwàsí ọmọ aráyé, kí wọ́n sì rí oògùn àtúnṣe sí i. Lẹ́yìn ọdún mẹ́wàá iṣẹ́ àṣekára tí àwùjọ mẹ́fà àwọn olùwádìí ṣe, wọ́n ṣàwárí pé apilẹ̀ àbùdá ló ń fa àìsàn Huntington, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn olùwádìí yìí kò mọ bí apilẹ̀ àbùdá náà ṣe ń fa àìsàn ọ̀hún. Àmọ́ nígbà tí ìwé ìròyìn Scientific American ń ròyìn nípa ìwádìí yìí, ó fa ọ̀rọ̀ Evan Balaban yọ, tí í ṣe onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ohun alààyè láti Harvard, ẹni tó sọ pé “kò dájú pé a máa lè ṣàwárí àwọn apilẹ̀ àbùdá tó ń fa àìmọ̀wàáhù.”

Ohun tó tiẹ̀ ṣẹlẹ̀ ni pé, ìwádìí tí wọ́n ń ṣe láti fi hàn pé apilẹ̀ àbùdá kan pàtó ló ń darí ìṣesí ẹ̀dá ti forí ṣánpọ́n. Bí àpẹẹrẹ, ìròyìn kan nínú ìwé ìròyìn Psychology Today, tó ròyìn nípa àwọn ìwádìí kan láti mọ̀ bóyá apilẹ̀ àbùdá ló ń fa ìsoríkọ́, sọ pé: “Ìsọfúnni tí wọ́n ti kó jọ nípa wíwá nǹkan ṣe sí akọ àìsàn ọpọlọ fi hàn kedere pé kì í ṣe apilẹ̀ àbùdá nìkan ló ń fà á.” Ìròyìn náà mú àpẹẹrẹ yìí wá, ó ní: “Àwọn ará Amẹ́ríkà tá a bí ṣáájú 1905 ní ìṣòro ìsoríkọ́ tó jẹ́ nǹkan bí ìdá kan nínú ọgọ́rùn-ún nígbà tí wọ́n pé ẹni ọdún márùndínlọ́gọ́rin [75]. Lára àwọn ará Amẹ́ríkà tá a bí ní àádọ́ta ọdún lẹ́yìn náà, ìdá mẹ́fà nínú ọgọ́rùn-ún wọn ló ní ìṣòro ìsoríkọ́ nígbà tí wọ́n pé ọmọ ọdún mẹ́rìnlélógún!” Ìdí nìyẹn tí ìròyìn náà fi parí ọ̀rọ̀ sí pé ó ní láti jẹ́ nǹkan kan lóde ara tàbí àwọn ìṣòro ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà ló fa ìyípadà pípabanbarì láàárín àkókò kúkúrú yẹn.

Kí ni ìwádìí wọ̀nyí àti ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ìwádìí mìíràn jẹ́ ká mọ̀? Wọ́n jẹ́ ká mọ̀ pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé apilẹ̀ àbùdá lè ní ipa tó ń kó nínú irú èèyàn tá a jẹ́, ó dájú pé àwọn nǹkan mìíràn tún wà tó ń nípa lórí wa. Kókó pàtàkì mìíràn ni àyíká wa, tó ti yí padà pátápátá lóde òní. Nígbà tí ìwé náà Boys Will Be Boys ń sọ̀rọ̀ nípa irú eré ìnàjú tó gbajúmọ̀ láàárín àwọn èwe ìwòyí, ó ní kò jọ pé àwọn ọmọdé máa dàgbà di ọmọlúwàbí mọ́, nítorí pé “àwọn eré tí wọ́n ń fi àìmọye wákàtí wò nínú tẹlifíṣọ̀n láti kékeré ni àwọn eré tí wọ́n ti ń lu àwọn èèyàn ní ìlùkulù, tí wọ́n ń yìn wọ́n níbọn, tí wọ́n ń gún wọn lọ́bẹ, tí wọ́n ń tú ìfun wọn jáde, tí wọ́n ń gé wọn sí wẹ́wẹ́, tí wọ́n ń bó wọn láwọ, tàbí tí wọ́n ń gé ẹ̀yà ara èèyàn sọ nù, nígbà tó jẹ́ pé láti kékeré làwọn ọmọdé ti ń gbọ́ àwọn orin tó ń gbé ìfipábáni-lòpọ̀, ìpara-ẹni, ìjoògùnyó, ìmutíyó àti ẹ̀mí kìígbọ́-kìígbà lárugẹ.”

Láìsí àní-àní, Sátánì, tí í ṣe “olùṣàkóso ayé yìí,” ti sọ àyíká ẹ̀dá ènìyàn di èyí tó kún fún àwọn ohun tí ń fa ìwàkíwà. Ǹjẹ́ ẹnì kankan sì lè sẹ́ òtítọ́ náà pé irú àyíká bẹ́ẹ̀ ń ní ipa tí kò kéré lórí gbogbo wa?—Jòhánù 12:31; Éfésù 6:12; Ìṣípayá 12:9, 12.

Orísun Ìṣòro Aráyé

Gẹ́gẹ́ bí àlàyé tá a ṣe ní ìṣáájú, ìgbà tí tọkọtaya àkọ́kọ́ dẹ́ṣẹ̀ ni ìṣòro aráyé bẹ̀rẹ̀. Kí ni ìyọrísí rẹ̀? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìran àtọmọdọ́mọ Ádámù kọ́ ló ṣẹ̀, síbẹ̀ inú ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé là ń bí wọn sí, wọ́n sì ti jogún ikú. Bíbélì ṣàlàyé pé: “Ìdí nìyẹn tí ó fi jẹ́ pé, gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ ti tipasẹ̀ ènìyàn kan wọ ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, ikú sì tipa báyìí tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí pé gbogbo wọn ti dẹ́ṣẹ̀.”—Róòmù 5:12.

Àìpé ẹ̀dá ti pa kún ìṣòro aráyé. Àmọ́ èèyàn ò wá lè di gbogbo ẹ̀bi náà ru àìpé ẹ̀dá. Bíbélì fi hàn pé àwọn tó bá lo ìgbàgbọ́ nínú ètò tí Jèhófà ṣe fún ìyè, tí wọ́n sì mú ìgbésí ayé wọn bá ìlànà Ọlọ́run mu yóò rí ojú rere rẹ̀. Nínú inú-rere-onífẹ̀ẹ́ rẹ̀, Jèhófà ṣe ètò tó fi ojú àánú rẹ̀ hàn láti ra aráyé padà, bíi pé ó ra ohun tí Ádámù pàdánù padà. Ìṣètò yẹn ni ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi Ọmọ rẹ̀ pípé, ẹni tó sọ pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.”—Jòhánù 3:16; 1 Kọ́ríńtì 15:21, 22.

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mọrírì ìṣètò yìí lọ́pọ̀lọpọ̀. Ó sọ pé: “Èmi abòṣì ènìyàn! Ta ni yóò gbà mí lọ́wọ́ ara tí ń kú ikú yìí? Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run nípasẹ̀ Jésù Kristi Olúwa wa!” (Róòmù 7:24, 25) Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé bí òun bá kó sínú ẹ̀ṣẹ̀ nítorí àìpé ẹ̀dá, òun lè tọrọ àforíjì lọ́dọ̀ Ọlọ́run nípasẹ̀ ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi. b

Gẹ́gẹ́ bó ti rí ní ọ̀rúndún kìíní, ọ̀pọ̀ èèyàn tó jẹ́ oníwà pálapàla tẹ́lẹ̀ rí tàbí àwọn tí ipò wọn dà bí aláìnírètí ti gba ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́ Bíbélì, wọ́n ti ṣe ìyípadà yíyẹ, wọ́n sì ti wà lójú ìlà fún rírí ìbùkún Ọlọ́run gbà. Àwọn ìyípadà tí wọ́n ti ṣe kò rọrùn, àwọn kan ṣì ní láti gbéjà ko àwọn ìwà burúkú kan. Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run, wọ́n ń pa ìwà títọ́ mọ́, wọ́n sì ń sìn ín tayọ̀tayọ̀. (Fílípì 4:13) Wo àpẹẹrẹ ẹnì kan tó ṣe ìyípadà tó pabanbarì kí ó bàa lè múnú Ọlọ́run dùn.

Ìrírí Kan Tí Ń Gbéni Ró

“Nígbà tí mo ṣì jẹ́ ọ̀dọ́mọdé tí mò ń lọ síléèwé tó ní ibùgbé fún àwa ọmọléèwé ni mo ti bẹ̀rẹ̀ sí lọ́wọ́ sí ìbẹ́yà-kannáà-lòpọ̀. Àmọ́ mi ò ka ara mi sí abẹ́yà-kannáà-lòpọ̀. Àwọn òbí mi ti kọ ara wọn sílẹ̀, ó sì máa ń dùn mí gan-an pé n kò ní òbí tó lè fìfẹ́ hàn sí mi. Lẹ́yìn tí mo parí iléèwé, mo lọ ṣe iṣẹ́ ológun tó jẹ́ dandan gbọ̀n. Àwọn kan tí wọ́n jẹ́ abẹ́yà-kannáà-lòpọ̀ wà ní bárékè tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ tiwa. Ọkàn mi bẹ̀rẹ̀ sí fà sí ọ̀nà ìgbésí ayé wọn. Bí mo ṣe bẹ̀rẹ̀ sí bá wọn rìn nìyẹn. Lẹ́yìn tí mo bá wọn rìn fún ọdún kan, mo bẹ̀rẹ̀ sí ka ara mi sí abẹ́yà-kannáà-lòpọ̀. Mo bẹ̀rẹ̀ sí ronú pé: ‘Irú èèyàn tí mo jẹ́ látilẹ̀wá nìyẹn. Kò sì sóhun tí mo lè ṣe sí i.’

“Mo bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ èdè wọn, mò ń lọ sí ilé ẹgbẹ́ wọn, níbi tí oògùn líle àti ọtí líle wà jaburata. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé lóde, ó jọ pé gbogbo rẹ̀ ń dùn yùngbà, síbẹ̀ ó ń ríni lára ní ti gidi. Nínú lọ́hùn-ún, ọkàn mi ń sọ fún mi pé ìṣekúṣe là ń ṣe yìí, kò sì lè gbé wa débì kankan.

“Ní ìlú kékeré kan, mo rí Gbọ̀ngàn Ìjọba àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà tí ìpàdé ń lọ lọ́wọ́. Mo wọlé lọ, mo sì gbọ́ àsọyé tó dá lórí bí ipò nǹkan yóò ṣe rí nínú Párádísè ọjọ́ iwájú. Lẹ́yìn náà, èmi àtàwọn Ẹlẹ́rìí kan jọ sọ̀rọ̀, wọ́n sì ní kí n wá sí àpéjọ kan. Mo lọ, ó sì là mí lójú. Mo rí àwọn ìdílé aláyọ̀ tí wọ́n ń jọ́sìn pa pọ̀. Àwọn Ẹlẹ́rìí wá bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

“Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn fún mi, síbẹ̀ mo bẹ̀rẹ̀ sí fi ohun tí mò ń kọ́ nínú Bíbélì sílò. Mo yọwọ́ nínú gbogbo ìwà àìmọ́ tí mò ń hù. Lẹ́yìn kíkẹ́kọ̀ọ́ fún oṣù mẹ́rìnlá, mo ya ìgbésí ayé mi sí mímọ́ fún Jèhófà, mo sì ṣèrìbọmi. Ìgbà àkọ́kọ́ nìyẹn tí mo ní àwọn ọ̀rẹ́ gidi láyé mi. Mo ti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nínú Bíbélì. Mo sì ń sìn gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ báyìí nínú ìjọ Kristẹni. Jèhófà ti bù kún mi lóòótọ́.”

Ọwọ́ Wa Ló Wà

Sísọ pé apilẹ̀ àbùdá wa ló fa gbogbo àṣìṣe wa kò lè yanjú ìṣòro wa. Kàkà kí ó yanjú àwọn ìṣòro wa, ìwé ìròyìn Psychology Today sọ pé dídi ẹ̀bi ru apilẹ̀ àbùdá “lè jẹ́ ká gbà pé a kò lè dá nǹkan kan ṣe. A sì mọ̀ pé olórí ìṣòro wa nìyẹn. Dípò kí irú ẹ̀mí yìí dín ìṣòro wọ̀nyí kù, ńṣe ló ń dá kún un.”

Òótọ́ ni pé ó di dandan ká gbógun ti àwọn agbára ńlá tó fẹ́ máa tì wá ṣe ohun tí kò tọ́, títí kan ìtẹ̀sí àwa fúnra wa láti dẹ́ṣẹ̀, àti akitiyan Sátánì láti mú wa kẹ̀yìn sí Ọlọ́run. (1 Pétérù 5:8) Òótọ́ tún ni pé apilẹ̀ àbùdá wa lè ní ipa lórí wa títí dé àyè kan. Àmọ́, ó dájú pé a ní olùrànlọ́wọ́. Àwọn Kristẹni tòótọ́ ní àwọn olùgbèjà tó lágbára—àwọn ni Jèhófà, Jésù Kristi, ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run, Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀, àti ìjọ Kristẹni.—1 Tímótì 6:11, 12; 1 Jòhánù 2:1.

Kí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tó wọ Ilẹ̀ Ìlérí, Mósè rán àwọn èèyàn náà létí ojúṣe wọn níwájú Ọlọ́run, pé: “Èmi ti fi ìyè àti ikú sí iwájú rẹ, ìbùkún àti ìfiré; kí o sì yan ìyè, kí o lè máa wà láàyè nìṣó, ìwọ àti ọmọ rẹ, nípa nínífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ, nípa fífetí sí ohùn rẹ̀ àti nípa fífà mọ́ ọn.” (Diutarónómì 30:19, 20) Bákan náà ni lónìí. Ojúṣe kálukú ni kí ó pinnu láti sin Ọlọ́run, kí ó sì pa òfin rẹ̀ mọ́. Yíyàn yẹn dọwọ́ rẹ.—Gálátíà 6:7, 8.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo Jí! September 22, 1996, ojú ìwé 3 sí 7.

b Wo ìwé náà Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, ojú ìwé 62 sí 69, tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Ṣé àléébù inú apilẹ̀ àbùdá ló sún Ádámù àti Éfà dẹ́ṣẹ̀ ni?

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Ǹjẹ́ ó yẹ kí kálukú gba ohun tó bá tẹ̀yìn ìpinnu rẹ̀ yọ?

[Credit Line]

Ajoògùnyó: Godo-Foto

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]

Gbogbo akitiyan àwọn èèyàn láti fi hàn pé apilẹ̀ àbùdá ló ń pinnu ìhùwàsí ẹ̀dá ti forí ṣánpọ́n

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Fífi ohun tí Bíbélì sọ sílò lè ran àwọn olóòótọ́ ọkàn lọ́wọ́ láti ṣe ìyípadà