Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ṣé dandan ni ká ri èèyàn bọmi pátápátá bí ẹni tó fẹ́ ṣe batisí bá jẹ́ abirùn tàbí bí àìsàn tó ń ṣe é bá jẹ́ kó nira láti rì í bọmi?
Ọ̀rọ̀ náà “ìbatisí” wá látinú ọ̀rọ̀ ìṣe Gíríìkì náà baʹpto, tó túmọ̀ sí “láti rì bọ nǹkan.” (Jòhánù 13:26) Nínú Bíbélì, ìtumọ̀ kan náà ni “láti batisí” àti “láti rì bọmi” ní. Nígbà tí The Emphasised Bible, ìtumọ̀ ti Rotherham, ń sọ̀rọ̀ nípa bí Fílípì ṣe batisí ìwẹ̀fà ará Etiópíà náà, bó ṣe túmọ̀ rẹ̀ ni pé: “Àwọn méjèèjì, àti Fílípì àti ìwẹ̀fà náà, jọ sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú omi,—ó sì rì í bọmi.” (Ìṣe 8:38) Tó túmọ̀ sí pé ńṣe là ń ri ẹni tí a fẹ́ batisí bọmi pátápátá.—Mátíù 3:16; Máàkù 1:10.
Jésù pàṣẹ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn.” (Mátíù 28:19, 20) Ìdí nìyẹn táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń ṣètò bíbatisí àwọn èèyàn nínú kòtò tó kún fún omi, nínú adágún odò, nínú odò tí ń ṣàn, tàbí àwọn ibòmíràn tí omi tó pọ̀ tó láti ri èèyàn bọnú rẹ̀ wà. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Ìwé Mímọ́ ló sọ pé ká máa batisí àwọn èèyàn nípa rírì wọ́n bọmi, ẹnì kan kò ní ọlá àṣẹ láti yọ̀ǹda ẹlòmíràn pé kó má ṣe batisí. Fún ìdí yìí, èèyàn gbọ́dọ̀ ṣe batisí, kódà bó bá di dandan láti gbé ìgbésẹ̀ àrà ọ̀tọ̀ nítorí ipò rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, a ti batisí àwọn arúgbó tàbí àwọn tó ní àìsàn líle gan-an nínú ọpọ́n ìwẹ̀. A lè mú kí omi inú ọpọ́n ìwẹ̀ náà lọ́ wọ́ọ́rọ́, ká wá rọra gbé ẹni tá a fẹ́ batisí sínú omi náà, kí a sì wá ṣe batisí náà lẹ́yìn tí omi náà bá bá a lára mu.
Kódà a ti batisí àwọn aláàbọ̀ ara tí ipò wọn gbẹgẹ́ gan-an. Fún àpẹẹrẹ, a ti batisí àwọn kan tí wọ́n ṣe iṣẹ́ abẹ ọ̀nà ọ̀fun fún, tí ihò tí kò ṣeé dí sì wà lọ́nà ọ̀fun wọn, tàbí àwọn tó di dandan fún láti máa lo ẹ̀rọ tí a fi ń mí. Àmọ́ ṣá o, a gbọ́dọ̀ múra sílẹ̀ dáadáa fún gbogbo irú ìbatisí bẹ́ẹ̀. Á dáa kí nọ́ọ̀sì tó dáńgájíá tàbí dókítà wà lárọ̀ọ́wọ́tó. Ó dájú pé bí a bá ṣètò ìtọ́jú àkànṣe sílẹ̀ tàbí tí a bá fi tìṣọ́ratìṣọ́ra ṣe é, ó sábà máa ń ṣeé ṣe láti batisí irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, gbogbo ohun tí a bá lè ṣe ló yẹ ká ṣe láti rí i dájú pé a batisí ẹnì kan nínú omi, bí ó bá ti ọkàn onítọ̀hún wá láti ṣe bẹ́ẹ̀, tó sì gbà pé òun kò kọ ohunkóhun tó lè tẹ̀yìn rẹ̀ yọ.