Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìfọkànsin Ọlọ́run Mú Èrè Wá fún Mi

Ìfọkànsin Ọlọ́run Mú Èrè Wá fún Mi

Ìtàn Ìgbésí Ayé

Ìfọkànsin Ọlọ́run Mú Èrè Wá fún Mi

GẸ́GẸ́ BÍ WILLIAM AIHINORIA ṢE SỌ Ọ́

Mo ta jí ní ààjìn òru bí bàbá mi ṣe tún bẹ̀rẹ̀ sí kérora. Ó fọwọ́ gbá ikùn mú, ó ń yí gbirigbiri nílẹ̀. Èmi, màmá mi, àtẹ̀gbọ́n mi obìnrin dúró yí i ká. Nígbà tó jọ pé ìrora náà lọ sílẹ̀ díẹ̀, ó jókòó dáadáa, ó mí kanlẹ̀, ó ní: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìkan ló ní àlàáfíà láyé yìí.” Ọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí kò yé mi. Àmọ́, ó gbé ìbéèrè dìde lọ́kàn mi nítorí pé mi ò tíì gbọ́ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà rí. Mo fẹ́ mọ̀dí ọ̀rọ̀ yẹn.

ÌYẸN ṣẹlẹ̀ lọ́dún 1953 nígbà tí mo jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́fà. Agboolé oníyàwó púpọ̀ la bí mi sí ní Ewossa, abúlé kan tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ oko ní àárín ìwọ̀ oòrùn Nàìjíríà. Èmi ni ọmọ kejì. Mo sì jẹ́ ọkùnrin àkọ́kọ́ tí wọ́n bí sínú ìdílé tó wá ní bàbá, ìyàwó mẹ́ta àtàwa ọmọ mẹ́tàlá nínú lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Inú ilé alábàrá tí bàbá wa àgbà kọ́, tá a fi koríko bò, tó ní yàrá mẹ́rin, ni gbogbo wa jọ ń gbé. Ìyá Àgbà, àtàwọn mẹ́ta tó jẹ́ arákùnrin bàbá wa àti ìdílé tiwọn tún wà nínú ilé kan náà.

Ojú mi rí màbo nígbà tí mo wà ní kékeré. Àìsàn bàbá mi ni ohun pàtàkì tó fà á. Inú kan tí kò gbóògùn ló máa ń run ún. Inú náà kò sì lọ títí tó fi kú ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà. Kò sẹ́ni tó mọ ohun tó fa àìsàn yìí. Gbogbo oògùn tí ìdílé mẹ̀kúnnù ará Áfíríkà lè rówó rà—ì báà jẹ́ oògùn òyìnbó tàbí ti ìbílẹ̀—kò ràn án rárá. Àìmọye ìgbà la kì í sùn lóru, tó jẹ́ pé ńṣe la óò máa sunkún lẹ́gbẹ̀ẹ́ bàbá wa bó ṣe ń yí nílẹ̀ nínú ìroragógó, títí àkùkọ á fi kọ láàárọ̀ ọjọ́ kejì. Òun àti Màmá sábà máa ń rìnrìn àjò, níbi tó ti ń wá ìtọ́jú kiri. Wọ́n á sì fi èmi àtàwọn ọmọ yòókù sábẹ́ ìtọ́jú Ìyá Àgbà.

Iṣẹ́ tá a fi ń gbéra ni ká ṣọ̀gbìn iṣu, ẹ̀gẹ́ àti obì, ká sì tà wọ́n. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọ̀nà kan ò wọjà, a tún ń kọ rọ́bà, láti fi kún owó táṣẹ́rẹ́ tí ń wọlé. Iṣu loúnjẹ pàtàkì tá à ń jẹ. Àá jẹ iṣu láàárọ̀, iyán lọ́sàn-án, àá tún jẹ iṣu sùn lálẹ́. A tún máa ń jẹ bọ̀ọ̀lì lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan.

Apá pàtàkì nínú ìgbésí ayé wa ni bíbọ àwọn baba ńlá. A máa ń bọ àwọn baba ńlá nípa gbígbé oúnjẹ síwájú àwọn ọ̀pá tí wọ́n to owó ẹyọ sí lára. Bàbá tún ń bọ òrìṣà kan láti fi lé àwọn ẹ̀mí burúkú àti àjẹ́ dà nù.

Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún márùn-ún, a ṣí kúrò lábúlé wa fúngbà díẹ̀ lọ sí abúléko kan tó jẹ́ nǹkan bíi kìlómítà mọ́kànlá sílùú wa. Sòbìyà mú bàbá mi níbẹ̀, láfikún sí inú tó ń yọ́ ọ lẹ́nu. Kò ní lè ṣiṣẹ́ lọ́sàn-án. Inú yẹn ò sì ní jẹ́ kó sùn lóru. Jìgá tún wọ èmi náà lẹ́sẹ̀. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé gbà-níbí gbà-lọ́hùn-ún látọ̀dọ̀ àwọn ẹbí la fi ń gbéra. A ṣí padà sí abúlé wa ní Ewossa, kí òṣì má bàa ta wá pa. Bàbá fẹ́ kí èmi àkọ́bí òun lọ́kùnrin di ẹni tó ní láárí, kí n má kàn jẹ́ àgbẹ̀ lásán. Ó gbà pé ìwé kíkà á tún ayé ìdílé wa ṣe, kí n lè rówó fi tọ́ àwọn àbúrò mi.

Mo Wá Mọ Àwọn Ẹ̀sìn Mìíràn

Mo bẹ̀rẹ̀ sí lọ síléèwé lábúlé wa. Èyí ló jẹ́ kí n mọ̀ nípa àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì. Ní àwọn ọdún 1950, bóyá lèèyàn lè lọ síléèwé kan láìṣe ẹ̀sìn àwọn òyìnbó tó dá iléèwé ọ̀hún sílẹ̀. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé iléèwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ti ìjọ Kátólíìkì ni mò ń lọ, ìyẹn túmọ̀ sí pé mo gbọ́dọ̀ di Kátólíìkì.

Ní 1966, nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún, wọ́n gbà mí sí Pilgrim Baptist Secondary School ní ìlú Ewohinmi, tó jẹ́ nǹkan bíi kìlómítà mẹ́jọ sí Ewossa. Ẹ̀kọ́ ìsìn tí wọ́n ń fi kọ́ mi níbẹ̀ tún yí padà. Nítorí pé iléèwé Pùròtẹ́sítáǹtì ni mò ń lọ nígbà yẹn, àwọn àlùfáà ìjọ Kátólíìkì kì í jẹ́ kí n jẹ ara Olúwa nígbà tá a bá ń ṣe ìsìn lọ́jọ́ Sunday.

Ìgbà tí mo wà ní iléèwé àwọn Onítẹ̀bọmi yìí ni mo kọ́kọ́ rí Bíbélì kà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò ṣíwọ́ lílọ sí ìjọ Kátólíìkì, mò ń dá ka Bíbélì lọ́jọọjọ́ Sunday lẹ́yìn tá a bá parí ìsìn nínú ìjọ Kátólíìkì. Ẹ̀kọ́ Jésù Kristi wú mi lórí gan-an, òun ló gbin ìfẹ́ láti gbé ìgbé-ayé ìfọkànsìn Ọlọ́run sí mi lọ́kàn. Bí mo ṣe túbọ̀ ń ka Bíbélì, bẹ́ẹ̀ náà ni àgàbàgebè àwọn aṣáájú ìsìn àti ìgbésí ayé oníṣekúṣe ọ̀pọ̀ ọmọ ìjọ wọn túbọ̀ ń kó mi nírìíra. Ohun tí mo rí láàárín àwọn tó ń pera wọn ní Kristẹni yàtọ̀ pátápátá sóhun tí Jésù àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ fi kọ́ni, tí wọ́n sì fi ṣèwà hù.

Àwọn nǹkan kan ṣẹlẹ̀ tó mú kí ara mi bù máṣọ. Lọ́jọ́ kan tí mo lọ sí ṣọ́ọ̀bù katikíìsì láti lọ ra ìlẹ̀kẹ̀ àdúrà, mo rí oògùn tó so rọ̀ sí àtẹ́rígbà ṣọ́ọ̀bù náà. Ìgbà kan tún wà tí ọ̀gá àgbà iléèwé Onítẹ̀bọmi tí mò ń lọ fẹ́ bá mi lò pọ̀. Mo gbọ́ lẹ́yìn náà pé abẹ́yà-kannáà-lòpọ̀ ni àti pé ó ti bá àwọn kan lò pọ̀. Ìrònú dorí mi kodò. Mo wá ń bi ara mi pé: ‘Ǹjẹ́ Ọlọ́run á tẹ́wọ́ gba ẹ̀sìn tí àwọn ọmọ ìjọ àtàwọn aṣáájú wọn ti ń dẹ́ṣẹ̀ wíwúwo, tí wọ́n sì ń mú un jẹ?’

Mo Wọ Ẹ̀sìn Mìíràn

Síbẹ̀, mo gbádùn ohun tí mò ń kà nínú Bíbélì. Mo sì pinnu pé màá máa kà á nìṣó. Ìgbà yẹn ni mo wá bẹ̀rẹ̀ sí ronú lórí ohun tí bàbá mi sọ ní nǹkan bí ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sẹ́yìn pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìkan ló ní àlàáfíà láyé yìí.” Àmọ́ ominú ń kọ mí, nítorí pé yẹ̀yẹ́ tí wọ́n ń fi àwọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí tó wà níléèwé wa ṣe ò kéré. Wọ́n tún ń fìyà jẹ wọ́n nígbà míì, nítorí pé wọn kì í bá wa ṣe ìjọsìn àràárọ̀. Ó sì jọ pé àwọn nǹkan míì tí wọ́n gbà gbọ́ kò bá ti gbogbo ayé mu. Fún àpẹẹrẹ, ó ṣòro fún mi láti gbà pé kìkì ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] ló ń lọ sọ́run. (Ìṣípayá 14:3) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọ̀run lèmi fẹ́ lọ, mi ò mọ̀ bóyá iye yìí ti pé kí wọ́n tó bí mi.

Láìsí àní-àní, ìwà àti ìṣe àwọn Ẹlẹ́rìí yàtọ̀. Wọn kì í lọ́wọ́ sí ìṣekúṣe àti ìwà ipá táwọn ọ̀dọ́ mìíràn ń hù níléèwé. Lójú tèmi, ńṣe ni wọ́n dìídì ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò nínú ayé. Mo sì ti kà á nínú Bíbélì pé bó ṣe yẹ káwọn tó ń ṣe ẹ̀sìn tòótọ́ rí nìyẹn.—Jòhánù 17:14-16; Jákọ́bù 1:27.

Mo pinnu pé màá ṣèwádìí síwájú sí i. Ní September 1969, mo gba ìwé “Otitọ ti Nsinni Lọ si Iye Aiyeraiye.” Ní oṣù tó tẹ̀ lé e, aṣáájú ọ̀nà kan, ìyẹn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, bẹ̀rẹ̀ sí bá mi ṣèkẹ́kọ̀ọ́. Ìkẹ́kọ̀ọ́ mi àkọ́kọ́ wú mi lórí gan-an, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí ka ìwé Òtítọ́ lóru ọjọ́ Sátidé kan títí mo fi parí rẹ̀ ní ọ̀sán ọjọ́ kejì. Láìsí lọ kábọ̀, mo bẹ̀rẹ̀ sí sọ àwọn ohun àgbàyanu tí mo kà fún àwọn ọmọléèwé wa. Àwọn ọmọléèwé àtàwọn olùkọ́ rò pé ìgbàgbọ́ tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ rí yìí ti ń dà mí lórí rú. Ṣùgbọ́n mo mọ̀ pé orí mi ò dà rú.—Ìṣe 26:24.

Òkìkí kàn dé ọ̀dọ̀ àwọn òbí mi pé ìwàásù nípa ẹ̀sìn tuntun kan ni mò ń ṣe kiri báyìí o. Wọ́n wá ní àfira, kí n yọjú sáwọn nílé, kí wọ́n lè mọ̀ bóyá òótọ́ lohun táwọn ń gbọ́ nípa mi. Mi ò rẹ́ni fọ̀ràn lọ̀, nítorí pé gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí ti lọ sí ọ̀kan lára àpéjọ àgbègbè wọn ní Iléṣà. Nígbà tí mo délé, ńṣe ni wọ́n da ìbéèrè bò mí, tí màmá mi àtàwọn ẹbí wa yòókù sì bẹ̀rẹ̀ sí bá mi wí. Mo ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe láti gbèjà àwọn ẹ̀kọ́ tí mò ń kọ́ nínú Bíbélì.—1 Pétérù 3:15.

Nígbà tí gbogbo ọgbọ́n tí wọ́n ń dá láti fi hàn pé olùkọ́ èké làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà já sí pàbó, arákùnrin bàbá mi wá dá ọgbọ́n mìíràn. Ó pàrọwà fún mi pé: “Rántí pé ẹ̀kọ́ la ní kó o lọ kọ́ níléèwé. Bó o bá wá fi ẹ̀kọ́ kíkọ́ sílẹ̀, tó jẹ́ pé ìwàásù lò ń ṣe kiri, a jẹ́ pé o ò ní parí ẹ̀kọ́ rẹ nìyẹn. Nítorí náà, o ò ṣe kọ́kọ́ parí ẹ̀kọ́ rẹ kó o tó wọ ẹ̀sìn tuntun yìí.” Ìyẹn bọ́gbọ́n mu lójú mi nígbà yẹn, ni mo bá ṣíwọ́ kíkẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí.

Ní December 1970, bí mo ṣe kẹ́kọ̀ọ́ yege tán báyìí, Gbọ̀ngàn Ìjọba ni mo forí lé. Mi ò sì pa ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ látìgbà yẹn. August 30, 1971, ni mo ṣèrìbọmi láti fi hàn pé mo ti ya ara mi sí mímọ́ fún Ọlọ́run. Kì í ṣe àwọn òbí mi nìkan lọkàn wọn gbọgbẹ́ nítorí èyí, ó tún mọ́kàn gbogbo ará abúlé wa gbọgbẹ́ pẹ̀lú. Wọ́n ní mo dójú ti àwọn, nítorí pé èmi lẹni tí ìjọba kọ́kọ́ fún ní ẹ̀bùn ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ ní gbogbo àgbègbè Ewossa. Ọ̀pọ̀ ń retí pé màá di ogún, màá di ọgbọ̀n. Ìrètí wọn ni pé màá fi ìwé tí mo kà mú ìgbéga bá abúlé wa.

Àbájáde Ṣíṣe Ẹ̀sìn Mìíràn

Ìdílé mi àtàwọn àgbààgbà ìlú rán àwọn ikọ̀ sí mi, pé kí wọ́n bá mi sọ̀rọ̀ kí n fi ẹ̀sìn yìí sílẹ̀. Kò jọ ègún, kò jọ èpè ló ń jáde lẹ́nu wọn. Wọ́n ní: “Bí o ò bá fi ẹ̀sìn yìí sílẹ̀, o fẹ́ bayé ara rẹ jẹ́ nìyẹn o. O ò ní ríṣẹ́. O ò ní kọ́lé. O ò ní lè fẹ́yàwó. O ò sì ní bímọ.”

Pẹ̀lú gbogbo bí wọ́n ti gégùn-ún tó yìí, oṣù mẹ́wàá lẹ́yìn tí mo jáde iléèwé ni mo rí iṣẹ́ tíṣà. October 1972 ni mo fẹ́ Veronica, ìyàwó mi àtàtà. Ẹ̀yìn ìyẹn ni ìjọba dá mi lẹ́kọ̀ọ́ kí n lè di alábòójútó ìtẹ̀síwájú iṣẹ́ ọ̀gbìn. Mo ra ọkọ̀ mi àkọ́kọ́. Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ilé wa. November 5, 1973, la bí Victory, ọmọbìnrin wa àkọ́kọ́. Ní àwọn ọdún tó tẹ̀ lé e, a bí Lydia, Wilfred, àti Joan. Ọdún 1986 la bí Micah, àbígbẹ̀yìn wa. Ọmọ gidi, tí Jèhófà fi jíǹkí mi, ni gbogbo wọn.—Sáàmù 127:3.

Bí mo ti ń ronú lórí ìgbésí ayé mi, mo lè sọ pé gbogbo èrò ibi táwọn aráàlú wa rò sí mi, rere ló já sí fún mi. Ìdí nìyẹn tí mo fi sọ àkọ́bí mi ní Victory [tó túmọ̀ sí Ìṣẹ́gun]. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àwọn aráàlú wa kọ̀wé sí mi pé: “Jọ̀wọ́, a fẹ́ kó o máa bọ̀ nílé, kó o wá lọ́wọ́ sí iṣẹ́ ìdàgbàsókè ìlú wa nísinsìnyí tí Ọlọ́run ti bù kún ọ.”

Títọ́ Àwọn Ọmọ Lọ́nà Ọlọ́run

Èmi àtìyàwó mi mọ̀ pé iṣẹ́ ọmọ títọ́ tí Ọlọ́run gbé lé wa lọ́wọ́ kò ní ṣeé ṣe, bí a bá gbájú mọ́ lílépa ọrọ̀. Ìdí nìyẹn tó fi tẹ́ wa lọ́rùn láti máa gbé ìgbé-ayé ṣe-bó-o-ti-mọ. A gbà pé ìyẹn dáa ju dídojúkọ àwọn ìṣòro tó wà nínú gbígbé ìgbésí ayé tó yàtọ̀.

Ní orílẹ̀-èdè wa, ó wọ́pọ̀ láti máa gbé ilé kan náà pẹ̀lú àwọn ìdílé mìíràn, tí a ó jọ máa lo ilé ìtura, ilé ìdáná, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ pa pọ̀. Inú wa dùn pé ilé fúláàtì la máa ń rẹ́ǹtì ní gbogbo ibi tí iṣẹ́ ìjọba bá gbé mi lọ. Òótọ́ ni pé irú ilé yẹn wọ́n ju àwọn ilé mìíràn lọ. Ṣùgbọ́n gbígbé irú ilé bẹ́ẹ̀ ni kò jẹ́ kí àwọn ọmọ wa kó ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé bí ọdún ti ń gorí ọdún, a ti tọ́ àwọn ọmọ wa ní àyíká tẹ̀mí.

Láfikún sí i, ńṣe ni ìyàwó mi ń jókòó ti àwọn ọmọ nílé. Nígbà tí mo bá tibi iṣẹ́ dé, a máa ń gbìyànjú láti ṣe nǹkan pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdílé. A máa ń ṣe gbogbo nǹkan bí òṣùṣù ọwọ̀ ni. Èyí kan ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ìdílé, mímúrasílẹ̀ àti lílọ sáwọn ìpàdé, jíjáde fún iṣẹ́ ìwàásù Kristẹni, àti lílọ sí òde afẹ́.

A gbìyànjú láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Diutarónómì 6:6, 7, tó rọ àwọn òbí pé kí wọ́n máa kọ́ àwọn ọmọ wọn, kì í ṣe nílé nìkan àmọ́ níbi gbogbo. Èyí mú káwọn ọmọ máa yan ọ̀rẹ́ láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí dípò àwọn èèyàn ayé. Wọ́n ti rí i nínú àpẹẹrẹ tiwa pé wọ́n gbọ́dọ̀ ṣọ́ àwọn tí wọ́n ń bá rìn, nítorí pé èmi àti Veronica kì í ṣe wọléwọ̀de pẹ̀lú àwọn tí ìgbàgbọ́ wọ́n yàtọ̀ sí tiwa.—Òwe 13:20; 1 Kọ́ríńtì 15:33.

Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe kìkì ìtọ́sọ́nà àti ẹ̀kọ́ tá à ń kọ́ wọn nìkan ló ní ipa rere lórí àwọn ọmọ wa. Ìgbà gbogbo la máa ń gba àwọn Kristẹni onítara lálejò, àwọn bí òjíṣẹ́ arìnrìn-àjò ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àkókò táwọn Kristẹni tó dàgbà dénú wọ̀nyí ń lò pẹ̀lú ìdílé wa ti fún àwọn ọmọ wa láǹfààní láti ṣàkíyèsí, kí wọ́n sì rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ àwọn wọ̀nyí. Èyí ti jẹ́ kí ẹ̀kọ́ tí à ń kọ́ wọn túbọ̀ wọ̀ wọ́n lọ́kàn, àwọn ọmọ sì ti sọ òtítọ́ Bíbélì di tiwọn.

Ìfọkànsin Ọlọ́run Mú Èrè Wá fún Mi

Lónìí, èmi àti ìyàwó mi, àti mẹ́rin lára àwọn ọmọ wa ló wà nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Èmi ni mo kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà lọ́dún 1973. Ó ti di dandan, bí ọdún ti ń gorí ọdún, láti dáwọ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún dúró lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan nítorí ọ̀ràn àtijẹ àtimu. Mo tún ń ní àǹfààní lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan láti kópa nínú kíkọ́ni ní Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Alàgbà àti Ìránṣẹ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́, ìyẹn ilé ẹ̀kọ́ tá a ti ń kọ́ àwọn Kristẹni tó jẹ́ alábòójútó láàárín àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ní lọ́wọ́lọ́wọ́, mo wà nínú Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn, èmi sì ni alábòójútó ìlú fún àwọn ìjọ Uhonmora.

Ọmọbìnrin mi àkọ́kọ́ àti èyí tó ṣìkejì, ìyẹn Victory àti Lydia, ń gbádùn lọ́dọ̀ ọkọ wọn. Àwọn Kristẹni alàgbà tó dáńgájíá ni wọ́n fẹ́. Àwọn àti ọkọ wọn ń sìn ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Igieduma, Nàìjíríà. Wilfred, àkọ́bí wa lọ́kùnrin, jẹ́ ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́. Micah, àbígbẹ̀yìn wa, máa ń ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Ọdún 1997 ni Joan jáde iléèwé girama, ó sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà déédéé.

Ara ìrírí tó máa ń wú mi lórí jù lọ nínú ìgbésí ayé mi ni ríran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti sin Jèhófà Ọlọ́run. Àwọn ẹbí mi wà lára àwọn tí mo ti ràn lọ́wọ́. Bàbá mi sapá láti sin Jèhófà, ṣùgbọ́n ìkóbìnrinjọ ò jẹ́. Látìgbà èwe mi ni mo ti fẹ́ràn àwọn èèyàn. Mo máa ń gbàgbé ìṣòro tara mi nígbà tí mo bá rí àwọn tí ìyà ń jẹ. Mo gbà pé àwọn èèyàn máa ń rí i pé tọkàntọkàn ni mo fi ń ran àwọn lọ́wọ́, ó sì ń jẹ́ kó rọrùn fún wọn láti bá mi sọ̀rọ̀.

Ọ̀kan lára àwọn tí mo ràn lọ́wọ́ láti mọ̀ nípa àwọn ète Ọlọ́run ni ọ̀dọ́kùnrin kan tí àìsàn tó ń ṣe é kò jẹ́ kó lè dìde ńlẹ̀. Òṣìṣẹ́ iléeṣẹ́ mànàmáná ni. Ọjọ́ kan lẹ́nu iṣẹ́ ni iná gbé e tó sì mú kí ara rẹ̀ rọ láti àyà sísàlẹ̀. Ó gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó tẹ́wọ́ gba ohun tí ó ń kọ́. Ìgbà tó ṣe ìrìbọmi ní October 14, 1995, nínú odò kan nítòsí ilé wa, ni ìgbà àkọ́kọ́ tó kúrò lórí bẹ́ẹ̀dì rẹ̀ láti ọdún kẹẹ̀ẹ́dógún tó ti dùbúlẹ̀. Ó sọ pé ọjọ́ yẹn lòun láyọ̀ jù lọ láyé òun. Ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ni nísinsìnyí nínú ìjọ.

Mi ò kábàámọ̀ rárá fún yíyàn tí mo ṣe ní nǹkan bí ọgbọ̀n ọdún sẹ́yìn, láti sin Jèhófà pẹ̀lú àwọn èèyàn rẹ̀ tí wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́ fún un, tí wọ́n sì wà níṣọ̀kan. Mo ti rí ìfẹ́ tòótọ́ láàárín wọn. Ká tiẹ̀ sọ pé ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun kò sí lára èrè tí Jèhófà fẹ́ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́, màá ṣì fẹ́ láti máa gbé ìgbé-ayé ìfọkànsin Ọlọ́run. (1 Tímótì 6:6; Hébérù 11:6) Èyí ló jẹ́ kí ayé mi lójú, tó tòrò minimini, tó sì mú ìdùnnú, ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn wá fún èmi àti ìdílé mi.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Èmi àti aya mi àtàwọn ọmọ mi lọ́dún 1990

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Èmi àti aya mi àtàwọn ọmọ mi àtàwọn ọkọ ọmọ mi méjì